ORÍ KEJÌLÁ
Ọlọ́run Rẹ̀ Tù Ú Nínú
1, 2. Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fún Èlíjà yìí?
ÈLÍJÀ ń sáré lọ nínú òjò bí ilẹ̀ ṣe túbọ̀ ń ṣú. Ọ̀nà rẹ̀ ṣì jìn sí Jésíréélì, bẹ́ẹ̀ sì rèé, Èlíjà tá à ń wí yìí kì í ṣe ọmọdé o. Síbẹ̀, ó ń sáré tete, kò sì rẹ̀ ẹ́ nítorí “ọwọ́ Jèhófà” wà lára rẹ̀. Agbára rẹ̀ kò pọ̀ tó báyìí rí. Ó pọ̀ débi pé, ó tiẹ̀ tún sáré kọjá àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ Áhábù Ọba pàápàá!—Ka 1 Ọba 18:46.
2 Wàyí o, Èlíjà fi Áhábù sílẹ̀ sẹ́yìn jìnnà-jìnnà, ó ń bá iná piti eré lọ níwájú. Fojú inú wo bí ọwọ́ òjò náà yóò ṣe máa bà á lójú bó ṣe ń sáré lọ, tó ń ronú nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Ó dájú pé lọ́jọ́ yìí, Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà àti ìsìn mímọ́ ṣẹ́gun, wọ́n sì gbògo. Ní báyìí, ọ̀nà Èlíjà ti wá jìn gan-an sí Òkè Ńlá Kámẹ́lì níbi tí Jèhófà ti lò ó lọ́nà ìyanu láti dójú ti Báálì àti àwọn tó ń bọ ọ́, òjò ńlá tó ń rọ̀ kò sì jẹ́ kó lè rí orí òkè náà mọ́. Àṣírí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn wòlíì Báálì tú lórí òkè yẹn pé olubi àti ẹlẹ̀tàn ni wọ́n, wọ́n sì pa wọ́n bó ṣe tọ́ sí wọn gẹ́lẹ́. Lẹ́yìn náà, Èlíjà wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fòpin sí ọ̀dá tó ti ń pọ́n àwọn èèyàn ilẹ̀ náà lójú láti ọdún mẹ́ta ààbọ̀ sẹ́yìn. Òjò sì rọ̀!—1 Ọba 18:18-45.
3, 4. (a) Kí nìdí tí Èlíjà fi lè máa retí pé nǹkan máa yí pa dà wàyí bó ṣe ń sáré lọ sí Jésíréélì? (b) Àwọn ìbéèrè wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò?
3 Bí Èlíjà ṣe ń sáré nínú òjò náà lọ sí Jésíréélì tó wà ní ọgbọ̀n kìlómítà sí ibi tó wà, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ náà lè mú kó máa retí pé gbogbo nǹkan máa yí pa dà wàyí. Ó lè máa ronú pé bí wọ́n ṣe pa àwọn wòlíì Báálì yẹn ìgbà ọ̀tun ti dé. Áhábù máa yí pa dà ṣáá ni! Dájúdájú, àwọn nǹkan tí Áhábù rí yẹn máa mú kó pa ìjọsìn Báálì tì, kò sì ní jẹ́ kí Jésíbẹ́lì aya rẹ̀ bọ òrìṣà mọ́, á sì tún fòpin sí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà.
4 Tí nǹkan bá ń lọ bá a ṣe fẹ́, a sábà máa ń rò pé a ti bọ́ sáyé, àti pé ṣe ni gbogbo nǹkan á máa ṣẹnuure lọ fún wa. A tiẹ̀ lè máa ronú pé a ti borí àwọn òkè ìṣòro wa pàápàá. Tí Èlíjà náà bá ní èrò wọ̀nyí, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu, torí pé “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa” ni. (Ják. 5:17) Àmọ́ ṣá o, ìṣòro Èlíjà kò tíì tán rárá. Torí, ní wákàtí díẹ̀ sí i, ẹ̀rù máa ba Èlíjà gan-an, ìdààmú ọkàn rẹ̀ yóò sì pọ̀, débi pé yóò fẹ́ láti kú. Kí ló wá fà á? Báwo ni Jèhófà sì ṣe ran wòlíì rẹ̀ yìí lọ́wọ́ tí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà rẹ̀ fi sọ jí? Ẹ jẹ́ ká wò ó.
Nǹkan Yí Pa Dà Bìrí
5. Ǹjẹ́ Áhábù bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀wọ̀ fún Jèhófà lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì? Báwo la ṣe mọ̀?
5 Nígbà tí Áhábù dé ààfin rẹ̀ ní Jésíréélì, ǹjẹ́ ó fi hàn pé òun ti ronú pìwà dà? Ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Áhábù sọ fún Jésíbẹ́lì nípa gbogbo ohun tí Èlíjà ṣe àti gbogbo bí ó ṣe fi idà pa gbogbo wòlíì.” (1 Ọba 19:1) Kíyè sí i pé nígbà tí Áhábù ń ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà, kò mẹ́nu kan Jèhófà, Ọlọ́run Èlíjà. Nítorí pé Áhábù kò sún mọ́ Ọlọ́run, ṣe ló ka iṣẹ́ ìyanu tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn sí “ohun tí Èlíjà ṣe,” kò kà á sí iṣẹ́ Ọlọ́run. Ó ṣe kedere pé kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run. Kí ni aya rẹ̀ tó jẹ́ òǹrorò sì wá ṣe?
6. Iṣẹ́ wo ni Jésíbẹ́lì rán sí Èlíjà, kí ló sì túmọ̀ sí?
6 Jésíbẹ́lì gbaná jẹ! Ó wá ránṣẹ́ sí Èlíjà tìbínú-tìbínú pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọlọ́run ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni kí wọ́n fi kún un, bí èmi kò bá ní ṣe ọkàn rẹ bí ọkàn olúkúlùkù wọn ní ìwòyí ọ̀la!” (1 Ọba 19:2) Nǹkan tó burú jáì ni obìnrin yìí fi lérí ikú gbígbóná sí Èlíjà. Ohun tó ń sọ ni pé kí ikú pa òun, tí òun kò bá pa Èlíjà kí ilẹ̀ ọjọ́ kejì tó ṣú, láti gbẹ̀san àwọn wòlíì Báálì tó pa. Fojú inú wo bó ṣe máa rí lára Èlíjà nígbà tí wọ́n jí i lójú oorun níbi tó sùn sí ní Jésíréélì lálẹ́ ọjọ́ tí òjò rọ̀ náà, tí wọ́n sì ń jẹ́ iṣẹ́ burúkú tí ayaba rán sí i. Kí ló wá ṣe?
Ìrẹ̀wẹ̀sì Dé Bá A, Ẹ̀rù sì Bà Á
7. Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Jésíbẹ́lì fún Èlíjà, báwo ló ṣe rí lára rẹ̀? Kí ni Èlíjà ṣe?
7 Bí Èlíjà bá rò pé ìjọsìn Báálì ti di àgbáwọlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló máa rí i pé ọ̀rọ̀ ti bẹ́yìn yọ. Torí Jésíbẹ́lì fàáké kọ́rí, kò jáwọ́. Àìmọye àwọn olóòótọ́ bí Èlíjà ni obìnrin yìí ti ṣekú pa, ó sì jọ pé Èlíjà ló fẹ́ nawọ́ gán wàyí. Báwo ló ṣe wá rí lára Èlíjà nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Jésíbẹ́lì fún? Bíbélì sọ pé: “Àyà sì bẹ̀rẹ̀ sí fò ó.” Ṣé Èlíjà ti ro irú ikú oró tí Jésíbẹ́lì máa ní kí wọ́n fi pa òun ni? Tó bá jẹ́ kí irú èrò yìí gbà á lọ́kàn, ẹ̀rù máa bà á lóòótọ́. Lọ́rọ̀ kan ṣá, Èlíjà “bẹ̀rẹ̀ sí lọ nítorí ọkàn rẹ̀,” ìyẹn ni pé ó sá kí wọ́n má bàa pa á.—1 Ọba 18:4; 19:3.
Tá ò bá fẹ́ pàdánù ìgboyà tá a ní, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn nǹkan tó bá ń bà wá lẹ́rù gbà wá lọ́kàn
8. (a) Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù ṣe jọ ti Èlíjà? (b) Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà àti Pétérù?
8 Èlíjà nìkan kọ́ ni olóòótọ́ èèyàn tó ṣojo. Irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù náà nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tí Jésù ń rìn lórí omi, ó ní kí Pétérù máa bọ̀. Bí Pétérù ṣe ń rìn lórí omi, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wo “ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà.” Ẹ̀rù wá bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. (Ka Mátíù 14:30.) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà àti Pétérù yìí kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ẹ̀kọ́ náà ni pé tá ò bá fẹ́ pàdánù ìgboyà tá a ní, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn nǹkan tó bá ń bà wá lẹ́rù gbà wá lọ́kàn. Ṣe ni ká ṣáà gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tó ń fún wa ní ìrètí àti agbára.
“Ó Tó Gẹ́ẹ́!”
9. Sọ bí ìrìn àjò Èlíjà ṣe rí àti ipò ọkàn rẹ̀ nígbà tó ń sá lọ.
9 Ẹ̀rù tó ba Èlíjà mú kó sá gba gúúsù ìwọ̀ oòrùn lọ sí ìlú Bíá-ṣébà tó wà nítòsí àlà ilẹ̀ Júdà lápá gúúsù. Ó jìnnà tó nǹkan bí àádọ́jọ [150] kìlómítà. Ó wá fi ẹmẹ̀wà rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, ó forí lé ọ̀nà aginjù lóun nìkan. Bíbélì sọ pé ó rin “ìrìn àjò ọjọ́ kan.” Torí náà, a lè fojú inú wò ó pé òwúrọ̀ ló gbéra ìrìn náà, ẹ̀rí sì fi hàn pé kò mú oúnjẹ, omi tàbí àwọn nǹkan míì tó nílò dání. Ìdààmú ọkàn tó bá a àti ẹ̀rù tó ń bà á ń mú kó tẹsẹ̀ mọ́rìn nínú aginjù tó rí gbágungbàgun tó dorí kọ nínú oòrùn tó mú ganrín-ganrín. Nígbà tó fi máa di pé oòrùn ń wọ̀ lọ, tí ilẹ̀ ń ṣú, ó ti wá rẹ̀ ẹ́. Ó rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu débi pé ó kàn jókòó wọ̀ọ̀ sábẹ́ igi wíwẹ́ kan, torí ibẹ̀ nìkan ló rí nítòsí tó lè forí pa mọ́ sí láàárín aginjù gbalasa náà.—1 Ọba 19:4.
10, 11. (a) Kí ni ìtumọ̀ àdúrà tí Èlíjà gbà sí Jèhófà? (b) Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí, kó o wá sọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì tí ìdààmú ọkàn bá.
10 Èlíjà wá gbàdúrà nínú ìdààmú ọkàn rẹ̀ pé òun fẹ́ kú. Ó ní: “Èmi kò sàn ju àwọn baba ńlá mi.” Èlíjà mọ̀ pé àwọn baba ńlá òun ti di erùpẹ̀ nígbà yẹn, pé egungun wọn ló ṣẹ́ kù sínú ibojì, kò sì sí ìrànlọ́wọ́ kankan tí wọ́n lè ṣe fún ẹnikẹ́ni. (Oníw. 9:10) Èlíjà ní òun náà kò yàtọ̀ sí wọn mọ́. Abájọ tó fi ké jáde pé: “Ó tó gẹ́ẹ́!” Ìyẹn ni pé, kí ni mo tún wà láàyè fún?
11 Ṣé ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ìdààmú ọkàn lè bá èèyàn Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀? Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu o. Àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin wà nínú Bíbélì tí ìdààmú ọkàn bá gan-an débi pé wọ́n fẹ́ láti kú. Lára wọn ni Rèbékà, Jákọ́bù, Mósè àti Jóòbù.—Jẹ́n. 25:22; 37:35; Núm. 11:13-15; Jóòbù 14:13.
12. Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíjà tí ìdààmú ọkàn bá bá ọ?
12 Lóde òní, a wà ní “àkókò tó le koko láti bá lò,” nítorí náà kò yani lẹ́nu pé, ìdààmú ọkàn máa ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà míì, títí kan àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàápàá. (2 Tím. 3:1) Tí o bá wà ní irú ipò tó le yẹn, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíjà, kó o sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún Ọlọ́run. Ó ṣe tán, Jèhófà ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.) Ǹjẹ́ ó tu Èlíjà nínú?
Jèhófà Fún Wòlíì Rẹ̀ Lókun
13, 14. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe tipasẹ̀ áńgẹ́lì kan bójú tó wòlíì rẹ̀ tí ìdààmú ọkàn bá? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ ìtùnú fún wa pé Jèhófà mọ gbogbo wa tinú tòde, títí kan ibi tí agbára wa mọ?
13 Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà lọ́run bó ṣe ń wo wòlíì rẹ̀ tó fẹ́ràn yìí tó dùbúlẹ̀ sábẹ́ igi ní aginjù, tó ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ikú pa òun? Ó dájú pé àánú rẹ̀ máa ṣe é. Nígbà tí Èlíjà sùn lọ fọnfọn, Jèhófà wá rán áńgẹ́lì kan sí i. Áńgẹ́lì náà rọra jí Èlíjà pẹ́pẹ́, ó ní: “Dìde, jẹun.” Èlíjà sì dìde jẹun, torí áńgẹ́lì náà gbé oúnjẹ kan wá fún un, ìyẹn búrẹ́dì tó gbóná fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ àti omi. Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ áńgẹ́lì náà? Bóyá ni. Torí ohun tí Bíbélì kàn sọ ni pé wòlíì náà jẹ, ó mu, ó sì pa dà sùn. Àbí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn rẹ̀ ló pọ̀ débi tí kò fi lè sọ̀rọ̀ ni? Láìfọ̀rọ̀ gùn, áńgẹ́lì náà jí Èlíjà lẹ́ẹ̀kejì, bóyá ní àfẹ̀mọ́jú. Ó tún rọ̀ ọ́ pé, “Dìde, jẹun, nítorí ìrìn àjò náà pọ̀ jù fún ọ.” Ọ̀rọ̀ pàtàkì ló sì sọ yìí.—1 Ọba 19:5-7.
14 Ọlọ́run fún áńgẹ́lì náà ní òye tó fi mọ ibi tí Èlíjà ń lọ. Ó tún mọ̀ pé ìrìn àjò náà máa kọjá agbára ti Èlíjà fúnra rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìtùnú ló jẹ́ láti máa sin Ọlọ́run tó mọ àwọn àfojúsùn wa àti ibi tí agbára wa mọ ju bí àwa fúnra wa ṣe mọ̀ ọ́n lọ! (Ka Sáàmù 103:13, 14.) Báwo ni oúnjẹ náà ṣe ṣe Èlíjà láǹfààní?
15, 16. (a) Kí ni oúnjẹ tí Jèhófà pèsè fún Èlíjà fún un lágbára láti ṣe? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára lónìí?
15 Bíbélì sọ pé: “Ó dìde, ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì ń lọ nípasẹ̀ agbára oúnjẹ yẹn fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, títí dé Hórébù, òkè ńlá Ọlọ́run tòótọ́.” (1 Ọba 19:8) Èlíjà gbààwẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru bíi ti Mósè tó gbé láyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ọdún ṣáájú rẹ̀ àti Jésù tó gbé láyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Èlíjà. (Ẹ́kís. 34:28; Lúùkù 4:1, 2) Oúnjẹ tó jẹ yẹn kò tán gbogbo ìṣòro rẹ̀ o, àmọ́ ó ń fún un lágbára lọ́nà ìyanu bó ṣe ń lọ. Ẹ ò rí i pé ohun ìyanu ló jẹ́ bí àgbàlagbà yẹn ṣe ń fẹsẹ̀ la aginjù lọ lójoojúmọ́ fún nǹkan bí oṣù kan ààbọ̀!
16 Lónìí náà, Jèhófà máa ń pèsè oúnjẹ tó ń fúnni lágbára fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àmọ́ irú oúnjẹ nípa tara tó pèsè fún Èlíjà lọ́nà ìyanu kọ́ ló ń fún wọn o. Oúnjẹ tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ ni. (Mát. 4:4) Tí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run látinú Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n gbé ka orí Bíbélì, wọ́n á máa fún wa ní agbára tí a ó fi máa sin Ọlọ́run nìṣó. Tá a bá ń jẹ irú oúnjẹ tẹ̀mí bẹ́ẹ̀, ó lè ṣàì mú gbogbo ìṣòro wa kúrò, àmọ́ yóò jẹ́ ká lè fara da ohun tí à bá má lè fara dà ní agbára tiwa. Yóò tún jẹ́ ká lè ní “ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòh. 17:3.
17. Ibo ni Èlíjà lọ, kí sì nìdí tó fi jẹ́ ibi tó ṣe pàtàkì?
17 Èlíjà rin ìrìn nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ó lé ogún kìlómítà [320] lọ sí Òkè Hórébù, ìyẹn Òkè Sínáì. Ibi pàtàkì ni, torí ibẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run ti tipasẹ̀ áńgẹ́lì kan fara han Mósè lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, níbi igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún tó ń jó. Ibẹ̀ náà ló ti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú Òfin lẹ́yìn náà. Nígbà tí Èlíjà débẹ̀, ó kọjá lọ sínú ihò àpáta kan.
Bí Jèhófà Ṣe Tu Wòlíì Rẹ̀ Nínú Tó sì Fún Un Lókun
18, 19. (a) Ìbéèrè wo ni áńgẹ́lì tí Jèhófà rán sí Èlíjà bi í? (b) Ohun mẹ́ta wo ló fa ìdààmú ọkàn Èlíjà?
18 Jèhófà wá gbẹnu áńgẹ́lì kan sọ “ọ̀rọ̀” fún Èlíjà lókè Hórébù yìí. Áńgẹ́lì náà bi í ní ìbéèrè ṣókí kan pé: “Kí ni iṣẹ́ rẹ níhìn-ín, Èlíjà?” Ó jọ pé ohùn pẹ̀lẹ́ ló fi béèrè ìbéèrè náà, torí Èlíjà kà á sí pé ṣe ló fẹ́ mọ ẹ̀dùn ọkàn òun. Ó sì sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ pátá! Ó ní: “Mo ti ń jowú fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun; nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, àwọn pẹpẹ rẹ ni wọ́n ti ya lulẹ̀, àwọn wòlíì rẹ sì ni wọ́n ti fi idà pa, tí ó fi jẹ́ pé èmi nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ọkàn mi láti gbà á kúrò.” (1 Ọba 19:9, 10) Ọ̀rọ̀ tí Èlíjà sọ yìí jẹ́ ká mọ ohun mẹ́ta, ó kéré tán, tó fa ìdààmú ọkàn rẹ̀.
19 Àkọ́kọ́ ni pé, Èlíjà rò pé iṣẹ́ òun já sásán. Ṣé ẹ rí i, ọ̀pọ̀ ọdún ni Èlíjà ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tó “ń jowú” nítorí rẹ̀, tó ń gbé orúkọ mímọ́ rẹ̀ àti ìjọsìn rẹ̀ lékè ohun gbogbo yòókù, síbẹ̀ nǹkan ń burú sí i ni. Àwọn èèyàn náà ṣì ya aláìnígbàgbọ́ àti ọlọ̀tẹ̀, ìbọ̀rìṣà sì túbọ̀ ń gbilẹ̀. Èkejì ni pé, Èlíjà gbà pé òun nìkan lòun dá dúró. Ó sọ pé, “èmi nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù,” bíi pé yàtọ̀ sí òun, kò tún sí ẹlòmíì tó ń sin Jèhófà mọ́ ní orílẹ̀-èdè náà. Ẹ̀kẹta ni pé, ẹ̀rù ń bà á. Ọ̀pọ̀ wòlíì bíi tiẹ̀ ni wọ́n ti pa, ó sì dá a lójú pé òun ló kàn báyìí tí wọ́n fẹ́ pa. Ó lè má rọrùn fún Èlíjà láti sọ ọ́ jáde lẹ́nu pé nǹkan wọ̀nyí ni ìṣòro òun, àmọ́ kò jẹ́ kí ìgbéraga tàbí ìtìjú dí òun lọ́wọ́ láti sọ ọ́. Bó ṣe sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Ọlọ́run rẹ̀ nínu àdúrà, ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún gbogbo àwọn tó jẹ́ olóòótọ́.—Sm. 62:8.
20, 21. (a) Àwọn nǹkan wo ni Èlíjà rí lẹ́nu ihò àpáta tó wà ní Òkè Hórébù? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni Èlíjà kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe fi agbára rẹ̀ hàn án?
20 Kí ni Jèhófà ṣe nípa ẹ̀rù tó ń ba Èlíjà àti nípa àníyàn rẹ̀? Áńgẹ́lì náà sọ fún Èlíjà pé kó dúró sí ẹnu ihò àpáta náà. Ó sì dúró síbẹ̀, láìmọ ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀. Lójijì, ẹ̀fúùfù ńláǹlà bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́! Ó dà bíi pé ìró rẹ̀ pàápàá máa fẹ́rẹ̀ẹ́ lè dini létí, nítorí agbára rẹ̀ pọ̀ débi pé ó fa àwọn òkè àtàwọn àpáta gàǹgà ya. Fojú inú wo bí Èlíjà ṣe máa fọwọ́ dí ojú rẹ̀, táá sì máa kó aṣọ onírun tó nípọn tó wà lára rẹ̀ mọ́ra bí afẹ́fẹ́ líle náà ṣe fẹ́ gba aṣọ mọ́ ọn lára. Lẹ́yìn èyí, ilẹ̀ ibẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mì débi pé ó ní láti máa dura kó lè dúró dáadáa nítorí ìmìtìtì ilẹ̀ náà. Bí ìyẹn ṣe ń rọlẹ̀, ni iná ńlá kan tún wáyé. Ló bá sá pa dà sínú ihò àpáta yẹn torí bí ooru iná náà ṣe gbóná janjan.—1 Ọba 19:11, 12.
21 Bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, tó ń jẹ́ kí Èlíjà rí agbára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, ṣe ń ṣẹlẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan, Bíbélì ń jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kò sí nínú èyíkéyìí lára wọn. Èlíjà mọ̀ pé Jèhófà ò dà bí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń pè mọ́ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Irú bíi Báálì tí àwọn tó ń bọ ọ́, tí wọ́n ti tàn jẹ, máa ń kì pé ó jẹ́ “ẹni tó ń gun sánmà kiri bí ẹṣin,” ìyẹn ẹni tó ń mú òjò wá. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo agbára kíkàmàmà tó wà nínú àwọn ìṣẹ̀dá ti wá, àmọ́ Jèhófà fúnra rẹ̀ ga ju gbogbo ohun tó dá lọ fíìfíì. Àwọn ọ̀run pàápàá kò lè gba Jèhófà! (1 Ọba 8:27) Báwo ni gbogbo nǹkan tí Èlíjà rí yìí ṣe wá ràn án lọ́wọ́? Ẹ rántí pé ẹ̀rù ló ń ba Èlíjà tó fi sá. Àmọ́ pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà Ọlọ́run tó ni gbogbo agbára kíkàmàmà yẹn, kò yẹ kí Èlíjà bẹ̀rù Áhábù àti Jésíbẹ́lì rárá!—Ka Sáàmù 118:6.
22. (a) Báwo ni “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” tí Èlíjà gbọ́ ṣe mú kó túbọ̀ dá a lójú pé ó wúlò gan-an? (b) Ta ló ṣeé ṣe kó sọ̀rọ̀ ní “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” yìí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
22 Lẹ́yìn iná náà, gbogbo nǹkan pa rọ́rọ́, Èlíjà sì wá gbọ́ “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” kan. Ohùn náà bi Èlíjà ní ìbéèrè tó máa jẹ́ kó tún sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀, ló bá tún sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì.a Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn túbọ̀ mú kí ara tù ú. Àmọ́ ó dájú pé ohun tí “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” náà sọ fún un lẹ́yìn náà ló tù ú nínú jù. Jèhófà mú kó túbọ̀ dá Èlíjà lójú pé ó wúlò fún òun gan-an ni. Báwo ló ṣe ṣe é? Ṣe ni Ọlọ́run sọ fún Èlíjà nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tí òun máa ṣe lọ́jọ́ iwájú láti fòpin sí ìjọsìn Báálì lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Èyí fi hàn pé iṣẹ́ tí Èlíjà ṣe kò já sásán, torí kò sí ohun tó lè dènà ìpinnu Ọlọ́run lórí ìjọsìn Báálì tó ń ní ìmúṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Èlíjà ṣì máa kópa nínú ìpinnu Ọlọ́run tó ń ní ìmúṣẹ yìí, torí Jèhófà ní kó pa dà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó sì sọ àwọn nǹkan tó máa ṣe fún un.—1 Ọba 19:12-17.
23. Ohun méjì wo ni Jèhófà ṣe nípa bí Èlíjà ṣe rò pé ńṣe lòun dá dúró?
23 Àmọ́, kí ni Jèhófà ṣe nípa bí Èlíjà ṣe rò pé ńṣe lòun dá dúró? Ohun méjì ni Jèhófà ṣe nípa rẹ̀. Àkọ́kọ́ ni pé, ó sọ fún Èlíjà pé kó fòróró yan Èlíṣà ṣe wòlíì tí yóò rọ́pò rẹ̀ nígbà tó bá yá. Ọkùnrin tó kéré sí Èlíjà lọ́jọ́ orí yìí yóò jẹ́ ẹnì kejì rẹ̀, tí yóò máa ràn án lọ́wọ́ fún ọdún bíi mélòó kan. Ẹ wo bí ìyẹn ṣe máa tu Èlíjà nínú tó! Èkejì ni pé, Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ amóríyá yìí fún un pé: “Mo sì ti jẹ́ kí ó ṣẹ́ ku ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ní Ísírẹ́lì, gbogbo eékún tí kò tẹ̀ ba fún Báálì, àti olúkúlùkù ẹnu tí kò fi ẹnu kò ó lẹ́nu.” (1 Ọba 19:18) Ìyẹn ni pé Èlíjà nìkan kọ́ ló ṣẹ́ kù. Inú Èlíjà máa dùn gan-an nígbà tó gbọ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún olóòótọ́ èèyàn ṣì wà tó kọ̀ láti bọ Báálì. Àwọn èèyàn yìí á fẹ́ kí Èlíjà máa bá ìṣòtítọ́ rẹ̀ nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, kó jẹ́ àpẹẹrẹ ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ní àkókò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ya ọlọ̀tẹ̀ yẹn. Dájúdájú, ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fi rán ońṣẹ́ rẹ̀ láti sọ fún Èlíjà ní “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” yìí máa wọ Èlíjà lọ́kàn gan-an ni.
Bíbélì lè dà bí “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” yẹn fún wa lóde òní, tí a bá jẹ́ kó máa ṣamọ̀nà wa
24, 25. (a) Báwo la ṣe lè gbọ́ “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” tí Jèhófà fi ń sọ̀rọ̀ lóde òní? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Èlíjà sọ tù ú nínú?
24 Ẹnu lè ya àwa náà bíi ti Èlíjà tí a bá rí agbára kíkàmàmà tó wà nínú ìṣẹ̀dá. Bó sì ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn. Nítorí pé àwọn ohun tí Ọlọ́run dá máa ń jẹ́ ká rí agbára Ẹlẹ́dàá lọ́nà tó ṣe kedere. (Róòmù 1:20) Bákan náà, Jèhófà ṣì máa ń lo agbára rẹ̀ tí kò láàlà láti fi ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lọ́wọ́ lónìí. (2 Kíró. 16:9) Àmọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló fi ń bá wa sọ̀rọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. (Ka Aísáyà 30:21.) Nítorí náà, Bíbélì lè dà bí “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” yẹn fún wa, tí a bá jẹ́ kó máa ṣamọ̀nà wa lóde òní. Jèhófà máa ń fi ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà, ó fi ń fún wa níṣìírí, ó sì fi ń mú un dá wa lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wa.
25 Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Èlíjà sọ ní orí Òkè Hórébù tù ú nínú? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ní kíá, wòlíì olóòótọ́ yìí pa dà sẹ́nu iṣẹ́, ó tún ń fi ìgboyà gbógun ti ìbọ̀rìṣà nìṣó. Bákan náà, tí a bá ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì tó ní ìmísí Ọlọ́run, ìyẹn “ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́” sọ́kàn, a ó lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Èlíjà.—Róòmù 15:4.
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé áńgẹ́lì tó sọ “ọ̀rọ̀ Jèhófà” fún Èlíjà ní 1 Àwọn Ọba 19:9 náà ló tún sọ̀rọ̀ ní “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” níbí. Ní ẹsẹ 15, Bíbélì pe áńgẹ́lì náà ní “Jèhófà.” Èyí lè mú wa rántí áńgẹ́lì tí Jèhófà ní kó máa tọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́nà ní aginjù, ẹni tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ pé: “Orúkọ mi wà lára rẹ̀.” (Ẹ́kís. 23:21) Lóòótọ́, a kò lè sọ pàtó pé ẹni báyìí ni, àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ṣáájú kí Jésù tó wá sí ayé, òun ni “Ọ̀rọ̀ náà,” ìyẹn Agbọ̀rọ̀sọ pàtàkì tí Jèhófà máa ń rán sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Jòh. 1:1.