ORÍ KẸJỌ
Ó Lo Ìfaradà Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Wọ́n Já A Kulẹ̀
1. Kí ló fà á tí àwọn ará Ṣílò fi banú jẹ́ gan-an tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀?
SÁMÚẸ́LÌ mọ̀ pé ìbànújẹ́ kékeré kọ́ ló bá àwọn ará Ṣílò. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ilé kan ní ìlú náà tí àwọn èèyàn ò ti máa da omi lójú pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. Mélòó la sì fẹ́ kà lára àwọn obìnrin tó ń sunkún nítorí àwọn ọkọ àtàwọn ọmọ wọn; àwọn ọmọdé tó ń sunkún nítorí àwọn bàbá wọ́n; àti bí gbogbo wọn lápapọ̀ ṣe ń sunkún torí àwọn ìbátan wọn tí wọ́n gbọ́ pé wọ́n ti kú sójú ogun? Nígbà tí àwọn Filísínì kọ́kọ́ bá àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì jà, wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] lára àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì. Àmọ́, láìpẹ́ sígbà yẹn tí wọ́n tún fìjà pẹẹ́ta pẹ̀lú wọn, nǹkan bí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [30,000] lára àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ló bá a lọ.—1 Sám. 4:1, 2, 10.
2, 3. Àwọn àrélù wo ló kó àbùkù bá ìlú Ṣílò tó sì mú kí ògo rẹ̀ wọmi?
2 Díẹ̀ lèyí jẹ́ lára àwọn àrélù tàbí ọ̀wọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó wáyé ní Ṣílò. Àwọn ọmọkùnrin méjì tí Élì Àlùfáà Àgbà bí, ìyẹn Hófínì àti Fíníhásì tí wọ́n jẹ́ ọmọkọ́mọ, gbé àpótí ẹ̀rí jáde kúrò ní ìlú Ṣílò. Ohun mímọ́ ni àpótí ẹ̀rí yìí, inú ibi mímọ́ jù lọ nínú àgọ́ ìjọsìn ni wọ́n sì máa ń gbé e sí. Àpótí ṣíṣeyebíye náà jẹ́ àmì pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn èèyàn náà gbé Àpótí náà lọ sójú ogun, wọ́n rò pé ó máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí oògùn oríire tó máa mú kí wọ́n ja àjàṣẹ́gun. Èrò òmùgọ̀ pátápátá mà lèyí o! Ńṣe làwọn Filísínì gba Àpótí náà, wọ́n sì pa Hófínì àti Fíníhásì.—1 Sám. 4:3-11.
3 Bí àpótí ẹ̀rí yìí ṣe wà ní Ṣílò láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún máa ń buyì kún àgọ́ ìjọsìn tó wà níbẹ̀. Àmọ́, àwọn ọ̀tá ti gba Àpótí náà báyìí. Nígbà tí Élì tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98] gbọ́ ìròyìn yìí, ńṣe ló ṣubú sẹ́yìn láti ibi tó jókòó sí, ó sì kú. Lọ́jọ́ yẹn ni ìyàwó ọmọ Élì di opó, ọjọ́ yẹn náà ló sì kú nígbà tó ń bímọ. Bó ṣe ń kú lọ, ó sọ pé: “Ògo ti fi Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ sí ìgbèkùn.” Kò sí àní-àní pé Ṣílò kò ní rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.—1 Sám. 4:12-22.
4. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí?
4 Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe máa fara da àwọn ìjákulẹ̀ tó lé kenkà yìí? Ní báyìí, Jèhófà ti fa ọwọ́ ààbò àti ojú rere rẹ̀ sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ṣé ìgbàgbọ́ Sámúẹ́lì wá lágbára débi táá fi lè ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́? Lóde òní, àwọn ìgbà míì wà tá a lè rí àwọn ìnira àti ìjákulẹ̀ tó máa dán ìgbàgbọ́ wa wò, torí náà, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a tún lè rí kọ́ lára Sámúẹ́lì.
Ó “Ṣiṣẹ́ Òdodo Yọrí”
5, 6. Kí ni Bíbélì sọ pé ó ṣẹlẹ̀ láàárín ogún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n gba àpótí ẹ̀rí? Kí ni Sámúẹ́lì ń ṣe ní gbogbo ìgbà yẹn?
5 Láàárín àkókò yìí, Bíbélì yà bàrà kúrò lórí ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa Àpótí mímọ́ náà. Ó sọ bí àwọn Filísínì ṣe jìyà torí pé wọ́n gbé Àpótí náà àti bí wọ́n ṣe dá a pa dà lọ́ranyàn. Ogún ọdún ti kọjá kí Bíbélì tó máa bá ọ̀rọ̀ lọ nípa Sámúẹ́lì. (1 Sám. 7:2) Kí ló ń ṣe láwọn ọdún wọ̀nyẹn? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀.
6 Bíbélì sọ pé kí ogún ọdún náà tó bẹ̀rẹ̀, “ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ ní títọ gbogbo Ísírẹ́lì wá.” (1 Sám. 4:1) Ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé lẹ́yìn ogún ọdún náà, Sámúẹ́lì máa ń ṣèbẹ̀wò déédéé sí àwọn ìlú mẹ́ta kan ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ó máa ń lọ yí ká àwọn ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lọ́dún láti yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín àwọn èèyàn kó sì tún dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Lẹ́yìn náà, á fi àbọ̀ sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ní Rámà. (1 Sám. 7:15-17) Ó ṣe kedere pé ọwọ́ Sámúẹ́lì máa ń dí, ó sì ní iṣẹ́ púpọ̀ tó ń ṣe láàárín ogún ọdún yẹn.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa Sámúẹ́lì fún ogún ọdún, ó dájú pé ńṣe ló ń bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lọ ní pẹrẹu
7, 8. (a) Kí ni Sámúẹ́lì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tó ti ṣiṣẹ́ àṣekára fún ogún ọdún? (b) Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lẹ́yìn ọ̀rọ̀ tí Sámúẹ́lì bá wọn sọ?
7 Ìwà pálapàla àti ìwà ìbàjẹ́ tí àwọn ọmọ Élì ń hù ti mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìnrìn. Ó sì jọ pé èyí mú kí ọ̀pọ̀ nínú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà. Àmọ́, lẹ́yìn tí Sámúẹ́lì ti ṣiṣẹ́ àṣekára fún ogún ọdún kí àwọn èèyàn náà lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sọ fún wọn pé: “Bí ó bá jẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà yín ni ẹ fi ń padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ mú àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè kúrò ní àárín yín àti àwọn ère Áṣítórétì pẹ̀lú, kí ẹ sì darí ọkàn-àyà yín sọ́dọ̀ Jèhófà láìyà bàrá, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo, yóò sì dá yín nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn Filísínì.”—1 Sám. 7:3.
8 Ìyà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ ní “ọwọ́ àwọn Filísínì” kúrò ní kékeré. Lẹ́yìn tí àwọn Filísínì ti ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, wọ́n ronú pé àwọn lè máa ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára láìsí ẹni tó máa yẹ àwọn lọ́wọ́ wò. Àmọ́, Sámúẹ́lì fi dá àwọn èèyàn náà lójú pé bí wọ́n bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà nìkan làwọn nǹkan máa yí pa dà. Ṣé wọ́n gbà láti pa dà? Bẹ́ẹ̀ ni. Inú Sámúẹ́lì dùn gan-an nígbà tí wọ́n kó àwọn ère wọn dà nù, tí wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà nìkan ṣoṣo.” Sámúẹ́lì pe àwọn èèyàn náà jọ sí Mísípà, ìyẹn ìlú kan tó wà ní àgbègbè tí àwọn òkè pọ̀ sí ní àríwá Jerúsálẹ́mù. Gbogbo wọ́n pé jọ, wọ́n sì gbààwẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ tó pọ̀ torí pé wọ́n ń bọ òrìṣà, wọ́n ronú pìwà dà.—Ka 1 Sámúẹ́lì 7:4-6.
Àwọn Filísínì rò pé bí àwọn èèyàn Jèhófà tó ti ronú pìwà dà ṣe pé jọ ní Mísípà máa fún àwọn ní àǹfààní láti fínná mọ́ wọn
9. Àǹfààní wo ni àwọn Filísínì gbà pé ó ṣí sílẹ̀ fún àwọn? Kí ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe nígbà tí wọ́n wà nínú ewu?
9 Àmọ́ nígbà tí àwọn Filísínì gbọ́ nípa àpéjọ ńlá yìí, wọ́n gbà pé àǹfààní ti sílẹ̀ fún wọn láti rẹ́yìn àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n rán àwọn ọmọ ogun wọn lọ sí Mísípà láti pa àwọn olùjọ́sìn Jèhófà tó wà níbẹ̀ run. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti ń kó ogun bọ̀ wá bá àwọn, ìbẹ̀rùbojo mú wọn, wọ́n sì ní kí Sámúẹ́lì gbàdúrà fún àwọn. Sámúẹ́lì gbàdúrà fún wọn, ó sì tún rúbọ. Ẹbọ yìí ni Sámúẹ́lì ń rú lọ́wọ́ nígbà tí àwọn ọmọ ogun Filísínì dé sí Mísípà. Jèhófà wá dáhùn àdúrà Sámúẹ́lì. Ó bínú torí ìwà ọ̀yájú tí àwọn Filísínì hù, ó sì “mú kí ààrá sán . . . pẹ̀lú ariwo dídún ròkè lu àwọn Filísínì ní ọjọ́ yẹn.”—1 Sám. 7:7-10.
10, 11. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé kì í ṣe ààrá lásán ni Jèhófà rán sí àwọn ọmọ ogun Filísínì? (b) Kí ni àbájáde ogun tó bẹ̀rẹ̀ ní Mísípà?
10 Ṣé ó wá yẹ ká rò pé ńṣe ni àwọn ọmọ ogun Filísínì yẹn dà bí àwọn ọmọdé tí ẹ̀rù máa ń bà tí ààrá bá sán, tí wọ́n á sì sá sẹ́yìn ìyá wọn? Rárá o! Akíkanjú tí kì í rí ogun sá ni wọn o! Torí náà, ààrá yìí ti ní láti yàtọ̀ pátápátá sí èyíkéyìí tí wọ́n tíì gbọ́ rí. Àbí ìró “ariwo dídún ròkè” ààrá náà ló ṣẹ̀rù bà wọ́n? Ṣé ààrá kàn ṣàdédé ń sán pàràpàrà láìjẹ́ pé òjò ṣú ni àbí àárín àwọn òkè ni ariwo rẹ̀ tó ń dẹ́rù bani ti ń wá? A kò lè sọ, ṣùgbọ́n ohun tá a mọ̀ ni pé ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ogun Filísínì yẹn, ṣìbáṣìbo sì bá wọn. Gbogbo nǹkan dojú rú fún wọn débi pé wọ́n sá níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì rọ́ jáde láti Mísípà, wọ́n ṣẹ́gun àwọn Filísínì, wọ́n sì lépa wọn jìnnà, títí tí wọ́n fi dé ibì kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù.—1 Sám. 7:11.
11 Àyípadà ńlá ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ńṣe làwọn Filísínì ń sá níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìyókù àkókò tí Sámúẹ́lì fi jẹ́ onídàájọ́. Àwọn èèyàn Ọlọ́run sì gba gbogbo ìlú wọn pa dà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.—1 Sám. 7:13, 14.
12. Kí ló túmọ̀ sí pé Sámúẹ́lì “ṣiṣẹ́ òdodo yọrí”? Àwọn ànímọ́ wo ló jẹ́ kó máa ṣe àṣeyọrí?
12 Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dárúkọ Sámúẹ́lì mọ́ àwọn onídàájọ́ àti wòlíì olóòótọ́ tí wọ́n “ṣiṣẹ́ òdodo yọrí.” (Héb. 11:32, 33) Ó dájú pé Sámúẹ́lì ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ tó fi di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó dára àti èyí tó tọ́ lójú Ọlọ́run. Ìdí tó fi ṣe àṣeyọrí ni pé ó fi sùúrù dúró de Jèhófà, ó sì ń fi ìṣòtítọ́ bá iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó láìka ìjákulẹ̀ sí. Ó tún ní ẹ̀mí ìmọrírì. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn Filísínì ní Mísípà, Sámúẹ́lì ṣe ọwọ̀n kan kó lè máa rán àwọn èèyàn létí bí Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́.—1 Sám. 7:12.
13. (a) Àwọn ànímọ́ wo la gbọ́dọ̀ ní tá a bá fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì? (b) Ìgbà wo lo rò pé ó yẹ ká ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní irú àwọn ànímọ́ tí Sámúẹ́lì ní?
13 Ǹjẹ́ ó wu ìwọ náà pé kó o ‘ṣiṣẹ́ òdodo yọrí’? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun tó dára ni pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ lára Sámúẹ́lì kó o lè ní sùúrù, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmọrírì bíi tirẹ̀. (Ka 1 Pétérù 5:6.) Gbogbo wa ló yẹ ká ní àwọn ànímọ́ yẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àǹfààní ló jẹ́ fún Sámúẹ́lì pé láti kékeré ló ti ní àwọn ànímọ́ yẹn tó sì ń fi wọn ṣèwà hù, torí pé ó ní ọ̀pọ̀ ìjákulẹ̀ nígbà tó dàgbà.
“Àwọn Ọmọkùnrin Tìrẹ Kò Rìn ní Àwọn Ọ̀nà Rẹ”
14, 15. (a) Ìjákulẹ̀ ńlá wo ni Sámúẹ́lì ní nígbà tó “darúgbó”? (b) Ṣé baba bíi Élì tí kò ṣe ojúṣe rẹ̀ ni Sámúẹ́lì? Ṣàlàyé.
14 Sámúẹ́lì ti “darúgbó” báyìí. Ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n ti dàgbà, ìyẹn Jóẹ́lì àti Ábíjà, ó sì yàn wọ́n láti máa ran òun lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ onídàájọ́. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ̀ kò ṣeé fọkàn tán. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sámúẹ́lì jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo, ńṣe làwọn ọmọ rẹ̀ ń fi ipò wọn wá ire ara wọn, wọ́n ń ṣe èrú nínú ìdájọ́, wọ́n sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.—1 Sám. 8:1-3.
15 Lọ́jọ́ kan, àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì lọ fẹjọ́ sun wòlíì tó ti dàgbà yìí. Wọ́n sọ fún un pé: “Àwọn ọmọkùnrin tìrẹ kò rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ.” (1 Sám. 8:4, 5) Ǹjẹ́ Sámúẹ́lì mọ̀ nípa ìwà táwọn ọmọ rẹ̀ ń hù yìí? Bíbélì kò sọ fún wa. Àmọ́ ó dájú pé Sámúẹ́lì ò dà bíi Élì tí kò ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi baba. Jèhófà bá Élì wí, ó sì fìyà jẹ ẹ́, torí pé kò bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí nígbà tí wọ́n ń hùwà burúkú, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ju Ọlọ́run lọ. (1 Sám. 2:27-29) Jèhófà ò rí irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ Sámúẹ́lì.
16. Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn òbí nígbà tí ọmọ wọn bá ya aláìgbọràn? Ìtọ́sọ́nà àti ìtùnú wo làwọn òbí lè rí nínú àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì?
16 Nígbà tí wọ́n sọ fún Sámúẹ́lì nípa ìwà burúkú tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń hù, Bíbélì ò sọ fún wa bí ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ ṣe pọ̀ tó nítorí ìtìjú, àníyàn tàbí ìjákulẹ̀ tó ní. Àmọ́ ọ̀pọ̀ òbí ló máa mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ̀. Ní àkókò búburú tá à ń gbé yìí, kárí ayé làwọn ọmọ ń tàpá sí àṣẹ àwọn òbí, tí wọ́n sì ń kọ ìbáwí. (Ka 2 Tímótì 3:1-5.) Àmọ́, dé ìwọ̀n àyè kan, àwọn òbí tí irú nǹkan yìí bá ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá lè rí ìtùnú àti ìtọ́sọ́nà látinú ohun tí Sámúẹ́lì ṣe. Sámúẹ́lì ò jẹ́ kí ìwà àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò ní ìgbàgbọ́ mú kí ìgbàgbọ́ tirẹ̀ yingin rárá. Ẹ sì máa rántí pé bí ọkàn àwọn ọmọ bá tiẹ̀ ti yigbì débi tí ọ̀rọ̀ àti ìbáwí kò fi lè yí i pa dà, àpẹẹrẹ rere tí ẹ̀yin òbí bá fi lélẹ̀ lè wọ irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ lọ́kàn. Bíi ti Sámúẹ́lì, ẹ̀yin òbí ní àǹfààní láti máa mú inú Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba yín ọ̀run dùn nígbà gbogbo.
“Yan Ọba Sípò fún Wa”
17. Kí ni àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì ní kí Sámúẹ́lì ṣe? Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lójú Sámúẹ́lì?
17 Ibi tí àwọn ọmọ Sámúẹ́lì kò fọkàn sí rárá ni ìwà wọ̀bìà àti ìmọtara-ẹni-nìkan wọn yọrí sí. Àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Wàyí o, yan ọba sípò fún wa láti máa ṣe ìdájọ́ wa bí ti gbogbo orílẹ̀ èdè.” Ǹjẹ́ Sámúẹ́lì wo ohun tí wọ́n béèrè yìí bíi pé òun ni wọ́n kọ̀ sílẹ̀? Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ ọdún ló ti fi ṣe onídàájọ́ àwọn èèyàn náà gẹ́gẹ́ bí aṣojú Jèhófà. Àmọ́ ní báyìí, wọn ò fẹ́ kí wòlíì lásán bíi ti Sámúẹ́lì máa ṣe onídàájọ́ wọn mọ́, ọba ni wọ́n ń fẹ́. Ọba ló ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè tó yí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ká, àwọn pẹ̀lú sì fẹ́ láti ní ọba tiwọn. Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lójú Sámúẹ́lì? Bíbélì sọ pé “ohun náà burú ní ojú Sámúẹ́lì.”—1 Sám. 8:5, 6.
18. Báwo ni Jèhófà ṣe tu Sámúẹ́lì nínú, tó sì tún fi bí ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe wúwo tó hàn?
18 Wàyí o, gbọ́ ohun tí Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì nígbà tó gbàdúrà sí i lórí ọ̀ràn náà. Ó ní: “Fetí sí ohùn àwọn ènìyàn náà ní ti gbogbo ohun tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ni wọ́n kọ̀ ní ọba lórí wọn.” Ọ̀rọ̀ yìí tu Sámúẹ́lì nínú gan-an, síbẹ̀, ìwà àrífín gbáà làwọn èèyàn náà hù sí Ọlọ́run Olódùmarè! Jèhófà ní kí wòlíì rẹ̀ sọ ohun tí ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rí tí èèyàn bá ń ṣàkóso wọn gẹ́gẹ́ bí ọba. Nígbà tí Sámúẹ́lì sọ ọ̀rọ̀ náà fún wọn, ńṣe ni wọ́n fi àáké kọ́rí pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ọba ni yóò wá wà lórí wa.” Gbogbo ìgbà ni Sámúẹ́lì máa ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run rẹ̀. Torí náà, ó lọ ta òróró sórí ọba tí Jèhófà yàn.—1 Sám. 8:7-19.
19, 20. (a) Nígbà tí Jèhófà ní kí Sámúẹ́lì fi Sọ́ọ̀lù jọba lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, báwo ló ṣe ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un? (b) Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe ń bá a nìṣó láti máa ran àwọn èèyàn Jèhófà lọ́wọ́?
19 Àmọ́, báwo ni Sámúẹ́lì ṣe ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un? Ṣé tìbínú-tìbínú ni àbí láìbìkítà? Ṣé bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi àáké kọ́rí dá ọgbẹ́ sí i lọ́kàn, tó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí kò dára nípa wọn? Bóyá ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣe nìyẹn, àmọ́ Sámúẹ́lì ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó fòróró yan Sọ́ọ̀lù, ó sì gbà pé ọkùnrin yìí ni Jèhófà yàn. Ó fẹnu ko Sọ́ọ̀lù lẹ́nu, èyí tó túmọ̀ sí pé ó tẹ́wọ́ gba ọba tuntun náà ó sì ṣe tán láti máa tẹrí ba fún un. Ó wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ṣé ẹ rí ẹni tí Jèhófà yàn, pé kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn?”—1 Sám. 10:1, 24.
20 Ibi tí ọkùnrin tí Jèhófà yàn yìí dáa sí ni Sámúẹ́lì ń wò, kì í ṣe ibi tó kù díẹ̀ káàtó sí. Àmọ́ ojú wo ni Sámúẹ́lì fi ń wo ara rẹ̀? Ìwà títọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run ló ń fún un láyọ̀, kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà àwọn èèyàn tí kò láyọ̀lé ló ń wá. (1 Sám. 12:1-4) Ó tún fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́. Ó ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run nípa àwọn ohun tó lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ó ń fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n má ṣe fi Jèhófà sílẹ̀. Ìmọ̀ràn tí Sámúẹ́lì gbà wọ́n yìí wọ̀ wọ́n lọ́kàn, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kò gbàdúrà nítorí àwọn. Ó fún wọn ní èsì tó dára yìí pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, láti ṣẹ̀ sí Jèhófà nípa ṣíṣíwọ́ láti gbàdúrà nítorí yín; èmi yóò sì fún yín ní ìtọ́ni ní ọ̀nà rere àti títọ́.”—1 Sám. 12:21-24.
Àpẹẹrẹ tí Sámúẹ́lì fi lélẹ̀ rán wa létí pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí owú tàbí ìbínú kíkorò jọba lọ́kàn wa
21. Tó bá ti dùn ẹ́ rí pé wọ́n fún ẹlòmíì ní ipò tàbí àǹfààní kan tó o rò pé ìwọ ló tọ́ sí, báwo ni àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
21 Ǹjẹ́ ó ti dùn ẹ́ rí pé wọ́n fún ẹlòmíì ní ipò tàbí àǹfààní kan tó o rò pé ìwọ ló tọ́ sí? Ó yẹ kí àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì máa rán wa létí pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí owú tàbí ìbínú kíkorò jọba lọ́kàn wa. (Ka Òwe 14:30.) Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó lérè tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́.
“Yóò Ti Pẹ́ Tó Tí Ìwọ Yóò Fi Máa Ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù?”
22. Kí nìdí tí Sámúẹ́lì fi tọ̀nà nígbà tó sọ pé ohun rere lòun rí lára Sọ́ọ̀lù nígbà tó kọ́kọ́ di ọba?
22 Sámúẹ́lì tọ̀nà nígbà tó sọ pé òun rí ohun rere lára Sọ́ọ̀lù, torí pé ó ní àwọn ànímọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó ga, ó sígbọnlẹ̀, ó nígboyà, ó mọ bó ṣe lè yanjú ìṣòro àti pé kó tó di ọba, ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (1 Sám. 10:22, 23, 27) Yàtọ̀ sí àwọn ànímọ́ yìí, ó tún ní ohun kan tó ṣeyebíye gan-an, ìyẹn ni òmìnira láti yan ohun tó wù ú kó sì dá ṣe ìpinnu. (Diu. 30:19) Ǹjẹ́ ó lo ẹ̀bùn yìí lọ́nà rere?
23. Kí ni Sọ́ọ̀lù ò ní mọ́ láìpẹ́ tó di ọba? Báwo ló ṣe fi hàn pé ìgbéraga ti ń wọ òun lẹ́wù?
23 Ó bani nínú jẹ́ pé ìrẹ̀lẹ̀ ló sábà máa ń kọ́kọ́ sọ nù nínú ìwà èèyàn nígbà téèyàn bá dépò agbára. Kò pẹ́ tí Sọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. Ó yàn láti kọ etí ikún sí àṣẹ Jèhófà tí Sámúẹ́lì sọ fún un. Lọ́jọ́ kan, torí pé Sọ́ọ̀lù kò ní sùúrù tó bó ṣe yẹ, ó rú ẹbọ tó yẹ kí Sámúẹ́lì rú. Sámúẹ́lì ní láti bá Sọ́ọ̀lù wí lọ́nà tó múná, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run á yàn ìdílé míì láti máa jọba dípò ìdílé Sọ́ọ̀lù. Kàkà tí Sọ́ọ̀lù ì bá fi kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìbáwí náà, ńṣe ló túbọ̀ ń ṣe àìgbọràn tó burú jáì.—1 Sám. 13:8, 9, 13, 14.
24. (a) Báwo ni Sọ́ọ̀lù ṣe ṣàìgbọràn sí Jèhófà nígbà tó lọ bá àwọn Ámálékì jagun? (b) Kí ni Sọ́ọ̀lù ṣe nígbà tí wọ́n bá a wí? Kí ni Jèhófà pinnu pé òun máa ṣe?
24 Jèhófà ní kí Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé kó lọ bá àwọn ará Ámálékì jagun. Ara ìtọ́ni tí Jèhófà fún un ni pé kó pa ọba wọn, ìyẹn Ágágì tó jẹ́ ọba búburú. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù dá Ágágì sí àtàwọn tó dára jù lára àwọn ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n pa run. Nígbà tí Sámúẹ́lì lọ bá Sọ́ọ̀lù wí lórí ọ̀ràn yìí, Sọ́ọ̀lù fi hàn pé òun ti yàtọ̀ sí irú ẹni tí òun jẹ́ níbẹ̀rẹ̀. Kàkà kó fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí yìí, ńṣe ló ń wá àwáwí tó sì ń wí àwíjàre. Ó tilẹ̀ fẹ́ dọ́gbọ́n fi ọ̀rọ̀ míì bo ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀, ó sì gbìyànjú láti di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ru àwọn èèyàn. Sọ́ọ̀lù ò fẹ́ fara mọ́ ìbáwí náà, torí náà, ó sọ pé ńṣe ni òun fẹ́ fi díẹ̀ lára ẹrù náà rúbọ sí Jèhófà. Èyí mú kí Sámúẹ́lì sọ ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa yìí pé: “Kíyèsí i, ìgbọràn sàn jù ẹbọ lọ.” Sámúẹ́lì wá fi ìgboyà bá Sọ́ọ̀lù wí, ó sì jẹ́ kó mọ ìpinnu Jèhófà pé: Ìṣàkóso náà máa kúrò lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù, Ọlọ́run á sì fún ọkùnrin míì tó sàn jù ú lọ.a—1 Sám. 15:1-33, Bíbélì Mímọ́.
25, 26. (a) Kí nìdí tí Sámúẹ́lì fi ṣọ̀fọ̀ nítorí Sọ́ọ̀lù? Báwo ni Jèhófà ṣe rọra tún ojú tí wòlíì rẹ̀ fi wo ọ̀rọ̀ náà ṣe? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni Sámúẹ́lì kọ́ nígbà tó lọ sí ilé Jésè?
25 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe ya aláìgbọràn àti agbéraga yìí da Sámúẹ́lì lọ́kàn rú gan-an. Ńṣe ló fi gbogbo òru ké pe Jèhófà lórí ọ̀ràn náà. Ó tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀. Sámúẹ́lì ti wòye bí àwọn ohun rere tí Sọ́ọ̀lù lè ṣe ti pọ̀ tó, àmọ́ gbogbo ìrètí rẹ̀ ti wọmi báyìí. Sọ́ọ̀lù ti yàtọ̀ sí irú ẹni tó jẹ́ tẹ́lẹ̀, ó ti sọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó dára jù lọ nù, ó sì ti kẹ̀yìn sí Jèhófà. Torí náà, Sámúẹ́lì ò pa dà rí Sọ́ọ̀lù mọ́. Àmọ́, nígbà tó ṣe, Jèhófà rọra tún ojú tí Sámúẹ́lì fi wo ọ̀rọ̀ náà ṣe. Ó ní: “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi máa ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù, nígbà tí ó jẹ́ pé èmi, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ti kọ̀ ọ́ láti máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì? Fi òróró kún ìwo rẹ, kí o sì lọ. Èmi yóò rán ọ lọ sọ́dọ̀ Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí pé mo ti pèsè ọba fún ara mi lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.”—1 Sám. 15:34, 35; 16:1.
26 Jèhófà kì í dúró de ẹ̀dá èèyàn aláìpé tí ọkàn rẹ̀ lè ṣàdédé yí pa dà kó tó ṣe ohun tó pinnu. Bí ẹnì kan bá di aláìṣòótọ́, Jèhófà á yan ẹlòmíì tó máa ṣe ohun tó fẹ́. Torí náà, Sámúẹ́lì tó ti di arúgbó kò kẹ́dùn nítorí Sọ́ọ̀lù mọ́. Jèhófà wá rán Sámúẹ́lì lọ sí ilé Jésè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Nígbà tó débẹ̀, ó rí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí ìrísí wọn dára. Àmọ́ bí ọmọkùnrin àkọ́kọ́ ṣe wá sí iwájú Sámúẹ́lì ni Jèhófà ti rán an létí pé kó má ṣe wo ìrísí rẹ̀ nìkan. (Ka 1 Sámúẹ́lì 16:7.) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n pe ọmọkùnrin tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn Jésè wá síwájú Sámúẹ́lì. Dáfídì ni orúkọ rẹ̀, òun sì ni Jèhófà yàn!
Ó yé Sámúẹ́lì pé kò sí ipò èyíkéyìí tàbí ìṣòro tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni tó kọjá agbára Jèhófà, kò sì pọ̀ jù fún un láti sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ di ìbùkún
27. (a) Kí ló mú kí ìgbàgbọ́ Sámúẹ́lì túbọ̀ máa lágbára? (b) Kí ni èrò rẹ nípa àpẹẹrẹ tí Sámúẹ́lì fi lélẹ̀?
27 Bí Sámúẹ́lì ṣe ń darúgbó lọ, ó túbọ̀ ń ṣe kedere sí i pé Jèhófà ò ṣi Dáfídì yan àti pé ó tọ́ bó ṣe fi í rọ́pò Sọ́ọ̀lù. Sọ́ọ̀lù jowú Dáfídì débi tó fi ń wá ọ̀nà láti pa á, ó sì tún di apẹ̀yìndà. Àmọ́ Dáfídì ní tirẹ̀ fi àwọn ànímọ́ rere hàn, irú bí ìgboyà, ìwà títọ́, ìgbàgbọ́ àti ìdúróṣinṣin. Bí Sámúẹ́lì ṣe túbọ̀ ń darúgbó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe ń lágbára sí i. Ó yé e pé kò sí ipò èyíkéyìí tàbí ìṣòro tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni tó kọjá agbára Jèhófà, kò sì pọ̀ jù fún un láti sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ di ìbùkún. Níkẹyìn, Sámúẹ́lì kú nígbà tó kù díẹ̀ kó pé ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, ìgbésí ayé rere ló sì gbé. Torí náà, kò yani lẹ́nu pé gbogbo Ísírẹ́lì ló ṣọ̀fọ̀ ọkùnrin olóòótọ́ yìí! Ó yẹ kí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní máa bi ara wa pé, ‘Ṣé màá ní irú ìgbàgbọ́ tí Sámúẹ́lì ní?’
a Sámúẹ́lì fúnra rẹ̀ ló pa Ágágì. Kò yẹ kí wọ́n fi ojú àánú hàn sí ọba búburú yìí àti ìdílé rẹ̀. Ẹ̀rí tó dájú wà pé ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ágágì ni “Hámánì ọmọ Ágágì.” Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló gbé ayé, ó sì gbìyànjú láti pa gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run run.—Ẹ́sítérì 8:3; wo Orí 15 àti 16 nínú ìwé yìí.