Ǹjẹ́ O Mọyì Àwọn Àgbàlagbà Tẹ́ Ẹ Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́?
NÍ ÀKÓKÒ tí Ísírẹ́lì ìgbàanì wà nínú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ó pa á láṣẹ fún wọn pé: “Kí [ẹ] dìde dúró níwájú orí ewú, kí [ẹ] sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó, kí [ẹ] sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run [yín].” (Léfítíkù 19:32) Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà jẹ́ ojúṣe mímọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú títẹríba fún Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni òde òní kò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́, síbẹ̀ ó rán wa létí pé Jèhófà mọyì àwọn àgbàlagbà tó ń sìn ín, wọ́n sì ṣeyebíye lójú rẹ̀. (Òwe 16:31; Hébérù 7:18) Ǹjẹ́ irú ojú tí Jèhófà fi ń wò wọ́n yìí làwa náà fi ń wò wọ́n? Ǹjẹ́ a mọyì àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa tó jẹ́ àgbàlagbà?
Èlíṣà Mọyì Ọ̀rẹ́ Rẹ̀ Tí Ó Jù Ú Lọ
Ìtàn Bíbélì kan tó fi hàn bí a ṣe lè fi ọ̀wọ̀ fún àwọn àgbà wà nínú ìwé àwọn Ọba Kejì. Ìtàn náà ṣàlàyé bí wòlíì Èlíjà ṣe fi iṣẹ́ lé wòlíì Èlíṣà lọ́wọ́, ẹni tí kò tó o lọ́jọ́ orí. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí Èlíjà parí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì lórí ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì.
Lọ́jọ́ yẹn, Jèhófà ní kí wòlíì àgbà yìí rin ìrìn àjò láti Gílígálì sí Bẹ́tẹ́lì, láti Bẹ́tẹ́lì sí Jẹ́ríkò, àti láti Jẹ́ríkò sí Odò Jọ́dánì. (2 Àwọn Ọba 2:1, 2, 4, 6) Nígbà tí wọ́n ń rin ìrìn àjò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta kìlómítà yẹn, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èlíjà sọ pé kí Èlíṣà padà lẹ́yìn òun. Àmọ́, bí Rúùtù ṣe kọ̀ jálẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò yẹn tó sọ pé òun ò ní fi Náómì sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èlíṣà náà ṣe kọ̀ jálẹ̀ pé òun ò ni fi wòlíì àgbà yìí sílẹ̀. (Rúùtù 1:16, 17) Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èlíṣà sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ, ó dájú pé èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀.” (2 Àwọn Ọba 2:2, 4, 6) Nǹkan bí ọdún mẹ́fà gbáko ni Èlíṣà ti fi bá Èlíjà ṣiṣẹ́ pọ̀ lákòókò yẹn. Síbẹ̀ ó wù ú láti máa bá wòlíì Èlíjà ṣiṣẹ́ lọ. Àní sẹ́, ìtàn náà fi kún un pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n ti ń rìn lọ, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ń rìn, họ́wù, wò ó! . . . Èlíjà sì gòkè.” (Ẹsẹ 11) Ńṣe ni Èlíjà àti Èlíṣà jùmọ̀ sọ̀rọ̀ títí dìgbà tí Èlíjà fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Ó hàn gbangba pé wòlíì yìí múra tán láti gba ìtọ́ni àti ìṣírí tó pọ̀ látọ̀dọ̀ wòlíì tó dàgbà tó sì nírìírí jù ú lọ yìí. Ní kedere, ó mọyì ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó jù ú lọ.
‘Gẹ́gẹ́ Bí Baba àti Ìyá’
Ó rọrùn láti lóye ìdí tí Èlíṣà fi nífẹ̀ẹ́ wòlíì àgbà náà, tó sì kà á sí ọ̀rẹ́—kódà tó kà á sí baba òun nípa tẹ̀mí pàápàá. (2 Àwọn Ọba 2:12) Nígbà tó kù díẹ̀ kí Èlíjà parí iṣẹ́ tá a yàn fún un ní Ísírẹ́lì, ó sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí èmi yóò ṣe fún ọ kí a tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Ẹsẹ 9) Nípa bẹ́ẹ̀, títí dé òpin iṣẹ́ ọ̀hún ni Èlíjà bìkítà nípa ire tẹ̀mí ẹni tó máa fi iṣẹ́ lé lọ́wọ́ yìí àti nípa bí iṣẹ́ Ọlọ́run yóò ṣe máa bá a lọ.
Lóde òní, ó ń múni lọ́kàn yọ̀ láti rí bí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ṣe ń bìkítà fún wa bíi baba àti ìyá, tí wọ́n sì ń fún àwọn tó kéré sí wọn ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ní ẹ̀ka ilé ìṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi tinútinú ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì kí wọ́n lè ní ìmọ̀ tí wọ́n nílò láti ṣe iṣẹ́ wọn. Bákan náà ni àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìyàwó wọn tí wọ́n ti ń bẹ àwọn ìjọ wò fún ọ̀pọ̀ ọdún máa ń fi ayọ̀ ṣàjọpín ọ̀pọ̀ ìrírí tí wọ́n ti ní pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ń dá lẹ́kọ̀ọ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò. Ìyẹn nìkan kọ́ o, a ti rí àwọn àgbà ọkùnrin àti obìnrin nínú àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, tí wọ́n ti fi tọkàntọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún tí wọ́n sì ń fi ayọ̀ ṣàjọpín ọgbọ́n wọn àti ìrírí wọn pẹ̀lú àwọn ẹni tuntun nínú ìjọ.—Òwe 2:7; Fílípì 3:17; Títù 2:3-5.
Bí àwọn Kristẹni tó ti dàgbà wọ̀nyí ṣe ń bìkítà tí wọ́n sì ń fìfẹ́ àtọkànwá hàn ló mú kó túbọ̀ rọrùn láti bọ̀wọ̀ fún wọn. Nítorí náà, a fẹ́ ṣe bíi ti Èlíṣà kí àwa náà mọyì àwọn àgbàlagbà tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe rán wa létí, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ ní híhùwà sí “àgbà ọkùnrin . . . gẹ́gẹ́ bí baba” àti “àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá.” (1 Tímótì 5:1, 2) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ń kópa tó pọ̀ gan-an nínú mímú kí ìjọ Kristẹni máa báṣẹ́ lọ bó ti tọ́ àti bó ṣe yẹ, kó sì máa tẹ̀ síwájú kárí ayé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ó wu Èlíṣà kó máa bá Èlíjà ṣiṣẹ́ lọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn Kristẹni àgbàlagbà máa ń ṣe àwọn tó kéré sí wọn láǹfààní gan-an