Máa Kó Ẹrù Ìnira Rẹ Sára Jehofa Nígbà Gbogbo
Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ lónìí ni ẹrù ìnira ń wọ̀ lọ́rùn. Ìṣòro ọ̀rọ̀ ajé, àwọn ìṣòro ìdílé tí ń fa ìrora ọkàn, àwọn ìṣòro àìlera, ìrora àti ìjìyà tí ó jẹ́ nítorí ìnilára àti ìwà òṣìkà agbonimọ́lẹ̀, àti ẹgbàágbèje ìpọ́njú mìíràn so mọ́ ọrùn wọn yíká bí ọlọ. Yàtọ̀ sí àwọn ìkìmọ́lẹ̀ ẹ̀yìn òde wọ̀nyí, ìmọ̀lára àìjámọ́-nǹkan kan ní ti ara ẹni àti ìkù-dìẹ́-káàtó nítorí àwọn àìpé tiwọn fúnra wọn ń kò ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ẹlòmíràn. A ti dán ọ̀pọ̀lọpọ̀ wò láti juwọ́ silẹ̀ pátápátá. Báwo ni o ṣe lè kojú rẹ̀ nígbà tí àwọn ẹrù ìnira bá dà bí èyí tí kò ṣeé fara dà?
Nígbà kan, Ọba Dafidi ti Israeli nímọ̀lára pé hílàhílo náà kò fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣeé fara dà mọ́. Ní ìbámu pẹ̀lú Orin Dafidi 55, àníyàn kó ṣìbáṣìbo bá a gidigidi nítorí àwọn hílàhílo àti kèéta láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ìrora ọkàn ńláǹlà bá a, ẹrù sì bá á. Ó wulẹ̀ lè kérora kìkì nínú ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀. (Orin Dafidi 55:2, 5, 17) Ṣùgbọ́n, láìka gbogbo wàhálà rẹ̀ sí, ó rí ọ̀nà láti kojú rẹ̀. Báwo? Ó yíjú sí Ọlọrun rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. Ìmọ̀ràn tí ó gba àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n lè ní irú ìmọ̀lára kan náà tí òún ní, ni pé: “Kó ẹrù ìnira rẹ lọ sára Jehofa fúnra rẹ̀.”—Orin Dafidi 55:22, NW.
Kí ni ó ní lọ́kàn nígbà tí ó wí pé “kó ẹrù ìnira rẹ lọ sára Jehofa fúnra rẹ̀”? Ó ha wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn títọ Jehofa lọ nínú àdúrà, kí a sì sọ àníyàn wa jáde? Àbí a lè fúnra wa ṣe ohun kan láti yanjú ipò náà? Bí a bá nímọ̀lára àìjẹ́-ẹni-yíyẹ láti tọ Jehofa lọ ńkọ́? A lè wádìí ohun tí Dafidi ní lọ́kàn nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìrírí díẹ̀ tí òún ti lè rántí dáradára nígbà tí ó ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
Ṣe Àwọn Nǹkan Pẹ̀lú Okun Jehofa
Ìwọ́ ha rántí bí Goliati ṣe da ìbẹ̀rùbojo bo ọkàn-àyà àwọn ọkùnrin jagunjagun Israeli? Ọkùnrin òmìrán yìí, tí ó ga ju mítà 2.7 lọ, da jìnnìjìnnì bò wọ́n. (1 Samueli 17:4-11, 24) Ṣùgbọ́n ẹ̀rù kò ba Dafidi. Èé ṣe? Nítorí pé kò gbìyànjú láti kojú Goliati pẹ̀lú okun ti ara rẹ̀. Láti ìgbà tí a ti fi òroro yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba lọ́la fún Israeli, ó ti yọ̀ọ̀da fún ẹ̀mí Ọlọrun láti darí òun, kí ó sì fún òun lókun nínú gbogbo ohun tí òun bá ń ṣe. (1 Samueli 16:13) Nítorí náà, ó wí fún Goliati pé: “Èmi tọ̀ ọ́ wá ní orúkọ Oluwa àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun ogun Israeli ti ìwọ ti gàn. Lónìí yìí ni Oluwa yóò fi ìwọ lé mí lọ́wọ́.” (1 Samueli 17:45, 46) Atamátàsé ni Dafidi, ṣùgbọ́n a lè ní ìdánilójú pé ẹ̀mí mímọ́ Jehofa ṣamọ̀nà rẹ̀, ó sì túbọ̀ fi kún agbára ìṣekúpani òkúta tí ó ta sí Goliati.—1 Samueli 17:48-51.
Dafidi kojú ìpènijà ńláǹlà yìí, ó sì ṣẹ́gun nípa níní ìgbọ́kànlé pé Ọlọrun yóò ti òun lẹ́yìn, yóò sì fún òun lókun. Ó ti mú ipò ìbátan rere, tí ó sì ṣeé gbára lé dàgbà pẹ̀lú Ọlọrun. Kò sí iyè méjì pé, ọ̀nà tí Jehofa ti gbà kó o yọ ní ìṣáájú túbọ̀ fìdí èyí múlẹ̀. (1 Samueli 17:34-37) Bíi Dafidi, ó lè ní ipò ìbátan lílágbára tí ó jẹ ti ara ẹni pẹ̀lú Jehofa, kí o sì ní ìgbọ́kànlé pátápátá nínú agbára àti ìmúratán rẹ̀ láti fún ọ lókun, kí ó sì mú ọ dúró nínú gbogbo àyíká ipò.—Orin Dafidi 34:7, 8.
Ṣe Ohun Tí O Bá Lè Ṣe Láti Yanjú Ìṣòro Náà
Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò túmọ̀ sí pé, kì yóò sì àwọn àkókò ìrora gógó, àníyàn, àti ìbẹ̀rù pàápàá, gẹ́gẹ́ bí Orin Dafidi 55 ṣe fi hàn ní kedere. Fún àpẹẹrẹ, ọdún díẹ̀ lẹ́yìn fífi ìgbọ́kànlé yìí hàn nínú Jehofa láìbẹ̀rù, Dafidi nírìírí ìbẹ̀rù ńláǹlà lójú àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó pàdánù ojú rere Ọba Saulu, ó sì ní láti sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. Tilẹ̀ ronú nípa ìdàrúdàpọ̀ ti èrò ìmọ̀lára tí èyí ti gbọ́dọ̀ fà fún Dafidi, àwọn ìbéèrè tí ó ti gbọ́dọ̀ gbé dìde nínú ọkàn rẹ̀ nípa àbáyọrí ète Jehofa. Ó ṣe tán, a ti fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba lọ́la ní Israeli, síbẹ̀, òún ṣì ní láti là á já gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá nínú aginjù, tí a ń dọdẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹranko ẹhànnà. Nígbà tí ó gbìyànjú láti wá ibi ìsádi nínú ìlú ńlá Gati, ìlú Goliati, wọ́n dá a mọ̀. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé, “ó sì bẹ̀rù . . . gidigidi.”—1 Samueli 21:10-12.
Ṣùgbọ́n kò yọ̀ọ̀da kí ìbẹ̀rù àti àníyàn rẹ̀ jíjinlẹ̀ dí i lọ́wọ́ nínú yíyíjú sí Jehofa fún ìrànlọ́wọ́. Ní ìbámu pẹ̀lú Orin Dafidi 34 (tí ó kọ gẹ́gẹ́ bí àbájáde ìrírí rẹ̀), Dafidi wí pé: “Èmi ṣe àfẹ́rí Oluwa, ó sì gbóhùn mi; ó sì gbà mí kúrò nínú gbogbo ìbẹ̀rù mi. Ọkùnrin olùpọ́njú yìí kígbe pè, Oluwa sì gbóhùn rẹ̀, ó sì gbà á nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.”—Orin Dafidi 34:4, 6.
Ó dájú pé, Jehofa ràn án lọ́wọ́. Síbẹ̀, ṣàkíyèsí pé Dafidi kò wulẹ̀ nawọ́ nasẹ̀ tẹtẹrẹ, kí ó sì máa dúró kí Jehofa gba òun là. Ó mọ̀ pé òun ní láti ṣe gbogbo ohun tí òún bá lè ṣe lábẹ́ àyíká ipò náà láti lè la ipò ìṣòro náà já. Ó rí ọwọ́ Jehofa nínú ìdáǹdè rẹ̀, ṣùgbọ́n, òun alára gbé ìgbésẹ̀, ó díbọ́n pé òún ń sínwín kí ọba Gati má bàá pa á. (1 Samueli 21:14–22:1) Àwa pẹ̀lú ní láti ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti lè kojú àwọn ẹrù ìnira wa, dípò wíwulẹ̀ dúró de Jehofa láti gbà wá là.—Jakọbu 1:5, 6; 2:26.
Má Ṣe Dì Kún Àwọn Ẹrù Ìnira Rẹ
Dafidi kọ́ ẹ̀kọ́ mìíràn, ọ̀kan tí ó le koko, ní apá ìgbẹ̀yìn ayé rẹ̀. Kí ni? Ìyẹn ni pé, nígbà míràn, a máa ń dì kún àwọn ẹrù ìnira wa. Lẹ́yìn tí ó ṣẹ́gun àwọn ará Filistini, nǹkan kò lọ déédéé fún Dafidi nígbà tí ó pinnu láti gbé àpótí ẹ̀rí lọ sí Jerusalemu. Àkọsílẹ̀ ìtàn náà sọ fún wa pé: “Dafidi sì dìde, ó sì lọ, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, láti Baale ti Juda wá, láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọrun ti ibẹ̀ wá . . . Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, . . . Ussa àti Ahio, àwọn ọmọ Abinadabu sì ń da kẹ̀kẹ̀ tuntun náà.”—2 Samueli 6:2, 3.
Lílo kẹ̀kẹ́ láti gbé Àpótí náà ta ko gbogbo ìtọ́ni tí Jehofa fi fún wọn nípa rẹ̀. A sọ ọ́ ní kedere pé, kìkì àwọn tí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti gbé e, àwọn ọmọ Kohati tí í ṣe ẹ̀yà Lefi, ni wọ́n ní láti gbé Àpótí náà lé èjìká wọn, ní lílo igi tí a kì bọ ihò róbótó tí a dìídì gbẹ́ ní àrà ọ̀tọ̀ sí inú Àpótí náà. (Eksodu 25:13, 14; Numeri 4:15, 19; 7:7-9) Àìka àwọn ìtọ́ni wọ̀nyí sí mú àjálù wá. Nígbà tí málúù tí ń fa kẹ̀kẹ́ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ dà á wó, Ussa, ẹni tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ẹ̀yà Lefi ṣùgbọ́n tí ó dájú pé kì í ṣe àlùfáà, dì í mú kí Àpótí náà má baà yẹ̀ lulẹ̀, Jehofa sì pà á nítorí ìwà àìlọ́wọ̀ rẹ̀.—2 Samueli 6:6, 7.
Nítorí èyí, Dafidi ni ó yẹ kí a dá lẹ́bi gẹ́gẹ́ bí ọba. Ìhùwàpadà rẹ̀ fi hàn pé àwọn tí wọ́n tilẹ̀ ní ipò ìbátan rere pẹ̀lú Jehofa pàápàá lè hùwà padà sí àwọn ipò àdánwò lọ́nà tí ó burú nígbà míràn. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, inú bi Dafidi. Lẹ́yìn náà, ẹ̀rù bà á. (2 Samueli 6:8, 9) A dán ipò ìbátan tí ó ṣeé gbára lé tí ó ní pẹ̀lú Jehofa wò gidigidi. Àkókò kan níyì tí ó dà bíi pé, ó kùnà láti kó ẹrù ìnira rẹ̀ lọ sí ará Jehofa, nígbà tí kò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ rẹ̀. Ìyẹn ha lè jẹ́ bí ọ̀ràn ti rí pẹ̀lú wa nígbà míràn bí? A ha ti fìgbà kan rí dá Jehofa lẹ́bi fún àwọn ìṣòro tí ó jẹ ìyọrísí pé a kò ka ìtọ́ni rẹ̀ sí bí?—Owe 19:3.
Kíkojú Ẹrù Ìnira Ẹ̀bi
Nígbà tí ó ṣe, Dafidi dá ẹrù ìnira ẹ̀bi ńláǹlà sílẹ̀ fún ara rẹ̀ nípa dídẹ́ṣẹ̀ biburu jáì lòdì sí àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù ti Jehofa. Ní àkókò yìí, Dafidi yẹ ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ láti ṣáájú àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ sí ojú ogun sílẹ̀. Ó dúró sí Jerusalemu nígbà tí àwọ́n lọ jagun. Èyí yọrí sí wàhálà ńláǹlà.—2 Samueli 11:1.
Ọba Dafidi rí Batṣeba òrékelẹ́wà tí ń wẹ̀. Ó bá a lò pọ̀, ó sì lóyún. (2 Samueli 11:2-5) Láti gbìyànjú láti bo ìwà àìtọ́ náà mọ́lẹ̀, ó ṣètò pé kí ọkọ rẹ̀, Uria, padà sí Jerusalemu láti pápá ìjà ogun. Uria kọ̀ láti ní ìṣe lọ́kọláya pẹ̀lú aya rẹ̀ nígbà tí Israeli ń jagun lọ́wọ́. (2 Samueli 11:6-11) Nísinsìnyí, Dafidi yíjú sí lílo ọ̀nà burúkú àti ọ̀nà békebèke láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó ṣètò fún àwọn jagunjagun ẹlẹgbẹ Uria láti fi Uria sílẹ̀ sí ipò tí ọṣẹ́ ti lè tètè ṣe é nínú ìjà ogun náà, kí wọn baà lè pa á. Ẹ wo irú ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì, tí ó sì wúwo tí èyí jẹ́!—2 Samueli 11:12-17.
Àmọ́ ṣáá o, àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ọwọ́ pálábá Dafidi ségi, àṣírí rẹ̀ sì tú. (2 Samueli 12:7-12) Gbìyànjú láti ronú nípa bí ẹ̀dùn ọkàn àti ẹ̀bi tí Dafidi nímọ̀lára yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ó rí bí ohun tí òún ṣe ti burú jáì tó gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìfẹ́ onígbòónára tí ó mú dàgbà. Ìmọ̀lára ìkùnà rẹ̀ fúnra rẹ̀ ì bá ti mú ọkàn rẹ̀ pòrúurùu, ní pàtàkì nítorí pé, ó dà bíi pé ó jẹ́ onígbòónára, tí ó tètè máa ń nímọ̀lára. Bákan náà ó sì ti lè nímọ̀lára àìjámọ́-nǹkan kan rárá!
Bí ó ti wù kí ó rí, Dafidi yára tẹ́wọ́ gba àṣìṣe rẹ̀, ní sísọ fún wòlíì Natani pé: “Èmi ṣẹ̀ sí Oluwa.” (2 Samueli 12:13) Orin Dafidi 51 sọ fún wa bí ìmọ̀lára rẹ̀ ṣe rí àti bí ó ṣe bẹ Jehofa Ọlọrun láti wẹ òun mọ́ tónítóní, kí ó sì dárí ji òun. Ó gbàdúrà pé: “Wẹ̀ mí ní àwẹ̀mọ́ kúrò nínú àìṣedéédéé mi, kí o sì wẹ̀ mí nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí ti mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi: nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi sì ń bẹ níwájú mi.” (Orin Dafidi 51:2, 3) Nítorí pé ó ronú pìwà dà ní tòótọ́, ó ṣeé ṣe fún un láti ṣe àtúnkọ́ ipò ìbátan rẹ̀ lílágbára, àti èyí tí ó wá pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú Jehofa. Dafidi kò darí ìrònú rẹ̀ sí àwọn ìmọ̀lára àbámọ̀ àti àìjámọ́-nǹkan kan. Ó kó ẹrù inira rẹ̀ lọ sára Jehofa nípa fífi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ẹ̀bi rẹ̀, ní fífi ojúlówó ìrònúpìwàdà hàn, àti gbígbàdúrà tọkàntọkàn fún ìdáríjì Jehofa. Ó rí ojú rere Ọlọrun gbà padà.—Orin Dafidi 51:7-12, 15-19.
Kíkojú Ìwà Ọ̀dàlẹ̀
Èyí mú wa wá sórí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó sún Dafidi láti kọ Orin Dafidi 55. Ó wà lábẹ́ ìdààmú ńláǹlà ní ti èrò ìmọ̀lára. Ó kọ̀wé pé: “Àyà dùn mí gidigidi nínú mi: ìpayà ikú sì ṣubú lù mí.” (Orin Dafidi 55:4) Kí ni ó fa ìrora yìí? Absalomu, ọmọkùnrin Dafidi, ti gbìmọ̀ láti jí ipò ọba mọ́ Dafidi lọ́wọ́. (2 Samueli 15:1-6) Ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí ọmọkùnrin rẹ̀ hù yìí ṣòro gidigidi láti fara dà, ṣùgbọ́n, ohun tí ó mú kí ó túbọ̀ burú ní pé, olùdámọ̀ràn tí Dafidi gbẹ́kẹ̀ lé jù lọ, ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ahitofeli, dara pọ̀ mọ́ ọ̀tẹ̀ náà lòdì sí Dafidi. Ahitofeli ni Dafidi ṣàpèjúwe nínú Orin Dafidi 55:12-14. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ọ̀tẹ̀ àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ náà, Dafidi ní láti sá kúrò ní Jerusalemu. (2 Samueli 15:13, 14) Ẹ wo irú làásìgbò tí èyí yóò ti fà fún un!
Síbẹ̀, kò yọ̀ọ̀da kí èrò ìmọ̀lára gbígbóná àti ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbọ́kànlé rẹ̀ nínú Jehofa dín kù. Ó gbàdúrà sí Jehofa pé kí ó da àwọn ìwéwèé àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà rú. (2 Samueli 15:30, 31) Lẹ́ẹ̀kan sí i, a rí i pé Dafidi kò wulẹ̀ jókòó tẹtẹrẹ kí Jehofa ṣe gbogbo iṣẹ́ náà. Gbàrà tí àǹfààní náà yọjú, ó ṣe ohun tí ó lè ṣe láti gbéjà ko ọ̀tẹ̀ tí a dì mọ́ ọn. Ó rán òmíràn nínú àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, Huṣai, padà sí Jerusalemu láti díbọ́n pé òún fara mọ́ ọ̀tẹ̀ náà, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, ní tòótọ́, ó lọ láti bà á jẹ́ ni. (2 Samueli 15:32-34) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa, ìwéwèé yìí ṣiṣẹ́. Huṣai jẹ́ kí Dafidi rí àkókò tí ó tó láti tún ọmọ ogun rẹ̀ kó jọ, kí ó sì ṣètò láti gbèjà ara rẹ̀.—2 Samueli 17:14.
Ẹ wo bí Dafidi jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ yóò ti mọrírì ìtọ́jú aláàbò Jehofa àti sùúrù pẹ̀lú ìmúratán rẹ̀ láti dárí jì tó! (Orin Dafidi 34:18, 19; 51:17) Ipò àtilẹ̀wá yìí ni ó mú kí Dafidi fi ìgbọ́kànlé fún wa níṣìírí láti yíjú sí Jehofa fún ìrànlọ́wọ́ ní àwọn àkókò ìrora ọkàn wa, láti ‘kó ẹrù ìnira wa lé Jehofa.’—Fi wé 1 Peteru 5:6, 7.
Mú Ipò Ìbátan Lílágbára, Tí Ó Ṣeé Gbára lé Dàgbà Pẹ̀lú Jehofa, Kí O sì Máa Bá A Nìṣo
Báwo ni a ṣe lè ní irú ipò ìbátan tí Dafidi ní yẹn pẹ̀lú Jehofa, ipò ìbátan tí ó mú un dúró ní àwọn àkókò ìdánwò àti ìpọ́njú gígọntíọ? A ń mú irú ipò ìbátan bẹ́ẹ̀ dàgbà nípa fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. A ń jẹ́ kí ó kọ́ wa ní àwọn òfin, ìlànà, àti àkópọ̀ ìwà rẹ̀. (Orin Dafidi 19:7-11) Bí a ṣe ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, a túbọ̀ ń sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, a sì ń kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. (Orin Dafidi 143:1-5) A ń mú ipò ìbátan wa jinlẹ̀ sí i, a sì ń fún un lókun, bí a ṣe ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa láti gba ìtọ́ni síwájú sí i láti ọ̀dọ̀ Jehofa. (Orin Dafidi 122:1-4) A túbọ̀ ń mú kí ipò ìbátan wa pẹ̀lú Jehofa lágbára sí i nípa àdúrà àtọkànwá.—Orin Dafidi 55:1.
Lóòótọ́, Dafidi, bí àwa náà, ní ìsoríkọ́ tirẹ̀, nígbà tí ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Jehofa kò lágbára tó bí ó ṣe yẹ kí ó rí. Ìnilára lè mú kí a “sínwín.” (Oniwasu 7:7) Ṣùgbọ́n Jehofa rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀, ó sì mọ ohun tí ó wà ní ọkàn-àyà wa. (Oniwasu 4:1; 5:8) A ní láti ṣiṣẹ́ kára láti mú kí ipò ìbátan wa pẹ̀lú Jehofa lágbára sí i. Lẹ́yìn náà, ẹrù ìnira yòówù tí a ní láti gbé, a lè gbára lé Jehofa láti dín pákáǹleke náà kù tàbí kí ó fún wa ní okun láti kojú ipò wa. (Filippi 4:6, 7, 13) Ó jẹ́ ọ̀ràn dídúró ti Jehofa pẹ́kípẹ́kí. Nígbà tí Dafidi ṣe èyí, a dáàbò bò ó délẹ̀délẹ̀.
Nítorí náà, àyíká ipò yòówù tí o lè wà, Dafidi sọ pé, màa kó ẹrù ìnira rẹ̀ sára Jehofa nígbà gbogbo. Nígbà náà, a óò nírìírí òtítọ́ ìlérí náà: “Òun ni yóò . . . mú ọ dúró: òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.”—Orin Dafidi 55:22.