Bí Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun
“Àwọn nǹkan tí ìwọ sì ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi . . . , fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́.”—2 TÍM. 2:2.
1. (a) Kí làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ nípa ìdálẹ́kọ̀ọ́, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì lónìí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
TIPẸ́TIPẸ́ làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti mọ̀ pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ máa ń mú kéèyàn ṣàṣeyọrí. Nígbà tí Ábúrámù, baba ńlá ìgbàanì fẹ́ lọ dá Lọ́ọ̀tì nídè, ó “pe àwọn ọkùnrin tí ó ti kọ́ jọ,” wọ́n sì ṣàṣeyọrí. (Jẹ́n. 14:14-16) Nígbà tí Dáfídì Ọba wà láyé, àwọn “tí a kọ́ ní iṣẹ́ orin kíkọ sí Jèhófà” ló ń kọrin ní ilé Ọlọ́run, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo. (1 Kíró. 25:7) Lónìí, à ń bá Sátánì àtàwọn tó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn jagun tẹ̀mí. (Éfé. 6:11-13) Bákan náà, à ń ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè fi ìyìn fún Jèhófà. (Héb. 13:15, 16) Nítorí náà, bíi ti àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́, ìdálẹ́kọ̀ọ́ ṣe pàtàkì ká bàa lè ṣàṣeyọrí. Nínú ìjọ, àwọn alàgbà ni Jèhófà gbé iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ẹlòmíì lé lọ́wọ́. (2 Tím. 2:2) Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà tó nírìírí ń gbà kọ́ àwọn arákùnrin kí wọ́n lè tóótun láti bójú tó agbo Ọlọ́run?
RAN AKẸ́KỌ̀Ọ́ LỌ́WỌ́ KÓ LÈ LÓKUN NÍPA TẸ̀MÍ
2. Kí ló yẹ kí alàgbà kan ṣe kí ó tó kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan, kí sì nìdí?
2 A lè fi ẹ̀yin alàgbà wé àgbẹ̀ kan. Kí àgbẹ̀ kan tó gbin irúgbìn sóko rẹ̀, ó lè rí i pé ó yẹ kí òun fi ajílẹ̀ sí inú ilẹ̀ tó fẹ́ gbin nǹkan sí kí àwọn irè oko rẹ̀ lè so dáadáa. Bákan náà, kí o tó dá arákùnrin kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí lẹ́kọ̀ọ́, o lè rí i pé ó máa dáa tí o bá kọ́kọ́ ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tó máa jẹ́ kí ẹ̀kọ́ náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn kó sì túbọ̀ fi ẹ̀kọ́ náà sílò.—1 Tím. 4:6.
3. (a) Báwo ni a ṣe lè lo ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Máàkù 12:29, 30 tá a bá ń bá akẹ́kọ̀ọ́ kan sọ̀rọ̀? (b) Ipa wo ni àdúrà tí alàgbà kan bá gbà lè ní lórí akẹ́kọ̀ọ́?
3 Tó o bá fẹ́ mọ bí akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ Ìjọba náà darí èrò àti ìṣe rẹ̀ tó, o lè bíi pé, ‘Báwo ni bó o ṣe ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà ṣe ti yí ọ̀nà tó o gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ pa dà?’ Ìbéèrè yẹn lè jẹ́ kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó gbámúṣé nípa ìdí tí a fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa tọkàntọkàn. (Ka Máàkù 12:29, 30.) Ní ìparí ọ̀rọ̀ yín ẹ lè gbàdúrà pa pọ̀, kó o sì bẹ Jèhófà pé kó fún akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ẹ̀mí mímọ́ tó nílò kó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu ìdálẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Bí arákùnrin náà ṣe ń gbọ́ tó ò ń gbàdúrà látọkàn wá nítorí rẹ̀ máa fún un níṣìírí gan-an ni.
4. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tó máa ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? (b) Kí ni àwọn alàgbà máa ń fẹ ṣe tí wọ́n bá ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́?
4 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, jíròrò àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì kan tó máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà rí ìdí tó fi yẹ kí òun múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́, kó ṣeé gbára lé, kó sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (1 Ọba 19:19-21; Neh. 7:2; 13:13; Ìṣe 18:24-26) Ó ṣe pàtàkì pé kí akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìwà yẹn bó ṣe ṣe pàtàkì pé kí àgbẹ̀ fi ajílẹ̀ sílẹ̀ tó fẹ́ fi dáko. Wọ́n máa jẹ́ kó tètè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Jean-Claude, láti orílẹ̀-èdè Faransé sọ pé: “Tí mo bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, mo máa ń fẹ́ ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè di ẹni tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn. Mo máa ń rí i pé a jọ ka àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtó kan tó máa ‘la ojú’ akẹ́kọ̀ọ́ náà sí ‘àwọn ohun àgbàyanu’ tó wà nínú Bíbélì.” (Sm. 119:18) Àwọn nǹkan míì wo la lè ṣe láti ran akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ́wọ́ kó lè lókun nípa tẹ̀mí?
DÁBÀÁ ÀWỌN ÀFOJÚSÙN KÓ O SÌ SỌ ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ
5. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jíròrò àwọn àfojúsùn tẹ̀mí pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ kan? (b) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà dá àwọn tó ṣì kéré lẹ́kọ̀ọ́? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
5 O lè bi akẹ́kọ̀ọ́ kan pé, ‘Àwọn nǹkan wo lo fi ṣe àfojúsùn rẹ nípa tẹ̀mí?’ Bí kò bá tíì ní àfojúsùn kan pàtó, ràn án lọ́wọ́ kó lè yan ọ̀kan tí agbára rẹ̀ ká tí ọwọ́ rẹ̀ sì lè tẹ̀. Sọ ohun kan pàtó tó o fi ṣe àfojúsùn rẹ nígbà kan rí, kó o sì fi ọ̀yàyà sọ bí inú rẹ ṣe dùn tó nígbà tí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́. Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé àbá yìí kò ṣòro rárá, síbẹ̀ ó gbéṣẹ́ gan-an ni. Alàgbà kan tó tún jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nílẹ̀ Áfíríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Victor, sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, alàgbà kan bi mí láwọn ìbéèrè mélòó kan tó ń múni ronú jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tí mo fi ṣe àfojúsùn mi. Àwọn ìbéèrè yẹn ló jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gan-an nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi.” Àwọn alàgbà tó nírìírí tún sọ pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, pàápàá tí wọ́n bá ti ń lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá. Ìyẹn gba pé ká máa fún wọn níṣẹ́ tó bá ọjọ́ orí wọn mu. Tí a bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́, nígbà tí wọ́n bá fi máa pé ọmọ ogún ọdún, àwọn àfojúsùn tẹ̀mí ni wọ́n á máa lépa dípò àwọn nǹkan ayé tó sábà máa ń pín ọkàn àwọn ọ̀dọ́ níyà.—Ka Sáàmù 71:5, 17.a
6. Kí ni ohun pàtàkì kan tí Jésù máa ń ṣe tó bá ń dáni lẹ́kọ̀ọ́?
6 Ohun míì tó o lè ṣe kó lè wu akẹ́kọ̀ọ́ kan láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ni pé kó o ṣàlàyé ohun tó yẹ kó ṣe àti ìdí tó fi yẹ kó ṣe é. Tó o bá ń sọ ìdí tó fi yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àwọn nǹkan kan, ńṣe lò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà. Bí àpẹẹrẹ, kí Jésù tó gbé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lé àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́, ó sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” Ó wá fi kún un pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:18, 19) Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó o bá ń dáni lẹ́kọ̀ọ́?
7, 8. (a) Báwo làwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíì? (b) Báwo ló ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká máa gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́? (d) Àwọn àbá wo ló lè ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíì? (Wo àpótí náà “Bá A Ṣe Lè Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́.”)
7 Ṣàlàyé ìdí tí ohun tó o ní kí akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe fi bá Ìwé Mímọ́ mu. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń kọ́ ọ láti máa ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì nínú ohun gbogbo tó bá ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé o ní kí arákùnrin kan máa rí i pé kò sí ohunkóhun tó lè ṣèpalára fáwọn èèyàn lẹ́nu ọ̀nà Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí ibẹ̀ sì máa wà ní mímọ́ tónítóní. O lè ka Títù 2:10, kó o wá ṣàlàyé fún un pé bó ṣe ń bójú tó ẹnu ọ̀nà Gbọ̀ngàn Ìjọba ń “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́.” Bákan náà, sọ pé kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ronú nípa àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ àti bí wọ́n ṣe máa jàǹfààní tó bá ń ṣe ojúṣe rẹ̀. Tá a bá ní irú ìjíròrò yìí pẹ̀lú ẹni tá à ń dá lẹ́kọ̀ọ́, á jẹ́ kó máa ronú nípa àǹfààní tí iṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe ìjọ dípò kó máa ronú nípa ìtọ́ni tá a fun. Inú rẹ̀ máa dùn bó ṣe ń rí i pé àwọn ará ń jàǹfààní nínú iṣẹ́ tó ń bójú tó.
8 Síwájú sí i, rí i pé ò ń gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ náà bó ṣe ń sapá láti fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò. Báwo nìyẹn ti ṣe pàtàkì tó? Omi máa ń mú kí irúgbìn dàgbà. Lọ́nà kan náà, tí a bá ń gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ ó máa jẹ́ kó dàgbà nípa tẹ̀mí.—Fi wé Mátíù 3:17.
ÌPÈNÍJÀ MÍÌ
9. (a) Ìṣòro wo ni àwọn alàgbà kan tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù máa ń kojú tí wọ́n bá fẹ́ dáni lẹ́kọ̀ọ́? (b) Kí nìdí tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan ò ṣe fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn?
9 Àwọn alàgbà tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù lè kojú ìpèníjà míì: Ìyẹn bí wọ́n ṣe máa ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin tó ti lé lọ́mọ ogún ọdún tàbí ọgbọ̀n ọdún tí wọ́n sì ti ṣèrìbọmi kí wọ́n lè gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. A béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà onírìírí tó wá láti ilẹ̀ tí ó tó ogún [20] ní Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ohun tí wọ́n rò pé ó fàá tí àwọn ọ̀dọ́ kan kì í fẹ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Púpọ̀ nínú wọn ló sọ pé: Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ kan ń dàgbà, kò sẹ́ni tó fún wọn níṣìírí láti fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣe àfojúsùn wọn. Kódà, nígbà táwọn ọ̀dọ́ kan fẹ́ fi ohun tẹ̀mí ṣe àfojúsùn wọn, ńṣe làwọn òbí wọn rọ̀ wọ́n láti kàwé dáadáa kí wọ́n lè ríṣẹ́ gidi ṣe! Irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ kò fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn.—Mát. 10:24.
10, 11. (a) Báwo ni alàgbà kan ṣe lè rọra tún èrò arákùnrin kan ṣe tó bá jọ pé kò fẹ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kankan nínú ìjọ? (b) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni alàgbà náà lè jíròrò pẹ̀lú arákùnrin náà, kí sì nìdí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
10 Tó bá jọ pé arákùnrin kan kò fẹ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kankan nínú ìjọ, ó máa gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti sùúrù kẹ́ ẹ tó lè tún èrò rẹ̀ ṣe, àmọ́ kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe. Bí àgbẹ̀ ṣe máa ń rọra lọ́ okùn iṣu mọ́ igi kí iṣu náà lè ta dáadáa, bẹ́ẹ̀ lo ṣe lè fara balẹ̀ ran àwọn arákùnrin kan lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbà láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Báwo lo ṣe lè ṣe é?
11 Wá àyè láti di ọ̀rẹ́ arákùnrin tó ò ń dá lẹ́kọ̀ọ́ náà. Jẹ́ kó mọ̀ pé a nílò rẹ̀ nínú ìjọ. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ẹ jọ jókòó sọ̀rọ̀, kí ẹ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pàtó, kó o sì ràn án lọ́wọ́ láti ronú nípa ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà. (Oníw. 5:4; Aísá. 6:8; Mát. 6:24, 33; Lúùkù 9:57-62; 1 Kọ́r. 15:58; 2 Kọ́r. 5:15; 13:5) O lè bi í pé, ‘Ìlérí wo lo ṣe fún Jèhófà nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún un?’ Kó o lè dé ọkàn rẹ̀, o lè bi í pé, ‘Báwo lo ṣe rò pé ó rí lára Jèhófà nígbà tó o ṣe ìrìbọmi?’ (Òwe 27:11) ‘Báwo ló ṣe rí lára Sátánì?’ (1 Pét. 5:8) Má ṣe fojú kéré ipa tí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o fara balẹ̀ yàn tó o sì kà fún arákùnrin náà lè ní lórí rẹ̀.—Ka Hébérù 4:12.b
Ẹ̀YIN AKẸ́KỌ̀Ọ́, Ẹ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́
12, 13. (a) Irú ìwà wo ni Èlíṣà hù nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Èlíjà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Èlíṣà nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀?
12 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, a nílò yín nínú ìjọ! Nítorí náà, àwọn ìwà wo ló máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè ṣàṣeyọrí? Láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹnì kan nígbà àtijọ́ tí òun náà jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́.
13 Ní nǹkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, wòlíì Èlíjà ní kí Èlíṣà tó jẹ́ ọ̀dọ́ di ìránṣẹ́ òun. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Èlíṣà gbà láti di ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fi ìṣòtítọ́ sin bàbá àgbàlagbà yìí nípa bíbá a ṣe àwọn iṣẹ́ tí kò jọjú. (2 Ọba 3:11) Lẹ́yìn tí Èlíṣà ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún nǹkan bí ọdún mẹ́fà, ó gbọ́ pé iṣẹ́ Èlíjà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì máa tó dópin. Èlíjà wá sọ fún alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ tó ti dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa yìí pé kó má tẹ̀ lé òun mọ́. Àmọ́, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èlíṣà sọ fún Èlíjà pé: “Èmi kí yóò fi ọ́ sílẹ̀.” Ó ṣe tán láti dúró ti ọ̀gá rẹ̀ tó bá ṣì ṣeé ṣe. Nítorí Èlíṣà jẹ́ olóòótọ́ tó sì dúró ti ọ̀gá rẹ̀ gbágbáágbá Jèhófà bù kún un, ó jẹ́ kó rí ìgbà tí Èlíjà lọ lọ́nà ìyanu.—2 Ọba 2:1-12.
14. (a) Báwo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lónìí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíṣà? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ olóòótọ́?
14 Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíṣà lónìí? Jẹ́ kó máa yá ẹ lára láti gba iṣẹ́ tí wọ́n bá fún ẹ, títí kan àwọn iṣẹ́ tí kò jọjú. Mú olùkọ́ rẹ lọ́rẹ̀ẹ́, kó o sì jẹ́ kó mọ̀ pé o mọyì bó ṣe ń sapá láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́. Ńṣe ni ìwà rere tó o bá hù máa dà bí ìgbà tó ò ń sọ fún un pé: “Èmi kí yóò fi ọ́ sílẹ̀.” Ju gbogbo rẹ̀ lọ, máa fi ìṣòtítọ́ bójú tó iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ẹ. Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé, lẹ́yìn tí àwọn alàgbà bá a rí i pé o jẹ́ olóòótọ́ tó o sì ṣeé fọkàn tán ni ọkàn wọn á tó balẹ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí wọ́n fún ẹ ní àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ.—Sm. 101:6; ka 2 Tímótì 2:2.
FI Ọ̀WỌ̀ TÓ YẸ HÀN
15, 16. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Èlíṣà gbà bọ̀wọ̀ fún olùkọ́ rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ni Èlíṣà ṣe tó fi ọkàn àwọn wòlíì tó kù balẹ̀?
15 Ohun tí Bíbélì sọ nípa Èlíṣà tó gbaṣẹ́ lọ́wọ́ Èlíjà tún jẹ́ ká rí bó ṣe yẹ kí àwọn arákùnrin lónìí máa bọ̀wọ̀ fún àwọn alàgbà tó nírìírí. Lẹ́yìn tí Èlíjà àti Èlíṣà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn wòlíì kan nílùú Jẹ́ríkò, àwọn méjèèjì rìn lọ sí Odò Jọ́dánì. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, “Èlíjà mú ẹ̀wù oyè rẹ̀, ó sì ká a, ó sì lu omi náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó pín.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn la àárín odò tó ti gbẹ náà kọjá, àwọn méjèèjì “ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ń rìn.” Ó ṣe kedere pé, Èlíṣà kò ronú pé òun ti mọ gbogbo nǹkan tán. Títí Èlíjà fi lọ, Èlíṣà fetí sí gbogbo ohun tí olùkọ́ rẹ̀ ń sọ. Lẹ́yìn náà, ìjì ẹlẹ́fùúùfù gbé Èlíjà lọ. Nígbà tí Èlíṣà pa dà dé Odò Jọ́dánì, ó fi ẹ̀wù Èlíjà lu odò náà, ó sì kígbe pé: “Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà dà?” Lẹ́ẹ̀kan sí i, odò náà pín sí méjì.—2 Ọba 2:8-14.
16 Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Èlíṣà ṣe kò yàtọ̀ rárá sí iṣẹ́ ìyanu tí Èlíjà ṣe gbẹ̀yìn? Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì? Ó jọ pé Èlíṣà kò ronú pé ní báyìí tí òun ti wà nípò àṣẹ, ó yẹ kí òun yí àwọn nǹkan kan pa dà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, bó ṣe ń bá a nìṣó láti ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ bí Èlíjà ṣe máa ń ṣe é fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún olùkọ́ rẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí ọkàn àwọn wòlíì yòókù balẹ̀. (2 Ọba 2:15) Ọgọ́ta [60] ọdún ni Èlíṣà fi ṣe iṣẹ́ wòlíì, Jèhófà sì lò ó láti ṣe iṣẹ́ ìyanu tó pọ̀ gan-an ju ti Èlíjà lọ. Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn yìí kọ́ ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ lónìí?
17. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè gbà fìwà jọ Èlíṣà lónìí? (b) Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà lo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ olóòótọ́?
17 Má ṣe ronú pé gbàrà tí wọ́n bá ti fún ẹ láwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan nínú ìjọ lo gbọ́dọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í yí nǹkan pa dà, kó o wá máa ṣe nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ pátápátá sí bí wọ́n ṣe ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Ìwọ kọ́ lo máa pinnu ìgbà tó yẹ kí nǹkan yí pa dà. Ohun tí ìjọ nílò àti ìtọ́ni tá a bá rí gbà látọ̀dọ̀ ètò Jèhófà ló máa jẹ́ ká mọ ìgbà tó yẹ kí ìyípadà wáyé. Ohun tí Èlíṣà ṣe fi àwọn wòlíì tó kù lọ́kàn balẹ̀, ó ń bá a nìṣó láti ṣe nǹkan bí Èlíjà ṣe máa ń ṣe é tó fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún Èlíjà tó gbaṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ìwọ náà lè fìwà jọ Èlíṣà tó o bá jẹ́ kí ọkàn àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ balẹ̀, tó o sì ń bọ̀wọ̀ fún àwọn alàgbà onírìírí nípa ṣíṣe nǹkan lọ́nà tí wọ́n gbà ń ṣe é tí kò sì ta ko ìlànà Bíbélì. (Ka 1 Kọ́ríńtì 4:17.) Àmọ́, bí o ṣe ń ní ìrírí sí i, ó dájú pé ìwọ̀ náà á wà lára àwọn tó ń ran ìjọ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà táá jẹ́ kí wọ́n lè máa bá ètò Jèhófà tó ń tẹ̀ síwájú rìn. Kódà, bíi ti Èlíṣà, Jèhófà ṣì lè lo ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ olóòótọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó pọ̀ ju èyí tí àwọn olùkọ́ yín ṣe lọ.—Jòh. 14:12.
18. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé kí a dá àwọn arákùnrin tó wà nínú ìjọ lẹ́kọ̀ọ́ lónìí?
18 A retí pé àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó ṣáájú rẹ̀ máa mú kí àwọn alàgbà máa wáyè láti dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́. Ǹjẹ́ kí àwọn arákùnrin tó tóótun múra tán láti gba irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ kí wọ́n sì fi ọgbọ́n lò ó bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà. Tí wọ́n bá ṣè bẹ́ẹ̀, ó máa fún gbogbo ìjọ kárí ayé lókun, á sì ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ lákòókò táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì máa wáyé lọ́jọ́ iwájú.
a Bí ọ̀dọ́kùnrin kan bá fi hàn pé òun dàgbà nípa tẹ̀mí, tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tó sì dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè, àwọn alàgbà lè dámọ̀ràn rẹ̀ láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kódà bí kò bá tíì pé ọmọ ogún ọdún.—1 Tím. 3:8-10, 12; wo Ilé Ìṣọ́nà July 1, 1989, ojú ìwé 29.
b Nínú ìjíròrò rẹ o lè lo àwọn kókó tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2012, ojú ìwé 14 sí 16, ìpínrọ̀ 8 sí 13 àti ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ orí 16, ìpínrọ̀ 1 sí 3.