Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó Rí Ìtùnú Gbà Lọ́dọ̀ Ọlọ́run Rẹ̀
ÈLÍJÀ ń sáré lọ nínú òjò bí ojú ọ̀run ṣe túbọ̀ ń ṣú sí i. Ọ̀nà rẹ̀ ṣì jìn sí Jésíréélì, ẹni tá a sì ń wí yìí kì í ṣe ọmọdé mọ́. Síbẹ̀, ó ń sáré tete, kò sì rẹ̀ ẹ́ nítorí “ọwọ́ Jèhófà” wà lára rẹ̀. Agbára tó wà lára rẹ̀ yìí pọ̀ ju èyí tó ní tẹ́lẹ̀ lọ. Ó pọ̀ débi pé, ó fẹsẹ̀ sáré kọjá lára àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ẹṣin Áhábù Ọba!—1 Àwọn Ọba 18:46.
Wàyí o, Èlíjà ti fi Áhábù Ọba sílẹ̀ sẹ́yìn ti pẹ́, ibi tí Èlíjà ń lọ ṣì jìnnà gan-an. Fojú inú wo bí òjò ṣe ń pa Èlíjà burúkú-burúkú bó ṣe ń sáré lọ, tó sì ń ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé rẹ̀ yìí. Kò sí àní-àní pé, ìṣẹ́gun ológo ni èyí jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà, ó sì gbé ìjọsìn tòótọ́ ga. Ọ̀nà Èlíjà ti jìnnà gan-an sí òkè Kámẹ́lì, ìjì tó ń jà ti mú kí orí òkè náà ṣú dùdù. Orí òkè yìí ni Jèhófà ti lo Èlíjà láti ṣẹ́gun ìjọsìn Báálì lọ́nà ìyanu. Ibẹ̀ ni àṣírí ìwà ibi ọgọ́rùn-ún mélòó kan àwọn wòlíì Báálì ti tú, wọ́n pa wọ́n, ohun tó sì tọ́ sí wọn gan-an nìyẹn. Lẹ́yìn náà ni Èlíjà gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fòpin sí ọ̀dá tó ti ń pọ́n àwọn èèyàn ilẹ̀ náà lójú láti ọdún mẹ́ta ààbọ̀ sẹ́yìn. Òjò sì rọ̀!a—1 Àwọn Ọba 18:18-45.
Bí Èlíjà ṣe ń sáré gba inú òjò náà lọ sí Jésíréélì tó tó ìrìn-àjò ọgbọ̀n kìlómítà, ìparun àwọn wòlíì Báálì yìí ti ní láti mú kí ó gbà pé ìyípadà ní láti wà. Áhábù ní láti yí pa dà! Ó dájú pé, àwọn nǹkan tí Áhábù rí yẹn máa mú kó pa ìjọsìn Báálì tì, á sì kìlọ̀ fún Jésíbẹ́lì, ìyàwó rẹ̀ pé kó jáwọ́ nínú ìjọsìn yìí, á sì fòpin sí inúnibíni tó ń ṣe sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà.
Tí nǹkan bá ń lọ bá a ṣe fẹ́, inú wa máa ń dùn, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀. A máa ń rò pé nǹkan á máa ṣẹnuure fún wa, a tiẹ̀ lè máa ronú pé a ti borí àwọn òkè ìṣòro wa pàápàá. Kò ní yà wá lẹ́nu tí Èlíjà bá ní irú èrò yìí, torí pé “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa” ni. (Jákọ́bù 5:17) Àmọ́ ṣá o, ìṣòro Èlíjà kò tíì tán. Nítorí pé, ní wákàtí díẹ̀ sí i, ẹ̀rù máa ba Èlíjà gan-an, ìdààmú ọkàn yóò sì bá a, débi tí á fi fẹ́ láti kú. Kí ló ṣẹlẹ̀? Báwo ni Jèhófà ṣe ran wòlíì rẹ̀ yìí lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lè pọ̀ sí i, tí á sì túbọ̀ ní ìgboyà? Ẹ jẹ́ ká wò ó.
Nǹkan Yí Pa Dà Bìrí
Nígbà tí Áhábù dé ààfin rẹ̀ ní Jésíréélì, ǹjẹ́ ó fẹ̀rí hàn pé òun ti yí pa dà, pé òun ti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run? Bíbélì sọ pé: “Áhábù sọ fún Jésíbẹ́lì nípa gbogbo ohun tí Èlíjà ṣe àti gbogbo bí ó ṣe fi idà pa gbogbo wòlíì.” (1 Àwọn Ọba 19:1) Ẹ kíyè sí pé nígbà tí Áhábù ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, kò sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run Èlíjà. Nítorí pé Áhábù kò bẹ̀rù Ọlọ́run, èrò rẹ̀ nípa iṣẹ́ ìyanu tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ni pé, “ohun tí Èlíjà ṣe” ni, kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Ó ṣe kedere pé kò tíì gbà pé ó yẹ kí òun máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run. Kí sì ni Jésíbẹ́lì to fẹ́ràn láti máa gbẹ̀san ṣe?
Inú bí i gan-an! Ó ránṣẹ́ sí Èlíjà tìbínú-tìbínú pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọlọ́run ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni kí wọ́n fi kún un, bí èmi kò bá ní ṣe ọkàn rẹ bí ọkàn olúkúlùkù wọn ní ìwòyí ọ̀la!” (1 Àwọn Ọba 19:2) Ó fi ikú dẹ́rù ba Èlíjà lọ́nà tó kàmàmà. Ohun tí Jésíbẹ́lì ń sọ ni pé, kí òun kú, tí òun kò bá pa Èlíjà lọ́jọ́ kejì láti gbẹ̀san àwọn wòlíì Báálì lára rẹ̀. Fojú inú wo bó ṣe máa rí lára Èlíjà nígbà tí wọ́n jí i lójú oorun níbi tó sùn sí ní Jésíréélì lálẹ́ ọjọ́ tí òjò rọ̀ náà tó wá ń gbọ́ iṣẹ́ burúkú tí ayaba rán sí i. Kí ló máa ṣe?
Ó Ní Ìrẹ̀wẹ̀sì, Ẹ̀rù sì Bà Á
Bí Èlíjà bá rò pé ìjọsìn Báálì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin, ibi tó fojú sí ọ̀nà ò gba ibẹ̀ o. Nítorí pé, Jésíbẹ́lì kò tíì yí èrò rẹ̀ pa dà lórí ìjọsìn Báálì. Wọ́n sì ti pa ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ bíi ti Èlíjà, àmọ́ nísinsìnyí, ó jọ pé Èlíjà ló kàn. Bíbélì sọ pé: “Àyà sì bẹ̀rẹ̀ sí fò ó.” Ṣé Èlíjà fojú inú rí ikú gbígbóná tí Jésíbẹ́lì pète láti fi pa á? Tó bá gbé irú èrò yìí sọ́kàn, kò sí iyèméjì pé ẹ̀rù á máa bà á. Ohun yòówù kó jẹ́, Èlíjà “bẹ̀rẹ̀ sí lọ nítorí ọkàn rẹ̀,” ìyẹn ni pé ó sá lọ kó má bàa kú.—1 Àwọn Ọba 18:4; 19:3.
Èlíjà nìkan kọ́ ni olóòótọ́ èèyàn tí ìbẹ̀rù kó láyà jẹ. Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pétérù náà ní irú ìṣòro yìí. Bí àpẹẹrẹ, lákòókò kan tí Jésù ń rìn lórí omi, ó ní kí Pétérù náà wá rìn pẹ̀lú òun lórí omi, àmọ́ Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í wo “ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà.” Ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. (Mátíù 14:30) Àpẹẹrẹ Pétérù àti Èlíjà yìí kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Tá ò bá fẹ́ pàdánù ìgboyà tá a ní, a kò gbọ́dọ̀ máa fọkàn ro àwọn nǹkan tó lè dáyà fò wá. A ní láti máa fọkàn wa sọ́dọ̀ Ẹni tó ń fún wa ní ìrètí àti okun.
“Ó Tó Gẹ́ẹ́!”
Nítorí ẹ̀rù tó ń ba Èlíjà, ó sá gba gúúsù ìwọ̀ oòrùn lọ sí ìlú Bíá-ṣébà tó wà nítòsí gúúsù ibodè Júdà, ìrìn náà tó nǹkan bí àádọ́jọ [150] kìlómítà. Nígbà tó dé ibẹ̀, ó fi ẹmẹ̀wà rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọnú aginjù lọ ní òun nìkan. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé, ó rin “ìrìn àjò ọjọ́ kan,” ẹ fojú inú wò ó bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò náà láti òwúrọ̀, tí kò sì gbé ohun jíjẹ kankan dání. Ìdààmú ọkàn bá a, ẹ̀rù sì ń bà á, ìyẹn ló mú kó máa rìn lọ nínú oòrùn tó mú ganrín-ganrín lójú ọ̀nà tó rí gbágungbàgun náà. Bí oòrùn náà ti ń wọ̀ lọ, tí ilẹ̀ sì ń ṣú bọ̀, Èlíjà kò lókun mọ́. Bó ṣe rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu, ó jókòó sábẹ́ igi wíwẹ́ kan, ìyẹn ni igi téèyàn lè rí jókòó sábẹ́ rẹ̀ ní aginjù náà.—1 Àwọn Ọba 19:4.
Èlíjà gbàdúrà kíkankíkan. Ó bẹ̀bẹ̀ pé kí òun kú. Ó ní: “Èmi kò sàn ju àwọn baba ńlá mi.” Èlíjà mọ̀ pé ní báyìí, àwọn baba ńlá òun ti di erùpẹ̀, egungun wọn ló ṣẹ́ kù nínú ibojì, wọ́n kò sì lè ṣe nǹkan kan fún ẹnikẹ́ni. (Oníwàásù 9:10) Èlíjà sọ pé òun kò yàtọ̀ sí wọn. Abájọ tó fi ké jáde pé: “Ó tó gẹ́ẹ́!” Kí ni mo wà láàyè fún?
Ṣé ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ìdààmú ọkàn bá èèyàn Ọlọ́run? Kò yẹ. Àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin wà nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì tí wọ́n ní ìdààmú ọkàn tó pọ̀ débi pé wọ́n fẹ́ kí àwọn kú, lára wọn ni Rèbékà, Jákọ́bù, Mósè àti Jóòbù.—Jẹ́nẹ́sísì 25:22; 37:35; Númérì 11:13-15; Jóòbù 14:13.
Lóde òní, à ń gbé ní “àkókò tó le koko láti bá lò,” nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàápàá máa ń ní ìdààmú ọkàn nígbà míì. (2 Tímótì 3:1) Tí o bá bá ara rẹ ní irú ipò tó le yẹn, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíjà, sọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ fún Ọlọ́run. Ó ṣe tán, Jèhófà ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3) Ǹjẹ́ ó tu Èlíjà nínú?
Jèhófà Fún Wòlíì Rẹ̀ Lókun
Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà nígbà tí ó ń wo wòlíì rẹ̀ tó fẹ́ràn yìí láti ọ̀run tó jókòó sábẹ́ igi ní aginjù tó ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ikú pa òun? A kò lè sọ. Lẹ́yìn tí Èlíjà sùn lọ fọnfọn, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí i. Áńgẹ́lì náà rọra jí Èlíjà pẹ́pẹ́, ó ní: “Dìde jẹun.” Èlíjà dìde, nítorí pé áńgẹ́lì náà ti gbé oúnjẹ ráńpẹ́ kan wá fún un, ìyẹn búrẹ́dì tó gbóná fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ àti omi. Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ áńgẹ́lì náà? Ohun tí àkọ́sílẹ̀ náà kàn sọ ni pé wòlíì náà jẹ, ó mu, ó sì pa dà lọ sùn. Ṣé ìṣòro tó bá a ló pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi lè sọ̀rọ̀ ni? Èyí ó wù kó jẹ́, áńgẹ́lì náà jí Èlíjà lẹ́ẹ̀kejì, ìyẹn sì lè jẹ́ ní àfẹ̀mọ́jú. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó rọ Èlíjà pé, “Dìde, jẹun,” ó sì fi àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí kún un pé, “nítorí ìrìn àjò náà pọ̀ jù fún ọ.”—1 Àwọn Ọba 19:5-7.
Ọlọ́run fún áńgẹ́lì náà ní òye láti mọ ibi tí Èlíjà ń lọ. Ó tún mọ̀ pé okun Èlíjà kò ní lè gbé ìrìn-àjò náà. Ẹ ò rí i pé ìtùnú ló jẹ́ láti máa sin Ọlọ́run tó mọ ohun tí à ń fẹ́ àti ibi tí agbára wa mọ ju bí àwa fúnra wa ṣe mọ̀ ọ́n lọ! (Sáàmù 103:13, 14) Báwo ni oúnjẹ náà ṣe ṣe Èlíjà láǹfààní?
Bíbélì sọ pé: “Ó dìde, ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì ń lọ nípasẹ̀ agbára oúnjẹ yẹn fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, títí dé Hórébù, òkè ńlá Ọlọ́run tòótọ́.” (1 Àwọn Ọba19:8) Èlíjà gbààwẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru bíi ti Mósè tó gbé láyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ọdún ṣáájú rẹ̀ àti Jésù tó gbé láyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún [1000] ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Èlíjà. (Ẹ́kísódù 34:28; Lúùkù 4:1, 2) Oúnjẹ tó jẹ yẹn kò mú gbogbo ìṣòro rẹ̀ kúrò, àmọ́ oúnjẹ yẹn fún un lókun lọ́nà ìyanu. Wo bí àgbàlagbà yẹn ṣe ń fẹsẹ̀ rìn la aginjù lọ lójoojúmọ́ fún nǹkan bí oṣù kan ààbọ̀!
Bákan náà lónìí, Jèhófà ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun, kì í ṣe nípa fífún wọn lóúnjẹ ti ara lọ́nà ìyanu, bí kò ṣe oúnjẹ tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ. (Mátíù 4:4) Àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ ń dára sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n fara balẹ̀ gbé ka ẹ̀kọ́ inú Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé jíjẹ irú oúnjẹ tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ lè máà mú gbogbo ìṣòro wa kúrò, àmọ́ ó lè fún wa lókun láti fara da ohun tó jọ pé kò ṣeé fara dà. Ó tún ń ṣamọ̀nà ẹni lọ sí “ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 17:3.
Èlíjà rin nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ogún kìlómítà [320] lọ sí Òkè Hórébù, ibẹ̀ ni Jèhófà ti fara han Mósè nípasẹ̀ áńgẹ́lì kan ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nínú igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún tó ń jó, lẹ́yìn ìgbà yẹn, ibẹ̀ náà ló ti dá májẹ̀mú Òfin pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Inú ihò àpáta ni Èlíjà wọ̀ lọ.
Bí Jèhófà Ṣe Tu Wòlíì Rẹ̀ Nínú Tó sì Fún Un Lókun
Ní òkè Hórébù, Jèhófà fi “ọ̀rọ̀” rẹ̀ rán ẹ̀dá ẹ̀mí kan sí Èlíjà, ó sì bi Èlíjà ní ìbéèrè ṣókí kan pé: “Kí ni iṣẹ́ rẹ níhìn-ín, Èlíjà?” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ló fi béèrè ìbéèrè náà, nítorí Èlíjà ka ìbéèrè náà sí pé, ó ní kí òun sọ ohun tó wà lọ́kàn òun. Ó sì sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ lóòótọ́! Ó ní: “Mo ti ń jowú fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun; nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, àwọn pẹpẹ rẹ ni wọ́n ti ya lulẹ̀, àwọn wòlíì rẹ sì ni wọ́n ti fi idà pa, tí ó fi jẹ́ pé èmi nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ọkàn mi láti gbà á kúrò.” (1 Àwọn Ọba 19:9, 10) Ọ̀rọ̀ tí Èlíjà sọ jẹ́ ká mọ ohun mẹ́ta tó mú kó ní ìdààmú ọkàn.
Ohun àkọ́kọ́ ni pé, Èlíjà rò pé iṣẹ́ òun ti já sásán. Láìka ọ̀pọ̀ ọdún tí Èlíjà ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tó sì “ń jowú” fún un, tó ń gbé orúkọ mímọ́ Ọlọ́run àti ìjọsìn rẹ̀ lékè ohun gbogbo yòókù, síbẹ̀ nǹkan ń burú sí i ni. Ìdí ni pé, àwọn èèyàn náà ṣì jẹ́ aláìnígbàgbọ́ àti ọlọ̀tẹ̀, ìjọsìn èké sì ń tàn kálẹ̀. Èkejì ni pé, Èlíjà dá nìkan wà. Ó sọ pé, “èmi nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù,” bíi pé òun nìkan ṣoṣo ló kù ní orílẹ̀-èdè náà tó ń sin Jèhófà. Ẹ̀kẹta ni pé, ẹ̀rù ń ba Èlíjà. Ọ̀pọ̀ wòlíì bíi tiẹ̀ ni wọ́n ti pa, ó sì mọ̀ pé òun ló kàn báyìí tí wọ́n fẹ́ pa. Ó lè má rọrùn fún Èlíjà láti gbà pé àwọn nǹkan yìí ni ìṣòro òun, àmọ́ kò jẹ́ kí ìgbéraga dí òun lọ́wọ́, ó sì pa ìtìjú tì. Sísọ tó sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Ọlọ́run rẹ̀ nínu àdúrà, jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún gbogbo olóòótọ́.—Sáàmù 62:8.
Kí ni Jèhófà ṣe sí ìbẹ̀rù àti àníyàn tó bá Èlíjà? Áńgẹ́lì náà sọ fún Èlíjà pé kó dúró ní ẹnu ihò àpáta tó wà. Ó ṣègbọràn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀. Ẹ̀fúùfù tó lágbára gan-an bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́! Kò sí àní-àní pé ariwo ńlá tó lè dini létí ló jáde nínú ẹ̀fúùfù náà, nítorí ó lágbára débi pé ó fa àwọn òkè àtàwọn àpáta gàǹgà ya. Fojú inú wo Èlíjà bó ṣe ń fọwọ́ dí gàgà ojú tó ń gbìyànjú láti kó aṣọ onírun tó nípọn náà mọ́ra bí afẹ́fẹ́ náà ṣe ń fẹ́ ẹ mọ́ ọn lára. Nítorí náà, ó ní láti dúró dáadáa nítorí pé ilẹ̀ àgbègbè náà bẹ̀rẹ̀ sí í mì tìtì! Bí ìyẹn ṣe ń rọlẹ̀, ni iná tún ṣẹ́ yọ, èyí sì mú kó pa dà sínú ihò àpáta kí ooru iná má bàa kàn án.—1 Àwọn Ọba 19:11, 12.
Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ méjì yẹn, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kò sí nínú ẹ̀fúùfù àti iná náà, èyí sì jẹ́ ká rí báwọn nǹkan tí Jèhófà dá ṣe lágbára tó. Èlíjà mọ̀ pé Jèhófà kì í ṣe àwọn ọlọ́run èké bíi Báálì, tí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tó ń tan ara wọn jẹ máa ń yìn pé ó jẹ́ “Ẹni tó ń gun sánmà kiri bí ẹṣin” tàbí ẹni tó ń mú òjò wá. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo agbára tí a rí nínú àwọn ìṣẹ̀dá ti wá, àmọ́ Jèhófà fúnra rẹ̀ tóbi fíìfíì ju gbogbo ohun tó dá lọ. Àwọn ọ̀run pàápàá kò lè gba Jèhófà! (1 Àwọn Ọba 8:27) Báwo ni gbogbo nǹkan tí Èlíjà rí yìí ṣe ràn án lọ́wọ́? Ṣé ẹ rántí ohun tó ń ba Èlíjà lẹ́rù? Àmọ́ pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ alágbára gbogbo, kò sí ìdí kankan fún Èlíjà láti bẹ̀rù Áhábù àti Jésíbẹ́lì mọ́!—Sáàmù 118:6.
Lẹ́yìn tí iná náà ti lọ, gbogbo nǹkan pa rọ́rọ́, Èlíjà gbọ́ “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀.” Ó sọ fún Èlíjà pé kó tún sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó sọ gbogbo àníyàn ọkàn rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì.b Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn túbọ̀ mú kí ara tù ú. Àmọ́ kò sí àní-àní pé, Èlíjà túbọ̀ rí ìtùnú gbà nínú ohun tí “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” náà sọ fún un lẹ́yìn náà. Jèhófà fi dá Èlíjà lójú pé ẹni tó wúlò ni. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, Ọlọ́run sọ fún Èlíjà nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tí òun máa ṣe lọ́jọ́ iwájú láti fòpin sí ìjọsìn Báálì lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ó ṣe kedere pé iṣẹ́ àṣekára tí Èlíjà ṣe kò já sásán, nítorí kò sí ohun tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń ṣe. Síwájú sí i, Èlíjà ṣì kópa nínú ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe, nítorí Jèhófà rán an pa dà pé kó lọ ṣe àwọn iṣẹ́ kan.—1 Àwọn Ọba 19:12-17.
Àmọ́, báwo ni ìṣòro wíwà tí Èlíjà dá nìkan wà ṣe yanjú? Ohun méjì ni Jèhófà ṣe nípa ìyẹn. Ohun àkọ́kọ́ ni pé, ó sọ fún Èlíjà pé kó fòróró yan Èlíṣà láti jẹ́ wòlíì tí yóò gba ipò Èlíjà. Ọ̀dọ́kùnrin yìí máa di alábàákẹ́gbẹ́ Èlíjà, yóò sì máa ràn án lọ́wọ́ fún ọdún bíi mélòó kan. Ẹ wo bí ìyẹn ti tu Èlíjà nínú tó! Èkejì ni pé, Jèhófà sọ ìròyìn amóríyá fún un pé: “Mo sì ti jẹ́ kí ó ṣẹ́ ku ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ní Ísírẹ́lì, gbogbo eékún tí kò tẹ̀ ba fún Báálì, àti olúkúlùkù ẹnu tí kò fi ẹnu kò ó lẹ́nu.” (1 Àwọn Ọba 19:18) Èlíjà nìkan ṣoṣo kọ́ ló ṣẹ́ kù. Inú Èlíjà ti ní láti dùn nígbà tó gbọ́ nípa ẹgbẹ̀rún mélòó kan àwọn olóòótọ́ èèyàn tí kò sìn Báálì. Àwọn èèyàn yìí fẹ́ kí Èlíjà máa bá ìṣòtítọ́ rẹ̀ nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kó jẹ́ àpẹẹrẹ nínu jíjẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìyẹsẹ̀ ní àkókò yẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ya ọlọ̀tẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi rán ońṣẹ́ rẹ̀ láti sọ fún Èlíjà ní “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” yìí ti ní láti wọ Èlíjà lọ́kàn gan-an ni.
Ẹnu lè ya àwa náà bíi ti Èlíjà tí a bá rí agbára kíkàmàmà tó wà nínú àwọn ìṣẹ̀dá, bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn. Ìṣẹ̀dá máa ń fi agbára Ẹlẹ́dàá hàn kedere. (Róòmù 1:20) Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ láti máa lo agbára rẹ̀ tí kò láàlà láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. (2 Kíróníkà 16:9) Àmọ́, Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Ọlọ́run fi ń bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó pọ̀ jù lọ. (Aísáyà 30:21) Nítorí náà lónìí, Bíbélì dà bí “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” tí Jèhófà fi ń ṣamọ̀nà wa, tó fí ń tọ́ wa sọ́nà, tó fi ń fún wa níṣìírí, tó sì fi ń mú un dá wa lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wa.
Ǹjẹ́ Èlíjà gba ìtùnú tí Jèhófà fún un ní orí Òkè Hórébù? Láìsí àní-àní, ó gbà á! Kò pẹ́ tí wòlíì yìí tó jẹ́ olóòótọ́ tó nígboyà tí kò fàyè gba ìjọsìn èké fi pa dà sẹ́nu iṣẹ́. Bákan náà, tí a bá ń fi ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí Ọlọ́run, ìyẹn “ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́” sọ́kàn, a ó lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Èlíjà.—Róòmù 15:4.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àkòrí náà, “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn,” ó ní àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí: “Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́,” ó wà nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2008 àti “Ó Ń Ṣọ́nà, Ó sì Ní Sùúrù,” ó wà nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 2008.
b Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀dá ẹ̀mí tó sọ “ọ̀rọ̀ Jèhófà” tó wà ní 1 Àwọn Ọba 19:9 ló tún sọ̀rọ̀ ní “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” yìí. Ní ẹsẹ 15, Bíbélì pe ẹ̀mí náà ní “Jèhófà.” Èyí lè rán wa létí ẹ̀dá ẹ̀mí kan tí Jèhófà rán níṣẹ́ láti máa tọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́nà ní aginjù, tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ pé: “Orúkọ mi wà lára rẹ̀.” (Ẹ́kísódù 23:21) Òótọ́ ni pé, a kò lè sọ pàtó pé ẹni báyìí ni, àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, ṣáájú kí Jésù tó wá sí ayé, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “Ọ̀rọ̀ náà,” ìyẹn Agbọ̀rọ̀sọ pàtàkì fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà.—Jòhánù 1:1.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Jèhófà fún Èlíjà lágbára gan-an lákòókò tí nǹkan lọ dáadáa àti lákòókò ìṣòro
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Èlíjà sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Jèhófà nígbà tí ìdààmú ọkàn bá a
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Jèhófà lo agbára rẹ̀ ńlá láti fi tu Èlíjà nínú, ó sì fún un níṣìírí