Jéhù Jà fún Ìjọsìn Mímọ́
JÉHÙ jà fún ìjọsìn mímọ́. Ó kọ́wọ́ ti ìjọsìn mímọ́ lẹ́yìn tokuntokun, kò fọ̀rọ̀ falẹ̀, kò gba gbẹ̀rẹ́, ó lo ìtara, ó sì ní ìgboyà. Jéhù ní àwọn ànímọ́ tó máa dára ká fi ṣèwà hù.
Ní àkókò tí ipò àwọn nǹkan kò rọgbọ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, Jèhófà yan Jéhù láti mú ìdájọ́ òun ṣẹ. Nígbà yẹn, Áhábù ọba ti kú, Jésíbẹ́lì tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ tó sì tún jẹ́ ìyá Jèhórámù ọba tó ń ṣàkóso, sì ń nípa búburú lórí orílẹ̀-èdè náà. Dípò kó jà fún ìjọsìn Jèhófà, ńṣe ló gbé ìjọsìn òrìṣà Báálì lárugẹ, ó pa àwọn wòlíì Ọlọ́run, ó sì fi “ìwà àgbèrè” àti “iṣẹ́ àjẹ́” rẹ̀ sọ àwọn èèyàn náà di apẹ̀yìndà. (2 Ọba 9:22; 1 Ọba 18:4, 13) Jèhófà sọ pé òun yóó pa gbogbo àwọn tó jẹ́ ti Áhábù run, tó fi mọ́ Jèhórámù àti Jésíbẹ́lì. Jéhù ló sì máa ṣáájú àwọn ọmọ ogun tó máa mú ìdájọ́ yìí ṣẹ.
Ìwé Mímọ́ sọ pé nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bá àwọn ọmọ ogun Síríà jà ní Ramoti-gílíádì, Jéhù wà láàárín àwọn olórí ẹgbẹ́ ogun. Oyè tó ga ni Jéhù ní nínú iṣẹ́ ológun, àfàìmọ̀ kó má tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni olórí àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì. Wòlíì Èlíṣà rán ọ̀kan lára ọmọ àwọn wòlíì láti fòróró yan Jéhù gẹ́gẹ́ bí ọba, ó sì tún ní kó fún un ní ìtọ́ni pé kó pa gbogbo àwọn ọkùnrin tó wà nílé Áhábù apẹ̀yìndà.—2 Ọba 8:28; 9:1-10.
Nígbà tí àwọn olórí ẹgbẹ́ ogun yòókù béèrè lọ́wọ́ Jéhù pé torí kí ni ọ̀kan lára ọmọ àwọn wòlíì ṣe wá bá a, kò fẹ́ láti sọ fún wọn. Àmọ́, nígbà tí wọn kò fi í lọ́rùn sílẹ̀, ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn, òun àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí Jèhórámù. (2 Ọba 9:11-14) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun kò fìgbà kan nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀nà tí ọba ń gbà ṣàkóso àti ipa búburú tí Jésíbẹ́lì ń ní lórí àwọn aráàlú, kí wọ́n sì ti máa wá bí wọ́n ṣe máa ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Síbẹ̀ náà, Jéhù ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà tó dára jù lọ tó lè gbà ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́.
Jèhórámù Ọba ti fara gbọgbẹ́ lójú ogun ó sì ti sá gba ìlú Jésíréélì lọ kó lè tọ́jú ara rẹ̀ níbẹ̀. Jéhù mọ̀ pé bí òun bá máa ṣàṣeyọrí, àwọn tó wà ní Jésíréélì kò gbọ́dọ̀ gbọ́ ohun tóun fẹ́ ṣe. Ó sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá lọ láti inú ìlú ńlá láti lọ ròyìn ní Jésíréélì.” (2 Ọba 9:14, 15) Ó ṣeé ṣe kó ti ronú pé ó kéré tán àwọn ọmọ ogun tó nífẹ̀ẹ́ Jèhórámù máa fẹ́ ṣe nǹkan kan láti gbèjà rẹ̀. Jéhù kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbèjà ọba náà.
Ó FI ẸṢIN SÁRÉ ÀSÁPAJÚDÉ!
Kí Jéhù lè yọ sí wọn lójijì, ó fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ rin ìrìn àjò kìlómítà méjìléláàádọ́rin [72] láti Ramoti-gílíádì sí Jésíréélì. Bó ti kù díẹ̀ kó sáré dé ibi tó ń lọ, olùṣọ́ kan tó dúró sórí ilé gogoro rí “ìrọ́sókèsódò àgbájọ ènìyàn Jéhù.” (2 Ọba 9:17) Ó ti ní láti jẹ́ pé Jéhù lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an kó lè rí i dájú pé òun ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun láṣeyọrí.
Bí olùṣọ́ náà ṣe rí i pé Jéhù tó jẹ́ onígboyà wà nínú ọ̀kan lára àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà, ó fohùn rara sọ pé: “Àsápajúdé eré ni ó ń sá.” (2 Ọba 9:20) Bó bá jẹ́ pé Jéhù sábà máa ń sáré bó bá ń gẹṣin, lọ́tẹ̀ yìí ohun tó fẹ́ ṣe ti ní láti mú kó sá eré àsápajúdé lóòótọ́.
Lẹ́yìn tí Jéhù ti kọ̀ láti dá àwọn ońṣẹ́ méjì tí ọba rán sí i lóhùn, ó pàdé Jèhórámù Ọba àti Ahasáyà Ọba Júdà tó jẹ́ onígbèjà rẹ̀, wọ́n wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn. Nígbà tí Jèhórámù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé àlàáfíà ni, Jéhù?” Jéhù dá a lóhùn pé: “Àlàáfíà báwo, níwọ̀n ìgbà tí ìwà àgbèrè Jésíbẹ́lì ìyá rẹ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ̀ bá ń bẹ?” Kí ni Jèhórámù gbọ́ bẹ́ẹ̀ sí, ńṣe ló yí pa dà kó lè sá lọ. Àmọ́ Jéhù yára jù ú lọ! Ó gbá ọrun rẹ̀ mú, ó sì ta ọfà lu Jèhórámù ní ọkàn-àyà, Jèhórámù ṣubú sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ ó sì kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ahasáyà sá lọ, nígbà tó yá Jéhù wá a kàn ó sì pa òun náà.—2 Ọba 9:22-24, 27.
Ẹni tó kàn ní ilé Áhábù tí ikú tọ́ sí báyìí ni Jésíbẹ́lì Ayaba búburú. Ó bá a mu wẹ́kú bí Jéhù ṣe pè é ní “ẹni ègún yìí.” Nígbà tí Jéhù gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọ ìlú Jésíréélì, ó rí i tí Jésíbẹ́lì ń bojú wolẹ̀ láti ojú fèrèsé tó wà ní ààfin. Láì fọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, Jéhù pàṣẹ fáwọn òṣìṣẹ́ ààfin pé kí wọ́n ju Jésíbẹ́lì sí ìsàlẹ̀ látojú fèrèsé. Jéhù wá fi ẹṣin tẹ obìnrin tó sọ gbogbo Ísírẹ́lì di apẹ̀yìndà náà mọ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn tí Jéhù pa ní ilé Áhábù ọba burúkú náà pọ̀ gan-an.—2 Ọba 9:30-34; 10:1-14.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tá a bá ronú nípa ìwà ipá ó lè rí wa lára, ó yẹ kó yé wa pé nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Jèhófà máa ń lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìṣubú Ahasáyà ti ṣẹlẹ̀ nípa wíwá tí ó wá sọ́dọ̀ Jèhórámù; nígbà tí ó sì dé, ó bá Jèhórámù jáde lọ sọ́dọ̀ Jéhù ọmọ-ọmọ Nímúṣì, ẹni tí Jèhófà ti fòróró yàn láti ké ilé Áhábù kúrò.” (2 Kíró. 22:7) Nígbà tí Jéhù ju òkú Jèhórámù kúrò nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó ṣe kedere sí i pé ohun tóun ṣe yìí mú ìlérí Jèhófà ṣẹ pé Òun máa fìyà jẹ Áhábù torí pé ó pa Nábótì. Àti pé, Jèhófà ti pàṣẹ fún Jéhù pé kó “gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ [Ọlọ́run]” tí Jésíbẹ́lì pa.—2 Ọba 9:7, 25, 26; 1 Ọba 21:17-19.
Lóde òní, kò sí ìránṣẹ́ Jèhófà kankan tó máa ń wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn tó bá ń ta ko ìjọsìn mímọ́. Ọlọ́run sọ pé: “Tèmi ni ẹ̀san.” (Héb. 10:30) Àmọ́, kí àwọn alàgbà ìjọ bàa lè mú gbogbo ohun tó bá lè kó èèràn ran ìjọ kúrò, ó máa ń pọn dandan nígbà míì pé kí wọ́n lo ìgboyà bíi ti Jéhù. (1 Kọ́r. 5:9-13) Gbogbo àwọn ará nínú ìjọ sì gbọ́dọ̀ pinnu láti má ṣe bá àwọn tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ ṣe wọlé wọ̀de.—2 Jòh. 9-11.
JÉHÙ KÒ FÀYÈ GBA BÍBÁ JÈHÓFÀ DÍJE
Ọ̀rọ̀ tí Jéhù sọ fún Jèhónádábù olóòótọ́ lẹ́yìn náà jẹ́ kí ohun tó mú kó ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé e lọ́wọ́ ṣe kedere. Ó sọ fún un pé: “Bá mi ká lọ, kí o sì wo bí èmi kò ṣe fàyè gba bíbá Jèhófà díje.” Jèhónádábù gbà láti bá Jéhù lọ, ó wọlé sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin Jéhù, ó sì bá a lọ sí Samáríà. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Jéhù “lo ọgbọ́n wẹ́wẹ́, fún ète àtipa àwọn olùjọsìn Báálì run.”—2 Ọba 10:15-17, 19.
Jéhù kéde pé òun fẹ́ “rú ẹbọ ńlá” sí Báálì. (2 Ọba 10:18, 19) Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Ọgbọ́n ìfọ̀rọ̀dárà ni Jéhù lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbólóhùn tó lò yìí “sábà máa ń túmọ̀ sí ‘ìrúbọ,’ òun náà ni wọ́n ń lò fún ‘dídúńbú’ àwọn apẹ̀yìndà.” Torí pé Jéhù fẹ́ kí gbogbo olùjọsìn Báálì wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó ní kí gbogbo wọn péjọ sí ilé Báálì kí wọ́n sì wọ aṣọ tó máa fi wọ́n hàn yàtọ̀. Bíbélì sọ pé: “Gbàrà tí [Jéhù] parí rírú ọrẹ ẹbọ sísun náà,” ó ní kí àwọn ọgọ́rin [80] ọkùnrin tó dìhámọ́ra ogun dúńbú àwọn olùfọkànsìn Báálì. Lẹ́yìn náà ni Jéhù ní kí wọ́n wó ilé Báálì, kí wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilé ìgbọ̀nsẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ibi tí kò yẹ fún ìjọsìn.—2 Ọba 10:20-27.
Òótọ́ ni pé Jéhù ta ẹ̀jẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn sílẹ̀. Síbẹ̀, ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ó jẹ́ onígboyà, òun ló sì gba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lọ́wọ́ Jésíbẹ́lì àti ìdílé rẹ̀ tí wọ́n jẹ gàba lé àwọn èèyàn lórí tí wọ́n sì fa ìnira fún wọn. Kí aṣáájú èyíkéyìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó lè ṣe ohun tí Jéhù ṣe yìí láṣeyọrí, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà, kó múra tán láti gbé ìgbésẹ̀, kó sì ní ìtara. Ìwé atúmọ̀ èdè kan tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé: “Iṣẹ́ yẹn kò rọrùn rárá, kò sì jáwọ́ nínú rẹ̀ títí tó fi ṣe é tán. Ká sọ pé kò fọwọ́ tó le tóyẹn mú iṣẹ́ yẹn ni ì bá má lè mú ẹ̀sìn Báálì kúrò ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.”
Kò sí àní-àní pé ìwọ náà máa rí i pé ipò tí àwọn Kristẹni ń dojú kọ lónìí gba pé kí wọ́n lo irú àwọn ànímọ́ kan tí Jéhù fi hàn. Bí àpẹẹrẹ, kí ló yẹ ká ṣe bí a bá dojú kọ ìdẹwò láti lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tí Jèhófà sọ pé kò dára? Ó yẹ ká gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀, ká jẹ́ onígboyà ká sì ṣe gbogbo ohun tó bá wà lágbára wa ká má bàa fàyè gba ìdẹwò náà. Ní ti ìfọkànsìn Ọlọ́run, a kò jẹ́ fàyè gba bíbá Jèhófà díje lọ́nà èyíkéyìí.
Ẹ JẸ́ KÍ ÒFIN JÈHÓFÀ MÁA DARÍ YÍN
Ibi tí kò dára ni ìtàn yìí parí sí, èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa. Jéhù ‘kò yà kúrò nínú títọ àwọn ọmọ màlúù wúrà tó wà ní Bẹ́tẹ́lì àti ní Dánì lẹ́yìn.’ (2 Ọba 10:29) Báwo ni ẹni tó jọ pé ó ní ìtara fún ìjọsìn mímọ́ ṣe lè máa lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà?
Ó ṣeé ṣe kí Jéhù ti rò pé níwọ̀n bí ìjọba Ísírẹ́lì kò ti sí lára ìjọba Júdà mọ́ a jẹ́ pé ìjọsìn àwọn ìjọba méjèèjì máa yàtọ̀ síra nìyẹn. Torí náà, bíi ti àwọn ọba tó ti jẹ sẹ́yìn ní Ísírẹ́lì, ó gbìyànjú láti mú kí àwọn ìjọba náà wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nípa mímú kí ìjọsìn ère ọmọ màlúù máa bá a nìṣó. Àmọ́, èyí fi hàn pé kò ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà tó yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba.
Jèhófà gbóríyìn fún Jéhù torí pé ‘ó ṣe dáadáa ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Ọlọ́run.’ Àmọ́ ṣá o, Jéhù “kò . . . kíyè sára láti fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ rìn nínú òfin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” (2 Ọba 10:30, 31) Bó o bá ronú lórí gbogbo ohun tí Jéhù ti ṣe tẹ́lẹ̀, ohun tó ṣe lọ́tẹ̀ yìí lè yà ẹ́ lẹ́nu kó sì bà ẹ́ nínú jẹ́. Síbẹ̀, a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ níbẹ̀. A kò gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. A gbọ́dọ̀ máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run lójoojúmọ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká máa ṣe àṣàrò lé e lórí, ká sì máa gbàdúrà látọkànwá sí Baba wa ọ̀run. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa kíyè sára ní gbogbo ọ̀nà ká lè máa bá a nìṣó láti fi gbogbo ọkàn-àyà wa rìn nínú òfin Jèhófà.—1 Kọ́r. 10:12.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Ìtàn Mẹ́nu Kan Jéhù
Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ sábà máa ń ṣiyè méjì pé bóyá làwọn èèyàn tí Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ wọn gbé láyé rí. Torí náà, yàtọ̀ sí ohun tí Bíbélì sọ nípa Jéhù, ǹjẹ́ a rí ẹ̀rí míì tó fi hàn pé Jéhù gbé láyé rí?
Ó kéré tán, àkọsílẹ̀ mẹ́ta tó wá láti ilẹ̀ Ásíríà àtijọ́ mẹ́nu kan orúkọ ọba Ísírẹ́lì yìí. Ọ̀kan lára wọn fi hàn pé Jéhù, tàbí ọ̀kan lára àwọn aṣojú rẹ̀ ń tẹrí ba níwájú Ṣálímánésà Kẹta, Ọba Ásíríà, ó sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un. Ohun tó wà lára ọ̀kan lára àkọsílẹ̀ náà kà pé: “Ìṣákọ́lẹ̀ tí Jéhù (Ia-ú-a), ọmọkùnrin Ómírì (Hu-um-ri) gbé wá; mo gba fàdákà lọ́wọ́ rẹ̀, mo gba wúrà, àwokòtò saplu oníwúrà, orù òdòdó oníwúrà tó ní ìdí gígùn, àwọn ife oníwúrà, àwọn korobá oníwúrà, agolo, ọ̀pá àṣẹ ti ọba, (àti) àwọn ohun èlò puruhtu tí wọ́n fi igi ṣe.” Jéhù kì í ṣe “ọmọ Ómírì,” àmọ́ wọ́n máa ń pe àwọn ọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó jẹ lẹ́yìn Ómírì ní ọmọ Ómírì bóyá torí pé ó gbajúmọ̀ àti pé òun ló kọ́ Samáríà, tó jẹ́ olú ìlú Ísírẹ́lì.
Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ ni Jéhù san ìṣákọ́lẹ̀ tí ọba Ásíríà sọ pé ó san fún òun. Síbẹ̀, ìgbà mẹ́ta ló mẹ́nu kan Jéhù, ìyẹn nínú àkọsílẹ̀ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè yìí, lára ère Ṣálímánésà àti nínú àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn ọba Ásíríà. Kò sí iyè méjì pé àwọn àkọsílẹ̀ yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni Jéhù tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gbáyé rí.