ORÍ KẸẸ̀Ẹ́DÓGÚN
Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
1-3. (a) Kí nìdí tí ẹ̀rù fi lè máa ba Ẹ́sítérì nígbà tó fẹ́ lọ rí ọkọ rẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nípa Ẹ́sítérì?
Ẹ́SÍTÉRÌ gbìyànjú láti ṣọkàn akin bó ṣe ń sún mọ́ àgbàlá tó wà nínú ààfin Ṣúṣánì. Àmọ́ kò rọrùn. Gbogbo ohun tó wà nínú ààfin náà ni wọ́n ṣe lọ́nà táá mú kéèyàn máa kọ hà. Wọ́n gbẹ́ àwọn màlúù abìyẹ́, àwọn tafàtafà àtàwọn kìnnìún aláwọ̀ mèremère tí wọ́n fi bíríkì dídán ṣe sí ara ògiri. Àwọn òpó aláràbarà tí wọ́n fi òkúta ṣe àtàwọn ère gàgàrà wà níbẹ̀. Kódà, ibi tí ààfin náà wà tún kàmàmà. Ó wà lórí àwọn ibi gíga tó wà nítòsí àwọn Òkè Ságírọ́sì tí yìnyín bò, ó sì dojú kọ odò Choaspes tí omi inú rẹ̀ mọ́ gaara. Gbogbo iṣẹ́ ọnà yìí máa ń jẹ́ kí àlejò kọ̀ọ̀kan tó bá wá sí ààfin mọ bí agbára ọkùnrin tí Ẹ́sítérì ń lọ bá yìí ṣe pọ̀ tó, ìyẹn ọba tó pe ara rẹ̀ ní “ọba ńlá.” Òun náà sì tún ni ọkọ rẹ̀.
2 Ọkọ rẹ̀ kẹ̀! Ahasuwérúsì yìí yàtọ̀ pátápátá sí irú ọkùnrin tí ọmọbìnrin Júù èyíkéyìí tó jẹ́ olùfọkànsìn máa fẹ́ fi ṣe ọkọ!a Kò dà bíi Ábúráhámù, tó fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un pé kó fetí sí Sárà, aya rẹ̀. (Jẹ́n. 21:12) Tí ọba yìí bá tiẹ̀ mọ̀ nípa Jèhófà, Ọlọ́run Ẹ́sítérì, tàbí Òfin rẹ̀, ohun tó mọ̀ kò tó nǹkan kan. Àmọ́, Ahasuwérúsì mọ òfin ilẹ̀ Páṣíà dáadáa, títí kan èyí tó ka ohun tí Ẹ́sítérì fẹ́ lọ ṣe yìí léèwọ̀. Kí ni òfin náà? Ohun tí òfin yẹn sọ ni pé kí wọ́n pa ẹnikẹ́ni tó bá tọ ọba Páṣíà wá láìjẹ́ pé ọba tí kọ́kọ́ sọ fún un pé kó wá. Ní ti Ẹ́sítérì, ọba kọ́ ló ní kó wá, àmọ́ ó ti gbéra báyìí, ó sì ti ń gba ọ̀dọ̀ ọba lọ. Bó ṣe ń sún mọ́ àgbàlá inú lọ́hùn-ún, níbi tí ọba ti máa rí i látorí ìtẹ́, ó lè ti máa rò pé wọ́n máa pa òun.—Ka Ẹ́sítérì 4:11; 5:1.
3 Kí nìdí tí Ẹ́sítérì fi fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu lọ́nà yẹn? Kí la sì lè rí kọ́ látinú ìgbàgbọ́ obìnrin àtàtà yìí? Lákọ̀ọ́kọ́ náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Ẹ́sítérì ṣe dé ipò ayaba ilẹ̀ Páṣíà, èyí tó jẹ́ ipò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀.
Ìgbà Kékeré Ẹ́sítérì
4. Kí la mọ̀ nípa ìgbà kékeré Ẹ́sítérì? Kí ló fà á tó fi wá ń gbé lọ́dọ̀ Módékáì tó jẹ́ ìbátan rẹ̀?
4 Ọmọ òrukàn ni Ẹ́sítérì. A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa àwọn òbí tó sọ ọ́ ní Hádásà, ìyẹn ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “igi mátílì,” ìyẹn igi kékeré tó ní òdòdó funfun tó fani mọ́ra. Nígbà tí àwọn òbí Ẹ́sítérì kú, ọ̀kan lára àwọn ìbátan rẹ̀, ìyẹn ọkùnrin onínúure kan tó ń jẹ́ Módékáì, ló bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú rẹ̀. Èèyàn òbí Ẹ́sítérì ni Módékáì, àmọ́ ó ju Ẹ́sítérì lọ dáadáa. Ó ní kí Ẹ́sítérì wá máa gbé lọ́dọ̀ òun, ó sì mú un bí ọmọ tirẹ̀.—Ẹ́sít. 2:5-7, 15.
5, 6. (a) Báwo ni Módékáì ṣe tọ́ Ẹ́sítérì dàgbà? (b) Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Ẹ́sítérì àti Módékáì ní Ṣúṣánì?
5 Módékáì àti Ẹ́sítérì wà lára àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn. Ṣúṣánì tó jẹ́ olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Páṣíà ni wọ́n ń gbé, ó sì ṣeé ṣe kí àwọn ará ibẹ̀ máa ṣe ẹ̀tanú sí wọn nítorí ẹ̀sìn wọn àti Òfin tí wọ́n ń tẹ̀ lé torí pé wọ́n jẹ́ Júù. Àmọ́ ó dájú pé Ẹ́sítérì túbọ̀ sún mọ́ Módékáì. Ìdí ni pé ìbátan rẹ̀ yìí ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú tó ti gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìṣòro lọ́pọ̀ ìgbà nígbà àtijọ́, tó sì tún máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Léf. 26:44, 45) Ó ṣe kedere pé Ẹ́sítérì àti Módékáì fẹ́ràn ara wọn, wọ́n sì ń fi inú kan bá ara wọn lò.
6 Àfàìmọ̀ ni kò fi ní jẹ́ pé Módékáì wà lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba ní Ṣúṣánì. Òun àtàwọn ìránṣẹ́ ọba míì máa ń jókòó sí ẹnu ibodè tó wọ ààfin déédéé. (Ẹ́sít. 2:19, 21; 3:3) A kò fi bẹ́ẹ̀ mọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ẹ́sítérì ń dàgbà, àmọ́ ó dájú pé ó tọ́jú Módékáì tó kù ní baba fún un dáadáa, ó sì ń ṣètọ́jú ilé. Ó jọ pé apá ibi tí àwọn tálákà ń gbé, ní òdìkejì odò tó ṣàn gba ààfin kọjá, ni ilé wọn wà. Ó ṣeé ṣe kó fẹ́ràn láti máa lọ sí ọjà tó wà ní Ṣúṣánì, níbi tí àwọn alágbẹ̀dẹ tó ń fi góòlù àti fàdákà ṣe ohun ọ̀ṣọ́ àti àwọn oníṣòwò pàtẹ ọjà wọn sí. Kò sí ohun tó máa mú kí Ẹ́sítérì ronú pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí òun á ní ànító àti àníṣẹ́kù àwọn ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yẹn. Kò mọ bí ìyípadà tó ń bọ̀ wá dé bá ìgbésí ayé rẹ̀ á ṣe pọ̀ tó.
Ó “Lẹ́wà ní Ìrísí”
7. Kí nìdí tí ọba fi yọ Fáṣítì kúrò nípò ayaba? Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?
7 Lọ́jọ́ kan, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í rojọ́ kiri nípa ọ̀rọ̀ kan tó ń jà ràn-ìn ní ààfin ọba ní Ṣúṣánì. Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ahasuwérúsì Ọba se àsè ńlá kan tó sì fi oúnjẹ àti ọtí wáìnì rẹpẹtẹ kó àwọn ìjòyè rẹ̀ lẹ́nu jọ, ó ránṣẹ́ pe Fáṣítì ayaba rẹ̀ tó rẹwà. Fáṣítì náà wà níbi tó ti ń ṣe àríyá pẹ̀lú àwọn obìnrin, àmọ́ ó kọ̀ láti jẹ́ ìpè ọba. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti ọba lójú gan-an, ó sì mú inú bí i. Torí náà, ó ní kí àwọn agbani-nímọ̀ràn òun sọ ìyà tí wọ́n rò pé ó tọ́ kí òun fi jẹ Fáṣítì. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn? Ńṣe ni ọba yọ ọ́ kúrò ní ipò ayaba. Àwọn ìránṣẹ́ ọba wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri ilẹ̀ náà láti wá àwọn wúńdíá tó rẹwà, kí ọba lè yan èyí tó máa jẹ́ ayaba tuntun lára wọn.—Ẹ́sít. 1:1–2:4.
8. (a) Bí Ẹ́sítérì ṣe ń dàgbà, kí ló lè mú kí Módékáì máà ṣàníyàn nípa rẹ̀? (b) Báwo lo ṣe rò pé a lè fi òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ nípa ẹwà ojú sílò? (Tún wo Òwe 31:30.)
8 Ó ṣeé ṣe kí orí Módékáì máa wú ní gbogbo ìgbà tó bá ṣáà ti ń rí Ẹ́sítérì. Àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún lè máa ṣàníyàn ní báyìí tí ọmọ èèyàn rẹ̀ kékeré ọjọ́sí yìí ti wá dàgbà di òrékelẹ́wà tí kò lẹ́gbẹ́. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọ̀dọ́bìnrin náà sì rẹwà ní wíwò, ó sì lẹ́wà ní ìrísí.” (Ẹ́sít. 2:7) Bíbélì ò bẹnu àtẹ́ lu ẹwà ojú, àmọ́ ó sọ pé ó yẹ kéèyàn ní ọgbọ́n àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè mú kéèyàn jọra ẹ lójú, kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, tàbí kéèyàn máa hu àwọn ìwà míì tí kò dára. (Ka Òwe 11:22.) Ṣé ìwọ náà gbà pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn? Àmọ́, irú èèyàn wo ni ẹwà máa sọ Ẹ́sítérì dà, ṣé ó máa wúlò fún un ni àbí ó máa ṣàkóbá fún un? Ọjọ́ iwájú ló máa sọ.
9. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ọba rí Ẹ́sítérì? Kí nìdí tó fi máa ṣòro fún Ẹ́sítérì láti fi Módékáì sílẹ̀? (b) Kí nìdí tí Módékáì fi gbà pé kí Ẹ́sítérì fẹ́ ẹni tí kì í ṣe Júù, tó tún jẹ́ abọ̀rìṣà? (Tún wo àpótí.)
9 Àwọn ìránṣẹ́ ọba rí Ẹ́sítérì pé ó jẹ́ arẹwà, wọ́n sì kó o mọ́ àwọn arẹwà yòókù tí wọ́n rí. Bó ṣe di pé wọ́n mú un kúrò lọ́dọ̀ Módékáì nìyẹn, tí wọ́n sì mú un lọ sí ààfin ńlá tó wà ní òdìkejì odò. (Ẹ́sít. 2:8) Ó dájú pé ó máa ṣòro fún àwọn méjèèjì láti ya ara wọn, torí pé ńṣe ni wọ́n dà bíi bàbá àti ọmọ. Kò ní wu Módékáì pé kí Ẹ́sítérì tó dà bí ọmọ fún un yìí fẹ́ aláìgbàgbọ́, kódà kó jẹ́ ọba, àmọ́ ọ̀rọ̀ náà kọjá agbára rẹ̀.b Ó dájú pé gbogbo ìmọ̀ràn tí Módékáì fún Ẹ́sítérì ló máa fetí sí dáadáa kó tó di pé wọ́n mú un lọ. Bí wọ́n ṣe ń mú un lọ sí ààfin tó wà ní Ṣúṣánì, oríṣiríṣi ìbéèrè lá máa jà gùdù lọ́kàn rẹ̀. Báwo ni nǹkan á ṣe rí fún un tó bá débẹ̀?
Ó Rí ‘Ojú Rere Gbogbo Àwọn Tó Ń Rí I’
10, 11. (a) Kí ló lè yára ṣẹlẹ̀ sí Ẹ́sítérì ní àyíká tuntun tó bá ara rẹ̀ yìí? (b) Báwo ni Módékáì ṣe fi hàn pé ọ̀ràn Ẹ́sítérì jẹ òun lógún?
10 Ẹ́sítérì bá ara rẹ̀ ní ibi tí kò dé rí, tó sì tún yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ó wà láàárín “àwọn ọ̀dọ́bìnrin púpọ̀” tí wọ́n ṣà jọ jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Àṣà, èdè àti ìwà wọn máa yàtọ̀ síra gan-an ni. Wọ́n fi àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà sábẹ́ àbójútó ìránṣẹ́ ọba kan tó ń jẹ́ Hégáì, kí wọ́n lè fún gbogbo wọn ní ìtọ́jú ẹwà fún odindi ọdún kan gbáko. Èyí gba pé kí wọ́n máa fi àwọn òróró tó ń ta sánsán wọ́ra fún wọn. (Ẹ́sít. 2:8, 12) Ibi tí àwọn ọ̀dọ́bìnrin yìí wà àti irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé níbẹ̀ lè mú kí ọ̀rọ̀ ìrísí ara yára gbà wọ́n lọ́kàn. Ó lè mú kí wọ́n máa bára wọn díje kí wọ́n sì jọra wọn lójú. Kí nìyẹn mú kí Ẹ́sítérì ṣe?
11 Kò sí ẹni tí ọ̀rọ̀ Ẹ́sítérì máa jẹ́ lógún tó Módékáì. Bíbélì sọ pé ojoojúmọ́ ló máa ń lọ sí itòsí ilé àwọn obìnrin. Ó máa ń sún mọ́ ibẹ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, kó lè mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún Ẹ́sítérì. (Ẹ́sítérì 2:11) Bí àwọn ìránṣẹ́ tó gba ti Módékáì ní agboolé ọba ṣe ń fún un ní ìsọfúnni díẹ̀díẹ̀ nípa Ẹ́sítérì, ńṣe ni orí rẹ̀ á máa wú. Kí nìdí?
12, 13. (a) Báwo ni àwọn tó sún mọ́ Ẹ́sítérì ṣe ń ṣe sí i? (b) Kí nìdí tí inú Módékáì á fi dùn nígbà tó gbọ́ pé Ẹ́sítérì ò tíì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé Júù ni òun?
12 Inú Hégáì dùn sí Ẹ́sítérì débi pé ó ṣe ojú rere tó pọ̀ gan-an sí i, ó fún un ní ìránṣẹ́bìnrin méje àti ibi tó dára jù lọ nínú ilé àwọn obìnrin. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Ní gbogbo àkókò yìí, Ẹ́sítérì ń bá a lọ ní jíjèrè ojú rere ní ojú gbogbo àwọn tí ó bá rí i.” (Ẹ́sít. 2:9, 15) Ṣé torí ẹwà nìkan ni gbogbo èèyàn ṣe fẹ́ràn Ẹ́sítérì tó bẹ́ẹ̀? Rárá o, ohun míì wà tó mú kí wọ́n fẹ́ràn Ẹ́sítérì.
13 Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Ẹ́sítérì kò tíì sọ nípa àwọn ènìyàn rẹ̀ tàbí nípa àwọn ìbátan rẹ̀, nítorí Módékáì fúnra rẹ̀ ti gbé àṣẹ kalẹ̀ fún un pé kí ó má sọ.” (Ẹ́sít. 2:10) Módékáì ti sọ fún ọmọbìnrin náà pé kò gbọ́dọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Júù ni òun. Ó ní láti jẹ́ pé Módékáì ti rí i pé àwọn tó ń ṣe ẹ̀tanú sáwọn èèyàn òun wà lára àwọn èèyàn ọba Páṣíà. Torí náà, ńṣe ni inú Módékáì á máa dùn pé bí Ẹ́sítérì ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ òun mọ́, ó ṣì jẹ́ ọlọgbọ́n àti onígbọràn.
14. Báwo ní àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí ṣe lè ṣe bíi ti Ẹ́sítérì?
14 Àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí náà lè mú inú àwọn òbí àti àwọn alágbàtọ́ wọn dùn. Ó lè ṣẹlẹ̀ pé wọn ò sí níbi tí ojú àwọn òbí wọn ti lè tó wọn. Irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ sì lè máa gbé ní àárín àwọn tí kò láròjinlẹ̀, àwọn oníṣekúṣe, tàbí àwọn oníjàgídíjàgan. Síbẹ̀, wọ́n lè ṣàì kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ kí wọ́n sì máa ṣe ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó tọ́. Tí wọ́n bá ṣe bíi ti Ẹ́sítérì, wọ́n á mú ọkàn Baba wọn ọ̀run yọ̀.—Ka Òwe 27:11.
15, 16. (a) Kí ló mú kí ọba nífẹ̀ẹ́ Ẹ́sítérì? (b) Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún Ẹ́sítérì láti máa ṣe bí ayaba?
15 Nígbà tó kan Ẹ́sítérì láti lọ rí ọba, wọ́n yọ̀ǹda fún un láti mú ohunkóhun tó bá rí pé ó máa wúlò fún òun, bóyá láti túbọ̀ gbé ẹwà rẹ̀ yọ. Àmọ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Ẹ́sítérì ò jẹ́ kó béèrè kọjá ohun tí Hégáì ní kó lò. (Ẹ́sít. 2:15) Kí nìdí? Ó ṣeé ṣe kó ti kíyè sí i pé òun ò lè torí ẹwà nìkan rí ojú rere ọba àti pé ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló máa ṣe pàtàkì jù lọ ní ààfin tí òun wà yẹn. Ṣé èrò Ẹ́sítérì tọ̀nà?
16 Bíbélì sọ pé: “Ọba sì wá nífẹ̀ẹ́ Ẹ́sítérì ju gbogbo àwọn obìnrin yòókù lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì jèrè ojú rere àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ púpọ̀ sí i níwájú rẹ̀ ju gbogbo àwọn wúńdíá yòókù. Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi ìwérí ayaba sí i ní orí, ó sì fi í ṣe ayaba dípò Fáṣítì.” (Ẹ́sít. 2:17) Bí Ẹ́sítérì ṣe di ìyàwó ọba tó lágbára jù lọ láyé ìgbà yẹn nìyẹn o! Gẹ́gẹ́ bí ayaba tuntun, ó máa ṣòro fún ọmọbìnrin Júù tó níwà ìrẹ̀lẹ̀ yìí láti máa ṣe bí ayaba. Ǹjẹ́ Ẹ́sítérì jẹ́ kí ipò tuntun yìí kó sí òun lórí, kó sì wá máa gbéra ga? Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀!
17. (a) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe ń bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí bàbá tó gbà á tọ́? (b) Kí nìdí tí àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì fi ṣe pàtàkì fún wa lóde òní?
17 Ẹ́sítérì ń bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí Módékáì tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀. Kò sọ fún ẹnikẹ́ni pé Júù lòun. Yàtọ̀ síyẹn, Módékáì sọ fún Ẹ́sítérì pé àwọn kan ń pète pèrò láti pa Ahasuwérúsì Ọba. Ẹ́sítérì ò kọ̀ sí Módékáì lẹ́nu, ó fi ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ náà tó ọba létí. Ọwọ́ ba àwọn tó ń pète láti pa ọba, ìmọ̀ wọn sì dòfo. (Ẹ́sít. 2:20-23) Bákan náà, Ẹ́sítérì ṣì ń bá a nìṣó láti máa lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó ń hùwà ìrẹ̀lẹ̀, ó sì jẹ́ onígbọràn. Lóde òní táwọn èèyàn ò ka jíjẹ́ onígbọràn sí nǹkan pàtàkì mọ́, tí àìgbọràn àti ìṣọ̀tẹ̀ sì gbayé kan, ó ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì. Àwọn èèyàn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ ka jíjẹ́ onígbọràn sí ohun iyebíye gẹ́gẹ́ bí Ẹ́sítérì ti ṣe.
Àdánwò Ló Jẹ́ fún Ìgbàgbọ́ Ẹ́sítérì
18. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Módékáì fi kọ̀ láti tẹrí ba fún Hámánì? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Lóde òní, báwo ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ní ìgbàgbọ́ ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Módékáì?
18 Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Hámánì di ẹni ńlá láàfin Ahasuwérúsì. Ọba yan Hámánì sí ipò tó ga jù lọ ní ilẹ̀ ọba náà, ó fi í ṣe olórí agbani-nímọ̀ràn àti igbá kejì rẹ̀. Ọba tiẹ̀ tún pàṣẹ pé gbogbo ẹni tó bá rí olóyè yìí gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún un. (Ẹ́sít. 3:1-4) Ó ṣòro fún Módékáì láti pa àṣẹ yẹn mọ́. Ó mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí ọba, àmọ́ kì í ṣe débi tí òun á fi ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Òótọ́ kan ni pé ọmọ Ágágì ni Hámánì. Ìyẹn fi hàn pé àtọmọdọ́mọ Ágágì, ìyẹn ọba Ámálékì tí Sámúẹ́lì wòlíì Ọlọ́run pa, ni ọ̀gbẹ́ni yìí. (1 Sám. 15:33) Àwọn ọmọ Ámálékì yìí burú débi pé wọ́n sọ ara wọn di ọ̀tá Jèhófà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, ẹni tí ìparun tọ́ sí lójú Ọlọ́run ni gbogbo àwọn ọmọ Ámálékì.c (Diu. 25:19) Báwo wá ni Júù kan tó jẹ́ adúróṣinṣin á ṣe máa tẹrí ba fún Hámánì tó jẹ́ ará Ámálékì? Módékáì ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ó kọ̀ láti tẹrí ba fún un. Títí dòní, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ní ìgbàgbọ́ ti fi ẹ̀mí ara wọn jin ikú torí kí wọ́n lè tẹ̀ lé ìlànà inú Bíbélì tó sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.
19. Kí ni Hámánì fẹ́ ṣe? Báwo ló ṣe yí ọba lérò pa dà?
19 Inú bí Hámánì gan-an. Àmọ́ kò wù ú kó jẹ́ pé Módékáì nìkan ló máa wá ọ̀nà láti pa. Ńṣe ló fẹ́ pa gbogbo àwọn èèyàn Módékáì run! Kí Hámánì bàa lè yí ọba lérò pa dà, ó sọ̀rọ̀ àwọn Júù láìdáa. Kò dárúkọ wọn fún ọba, àmọ́ ó jẹ́ kí ọba rí wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Ó pè wọ́n ní àwọn èèyàn “tí a tú ká, tí a sì yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ènìyàn.” Èyí tó tún wá burú jù níbẹ̀ ni bó ṣe sọ pé wọn kò pa àwọn àṣẹ ọba mọ́, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ paraku. Ó sọ pé òun máa san owó púpọ̀ jaburata sínú ibi ìṣúra ọba, kí wọ́n lè ná an láti fi pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní ilẹ̀ ọba náà run.d Ahasuwérúsì fún Hámánì ní òrùka àmì àṣẹ rẹ̀ pé kó fi lu àṣẹ èyíkéyìí tó bá ní lọ́kàn láti pa ní òǹtẹ̀.—Ẹ́sít. 3:5-10.
20, 21. (a) Nígbà tí Módékáì àti gbogbo àwọn Júù tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Páṣíà gbọ́ ìkéde tí Hámánì ṣe, báwo ló ṣe rí lára wọn? (b) Kí ni Módékáì bẹ Ẹ́sítérì pé kó ṣe?
20 Kò pẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ fi bẹ̀rẹ̀ sí í gun ẹṣin sáré lọ sí ibi gbogbo ní ilẹ̀ ọba gbígbòòrò náà, tí wọ́n sì ń jíṣẹ́ tó já sí ìdájọ́ ikú fáwọn Júù. Ẹ fojú inú wo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára àṣẹ́kù àwọn Júù tó kúrò ní ìgbèkùn ní Bábílónì nígbà tí wọ́n gbọ́ ní iyànníyàn Jerúsálẹ́mù, níbi tí wọ́n ti ń sapá láti ṣàtúnkọ́ ìlú tí kò tíì ní ògiri tó lè dáàbò bò ó. Nígbà tí Módékáì gbọ́ ìròyìn tó ń bani lẹ́rù yìí, ó ṣeé ṣe kó ronú nípa àwọn àṣẹ́kù yìí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó wà ní Ṣúṣánì. Torí pé inú rẹ̀ bà jẹ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ, ó ku eérú sórí, ó sì ń sunkún kíkankíkan ní àárín ìlú náà. Àmọ́ ní ti Hámánì, ó jókòó ti ọba, wọ́n jọ ń mutí, kò bìkítà rárá nípa ìbànújẹ́ tó dá sílẹ̀ láàárín àwọn Júù tó pọ̀ rẹpẹtẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn tó wà ní Ṣúṣánì.—Ka Ẹ́sítérì 3:12–4:1.
21 Módékáì mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ kí ló lè ṣe sí i? Ẹ́sítérì gbọ́ nípa bí Módékáì ṣe ń banú jẹ́, ó sì fi aṣọ ránṣẹ́ sí i, àmọ́ ìyẹn ò tu Módékáì nínú. Ó lè ti máa ṣe kàyéfì tipẹ́ nípa ìdí tí Jèhófà, Ọlọ́run rẹ̀, fi yọ̀ǹda pé kí wọ́n mú Ẹ́sítérì ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, kí wọ́n sì sọ ọ́ di ayaba fún alákòóso tó jẹ́ abọ̀rìṣà. Ó wá jọ pé ìdí náà ti ń ṣe kedere bọ̀ báyìí. Módékáì ránṣẹ́ sí Ẹ́sítérì ayaba pé kó lọ bẹ ọba, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbèjà “àwọn ènìyàn rẹ̀.”—Ẹ́sít. 4:4-8.
22. Kí nìdí tí ẹ̀rù fi ba Ẹ́sítérì láti lọ bá ọba tó jẹ́ ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
22 Àyà Ẹ́sítérì ti ní láti já nígbà tó gbọ́ nǹkan tí Módékáì ní kó ṣe. Àdánwò ńlá lèyí jẹ́ fún ìgbàgbọ́ Ẹ́sítérì. Bó ṣe dá Módékáì lóhùn láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fi hàn pé ẹ̀rù bà á. Ó rán Módékáì létí òfin ọba pé téèyàn bá tọ ọba Páṣíà lọ láìjẹ́ pé ọba ké sí i, ńṣe ni wọ́n máa pa á. Àyàfi bí ọba bá na ọ̀pá aládé wúrà rẹ̀ sí ẹni náà ni ikú fi máa yẹ̀ lórí rẹ̀. Ṣé ó wá yẹ kí Ẹ́sítérì ronú pé ọba máa fi àánú hàn sí òun lọ́nà yẹn, àgàgà tó bá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Fáṣítì nígbà tó kọ̀ láti jẹ́ ìpè ọba nígbà tí ọba pàṣẹ pé kó wá? Ẹ́sítérì sọ fún Módékáì pé ọba kò tíì pe òun láti ọgbọ̀n ọjọ́ sẹ́yìn! Níwọ̀n bó ti pẹ́ díẹ̀ tí ọba ti pa Ẹ́sítérì tì, ìdí púpọ̀ wà fún un láti máa ṣiyè méjì pé bóyá ọba tí èrò rẹ̀ lè yí pa dà nígbàkigbà yìí kò gba tòun mọ́.e—Ẹ́sít. 4:9-11.
23. (a) Kí ni Módékáì sọ kó lè fún ìgbàgbọ́ Ẹ́sítérì lókun? (b) Kí nìdí tí Módékáì fi yẹ lẹ́ni tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
23 Módékáì dá Ẹ́sítérì lóhùn láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ láti fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun. Ó sọ fún un pé bí kò bá ṣe ohun tó yẹ, àwọn Júù á rí ìgbàlà láti ibòmíì. Àmọ́, báwo ni Ẹ́sítérì ṣe lè rò pé inúnibíni náà máa yọ òun sílẹ̀ tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í le ju bó ṣe wà yẹn lọ? Lọ́nà yìí, Módékáì fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà pé kò ní jẹ́ kí wọ́n pa àwọn èèyàn rẹ̀ run, kò sì ní jẹ́ kí àwọn ìlérí rẹ̀ kùnà. (Jóṣ. 23:14) Módékáì tún wá bi Ẹ́sítérì pé: “Ta sì ni ó mọ̀ bóyá nítorí irú àkókò yìí ni ìwọ fi dé ipò ọlá ayaba?” (Ẹ́sít. 4:12-14) Ǹjẹ́ kò wá yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Módékáì? Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pátápátá. Ṣé àwa náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá?—Òwe 3:5, 6.
Ìgbàgbọ́ Tó Borí Ìbẹ̀rù Ikú
24. Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà?
24 Ní báyìí, ọ̀rọ̀ ti dójú ẹ̀ fún Ẹ́sítérì. Ó ní kí Módékáì sọ fún àwọn Júù pé kí wọ́n bá òun gbààwẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí ó bá ṣe pé èmi yóò ṣègbé, èmi yóò ṣègbé.” (Ẹ́sít. 4:15-17) Títí di òní, gbogbo àwọn tó ń gbọ́ gbólóhùn yìí ló gbà pé Ẹ́sítérì fi ìgbàgbọ́ àti ìgboyà hàn. Ó dájú pé ó ti ní láti gbàdúrà kíkankíkan láàárín ọjọ́ mẹ́ta yẹn ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àmọ́ níkẹyìn, àkókò tó láti lọ rí ọba. Ó wọ èyí tó dára jù lọ nínú àwọn aṣọ oyè rẹ̀, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ìrísí rẹ̀ lè wu ọba. Lẹ́yìn náà, ó lọ sọ́dọ̀ ọba.
25. Sọ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ bí Ẹ́sítérì ṣe yọ sí ibi tí ọkọ rẹ̀ wà.
25 Bá a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí, Ẹ́sítérì forí lé ibi tí ọba ń gúnwà sí nínú ààfin. Ẹ wo bí oríṣiríṣi èrò á ṣe kún inú ọkàn rẹ̀ tó, táá sì máa gbàdúrà kíkankíkan bó ṣe ń lọ. Ó wọ inú àgbàlá tó wà nínú ààfin, ó sì dúró síbi tó ti lè rí Ahasuwérúsì lórí ìtẹ́ rẹ̀. Bóyá ńṣe ló ń gbìyànjú láti wo bí ojú ọba ṣe rí láàárín irun orí rẹ̀ tó máa ń wé wálẹ̀ àti irùngbọ̀n rẹ̀ tó máa ń gún régé bí wọ́n bá dì í tán, kó lè fi òye mọ ohun tó ń rò. Tó bá sì ní láti dúró kó tó rí ọba, ńṣe ló máa dà bíi pé ó ti pẹ́ jù. Láìpẹ́ láìjìnnà, ọkọ rẹ̀ rí i. Ó dájú pé èyí ya ọba lẹ́nu, àmọ́ ìrísí ojú rẹ̀ fi hàn pé ó yọ́nú sí Ẹ́sítérì. Ó na ọ̀pá aládé wúrà rẹ̀ sí i!—Ẹ́sít. 5:1, 2.
26. Kí nìdí tí àwa Kristẹni tòótọ́ fi nílò ìgboyà bíi ti Ẹ́sítérì? Kí ló fi hàn pé Ẹ́sítérì ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe?
26 Ọba ti ṣe tán báyìí láti fetí sí ohun tí Ẹ́sítérì fẹ́ sọ. Ẹ́sítérì ti múra tán láti ṣojú fún Ọlọ́run rẹ̀ kó sì gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀. Láti ìgbà yẹn wá títí di òní, ọ̀nà tó gbà lo ìgbàgbọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ tó gbámúṣé fún gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Lóde òní, àwa Kristẹni tòótọ́ mọyì irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀. Jésù sọ pé ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ làwọn èèyàn máa fi mọ àwọn tó jẹ́ ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn òun. (Ka Jòhánù 13:34, 35.) Ó sábà máa ń gba pé ká ní ìgboyà bíi ti Ẹ́sítérì ká tó lè fi irú ìfẹ́ yìí hàn. Àmọ́, lẹ́yìn tí Ẹ́sítérì ti múra tán láti gbèjà àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́jọ́ yẹn, ó ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe. Báwo ló ṣe máa mú kí ọba gbà pé elétekéte ni Hámánì tó jẹ́ agbani-nímọ̀ràn tí ọba fẹ́ràn jù lọ? Báwo ló ṣe máa mú kí ikú yẹ̀ lórí àwọn èèyàn rẹ̀? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí ní orí tó kàn.
a Ọ̀pọ̀ ló gbà pé Ahasuwérúsì náà ló ń jẹ́ Sásítà Kìíní, tó ṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Páṣíà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
b Wo àpótí náà, “Ohun Tí Àwọn Kan Béèrè Nípa Ẹ́sítérì,” ní Orí 16.
c Ìgbà ayé Hesekáyà Ọba ni wọ́n ti pa “àṣẹ́kù” àwọn ọmọ Ámálékì, torí náà, ó ṣeé ṣe kí Hámánì wà lára àwọn tó gbẹ̀yìn pátápátá lára wọn.—1 Kíró. 4:43.
d Hámánì sọ pé òun á fún ọba ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] tálẹ́ńtì fàdákà. Lóde òní, iye yẹn tó ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù dọ́là. Tó bá jẹ́ pé Ahasuwérúsì yìí ni Sásítà Kìíní, owó tí Hámánì sọ yìí ti ní láti wọ̀ ọ́ lójú. Ìdí ni pé Sásítà nílò owó rẹpẹtẹ tó máa ná sórí ogun tó ti wà lọ́kàn rẹ̀ tipẹ́ láti bá ilẹ̀ Gíríìsì jà, síbẹ̀ kò rọ́wọ́ mú nínú ogun náà.
e Sásítà Kìíní jẹ́ onínúfùfù, ìgbàkigbà ni èrò rẹ̀ sì lè yí pa dà. A rí àpẹẹrẹ èyí nínú ìtàn tí òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tó ń jẹ́ Herodotus kọ nípa ogun tí Sásítà bá ilẹ̀ Gíríìsì jà. Sásítà pàṣẹ pé kí wọ́n to ọkọ ojú omi sí ẹgbẹ́ ara wọn láti fi ṣe afárá sórí odò Hellespont. Nígbà tí ìjì ba afárá náà jẹ́, Sásítà pàṣẹ pé kí wọ́n bẹ́ orí àwọn ẹnjiníà tó ṣe afárá náà. Ó tiẹ̀ tún ní kí àwọn ìránṣẹ́ òun máa kó ẹgba bo odò Hellespont kí wọ́n sì máa ṣépè lé e lórí bíi ká sọ pé wọ́n ń fìyà jẹ omi odò náà. Lákòókò yìí kan náà, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wá bẹ Sásítà pé kó máà jẹ́ kí wọ́n mú ọmọ òun wọṣẹ́ ológun. Àmọ́, ńṣe ni Sásítà ní kí wọ́n gé ọmọ náà sí méjì, kí wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí gbangba kó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn míì.