Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Gidi Tí Àárín Ìwọ àti Ọ̀rẹ́ Rẹ Bá Fẹ́ Dàrú
Àádọ́ta [50] ọdún rèé tí Gianni àti Maurizio ti ń ṣọ̀rẹ́. Àmọ́, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fẹ́ já okùn ọ̀rẹ́ wọn. Maurizio sọ pé: “Nígbà kan tí mo níṣòro, mo ṣàṣìṣe tó burú jáì, ìyẹn sì mú ká jìnnà síra wa.” Gianni wá fi kún un pé: “Maurizio ló kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Òun ló sábà máa ń gbà mí nímọ̀ràn. Torí náà, ohun tó ṣe yẹn yà mí lẹ́nu gan-an. Ṣe ni gbogbo nǹkan tojú sú mi pátápátá torí mo mọ̀ pé a ò ní jọ máa ṣọ̀rẹ́ mọ́. Ṣe ló wá dà bíi pé mi ò rẹ́ni fojú jọ.”
Ọ̀RẸ́ gidi ṣọ̀wọ́n, ó gba ìsapá kéèyàn tó lè nírú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀, èèyàn sì ní láti sapá kí okùn ọ̀rẹ́ náà má bàa já. Kí wá lèèyàn lè ṣe tí okùn ọ̀rẹ́ bá fẹ́ já? A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn kan nínú Bíbélì tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, àmọ́ tí ohun kan fẹ́ já okùn ọ̀rẹ́ wọn.
TÍ Ọ̀RẸ́ RẸ BÁ ṢÀṢÌṢE
Ó dájú pé Dáfídì láwọn ọ̀rẹ́ nígbà tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti nígbà tó di ọba. Ó ṣeé ṣe kó o rántí pé Jónátánì wà lára wọn. (1 Sám. 18:1) Àmọ́ Dáfídì tún láwọn ọ̀rẹ́ míì, ọ̀kan lára wọn ni wòlíì Nátánì. Bíbélì ò sọ ìgbà táwọn méjèèjì dọ̀rẹ́. Síbẹ̀, ìgbà kan wà tí Dáfídì sọ ohun kan tó wà lọ́kàn ẹ̀ fún Nátánì bíwọ náà ṣe lè sọ tinú rẹ fún ọ̀rẹ́ rẹ. Ó wu Dáfídì pé kó kọ́lé fún Jèhófà. Dáfídì mọ̀ pé ìmọ̀ràn gidi ni Nátánì ọ̀rẹ́ òun máa gba òun torí pé ẹ̀mí Jèhófà wà lára rẹ̀.—2 Sám. 7:2, 3.
Àmọ́, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fẹ́ ba àárín wọn jẹ́. Ọba Dáfídì ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ẹ̀yìn náà ló tún ṣekú pa Ùráyà ọkọ rẹ̀. (2 Sám. 11:2-21) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ọ̀pọ̀ ọdún ni Dáfídì ti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, tó sì ń ṣèdájọ́ òdodo. Òun ló wá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì bẹ́ẹ̀! Kí ló mú kí Dáfídì ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Ṣé kò mọ bọ́ràn náà ṣe burú tó ni? Àbí ó ronú pé òun lè rọ́gbọ́n ẹ̀ dá tí Jèhófà kò fi ní mọ̀?
Kí wá ni Nátánì máa ṣe? Ṣó máa káwọ́ gbera títí ẹlòmíì á fi gbé ọ̀rọ̀ náà ko Dáfídì lójú ni? Ó ṣe tán àwọn míì náà mọ bí Dáfídì ṣe pa Ùráyà. Ṣé Nátánì máa wá dá sọ́rọ̀ náà, tó sì mọ̀ pé ìyẹn lè mú kí okùn ọ̀rẹ́ àwọn já? Ohun míì tún ni pé Dáfídì lè ní kí wọ́n pa á tó bá dá sọ́rọ̀ náà. Ó ṣe tán, Dáfídì ṣáà ti pa Ùráyà tí kò mọwọ́mẹsẹ̀.
Àmọ́, wòlíì Ọlọ́run ni Nátánì. Ó mọ̀ pé tóun bá dákẹ́, àárín òun àti Dáfídì kò ní gún mọ́, ẹ̀rí ọkàn òun á sì máa dá òun lẹ́bi. Dáfídì ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló ti ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra yìí. Ó sì mọ̀ pé Dáfídì nílò ẹni tó máa ràn án lọ́wọ́ láti pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, Dáfídì nílò ọ̀rẹ́ gidi, tó lè bá a sòótọ́ ọ̀rọ̀. Ó dájú pé irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Nátánì. Torí pé olùṣọ́ àgùntàn ni Dáfídì tẹ́lẹ̀, Nátánì yàn láti lo àpèjúwe olùṣọ́ àgùntàn, ó sì mọ̀ pé ìyẹn á gún ọkàn Dáfídì ní kẹ́ṣẹ́. Nátánì jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an, àmọ́ ó ṣe é lọ́nà tí Dáfídì fi rí bí ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe burú tó, ìyẹn sì mú kó kábàámọ̀ ohun tó ṣe.—2 Sám. 12:1-14.
Kí ni wàá ṣe tí ọ̀rẹ́ rẹ bá ṣàṣìṣe ńlá kan tàbí tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì? O lè ronú pé á dáa kó o fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́ kí àárín yín máa bàa dàrú. Ó sì lè ṣe ẹ́ bíi pé o dalẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ tó o bá sọ̀rọ̀ náà fáwọn alàgbà tó lè ràn án lọ́wọ́ láti kọ́fẹ pa dà. Kí lo máa wá ṣe?
Gianni tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lókè sọ pé: “Mo kíyè sí i pé nǹkan ti yàtọ̀ láàárín èmi àti Maurizio. Kì í sọ tinú ẹ̀ fún mi mọ́. Mo pinnu pé màá lọ bá a, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún mi rárá. Mo ronú pé: ‘Kí ni mo fẹ́ sọ fún un tí kò tíì mọ̀? Ó mà lè gbaná jẹ!’ Àmọ́ nígbà tí mo rántí àwọn nǹkan tá a ti jọ kẹ́kọ̀ọ́, mo pinnu pé màá lọ bá a. Ó ṣe tán, Maurizio náà ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún mi nígbà témi náà nílò ìrànwọ́. Mi ò fẹ́ kí àárín wa bà jẹ́, mo bá pinnu pé màá ràn án lọ́wọ́ torí mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.”
Maurizio sọ pé: “Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni Gianni bá mi sọ, kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ rárá. Mo mọ̀ pé òun kọ́ ló fa àbájáde ìpinnu búburú tí mo ṣe, ó sì dájú pé kì í ṣe Jèhófà ló fà á. Torí náà, mo gba ìbáwí tí wọ́n fún mi, nígbà tó sì yá mo kọ́fẹ pa dà.”
KÍ NI WÀÁ ṢE TÍ Ọ̀RẸ́ RẸ BÁ NÍṢÒRO?
Dáfídì tún láwọn ọ̀rẹ́ míì tí wọ́n jẹ́ adúrótini nígbà ìṣòro. Ọ̀kan lára wọn ni Húṣáì, tí Bíbélì pè ní ọ̀rẹ́ Dáfídì. (2 Sám. 16:16; 1 Kíró. 27:33) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ kòríkòsùn Dáfídì, tó ń bá a ṣiṣẹ́ láàfin, tí Dáfídì sì máa ń rán láwọn iṣẹ́ tí etí míì ò gbọ́dọ̀ gbọ́.
Nígbà tí Ábúsálómù gba ìjọba lọ́wọ́ Dáfídì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gbè sẹ́yìn Ábúsálómù ò lóǹkà, àmọ́ Húṣáì kò dara pọ̀ mọ́ wọn. Nígbà tí Dáfídì ń sá kúrò nílùú, Húṣáì lọ bá a. Ó dun Dáfídì gan-an pé ọmọ òun àtàwọn míì tóun fọkàn tán ló dìtẹ̀ mọ́ òun. Àmọ́, Húṣáì jẹ́ adúróṣinṣin, ó sì ṣe tán láti fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, ó gbà láti lọ jíṣẹ́ tí Dáfídì rán an kí ìgbésẹ̀ àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà lè já sí pàbó. Húṣáì jẹ́ iṣẹ́ yìí, kì í ṣe torí pé ọba ló rán an nìkan, àmọ́ ìfẹ́ tó ní sí Dáfídì ló mú kó gbà láti ṣe é. Ó sì fi hàn pé ọ̀rẹ́ gidi lòun.—2 Sám. 15:13-17, 32-37; 16:15–17:16.
Inú wa dùn gan-an pé àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin wà níṣọ̀kan láìka ti pé ojúṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbogbo wọn ní nínú ìjọ. Bí wọ́n ṣe ń ṣe síra wọn fi hàn pé ọ̀rẹ́ ni gbogbo wọn, kì í ṣe torí pé ó pọn dandan kí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́, àmọ́ ó jẹ́ torí pé wọ́n mọyì ara wọn.
Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Federico. Ìgbà kan wà tó níṣòro, àmọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Antonio ràn án lọ́wọ́ tó fi kọ́fẹ pa dà. Federico sọ pé: “Kò pẹ́ tí Antonio dé ìjọ wa làwa méjèèjì dọ̀rẹ́. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni wá, a sì gbádùn ká jọ máa ṣiṣẹ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ló di alàgbà. Yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi, ó tún jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún mi.” Ó wá ṣẹlẹ̀ pé Federico hùwà àìtọ́. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sọ fáwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́, bó ṣe di pé kì í ṣe aṣáájú-ọ̀nà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ mọ́ nìyẹn. Kí wá ni Antonio ṣe?
Federico sọ pé: “Mo rí i pé Antonio mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi. Ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ẹ̀dùn ọkàn tí mo ní má bàa pọ̀. Ó wù ú gan-an pé kí n pa dà máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn mi, torí bẹ́ẹ̀ kò pa mí tì. Ó gbà mí níyànjú pé kí n sapá láti kọ́fẹ pa dà, kí n má sì jẹ́ kó sú mi.” Antonio sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń wà pẹ̀lú Federico. Mo jẹ́ kó mọ̀ pé kò sóhun tí kò lè bá mi sọ, títí kan bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀.” Nígbà tó yá, Federico kọ́fẹ pa dà, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ó tún di aṣáájú-ọ̀nà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Antonio wá sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la wà báyìí, ṣe ni okùn ọ̀rẹ́ wa túbọ̀ ń lágbára sí i.”
ṢÉ KÒ NÍ ṢE Ẹ́ BÍI PÉ WỌ́N DALẸ̀ RẸ?
Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tí ọ̀rẹ́ rẹ bá pa ẹ́ tì nígbà tó o nílò rẹ̀ jù lọ? Ó máa ń duni gan-an tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Ṣé wàá lè dárí ji onítọ̀hún? Ṣé àárín yín sì tún lè pa dà gún bó ṣe wà tẹ́lẹ̀?
Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ní ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀. Òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ ni wọ́n jọ ń jẹ, tí wọ́n jọ ń mu, àárín wọn sì gún gan-an. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kà wọ́n sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jòh. 15:15) Síbẹ̀, kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n mú Jésù? Ṣe làwọn àpọ́sítélì fẹsẹ̀ fẹ. Kódà Pétérù ti sọ lójú gbogbo wọn pé òun ò ní fi Jésù sílẹ̀ láéláé, àmọ́ lálẹ́ ọjọ́ yẹn ó sọ pé òun ò mọ Jésù rí!—Mát. 26:31-33, 56, 69-75.
Jésù mọ̀ pé òun nìkan lòun máa kojú àdánwò náà. Síbẹ̀, tó bá bínú, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tó bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ lẹ́yìn tó jíǹde fi hàn pé kò bínú sí wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò kábàámọ̀ pé òun ní wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Kò torí ìyẹn wá máa rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà létí àwọn àṣìṣe wọn, títí kan bí wọ́n ṣe pa á tì lálẹ́ ọjọ́ táwọn èèyàn wá mú un.
Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù fi Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù lọ́kàn balẹ̀. Ó fi dá wọn lójú pé òun ṣì fọkàn tán wọn, ó wá fún wọn ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tẹ́nì kan ò ṣe rí. Jésù ṣì gbà pé ọ̀rẹ́ òun làwọn àpọ́sítélì náà. Àwọn náà ò sì gbàgbé bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. Ó dájú pé wọ́n á ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n má bàa já Ọ̀gá wọn kulẹ̀. Kódà, ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wọn láṣeyanjú.—Ìṣe 1:8; Kól. 1:23.
Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Elvira rántí ìgbà tóun àti Giuliana ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní èdèkòyédè, ó sọ pé: “Nígbà tí Giuliana sọ fún mi pé ohun tí mo ṣe bí òun nínú, ó dùn mí gan-an. Mo mọ̀ pé ó yẹ kó bínú lóòótọ́. Àmọ́ ohun tó yà mí lẹ́nu ni pé kì í ṣe ìwà tí mo hù sí i ló ká a lára jù. Ó sọ pé àkóbá tọ́rọ̀ náà máa ṣe fún mi ló ń dun òun. Mo sì mọyì ohun tó ṣe yẹn gan-an. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo lọ́rẹ̀ẹ́ tọ́rọ̀ mi jẹ lógún ju tara ẹ̀ lọ.”
Torí náà, kí ni ọ̀rẹ́ gidi máa ṣe tí àárín òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá fẹ́ dàrú? Ọ̀rẹ́ gidi máa wá àyè bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, á sì sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ fún un tìfẹ́tìfẹ́. Á ṣe bíi Nátánì àti Húṣáì tó dúró ti ọ̀rẹ́ wọn nígbà ìṣòro. Á sì tún ṣe bíi Jésù tó forí ji àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ṣé bí ìwọ náà ṣe rí nìyẹn?