“Kọ́ Mi Láti Máa Ṣe Ìfẹ́ Rẹ”
“Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run mi.”—SM. 143:10.
1, 2. Báwo la ṣe lè jàǹfààní tá a bá ń ronú lórí ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan? Kí la lè rí kọ́ lára Dáfídì Ọba?
Ọ̀NÀ wo lo rò pé ó dára jù lọ tó o lè gbà ṣe ìpinnu pàtàkì kan? Ohun tí ì bá dára jù lọ ni pé kó o béèrè ohun tí kò yé ẹ lọ́wọ́ ẹnì kan tó mọ̀ jù ẹ́ lọ, kó o lè túbọ̀ lóye àwọn ohun tó wé mọ́ ìpinnu tó o fẹ́ ṣe. Jèhófà ló mọ̀ ju gbogbo wa lọ. Torí náà, tá a bá ń ronú lórí ojú tó fi ń wo nǹkan ká tó ṣe ìpinnu, ó dájú pé ìpinnu tó dáa la máa ṣe. Irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ á sì jẹ́ ká lè máa ‘rìn ní ọ̀nà’ Jèhófà.—Aísá. 30:21.
2 Dáfídì Ọba sábà máa ń ronú lórí ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan kó tó ṣe ìpinnu. Àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn sì jẹ́ fún wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú bí Dáfídì ṣe fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run àti ohun tó ṣe nígbà tó wà nínú ìṣòrò.—1 Ọba 11:4.
DÁFÍDÌ BỌ̀WỌ̀ FÚN ORÚKỌ JÈHÓFÀ GAN-AN
3, 4. (a) Kí nìdí tí ẹ̀rù kò fi ba Dáfídì láti bá Gòláyátì jà? (b) Ọwọ́ wo ni Dáfídì fi mú orúkọ Ọlọ́run?
3 Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dáfídì bá Gòláyátì tó jẹ́ akọgun Filísínì jà. Òmìrán ni Gòláyátì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó mítà mẹ́ta, ìyẹn nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́sàn-án àtààbọ̀, ó sì dira ogun. Kí nìdí tí ẹ̀rù kò fi ba Dáfídì láti bá a jà? (1 Sám. 17:4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Ṣé torí pé ó ní ìgboyà ni àbí torí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run? Òótọ́ ni pé ìgboyà àti ìgbàgbọ́ wà lára ohun tó mú kí Dáfídì hùwà akin. Àmọ́, ìdí pàtàkì tí Dáfídì fi bá Gòláyátì jà ni pé ó ní ọ̀wọ̀ fún Jèhófà àti orúkọ ńlá rẹ̀, kò sì dùn mọ́ ọn nínú pé Gòláyátì yájú sí àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ta ni Filísínì aláìdádọ̀dọ́ yìí jẹ́ tí yóò fi máa ṣáátá àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè?”—1 Sám. 17:26.
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́kùnrin ni Dáfídì, ó fìgboyà sọ fún Gòláyátì pé: “Ìwọ ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ ti ṣáátá.” (1 Sám. 17:45) Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tòótọ́ ó sì gbà pé ó lè ran òun lọ́wọ́. Òkúta kan ṣoṣo péré ló fi mú Filísínì náà balẹ̀. Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ó sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Kódà, ó rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa ‘ṣògo nínú orúkọ mímọ́ Jèhófà.’—Ka 1 Kíróníkà 16:8-10.
5. Bíi ti Gòláyátì, báwo làwọn èèyàn ṣe ń ṣáátá orúkọ Ọlọ́run lónìí?
5 Ṣé inú rẹ máa ń dùn pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ? (Jer. 9:24) Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ bí àwọn aládùúgbò rẹ, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọléèwé rẹ, tàbí àwọn ìbátan rẹ bá sọ ohun tí kò dára nípa Jèhófà tí wọ́n sì ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́? Ṣé o kì í dákẹ́ táwọn èèyàn bá ń ṣáátá orúkọ Jèhófà, ṣé ó sì dá ẹ lójú pé ó máa tì ẹ́ lẹ́yìn? Òótọ́ ni pé, “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” wà, àmọ́ ojú kò gbọ́dọ̀ tì wá torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọmọlẹ́yìn Jésù. (Oníw. 3:1, 7; Máàkù 8:38) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ ká máa fi ọgbọ́n hùwà ká sì máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ nígbà tá a bá ń bá wọn sọ̀rọ̀, ẹ má ṣe jẹ́ ká dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí “àyà wọ́n já” tí “wọ́n sì fòyà gidigidi” nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣáátá Gòláyátì. (1 Sám. 17:11) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká jẹ́ onígboyà ká bàa lè ya orúkọ Jèhófà Ọlọ́run sí mímọ́. Ńṣe la fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ irú Ọlọ́run tí Jèhófà jẹ́. Ìdí nìyẹn tá a fi ń lo Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run.—Ják. 4:8.
6. Kí ni ohun tó wáyé láàárín Dáfídì àti Gòláyátì fi hàn nípa Dáfídì? Kí ló yẹ kó jẹ wá lógún?
6 Ẹ̀kọ́ pàtàkì mìíràn wà tá a tún lè rí kọ́ nínú ohun tó wáyé láàárín Dáfídì àti Gòláyátì. Nígbà tí Dáfídì ń sáré lọ síbi ìjà ogun, ó béèrè pé: “Kí ni ohun tí a ó ṣe fún ọkùnrin náà tí ó bá ṣá Filísínì náà tí ó wà níbẹ̀ yẹn balẹ̀, tí ó sì yí ẹ̀gàn kúrò lórí Ísírẹ́lì ní ti tòótọ́?” Àwọn èèyàn náà sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà gẹ́gẹ́ bí ti ìṣáájú fún un, pé: “Ọkùnrin tí ó bá ṣá [Gòláyátì] balẹ̀, ọba yóò fi ọrọ̀ ńláǹlà sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀, yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún un.” (1 Sám. 17:25-27) Àmọ́, èrè nípa tara kọ́ ló jẹ Dáfídì lógún. Ohun tó ju ìyẹn lọ ló gbà á lọ́kàn. Ohun náà sì ni pé ó fẹ́ láti fi ògo fún Ọlọ́run tòótọ́. (Ka 1 Sámúẹ́lì 17:46, 47.) Àwa náà ńkọ́? Ṣé bá a ṣe máa ṣe orúkọ fún ara wa nípa kíkó ọrọ̀ jọ ká sì di olókìkí nínú ayé ló jẹ wá lógún? Ó dájú pé a máa fẹ́ láti dà bíi Dáfídì tó sọ pé: “Ẹ gbé Jèhófà ga lọ́lá pẹ̀lú mi, ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga.” (Sm. 34:3) Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ká sì jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ jẹ wá lógún ju orúkọ tiwa lọ.—Mát. 6:9.
7. Báwo la ṣe lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára táá mú ká lè wàásù fáwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́?
7 Ìgbàgbọ́ tí Dáfídì ní pé Jèhófà kò ní já òun kulẹ̀ láé ló mú kó fìgboyà kojú Gòláyátì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni Dáfídì, ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára. Ohun kan tó sì mú kó ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ni pé iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn mú kó gbára lé Ọlọ́run. (1 Sám. 17:34-37) Ìgbàgbọ́ tiwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ lágbára ká lè máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nìṣó, pàápàá jù lọ tá a bá bá àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ pàdé. A lè ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ tá a bá ń gbára lé Ọlọ́run nínú gbogbo nǹkan tá a bá ń ṣe lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, a lè wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn tó bá jókòó tì wá nínú ọkọ̀ èrò. Ó sì yẹ ká máa wàásù fáwọn èèyàn tá a bá bá pàdé ní òpópónà nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé.—Ìṣe 20:20, 21.
DÁFÍDÌ FỌKÀN TÁN JÈHÓFÀ
8, 9. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń lépa Dáfídì, báwo ni Dáfídì ṣe fi hàn pé ohun tó wu Jèhófà lòun fẹ́ ṣe?
8 Ohun tó wáyé láàárín Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọba àkọ́kọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì tún jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ ni Dáfídì fẹ́ láti fọkàn tán Jèhófà. Torí pé Sọ́ọ̀lù ń jowú Dáfídì, ìgbà mẹ́ta ló gbìyànjú láti fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́ ògiri, àmọ́ Dáfídì yẹ̀ ẹ́ ní ìgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, kò sì gbẹ̀san. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó sá fún Sọ́ọ̀lù. (1 Sám. 18:7-11; 19:10) Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù mú ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] àṣàyàn ọkùnrin nínú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Dáfídì nínú aginjù. (1 Sám. 24:2) Lọ́jọ́ kan, Sọ́ọ̀lù lọ sínú ihò àpáta tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sá pa mọ́ sí láìmọ̀ pé ibẹ̀ ni wọ́n wà. Níwọ̀n bí Dáfídì ti mọ̀ pé òun ni Ọlọ́run fẹ́ fi rọ́pò Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba, ì bá ti rò pé àǹfààní nìyẹn jẹ́ fún òun láti pa Sọ́ọ̀lù tó ti ń lépa ẹ̀mí rẹ̀. (1 Sám. 16:1, 13) Ká tiẹ̀ sọ pé Dáfídì gbọ́ ohun táwọn ọmọ ogun rẹ̀ sọ fún un ni, ì bá ti pa Sọ́ọ̀lù. Àmọ́, Dáfídì sọ pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, láti ojú ìwòye Jèhófà, pé kí n ṣe ohun yìí sí olúwa mi, ẹni àmì òróró Jèhófà.” (Ka 1 Sámúẹ́lì 24:4-7.) Ọba tí Ọlọ́run fòróró yàn ni Sọ́ọ̀lù, Ọlọ́run ò sì tíì mú un kúrò nípò. Torí náà, Dáfídì ò fẹ́ láti gba ipò mọ́ ọn lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Dáfídì yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ gé etí aṣọ àwọ̀lékè Sọ́ọ̀lù. Ìyẹn sì fi hàn pé kò ní in lọ́kàn láti pa á.—1 Sám. 24:11.
9 Kódà, nígbà tí Dáfídì rí Sọ́ọ̀lù kẹ́yìn, ó ṣì bọ̀wọ̀ fún un torí pé ẹni àmì òróró Ọlọ́run ni. Nígbà yẹn, Dáfídì àti Ábíṣáì dé ibì kan tí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ sí, wọ́n sì bá a tí ó ń sùn. Ábíṣáì gbà pé Ọlọ́run ti fi ọ̀tá Dáfídì lé e lọ́wọ́, ó sì ní kó jẹ́ kí òun fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, Dáfídì ò gbà fún un. (1 Sám. 26:8-11) Torí pé Dáfídì ń bá a nìṣó láti máa wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, kò fẹ́ pa ọba tí Jèhófà fòróró yàn bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábíṣáì rọ̀ ọ́ pé kó pa á.
10. Ìṣòro wo ni a lè dojú kọ? Kí ló máa mú ká jẹ́ adúróṣinṣin?
10 Àwa náà lè dojú kọ ìṣòro. Àwọn ẹlẹgbẹ́ wa lè gbìyànjú láti mú ká ṣe ohun tí wọ́n rò pé ó tọ́ dípò kí wọ́n kọ́wọ́ tì wá láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Bíi ti Ábíṣáì, àwọn kan tiẹ̀ lè sọ pé ká ṣe àwọn nǹkan kan láì kọ́kọ́ ronú lórí ohun tí Ọlọ́run máa fẹ́ ká ṣe. Ká bàa lè jẹ́ adúróṣinṣin, a gbọ́dọ̀ máa ronú lórí ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, ká sì pinnu láti ṣe ohun tó bá fẹ́ ká ṣe.
11. Kí lo rí kọ́ lára Dáfídì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fi ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́?
11 Dáfídì gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run pé kó kọ́ òun láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ. (Ka Sáàmù 143:5, 8, 10.) Dípò tí Dáfídì á fi máa gbẹ́kẹ̀ lé èrò tara rẹ̀ tàbí kó máa ṣe ohun tí ẹlòmíràn bá sọ pé kó ṣe, ó máa ń hára gàgà láti gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó máa ń ‘ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò Jèhófà, tinútinú ló sì fi fẹ́ láti máa fi àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run ṣe ìdàníyàn rẹ̀.’ Àwa pẹ̀lú lè fi òye mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fara balẹ̀ ka Ìwé Mímọ́, tá a sì ń ṣe àṣàrò lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Jèhófà ṣe tọ́ àwọn èèyàn sọ́nà nígbà àtijọ́.
DÁFÍDÌ MÁA Ń TẸ̀ LÉ ÀWỌN ÌLÀNÀ TÓ WÀ NÍNÚ ÒFIN ỌLỌ́RUN
12, 13. Kí nìdí tí Dáfídì fi da omi tí mẹ́ta lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bù wá fún un sórí ilẹ̀?
12Dáfídì tún jẹ́ àwòkọ́ṣe fún wa torí pé ó máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú òfin Ọlọ́run, orí àwọn ìlànà náà ló sì máa ń gbé ohun tó bá fẹ́ ṣe kà. Ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dáfídì sọ pé òun fẹ́ mu “omi láti inú ìkùdu Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Filísínì ti wà nínú ìlú, mẹ́ta lára àwọn ọmọ ogun Dáfídì forí la ikú lọ sáàárín ìlú náà, wọ́n sì fa omi wá fún un. Àmọ́, “Dáfídì kò . . . gbà láti mu ún, ṣùgbọ́n ó dà á jáde fún Jèhófà.” Kí nìdí? Dáfídì ṣàlàyé pé: “Kò ṣeé ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ti Ọlọ́run mi, láti ṣe èyí! Ṣé ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni kí n mu ní fífi ọkàn wọn wewu? Nítorí ní fífi ọkàn wọn wewu ni wọ́n fi gbé e wá.”—1 Kíró. 11:15-19.
13 Dáfídì mọ̀ pé Òfin sọ pé kéèyàn má jẹ ẹ̀jẹ̀, àmọ́ kó “dà á jáde fún Jèhófà.” Ó tún mọ ìdí tí òfin Ọlọ́run fi sọ pé kéèyàn má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀. Ó mọ̀ pé “ọkàn ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀.” Àmọ́, omi ni wọ́n lọ bù wá fún Dáfídì, kì í ṣe ẹ̀jẹ̀. Kí wá nìdí tó fi kọ̀ láti mu ún? Ìdí ni pé ó lóye ìlànà tó wà nínú òfin Ọlọ́run tó sọ pé kéèyàn má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀. Dáfídì ronú pé tí òun bá mu omi náà, ńṣe ló máa fi hàn pé ẹ̀mí àwọn ọmọ ogun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà kò jọ òun lójú. Torí náà, dípò tí ì bá fi mu ún, ńṣe ló dà á sórí ilẹ̀.—Léf. 17:11; Diu. 12:23, 24.
14. Kí ló mú kí Dáfídì máa ṣe àwọn ìpinnu tí inú Jèhófà dùn sí?
14 Dáfídì ka òfin Ọlọ́run sí pàtàkì gan-an nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó sọ nínú orin tó kọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” (Sm. 40:8) Dáfídì kẹ́kọ̀ọ́ òfin Ọlọ́run, ó sì fi tọkàntọkàn ṣe àṣàrò lé e lórí. Ó mọ̀ pé ó bọ́gbọ́n mu láti máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ Jèhófà. Nítorí èyí, kì í wulẹ̀ ṣe Òfin Mósè nìkan ló wu Dáfídì láti pa mọ́, àmọ́ ó tún máa ń ronú lórí ohun tó rọ̀ mọ́ òfin náà. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó bọ́gbọ́n mu pé ká máa ṣe àṣàrò lórí ohun tí a bá kà, ká sì jẹ́ kó máa wà lọ́kàn wa lójoojúmọ́. Èyí á jẹ́ ká lè máa ṣe ìpinnu tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn.
15. Àwọn ọ̀nà wo ni Sólómọ́nì gbà ṣàìgbọràn sí Òfin Ọlọ́run?
15 Jèhófà Ọlọ́run ṣojú rere sí Sólómọ́nì, ọmọ Dáfídì gan-an ni. Àmọ́, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, Sólómọ́nì kò ka Òfin Ọlọ́run sí pàtàkì mọ́. Ó ṣàìgbọràn sí àṣẹ Jèhófà tó sọ pé ọba Ísírẹ́lì kankan kò gbọ́dọ̀ “sọ aya di púpọ̀ fún ara rẹ̀.” (Diu. 17:17) Kódà, Sólómọ́nì fẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin àjèjì. Nígbà tó darúgbó, “àwọn aya rẹ̀ alára ti tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.” Ohun yòówù kí Sólómọ́nì sọ pé ó fà á tóun fi ṣàìgbọràn sí òfin Ọlọ́run, Bíbélì sọ pé: “[Ó] sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, kò sì tọ Jèhófà lẹ́yìn ní kíkún gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ̀.” (1 Ọba 11:1-6) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà pé ká máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Bí àpẹẹrẹ, èyí ṣe pàtàkì tá a bá ń gbèrò láti ṣègbéyàwó.
16. Kí ni àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó lè rí kọ́ nínú àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé ká ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa”?
16 Bí àwọn tí kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà bá sọ pé àwọn fẹ́ ká jọ máa fẹ́ra, ṣé Dáfídì la máa fìwà jọ ni àbí Sólómọ́nì? Bíbélì sọ pé kí àwọn olùjọsìn tòótọ́ ṣe ìgbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́r. 7:39) Bí Kristẹni kan bá yàn láti ṣe ìgbéyàwó, ẹni tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà ló gbọ́dọ̀ fẹ́. Tá a bá sì fòye mọ ohun tí àṣẹ Ọlọ́run yìí túmọ̀ sí, a kò ní fẹ́ ẹni tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà. A ò sì ní máa ṣe ohun tó fi hàn pé ojú tiwa gan-an ò kúrò lára irú ẹni bẹ́ẹ̀.
17. Kí ni kò ní jẹ́ ká kó sínú ìdẹkùn wíwo àwòrán tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe?
17 Dáfídì fi tọkàntọkàn wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká jíròrò bí àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa kó sínú ìdẹkùn wíwo àwọn àwòrán tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kó o sì ronú lórí ìlànà inú wọn. Kó o wá gbìyànjú láti fòye mọ̀ bóyá inú Jèhófà dùn sí irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀ tàbí inú rẹ̀ kò dùn sí i. (Ka Sáàmù 119:37; Mátíù 5:28, 29; Kólósè 3:5.) Tí a kò bá fẹ́ kó sínú ìdẹkùn wíwo àwòrán tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe, a gbọ́dọ̀ máa ronú lórí àwọn ìlànà Ọlọ́run.
MÁA RONÚ LÓRÍ OJÚ TÍ ỌLỌ́RUN FI Ń WO NǸKANS
18, 19. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni Dáfídì, kí ló mú kó máa rí ojú rere Ọlọ́run? (b) Kí ni wàá máa ṣe báyìí?
18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ ní onírúurú ọ̀nà, síbẹ̀ ó dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. (2 Sám. 11:2-4, 14, 15, 22-27; 1 Kíró. 21:1, 7) Àmọ́, ní gbogbo àkókò tí Dáfídì fi gbé láyé, ó máa ń ronú pìwà dà tó bá dẹ́ṣẹ̀. Ó sin Ọlọ́run “pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn-àyà.” (1 Ọba 9:4) Kí nìdí tá a fi lè sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Dáfídì gbìyànjú láti ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu.
19 Bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, a ṣì lè máa rí ojú rere Jèhófà. Látàrí èyí, ẹ jẹ́ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run taápọntaápọn. Ká máa ṣe àṣàrò tó jinlẹ̀ lórí ohun tá a bá kọ́ nínú rẹ̀ ká sì tètè máa fi ṣèwà hù. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àwa náà á dà bí onísáàmù tó fìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà pé: “Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ.”