Àwọn Wàláà Ayé Àtijọ́ àti Bíbélì
LẸ́YÌN tí Ọlọ́run da èdè aráyé rú nílùú Bábélì, oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbà kọ̀wé. Wàláà làwọn tó ń gbé lágbègbè Mesopotámíà, irú bí àwọn ará Súmà àtàwọn ará Bábílónì, máa fi ń kọ̀wé. Òkúta tàbí amọ̀ tútù tí wọ́n fi nǹkan tó lẹ́nu ṣóńṣó gbẹ́ ọ̀rọ̀ sí lára là ń pè ní wàláà, ó sì lè jẹ́ pákó tí wọ́n fi yíǹkì kọ̀rọ̀ sí lára.
Àwọn awalẹ̀pìtàn ti hú àwọn wàláà kan, tó ṣàlàyé nípa àwọn èèyàn àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa wọn, jáde nínú ilẹ̀. Kí la mọ̀ nípa ọ̀nà tí wọ́n ń gba kọ̀wé sórí wàláà láyé àtijọ́? Báwo sì làwọn ọ̀rọ̀ tó wà lára àwọn wàláà wọ̀nyẹn ṣe jẹ́rìí sí i pé Bíbélì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé?
Àwọn Àkọsílẹ̀ Tó Ti Wà Tipẹ́
Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé nígbà kan àwòrán làwọn èèyàn fi máa ń ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ lágbègbè Mesopotámíà, wọ́n ní àwọn àmì tàbí àwòrán tí wọ́n gbà pé ó dúró fún àwọn ọ̀rọ̀ tàbí àwọn èrò kan. Bí àpẹẹrẹ, nígbà yẹn àmì tó jọ orí màlúù ni wọ́n fi máa ń ṣàpèjúwe màlúù. Bí wọ́n ṣe rí i pé ó ti di dandan káwọn bẹ̀rẹ̀ sí í ní àkọsílẹ̀ torí ọjọ́ iwájú, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀wé sórí wàláà. Ìwé NIV Archaeological Study Bible sọ pé: “Ní báyìí tá a ti ń kọ̀wé sórí wàláà, àmì ò kàn ní máa dúró fún àwọn ọ̀rọ̀ nìkan mọ́ àmọ́ á tún máa dúró fáwọn sílébù, a sì lè pa oríṣiríṣi sílébù pọ̀ kó lè dúró fún odindi ọ̀rọ̀ kan.” Nígbà tó yá àwọn àmì tó tó nǹkan bí igba [200] ti jẹ́ kó ṣeé ṣe láti “kọ àwọn ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan bá sọ, títí kan àwọn àkànlò èdè àti gírámà tó bá lò” sórí wàláà.
Nígbà tó fi máa dìgbà ayé Ábúráhámù, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, kíkọ̀wé sórí wàláà ti wá dohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn èdè bíi mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sórí wàláà fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] tó tẹ̀ lé e. Wàláà pẹlẹbẹ tí wọ́n fi amọ̀ ṣe ló pọ̀ jù lọ lára àwọn wàláà táwọn awalẹ̀pìtàn rí. Láti nǹkan bí àádọ́jọ [150] ọdún sẹ́yìn, àìmọye irú àwọn wàláà tí wọ́n fi amọ̀ ṣe yìí ni wọ́n ti rí láwọn ìlú bí Úrì, Yúríkì, Bábílónì, Nímírúdù, Nípúrì, Áṣúrì, Nínéfè, Márì, Ẹ́bílà, Yúgárítì àti Àmánà. Ìwé Archaeology Odyssey sọ pé: “Àwọn ògbóǹkangí fojú bù ú pé nǹkan bíi mílíọ̀nù kan tàbí méjì wàláà tí wọ́n fi amọ̀ ṣe ni wọ́n ti hú jáde, ó sì ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] tí wọ́n ń hú jáde lọ́dọọdún.”
Àwọn ògbógi tó mọ̀ nípa àkọsílẹ̀ orí wàláà tún ní iṣẹ́ ńlá kan láti ṣe, ìyẹn sì ni bí wọ́n ṣe máa túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lórí àwọn wàláà tí wọ́n ń hú jáde. Àwọn kan fojú bù ú pé “lóde òní nǹkan bíi wàláà kan ṣoṣo nínú mẹ́wàá làwọn ògbógi tíì kà lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo rí.”
Báwọn ọ̀mọ̀wé ṣe ṣàwárí àwọn wàláà tí wọ́n fi èdè méjì sí mẹ́ta kọ ọ̀rọ̀ sórí wọn ti jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wọn láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni tó wà lórí àwọn wàláà náà dáadáa. Àwọn ọ̀mọ̀wé fòye gbé e pé ìsọfúnni kan náà ló wà lórí àwọn wàláà náà, èdè wọn ló kàn yàtọ̀. Ohun tó tún ran àwọn tó ń ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ orí wàláà lọ́wọ́ ni bí wọ́n ṣe wá mọ̀ pé kì í ṣe orí wàláà kan ṣoṣo péré ni wọ́n kọ àwọn orúkọ, orúkọ oyè, ìtàn àwọn lọ́balọ́ba, àtàwọn oríkì tí wọ́n rí sí.
Nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 1859, àwọn ọ̀mọ̀wé ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka èdè àjùmọ̀lò tí wọ́n ń sọ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn láyé àtijọ́, ìyẹn àwọn èdè àwọn ará ìlú Ákádì, lórí wàláà. Ìwé Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé: “Bí [àwọn ọ̀mọ̀wé] ti ṣe wá lè ka èdè àwọn ará Ákádì dáadáa báyìí ti jẹ́ kí wọ́n lóye ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń kọ̀wé sórí wàláà, èyí sì wá jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti túmọ̀ àwọn èdè míì tí wọ́n ń rí lórí wàláà.” Báwo làwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n rí lórí àwọn wàláà wọ̀nyí ṣe wá bá ohun tí Bíbélì sọ mu?
Ẹ̀rí Tó Bá Bíbélì Mu
Bíbélì sọ pé àwọn ọba ilẹ̀ Kénáánì ló ń ṣàkóso ìlú Jerúsálẹ́mù títí dìgbà tí Dáfídì fi ṣẹ́gun ìlú náà ní nǹkan bí ọdún 1070 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Jóṣ. 10:1; 2 Sám. 5:4-9) Àmọ́, àwọn ọ̀mọ̀wé kan jiyàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Lọ́dún 1887, obìnrin kan tó jẹ́ àgbẹ̀ rí wàláà pẹlẹbẹ kan tí wọ́n fi amọ̀ ṣe nílùú Àmánà, lórílẹ̀-èdè Íjíbítì. Lẹ́yìn táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàyẹ̀wò àgbègbè yìí dáadáa, wọ́n rí wàláà tó tó okòódínnírínwó [380] níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì máa túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lórí àwọn wàláà náà, wọ́n rí i pé àdéhùn tó wà láàárín àwọn ọba Íjíbítì (ìyẹn Amenhotep Kẹta àti Akhenaton) àtàwọn ìjọba ilẹ̀ Kénáánì ló wà níbẹ̀. Mẹ́fà lára àwọn lẹ́tà tó wà lórí àwọn wàláà náà ló sì jẹ́ ti ‘Abdi-Heba, olùṣàkóso Jerúsálẹ́mù.
Ìwé Biblical Archaeology Review sọ pé: “Àwọn wàláà pẹlẹbẹ tí wọ́n fi amọ̀ ṣe tí wọ́n rí nílùú Àmánà jẹ́rìí sí i pé Jerúsálẹ́mù kì í ṣe abúlé, ìlú ni, ó sì tún jẹ́rìí sí i pé gómìnà ni ‘Abdi-Heba, pé ó . . . ní ilé ìjọba tirẹ̀, ó sì ní àádọ́ta [50] àwọn ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì tí wọ́n pàgọ́ sí ibùdó ológun nílùú Jerúsálẹ́mù, èyí fi hàn pé orílẹ̀-èdè kékeré kan tó wà lórí òkè tó sì ní ìjọba tirẹ̀ ni Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn.” Ìwé kan náà tún sọ pé: “Torí àwọn ẹ̀rí tá a rí nílùú Àmánà, ó dá wa lójú pé ìlú kan tó lórúkọ ju àwọn ìlú tó kù lọ ti wà rí.”
Àwọn Orúkọ Tó Wà Nínú Ìtàn Àwọn Ará Ásíríà àti Bábílónì
Orí àwọn wàláà pẹlẹbẹ tí wọ́n fi amọ̀ ṣe làwọn ará Ásíríà àtàwọn ará Bábílónì máa ń kọ ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí, ìgbà míì wọ́n á kọ ọ́ sorí àwọn nǹkan tí wọ́n gbẹ́ bí agolo, tàbí kí wọ́n kọ ọ́ sórí àwọn òkúta iyebíye tó dà bíi gíláàsì, wọ́n sì tún máa ń kọ ọ́ sára àwọn òkúta ńlá. Torí náà, nígbà táwọn ọ̀mọ̀wé ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tó wà lára wàláà táwọn ará Ákádì kọ, wọ́n rí i pé orúkọ àwọn èèyàn tí Bíbélì dárúkọ wà níbẹ̀.
Ìwé The Bible in the British Museum sọ pé: “Nínú ọ̀rọ̀ tí Ọ̀mọ̀wé Samuel Birch bá Àwùjọ Àwọn Awalẹ̀pìtàn Bíbélì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ sọ lọ́dún 1870, ó dárúkọ àwọn ọba Hébérù [bó ṣe wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n rí lórí wàláà], lára àwọn tó dárúkọ ni ọba Ómírì, Áhábù, Jéhù, Asaráyà . . . , Ménáhémù, Pékà, Hóṣéà, Hesekáyà, Mánásè, ó dárúkọ àwọn ọba Ásíríà, lára wọn ni Tigilati-Pílésà . . . [Kẹta], Ságónì, Senakéríbù Esarihádónì àti Aṣọbánípà, . . . ó sì dárúkọ àwọn ọmọ ìlú Síríà, ìyẹn Bẹnihádádì, Hásáélì àti Résínì.”
Ìwé The Bible and Radiocarbon Dating fàwọn ìtàn Bíbélì tó dá lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà wéra pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lórí àwọn wàláà ìgbàanì. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ìwé náà sọ pé: “Orúkọ àwọn ọba tó jẹ nílẹ̀ Júdà àti Ísírẹ́lì tó wà nínú gbogbo àwọn wàláà tá a rí láwọn orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ sí tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tàbí mẹ́rìndínlógún [16], èyí sì bá ohun tí [ìwé] Àwọn Ọba [nínú Bíbélì] sọ nípa orúkọ àti ìgbà tí wọ́n jọba mu gẹ́lẹ́. Gbogbo orúkọ àwọn ọba tó wà nínú ìwé Àwọn Ọba la rí lórí àwọn wàláà ọ̀hún.”
Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lára wàláà kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa tí wọ́n gbẹ́ bí agolo, ìyẹn Cyrus Cylinder, tí wọ́n rí lọ́dún 1879 jẹ́ ká mọ̀ pé, bí Kírúsì ọba ṣe máa ń ṣe, ó dá àwọn ẹrú sílẹ̀ lómìnira lẹ́yìn tó ṣẹ́gun ìlú Bábílónì lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn Júù sì wà lára àwọn tó jàǹfààní ìtúsílẹ̀ yìí. (Ẹ́sírà 1:1-4) Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún [19] ló sọ pé àwọn ò gbà pé òótọ́ làṣẹ tí Bíbélì sọ pé Kírúsì pa yìí. Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lára àwọn wàláà tó ti wà látìgbà táwọn ará Páṣíà ń ṣàkóso, títí kan wàláà tí wọ́n ń pè ní Cyrus Cylinder, ló jẹ́rìí lọ́nà tó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pé pérépéré.
Lọ́dún 1883, àwọn awalẹ̀pìtàn rí àwọn wàláà tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] lọ níbì kan nílùú Nípúrì nítòsí Bábílónì. Lára àwọn orúkọ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [2,500] tó wà lára àwọn wàláà wọ̀nyẹn, nǹkan bí àádọ́rin [70] ló jẹ́ orúkọ Júù. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Edwin Yamauchi sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orúkọ “àwọn tó ń bára wọn ṣe àdéhùn, àwọn aṣojú, àwọn ẹlẹ́rìí, àwọn agbowó orí àtàwọn òṣìṣẹ́ ọba” ló wà lára àwọn wàláà náà. Ẹ̀rí tó wà pé àwọn Júù ṣì ń ṣe irú àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí lẹ́yìn tí wọ́n kúrò nígbèkùn àwọn ará Bábílónì lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ gan-an. Ẹ̀rí yìí bá àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mu pé àwọn kan ò kúrò ní Ásíríà àti Bábílónì nígbà tí “àṣẹ́kù” àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà sí ilẹ̀ Jùdíà.—Aísá. 10:21, 22.
Ní ẹgbẹ̀rún ọdún àkọ́kọ́ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n máa ń fi ááfábẹ́ẹ̀tì kọ̀wé, wọ́n sì tún máa ń kọ̀wé sórí wàláà. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn ará Ásíríà àti Bábílónì pa kíkọ̀wé sórí wàláà tì, wọ́n sì wá ń fi ááfábẹ́ẹ̀tì kọ̀wé.
Àìmọye àwọn wàláà pẹlẹbẹ tí wọ́n fi amọ̀ ṣe tó wà níbi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí làwọn ọ̀mọ̀wé ò tíì mọ nǹkan kan nípa wọn. Àmọ́ àwọn wàláà táwọn ògbógi ti ṣàyẹ̀wò fún wa ní ẹ̀rí tó dájú pé Bíbélì ṣe é gbẹ́kẹ̀ lé. Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ráwọn ẹ̀rí tó pọ̀ sí i nígbà tí wọ́n bá ṣàyẹ̀wò àwọn wàláà pẹlẹbẹ tó kù.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé ìwé 21]
A ya fọ́tò yìí nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda British Museum