Jobu Lo Ìfaradà—Àwa Pẹ̀lú Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀!
“Wò ó! Awọn wọnnì tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀.”—JAKỌBU 5:11, NW.
1. Kí ni Kristian àgbàlagbà kan sọ nípa àwọn àdánwò rẹ̀?
‘ÈṢÙ ń lépa à mi! Mo nímọ̀lára gẹ́gẹ́ bíi ti Jobu!’ Pẹ̀lú irú àwọn ọ̀rọ̀ báwọ̀nyí, A. H. Macmillan sọ ìmọ̀lára rẹ̀ jáde fún ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan ní orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Arákùnrin Macmillan parí ipa-ọ̀nà rẹ̀ ti orí ilẹ̀-ayé ní ẹni ọdún 89 ní August 26, 1966. Ó mọ̀ pé èrè fún iṣẹ́-ìsìn àfòtítọ́ṣe ti àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró bíi ti òun yóò máa “bá wọn lọ ní tààràtà.” (Ìṣípayá 14:13, NW) Ní tòótọ́, wọn yóò máa bá iṣẹ́-ìsìn wọn nìṣó sí Jehofa láìsọsẹ̀ nípasẹ̀ àjíǹde sí ìyè àìleèkú ní ọ̀run. Inú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dùn pé Arákùnrin Macmillan gba èrè yẹn. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ọjọ́ ogbó bẹ̀rẹ̀ sí dé sí i lórí ilẹ̀-ayé, onírúurú àwọn ìdánwò ni ó yí i ká, èyí tí ó ní nínú àwọn ìṣòro àìlera tí ó mú kí ó mọ̀ dájú nípa ìsapá Satani láti ba ìwàtítọ́ òun sí Ọlọrun jẹ́.
2, 3. Ta ni Jobu?
2 Nígbà tí Arákùnrin Macmillan wí pé òun nímọ̀lára gẹ́gẹ́ bíi ti Jobu, ó ń tọ́kasí ọkùnrin kan tí ó ti farada àwọn àdánwò ńlá ti ìgbàgbọ́. Jobu gbé ní “ilẹ̀ Usi,” tí ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ ní gúúsù Arabia. Àtọmọdọ́mọ Ṣemu ọmọkùnrin Noa ni, ó jẹ́ olùjọsìn Jehofa. Ó dàbí ẹni pé àwọn àdánwò Jobu wáyé láàárín ikú Josefu àti àkókò tí Mose fi araarẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin. Ní àkókò yẹn kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ èkejì Jobu ní ayé níti ìfọkànsìn Ọlọrun. Jehofa wo Jobu gẹ́gẹ́ bí ẹni aláìlábàwọ́n, adúróṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọrun.—Jobu 1:1, 8.
3 Gẹ́gẹ́ bí ‘ẹni tí ó pọ̀ ju gbogbo àwọn ọmọ ará ìlà-oòrùn lọ,’ Jobu ní ìránṣẹ́ púpọ̀, àwọn ohun-ọ̀sìn rẹ̀ sì tó 11,500. Ṣùgbọ́n ọrọ̀ tẹ̀mí ni ó jẹ ẹ́ lógún jùlọ. Bíi ti àwọn bàbá tí wọ́n jẹ́ oníwà-bí-Ọlọrun lónìí, ó ṣeéṣe kí Jobu ti kọ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèje àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nípa Jehofa. Àní lẹ́yìn tí wọn kò gbé inú ilé rẹ̀ mọ́, ó ń ṣe bí àlùfáà ìdílé nípa rírúbọ fún wọn, nítorí a kìí mọ̀ wọ́n ti lè dẹ́ṣẹ̀.—Jobu 1:2-5.
4. (a) Èéṣe tí àwọn Kristian tí a ń ṣe inúnibíni sí fi níláti gbé ọ̀ràn ọkùnrin náà Jobu yẹ̀wò? (b) Nípa Jobu, àwọn ìbéèrè wo ni a lè gbéyẹ̀wò?
4 Jobu jẹ́ ẹnìkan tí ó yẹ fún àwọn Kristian tí a ń ṣe inúnibíni sí láti gbéyẹ̀wò kí wọn baà lè fún araawọn lókun fún ìfaradà tí sùúrù ń bá rìn. Ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu kọ̀wé pé, “Wò ó! Awọn wọnnì tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nipa ìfaradà Jobu ẹ sì ti rí àbárèbábọ̀ tí Jehofa mú wá, pé Jehofa jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jakọbu 5:11, NW) Bíi ti Jobu, àwọn ẹni-àmì-òróró ọmọlẹ́yìn Jesu àti àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti òde-òní nílò ìfaradà láti lè kojú àwọn àdánwò ìgbàgbọ́. (Ìṣípayá 7:1-9, NW) Tóò, àwọn àdánwò wo ní Jobu faradà? Èéṣe tí wọ́n fi wáyé? Báwo sì ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú àwọn ìrírí rẹ̀?
Àríyànjiyàn Kánjúkánjú Kan
5. Bí Jobu kò tilẹ̀ mọ̀ rárá, kí ni ó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run?
5 Bí Jobu kò tilẹ̀ mọ̀ rárá, àríyànjiyàn ńlá kan ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run. Lọ́jọ́ kan “àwọn ọmọ Ọlọrun wá í pé níwájú Oluwa.” (Jobu 1:6) Ọmọkùnrin olùfẹ́ ọ̀wọ́n sí Ọlọrun, Ọ̀rọ̀ náà, wà níbẹ̀. (Johannu 1:1-3) Àwọn áńgẹ́lì olódodo àti àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn “ọmọ Ọlọrun” sì pésẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú. (Genesisi 6:1-3) Satani pẹ̀lú wà níbẹ̀, nítorí pé ìléjáde rẹ̀ kúrò ní ọ̀run kí yóò wáyé títí di ẹ̀yìn ìgbà tí a bá fi ìdí Ìjọba náà múlẹ̀ ní 1914. (Ìṣípayá 12:1-12, NW) Ní ọjọ́ Jobu, Satani yóò gbé àríyànjiyàn kánjúkánjú kan dìde. Kò ní pẹ́ gbé ìbéèrè dìde sí ẹ̀tọ́ ipò ọba-aláṣẹ Jehofa lórí gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá Rẹ̀.
6. Kí ni Satani ń gbìyànjú láti ṣe, báwo ni ó sì ṣe ba orúkọ Jehofa jẹ́?
6 Jehofa béèrè pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Satani fèsì pé: “Ní ìlọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀-ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.” (Jobu 1:7) Ó ti ń wá ẹnìkan tí yóò pajẹ. (1 Peteru 5:8, 9) Nípa bíba ìwàtítọ́ àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ń ṣiṣẹ́sin Jehofa jẹ́, Satani yóò gbìyànjú láti lè fihàn pé kò sí ẹnìkan tí ìfẹ́ yóò sún láti ṣègbọràn sí Ọlọrun délẹ̀délẹ̀. Ní dídáhùn sí àríyànjiyàn náà, Jehofa bi Satani pé: “Ìwọ ha kíyèsí Jobu ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí èkejì rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòótọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, tí ó sì kórìíra ìwà búburú.” (Jobu 1:8) Jobu kún ojú ìwọ̀n àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n àtọ̀runwá tí ó fàyèsílẹ̀ fún àwọn àìpé rẹ̀. (Orin Dafidi 103:10-14) Ṣùgbọ́n Satani fi ìbínú fèsì pé: “Jobu ha bẹ̀rù Oluwa ní asán bí? Ìwọ kò ha ti sọgbà yí i ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ síi ní ilẹ̀.” (Jobu 1:9, 10) Eṣu tipa báyìí ba orúkọ Jehofa jẹ́ nípa dídọ́gbọ́n sọ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ tí ó sì ń sìn Ín nítorí oun tí Ó jẹ́ ṣùgbọ́n pé Ó ń fún àwọn ìṣẹ̀dá ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti lè ṣiṣẹ́sìn Ín. Satani fẹjọ́ sùn pé Jobu ń ṣiṣẹ́sin Ọlọrun nítorí àǹfààní ìmọtara-ẹni-nìkan, kìí ṣe láti inú ìfẹ́.
Satani Gbógun Tì Í!
7. Ní ọ̀nà wo ni Eṣu gbà pe Ọlọrun níjà, báwo sì ni Jehofa ṣe fèsìpadà?
7 Satani wí pé, “Ǹjẹ́ nawọ́ rẹ nísinsìnyí, kí o sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ní; bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.” Báwo ni Ọlọrun yóò ṣe fèsìpadà sí irú ìpèníjà tí ń fẹ̀gbin lọni bẹ́ẹ̀? Jehofa wí pé, “Kíyèsí i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkaraarẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.” Eṣu ti wí pé gbogbo ohun-ìní Jobu ni a bùkún, ni a mú pọ̀ sí i, tí a sì sọgbà yíká. Ọlọrun yóò fàyègba Jobu láti jìyà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbọdọ̀ fọwọ́kan ara rẹ̀. Ní pípinnu láti hùwà ibi, Satani fi àpéjọ náà sílẹ̀.—Jobu 1:11, 12.
8. (a) Àwọn ìpàdánù ohun-ìní ti ara wo ni Jobu ní ìrírí rẹ̀? (b) Kí ni òtítọ́ náà nípa “iná ńlá Ọlọrun”?
8 Láìpẹ́, Satani bẹ̀rẹ̀ ìgbóguntì rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jobu fún un ní ìròyìn burúkú yìí: “Àwọn ọ̀dá-màlúù ń túlẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀bá wọn; àwọn ará Saba sì kọlù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lù wọ́n ti fi idà ṣá àwọn ìránṣẹ́ pa.” (Jobu 1:13-15) A ti wó ọgbà tí ó yí dúkìá Jobu ká palẹ̀. Ká wí ká fọ̀, agbára ẹ̀mí-èṣù wọ̀ ọ́, nítorí pé ìránṣẹ́ mìíràn ròyìn pé: “Iná ńlá Ọlọrun ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùtàn àti àwọn ìránṣẹ́ ní àjórun.” (Jobu 1:16) Ẹ wo bí ó ti burúbèṣù tó láti mú kí ó dàbí ẹni pé Ọlọrun ni ó wà lẹ́yìn irú àjálù bẹ́ẹ̀ àní èyí tí ń já lé àwọn ìránṣẹ́ tirẹ̀ alára lórí! Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé láti ọ̀run ni mànàmáná ti ń wá, a bá ti lè fi tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn dá Jehofa lẹ́bi, ṣùgbọ́n níti gidi iná náà wá láti orísun kan tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí-èṣù.
9. Báwo ni ọ̀rọ̀-ajé tí ó wọmi ṣe kan ipò-ìbátan Jobu pẹ̀lú Ọlọrun?
9 Bí Satani ṣe ń bá ìgbóguntì rẹ̀ nìṣó, ìránṣẹ́ mìíràn ròyìn pé àwọn ará Kaldea ti kó àwọn ìbakasíẹ Jobu lọ wọ́n sì ti pa gbogbo àwọn ìránṣẹ́. (Jobu 1:17) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọrọ̀-ajé Jobu wọmi, èyí kò ba ipò-ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọrun jẹ́. Ìwọ ha lè farada ìpàdánù ohun-ìní tabua láìba ìwàtítọ́ rẹ sí Jehofa jẹ́ bí?
Arabaríbí Ìjàm̀bá Ṣẹlẹ̀
10, 11. (a) Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Jobu mẹ́wẹ̀ẹ̀wá? (b) Lẹ́yìn ikú bíbaninínújẹ́ àwọn ọmọ Jobu, ojú wo ni ó fi wo Jehofa?
10 Eṣu kò tíì dẹ̀yìn lẹ́yìn Jobu. Síbẹ̀ ìránṣẹ́ mìíràn ròyìn pé: “Àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin ń jẹ wọ́n ń mu ọtí-wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọ́n ọkùnrin. Sì kíyèsí i, ẹ̀fúùfù ńláǹlà ti ìhà ijù fẹ́ wá íkọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wólu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkanṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.” (Jobu 1:18, 19) Àwọn aláìlóye lè sọ pé ‘àmúwá Ọlọrun’ ni ìparun tí ẹ̀fúùfù náà fà. Bí ó ti wù kí ó rí, agbára ẹ̀mí-èṣù ti kan Jobu ní ibi ẹlẹgẹ́ gidigidi.
11 Ìbànújẹ́ bá a, Jobu “fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fárí rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì gbàdúrà.” Síbẹ̀, tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. “Oluwa fifúnni Oluwa sì gbà lọ, ìbùkún ni orúkọ Oluwa.” Àkọsílẹ̀ náà fikún un pé: “Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi wèrè pé Ọlọrun lẹ́jọ́.” (Jobu 1:20-22) Satani tún fìdírẹmi lẹ́ẹ̀kan síi. Bí àwa náà bá nírìírí ọ̀fọ̀ àti ẹ̀dùn-ọkàn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọrun ń kọ́? Ìfọkànsìn aláìnímọtara-ẹni-nìkan sí Jehofa àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ lè mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti lo ìfaradà gẹ́gẹ́ bí olùpa ìwàtítọ́ mọ́, gẹ́gẹ́ bí Jobu ti ṣe. Dájúdájú àwọn ẹni-àmì-òróró àti àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wọn tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀-ayé lè rí ìtùnú àti okun gbà láti inú àkọsílẹ̀ nípa ìfaradà Jobu yìí.
Àríyànjiyàn náà Ń Gbóná Síi
12, 13. Níbi àpéjọ mìíràn ní ọ̀run, kì ni ohun tí Satani béèrè fún, báwo sì ni Ọlọrun ṣe fèsìpadà?
12 Kò pẹ́ kò jìnnà, Jehofa tún pe àpéjọ mìíràn ní ààfin àjùlé ọ̀run. Jobu ti di ọkùnrin aláìlọ́mọ, tí a sọ di òtòṣì, tí ó dàbí ẹni pé Ọlọrun ń pọ́n lójú, ṣùgbọ́n ìwàtítọ́ rẹ̀ kò yingin. Àmọ́ ṣáá o, Satani kò ní gbà pé èké ni àwọn ẹ̀sùn tí òun fi kan Ọlọrun àti Jobu. Wàyí o, ó tó àkókò kí “àwọn ọmọ Ọlọrun” tẹ́tísí ìjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìjiyànpadà bí Jehofa yóò ṣe máa dọ́gbọ́n darí Eṣu láti mú àríyànjiyàn náà wá sí ìpàdé ìdíjemọ̀gá.
13 Láti gbọ́ tẹnu Satani, Jehofa béèrè pé: “Níbo ni ìwọ ti wá?” Kí ni èsì rẹ̀? “Láti ìlọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.” Lẹ́ẹ̀kan síi, Jehofa darí àfiyèsí sí Jobu aláìlábàwọ́n, adúróṣinṣin, ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, ẹni tí ó ṣì di ìwàtítọ́ rẹ̀ mú ṣinṣin. Eṣu fèsì pé: “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, ohun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀. Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsìnyí, kí o sì fi tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.” Nítorí náà Ọlọrun wí pé: “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.” (Jobu 2:2-6) Ní pípẹ́ ẹ sọ pé Jehofa kò tíì mú gbogbo ohun ìdènà ewu kúrò síbẹ̀síbẹ̀, Satani béèrè fún fífọwọ́ kan egungun àti ẹran-ara Jobu. A kì yóò gba Eṣu láyè láti pa Jobu; ṣùgbọ́n Satani mọ̀ pé àrùn ara-ìyára yóò dùn ún yóò sì mú kí ó dàbí ẹni pé ó ń jìyà látọwọ́ Ọlọrun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀.
14. Kí ni Satani fi sọ Jobu, èésìtiṣe tí kò fi sí ẹ̀dá ènìyàn kankan tí ó lè fún òjìyà náà ní ìtura?
14 Bí a ṣe lé e kúrò ní àpéjọ yẹn, Satani ń bá ìwà-ìkà rírorò tí ń dùn mọ́ ọn nìṣó. Ó fi “oówo kíkankíkan” sọ Jobu “láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ lọ dé àtàrí rẹ̀.” Ẹ wo irú ìrora gógó tí Jobu faradà bí ó ti jókòó sínú eérú tí ó sì ń fi àpáàdì ha araarẹ̀! (Jobu 2:7, 8) Kò sí ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó jẹ́ oníṣègùn tí ó lè mú ìtura wá fún un kúrò nínú àìsàn onírora burúkú, tí ń rínilára, tí ó sì ń tẹ́nilógo yìí, nítorí pè agbára Satani ni ó fà á. Jehofa nìkanṣoṣo ni ó lè wo Jobu sàn. Bí ìwọ bá jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun kan tí o sì ń ṣàìsàn, máṣe gbàgbé láé pé Ọlọrun lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lo ìfaradà ó sì lè fún ọ ní ìyè nínú ayé titun kan tí ó bọ́ lọ́wọ́ àrùn.—Orin Dafidi 41:1-3; Isaiah 33:24.
15. Kí ni aya Jobu rọ̀ ọ́ láti ṣe, kí sì ni ìhùwàpadà rẹ̀?
15 Paríparí rẹ̀, aya Jobu wí pé: “Ìwọ di ìwà òtítọ́ rẹ mú síbẹ̀! bú Ọlọrun kí o sì kú.” “Ìwà òtítọ́” ń tọ́kasí ìfọkànsìn aláìlábàwọ́n, ó sì ti lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tí kò báradé láti lè mú kí Jobu bú Ọlọrun. Ṣùgbọ́n ó fèsì pé: “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan nínú àwọn obìnrin aláìmòye ti í sọ̀rọ̀; kínla! àwa ó ha gba ire lọ́wọ́ Ọlọrun, kí a má sì gba ibi!” Àní ọ̀nà-àdàkàdekè Satani yìí kò ṣiṣẹ́, nítorí a ti sọ fún wa pé: “Nínú gbogbo èyí Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.” (Jobu 2:9, 10) Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí ń ṣàtakò ba sọ pé a wulẹ̀ ń fi ìwà òmùgọ̀ lo araawa lépo dànù lásán nínú àwọn ohun ìlépa ti Kristian tí wọ́n sì rọ̀ wá láti kọ Jehofa Ọlọrun sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Jobu, a lè farada irú àdánwò bẹ́ẹ̀ nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jehofa a sì lọ́kàn-ìfẹ́ láti yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.—Orin Dafidi 145:1, 2; Heberu 13:15.
Àwọn Agbéraga Ẹlẹ̀tàn Mẹ́ta
16. Àwọn wo ni wọ́n wá, tí wọ́n sì ṣe bí ẹni fẹ́ tu Jobu nínú, ṣùgbọ́n báwo ni Satani ṣe dọ́gbọ́n darí wọn?
16 Nínú ohun mìíràn tí ó jọbí ìwéwèé Satani mìíràn, àwọn “ọ̀rẹ́” mẹ́ta wá, wọ́n sì farahàn bí ẹni fẹ́ tu Jobu nínú. Ọ̀kan lára wọn ní Elifasi, tí ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Abrahamu nípasẹ̀ Esau. Níwọ̀n bí Elifasi ti ní àǹfààní sísọ̀rọ̀ ṣáájú, kò sí iyèméjì pé òun ni ó dàgbà jù àwọn yòókù lọ. Bildadi, àtọmọdọ́mọ Ṣua, ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin tí Ketura bí fún Abrahamu náà wà níbẹ̀. Ọkùnrin kẹta ni Sofari, tí a pè ní ará Naama láti lè mọ ìdílé rẹ̀ tàbí ibùgbé rẹ̀, bóyá ní apá ìwọ̀-oòrùn gúúsù Arabia. (Jobu 2:11; Genesisi 25:1, 2; 36:4, 11) Bí àwọn wọnnì tí wọ́n gbìyànjú láti mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kọ Ọlọrun sílẹ̀ lónìí, Satani dọ́gbọ́n darí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí nínú ìsapá láti mú kí Jobu gbà pé òun jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn èké kí ó sì ba ìwàtítọ́ rẹ̀ jẹ́.
17. Kí ni ohun tí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n wá ṣèbẹ̀wò náà ṣe, kí ni wọn kò sì ṣe fún ọ̀sán méje àti òru méje?
17 Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà fakọyọ níti ìbánikẹ́dùn nípa sísọkún, fífa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn ya, àti kíku eruku sí orí araawọn. Síbẹ̀ náà wọ́n jókòó ti Jobu fún ọ̀sán méje àti òru méje láìsọ ọ̀rọ̀ ìtùnú kankan! (Jobu 2:12, 13; Luku 18:10-14) Àwọn agbéraga ẹlẹ̀tàn mẹ́ta wọ̀nyí ti pàdánù ipò tẹ̀mí wọn tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò fi ní ọ̀rọ̀ ìtùnú kankan láti sọ nípa Jehofa àti àwọn ìlérí rẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n dé ìparí èrò tí kò tọ̀nà wọ́n sì ṣetán láti lò wọ́n lòdìsí Jobu ní gẹ́rẹ́ tí wọ́n ba ti lè ṣetán pẹ̀lú fífi ẹ̀dùn ọkàn hàn ní gbangba gẹ́gẹ́ bí àṣà. Ó dùnmọ́ni pé, ṣáájú kí ọjọ́ méje píparọ́rọ́ náà to parí, ọ̀dọ́mọkùnrin náà Elihu jókòó síbi tí ó ti lè máa gbọ́ wọn.
18. Èéṣe tí Jobu fi tọrọ ikú kí ara baà lè tù ú?
18 Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín Jobu fọhùn. Níwọ̀n bí kò ti rí ìtùnú kankan gbà láti inú ìbẹ̀wò àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà, ó fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré ó sì ṣe kàyéfì nípa ìdí tí a fi mú ìwàláàyè bíbaninínújẹ́ rẹ̀ gùn tóbẹ́ẹ̀. Ó tọrọ ikú kí ara baà lè tù ú, kò tilẹ̀ ronú pé òun tún lè ní ìdùnnú tòótọ́ gidi mọ́ ṣáájú ikú òun, nísinsìnyí ó ti di abòṣì, aṣọ̀fọ̀, àti ẹni tí àìsàn lílekoko ń ṣe. Ṣùgbọ́n Ọlọrun kò ní gbà kí a fọwọ́kan Jobu débi tí yóò fi yọrísí ikú.—Jobu 3:1-26.
Àwọn Olùfisùn Jobu Gbógun Tì Í
19. Ní àwọn ọ̀nà wo ní Elifasi gbà fi ẹ̀sùn èké kan Jobu?
19 Elifasi ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nígbà abala ìjíròrò mẹ́ta tí ó dán ìwàtítọ́ Jobu wò síwájú síi. Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀, Elifasi béèrè pé: “Níbo ni a gbé ké olódodo kúrò rí?” Ó dé ìparí èrò náà pé Jobu ti níláti hùwà ibi kí ó tó lè jìyà bẹ́ẹ̀ látọwọ́ Ọlọrun. (Jobu, orí 4, 5) Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ẹ̀ẹ̀kejì, Elifasi bu ẹnu àtẹ́ lu ọgbọ́n Jobu ó sì bi í pé: “Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀?” Elifasi ń dọ́gbọ́n sọ pé Jobu ń gbìyànjú láti fi araarẹ̀ hàn bí ẹni tí ó ga ju Olodumare lọ. Ní píparí ìkọlù rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, ó fi Jobu hàn bí ẹni tí ó jẹ̀bi ìpẹ̀yìndà, àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àti ìtànjẹ. (Jobu, orí 15) Nínú ọ̀rọ̀ àsọparí rẹ̀, Elifasi fi ẹ̀sùn èké kan Jobu lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ọ̀daràn—ìlọ́nilọ́wọ́gbà, fífi búrẹ́dì àti omi du àwọn aláìní, àti fífìyàjẹ àwọn opó àti ọmọ òrukàn.—Jobu, orí 22.
20. Ní ọ̀nà wo ni Bildadi gbà ṣàtakò sí Jobu?
20 Ní sísọ̀rọ̀ ṣìkejì nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìjiyàn mẹ́ta náà, Bildadi sábà máa ń tẹ̀lé ẹṣin-ọ̀rọ̀ tí Elifasi fi lélẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ Bildadi kò gùn púpọ̀ ṣùgbọ́n wọ́n ń gúnnilára ju ti ẹni ìṣáájú lọ. Ó tilẹ̀ fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ Jobu fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́ tí wọ́n sì tìpa bẹ́ẹ̀ yẹ fún ikú. Pẹ̀lú ojú-ìwòye òdì, ó lo àpèjúwe yìí: Bí koríko odò àti eèsú ṣe ń gbẹ tí wọ́n sì ń kú bí kò bá sí omi, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí pẹ̀lú fún “gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọrun.” Òtítọ́ ní gbólóhùn ọ̀rọ̀ yẹn, ṣùgbọ́n kò bá a mu nínú ọ̀ràn Jobu. (Jobu, orí 8) Bildadi ka ìpọ́njú Jobu sí irú èyí tí ń wá sórí àwọn ènìyàn búburú. (Jobu, orí 18) Nínú ọ̀rọ̀ kúkúrú rẹ̀ kẹta, Bildadi jiyàn pé “ìdin” àti “kòkòrò” ni ènìyàn jẹ́ ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ aláìmọ́ lójú Ọlọrun.—Jobu, orí 25.
21. Ẹ̀sùn wo ni Sofari fi kan Jobu?
21 Sofari ni ẹnìkẹta tí ó sọ̀rọ̀ nínú ìjiyàn náà. Látòkèdélẹ̀, ipa ọ̀nà ìrònú rẹ̀ tẹ̀lé ti Elifasi àti Bildadi. Sofari fi ẹ̀sùn ìwà búburú kan Jobu ó sì rọ̀ ọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. (Jobu, orí 11, 20) Lẹ́yìn ìgbà méjì Sofari dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ. Kò ní ohunkóhun tí ó lè fikún un nígbà kẹta. Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín gbogbo àkókò ìjiyàn yìí, Jobu dá àwọn olùfisùn rẹ̀ lóhùn tìgboyà-tìgboyà. Fún àpẹẹrẹ, ó wí fún wọn nígbà kan pé: “Ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ni gbogbo yín. Ọ̀rọ̀ asan lè ní òpin?”—Jobu 16:2, 3.
A Lè Lo Ìfaradà
22, 23. (a) Bí ó ti rí nínú ọ̀ràn Jobu, báwo ní Eṣu ṣe lè máa lọ káàkiri láti ba ìwàtítọ́ wa sí Jehofa Ọlọrun jẹ́? (b) Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé Jobu ń farada onírúurú àwọn ìdánwò, kí ni a lè béèrè nípa ìṣarasíhùwà rẹ̀?
22 Gẹ́gẹ́ bíi ti Jobu, a lè dojúkọ àdánwò tí ó ju ẹyọkan lọ lẹ́ẹ̀kan, Satani sì lè lo ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí àwọn kókó-abájọ mìíràn nínú ìsapá rẹ̀ láti ba ìwàtítọ́ wa jẹ́. Ó lè gbìyànjú láti kẹ̀yìn wa sí Jehofa bí a bá ní ìdààmú níti ọrọ̀-ajé. Bí olólùfẹ́ kan bá kú tàbí bí a bá ní àìlera ara, Satani lè gbìyànjú láti sún wa láti da Ọlọrun lẹ́bi. Bíi ti àwọn ọ̀rẹ́ Jobu, ẹnìkan tilẹ̀ lè parọ́ mọ́ wa. Bí Arákùnrin Macmillan ṣe sọ, Satani lè máa ‘lépa wa,’ ṣùgbọ́n a lè lo ìfaradà.
23 Bí a ti ṣe kíyèsí i láti ìbẹ̀rẹ̀, Jobu ń lo ìfaradà nínú onírúurú àdánwò tí ó débá a. Bí ó ti wù kí ó rí, òun ha wulẹ̀ ń faradà á lásán ni bí? Ó ha ní ìròbìnújẹ́ ọ̀kan níti tòótọ́ bí? Ẹ jẹ kí a wò ó bí ó bá jẹ́ pé nítòótọ́ ni Jobu ti sọ ìrètí nú pátápátá.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsìpadà?
◻ Àríyànjiyàn ńlá wo ni Satani gbé dìde ní ọjọ́ Jobu?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni a gbà dán Jobu wò dé òpin?
◻ Ẹ̀sùn wo ni àwọn “ọ̀rẹ́” Jobu mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi kàn án?
◻ Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí nínú ọ̀ràn Jobu, báwo ni Satani ṣe lè gbìyànjú láti ba ìwàtítọ́ wa sí Jehofa jẹ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
A. H. Macmillan