ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Hùwà Ọgbọ́n
    Ilé Ìṣọ́—2009 | July 1
    • Báwo làwọn akíkanjú ọmọ ogun Dáfídì ṣe máa ń ṣe sáwọn tó ń bá Nábálì da ẹran? Kò nira fún wọn láti máa jí àgùntàn wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n dà bí ògiri tó ń dàábò bo agbo ẹran àtàwọn ìránṣẹ́ Nábálì. (1 Sámúẹ́lì 25:15, 16) Ewu tó pọ̀ ló máa ń dojú kọ àgùntàn àtàwọn tó ń dà wọ́n. Àwọn ẹranko tó lè ṣèpalára fáwọn àgùntàn pọ̀ gan-an nígbà yẹn. Wọ́n sì ti ti ibodè tó wà lápá gúúsù tó wọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pa, torí náà àwọn olè máa ń ṣọṣẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà.b

  • Ó Hùwà Ọgbọ́n
    Ilé Ìṣọ́—2009 | July 1
    • b Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì máa rò ó pé dídáàbò bo àwọn onílẹ̀ àti agbo ẹran wọn jẹ́ iṣẹ́ ìsìn kan sí Jèhófà Ọlọ́run. Nígbà yẹn, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé káwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù máa gbé nílẹ̀ náà. Torí náà, dídáàbò bo ilẹ̀ yẹn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá àtàwọn olè jẹ́ ìjọsìn mímọ́.

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́