Nígbà Tí Jésù Bá Wá Nínú Ògo Ìjọba
“Àwọn kan . . . lára àwọn wọnnì tí wọ́n dúró níhìn-ín . . . kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.”—MÁTÍÙ 16:28.
1, 2. Kí ní ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 32 Sànmánì Tiwa, kí sì ni ète ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
KÉTÉ lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 32 Sànmánì Tiwa, mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi rí ìran mánigbàgbé kan. Bí àkọsílẹ̀ tí a mí sí ti sọ ọ́, “Jésù mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́ ó sì mú wọn wá sí orí òkè ńlá gíga fíofío kan ní àwọn nìkan. A sì yí i pa dà di ológo níwájú wọn.”—Mátíù 17:1, 2.
2 Ìran ìyípadà ológo náà ṣẹlẹ̀ ní àkókò kan tí ó le koko. Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun yóò jìyà, òun yóò sì kú ní Jerúsálẹ́mù, ṣùgbọ́n, ó ṣòro fún wọn láti lóye ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Mátíù 16:21-23) Ìran náà fún ìgbàgbọ́ àwọn àpọ́sítélì Jésù mẹ́ta náà lókun, ní mímúra wọn sílẹ̀ fún ikú rẹ̀ tí ń bọ̀, àti fún ọ̀pọ̀ ọdún iṣẹ́ àṣekára àti àdánwò tí yóò tẹ̀ lé e fún ìjọ Kristẹni. Àwa lónìí ha lè rí ohun kọ́ láti inú ìran náà bí? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé, ohun tí ó ń ṣàpẹẹrẹ ṣẹlẹ̀ ní àkókò wa.
3, 4. (a) Kí ni Jésù sọ ní ọjọ́ mẹ́fà ṣáájú ìyípadà ológo náà? (b) Ṣàpèjúwe ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìyípadà ológo náà.
3 Ọjọ́ mẹ́fà ṣáájú ìyípadà ológo náà, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “A ti yan Ọmọkùnrin ènìyàn tẹ́lẹ̀ láti wá nínú ògo Bàbá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, nígbà náà ni òun yóò sì san èrè iṣẹ́ fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ìhùwàsí rẹ̀.” A óò mú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣẹ ní “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.” Jésù sọ síwájú sí i pé: “Ní òótọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn wọnnì tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.” (Mátíù 16:27, 28; 24:3; 25:31-34, 41; Dáníẹ́lì 12:4) Ìyípadà ológo náà wáyé láti mú àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ gbẹ̀yìn wọ̀nyí ṣẹ.
4 Kí ni àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta náà rí gan-an? Bí Lúùkù ṣe ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà nìyí: “Bí [Jésù] sì ti ń gbàdúrà ìrísí ojú rẹ̀ di èyí tí ó yàtọ̀ aṣọ ọ̀ṣọ́ rẹ̀ sì di funfun tí ń dán yinrin. Pẹ̀lúpẹ̀lù, wò ó! àwọn ọkùnrin méjì ń bá a sọ̀rọ̀, àwọn ẹni tí í ṣe Mósè àti Èlíjà. Àwọn wọ̀nyí fara hàn pẹ̀lú ògo wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa lílọ rẹ̀ tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ fún un láti mú ṣẹ ní Jerúsálẹ́mù.” Lẹ́yìn náà, “àwọ sánmà kan gbára jọ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣíji bo [àwọn àpọ́sítélì náà]. Bí wọ́n ti wọ inú àwọ sánmà náà, ẹ̀rù bà wọ́n. Ohùn kan sì wá láti inú àwọ sánmà náà, wí pé: ‘Èyí ni Ọmọkùnrin mi, ẹni náà tí a ti yàn. Ẹ fetí sílẹ̀ sí i.’”—Lúùkù 9:29-31, 34, 35.
A fún Ìgbàgbọ́ Lókun
5. Ipa wo ni ìyípadà ológo náà ní lórí àpọ́sítélì Pétérù?
5 Àpọ́sítélì Pétérù ti fi Jésù hàn ṣáájú gẹ́gẹ́ bíi “Kristi náà, Ọmọkùnrin Ọlọ́run alààyè.” (Mátíù 16:16) Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ látọ̀run fìdí ìfihàn náà múlẹ̀, ìran ìyípadà ológo Jésù sì jẹ́ ìfojúsọ́nà fún wíwáa Kristi nínú agbára àti ògo Ìjọba, láti ṣèdájọ́ aráyé nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ní èyí tí ó lé ní 30 ọdún lẹ́yìn ìyípadà ológo náà, Pétérù kọ̀wé pé: “Kì í ṣe nípa títẹ̀lé àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá ni àwa fi sọ yín di ojúlùmọ̀ agbára àti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nípa dídi ẹlẹ́rìí olùfojúrí ọlá ńlá rẹ̀. Nítorí òun gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Bàbá, nígbà tí ògo ọlọ́lá ńlá gbé àwọn ọ̀rọ̀ bí irú ìwọ̀nyí wá fún un pé: ‘Èyí ni ọmọkùnrin mi, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹni tí èmi tìkára mi ti fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà.’ Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni àwa gbọ́ tí a gbé wá láti ọ̀run nígbà tí a wà pẹ̀lú rẹ̀ ní òkè ńlá mímọ́ náà.”—Pétérù Kejì 1:16-18; Pétérù Kíní 4:17.
6. Báwo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyípadà ológo náà?
6 Lónìí, ohun tí àwọn àpọ́sítẹ́lì mẹ́ta náà rí ń fún ìgbàgbọ́ àwa pẹ̀lú lókun. Dájúdájú, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé láti ọdún 32 Sànmánì Tiwa. Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, Jésù kú, a sì jí i dìde, ó sì gòkè re ọwọ́ ọ̀tún Bàbá rẹ̀. (Ìṣe 2:29-36) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún yẹn, a bí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” a sì bẹ̀rẹ̀ ìgbétásì iṣẹ́ ìwàásù, bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù, tí ó sì tàn kálẹ̀ dé òpin ilẹ̀ ayé nígbà tí ó yá. (Gálátíà 6:16; Ìṣe 1:8) A dán ìgbàgbọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wò láìpẹ́ rárá lẹ́yìn náà. A fi àṣẹ ọba mú àwọn àpọ́sítélì, a sì lù wọ́n bí ẹní máa kú, nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣíwọ́ wíwàásù. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, a pa Sítéfánù. Lẹ́yìn náà, a pa Jákọ́bù, ọ̀kan lára àwọn tí ó fojú rí ìyípadà ológo náà. (Ìṣe 5:17-40; 6:8–7:60; 12:1, 2) Ṣùgbọ́n, Pétérù àti Jòhánù là á já láti fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. Ní tòótọ́, bí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa ti ń kógbá wọlé, Jòhánù ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìran mìíràn nípa ìkófìrí Jésù nínú ògo ọ̀run.—Ìṣípayá 1:12-20; 14:14; 19:11-16.
7. (a) Nígbà wo ni ìran ìyípadà ológo náà bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ? (b) Nígbà wo ni Jésù san èrè iṣẹ́ fún àwọn kan ní ìbámu pẹ̀lú ìhùwàsí wọn?
7 Láti ìbẹ̀rẹ̀ “ọjọ́ Olúwa” ní 1914, a ti mú ọ̀pọ̀ lára ìran tí Jòhánù rí ṣẹ. (Ìṣípayá 1:10) ‘Wíwá nínú ògo Bàbá rẹ̀’ tí Jésù yóò wá ńkọ́, gẹ́gẹ́ bí ìyípadà ológo náà ti fi hàn ṣáájú? Ìran yìí bẹ̀rẹ̀ sí í nímùúṣẹ nígbà ìbí Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run ní 1914. Nígbà tí Jésù yọ bí ọjọ́ nínú ìran àgbáyé gẹ́gẹ́ bí Ọba tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́, ìyẹn jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tuntun kan, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. (Pétérù Kejì 1:19; Ìṣípayá 11:15; 22:16) Ní àkókò yẹn, Jésù ha san èrè iṣẹ́ fún àwọn kan ní ìbámu pẹ̀lú ìhùwàsí wọn bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀rí lílágbára wà pé àjíǹde àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sí ọ̀run bẹ̀rẹ̀ kété lẹ́yìn ìgbà yẹn.—Tímótì Kejì 4:8; Ìṣípayá 14:13.
8. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ní yóò sàmì sí òtéńté ìmúṣẹ ìran ìyípadà ológo náà?
8 Ṣùgbọ́n, láìpẹ́, Jésù yóò dé “nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀,” kí ó baà lè ṣèdájọ́ aráyé lápapọ̀. (Mátíù 25:31) Ní àkókò yẹn, yóò fara rẹ̀ hàn nínú gbogbo ògo ọlọ́lá ńlá rẹ̀, yóò sì san èrè iṣẹ́ tí ó tọ́ fún “olúkúlùkù” ní ìbámu pẹ̀lú ìhùwàsí rẹ̀. Àwọn ẹni bí àgùntàn yóò jogún ìyè àìnípẹ̀kun nínú Ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún wọn, àwọn ẹni bí ewúrẹ́ yóò sì lọ sínú “ìkékúrò àìnípẹ̀kun.” Ẹ wo irú òpin kíkọyọyọ tí ìyẹn yóò jẹ́ sí ìmúṣẹ ìran ìyípadà ológo náà!—Mátíù 25:34, 41, 46; Máàkù 8:38; Tẹsalóníkà Kejì 1:6-10.
Àwọn Alábàákẹ́gbẹ́ Jésù Tí A Ṣe Lógo
9. Ó ha yẹ kí a retí pé kí Mósè àti Èlíjà wà pẹ̀lú Jésù nínú ìmúṣẹ ìran ìyípadà ológo náà bí? Ṣàlàyé.
9 Jésù nìkan kọ́ ni ó wà nínú ìran ìyípadà ológo náà. A rí Mósè àti Èlíjà pẹ̀lú rẹ̀. (Mátíù 17:2, 3) Wọ́n ha wà pẹ̀lú rẹ̀ ní ti gidi bí? Rárá o, nítorí àwọn ọkùnrin méjèèjì náà ti kú tipẹ́, wọ́n sì ń sùn nínú sàárè, wọ́n ń dúró de àjíǹde. (Oníwàásù 9:5, 10; Hébérù 11:35) Wọn yóò ha fara hàn pẹ̀lú Jésù nígbà tí ó bá wá nínú ògo ọ̀run bí? Rárá o, nítorí pé, Mósè àti Èlíjà gbé ayé ṣáájú kí ìrètí ọ̀run tó ṣí sílẹ̀ fún ẹ̀dá ènìyàn. Wọn yóò jẹ́ apá kan “àjíǹde àwọn olódodo,” tí yóò ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣe 24:15) Nítorí náà, ìfarahàn wọn nínú ìran ìyípadà ológo náà jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ. Ìṣàpẹẹrẹ kí ni?
10, 11. Àwọn wo ni Èlíjà àti Mósè dúró fún ní àyíká ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?
10 Nínú àwọn àyíká ọ̀rọ̀ míràn, Mósè àti Èlíjà jẹ́ ẹ̀dá inú àsọtẹ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí alárinà májẹ̀mú Òfin, Mósè dúró fún Jésù, Alárinà májẹ̀mú tuntun náà. (Diutarónómì 18:18; Gálátíà 3:19; Hébérù 8:6) Èlíjà dúró fún Jòhánù Oníbatisí, ẹni tí a rán ṣíwájú Mèsáyà náà. (Mátíù 17:11-13) Síwájú sí i, nínú àyíká ọ̀rọ̀ Ìṣípayá orí 11, Mósè àti Èlíjà dúró fún àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ní àkókò òpin. Báwo ni a ṣe mọ ìyẹn?
11 Toò, ṣí ìwé Ìṣípayá 11:1-6. A kà ní ẹsẹ 3 pé: “Dájúdájú èmi yóò sì mú kí àwọn ẹlẹ́rìí mi méjì sọ tẹ́lẹ̀ fún ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ ní wíwọ aṣọ ọ̀fọ̀.” Àsọtẹ́lẹ̀ yí ní ìmúṣẹ lórí àwọn Kristẹni àṣẹ́kù ẹni àmì òróró, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní.a Èé ṣe tí ó fi jẹ́ ẹlẹ́rìí méjì? Nítorí pé, àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ṣe irú iṣẹ́ tí ó jọ èyí tí Mósè àti Èlíjà ṣe, lọ́nà tẹ̀mí. Ẹsẹ 5 àti 6, ń báa lọ láti wí pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá . . . fẹ́ pa [àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà] lára, iná á jáde wá láti ẹnu wọn a sì jẹ àwọn ọ̀tá wọn run; bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọ́n lára pẹ́nrẹ́n, ní irú ọ̀nà yí ni a gbọ́dọ̀ pa á. Àwọn wọ̀nyí ní ọlá àṣẹ láti sé ọ̀run pa kí òjò kankan má baà rọ̀ ní àwọn ọjọ́ ìsọtẹ́lẹ̀ wọn, wọ́n sì ní ọlá àṣẹ lórí àwọn omi láti sọ wọ́n di ẹ̀jẹ̀ àti láti fi gbogbo onírúurú ìyọnu àjàkálẹ̀ kọlu ilẹ̀ ayé nígbàkúùgbà tí wọ́n bá fẹ́.” Nípa báyìí, a mú wa rántí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Èlíjà àti Mósè ṣe.—Númérì 16:31-34; Àwọn Ọba Kìíní 17:1; Àwọn Ọba Kejì 1:9-12.
12. Nínú àyíká ọ̀rọ̀ ìyípadà ológo náà, àwọn wo ni Mósè àti Èlíjà dúró fún?
12 Nígbà náà, àwọn wo ni Mósè àti Èlíjà dúró fún nínú àyíká ọ̀rọ̀ inú ìran ìyípadà ológo náà? Lúùkù sọ pé, wọ́n fara hàn pẹ̀lú Jésù “pẹ̀lú ògo.” (Lúùkù 9:31) Ní kedere, wọ́n dúró fún àwọn Kristẹni tí a ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn, gẹ́gẹ́ bí “ajùmọ̀jogún” pẹ̀lú Jésù, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gba ìrètí àgbàyanu ti ṣíṣe wọ́n “lógo pa pọ̀” pẹ̀lú rẹ̀. (Róòmù 8:17) Àwọn ẹni àmì òróró tí a jí dìde yóò wà pẹ̀lú Jésù nígbà tí ó bá wá nínú ògo Bàbá rẹ̀ láti “san èrè iṣẹ́ fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ìhùwàsí rẹ̀.”—Mátíù 16:27.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Bíi Mósè àti Èlíjà
13. Àwọn ohun wo ni ó fi Mósè àti Èlíjà hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó dúró fún ẹni àmì òróró ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù, tí a ṣe lógo pẹ̀lú rẹ̀?
13 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ agbàfiyèsí kan ṣẹlẹ̀ tí ó mú kí Mósè àti Èlíjà bá àpẹẹrẹ alásọtẹ́lẹ̀ ti àwọn ẹni àmì òróró ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù mu rẹ́gí. Mósè àti Èlíjà ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn méjèèjì dojú kọ ìbínú alákòóso kan. Ní àkókò àìní, ìdílé àjèjì ṣètìlẹ́yìn fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn méjèèjì fi ìgboyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ọba, wọ́n sì dúró ṣánṣán lòdì sí àwọn wòlíì èké. Mósè àti Èlíjà rí ìfihàn agbára Jèhófà lórí Òkè Sínáì (ti a tún ń pè ní Hórébù). Àwọn méjèèjì yan arọ́pò wọn ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì. Àwọn ọjọ́ Mósè (pẹ̀lú Jósúà) àti Èlíjà (pẹ̀lú Èlíṣà) ni a tí ì ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ó pọ̀ jù lọ, yàtọ̀ sí àwọn tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Jésù.b
14. Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró ṣe ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ fún Jèhófà, bí Mósè àti Èlíjà ti ṣe?
14 Gbogbo ìwọ̀nyí kò ha mú wa rántí Ísírẹ́lì Ọlọ́run bí? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olùṣòtítọ́ pé: “Nítorí náà ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Bàbá àti ti Ọmọkùnrin àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:19, 20) Ní ṣíṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ fún Jèhófà láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa títí di ìsinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bíi Mósè àti Èlíjà, wọ́n ti dojú kọ ìbínú àwọn alákòóso, wọ́n sì ti jẹ́rìí fún wọn. Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ 12 pé: “Wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 10:18) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ nínú ìtàn ìjọ Kristẹni.—Ìṣe 25:6, 11, 12, 24-27; 26:3.
15, 16. Ìjọra wo ni ó wà láàárín àwọn ẹni àmì òróró ní ọwọ́ kan àti Mósè pẹ̀lú Èlíjà ní ọwọ́ kejì nínú ọ̀ràn (a) fífi ìgboyà dúró ti òtítọ́? (b) gbígba ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì?
15 Síwájú sí i, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti jẹ́ onígboyà gẹ́gẹ́ bíi Mósè àti Èlíjà ní ti dídúró fún òtítọ́ lòdì sí èké inú ìsìn. Rántí bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi wòlíì èké tí í ṣe Júù náà, Baa-Jésù, bú àti bí ó ṣe fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tú jíjẹ́ èké àwọn ọlọ́run àwọn ará Áténì fó, ṣùgbọ́n tí kò gba gbẹ̀rẹ́. (Ìṣe 13:6-12; 17:16, 22-31) Rántí pẹ̀lú pé, ní òdé òní, àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ti fi ìgboyà tú Kirisẹ́ńdọ̀mù fó, irú ìjẹ́rìí bẹ́ẹ̀ sì ti mú ìyọnu bá a.—Ìṣípayá 8:7-12.c
16 Nígbà tí Mósè sá lọ nítorí ìrunú Fáráò, ó rí ìsádi nínú ilé Réúẹ́lì, tí a tún ń pè ní Jẹ́tírò, tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Ní àkókò míràn, Mósè gba ìmọ̀ràn oníyebíye lórí ìṣètò lọ́wọ́ Réúẹ́lì, tí ọmọkùnrin rẹ̀, Hóbábù, ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la aginjù já.d (Ẹ́kísódù 2:15-22; 18:5-27; Númérì 10:29) Lọ́nà kan náà, àwọn mẹ́ńbà Ísírẹ́lì Ọlọ́run ha ti rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ẹni àmì òróró Ísírẹ́lì Ọlọ́run bí? Bẹ́ẹ̀ ni, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn míràn,” tí wọ́n ti fara hàn sójú táyé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, ti tì wọ́n lẹ́yìn. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16; Aísáyà 61:5) Ní sísọtẹ́lẹ̀ nípa ìtìlẹ́yìn ọlọ́yàyà, onífẹ̀ẹ́, tí àwọn “àgùntàn” wọ̀nyí yóò ṣe fún àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin rẹ̀, Jésù sọ fún wọn lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ebi pa mí ẹ sì fún mi ní nǹkan láti jẹ; òùngbẹ gbẹ mí ẹ sì fún mi ní nǹkan láti mu. Mo jẹ́ àjèjì ẹ sì gbà mí pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò; mo wà ní ìhòòhò, ẹ sì fi aṣọ wọ̀ mí. Mo dùbúlẹ̀ àìsàn ẹ sì bójú tó mi. Mo wà nínú ẹ̀wọ̀n ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi. . . . Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn kíkéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, ẹ̀yin ti ṣe é fún mi.”—Mátíù 25:35-40.
17. Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró ṣe ní ìrírí tí ó jọ irú èyí tí Èlíjà ní ní Òkè Hórébù?
17 Síwájú sí i, Ísírẹ́lì Ọlọ́run ní ìrírí tí ó jọ èyí tí Èlíjà ní ní Òkè Hórébù.e Bí Èlíjà, nígbà tí ó ń sá fún Ayaba Jésíbẹ́lì, àṣẹ́kù ẹni àmì òróró, tí ìbẹ̀rùbojo ti bá, rónu pé iṣẹ́ wọn ti parí ní òpin Ogun Àgbáyé Kìíní. Lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bíi ti Èlíjà, wọ́n ṣalábàápàdé Jèhófà, tí ó wá láti ṣèdájọ́ àwọn ètò àjọ tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ “ilé Ọlọ́run.” (Pétérù Kíní 4:17; Málákì 3:1-3) Bí Kirisẹ́ńdọ̀mù kò tilẹ̀ kún ojú ìwọ̀n, a mọ àṣẹ́kù ẹni àmì òróró sí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” náà, a sì yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní Jésù. (Mátíù 24:45-47) Ní Hórébù, Èlíjà gbọ́ “ohùn kẹ́lẹ́ kékeré” tí ó jẹ́ ti Jèhófà, tí ń fún un ní iṣẹ́ púpọ̀ sí i láti ṣe. Ní àkókò ẹ̀yìn ogun tí kò sí wàhálà, àwọn ìránṣẹ́ ẹni àmì òróró àdúróṣinṣin ti Jèhófà gbọ́ ohùn rẹ̀ láti inú àwọn ojú ìwé Bíbélì. Àwọn pẹ̀lú fòye mọ̀ pé àwọn ní ẹrù iṣẹ́ kan láti mú ṣẹ.—Àwọn Ọba Kìíní 19:4, 9-18; Ìṣípayá 11:7-13.
18. Báwo ni a ṣe fi agbára títayọ lọ́lá ti Jèhófà hàn nípasẹ̀ Ísírẹ́lì Ọlọ́run?
18 Lákòótán, a ha ti fi agbára títayọ lọ́lá ti Jèhófà hàn nípasẹ̀ Ísírẹ́lì Ọlọ́run bí? Lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn àpọ́sítélì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí dópin ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. (Kọ́ríńtì Kíní 13:8-13) Lóde òní, a kì í rí iṣẹ́ ìyanu lọ́na ti ara. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ní òótọ́ dájúdájú ni mo wí fún yín, Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, ẹni yẹn pẹ̀lú yóò ṣe àwọn iṣẹ́ tí èmi ń ṣe; òun yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí.” (Jòhánù 14:12) Èyí ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́ nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wàásù ìhìn rere jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ní ọ̀rúndún kìíní. (Róòmù 10:18) A tilẹ̀ ti ṣe iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ lónìí, bí àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ti múwájú nínú wíwàásù ìhìn rere “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Kí ni àbájáde èyí? Ọ̀rúndún ogún yìí ti rí ìkójọ iye àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, tí ó ti pọ̀ jù lọ nínú ìtàn. (Ìṣípayá 5:9, 10; 7:9, 10) Ẹ wo irú ẹ̀rí kíkọyọyọ tí èyí jẹ́ nípa agbára Jèhófà!—Aísáyà 60:22.
Àwọn Arákùnrin Jésù Wá Nínú Ògo
19. Nígbà wo ni a rí àwọn arákùnrin ẹni àmì òróró Jésù pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo?
19 Bí àṣẹ́kù àwọn arákùnrin ẹni àmì òróró Jésù ti ń parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé, a ń ṣe wọ́n lógo pẹ̀lú rẹ̀. (Róòmù 2:6, 7; Kọ́ríńtì Kíní 15:53; Tẹsalóníkà Kíní 4:14, 17) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n di ọba àti àlùfáà aláìleèkú ní Ìjọba ọ̀run. Pẹ̀lú Jésù, wọn yóò wá “fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ tí a óò fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí àwọn ohun ìlò amọ̀.” (Ìṣípayá 2:27; 20:4-6; Orin Dáfídì 110:2, 5, 6) Pẹ̀lú Jésù, wọn yóò jókòó sórí ìtẹ́, wọ́n yóò máa ṣèdájọ́ “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” (Mátíù 19:28) Ìṣẹ̀dá tí ń kérora ti ń fi ìháragàgà dúró de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, tí wọ́n jẹ́ apá kan “ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:19-21; Tẹsalóníkà Kejì 1:6-8.
20. (a) Nínú ìfojúsọ́nà wo ni ìyípadà ológo náà ti mú ìgbàgbọ́ Pétérù lókun? (b) Báwo ni ìyípadà ológo náà ṣe fún àwọn Kristẹni lókun lónìí?
20 Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìṣípayá Jésù nígbà “ìpọ́njú ńlá,” nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Òun . . dé láti di àyìnlógo ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ tí a óò sì bojú wò ó ní ọjọ́ yẹn pẹ̀lú kàyéfì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n lo ìgbàgbọ́.” (Mátíù 24:21; Tẹsalóníkà Kejì 1:10) Ẹ wo irú ìfojúsọ́nà kíkọyọyọ tí ìyẹn jẹ́ fún Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù, àti gbogbo àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí yàn! Ìyípadà ológo náà fún ìgbàgbọ́ Pétérù lókun. Dájúdájú, kíkà nípa rẹ̀ fún ìgbàgbọ́ àwa pẹ̀lú lókun, ó sì gbé ìgbọ́kànlé wa ró pé Jésù yóò “san èrè iṣẹ́ fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ìhùwàsí rẹ̀” láìpẹ́. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́, tí wọ́n ṣì wà láàyè títí di ìsinsìnyí, ti rí ìgbọ́kànlé wọn tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé a óò ṣe wọ́n lógo pẹ̀lú Jésù. A fún ìgbàgbọ́ àwọn àgùntàn míràn lókun ní mímọ̀ pé òun yóò gbà wọ́n là la òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí já sínú ayé tuntun ológo. (Ìṣípayá 7:14) Ẹ wo irú ìṣírí ti èyí jẹ́ fún wa láti dúró gbọn-in títí dé òpin! A sì lè rí ohun púpọ̀ sí i kọ́ nínú ìran yìí, bí a óò ti rí i nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé náà, “Let Your Name Be Sanctified,” ojú ìwé 313 àti 314, àti Revelation—Its Grand Climax At Hand!, ojú ìwé 164 àti 165, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
b Ẹ́kísódù 2:15-22; 3:1-6; 5:2; 7:8-13; 8:18; 19:16-19; Diutarónómì 31:23; Àwọn Ọba Kìíní 17:8-16; 18:21-40; 19:1, 2, 8-18; Àwọn Ọba Kejì 2:1-14.
c Wo ojú ìwé 133 sí 141 ìwé Revelation—Its Grand Climax At Hand!
d Wo ìwé náà, You May Survive Armageddon Into God’s New World, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, ojú ìwé 281 sí 283.
e Wo “Let Your Name Be Sanctified,” ojú ìwé 317 sí 320.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Àwọn wo ni ó fara hàn pẹ̀lú Jésù nínú ìyípadà ológo náà?
◻ Báwo ni ìyípadà ológo náà ṣe fún ìgbàgbọ́ àwọn àpọ́sítélì lókun?
◻ Nígbà tí Mósè àti Èlíjà fara hàn “pẹ̀lú ògo” pẹ̀lú Jésù nínú ìyípadà ológo náà, ta ni wọ́n dúró fún?
◻ Ìjọra wo ni ó wà láàárín Mósè àti Èlíjà ní ọwọ́ kan, àti Ísírẹ́lì Ọlọ́run ní ọwọ́ kejì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìyípadà ológo náà ti fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni àtijọ́ àti tòde òní lókun