Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
SEPTEMBER 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 23-24
“Má Ṣe Tẹ̀ Lé Ọ̀pọ̀ Èèyàn”
Máa Rí Àrídájú Ọ̀rọ̀
Ǹjẹ́ o máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o fi gbogbo ìsọfúnni tó o bá ti rí ránṣẹ́ sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ rẹ dà bíi ti oníròyìn kan tó máa ń fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó máa gbé ìròyìn tuntun kan sáfẹ́fẹ́. Àmọ́, kó o tó fi ìsọfúnni kan ránṣẹ́ lórí fóònù, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ó dá mi lójú pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ìsọfúnni tí mo fẹ́ fi ránṣẹ́ yìí? Ṣé mo tiẹ̀ ti rí àrídájú ẹ̀?’ Tí kò bá dá ẹ lójú àmọ́ tó o fi ránṣẹ́ sáwọn ará, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìròyìn èké lò ń tàn kálẹ̀ láìmọ̀. Torí náà, tí ìsọfúnni kan kò bá dá ẹ lójú, á dáa kó o pa á rẹ́ kúrò lórí fóònù rẹ dípò kó o fi ránṣẹ́ sáwọn míì.
Ewu míì tún wà níbẹ̀ tá a bá ń tètè fi àwọn ìsọfúnni tí kò dá wa lójú ránṣẹ́ sáwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ilẹ̀ kan wà tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. Àwọn alátakò wa láwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè mọ̀ọ́mọ̀ gbé àwọn ìsọfúnni kan sáfẹ́fẹ́ kí wọ́n lè dẹ́rù bà wá, ká má sì fọkàn tán àwọn ará wa mọ́. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa nígbà ìjọba Soviet Union. Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB bẹ̀rẹ̀ sí í tan irọ́ kálẹ̀, wọ́n sọ pé àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, wọ́n sì ti dalẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló gba ìròyìn èké yìí gbọ́, èyí sì mú kí wọ́n fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ wọn pa dà sínú ètò Ọlọ́run nígbà tó yá, àmọ́ àwọn kan ò pa dà torí wọ́n ti jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn rì. (1 Tím. 1:19) Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa? Tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan tí kò dáa nípa àwọn ará wa tàbí ọ̀rọ̀ kan tí kò dá ẹ lójú, má ṣe tan irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kálẹ̀. Àwọn tí kò gbọ́n ló máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, torí náà, rí i dájú pé ó rí àrídájú ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tó o bá gbọ́.
it-1 11 ¶3
Áárónì
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Áárónì ò lè sọ pé òun ò mọ̀ nípa aṣemáṣe mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wáyé náà, ó hàn pé òun kọ́ ni òléwájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jọ pé ṣe ló gbà káwọn míì mú kóun lọ́wọ́ sóhun tí kò tọ́ tàbí kẹ̀, ṣe ló fi ìtìjú kárùn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní kó ṣe ọlọ́run kan fún àwọn, ó yẹ kó rántí kó sì ronú lórí òfin Ọlọ́run tó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ èèyàn láti hùwà ibi.” (Ẹk 23:2) Láìfi gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn pè, Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ Áárónì dáadáa, Jésù Ọmọ Ọlọ́run sì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nígbà tó wà láyé, kódà ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ara ìṣètò Ọlọ́run ni báwọn ọmọ Áárónì ṣe ń ṣiṣẹ́ àlùfáà.—Sm 115:10, 12; 118:3; 133:1, 2; 135:19; Mt 5:17-19; 8:4.
it-1 343 ¶5
Ìfọ́jú
Ọlọ́run ò fẹ́ kéèyàn máa fi igbá kan bọ̀kan nínú tó bá dọ̀rọ̀ ìgbẹ́jọ́ tàbí kéèyàn máa ṣègbè. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ẹni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ wé ẹni tó dijú sí òtítọ́ tàbí afọ́jú. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Òfin Mósè rọ àwọn aṣáájú tàbí àwọn adájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọn ò si gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn nǹkan yìí lè mú kí wọ́n gbé ẹ̀bi fún aláre kí wọ́n sì gbé àre fún ẹlẹ́bi. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí àwọn tó ríran kedere lójú.” (Ẹk 23:8) Níbòmíì, ó sọ pé: “Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí ọlọ́gbọ́n lójú.” (Di 16:19) Bí adájọ́ kan bá fẹ́ràn àtimáa ṣe ẹ̀tọ́, kódà kó jẹ́ni tó ní làákàyè, tó bá fi lè gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn tó ń bójú tó ẹjọ́ wọn, láìfura ó lè yí ìdájọ́ po, ó sì lè mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ẹ̀bùn tí wọ́n fún un. Abájọ tí Òfin Ọlọ́run fi kìlọ̀ fáwọn onídàájọ́ pé kí wọ́n kíyè sára, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ èrò wọn nípa ẹnì kan tàbí ẹ̀bùn táwọn èèyàn ń fún wọn lè mú kí wọ́n yí ìdájọ́ po. Òfin yẹn sọ pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ rẹ́ aláìní jẹ tàbí kí ẹ ṣe ojúsàájú sí ọlọ́rọ̀.” (Le 19:15) Torí náà, adájọ́ kan ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò tóun ní nípa ẹnì kan mú kóun gbé àre fún olówó torí pé ó lówó lọ́wọ́, kò sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ torí kó lè rí ojúure àwọn èèyàn.—Ẹk 23:2, 3.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Ẹ Má Gbàgbé Aájò Àlejò”
Jèhófà ò fi dandan lé e pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì, ṣe ló rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ro tàwọn èèyàn náà mọ́ tiwọn. (Ka Ẹ́kísódù 23:9.) Ó ṣe tán, àwọn náà mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn bá jẹ́ àjèjì nílẹ̀ ibòmíì. Ilẹ̀ Íjíbítì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé kó tó di pé àwọn èèyàn náà sọ wọ́n dẹrú. Kódà ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ará Íjíbítì ò ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì séèyàn, torí wọ́n gbà pé àwọn dáa jù wọ́n lọ àti pé ẹ̀sìn wọn ò nítumọ̀. (Jẹ́n. 43:32; 46:34; Ẹ́kís. 1:11-14) Ojú pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gan-an nígbà yẹn, àmọ́ ní báyìí tí wọ́n ti wà nílẹ̀ tiwọn, Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n fojú pọ́n àwọn àjèjì tó wà láàárín wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fẹ́ kí wọ́n kà wọ́n sí “ọmọ ìbílẹ̀” wọn.—Léf. 19:33, 34.
it-2 393
Máíkẹ́lì
Yàtọ̀ sí Gébúrẹ́lì, áńgẹ́lì Jèhófà míì tí Bíbélì dárúkọ ni Máíkẹ́lì, òun nìkan sì ni Bíbélì pè ní “olú áńgẹ́lì.” (Júùdù 9) Inú orí kẹwàá ìwé Dáníẹ́lì ni wọ́n ti kọ́kọ́ dárúkọ Máíkẹ́lì, wọ́n pè é ní “ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ipò wọn ga jù.” Nínú àkọsílẹ̀ yẹn, Máíkẹ́lì wá ṣèrànwọ́ fún áńgẹ́lì kan tí ipò ẹ̀ kò tó tiẹ̀ torí pé “olórí ilẹ̀ ọba Páṣíà” dí áńgẹ́lì náà lọ́nà. Bíbélì tún pe Máíkẹ́lì ní ‘olórí àwọn èèyàn Dáníẹ́lì,’ “ọmọ aládé ńlá tó dúró nítorí àwọn èèyàn [Dáníẹ́lì].” (Da 10:13, 20, 21; 12:1) Èyí mú ká rí i pé Máíkẹ́lì ni áńgẹ́lì tó ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la aginjù já. (Ẹk 23:20, 21, 23; 32:34; 33:2) Àkọsílẹ̀ míì tún fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ nìgbà tí Bíbélì sọ pé “Máíkẹ́lì olú áńgẹ́lì ń bá Èṣù fa ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń jiyàn nípa òkú Mósè.”—Júùdù 9.
Bíbélì Kíkà
SEPTEMBER 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 25-26
“Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Àgọ́ Ìjọsìn”
it-1 165
Àpótí Májẹ̀mú
Bí Àpótí Náà Ṣe Rí. Nígbà tí Jèhófà ń sọ fún Mósè pé ó máa kọ́ àgọ́ ìjọsìn, àpótí májẹ̀mú lohun àkọ́kọ́ tí Jèhófà dìídì ṣàlàyé fún Mósè nípa ẹ̀. Ó sọ bí àpótí náà ṣe máa rí àti bí wọ́n ṣe máa dárà sí i. Ìdí sì ni pé nínú gbogbo ohun tó máa wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà àti ní ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àpótí yẹn ló ṣe pàtàkì jù. Àpótí náà gùn tó ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀, á fẹ̀ tó ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀, á sì ga tó ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀. (c. 111 × 67 × 67 cm; 44 × 26 × 26 in.). Igi bọn-ọ̀n-ní ni wọ́n fi ṣe àpótí náà, wọ́n sì fi ògidì wúrà bò ó nínú àti níta. Wọ́n tún fi wúrà dárà sí eteetí àpótí náà yíká. Ní ti ìbòrí Àpótí Májẹ̀mú náà, ògidì wúrà ni wọ́n fi ṣe é, kì í ṣe igi tí wọ́n kàn fi wúrà bò, ògidì wúrà ni látòkèdélẹ̀. Wọ́n wá fi wúrà ṣe kérúbù méjì sórí ìbòrí náà. Òòlù ni wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ọnà àwọn kérúbù náà, ọ̀kan wà ní ìkángun kan, èkejì sì wà ní ìkángun kejì wọ́n dojú kọra. Àwọn kérúbù méjèèjì tẹrí ba mọ́lẹ̀, wọ́n ń wo ìbòrí náà bí ìyẹ́ wọn ṣe wà ní nínà sókè, tó sì bo ìbòrí Àpótí náà. (Ẹk 25:10, 11, 17-22; 37:6-9) Wọ́n tún ń pe ìbòrí náà ní “ìbòrí ìpẹ̀tù” tàbí “ibi ìpẹ̀tù.”—Ẹk 25:17; Heb 9:5, àlàyé ìsàlẹ̀; wo ÌBÒRÍ ÌPẸ̀TÙ.
it-1 166 ¶2
Àpótí Májẹ̀mú
Wọ́n tún máa ń tọ́jú àwọn nǹkan pa mọ́ sínú àpótí náà, ìyẹn àwọn ohun tí wọ́n kà sí mímọ́ tí wọ́n fẹ́ máa rántí. Èyí tó ṣe pàtàkì lára wọn ni wàláà ẹ̀rí méjì tàbí wàláà Òfin Mẹ́wàá. (Ẹk 25:16) Ìgbà kan wà tí wọ́n kó “ìṣà wúrà tí wọ́n kó mánà sí” àti “ọ̀pá Áárónì tó yọ òdòdó” sínú Àpótí Májẹ̀mú náà, àmọ́ wọ́n kó wọn kúrò nígbà tó kú díẹ̀ kí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì. (Heb 9:4; Ẹk 16:32-34; Nọ 17:10; 1Ọb 8:9; 2Kr 5:10) Ṣáájú kí Mósè tó kú, ó fún àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ àlùfáà ní ẹ̀dà “ìwé Òfin” ó sì fún wọn ní ìtọ́ni pé kí wọ́n tọ́jú ìwé náà sí “ẹ̀gbẹ́ àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín, kó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lòdì sí yín.”—Di 31:24-26.
it-1 166 ¶3
Àpótí Májẹ̀mú
Ó jẹ́ àmì pé Ọlọ́run wà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Ní gbogbo àsìkò tí Àpótí náà fi wà, ó máa ń jẹ́ àmì pé Ọlọ́run wà níbi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jọ́sìn. Jèhófà ṣèlérí pé: “Màá pàdé rẹ níbẹ̀, màá sì bá ọ sọ̀rọ̀ látorí ìbòrí náà, láti àárín àwọn kérúbù méjì tó wà lórí àpótí Ẹ̀rí náà.” Ó tún sọ pé: “Màá fara hàn nínú ìkùukùu lórí ìbòrí náà.” (Ẹk 25:22; Le 16:2) Sámúẹ́lì sọ pé Jèhófà “jókòó lórí àwọn kérúbù” (1Sa 4:4); torí náà, àwọn kérúbù yẹn ló ṣàpẹẹrẹ “kẹ̀kẹ́ ẹṣin” Jèhófà. (1Kr 28:18) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, “nígbàkigbà tí Mósè bá lọ sínú àgọ́ ìpàdé láti bá [Jèhófà] sọ̀rọ̀, ó máa ń gbọ́ ohùn tó ń bá a sọ̀rọ̀ láti òkè ìbòrí àpótí Ẹ̀rí, láàárín àwọn kérúbù méjèèjì; Ọlọ́run á sì bá a sọ̀rọ̀.” (Nọ 7:89) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jóṣúà àti Fíníhásì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà níwájú Àpótí náà. (Joṣ 7:6-10; Ond 20:27, 28) Àmọ́, àlùfáà àgbà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ lẹ́ẹ̀kan péré láàárín ọdún, ó sì máa rí Àpótí náà. Kì í ṣe torí kó lè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà ló ṣe lọ, ààtò Ọjọ́ Ètùtù ló máa ṣe lọ́jọ́ yẹn.—Le 16:2, 3, 13, 15, 17; Heb 9:7.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 432 ¶1
Kérúbù
Àwòrán kérúbù wà lára ohun tí Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi sínú àgọ́ ìjọsìn tí wọ́n máa kọ́ sínú aginjù. Ó ní kí wọ́n fi òòlù ṣe kérúbù méjì tó jẹ́ wúrà sí ìkángun kọ̀ọ̀kan ìbòrí Àpótí Májẹ̀mú. Àwọn kérúbù náà dojú kọra, wọ́n sì tẹrí ba lórí ìbòrí náà bíi pé wọ́n ń jọ́sìn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, wọ́n nà án sókè, wọ́n sì fi bo ìbòrí náà bíi pé wọ́n ń ṣọ́ ọ. (Ẹk 25:10-21; 37:7-9) Yàtọ̀ síyẹn, àwòrán kérúbù wà lára aṣọ tí wọ́n kọ́kọ́ fi bo àgọ́ ìjọsìn náà àti aṣọ ìkélé tó pín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ.—Ẹk 26:1, 31; 36:8, 35.
it-2 936
Búrẹ́dì Àfihàn
Ìṣù búrẹ́dì méjìlá ni búrẹ́dì yìí, wọ́n máa ń gbé e sórí tábìlì nínú Ibi Mímọ́ ní àgọ́ ìjọsìn tàbí tẹ́ńpìlì, gbogbo ọjọ́ Sábáàtì ni wọ́n sì máa ń fi búrẹ́dì tuntun pààrọ̀ rẹ̀. (Ẹk 35:13; 39:36; 1Ọb 7:48; 2Kr 13:11; Ne 10:32, 33) Lédè Hébérù, búrẹ́dì àfihàn túmọ̀ sí “búrẹ́dì iwájú.” Nígbà míì, ọ̀rọ̀ náà “iwájú” máa ń tọ́ka sí ohun kan tàbí ẹnì kan tó wà “níwájú” ẹni (2Ki 13:23), torí náà, búrẹ́dì àfihàn yìí máa ń wà níwájú Jèhófà nígbà gbogbo gẹ́gẹ́ bí ọrẹ. (Ẹk 25:30) Wọ́n tún máa ń pe búrẹ́dì àfihàn yìí ní “búrẹ́dì onípele” (2Kr 2:4) àti “búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú” (Mk 2:26).
Bíbélì Kíkà
SEPTEMBER 21-27
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 27-28
“Ohun Tá A Rí Kọ́ Nípa Aṣọ Àlùfáà?”
it-2 1143
Úrímù àti Túmímù
Àwọn kan tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì gbà pé kèké ni Úrímù àti Túmímù. Ìtumọ̀ Bíbélì James Moffatt pè é ní “kèké mímọ́” nínú Ẹ́kísódù 28:30. Èrò àwọn kan ni pé ẹyọ mẹ́ta ni Úrímù àti Túmímù yìí, wọ́n kọ “bẹ́ẹ̀ ni” sára ọ̀kan, “bẹ́ẹ̀ kọ́” sára ìkejì, wọn ò sì kọ nǹkan kan sára ìkẹta. Èyí tí wọ́n bá mú nínú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n fi ń mọ ìdáhùn sí ìbéèrè wọn. Àmọ́ tó bá jẹ́ èyí tí wọn ò kọ nǹkan kan sí lára ni wọ́n mú, a jẹ́ pé kò sí ìdáhùn nìyẹn. Àwọn kan tún rò pé òkúta pẹlẹbẹ méjì ni Úrímù àti Túmímù, tí iwájú àti ẹ̀yìn òkúta méjèèjì sì máa ń jẹ́ dúdú àti funfun. Tí wọ́n bá dà á sílẹ̀, tó sì jẹ́ pé ibi tó funfun lára òkúta méjèèjì ló kọjú sókè, ìdáhùn wọn máa jẹ́ “bẹ́ẹ̀ ni,” tó bá sì jẹ́ dúdú ni méjèèjì, ìdáhùn máa jẹ́ “bẹ́ẹ̀ kọ́,” àmọ́ tó bá jẹ́ dúdú kan àti funfun kan, kò sí ìdáhùn nìyẹn. Nígbà kan tí Sọ́ọ̀lù lọ bá àlùfáà pé kó bá òun wádìí bóyá kí òun tún lọ bá àwọn Filísínì jà, kò rí ìdáhùn. Sọ́ọ̀lù rò pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun òun ti ṣẹ̀, ó wá bẹ Jèhófà pé: “Ọlọ́run Ísírẹ́lì, fi Túmímù dáhùn!” Wọ́n wá ya Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó wà níbẹ̀, lẹ́yìn náà wọ́n ṣẹ́ kèké láti mọ ẹni tó ṣẹ̀ nínú àwọn méjèèjì. Nínú ìtàn yìí, bí Sọ́ọ̀lù ṣe bẹ Jèhófà pé kó “fi Túmímù dáhùn” jẹ́ ká rí i pé ó ṣeé ṣe kí Túmímù yàtọ̀ sí kèké, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí méjèèjì fẹ́ jọra lọ́nà kan.—1Sa 14:36-42.
it-1 849 ¶3
Iwájú Orí
Àlùfáà Àgbà Ísírẹ́lì. Láyé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, irin pẹlẹbẹ tí wọ́n fi wúrà ṣe wà lára láwàní tí àlùfáà àgbà máa ń wé sórí. Irin yìí jẹ́ “àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́,” wọ́n sì fín ọ̀rọ̀ kan sára rẹ̀ “bí ẹni fín èdìdì,” pé, “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.” (Ẹk 28:36-38; 39:30) Àlùfáà àgbà ni aṣojú àgbà fún ìjọsìn Jèhófà ní Ísírẹ́lì, torí náà, ó yẹ kí àlùfáà àgbà máa jẹ́ mímọ́, ọ̀rọ̀ tí wọ́n sì kọ sára irin pẹlẹbẹ yìí tún máa rán gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé ó yẹ kí wọ́n máa jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń jọ́sìn Jèhófà. Ó tún ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà títóbi àti bí Jèhófà ṣe yà á sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ àlùfáà, kó lè gbé ìjẹ́mímọ́ Ọlọ́run ga.—Heb 7:26.
Máa Ṣe Ohun Tó Ń gbé Iyì Jèhófà Yọ
A gbọ́dọ̀ rí i pé a kì í ṣe ohun tó lè tàbùkù sí Jèhófà nígbà ìjọsìn. Oníwàásù 5:1 sọ pé: “Ṣọ́ ẹsẹ̀ rẹ nígbàkigbà tí o bá ń lọ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́.” Bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún Mósè nígbà kan ló ṣe pàṣẹ fún Jóṣúà náà pé kó bọ́ sálúbàtà rẹ̀ nígbà tó wà ní ibi mímọ́. (Ẹ́kís. 3:5; Jóṣ. 5:15) Àwọn méjèèjì ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. Ọlọ́run pa á láṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àlùfáà pé kí wọ́n máa wọ ṣòkòtò tá a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe “láti [fi] bo ara tí ó wà ní ìhòòhò.” (Ẹ́kís. 28:42, 43) Èyí kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni rí ìhòòhò wọn nígbà tí wọ́n bá wà lẹ́nu iṣẹ́ wọn nídìí pẹpẹ. Gbogbo ìdílé àlùfáà pẹ̀lú ló gbọ́dọ̀ máa hùwà tí kò ní tàbùkù sí Ọlọ́run.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ibo ni wọ́n ti rí àwọn òkúta iyebíye tó wà lára aṣọ ìgbàyà àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì?
Ẹ̀yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì tí wọ́n dé inú aginjù ni Ọlọ́run pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe aṣọ ìgbàyà yìí. (Ẹ́kísódù 28:15-21) Àwọn òkúta tó wà lára aṣọ ìgbàyà náà ni rúbì, tópásì, émírádì, tọ́kọ́wásì, sàfáyà, jásípérì, léṣémù, ágétì, ámétísì, kírísóláítì, ónísì àti jéèdì. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tiẹ̀ lè rí àwọn òkúta iyebíye yìí?
Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ohun pàtàkì ni wọ́n ka àwọn òkúta iyebíye sí, wọ́n sì máa ń tà wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Íjíbítì àtijọ́ máa ń wá àwọn òkúta iyebíye yẹn dé ibi tó jìnnà gan-an, irú bí àwọn orílẹ̀-èdè tí a wá mọ̀ sí Ìráànì, Afghanistan, àti bóyá títí dé Íńdíà. Oríṣiríṣi òkúta iyebíye ni àwọn ará Íjíbítì máa ń rí níbi tí wọ́n ti ń wa kùsà. Àwọn ọba Íjíbítì nìkan ló sì ní àṣẹ lórí wíwa àwọn òkúta iyebíye jáde ní àgbègbè abẹ àṣẹ wọn. Baba ńlá náà Jóòbù sọ bí àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ ṣe ń gba ojú ihò abẹ́lẹ̀ àti ojú ọ̀nà abẹ́lẹ̀ láti lọ wá àwọn òkúta iyebíye. Jóòbù mẹ́nu ba sàfáyà àti tópásì ní pàtó, pé wọ́n wà lára àwọn ìṣúra tí wọ́n máa ń wà jáde látinú ilẹ̀.—Jóòbù 28:1-11, 19.
Ìwé Ẹ́kísódù sọ pé nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, “wọ́n . . . gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì,” ìyẹn ni pé wọ́n gba àwọn nǹkan olówó iyebíye lọ́wọ́ wọn. (Ẹ́kísódù 12:35, 36) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilẹ̀ Íjíbítì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti rí àwọn òkúta tó wà lára aṣọ ìgbàyà àlùfáà àgbà.
it-1 1130 ¶2
Ìjẹ́mímọ́
Ẹranko àti Irè Oko. Gbogbo akọ màlúù, ewúrẹ́ tàbí àgùntàn tó jẹ́ àkọ́bí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kà sí ohun mímọ́ fún Jèhófà, wọn ò sì gbọ́dọ̀ rà á pa dà. Wọ́n gbọ́dọ̀ fi rúbọ, kí wọ́n sì mú lára ẹ̀ fún àlùfáà tó bá tọ́ sí. (Nọ 18:17-19) Bó ṣe jẹ́ pé ohun mímọ́ ni gbogbo ẹbọ tí wọ́n rú àtàwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá sí ibi mímọ́, bẹ́ẹ̀ náà làwọn irè oko tó kọ́kọ́ so àti ìdámẹ́wàá ṣe jẹ́ mímọ́. (Ẹk 28:38) Wọ́n gbọ́dọ̀ ya gbogbo ohun tí wọ́n bá mú wá sí mímọ́ fún Jèhófà, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú wọn, tàbí kí wọ́n lò wọ́n lọ́nà àìtọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ti òfin tó wà fún ìdámẹ́wàá. Ká sọ pé ọkùnrin kan ya ohun kan sọ́tọ̀ láti fi san ìdámẹ́wàá, bí àpẹẹrẹ tó bá jẹ́ àlìkámà. Tí òun tàbí ẹlòmíì bá ṣèèṣì mú lára àlìkámà yẹn tó wá lọ sè é, ọkùnrin yẹn ti jẹ̀bi torí ó ti rú òfin Ọlọ́run tó ní ín ṣe pẹ̀lú ohun mímọ́. Ohun tí Òfin sọ ni pé ẹni náà gbọ́dọ̀ san ìwọ̀n àlìkámà tó mú náà pa dà, á sì fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un. Ìyẹn lẹ́yìn tó bá ti kọ́kọ́ fi àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá rúbọ sí Jèhófà. Èyí jẹ́ ká rí bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ohun tí wọ́n yà sí mímọ́ fún Jèhófà.—Le 5:14-16.
Bíbélì Kíkà
SEPTEMBER 28–OCTOBER 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 29-30
“Wọ́n Mú Ọrẹ Wá fún Jèhófà”
it-2 764-765
Ìforúkọsílẹ̀
Ní Sínáì. Ìgbà àkọ́kọ́ tí Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n forúkọ sílẹ̀ ni ìgbà tí wọ́n pàgọ́ sí Sínáì, ní oṣù kejì ọdún kejì tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì. Kí iṣẹ́ náà má bàa wọ Mósè lọ́rùn, Jèhófà ní kó yan ìjòyè kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kàn táá máa bójú tó ìforúkọsílẹ̀ náà ní ẹ̀yà rẹ̀. Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun, ló forúkọ sílẹ̀. Àmọ́ Òfin tún sọ pé gbogbo àwọn tó forúkọ sílẹ̀ gbọ́dọ̀ san owó orí tí iye rẹ̀ jẹ́ ààbọ̀ ṣékélì, kí wọ́n lè máa fi bójú tó àgọ́ ìjọsìn. (Ẹk 30:11-16; Nọ 1:1-16, 18, 19) Gbogbo àwọn tó forúkọ sílẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550), yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Léfì, torí wọn ò ní bá àwọn ẹ̀yà yòókù pín ilẹ̀. Àwọn ọmọ Léfì ò ní san owó orí ní tiwọn, wọn ò sì ní dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun.—Nọ 1:44-47; 2:32, 33; 18:20, 24.
it-1 502
Ọrẹ
Òfin sọ pé ó pọn dandan kí wọ́n san àwọn ọrẹ kan. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Mósè ní kí wọ́n ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè gbọ́dọ̀ san “ààbọ̀ ṣékélì, [tó] jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́” láti fi ra ẹ̀mí wọn pa dà. Ó jẹ́ “ọrẹ fún Jèhófà” kí wọ́n lè fi ṣe ètùtù fún ẹ̀mí wọn, kí wọ́n sì lè lò ó “fún iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé.” (Ẹk 30:11-16) Bí òpìtàn Júù tó ń jẹ́ Josephus ṣe sọ (nínú ìwéThe Jewish War, VII, 218 [vi, 6]), wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í san “owó orí mímọ́” yìí lọ́dọọdún nígbà tó yá.—2Kr 24:6-10; Mt 17:24.
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Báwo ni wọ́n ṣe ń rí owó tí wọ́n ń ná sórí àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe ní tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù?
Owó orí ni wọ́n fi ń bójú tó oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n ń ṣe ní tẹ́ńpìlì, ìdámẹ́wàá tó jẹ́ owó orí tó pọn dandan sì lò pọ̀ jù lára owó náà. Àmọ́, wọ́n tún máa ń lo àwọn owó orí míì pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn, Jèhófà sọ fún Mósè pé kó gba ààbọ̀ ṣékélì fàdákà gẹ́gẹ́ bí “ọrẹ fún Jèhófà,” lọ́wọ́ gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tí orúkọ wọ́n wà nínú àkọsílẹ̀.—Ẹ́kísódù 30:12-16.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bó ṣe di ohun tí àwọn Júù wá ń ṣe nìyẹn, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń mú iye yìí wá lọ́dọọdún gẹ́gẹ́ bí owó orí tẹ́ńpìlì. Owó orí yìí ni Jésù ní kí Pétérù fi owó ẹyọ tó rí lẹ́nu ẹja san.—Mátíù 17:24-27.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 1029 ¶4
Ọwọ́
Gbígbé Ọwọ́ Léni. Yàtọ̀ sí kéèyàn di nǹkan mú, wọ́n tún máa ń gbé ọwọ́ lé èèyàn tàbí nǹkan míì fún àwọn ìdí kan. Ohun tó sábà máa ń túmọ̀ sí tí wọ́n bá gbé ọwọ́ lé ẹnì kan tàbí nǹkan kan ni pé wọ́n yan ẹni náà sípò kan tàbí pé wọ́n ya nǹkan ọ̀hún sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ kan. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n ń fi iṣẹ́ àlùfáà lé Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé orí akọ màlúù àti àgbò tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ. Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé wọ́n gbà kí wọ́n fi àwọn ẹran yìí rúbọ fún àwọn torí kí wọ́n lè di àlùfáà Jèhófà Ọlọ́run. (Ẹk 29:10, 15, 19; Le 8:14, 18, 22) Nígbà tí Ọlọ́run ní kí Mósè yan Jóṣúà kó lè faṣẹ́ lé e lọ́wọ́, Mósè gbé ọwọ́ lé Jóṣúà, “ẹ̀mí ọgbọ́n sì kún inú” rẹ̀. Ìyẹn jẹ́ kó lè darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bó ṣe tọ́. (Di 34:9) Wọ́n tún máa ń gbé ọwọ́ lé àwọn èèyàn tí wọ́n bá fẹ́ súre fún wọn. (Jẹ 48:14; Mk 10:16) Jésù Kristi náà gbé ọwọ́ lé àwọn kan kó tó wò wọ́n sàn. (Mt 8:3; Mk 6:5; Iṣe 13:13) Nígbà tí àwọn àpọ́sítélì gbé ọwọ́ lé àwọn kan, àwọn ẹni náà rí ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ gbà.—Iṣe 8:14-20; 19:6.
it-1 114 ¶1
Ẹni Àmì Òróró, Òróró Àfiyanni
Nínú Òfin tí Jèhófà fún Mósè, ó ṣàlàyé ohun tí wọ́n máa fi ṣe òróró àfiyanni. Òróró yìí ṣàrà ọ̀tọ̀, torí àwọn ohun èlò tó dáa jù ni wọ́n lò láti fi ṣe é, bíi òjíá, sínámónì dídùn, ewéko kálámọ́sì dídùn, kaṣíà, àti òróró ólífì. (Ẹk 30:22-25) Tí ẹnikẹ́ni bá ṣe irú òróró yìí tó sì lò ó lọ́nà tí ò yẹ tàbí tó lò ó fún ẹni tí kò tọ́ sí, ṣe ni wọ́n á pa á. (Ẹk 30:31-33) Èyí jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré tí wọ́n bá fi òróró mímọ́ yan ẹnì kan sípò kan, torí ohun mímọ́ ni lójú Ọlọ́run.
Bíbélì Kíkà