ORÍ 4
‘Agbára Jèhófà Pọ̀’
1, 2. Àwọn nǹkan àgbàyanu wo ló ti ṣojú Èlíjà, àmọ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ wo ló rí nígbà tó wà lórí Òkè Hórébù?
Ọ̀PỌ̀ nǹkan àgbàyanu ló ti ṣojú Èlíjà. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí ẹyẹ ìwò ń gbé oúnjẹ lọ fún un lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́ níbi tó sá pa mọ́ sí. Ìgbà kan tún wà tó rí i tí ìyẹ̀fun ò tán nínú ìkòkò tí wọ́n ń kó oúnjẹ sí, tí òróró ò sì gbẹ nínú ìṣà kékeré kan ní gbogbo àkókò gígùn tí ìyàn fi mú. Kódà, Èlíjà ti rí i tí Jèhófà rán iná wá látọ̀run láti dáhùn àdúrà rẹ̀. (1 Àwọn Ọba, orí 17 àti 18) Síbẹ̀, ohun tí Èlíjà rí lọ́tẹ̀ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀.
2 Nígbà tó dúró sí ẹnu ihò kan lórí Òkè Hórébù, ó rí onírúurú ohun àrà tó ṣẹlẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ̀fúùfù ńlá kan fẹ́. Ẹ̀fúùfù náà le débi pé ariwo ẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ lè dini létí, ó sì lágbára débi tó fi ń ya àwọn òkè, tó sì ń fọ́ àwọn àpáta. Bákan náà, ilẹ̀ mì tìtì lọ́nà tó lágbára, èyí sì mú kí ooru gbígbóná tú jáde láti abẹ́ ilẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, iná sọ. Bí ooru iná yẹn ṣe ń sún mọ́ Èlíjà, ó ṣeé ṣe kó máa rà á lára.—1 Àwọn Ọba 19:8-12.
3. Kí làwọn nǹkan tí Èlíjà rí jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà, àwọn nǹkan wo làwa náà ń rí lónìí tó ń jẹ́rìí sí i pé alágbára ni Jèhófà?
3 Ohun kan tó jọra nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí Èlíjà rí yìí ni pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló fi hàn pé alágbára ńlá ni Jèhófà Ọlọ́run. Ká sòótọ́, kò dìgbà téèyàn bá rí iṣẹ́ ìyanu kéèyàn tó mọ̀ pé alágbára ni Ọlọ́run. Gbogbo ohun tó wà láyìíká wa ló ń jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run lágbára. Bíbélì sọ pé àwọn nǹkan tí Jèhófà dá jẹ́ ká mọ̀ nípa “agbára ayérayé tó ní àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run.” (Róòmù 1:20) Ronú nípa bí mànàmáná ṣe ń kọ yẹ̀rì, tí òjò ń kù rìrì, tí ààrá ń sán wàá, tó sì máa ń milẹ̀ tìtì! Tún wo ọ̀nà àrà tí omi gbà ń dà ṣọ̀ọ̀rọ̀ láti orí àpáta, àti bí ìràwọ̀ ṣe lọ salalu lójú ọ̀run! Ó dájú pé àwọn nǹkan yìí jẹ́ ká mọ bí agbára Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni ò kíyè sí àwọn nǹkan yìí kí wọ́n lè rí i pé Ọlọ́run lágbára. Nínú apá yìí, a máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa agbára tí kò lẹ́gbẹ́ tí Jèhófà ní, èyí sì máa mú kó wù wá gan-an láti sún mọ́ ọn.
“Sì wò ó! Jèhófà ń kọjá lọ”
Ọ̀kan Pàtàkì Lára Ìwà àti Ìṣe Jèhófà
4, 5. (a) Kí ni Bíbélì sọ nípa orúkọ Jèhófà? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu bí Jèhófà ṣe fi màlúù ṣàpẹẹrẹ agbára rẹ̀?
4 Agbára Jèhófà ò láfiwé. Jeremáyà 10:6 sọ pé: “Jèhófà, kò sí ẹni tó dà bí rẹ. O tóbi, orúkọ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà.” Kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé orúkọ Jèhófà tóbi, ó sì kàmàmà. Má gbàgbé pé ẹ̀rí fi hàn pé orúkọ yìí túmọ̀ sí “Alèwílèṣe” tàbí ẹni tó lè di ohunkóhun tó bá fẹ́. Kí ló jẹ́ kí Jèhófà lè ṣẹ̀dá ohunkóhun tó bá fẹ́, kó sì lè di ohunkóhun tó bá fẹ́? Ohun kan tó mú kó lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni o, agbára tí Jèhófà ní láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ kò lópin. Agbára yẹn jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀.
5 Àwa èèyàn ò lè lóye bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó, ìdí nìyẹn tó fi lo àwọn àpèjúwe tó lè ràn wá lọ́wọ́. A ti kẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ pé ó fi akọ màlúù ṣàpẹẹrẹ agbára rẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 1:4-10) Àpèjúwe yẹn sì bá a mu gan-an, nítorí pé akọ màlúù tí wọ́n ń sìn nílé lásán máa ń tóbi, ó sì lágbára. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bóyá ni àwọn ará Palẹ́sìnì tún mọ ẹranko míì tó lágbára ju akọ màlúù lọ. Wọ́n tiẹ̀ mọ àwọn akọ màlúù igbó kan tó bani lẹ́rù gan-an, àmọ́ àwọn màlúù náà ò sí mọ́ báyìí. (Jóòbù 39:9-12) Alákòóso ilẹ̀ Róòmù kan tó ń jẹ́ Julius Caesar sọ nígbà kan pé akọ màlúù yìí máa ń tóbi tó erin. Nínú ìwé kan tó kọ, ó ní: “Wọ́n lágbára gan-an, wọ́n sì máa ń sáré gan-an.” Téèyàn bá dúró ti ẹranko yìí, ó dájú pé ńṣe lèèyàn á kéré lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀, tí ẹ̀rù á sì máa ba èèyàn!
6. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan là ń pè ní “Olódùmarè”?
6 Bákan náà, agbára àwa èèyàn ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Jèhófà, alágbára gíga jù lọ. Kódà, bí eruku fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n làwọn orílẹ̀-èdè alágbára pàápàá ṣe rí lójú ẹ̀. (Àìsáyà 40:15) Agbára Jèhófà yàtọ̀ sí ti ẹ̀dá èyíkéyìí, nítorí agbára rẹ̀ kò lópin. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo là ń pè ní “Olódùmarè.”a (Ìfihàn 15:3) “Okun rẹ̀ tó fi ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yanturu, agbára rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù.” (Àìsáyà 40:26) Òun ni Orísun agbára ńlá tí kò sì lópin. Kò gbára lé ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun kó tó lè ní agbára, torí pé “agbára jẹ́ ti Ọlọ́run.” (Sáàmù 62:11) Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe ń lo agbára rẹ̀?
Bí Jèhófà Ṣe Ń Lo Agbára Rẹ̀
7. Kí ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, kí làwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti Gíríìkì jẹ́ ká mọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́?
7 Ẹ̀mí mímọ́ tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà ò lè tán láéláé. Ẹ̀mí mímọ́ yìí ni Ọlọ́run máa ń fi ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́. Kódà ní Jẹ́nẹ́sísì 1:2, Bíbélì pè é ní “ẹ̀mí Ọlọ́run.” Àwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti ti Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ẹ̀mí” lè túmọ̀ sí “ẹ̀fúùfù” tàbí “èémí,” láwọn ibòmíì. Àwọn onímọ̀ nípa èdè sọ pé ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ohun kan téèyàn ò lè rí àmọ́ téèyàn ń rí iṣẹ́ tó ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, a ò lè fojú rí afẹ́fẹ́, ṣùgbọ́n a máa ń mọ̀ ọ́n lára, a sì máa ń rí ohun tó ń ṣe. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ ẹ̀mí mímọ́ ṣe rí.
8. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Bíbélì fi ṣàpèjúwe ẹ̀mí Ọlọ́run, kí sì nìdí táwọn ọ̀rọ̀ yẹn fi bá a mu?
8 Jèhófà lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lónírúurú ọ̀nà láti ṣe ohunkóhun tó bá wù ú. Ìdí nìyẹn táwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe ẹ̀mí Ọlọ́run fi bá a mu. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì pè é ní “ìka Ọlọ́run,” “ọwọ́ agbára” rẹ̀, tàbí “apá rẹ̀ tó nà jáde.” (Lúùkù 11:20; Diutarónómì 5:15; Sáàmù 8:3) Bó ṣe jẹ́ pé èèyàn lè fi ọwọ́ ẹ̀ ṣe onírúurú iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run lè lo ẹ̀mí rẹ̀ láti fi ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dá àwọn nǹkan tín-tìn-tín, ó fi pín Òkun Pupa níyà, ó sì fi mú káwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sọ oríṣiríṣi èdè.
9. Kí lohun míì tó tún jẹ́ ká mọ bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó?
9 Ohun míì tó tún jẹ́ ká mọ bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó ni àṣẹ tó ní gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Rò ó wò ná: Jèhófà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tí wọ́n lágbára, tí wọ́n sì múra tán láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́! Jèhófà tún láwọn ìránṣẹ́ tó jẹ́ èèyàn, Ìwé Mímọ́ sì sábà máa ń fi wọ́n wé ọmọ ogun. (Sáàmù 68:11; 110:3) Àmọ́ agbára àwọn èèyàn ò tó nǹkan kan rárá tá a bá fi wé tàwọn áńgẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, lóru ọjọ́ kan péré, áńgẹ́lì kan ṣoṣo pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) lára àwọn ọmọ ogun Ásíríà nígbà tí wọ́n gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run! (2 Àwọn Ọba 19:35) Ká sòótọ́, “alágbára ńlá” làwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.—Sáàmù 103:19, 20.
10. (a) Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Olódùmarè ní Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun? (b) Ta ló lágbára jù lọ nínú gbogbo ohun tí Jèhófà dá?
10 Áńgẹ́lì mélòó ló wà? Nínú ìran kan tí wòlíì Dáníẹ́lì rí nípa ọ̀run, ó rí ohun tó ju ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù áńgẹ́lì níwájú ìtẹ́ Jèhófà, àmọ́ kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé gbogbo wọn pátá ló rí. (Dáníẹ́lì 7:10) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù àwọn áńgẹ́lì ló wà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ọlọ́run ní Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Orúkọ oyè yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àìmọye àwọn áńgẹ́lì alágbára tí wọ́n wà létòlétò ni Jèhófà ń darí. Ó wá fi áńgẹ́lì alágbára kan ṣe alábòójútó àwọn áńgẹ́lì náà, ìyẹn Jésù ààyò Ọmọ rẹ̀, tó jẹ́ “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Òun ló lágbára jù lọ nínú gbogbo ohun tí Jèhófà dá. Bíbélì pè é ní olú áńgẹ́lì torí pé ipò tó wà ga ju ti gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó kù, títí kan àwọn séráfù àtàwọn kérúbù.
11, 12. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà ń lo agbára? (b) Kí ni Jésù sọ nípa bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó?
11 Ọ̀nà míì tún wà tí Jèhófà gbà ń lo agbára. Hébérù 4:12 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára.” Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti kíyè sí agbára àrà ọ̀tọ̀ tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí àwọn ìsọfúnni onímìísí tó wà nínú Bíbélì ní. Ó lè fún wa lókun, ó lè gbé ìgbàgbọ́ wa ró, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yí ìwà wa pa dà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ń lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe àtàwọn ìwà ìbàjẹ́ míì. Lẹ́yìn náà, ó wá fi kún un pé: “Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn.” (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Bẹ́ẹ̀ ni o, agbára tí “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ní ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè yíwà pa dà.
12 Agbára Jèhófà pọ̀ gan-an, ọ̀nà tó sì ń gbà lò ó gbéṣẹ́ gan-an débi pé kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́. Jésù sọ pé: “Ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Mátíù 19:26) Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà máa ń fi agbára rẹ̀ ṣe?
Ọlọ́run Máa Ń Fi Agbára Ẹ̀ Ṣe Ohun Tó Bá Ìfẹ́ Rẹ̀ Mu
13, 14. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà kì í ṣe alágbára kan tó kàn máa ń lo agbára rẹ̀ bó ṣe wù ú? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń lo agbára ẹ̀?
13 Ẹ̀mí Jèhófà lágbára ju ohunkóhun tá a lè fojú rí lọ. Àmọ́, kì í ṣe pé Jèhófà kàn jẹ́ alágbára kan tó máa ń lo agbára náà bó ṣe wù ú, kàkà bẹ́ẹ̀ ó láwọn ìwà àti ìṣe tó dáa, ìyẹn sì máa ń mú kó lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Àmọ́, kí ló máa ń mú kó lo agbára ẹ̀?
14 Bá a ṣe máa rí i níwájú, Ọlọ́run máa ń lo agbára rẹ̀ láti fi dá nǹkan, láti fi pa àwọn nǹkan run, láti fi dáàbò boni àti láti fi mú nǹkan bọ̀ sípò. Ìyẹn ni pé ó máa ń fi agbára ẹ̀ ṣe ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Àìsáyà 46:10) Nígbà míì, Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ láti jẹ́ ká mọ irú ẹni tóun jẹ́, ká sì mọ ohun tó ń retí pé ká ṣe ká tó lè rí ojúure rẹ̀. Jèhófà máa lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó ga jù lọ nígbà tó bá mú gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà, tó sì mú ẹ̀gàn tí Sátánì mú bá orúkọ rẹ̀ kúrò, kó lè hàn kedere pè ọ̀nà tóun ń gbà ṣàkóso ló dáa jù lọ. Ó sì dájú pé kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.
15. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń lo agbára ẹ̀ nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà sì ṣe jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀?
15 Jèhófà tún máa ń lo agbára rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Kíyè sí ohun tí 2 Kíróníkà 16:9 sọ, ó ní: “Ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.” Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà, bá a ṣe rí i níbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kó rí agbára rẹ̀ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tóyẹn? Ìdí ni pé Jésíbẹ́lì Ayaba ti halẹ̀ mọ́ Èlíjà pé òun máa pa á. Ni Èlíjà bá fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ kí wọ́n má bàa rí i pa. Ó gbà pé òun nìkan ṣoṣo ló ń sin Jèhófà, ẹ̀rù bà á, ayé sì sú u. Ńṣe ló dà bíi pé gbogbo iṣẹ́ àṣekára tó ṣe ti já sí asán. Jèhófà ṣe àwọn nǹkan kan kó lè rán Èlíjà létí pé alágbára lòun, ìyẹn sì tu Èlíjà nínú gan-an. Nígbà tí Èlíjà rí ẹ̀fúùfù, ìmìtìtì ilẹ̀ àti iná tó ń jó, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ torí ó mọ̀ pé Olódùmarè tó lágbára jù lọ láyé àtọ̀run wà lẹ́yìn òun. Ó dájú pé kò sídìí kankan tó fi yẹ kí Èlíjà máa bẹ̀rù Jésíbẹ́lì, torí pé Ọlọ́run Olódùmarè wà lẹ́yìn rẹ̀.—1 Àwọn Ọba 19:1-12.b
16. Tá a bá ń ronú nípa bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó, báwo nìyẹn ṣe máa tù wá nínú?
16 Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í ṣe irú iṣẹ́ ìyanu tó ṣe nígbà ayé Èlíjà mọ́ lónìí, síbẹ̀ kò tíì yí pa dà. (1 Kọ́ríńtì 13:8) Bíi tìgbà ayé Èlíjà, ó ṣì ń wu Jèhófà láti lo agbára rẹ̀ nítorí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Agbára rẹ̀ kò lópin, kò sì síbi tí kò ti lè lo agbára náà. Òótọ́ ni pé òkè ọ̀run ló ń gbé, síbẹ̀ kò jìnnà sí wa. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé “Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é.” (Sáàmù 145:18) Ìgbà kan wà tí wòlíì Dáníẹ́lì bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, kò tíì parí àdúrà náà tí áńgẹ́lì kan ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀! (Dáníẹ́lì 9:20-23) Kò sóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lókun kó sì ràn wọ́n lọ́wọ́.—Sáàmù 118:6.
Ṣé Agbára Ọlọ́run Mú Kó Dẹni Tí Kò Ṣeé Sún Mọ́?
17. Tá a bá ronú nípa bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó, irú ìbẹ̀rù wo ló yẹ ká ní fún un, àmọ́ irú ìbẹ̀rù wo ni kò yẹ ká ní fún un?
17 Ṣó yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run torí pé ó jẹ́ alágbára? A lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, a sì tún lè sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́. Tá a bá sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, ìyẹn bá ohun tá a kọ́ ní orí tó ṣáájú èyí mu. Nínú orí náà, a kẹ́kọ̀ọ́ pé a gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù Jèhófà tàbí ká ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un torí pé Ọlọ́run alágbára ni. Irú ìbẹ̀rù yìí ni Bíbélì sọ pé ó jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.” (Sáàmù 111:10) Àmọ́ a tún lè sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́, torí pé kò yẹ ká jẹ́ kí agbára tí Ọlọ́run ní máa bà wá lẹ́rù débi tí àá fi máa gbọ̀n jìnnìjìnnì tá ò sì ní fẹ́ sún mọ́ ọn.
18. (a) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi í fọkàn tán àwọn alágbára? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ò lè ṣi agbára rẹ̀ lò láé?
18 Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Lord Acton sọ ọ̀rọ̀ kan lọ́dún 1887, ó ní: “Ńṣe ni agbára máa ń gun alágbára, tá a bá wá lọ gbé gbogbo agbára lé ẹnì kan lọ́wọ́, gàràgàrà ni yóò máa gun onítọ̀hún.” Léraléra làwọn èèyàn ti sọ ọ̀rọ̀ yìí torí wọ́n gbà pé òótọ́ ni. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn sì ti jẹ́ ká rí i pé àwa èèyàn sábà máa ń ṣi agbára lò. (Oníwàásù 4:1; 8:9) Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ò fọkàn tán àwọn alágbára, kódà wọn kì í fẹ́ sún mọ́ wọn. Ní ti Jèhófà, agbára rẹ̀ pọ̀ ju ti èèyàn èyíkéyìí lọ. Àmọ́, ṣé ó ti ṣi agbára yìí lò rí? Rárá o! Bá a ṣe rí i nínú orí tó ṣáájú èyí, ẹni mímọ́ ni Ọlọ́run, kò sì ní àbààwọ́n kankan. Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ alágbára nínú ayé burúkú yìí. Kò ṣi agbára rẹ̀ lò rí, kò sì ní ṣì í lò láéláé.
19, 20. (a) Àwọn ìwà àti ìṣe míì wo ni Jèhófà máa ń lo pọ̀ mọ́ agbára ẹ̀, kí sì nìdí tí ìyẹn fi fini lọ́kàn balẹ̀? (b) Ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe máa ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu, kí sì nìdí tíyẹn fi fà ọ́ mọ́ra?
19 Rántí pé Jèhófà tún láwọn ìwà àti ìṣe míì tó yàtọ̀ sí agbára. A ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdájọ́ òdodo rẹ̀, ọgbọ́n rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀. Àmọ́ o, kì í ṣe pé Jèhófà máa ń lo àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń lò wọ́n pa pọ̀. Bá a ṣe máa rí i nínú àwọn orí tó wà níwájú, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo rẹ̀, ọgbọ́n rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀. Bákan náà, Ọlọ́run máa ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu tó bá ń lo agbára rẹ̀, ìyẹn sì mú kó yàtọ̀ pátápátá sáwọn alákòóso ayé.
20 Ká sọ pé o pàdé ọkùnrin kan tó ga gan-an tó sì lágbára, ẹ̀rù wá ń bà ẹ́ nígbà tó o kọ́kọ́ rí i. Àmọ́, kò pẹ́ lo wá rí i pé èèyàn jẹ́jẹ́ ni. Ó máa ń fi agbára rẹ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó sì máa ń fi dáàbò bò wọ́n, ní pàtàkì àwọn tí kò lágbára láti dáàbò bo ara wọn. Agbára kì í gùn ún gàràgàrà. O rí i táwọn kan ń parọ́ mọ́ ọkùnrin náà láti bà á lórúkọ jẹ́, síbẹ̀ kò ṣìwà hù, kódà ṣe ló túbọ̀ ń ṣoore fáwọn èèyàn. O wá ń ronú pé bóyá ni wàá lè ní sùúrù tó ọkùnrin náà ká sọ pé o lágbára bíi tiẹ̀. Bó o ṣe túbọ̀ ń mọ irú ẹni tí ọkùnrin náà jẹ́, ó dájú pé ó máa wù ẹ́ kó o sún mọ́ ọn. Bí ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe rí náà nìyẹn, bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọ irú ẹni tó jẹ́, bẹ́ẹ̀ láá máa wù ẹ́ pé kó o sún mọ́ ọn, kódà ju bó ṣe máa wù ẹ́ pé kó o sún mọ́ ọkùnrin yẹn. Ronú nípa ẹsẹ Bíbélì tá a ti mú ẹṣin ọ̀rọ̀ orí yìí. Ó sọ pé: “Jèhófà kì í tètè bínú, agbára rẹ̀ sì pọ̀.” (Náhúmù 1:3) Jèhófà kì í tètè fi agbára ẹ̀ jẹ àwọn èèyàn níyà, tó fi mọ́ àwọn ẹni burúkú pàápàá. Ó jẹ́ onínú tútù àti onínúure. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ti ṣe oríṣiríṣi nǹkan tó yẹ kó bí i nínú, ó ti fi hàn pé òun “kì í tètè bínú.”—Sáàmù 78:37-41.
21. Kí nìdí tí Jèhófà kì í fi í fipá mú wa láti jọ́sìn òun, kí lèyí sì kọ́ wa nípa irú ẹni tó jẹ́?
21 Jẹ́ ká ronú nípa ọ̀nà míì tí Jèhófà gbà ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Ká sọ pé o lágbára tó Jèhófà, ṣé kò ní máa wù ẹ́ nígbà míì pé kó o fipá mú àwọn èèyàn ṣe ohun tó o bá fẹ́? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lágbára gan-an, kì í fipá mú àwọn èèyàn láti sin òun. Òótọ́ ni pé kò sí ọ̀nà mìíràn téèyàn lè gbà rí ìyè àìnípẹ̀kun àyàfi tó bá ń sin Ọlọ́run, síbẹ̀ Jèhófà kì í fipá mú wa láti sin òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lómìnira láti yan ohun tó bá wù wá. Ó jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá pinnu láti ṣe ohun tí kò dáa, ó sì jẹ́ ká mọ àǹfààní tá a máa rí tá a bá ṣe ohun tó tọ́. Àmọ́ àwa fúnra wa la máa pinnu ohun tá a máa ṣe. (Diutarónómì 30:19, 20) Jèhófà ò fẹ́ ká máa sin òun torí pé ẹnì kan fipá mú wa pé ká ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí torí pé à ń bẹ̀rù rẹ̀ pé ó jẹ́ alágbára. Dípò ìyẹn, ṣe ló fẹ́ ká máa sin òun torí pé a nífẹ̀ẹ́ òun látọkàn wá.—2 Kọ́ríńtì 9:7.
22, 23. (a) Kí ló fi hàn pé inú Jèhófà máa ń dùn láti fún àwọn míì lágbára? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí tó kàn?
22 Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìdí míì tí kò fi yẹ kí jìnnìjìnnì máa bò wá nítorí Ọlọ́run Olódùmarè. Àwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ sábà máa ń bẹ̀rù láti fún àwọn míì lágbára. Àmọ́, inú Jèhófà máa ń dùn láti fún àwọn adúróṣinṣin tó ń jọ́sìn rẹ̀ lágbára. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fún Jésù Ọmọ ẹ̀ lágbára láti pàṣẹ, ó sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn míì. (Mátíù 28:18) Jèhófà tún máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára lọ́nà míì. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà, tìrẹ ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ògo àti ọlá ńlá, nítorí gbogbo ohun tó wà ní ọ̀run àti ní ayé jẹ́ tìrẹ. . . . Ọwọ́ rẹ ni agbára àti títóbi wà, ọwọ́ rẹ ló lè sọni di ńlá, òun ló sì lè fúnni lágbára.”—1 Kíróníkà 29:11, 12.
23 Bẹ́ẹ̀ ni o, inú Jèhófà máa dùn láti fún ọ lágbára. Kódà, ó máa ń fún àwọn tó bá fẹ́ sìn ín ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ó dájú pé ó máa wù ọ́ pé kó o sún mọ́ Ọlọ́run wa tó lágbára, tó sì máa ń lo agbára ẹ̀ lọ́nà tó tọ́ àti lọ́nà tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa? Nínú orí tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe fi agbára ẹ̀ dá àwọn nǹkan.
a Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “Olódùmarè” nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí “Alákòóso Gbogbo Ẹ̀dá Ayé Àtọ̀run tàbí Alágbára Gíga Jù Lọ.”
b Bíbélì sọ pé: “Jèhófà kò sí nínú ẹ̀fúùfù náà . . . , ìmìtìtì ilẹ̀ náà . . . , [àti] iná náà.” Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yàtọ̀ sáwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n máa ń jọ́sìn afẹ́fẹ́, iná tàbí òjò. Jèhófà lágbára gan-an, torí náà kò lè wà nínú àwọn nǹkan tóun fúnra ẹ̀ dá.—1 Àwọn Ọba 8:27.