-
Wòlíì Ayé Àtijọ́ Tó Jíṣẹ́ Tó Bóde Òní MuÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
7. Ṣàpèjúwe bí ipò àwọn nǹkan ṣe rí ní Júdà lọ́jọ́ Aísáyà.
7 Ayé ìgbà Aísáyà àti ìdílé rẹ̀ jẹ́ àkókò tí rúkèrúdò gbòde kan ní Júdà. Rògbòdìyàn òṣèlú gbilẹ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbígbà ti ba àwọn ilé ẹjọ́ jẹ́, àgàbàgebè ti sọ ẹ̀sìn dìdàkudà láwùjọ. Orí àwọn òkè kún fọ́fọ́ fún pẹpẹ àwọn ọlọ́run èké. Kódà òmíràn nínú àwọn ọba ń gbé ìbọ̀rìṣà lárugẹ. Bí àpẹẹrẹ, yàtọ̀ sí pé Áhásì fàyè gba ìbọ̀rìṣà láàárín àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀, òun gan-an tún ń bọ̀rìṣà, ó ń mú ọmọ tirẹ̀ alára “la iná kọjá” nígbà ààtò ẹbọ rírú sí Mólékì ọlọ́run àwọn ará Kénáánì.b (2 Àwọn Ọba 16:3, 4; 2 Kíróníkà 28:3, 4) Áà, kí gbogbo èyí sì máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tí wọ́n ti bá Jèhófà dá májẹ̀mú!—Ẹ́kísódù 19:5-8.
-
-
Wòlíì Ayé Àtijọ́ Tó Jíṣẹ́ Tó Bóde Òní MuÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
b Àwọn kan sọ pé ‘líla iná kọjá’ lè túmọ̀ sí ṣíṣe ààtò ìwẹ̀nùmọ́. Àmọ́, ó jọ pé rírúbọ ní ti gidi ni gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí. Kò sí àní-àní ní ti pé àwọn ará Kénáánì àti Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà máa ń fọmọ rúbọ.—Diutarónómì 12:31; Sáàmù 106:37, 38.
-