Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́
ÈLÍJÀ ń wo àwọn èrò tó ń bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán bí wọ́n ṣe ń fi ìrọ́jú gun Òkè Ńlá Kámẹ́lì. Láàárọ̀ ọjọ́ tá à ń wí yìí, kò ṣòro fún Èlíjà láti rí ohun tí ìṣẹ́ àti ìyàn ti sọ àwọn èèyàn yìí dà. Àìrọ̀ òjò láti bí ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ sẹ́yìn kò jẹ́ kí wọ́n rí oúnjẹ tó dáa jẹ.
Àádọ́talénírínwó [450] àwọn wòlíì Báálì ń rìn bọ̀ tìgbéraga-tìgbéraga láàárín àwọn èrò náà, bí ẹ̀gbin ni wọ́n sì ṣe kórìíra Èlíjà tó jẹ́ wòlíì Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésíbẹ́lì ayaba ti pa ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, Èlíjà ṣì lòdì sí ìjọsìn Báálì. Àmọ́, ǹjẹ́ ó máa lè dúró gbọn-in? Ó ṣeé ṣe káwọn wòlíì Báálì yẹn máa rò ó pé, ọkùnrin kan ṣoṣo yìí kò ní lè borí àwọn láé. (1 Àwọn Ọba 18:3, 19, 20) Áhábù Ọba pàápàá wá, tòun ti kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀. Òun náà kò nífẹ̀ẹ́ Èlíjà rárá.
Èlíjà nìkan ṣoṣo ni olùjọsìn Jèhófà láàárín wọn, ó sì máa tó rí ohun àrà ńlá tó máa ṣẹlẹ̀. Èlíjà dúró ó ń wò wọ́n bí ìfàgagbága táráyé ò rírú ẹ̀ rí ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn olubi àti èèyàn Ọlọ́run. Kí ni Èlíjà á máa rò láàárọ̀ ọjọ́ yẹn? Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀rù fẹ́ máa bà á, nítorí “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa” lòun náà. (Jákọ́bù 5:17) Ohun kan tó dá wa lójú ni pé: Èlíjà á máa rò pé òun nìkan lòun dá wà, nítorí àwọn èèyàn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, ọba tó ti di apẹ̀yìndà, àtàwọn àlúfáà Báálì tó jẹ́ apaàyàn ló yí i ká.—1 Àwọn Ọba 18:22.
Àmọ́, báwo ni Ísírẹ́lì ṣe kó sí irú ìṣòro yìí? Báwo sì ni ìtàn yìí ṣe kàn ọ́ lónìí? Bíbélì rọ̀ wá pé ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tó fi tọ́kàntọkàn sin Ọlọ́run ká sì “máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.” (Hébérù 13:7) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Èlíjà yẹ̀ wò.
Ọ̀ràn Náà Dójú Ọ̀gbagadè
Ọjọ́ pẹ́ tí Èlíjà ti ń rí báwọn èèyàn ṣe pa ìjọsìn mímọ́ tó jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ní ìlú rẹ̀ tì, tí wọ́n sì ń tàbùkù rẹ̀, tí kò sì sohun tó lè ṣe sí i. Ṣẹ́ ẹ rí i, ó pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń dààmú lórí èrò méjì, wọn ò mọ èyí tí wọn ì bá ṣe nínú ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké, ìyẹn ni pé bóyá kí wọ́n máa jọsìn Jèhófà Ọlọ́run tàbí kí wọ́n máa bọ òrìṣà bíi tàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Èlíjà, gbogbo ẹ̀ ti wá dojú rú fún wọn.
Áhábù Ọba fi Jésíbẹ́lì ọmọ ọba Sídónì ṣaya. Jésíbẹ́lì sì pinnu pé òun á mú kí ìjọsin Báálì tàn kálẹ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, débi pé kò ní sí ẹni tá máa sin Jèhófà mọ́. Áhábù gbà pẹ̀lú ohun ti Jésíbẹ́lì fẹ́ ṣe yìí láìjanpata. Áhábù kọ́ tẹ́ńpìlì ó sì mọ pẹpẹ fún Báálì, ó sì tún ń ṣáájú àwọn èèyàn náà nígbà tí wọ́n bá ń bọ òrìṣà yìí. Áhábù tipa báyìí dẹ́ṣẹ̀ ńlá sí Jèhófà.—1 Àwọn Ọba 16:30-33.a
Kí nìdí tí ìjọsìn Báálì fi jẹ́ ohun ìríra? Ìdí ni pé ó ń sún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹ́sẹ̀, ó ń tàn wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́. Òkú òǹrorò làwọn olùjọsìn Báálì, ìṣekúṣe sì pọ̀ nínú ẹ̀sìn wọn. Ṣíṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó nínú tẹ́ńpìlì, ṣíṣe ìṣekúṣe nínú ààtò ẹ̀sìn àti fífi ọmọ rúbọ jẹ́ ara ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Báálì. Jèhófà gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní kí Èlíjà sọ fún Áhábù pé òjò kò ní rọ̀ ní ilẹ̀ náà títí dìgbà tí wòlíì Ọlọ́run yóò fi kéde pé kó rọ̀. (1 Àwọn Ọba 17:1) Ọ̀pọ̀ ọdún kọjá kí Èlíjà tó tún yọjú sí Áhábù, ó sì sọ fún Áhábù pé kí ó kó àwọn èèyàn àtàwọn wòlíì Báálì jọ sórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì.
Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe kàn wá lóde òní? Àwọn kan lè rò pé ìtàn tí kò bóde mu ni ọ̀rọ̀ ìjọsìn Báálì, torí pé kò sí tẹ́ńpìlì tàbí àwọn pẹpẹ Báálì lóde òní. Àmọ́ ìtàn yìí kì í ṣe ìtàn ayé àtijọ́ lásán o. (Róòmù 15:4) Ọ̀rọ̀ náà “Báálì” túmọ̀ sí “oníǹkan” tàbí “ọ̀gá.” Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n fòun ṣe “báálì” wọn, ìyẹn ọkọ olówó orí wọn. (Aísáyà 54:5) Ǹjẹ́ kì í ṣe oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn ti sọ di ọ̀gá wọn tí wọ́n ń jọ́sìn yàtọ̀ sí Ọlọ́run Olódùmarè? Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohunkóhun táwọn èèyàn bá ń fi ìgbésí ayé wọn lé ni ọ̀gá wọn, ì báà jẹ́ owó, ipò ọlá, eré ìtura, fàájì, ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ tàbí ohun yòówù táwọn èèyàn ń sìn dípò Jèhófà. (Mátíù 6:24; Róòmù 6:16) Ká sòótọ́, gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Báálì ló wà yí wa ká lóde òní. Nítorí náà, ohun tó ṣẹlẹ̀ láyé àtijọ́ yìí tó jẹ́ ká mọ ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ láàárín Jèhófà àti Báálì, yóò jẹ́ ká lè fi ọgbọ́n yan ẹni ta óò máa sìn.
Wọ́n Ń “Tiro Lórí Èrò Méjì”—Lọ́nà Wo?
Téèyàn bá wà lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì níbi tí ẹ̀fúùfù ti ń fẹ́ gan-an, èèyàn lè rí gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ìyẹn láti àfonífojì ọ̀gbàrá Kíṣónì lọ sí Òkun Ńlá, ìyẹn (Òkun Mẹditaréníà) tí kò jìnnà sí Òkè Ńlá Kámẹ́lì, títí lọ dé òkè ńlá Lẹ́bánónì tó wà lọ́nà jíjìn lápá àríwá.b Àmọ́ bí oòrùn ti yọ láàárọ̀ ọjọ́ tí Èlíjà fìpàdé sí yìí, téèyàn bá wo ọ̀ọ́kán, èèyàn á rí i pé gbogbo ilẹ̀ náà ti bà jẹ́. Ilẹ̀ ọlọ́ràá tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ábúráhámù ti di aṣálẹ̀, kò sì méso jáde mọ́. Ìwà òpònú àwọn tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run ti fa oòrùn tó mú débi pé ilẹ̀ náà gbẹ táútáú. Báwọn èèyàn náà ti kóra jọ, Èlíjà sún mọ́ wọn, ó sì wí pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó fi máa tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra? Bí Jèhófà bá ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”—1 Àwọn Ọba 18:21.
Kí ni Èlíjà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé wọ́n ń “tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra”? Ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwọn èèyàn náà kò mọ̀ pé ọ̀kan ló yẹ káwọn yàn nínú ìjọsìn Jèhófà àti ti Báálì. Wọ́n rò pé àwọn lè máa ṣe ìjọsìn méjèèjì pa pọ̀, káwọn máa fi àwọn ètùtù wọn tó ń kóni nírìíra tu Báálì lójú, lẹ́sẹ̀ kan náà káwọn máa bẹ Jèhófà Ọlọ́run pé kó ṣojú rere sáwọn. Wọ́n lè máa rò pé Báálì á jẹ́ kí irè oko wọn dàgbà á sì tún máa bù kún àwọn ohun ọ̀sìn wọn, kí “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” sì máa dáàbò bò wọ́n lójú ogun. (1 Sámúẹ́lì 17:45) Wọ́n ti gbàgbé ohun pàtàkì kan, ìyẹn ni pé Jèhófà kì í bá òrìṣà pín ìjọsìn pa pọ̀, àní bí ọ̀pọ̀ èèyàn ò ṣe mọ̀ lóde òní. Jèhófà sọ pé òun nìkan la gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn, òun náà ló sì yẹ kó gba ìjọsìn wa. Tá a bá da ìjọsìn èyíkéyìí mìíràn pọ̀ mọ́ ìjọsìn wa, Ọlọ́run kò ní tẹ́wọ́ gbà á torí pé ohun ìríra ló jẹ́ lójú rẹ̀.—Ẹ́kísódù 20:5.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò mọ èyí tí wọn ì bá ṣe, bíi ti àlejò tó dé oríta mẹ́ta tí kò mọ ibi tó máa yà sí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe irú àṣìṣe kan náà lóde òní, wọ́n sọ àwọn nǹkan míì di báálì tiwọn tí wọ́n ń jọ́sìn, wọ́n sì pa ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ tì. Ọ̀rọ̀ tí Èlíjà sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n yéé ṣiyèméjì yóò ran àwa náà lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ara wa ká lè mọ ohun tó gbawájú nígbèésí ayé wa àti irú ìjọsìn tá à ń ṣe.
Ìdánwò Pàtàkì Kan
Èlíjà wá ṣètò ìdánwò kan. Ìdánwò yìí ò le rárá. Ó ní kí àwọn wòlíì Báálì ṣètò pẹpẹ kan, kí wọ́n sì kó àwọn ohun tí wọ́n á fi rúbọ sórí pẹpẹ náà, kí wọ́n wá ké pe òrìṣà wọn pé kó finá sí ẹbọ náà. Èlíjà ní ohun tóun náà máa ṣe nìyẹn. Ó wá sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ tí ó bá fi iná dáhùn ni Ọlọ́run tòótọ́.” Èlíjà mọ ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ náà dáadáa. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára débi pé ó jẹ́ kí àwọn wòlíì Báálì yẹn kọ́kọ́ ké pe òrìṣà wọn. Ó gbà wọ́n láyè dáadáa, ó ní kí wọ́n kọ́kọ́ yan akọ màlúù tí wọ́n á fi rúbọ, kí wọ́n sì ké pe Báálì.c—1 Àwọn Ọba 18:24, 25.
Kò sí iṣẹ́ ìyanu lóde òní bíi ti ìgbà àtijọ́. Àmọ́ ṣá, kì í ṣe pé Jèhófà ti yí padà o. Àwa náà lè gbọ́kàn lé e bí Èlíjà ti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, táwọn èèyàn bá ta ko ohun ti Bíbélì sọ, kó yẹ ká bẹ̀rù, ńṣe ni ká fún wọn láyè láti sọ èrò ọkàn wọn. Ká wá jẹ́ kí Ọlọ́run tòótọ́ yanjú ọ̀ràn náà, bíi ti Èlíjà. Bá a ṣe lè ṣe èyí ni pé, ká má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ara wa, kàkà bẹ́ẹ̀ ká gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyí tó wà “fún mímú àwọn nǹkan tọ́.”—2 Tímótì 3:16.
Àwọn wòlíì Báálì ṣètò ẹbọ tí wọ́n fẹ́ rú, wọ́n sì ń ké pe òrìṣà wọn. Wọ́n ṣáà ń kígbe pé, “Báálì, dá wa lóhùn!” Láti òwúrọ̀ ni wọ́n ti kígbe títí di ọ̀sán gangan. Bíbélì sọ pé: “Ṣùgbọ́n kò sí ohùn kankan, kò sì sí ẹnì kankan tí ó dáhùn.” Nígbà tó di ọ̀sán gangan, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, ó ń tẹnu mọ́ ọn pé, bóyá ọwọ́ Báálì dí ni kò fi dá yín lóhùn, tàbí ó fẹ́ ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó fi ní láti lọ sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀, tàbí ó ń sùn ni, ó sì yẹ kí ó jí. Èlíjà wá sọ fún àwọn ẹlẹ́tàn yẹn pé, “Ẹ ké ní bí ohùn yín ṣe lè ròkè tó.” Èlíjà mọ̀ dájú pé ayédèrú ni ìjọsìn Báálì, ó sì fẹ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run fojú ara wọn rí i pé ẹ̀tàn lásánlàsàn ni ìjọsìn Báálì.—1 Àwọn Ọba 18:26, 27.
Kí làwọn wòlíì Báálì ṣe? Ńṣe lorí wọ́n túbọ̀ gbóná tí “wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké ní bí ohùn wọn ṣe lè ròkè tó, wọ́n sì ń fi ọ̀bẹ aláṣóró àti aṣóró gé ara wọn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn, títí wọ́n fi mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn jáde lára wọn.” Ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí! Bíbélì ní: “Kò sí ohùn kankan, kò sì sí ẹnì kankan tí ó dáhùn, kò sì sí fífetísílẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 18:28, 29) Ká sòótọ́, kò sí Báálì kan níbì kankan. Ńṣe ni Sátánì hùmọ̀ rẹ̀ láti lè tan àwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. Bí Báálì ṣe já wọn kulẹ̀ nígbà yẹn, bẹ́ẹ̀ náà ni ohun yòówù téèyàn bá sọ di ọ̀gá tó ń jọ́sìn yàtọ̀ sí Jèhófà ṣe máa já a kulẹ̀, táá sì kó ìtìjú bá a.—Sáàmù 25:3; 115:4-8.
Èsì Ìdánwò
Nígbà tó ń sún mọ́ ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ọpọ́n sún kan Èlíjà láti rúbọ. Ó tún pẹpẹ Jèhófà táwọn ọ̀tá ìjọsìn mímọ́ ti ya lulẹ̀ ṣe. Ó fi òkúta méjìlá mọ ọ́n bóyá láti lè fi rán ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì létí pé wọ́n ṣì wà lábẹ́ òfin tí Ọlọ́run fún gbogbo ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, Èlíjà wá kó àwọn ohun tí yóò fi rúbọ sórí rẹ̀, ó sì da omi sí i. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Òkun Mẹditaréníà tó wà nítòsí ni wọ́n ti lọ pọn omi náà. Èlíjà tiẹ̀ tún ní kí wọ́n wa yàrà yí pẹpẹ náà ká, ó sì pọn omi kún un. Ó gba àwọn wòlíì Báálì láyè dáadáa láti ṣe bó ṣe wù wọ́n, àmọ́ nígbà tó kan ẹbọ ti Jèhófà, ó da omi sí i kó lè dà bí pé iná ò ní lè jó o láéláé. Èyí tó fi hàn pé ó dá a lójú pé kò sóhun tí Ọlọ́run rẹ̀ ò lè ṣe.—1 Àwọn Ọba 18:30-35.
Nígbà tí Èlíjà ṣètò ohun gbogbo tán, ó gbàdúrà. Àdúrà náà kò gùn jànràn janran, àmọ́ ó nítumọ̀, ó sì fi ohun tó jẹ Èlíjà lógún hàn kedere. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó fẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì” kì í ṣe Báálì. Lẹ́yìn náà, ó fẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀ pé ìránṣẹ́ Jèhófà lòun, pé Ọlọ́run ni gbogbo ìyìn àti ògo yẹ. Níkẹyìn, ó fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn òun ṣì jẹ òun lógún, nítorí ó fẹ́ rí i pé Jèhófà “yí ọkàn-àyà wọn padà.” (1 Àwọn Ọba 18:36, 37) Pẹ̀lú gbogbo ìnira táwọn èèyàn náà ti fà nítorí àìnígbàgbọ́ wọn, Èlíjà ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn. Nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ǹjẹ́ àwa náà lè fi hàn pé à ń fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga? Ǹjẹ́ à ń gbàdúrà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, tí a sì ń rántí àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́?
Kí Èlíjà tó gbàdúrà, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn yẹn ti máa rò ó pé, ṣé Jèhófà máa dáhùn àbí tiẹ̀ náà máa dà bíi ti Báálì tó jẹ́ ẹ̀tàn? Lẹ́yìn àdúrà Èlíjà, gbogbo wọn rí i pé ó dáhùn lóòótọ́. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Látàrí ìyẹn, iná Jèhófà já bọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọrẹ ẹbọ sísun náà àti àwọn igi àti àwọn òkúta àti ekuru náà ní àjẹtán, ó sì lá omi tí ó wà nínú yàrà náà láú.” (1 Àwọn Ọba 18:38) Ẹ ò rí i pé ọ̀nà àrà ni Jèhófà gbà dáhùn àdúrà yẹn! Kí làwọn èèyàn náà wá ṣe?
Ńṣe ni gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́! Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!” (1 Àwọn Ọba 18:39) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín wọ́n mọ ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́. Àmọ́ ṣá, wọn ò tíì fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ o. Ká sòótọ́, báwọn èèyàn náà ṣe sọ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ lẹ́yìn tí wọ́n rí iná tó já bọ́ látọ̀run lẹ́yìn àdúrà Èlíjà kò tíì fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́. Ìdí nìyí tí Èlíjà fi ní kí wọ́n ṣe ohun míì tó máa fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́. Ó ní kí wọ́n ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ti ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ìyẹn ni pé kí wọ́n ṣe ohun tí Òfin Jèhófà wí. Òfin Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn wòlíì èké àtàwọn abọ̀rìṣà. (Diutarónómì 13:5-9) Àwọn wòlíì Báálì dìídì sọ ara wọn di ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n sì mọ̀ọ́mọ̀ ń tako ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe. Ǹjẹ́ àánú tọ́ sírú wọn? Rárá o. Torí àwọn náà kì í ṣàánú àwọn ọmọ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tí wọ́n ń dáná sun láàyè láti fi rúbọ sí Báálì. (Òwe 21:13; Jeremáyà 19:5) Dájúdájú, àánú ò tọ́ sí wọn. Nítorí náà, Èlíjà pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo wọn, àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ sì pa wọ́n.—1 Àwọn Ọba 18:40.
Lóde òní àwọn aṣelámèyítọ́ kan ti tako bí Èlíjà ṣe ní kí wọ́n pa àwọn wòlíì Báálì lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì yìí. Àwọn kan lè máa wò ó pé àwọn onítara ìsìn lè lo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí láti wí àwíjàre pé táwọn bá ń ja ìjà ẹ̀sìn kò burú. Ó sì bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ àwọn agbawèrèmẹ́sìn ń dá rògbòdìyàn ìsìn sílẹ̀ lóde òní. Àmọ́, Èlíjà kì í ṣe agbawèrèmẹ́sìn o. Ohun tó tọ́ ni Èlíjà ṣe torí iṣẹ́ Jèhófà ló jẹ́. Síwájú sí i, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé àwọn kò gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí Èlíjà ṣe, ìyẹn ni pé kí wọ́n pa àwọn ẹni burúkú. Lẹ́yìn tí Mèsáyà ti wá sáyé, ìlànà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń tẹ̀ lé wà nínú ọ̀rọ̀ tí Kristi sọ fún Pétérù, ó ní: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà yóò lo Ọmọ rẹ̀ láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ.
Ojúṣe Kristẹni kọ̀ọ̀kan ni láti gbé ìgbé ayé tó fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́. (Jòhánù 3:16) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe èyí ni pé ká máa fara wé àwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ bí Èlíjà. Ó sin Jèhófà tọkàntọkàn, ó sì tún rọ àwọn ẹlòmíì láti ṣe bẹ́ẹ̀. Láìṣojo, ó jẹ́ kó hàn pé ayédèrú ni ẹ̀sìn kan tí Sátánì ń lò láti fi tan àwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. Èlíjà kò ṣe ìfẹ́ inú ara rẹ̀ tàbí kó gbára lé agbára rẹ̀, Jèhófà ló gbẹ́kẹ̀ lé pé kó yanjú ọ̀ràn. Láìsí àní-àní, Èlíjà gbèjà ìjọsìn mímọ́. Ẹ jẹ́ kí àwa náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ láàárín Èlíjà àti Áhábù ṣáájú àkókò yìí, ka àpilẹ̀kọ náà “Iwọ Ha Ni Igbagbọ Bii Ti Elija Bi?” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, April 1, 1992.
b Torí pé afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ wá láti òkun máa ń mú kí òjò rọ̀ kí ìrì sì máa sẹ̀ láyìíká Kámẹ́lì, ṣe ni àwọn ewéko ibẹ̀ sábà máa ń tutù yọ̀yọ̀. Àwọn tó ń sin Báálì wá ka orí òkè yìí sí ojúbọ pàtàkì, torí wọ́n gbà pé Báálì ló ń rọ̀jò. Ní báyìí tí orí òkè yìí ti wá gbẹ táútáú, ibẹ̀ ló dáa jú láti fìpàdé sí kó lè hàn kedere pé ẹ̀sìn èké lẹ̀sìn Báálì.
c Ó ṣe pàtàkì bí Èlíjà ṣe sọ fáwọn èèyàn náà pé, “ẹ má fi iná sí” ẹbọ náà. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé àwọn abọ̀rìṣà wọ̀nyẹn sábà máa ń dá ihò sábẹ́ pẹpẹ, tí wọ́n á wá fi iná sí ihò yẹn kó lè dà bí pé ọ̀nà ìyanu ni iná gbà wá.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]
Ńṣe ni ohun yòówù téèyàn bá sọ di ọ̀gá tó ń jọ́sìn yàtọ̀ sí Jèhófà máa ń jáni kulẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
“Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!”