Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí táwọn Júù ò fi sí lójú kan nígbà tí Jésù wà láyé?
Nígbà tí Jésù sọ fáwọn kan tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé wọn ò ní lè wá síbi tóun ń lọ, àwọn Júù ń bi ara wọn pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ń pète-pèrò láti lọ . . . ? Kò pète-pèrò láti lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù tí ó fọ́n ká sáàárín àwọn Gíríìkì . . . àbí òun fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni?” (Jòhánù 7:32-36) Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì lọ wàásù ìhìn rere fáwọn Júù tó ń gbé láwọn ilẹ̀ tó yí Òkun Mẹditaréníà ká.—Ìṣe 2:5-11; 9:2; 13:5, 13, 14; 14:1; 16:1-3; 17:1; 18:12, 19; 28:16, 17.
Ìdí táwọn Júù fi wà láwọn ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn wọ̀nyẹn ni pé àwọn orílẹ̀-èdè alágbára kó wọn lẹ́rú kúrò ní ìlú ìbílẹ̀ wọn, orílẹ̀-èdè Ásíríà ló kọ́kọ́ kó wọn lẹ́rú lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, lẹ́yìn náà ni orílẹ̀-èdè Bábílónì náà wá kó wọn lẹ́rú lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú ló pa dà sí Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀ lómìnira. (Aísáyà 10:21, 22) Àwọn tó kù ò pa dà sílé.
Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àdúgbò táwọn Júù ń gbé wà ní ọgọ́rùn-ún kan àti mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [127] ilẹ̀ tó wà lábẹ́ ìdarí Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. (Ẹ́sítérì 1:1; 3:8) Gbogbo ìsapá àwọn Júù láti jẹ́ káwọn tó wà ládùúgbò wọn máa ṣe Ìsìn Àwọn Júù ló wá jẹ́ kí púpọ̀ lára àwọn aládùúgbò wọn ní ìmọ̀ nípa Jèhófà àti Òfin tó fún àwọn Júù. (Mátíù 23:15) Àwọn Júù láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló wá síbi Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, níbi tí wọ́n ti gbọ́ ìhìn rere nípa Jésù. Torí náà, báwọn Júù ṣe wà káàkiri àwọn ilẹ̀ tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù wà lára ohun tó jẹ́ kí ìsìn Kristẹni tètè gbilẹ̀.
Báwo ni wúrà tí Sólómọ́nì Ọba ní ṣe pọ̀ tó?
Bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ, tá a bá ní ká wọn iye wúrà, ìyẹn góòlù, tí Hírámù ọba ìlú Tírè fi ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì, ó máa wúwo tó ọgọ́rin [80] àpò sìmẹ́ǹtì, iye yẹn náà sì ni ọbabìnrin Ṣébà fi ránṣẹ́ sí i, iye wúrà tí wọ́n sì kó wọlé fún Sólómọ́nì fúnra rẹ̀ láti ìlú Ófírì wúwo ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] àpò sìmẹ́ǹtì lọ. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ìwọ̀n wúrà tí ó ń dé sọ́dọ̀ Sólómọ́nì ní ọdún kan . . . jẹ́ ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà tálẹ́ńtì wúrà,” ìyẹn sì wúwo ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] àpò sìmẹ́ǹtì lọ. (1 Àwọn Ọba 9:14, 28; 10:10, 14) Ṣé àsọdùn ò ti wọ ọ̀rọ̀ yìí báyìí? Ó dáa, báwo ni ìwọ̀n góòlù táwọn ọba máa ń ní nígbà yẹn ṣe máa ń pọ̀ tó?
Ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ti kọ láìmọye ọdún sẹ́yìn táwọn ọ̀mọ̀wé rí tí wọ́n sì gbà pó jóòótọ́ sọ pé iye ìwọ̀n wúrà tí Pharaoh Thutmose Kẹta ti Íjíbítì (tó jọba ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] ṣáájú Sànmánì Kristẹni) fi ṣètọrẹ sí tẹ́ńpìlì Amun-Ra tó wà ní Karnak wúwo tó ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́rin [270] àpò sìmẹ́ǹtì. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́jọ [800] ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n fi ìwọ̀n góòlù tó tó ọgọ́rin [80] àpò sìmẹ́ǹtì ránṣẹ́ sí Tiglath-pileser Kẹta, ọba ìlú Ásíríà láti ìlú Tírè, ìwọ̀n góòlù yìí kan náà sì ni Sargon Kejì fi ránṣẹ́ sáwọn ọlọ́run Bábílónì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. Àwọn èèyàn ròyìn pé ìwọ̀n góòlù tí Philip Kejì, ọba ìlú Makedóníà (tó jọba ní ọdún 359 sí ọdún 336 ṣáájú Sànmánì Kristẹni) máa ń wà lọ́dọọdún ní Pangaeum ti Tírésì máa ń wúwo tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti ọgọ́ta [560] àpò sìmẹ́ǹtì.
Nígbà tí ọmọ Philip, ìyẹn Alẹkisáńdà Ńlá (tó jọba ní ọdún 336 sí ọdún 323 ṣáájú Sànmánì Kristẹni) kó Súsà ọ̀kan lára àwọn ìlú tó wà ní Páṣíà lẹ́rú, ìwọ̀n góòlù tí wọ́n sọ pé ó kó ní Súsà nìkan wúwo tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [23,600] àpò sìmẹ́ǹtì, nígbà tí àròpọ̀ èyí tó kó ní gbogbo ilẹ̀ Páṣíà wúwo tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogóje [140,000] àpò sìmẹ́ǹtì. Torí náà, nígbà tá a bá fi gbogbo àwọn ìròyìn wọ̀nyí wé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwọ̀n góòlù tí Sólómọ́nì Ọba ní, a máa rí i pé kò sí àsọdùn nínú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ.