Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Nehemáyà
ỌDÚN méjìlá ti kọjá lẹ́yìn táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó kẹ́yìn tá a rí àkọsílẹ̀ wọn nínú ìwé Ẹ́sírà ti ṣẹlẹ̀. Àkókò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó fún “ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́.” Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló jẹ́ àmì pé àádọ́rin ọ̀sẹ̀ tó wá parí sí àkókò Mèsáyà ti bẹ̀rẹ̀. (Dáníẹ́lì 9:24-27) Ìwé Nehemáyà dá lórí ìtàn báwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe tún ògiri ìlú Jerúsálẹ́mù kọ́. Ó tún dá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò pàtàkì kan tó ju ọdún méjìlá lọ, ìyẹn láti ọdún 456 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ọdún 443 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
Gómìnà Nehemáyà ló kọ ìwé yìí, ó sì jẹ́ ìtàn fífanimọ́ra kan tó fi hàn pé tá a bá múra tán lọ́kàn wa láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tá a sì gbára lé e pátápátá, ìjọsìn mímọ́ á di èyí tá a gbé ga. Ìwé yìí fi hàn kedere bí Jèhófà ṣe ń darí nǹkan kí ìfẹ́ rẹ̀ lè di ṣíṣe. Ó tún jẹ́ ìtàn nípa olórí kan tó jẹ́ akínkanjú àti onígboyà èèyàn. Ẹ̀kọ́ pàtàkì lohun tó wà nínú ìwé Nehemáyà jẹ́ fún gbogbo olùjọ́sìn tòótọ́ lónìí “nítorí tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”—Hébérù 4:12.
“NÍGBÀ TÍ Ó ṢE, ÒGIRI NÁÀ PARÍ”
Ṣúṣánì ilé aláruru ni Nehemáyà wà tó ti ń ṣiṣẹ́ sin Ọba Atasásítà Lọngimánọ́sì. Iṣẹ́ kan tó gba pé ká fọkàn tánni ló sì ń ṣe fún ọba náà. Nígbà tí Nehemáyà gbọ́ ìròyìn pé àwọn èèyàn òun “wà nínú ipò ìṣòro tí ó burú gidigidi àti nínú ẹ̀gàn” àti pé “ògiri Jerúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀, àwọn ẹnubodè rẹ̀ pàápàá ni a [sì] ti fi iná sun,” ọkàn Nehemáyà bà jẹ́ gan-an. Ó gbàdúrà gidigidi sí Ọlọ́run pé kó tọ́ òun sọ́nà. (Nehemáyà 1:3, 4) Kò pẹ́ kò jìnnà, ọba ṣàkíyèsí pé inú Nehemáyà kò dùn, ó sì fún un láǹfààní láti lọ sí Jerúsálẹ́mù.
Lẹ́yìn tí Nehemáyà dé sí Jerúsálẹ́mù, ó lọ wo ògiri náà ní òru, ó sì sọ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fáwọn Júù, ìyẹn láti tún ògiri náà kọ́. Bí iṣẹ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn èèyàn gbé àtakò dìde sí iṣẹ́ náà. Ṣùgbọ́n nítorí pé Nehemáyà jẹ́ olórí tó nígboyà, “nígbà tí ó ṣe, ògiri náà parí.”—Nehemáyà 6:15.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:1; 2:1—Ṣé àkókò kan náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ka “ọdún ogún” tí ẹsẹ méjèèjì yìí mẹ́nu kàn? Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbà ìṣàkóso Atasásítà Ọba ni ọdún ogún yìí. Àmọ́ ìlànà tí wọ́n lò láti ka àwọn ọdún náà nínú ẹsẹ méjèèjì yìí yàtọ̀ síra. Àkọsílẹ̀ àwọn òpìtàn sọ pé ọdún 475 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Atasásítà Ọba gorí ìtẹ́. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ àṣà àwọn akọ̀wé ilẹ̀ Bábílónì láti máa ka ọdún táwọn ọba ilẹ̀ Páṣíà fi ṣàkóso láti oṣù Nísàn ọdún kan (oṣù March sí April) sí Nísàn ọdún kejì, ọdún 474 ṣáájú Sànmánì Kristẹni lọdún àkọ́kọ́ nínú ìṣàkóso Atasásítà. Nípa bẹ́ẹ̀, oṣù Nísàn ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ọdún ogún tí Nehemáyà 2:1 mẹ́nu kàn bẹ̀rẹ̀. Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé oṣù Kísíléfì (oṣù November sí December) ọdún tó ṣáájú ọdún 456 ṣáájú Sànmánì Kristẹni loṣù Kísíléfì tó wà ní Nehemáyà 1:1 ń tọ́ka sí. Nehemáyà sọ pé oṣù yìí tún bọ́ sí ọdún tó kẹ́yìn nínú ọdún ogún tí Atasásítà ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé níbí yìí, ìgbà tí ọba náà gorí ìtẹ́ ni Nehemáyà bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ọdún náà. Ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun táwọn Júù ọjọ́ òní ń pè ní kàlẹ́ńdà ayé, èyí tó máa ń bẹ̀rẹ̀ lóṣù Tishri tó ṣe déédéé pẹ̀lú oṣù September sí October, ni Nehemáyà fi ṣírò àkókò náà. Èyí tó wù kó jẹ́, ọdún 455 lọdún tí ọ̀rọ̀ náà jáde lọ láti tún Jerúsálẹ́mù kọ́.
4:17, 18—Báwo lọkùnrin kan ṣe lè máa fi ọwọ́ kan ṣoṣo mọ ògiri? Bó bá jẹ́ àwọn tó máa ń ru ẹrù ni, ìyẹn kò ṣòro. Bí wọ́n bá ti gbé ẹrù náà lé orí tàbí lé èjìká wọn, kò nira fún wọn láti fi ọwọ́ kan dì í mú “nígbà tí ọwọ́ kejì [á sì] di ohun ọṣẹ́ mú.” Àwọn kọ́lékọ́lé tó jẹ́ pé ọwọ́ méjèèjì ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ máa ń “di àmùrè, olúkúlùkù pẹ̀lú idà rẹ̀ ní ìgbáròkó rẹ̀, bí ó ti ń mọlé.” Wọ́n wà ní sẹpẹ́ láti jà bó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọ̀tá dojú ìjà kọ wọ́n.
5:7—Ọ̀nà wo ni Nehemáyà gbà bẹ̀rẹ̀ sí í “rí àléébù lára àwọn ọ̀tọ̀kùlú àti àwọn ajẹ́lẹ̀”? Àwọn ọkùnrin yìí ń fipá gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn Júù ẹgbẹ́ wọn, èyí tó lòdì sí Òfin Mósè. (Léfítíkù 25:36; Diutarónómì 23:19) Yàtọ̀ síyẹn, èlé táwọn ayánilówó yìí máa ń béèrè ti pọ̀ jù. Bó bá jẹ́ pé oṣooṣù ni wọ́n ń gba èlé náà, ìdá méjìlá nínú ọgọ́rùn-ún owó táwọn èèyàn náà yá ni “ìdá ọgọ́rùn-ún” jẹ́ lọ́dún. (Nehemáyà 5:11) Ìwà ìkà ló jẹ́ láti máa gba irú owó bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tí ara ti ń ni tẹ́lẹ̀ nítorí owó orí tí wọ́n ń san àti nítorí àìtó oúnjẹ. Nehemáyà rí àléébù lára àwọn ọlọ́rọ̀ náà ni ti pé, ó lo Òfin Ọlọ́run láti bá wọn wí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ tú àṣírí ìwàkíwà wọn.
6:5—Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú àpò tí wọ́n lẹ ẹnu rẹ̀ pa ni wọ́n sábà máa ń fi àwọn lẹ́tà tó bá jẹ́ àṣírí sí, kí nìdí tí Sáńbálátì ṣe fi “lẹ́tà tí a kò lẹ̀” ránṣẹ́ sí Nehemáyà? Ó lè jẹ́ pé Sáńbálátì fẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹ̀sùn èké tó wà nínú lẹ́tà náà ló ṣe fi ránṣẹ́ láìlẹ̀ ẹ́. Bóyá ó ronú pé èyí yóò bí Nehemáyà nínú débi pé yóò fi iṣẹ́ ògiri tó ń mọ náà sílẹ̀ láti wá wí àwíjàre. Tàbí kẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Sáńbálátì ń ronú pé ohun tó wà nínú lẹ́tà náà yóò kó jìnnìjìnnì bá àwọn Júù débi pé wọ́n á dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró pátápátá. Nehemáyà kò jẹ́ kó fi èyí kóun láyà jẹ, ńṣe ló ń bá iṣẹ́ náà lọ láìmikàn.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:4; 2:4; 4:4, 5. Tá a bá bára wa nínú ìṣòro tàbí tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì, a ní láti “ní ìforítì nínú àdúrà” ká sì ṣe ohun tó bá ìtọ́sọ́nà tá a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu.—Róòmù 12:12.
1:11–2:8; 4:4, 5, 15, 16; 6:16. Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà àtọkànwá táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá gbà.—Sáàmù 86:6, 7.
1:4; 4:19, 20; 6:3, 15. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nehemáyà jẹ́ ẹnì kan tó lójú àánú, síbẹ̀ àpẹẹrẹ tó dára ló jẹ́ fún wa láti tẹ̀ lé ní ti pé kò gba gbẹ̀rẹ́ ó sì ṣe ohun tó mọ̀ pé ó jẹ́ òdodo.
1:11–2:3. Olórí ohun tó ń fún Nehemáyà láyọ̀ kì í ṣe ipò ńlá tó wà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń gbọ́tí fọba. Ohun to ń fún un láyọ̀ ni ìjọsìn tòótọ́ tó ń tẹ̀ síwájú. Ǹjẹ́ ìjọsìn Jèhófà àti gbogbo ohun tó ń mú kí ìjọsìn náà tẹ̀ síwájú kọ́ ló yẹ kó jẹ àwa náà lógún jù, kó sì jẹ́ olórí ohun tó ń fún wa láyọ̀?
2:4-8. Jèhófà ló jẹ́ kí Atasásítà fún Nehemáyà láyè láti lọ tún ògiri ìlú Jerúsálẹ́mù kọ́. Òwe 21:1 sọ pé: “Ọkàn-àyà ọba dà bí ìṣàn omi ní ọwọ́ Jèhófà. Ibi gbogbo tí ó bá ní inú dídùn sí, ni ó ń darí rẹ̀ sí.”
3:5, 27. A ò gbọ́dọ̀ jọ ara wa lójú débi tá a ó máa ka àwọn iṣẹ́ tó yẹ ká ṣe kí ìjọsìn tòótọ́ lè tẹ̀ síwájú sí iṣẹ́ tó kéré sí wa bí àwọn “ọlọ́lá ọba” ará Tékóà ti ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn mẹ̀kúnnù ìlú Tékóà tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà tinútinú ló yẹ ká fara wé.
3:10, 23, 28-30. Ó ṣeé ṣe fáwọn kan láti ṣí lọ sáwọn àgbègbè tá a ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run gan-an, ọ̀pọ̀ lára wa sì ń ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn lágbègbè tá a wà. A lè ṣe é nípa lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ṣíṣèrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Àmọ́ olórí ọ̀nà tá a lè gbà ṣe é ni kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.
4:14. Nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣàtakò sí wa, àwa náà lè borí ìbẹ̀rù nípa fífi “Ẹni ńlá tí ń múni kún fún ẹ̀rù” sọ́kàn.
5:14-19. Àpẹẹrẹ tó dára gan-an ni Gómìnà Nehemáyà jẹ́ fáwọn Kristẹni tó jẹ́ alábòójútó ní ti bó ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, aláìmọtara-ẹni-nìkan àti olóye èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lo ìtara láti mú káwọn èèyàn náà pa Òfin Ọlọ́run mọ́, kò jẹgàba lé wọn lórí fún èrè tara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ẹni tó ń fọ̀rọ̀ àwọn tára ń ni àtàwọn tálákà sọ́kàn. Ọ̀làwọ́ tún ni Nehemáyà, àpẹẹrẹ tó dára tí gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè máa tẹ̀ lé ló jẹ́.
“JỌ̀WỌ́, ỌLỌ́RUN MI, RÁNTÍ MI FÚN RERE”
Bí iṣẹ́ kíkọ́ ògiri ìlú Jerúsálẹ́mù ti ń parí ni Nehemáyà ṣe àwọn ẹnubodè rẹ̀ sí i tó sì ṣe àwọn ètò láti dáàbò bo ìlú náà. Lẹ́yìn náà ló wá ṣe àkọsílẹ̀ nípa ìran àwọn èèyàn náà. Bí gbogbo àwọn èèyàn náà ti kóra jọ “sí ojúde ìlú tí ó wà ní àtidé Ẹnubodè Omi,” Ẹ́sírà tó jẹ́ àlùfáà ka ìwé Òfin Mósè, Nehemáyà àtàwọn ọmọ Léfì sì ṣàlàyé Òfin náà fáwọn èèyàn yékéyéké. (Nehemáyà 8:1) Òye tí wọ́n ní nípa Àjọyọ̀ Àtíbàbà mú kí wọ́n ṣayẹyẹ rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.
Àpéjọ mìíràn tún tẹ̀ lé èyí. Lákòókò náà, “àwọn irú-ọmọ Ísírẹ́lì” jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ jẹ̀bi rẹ̀, àwọn ọmọ Léfì ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lò, àwọn èèyàn náà sì búra “láti [máa] rìn nínú òfin Ọlọ́run tòótọ́.” (Nehemáyà 9:1, 2; 10:29) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn tó ń gbé inú ìlú Jerúsálẹ́mù kò tíì fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, wọ́n ṣẹ́ kèké láti mú kí ọkùnrin kan nínú mẹ́wàá tó ń gbé lẹ́yìn ìlú Jerúsálẹ́mù kó lọ sínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá ṣe ìyàsímímọ́ ògiri náà pẹ̀lú ayọ̀ ńláǹlà “tí ó fi jẹ́ pé a gbọ́ ayọ̀ yíyọ̀ Jerúsálẹ́mù ní ibi jíjìnnà réré.” (Nehemáyà 12:43) Ẹ̀yìn ọdún méjìlá tí Nehemáyà ti dé sí Jerúsálẹ́mù ló tó kúrò tó sì padà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ lọ́dọ̀ Atasásítà. Àmọ́ kò pẹ́ tí ìwà àìmọ́ tún fi jẹyọ láàárín àwọn Júù. Bí Nehemáyà ti ń padà dé sí Jerúsálẹ́mù ló gbégbèésẹ̀ kíákíá láti ṣàtúnṣe ipò náà. Ó wá fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà fún ara rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, Ọlọ́run mi, rántí mi fún rere.”—Nehemáyà 13:31.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
7:6-67—Kí nìdí tí iye àwọn tó ṣẹ́ kù tí Nehemáyà kọ sílẹ̀ pé wọ́n padà sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú Serubábélì fi yàtọ̀ sí iye tí Ẹ́sírà kọ sílẹ̀ fún ìdílé kọ̀ọ̀kan? (Ẹ́sírà 2:1-65) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó fa àwọn ìyàtọ̀ yìí ni pé ibi tí Ẹ́sírà àti Nehemáyà ti mú àkọsílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé iye àwọn tó forúkọ sílẹ̀ pé àwọn fẹ́ padà sí Jerúsálẹ́mù yàtọ̀ sí iye àwọn tó wá padà. Ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí táwọn àkọsílẹ̀ méjèèjì náà fi yàtọ̀ síra ni pé àwọn Júù kan tí wọn ò kọ́kọ́ mọ ìran wọn wá mọ̀ ọ́n nígbà tó yá. Àmọ́ àwọn àkọsílẹ̀ méjèèjì fohùn ṣọ̀kan lórí kókó kan, ìyẹn ni pé: Ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì, ọ̀ọ́dúnrún, àti ọgọ́ta [42,360] ni iye àwọn èèyàn tó kọ́kọ́ padà wá, láìka àwọn ẹrú àtàwọn akọrin mọ́ wọn.
10:34—Kí nìdí tí wọ́n fi sọ pé káwọn èèyàn náà máa mú igi wá? Òfin Mósè kò sọ pé kí wọ́n máa fi igi ṣe ìrúbọ. Torí pé wọ́n nílò igi gan-an ló mú kí wọ́n pa àṣẹ yìí. Wọ́n nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi láti fi sun ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó hàn kedere pé àwọn Nétínímù kò tó, ìyẹn àwọn tó jẹ́ ẹrú ní tẹ́ńpìlì àmọ́ tí wọn kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Èyí ló mú kí wọ́n ṣẹ́ kèké láti rí i dájú pé igi kò wọ́n wọn.
13:6—Báwo ni àkókò tí Nehemáyà kò fi sí ní Jerúsálẹ́mù ṣe gùn tó? Ohun tí Bíbélì kàn sọ ni pé ní “àkókò kan lẹ́yìn náà” tàbí “lẹ́yìn àwọn ọjọ́,” Nehemáyà bẹ ọba pé kó fòun láyè láti padà lọ sí Jerúsálẹ́mù. Nípa bẹ́ẹ̀ kò ṣeé ṣe láti sọ ní pàtó bí àkókò tí kò fi sí ní Jerúsálẹ́mù ṣe gùn tó. Àmọ́ nígbà tí Nehemáyà padà dé sí Jerúsálẹ́mù, ó rí i pé àwọn èèyàn kò ṣètìlẹ́yìn fáwọn àlùfáà mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì pa òfin Sábáàtì mọ́. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti fẹ́ àwọn aya àjèjì bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ wọn pàápàá kò sì lè sọ èdè àwọn Júù. Kí ipò nǹkan tó lè burú tó bẹ́ẹ̀ yẹn, ó ní láti jẹ́ pé ó pẹ́ gan-an tí Nehemáyà ti kúrò ní Jerúsálẹ́mù.
13:25, 28—Yàtọ̀ sí pé Nehemáyà “rí àléébù” lára àwọn Júù tó pẹ̀yìn dà, àwọn ohun wo ló tún ṣe láti fi pe orí àwọn èèyàn náà wálé? Nehemáyà “pe ibi wá sórí wọn” nípa kíka àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run tó wà nínú Òfin Ọlọ́run lé wọn lórí. Ó ‘lu àwọn kan lára wọn’ èyí tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí pé ó pàṣẹ káwọn kan gbọ́ ẹjọ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí àmì láti fi hàn pé òun kórìíra ìwàkiwà, ó ‘fa díẹ̀ lára irun wọn tu.’ Ó tún lé ọmọ ọmọ Élíáṣíbù tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà da nù nítorí pé ó lọ fẹ́ ọmọbìnrin Sáńbálátì tí í ṣe Hórónì.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
8:8. Níwọ̀n báa ti jẹ́ ẹni tó ń kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, à “ń fi ìtumọ̀ sí i” nípa kíkà á ketekete àti nípa títẹnu mọ́ àwọn kókó tá a nílò àti nípa ṣíṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó tọ́, a sì ń tipa báyìí mú kí ọ̀nà táwọn èèyàn yóò gbà fi sílò túbọ̀ ṣe kedere.
8:10. Kéèyàn mọ̀ pé òun nílò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó sì máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì, kó tún máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ètò Ọlọ́run ló ń fúnni ní “ìdùnnú Jèhófà.” Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn, ká máa lọ sípàdé déédéé, ká sì máa fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn!
11:2. Fífi táwọn kan fi ilẹ̀ wọn tí wọ́n jogún sílẹ̀ tí wọ́n sì ṣí lọ sínú ìlú Jerúsálẹ́mù ná wọn láwọn ohun kan, wọ́n sì pàdánù àwọn àǹfààní kan. Ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan làwọn tó yọ̀ǹda ara wọn yìí ní tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àwa náà lè fi irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ hàn tí àǹfààní bá yọjú láti yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ará wa ní àwọn àpéjọ àgbègbè àti láwọn àkókò mìíràn.
12:31, 38, 40-42. Orin kíkọ jẹ́ ọ̀nà kan tó dára láti yin Jèhófà àti láti fi ọpẹ́ wa hàn fún un. Ó yẹ ká máa fi gbogbo ọkàn wa kọrin láwọn ìpàdé àti àpéjọ wa.
13:4-31. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe gba ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ìwà ìbàjẹ́ àti ìpẹ̀yìndà láyè láti ba ìgbésí ayé wa jẹ́.
13:22. Nehemáyà mọ̀ dájú pé òun yóò jíhìn fún Ọlọ́run. Ó yẹ káwa náà mọ̀ pé a óò jíhìn fún Jèhófà.
Ìbùkún Jèhófà Ṣe Pàtàkì!
Onísáàmù sọ pé: “Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà, lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.” (Sáàmù 127:1) Ẹ ò rí i pé ọ̀nà tó dára gan-an ni Nehemáyà gbà fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí!
Ẹ̀kọ́ tó yẹ ká kọ́ ṣe kedere. Ká tó lè ṣàṣeyọrí nínú ohunkóhun tá a bá dáwọ́ lé, àfi kí Jèhófà bù kún wa. Ǹjẹ́ a lè retí pé kí Jèhófà bù kún wa láìṣe pé a fi ìjọsìn tòótọ́ sípò kìíní nínú ìgbésí ayé wa? Nítorí náà, bíi ti Nehemáyà, ẹ jẹ́ kí ìjọsìn Jèhófà àti bí ìjọsìn náà yóò ṣe máa tẹ̀ síwájú, máa jẹ wá lọ́kàn nígbà gbogbo.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
“Ọkàn-àyà ọba dà bí ìṣàn omi ní ọwọ́ Jèhófà.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Nehemáyà, ẹni tí kò gba gbẹ̀rẹ́ tó sì lójú àánú, wá sí Jerúsálẹ́mù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
Ǹjẹ́ o mọ bá a ti “ń fi ìtumọ̀ sí” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?