ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Hùwà Ọlọgbọ́n
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 12 Nábálì bínú gidigidi! Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Ábígẹ́lì, ó ní Nábálì “fi ìkanra sọ̀rọ̀ sí wọn.” Ṣe ni Nábálì ahun fárígá, tó bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé òun kò lè fún wọn ní búrẹ́dì aládùn òun, omi òun àtàwọn ẹran àtàtà tóun pa. Ó wá ń láálí Dáfídì pé kò já mọ́ nǹkan kan, pé ìsáǹsá ìránṣẹ́ tó sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò kan náà ni Nábálì àti Sọ́ọ̀lù, tó kórìíra Dáfídì ní. Àwọn méjèèjì kò fi ojú tí Jèhófà fi ń wo Dáfídì wò ó. Ọlọ́run fẹ́ràn Dáfídì, kò sì fojú ìránṣẹ́ tó ya ọlọ̀tẹ̀ wò ó. Kàkà bẹ́ẹ̀ ojú ẹni tó máa jọba Ísírẹ́lì láìpẹ́ ló fi ń wò ó.—1 Sám. 25:10, 11, 14.

  • Ó Hùwà Ọlọgbọ́n
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 14. (a) Kí ni Ábígẹ́lì ṣe tó fi hàn pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ tó máa jẹ́ kó lè yanjú ìṣòro tí Nábálì dá sílẹ̀? (b) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ìwà Ábígẹ́lì tó yàtọ̀ sí ti Nábálì? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      14 A ti rí i níṣàájú pé, dé ìwọ̀n àyè kan, Ábígẹ́lì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ tó máa jẹ́ kó lè yanjú ìṣòro ńlá tí Nábálì dá sílẹ̀ yìí. Ó tẹ́tí sílẹ̀ ní tirẹ̀, kò ṣe bíi ti Nábálì ọkọ rẹ̀. Ohun tí ìránṣẹ́ tó bá Ábígẹ́lì sọ̀rọ̀ sọ pé ó fà á tí òun kò fi sọ fún Nábálì ni pé ó jẹ́ “àwé tí kò dára fún ohunkóhun rárá láti bá sọ̀rọ̀.”c (1 Sám. 25:17) Ó mà ṣe o, Nábálì jọra rẹ̀ lójú débi pé kì í fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. Irú ìwà ìjọra-ẹni-lójú bẹ́ẹ̀ ṣì wọ́pọ̀ gan-an títí dòní. Àmọ́, ọ̀dọ́kùnrin yẹn mọ̀ pé Ábígẹ́lì yàtọ̀ ní tiẹ̀, ìdí sì nìyẹn tó fi lọ ṣàlàyé ìṣòro tó wà nílẹ̀ fún un.

      Ábígẹ́lì tẹ́tí sílẹ̀ ní tirẹ̀, kò ṣe bíi ti Nábálì

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́