ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 12
Ṣé Ò Ń Rí Ohun Tí Sekaráyà Rí?
“‘Nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.” —SEK. 4:6.
ORIN 73 Fún Wa Ní Ìgboyà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Nǹkan amóríyá wo ló máa tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù tó wà nígbèkùn?
INÚ gbogbo àwọn Júù ló ń dùn. Ìdí sì ni pé Jèhófà ti mú kí “Kírúsì ọba Páṣíà” dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti lo ọ̀pọ̀ ọdún nígbèkùn Bábílónì. Ọba kéde pé kí gbogbo àwọn Júù pa dà sí ìlú wọn, kí wọ́n sì “tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́.” (Ẹ́sírà 1:1, 3) Ẹ wo bí inú wọn ṣe máa dùn tó! Ìdí sì ni pé á ṣeé ṣe fún wọn láti pa dà máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ lórí ilẹ̀ tó fún wọn.
2. Nígbà táwọn Júù tó wà nígbèkùn pa dà sí Jerúsálẹ́mù, kí ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe?
2 Lọ́dún 537 Ṣ.S.K., díẹ̀ lára àwọn Júù tó wà nígbèkùn dé sí Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú ìjọba Júdà lápá gúúsù. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn Júù yẹn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, nígbà tó sì máa fi di ọdún 536 Ṣ.S.K., wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì náà lélẹ̀!
3. Ìṣòro wo làwọn Júù yẹn kojú?
3 Nígbà táwọn Júù yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í tún tẹ́ńpìlì kọ́, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wọ́n. Àwọn tó ń gbé nítòsí Jerúsálẹ́mù “ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn èèyàn Júdà, wọ́n sì ń mú kí ọkàn wọn domi, kí wọ́n má [bàa] lè kọ́ ilé náà.” (Ẹ́sírà 4:4) Ohun tí wọ́n kojú yẹn ò rọrùn rárá, kàkà kéwé àgbọn dẹ̀, ṣe ló ń le sí i. Nígbà tó di ọdún 522 Ṣ.S.K., ọba Páṣíà tuntun tó ń jẹ́ Atasásítà gorí ìtẹ́.b Àwọn tó ń ta kò wọ́n lo àǹfààní yẹn láti dá iṣẹ́ náà dúró torí pé ṣe ni wọ́n “ń fi òfin bojú láti dáná ìjàngbọ̀n.” (Sm. 94:20) Lára ohun tí wọ́n sọ fún Ọba Atasásítà ni pé àwọn Júù ń gbìmọ̀ pọ̀ láti ṣọ̀tẹ̀ sí i. (Ẹ́sírà 4:11-16) Ọba gba irọ́ wọn gbọ́, ó sì ní kí wọ́n dá iṣẹ́ tẹ́ńpìlì náà dúró. (Ẹ́sírà 4:17-23) Bó ṣe di pé àwọn Júù yẹn ò lè kọ́ tẹ́ńpìlì náà mọ́ nìyẹn.—Ẹ́sírà 4:24.
4. Kí ni Jèhófà ṣe nígbà táwọn èèyàn ta ko iṣẹ́ tẹ́ńpìlì náà? (Àìsáyà 55:11)
4 Àwọn tí ò sin Jèhófà tó ń gbé nítòsí Jerúsálẹ́mù àtàwọn alákòóso kan nílẹ̀ Páṣíà ti pinnu pé àwọn máa dá iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà dúró. Àmọ́ Jèhófà ti pinnu pé iṣẹ́ náà ò ní dáwọ́ dúró torí pé kò sóhun tí Jèhófà sọ tí kò ní ṣẹ. (Ka Àìsáyà 55:11.) Ó gbé wòlíì kan tó nígboyà tó ń jẹ́ Sekaráyà dìde, ó sì fi ìran mẹ́jọ kan hàn án. Àwọn ìran yìí máa fún àwọn Júù níṣìírí láti máa bá iṣẹ́ náà lọ. Àwọn ìran yẹn fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé kò sídìí tó fi yẹ kí wọ́n máa bẹ̀rù àwọn ọ̀tá wọn, ó sì fún wọn níṣìírí láti máa bá iṣẹ́ náà lọ. Nínú ìran karùn-ún tí Jèhófà fi han Sekaráyà, ó rí ọ̀pá fìtílà kan àti igi ólífì méjì.
5. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
5 Gbogbo wa la máa ń rẹ̀wẹ̀sì nígbà míì. Torí náà, a máa jàǹfààní látinú ìran karùn-ún tí Jèhófà fi han Sekaráyà. Jèhófà fi ìran yìí han Sekaráyà kó lè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níṣìírí. Tá a bá lóye ìran yìí dáadáa, ó máa jẹ́ káwa náà máa fòótọ́ sin Jèhófà nìṣó nígbà táwọn èèyàn bá ń ta kò wá, tí nǹkan bá yí pa dà fún wa tàbí nígbà tá ò bá lóye ìdí tí ètò Ọlọ́run fi ní ká ṣe àwọn nǹkan kan.
TÁWỌN ÈÈYÀN BÁ Ń TA KÒ WÁ
6. Báwo ni ìran ọ̀pá fìtílà àti igi ólífì méjì tó wà nínú Sekaráyà 4:1-3 ṣe mú káwọn Júù nígboyà? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
6 Ka Sekaráyà 4:1-3. Ìran ọ̀pá fìtílà àti igi ólífì méjì tí Sekaráyà rí mú káwọn Júù borí àtakò táwọn ọ̀tá wọn ń ṣe sí wọn. Lọ́nà wo? Ṣé o kíyè sí i pé ibì kan ni òróró tó ń dà sínú ọ̀pá fìtílà yẹn ti ń wá, kò sì dáwọ́ dúró? Àtinú igi ólífì méjì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ ni òróró ti ń dà sínú agbada òróró náà. Àtinú agbada yẹn sì ni òróró ti ń dà sínú fìtílà méjèèje tó wà lórí ọ̀pá fìtílà náà. Òróró yìí ló ń jẹ́ kí fìtílà náà máa jó nìṣó. Sekaráyà béèrè pé: “Kí làwọn nǹkan yìí túmọ̀ sí?” Áńgẹ́lì náà wá sọ ohun tí Jèhófà ní kó sọ, ó ní: “‘Kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.” (Sek. 4:4, 6) Òróró tó ń wá látinú àwọn igi náà ṣàpẹẹrẹ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, ẹ̀mí mímọ́ yẹn ò sì lè dáwọ́ iṣẹ́ dúró láé. Bó ti wù kí Ìjọba Ilẹ̀ Páṣíà lágbára tó, kò lè lágbára tó ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Torí pé Jèhófà ń ti àwọn èèyàn ẹ̀ lẹ́yìn, wọ́n máa borí àwọn tó ń ta ko iṣẹ́ náà, wọ́n sì máa parí iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà. Ẹ ò rí i pé ìròyìn yẹn máa mára tu àwọn Júù yẹn gan-an! Ohun tó yẹ káwọn Júù yẹn ṣe ò ju pé kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì pa dà sẹ́nu iṣẹ́. Ohun tí wọ́n ṣe gan-an nìyẹn bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọba ṣì fòfin de iṣẹ́ náà.
7. Kí ló ṣẹlẹ̀ tó mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fáwọn tó ń kọ́ tẹ́ńpìlì náà?
7 Ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fáwọn tó ń kọ́ tẹ́ńpìlì yẹn. Kí ni nǹkan náà? Ọba Páṣíà tuntun tó ń jẹ́ Dáríúsì Kìíní gorí ìtẹ́. Ní ọdún kejì tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, ìyẹn ọdún 520 Ṣ.S.K., ó rí i pé kò tọ̀nà bí wọ́n ṣe fòfin de iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì yẹn. Dáríúsì wá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ parí iṣẹ́ náà. (Ẹ́sírà 6:1-3) Ó dájú pé ìròyìn yẹn máa ya gbogbo èèyàn lẹ́nu, àmọ́ ọba tún ṣe jùyẹn lọ. Ó pàṣẹ fáwọn tó ń gbé lágbègbè náà pé wọn ò gbọ́dọ̀ dá iṣẹ́ yẹn dúró mọ́ àti pé kí wọ́n pèsè owó àtàwọn nǹkan míì táwọn Júù máa lò fún iṣẹ́ náà! (Ẹ́sírà 6:7-12) Ohun tó ṣe yìí ló jẹ́ káwọn Júù kọ́ tẹ́ńpìlì yẹn parí ní ọdún mẹ́rin ó lé díẹ̀, ìyẹn ọdún 515 Ṣ.S.K.—Ẹ́sírà 6:15.
8. Kí ló máa jẹ́ kó o nígboyà táwọn èèyàn bá ń ta kò ẹ́?
8 Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà làwọn èèyàn ń ṣenúnibíni sí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ń gbé lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Nírú àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀, wọ́n lè fàṣẹ ọba mú àwọn ará wa, kí wọ́n sì mú wọn “lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba” kó lè jẹ́ ẹ̀rí fáwọn alákòóso náà. (Mát. 10:17, 18) Nígbà míì, àwọn míì lè gorí ìtẹ́ kíyẹn sì mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fáwọn ará wa. Ó sì lè jẹ́ pé adájọ́ kan ló máa dájọ́ tó máa jẹ́ káwọn ará wa lè máa bá ìjọsìn wọn nìṣó. Àtakò táwọn ará wa kan ń dojú kọ tún yàtọ̀ síyẹn. Lóòótọ́, orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fàyè gbà wá láti sin Jèhófà ni wọ́n ń gbé, àmọ́ ṣe làwọn mọ̀lẹ́bí wọn ń fúngun mọ́ wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ sin Jèhófà mọ́. (Mát. 10:32-36) Lọ́pọ̀ ìgbà, táwọn mọ̀lẹ́bí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ta kò wọ́n bá ti rí i pé pàbó ni gbogbo ìsapá àwọn já sí, wọn kì í ta kò wọ́n mọ́. Kódà, àwọn kan tó hùwà ìkà sáwọn ará wa kan kí wọ́n má bàa jọ́sìn Jèhófà mọ́ ti wá di Ẹlẹ́rìí tó ń fìtara wàásù. Torí náà, tí wọ́n bá ń ta kò ẹ́, má jẹ́ kíyẹn mú kó o fi Jèhófà sílẹ̀! Má bẹ̀rù. Jèhófà máa wà pẹ̀lú ẹ, ó sì tún máa fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́, torí náà kò sídìí fún ẹ láti bẹ̀rù!
TÍ NǸKAN BÁ YÍ PA DÀ FÚN WA
9. Kí nìdí tínú àwọn Júù kan ò fi dùn nígbà tí wọ́n fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì tuntun náà lélẹ̀?
9 Nígbà tí wọ́n fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì tuntun náà lélẹ̀, àwọn àgbààgbà Júù kan sunkún. (Ẹ́sírà 3:12) Wọ́n mọ bí tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ tẹ́lẹ̀ ṣe rẹwà tó. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ronú pé tẹ́ńpìlì tuntun yìí ò ní “já mọ́ nǹkan kan” lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyẹn. (Hág. 2:2, 3) Nígbà tí wọ́n fi tẹ́ńpìlì ti tẹ́lẹ̀ wé èyí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́, wọ́n banú jẹ́ gan-an. Àmọ́ ìran tí Sekaráyà rí máa jẹ́ kí wọ́n pa dà láyọ̀. Lọ́nà wo?
10. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì Jèhófà kan sọ nínú Sekaráyà 4:8-10 ṣe mú káwọn Júù borí ẹ̀dùn ọkàn wọn?
10 Ka Sekaráyà 4:8-10. Kí ni áńgẹ́lì náà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “inú wọn á dùn, wọ́n á sì rí okùn ìwọ̀n ní ọwọ́ Serubábélì [ìyẹn gómìnà àwọn Júù]”? Wọ́n máa ń fi okùn ìwọ̀n díwọ̀n bí nǹkan ṣe gún régé tó. Torí náà, ṣe ni áńgẹ́lì yẹn fi ń dá wọn lójú pé bí tẹ́ńpìlì yẹn tiẹ̀ kéré lójú àwọn kan, wọ́n máa parí ẹ̀, bí Jèhófà sì ṣe fẹ́ kó rí ló máa rí gẹ́lẹ́. Tẹ́ńpìlì yẹn máa múnú Jèhófà dùn, ó sì yẹ kó múnú tiwọn náà dùn. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà ni pé kí wọ́n máa jọ́sìn ẹ̀ lọ́nà tó fẹ́ nínú tẹ́ńpìlì náà. Táwọn Júù bá ń ronú lórí bí wọ́n ṣe máa sin Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà, kí wọ́n sì rí ojúure rẹ̀, wọ́n á pa dà láyọ̀.
11. Ìṣòro wo làwọn kan lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń dojú kọ lónìí?
11 Kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ nínú wa tí nǹkan bá yí pa dà fún wa. Àwọn kan tó ti wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn fún ọ̀pọ̀ ọdún ti gba iṣẹ́ ìsìn míì báyìí. Àwọn míì sì ní láti fi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọ sílẹ̀ torí pé wọ́n ti dàgbà. Inú wa kì í dùn tírú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. A lè má kọ́kọ́ mọ ìdí tí àyípadà náà fi wáyé, a sì lè má fara mọ́ ọn. A lè máa ronú pé ibi tá a wà àbí iṣẹ́ tá à ń ṣe tẹ́lẹ̀ dáa ju èyí tá à ń ṣe báyìí lọ. Ìyẹn lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, ká wá máa ronú pé a ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò fún Jèhófà mọ́. (Òwe 24:10) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni ìran tí Sekaráyà rí ṣe lè mú ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà?
12. Báwo ni ìran tí Sekaráyà rí ṣe lè jẹ́ ká máa láyọ̀ tí nǹkan bá tiẹ̀ yí pa dà fún wa?
12 Tó bá jẹ́ pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan làwa náà fi ń wò ó, ó máa rọrùn fún wa láti fara dà á tí nǹkan bá yí pa dà fún wa. Ọ̀pọ̀ nǹkan àgbàyanu ni Jèhófà ń ṣe lónìí, àǹfààní ńlá ló sì jẹ́ pé à ń bá a ṣiṣẹ́. (1 Kọ́r. 3:9) Iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà lè yí pa dà, àmọ́ ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ò ní yí pa dà láé. Torí náà, táwọn àyípadà kan bá kàn ẹ́, má ṣe lo gbogbo àkókò ẹ láti máa ronú nípa ìdí tí àyípadà náà fi wáyé. Dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá nípa àwọn “ọjọ́ àtijọ́,” ṣe ni kó o bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí àwọn nǹkan dáadáa nínú àyípadà náà. (Oníw. 7:10) Dípò tí wàá fi máa ronú nípa àwọn nǹkan tó ò lè ṣe mọ́, àwọn nǹkan tó o lè ṣe báyìí ni kó o máa ronú nípa ẹ̀. Ohun tá a kọ́ nínú ìran Sekaráyà ni pé ó ṣe pàtàkì ká gbà pé nǹkan ṣì máa dáa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó kódà tí nǹkan bá yí pa dà fún wa.
TÁ Ò BÁ LÓYE ÌDÍ TÍ ÈTÒ ỌLỌ́RUN FI NÍ KÁ ṢE ÀWỌN NǸKAN KAN
13. Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan fi lè ronú pé kì í ṣe àkókò yẹn ló yẹ káwọn bẹ̀rẹ̀ sí í tún tẹ́ńpìlì yẹn kọ́?
13 Ọba ti fòfin de iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà. Síbẹ̀, àwọn ọkùnrin tí Ọlọ́run ní kó máa ṣáájú wọn, ìyẹn Àlùfáà Àgbà Jéṣúà (Jóṣúà) àti Gómìnà Serubábélì “bẹ̀rẹ̀ sí í tún ilé Ọlọ́run kọ́.” (Ẹ́sírà 5:1, 2) Ó ṣeé ṣe kí ìpinnu yẹn má bá àwọn Júù kan lára mu. Ìdí sì ni pé kò sí báwọn ọ̀tá wọn ò ṣe ní mọ̀ pé wọ́n ti ń tún tẹ́ńpìlì náà kọ́, tí wọ́n bá sì ti mọ̀, gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe ni wọ́n máa ṣe láti dá iṣẹ́ náà dúró. Torí náà, ó gbọ́dọ̀ dá Jóṣúà àti Serubábélì tó ń bójú tó iṣẹ́ náà lójú pé Jèhófà máa tì wọ́n lẹ́yìn. Kí ni Jèhófà ṣe kó lè dá wọn lójú?
14. Bí Sekaráyà 4:12, 14 ṣe sọ, kí ni Jèhófà fi dá Àlùfáà Àgbà Jóṣúà àti Gómìnà Serubábélì lójú?
14 Ka Sekaráyà 4:12, 14. Nínú ìran yìí, áńgẹ́lì Jèhófà jẹ́ kí Sekaráyà mọ̀ pé igi ólífì méjì náà ṣàpẹẹrẹ “àwọn ẹni àmì òróró méjì,” ìyẹn Jóṣúà àti Serubábélì. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn ọkùnrin méjì yẹn “dúró ní ẹ̀gbẹ́ [Jèhófà] Olúwa gbogbo ayé.” Ẹ ò rí i pé àǹfààní tí ò lẹ́gbẹ́ nìyẹn! Jèhófà fọkàn tán wọn pé wọ́n á bójú tó iṣẹ́ náà dáadáa. Torí náà, ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa balẹ̀ láti ṣe ohun tí wọ́n bá ní kí wọ́n ṣe torí pé àwọn méjèèjì ni Jèhófà ń lò láti darí wọn.
15. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fara mọ́ ohun tí Jèhófà ní ká ṣe nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀?
15 Bíbélì wà lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà tọ́ àwa èèyàn ẹ̀ sọ́nà lónìí. Inú ìwé tó mí sí yìí ló ti sọ bá a ṣe lè jọ́sìn òun lọ́nà tóun tẹ́wọ́ gbà. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fara mọ́ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ká ṣe? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kà á déédéé, tá a sì ń ronú lé e lórí kó lè yé wa dáadáa. Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Tí mo bá ń ka Bíbélì tàbí ọ̀kan lára àwọn ìwé wa, ṣé mo máa ń dánu dúró kí n lè ronú lórí ohun tí mò ń kà? Ṣé mo máa ń ṣèwádìí nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tó “ṣòroó lóye”? Àbí ṣe ni mo máa ń sáré ka àwọn ìwé náà gààràgà?’ (2 Pét. 3:16) Tá a bá ń ronú lórí ohun tí Jèhófà ń kọ́ wa, á rọrùn fún wa láti ṣe ohun tó ní ká ṣe, àá sì ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yanjú.—1 Tím. 4:15, 16.
16. Tá ò bá fi bẹ́ẹ̀ lóye ìdí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” fi ní ká ṣe ohun kan, kí ló máa jẹ́ ká ṣe ohun tí wọ́n bá ní ká ṣe?
16 Jèhófà tún ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti tọ́ wa sọ́nà. (Mát. 24:45) Nígbà míì, ẹrú yìí máa ń fún wa láwọn ìtọ́ni kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ yé wa. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ní ká múra sílẹ̀ de àwọn àjálù kan tá a ronú pé kò lè ṣẹlẹ̀ lágbègbè wa láé. A sì lè ronú pé ọwọ́ tí ẹrú náà fi ń mú nǹkan lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn ti le jù. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ronú pé ìtọ́ni tí wọ́n fún wa ò bọ́gbọ́n mu? A lè ronú nípa àǹfààní táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí nígbà tí wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jóṣúà àti Serubábélì fún wọn. A tún lè ronú nípa àwọn ẹlòmíì tá a kà nípa wọn nínú Bíbélì. Àwọn ìgbà kan wà táwọn èèyàn Ọlọ́run ti gba àwọn ìtọ́ni kan tó jẹ́ pé lójú èèyàn, kò bọ́gbọ́n mu, àmọ́ àwọn ìtọ́ni yẹn gan-an ló gba ẹ̀mí wọn là.—Oníd. 7:7; 8:10.
ṢÉ ÌWỌ NÁÀ Ń RÍ OHUN TÍ SEKARÁYÀ RÍ?
17. Kí làwọn Júù ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa ìran ọ̀pá fìtílà àti igi ólífì méjì náà?
17 Ìran karùn-ún tí Sekaráyà rí ò gùn púpọ̀, àmọ́ ó jẹ́ káwọn Júù yẹn nígboyà láti máa bá iṣẹ́ náà lọ, kí wọ́n sì máa jọ́sìn Jèhófà. Nígbà tí wọ́n fi ohun tí wọ́n kọ́ nínú ìran Sekaráyà sílò, wọ́n rí i pé Jèhófà ń ti àwọn lẹ́yìn, ó sì ń tọ́ àwọn sọ́nà. Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ náà lọ, wọ́n sì tún pa dà láyọ̀.—Ẹ́sírà 6:16.
18. Kí ni ìran tí Sekaráyà rí máa mú kíwọ náà ṣe?
18 Ìran ọ̀pá fìtílà àti igi ólífì méjì tí Sekaráyà rí máa ṣe ìwọ náà láǹfààní gan-an. Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, Jèhófà lè fún wa lókun láti kojú àwọn alátakò, ó lè jẹ́ ká máa láyọ̀ tí iṣẹ́ ìsìn wa bá yí pa dà, á sì tún jẹ́ ká fọkàn tán àwọn ìtọ́ni tá à ń rí gbà tá ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lóye wọn. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá ń kojú àwọn ìṣòro kan nígbèésí ayé ẹ? Àkọ́kọ́, wò ó bíi pé ò ń rí ohun tí Sekaráyà rí, ìyẹn àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ń bójú tó àwọn èèyàn ẹ̀. Ìkejì, jẹ́ káwọn ẹ̀rí tó o rí yẹn mú kó o túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kó sì mú kó o máa fi tọkàntọkàn sin Jèhófà nìṣó. (Mát. 22:37) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fayọ̀ jọ́sìn ẹ̀ títí láé.—Kól. 1:10, 11.
ORIN 7 Jèhófà Ni Agbára Wa
a Jèhófà jẹ́ kí wòlíì Sekaráyà rí àwọn ìran kan tó máa múnú òun àtàwọn èèyàn Ọlọ́run dùn. Ìran tí Sekaráyà rí yìí fún òun àtàwọn èèyàn Ọlọ́run lókun láti borí àwọn ìṣòro tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń tún tẹ́ńpìlì kọ́. Àwọn ìran yẹn máa ran àwa náà lọ́wọ́ lónìí láti máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó bá a tiẹ̀ ń kojú ìṣòro. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tá a lè kọ́ látinú ọ̀kan lára ìran tí Sekaráyà rí, ìyẹn ìran ọ̀pá fìtílà àti igi ólífì.
b Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà nígbà tí Gómìnà Nehemáyà ń ṣàkóso, ọba míì tó ń jẹ́ Atasásítà fojú rere hàn sáwọn Júù.
c ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ti dàgbà, kò sì fi bẹ́ẹ̀ lókun mọ́. Síbẹ̀, ó ṣì ń fayọ̀ sin Jèhófà torí ó gbà pé nǹkan ṣì máa dáa.
d ÀWÒRÁN: Bí arábìnrin kan ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lẹ́yìn bíi ti Jóṣúà àti Serubábélì.