Iṣẹda Sọ Pe, ‘Wọn Wà Ni Àìríwí’
“Ohun rẹ̀ ti o farasin lati ìgbà dídá ayé a ri wọn gbangba, a ń fi òye ohun ti a dá mọ̀ ọ́n, àní agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ ayeraye, ki wọn ki o lè wà ni àìríwí.”—ROMU 1:20.
1, 2. (a) Awawi kikoro wo ni Jobu ṣe fun Jehofa? (b) Ìyíhùnpadà wo ni Jobu wa ṣe tẹlee?
JOBU, ọkunrin ìgbà atijọ kan ti ó ní iwatitọ ti kò ṣeebajẹ si Jehofa Ọlọrun, ni Satani ti fi sabẹ idanwo lilekoko. Eṣu ti mú ki Jobu padanu gbogbo ohun-ìní rẹ̀ nipa ti ara, o ti fa iku awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin rẹ̀, o sì ti fi arun oniwọsi kọlù ú. Jobu lero pe Ọlọrun ni o ń mú gbogbo ìyọnu wọnyi wá sori oun, ó sì ṣaroye fun Jehofa lọna kikoro pe: “O ha tọ́ si ọ ti iwọ ìbá maa tẹ̀mọ́lẹ̀, . . . ti iwọ fi ń beere aiṣedeedee mi, ti iwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí? Iwọ mọ̀ pe emi kìí ṣe oniwa-buburu.”—Jobu 1:12-19; 2:5-8; 10:3, 6, 7.
2 Ni akoko diẹ lẹhin eyi, awọn ọ̀rọ̀ Jobu si Ọlọrun fi odikeji èrò patapata hàn: “Emi . . . ń sọ eyi ti emi kò mọ̀, ohun ti o ṣe iyanu jọjọ niwaju mi, ti emi kò moye. Emi ti fi gbígbọ́ etí gburoo rẹ, ṣugbọn nisinsinyi oju mi ti ri ọ. Ǹjẹ́ nitori naa emi koriira araami, mo sì ronupiwada ninu ekuru ati eérú.” (Jobu 42:3, 5, 6) Ki ni ti ṣẹlẹ lati yí iṣarasihuwa Jobu pada?
3. Oju-iwoye titun wo ni Jobu gbà nipa iṣẹda?
3 Bi akoko ti ń lọ, Jehofa ti ko Jobu loju ninu ìjì àjàyíká. (Jobu 38:1) O ti da ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ibeere bo Jobu. ‘Nibo ni iwọ wà nigba ti mo fi ipilẹ ayé sọlẹ̀? Ta ni o fi ilẹkun sé omi òkun mọ́ ti o sì pààlà ibi ti ìgbì rẹ̀ gbọdọ dé? Iwọ ha lè mú ki awọsanmọ rọ òjò si ilẹ̀-ayé bi? Iwọ ha lè mú kí koriko hù? Iwọ ha lè so awọn ìdìpọ̀-ìràwọ̀ pọ̀ ki o sì ṣamọna wọn sipa ọ̀nà wọn bi?’ Jalẹjalẹ ori 38 si 41 ninu iwe Jobu, Jehofa rọ̀jò awọn ibeere wọnyi ati pupọ sii nipa iṣẹda Rẹ̀ sori Jobu. Ó mú ki Jobu rí àlàfo gbàràmù gbaramu ti o wà laaarin Ọlọrun ati eniyan, ti o sì fi bẹẹ rán Jobu létí ọgbọ́n ati agbára ti o farahan ninu iṣẹda Ọlọrun lọna lilagbara, awọn ohun ti o kọja agbara Jobu lati ṣe tabi lati loye paapaa. Jobu, ẹni ti agbára ati agbayanu ọgbọ́n Ọlọrun olodumare amunikun fun ibẹru ọlọ́wọ̀ bò gẹgẹ bi a ti fihàn ninu awọn iṣẹda Rẹ̀, ni ẹ̀rù bà lati ronu pe oun ti ní igboju lati bá Jehofa jiyan. Nitori naa ó wi pe: “Emi ti fi gbígbọ́ etí gburoo rẹ, ṣugbọn nisinsinyi oju mi ti rí ọ.”—Jobu 42:5.
4. Ki ni a gbọdọ loye lati inu awọn iṣẹda Jehofa, ki sì ni ipo-ọran naa ti rí pẹlu awọn wọnni ti wọn kuna lati ri i?
4 Ní ọpọ ọrundun lẹhin naa onkọwe Bibeli kan ti a mísí jẹ́rìí síi pe awọn animọ Jehofa ni a lè rí nipasẹ awọn iṣẹda rẹ̀. Aposteli Paulu kọwe ninu Romu 1:19, 20 pe: “Ohun ti a lè mọ̀ niti Ọlọrun o farahan ninu wọn; nitori Ọlọrun ti fi í hàn fun wọn. Nitori ohun rẹ̀ ti o farasin lati ìgbà dídá ayé a ri wọn gbangba, a ń fi òye ohun ti a dá mọ̀ ọn, àní agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ ayeraye, ki wọn ki o lè wà ni àìríwí.”
5. (a) Aini abinibi wo ni awọn eniyan ní, bawo sì ni awọn kan ṣe ń kájú rẹ̀ lọna ti kò tọ́? (b) Ki ni idamọran Paulu fun awọn Griki ni Ateni?
5 A dá eniyan pẹlu aini adanida kan lati jọsin agbara giga ju kan. Dokita C. G. Jung, ninu iwe rẹ̀ The Undiscovered Self, tọka si aini yii gẹgẹ bi “iṣarasihuwa ọgbọ́n-inú ti o wọpọ laaarin eniyan, iṣagbeyọ rẹ̀ ni a sì lè tọpa rẹ̀ la ìtàn iran eniyan já.” Aposteli Paulu sọ nipa isunniṣe abinibi eniyan lati jọsin, eyi ti o ṣalaye idi ti awọn ara Griki ní Ateni fi ṣe awọn ère ati pẹpẹ fun ọpọlọpọ awọn ọlọrun, eyi ti a mọ̀ ati eyi ti a kò mọ̀. Paulu tun fi Ọlọrun tootọ naa hàn wọn ó sì fi hàn wọn pe wọn gbọdọ tẹ́ isunniṣe abinibi yii lọrun daradara nipa wíwá Jehofa Ọlọrun otitọ naa, “boya bi ọkàn wọn bá lè fà sí i, ti wọn sì rí i, bi o tilẹ ṣe pe kò jìnnà si olukuluku wa.” (Iṣe 17:22-30) Gẹgẹ bi a bá ṣe sunmọ awọn iṣẹda rẹ̀ tó, bẹẹ gan-an ni a ṣe sunmọ kikiyesi awọn animọ ati awọn ìwà-ẹ̀yẹ rẹ̀ tó.
Agbayanu Àyípoyípo Omi
6. Awọn animọ Jehofa wo ni a rí ninu àyípoyípo omi?
6 Awọn animọ Jehofa wo ni a rí, fun apẹẹrẹ, ninu agbára-ìṣiṣẹ́ awọsanmọ múlọ́múlọ́ lati gba ọpọlọpọ tọọnu omi duro? A ri ifẹ ati ọgbọ́n rẹ̀, nitori ti o tipa bayii pese fífọ́n òjò fun ibukun ilẹ̀-ayé. Ó ṣe eyi nipasẹ ìṣẹ́-ọnà agbayanu ti ó wémọ́ àyípoyípo omi, ti a mẹnukan ninu Oniwasu 1:7: “Odò gbogbo ni ń ṣàn sinu òkun; ṣugbọn òkun kò kún, nibi ti awọn odò ti ń ṣàn wá, nibẹ ni wọn sì tun pada lọ.” Iwe Bibeli ti Jobu sọ pàtó nipa bi ó ti ń ṣẹlẹ.
7. Bawo ni omi ṣe ń ti òkun dé oju awọsanmọ, bawo sì ni awọsanmọ múlọ́múlọ́ ṣe lè gba ọpọ tọọnu omi duro?
7 Nigba ti awọn odò bá ṣàn sinu òkun, wọn kìí duro sibẹ. Jehofa “fa ìkán omi lati inu òkun ó sì ń pọn òjò lati inu ikuuku ti ó ti ṣe.” Nitori pe omi naa dàbi oruku omi ti o sì di ìkùukùu daradara kan nikẹhin, “awọsanmọ sorọ̀ jẹẹ, iṣẹ iyanu òye rẹ̀ ti ó pé.” (Jobu 36:27; 37:16; The New English Bible) Awọsanmọ léfòó niwọn bi wọn ti jẹ́ ìkùukùu: “Ó di omi pọ̀ ninu awọsanmọ rẹ̀—ìkùukùu kò sì gbọ̀nya nitori ìwúwo wọn.” Tabi gẹgẹ bi itumọ miiran ṣe sọ: “Ó sé omi mọ́ ninu awọn okiti awọsanmọ dídì, awọsanmọ kò si gbọ̀nya nitori ìwúwo wọn.”—Jobu 26:8, The Jerusalem Bible; NE.
8. Nipa awọn igbesẹ yiyatọ wo ni ‘awọn ìsà omi ọ̀run’ ṣe ń da omi ti a sì ń pari àyípoyípo omi?
8 ‘Awọn ìṣà ọ̀run,’ wọnyi ‘ta ni ó lè dà wọn jade’ lati mú ki òjò rọ̀ sori ilẹ̀-ayé? (Jobu 38:37) Ẹni naa ti “iṣẹ iyanu òye” rẹ̀ fi wọn sibẹ lakọọkọ ni, ẹni ti ó “pọn òjò lati inu ìkùukùu ti o ti ṣe.” Ki sì ni a nilo lati pọn òjò lati inu ìkùukùu? Ohun líle kékeré bín-ń-tín, iru bi awọn egúnrín eruku—lati ori ẹgbẹẹgbẹrun si ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun wọn ninu igbọnwọ inṣi kọọkan afẹ́fẹ́—lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi ibi ìwọ́jọsí fun kíkán tótó omi lati korajọ yika. A diyele pe ó ń gbà tó million kan ìkán tótó omi lati di òjò ti o mọniwọn. Kiki lẹhin gbogbo idagbasoke wọnyi ni awọsanmọ tó lè da awọn àgbàrá òjò wọn si ilẹ̀-ayé lati di odò ti yoo dá omi naa pada sinu òkun. Nipa bayii àyípoyípo omi naa yoo wá sí ipari rẹ̀. Ǹjẹ́ gbogbo eyi ṣẹlẹ laisi idari bi? “Àìríwí,” gbáà ni!
Orisun kan Niti Ọgbọ́n Solomoni
9. Ki ni Solomoni ri ni àrà-ọ̀tọ̀ nipa iru-ẹ̀yà èèrùn kan?
9 Ni ayé atijọ, ọgbọ́n Solomoni kò ni afiwe. Pupọ ninu ọgbọ́n yẹn kan iṣẹda Jehofa: “[Solomoni] sì sọrọ ti igi, lati kedari ti ń bẹ ni Lebanoni, àní titi de hissopu ti ń hù lara ogiri: ó sì sọ ti ẹranko pẹlu, ati ti ẹyẹ, ati ohun ti ń rákò, ati ti ẹja.” (1 Ọba 4:33) Ọba Solomoni yii kan-naa ni o kọwe pe: “Tọ èèrùn lọ, iwọ ọ̀lẹ: kiyesi iṣẹ rẹ̀, ki iwọ ki o sì gbọ́n: ti kò ni onidaajọ, alaboojuto, tabi alakooso, ti ń pese ounjẹ rẹ̀ ni ìgbà ẹ̀rùn, ti ó sì ń kó ounjẹ rẹ̀ jọ ni ìgbà ikore.”—Owe 6:6-8.
10. Bawo ni apejuwe Solomoni nipa awọn èèrùn olukore ṣe di eyi ti a dalare gẹgẹ bi otitọ?
10 Ta ni o kọ́ awọn èèrùn lati kó ounjẹ jọ ni ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn lati bọ́ wọn ninu ọ̀gìnnìtìn ìgbà òtútù? Fun ọpọ ọrundun ìpéye akọsilẹ Solomoni nipa awọn èèrùn wọnyi ti wọn ká irugbin ti wọn sì kó wọn jọ fun ìlò ni ìgbà òtútù ni a ṣiyemeji rẹ̀. Kò si ẹnikẹni ti o tii rí ẹ̀rí idaniloju eyikeyii nipa wíwà wọn. Bi o ti wu ki o ri, ni 1871, onimọ-ijinlẹ nipa iṣẹda ọmọ ilẹ Gẹẹsi kan, ṣawari awọn ile-akojọ wọn labẹ ilẹ, ìpéye Bibeli nipa rirohin nipa wọn ni a sì dalare. Ṣugbọn bawo ni gbogbo awọn èèrùn wọnyi ṣe jere imọtẹlẹ lati mọ nigba ẹ̀ẹ̀rùn pe ògìnnìtìn ìgbà òtútù ti ń bọ̀ ati ọgbọ́n lati mọ ohun ti wọn nilati ṣe nipa rẹ̀? Bibeli fúnraarẹ̀ ṣalaye pe pupọ ninu awọn iṣẹda Jehofa ní ọgbọ́n ti a ti tolẹsẹẹsẹ sinu wọn fun lilaaja. Awọn èèrùn olùkórè naa ni olùgba ibukun yii lati ọ̀dọ̀ Ẹlẹdaa wọn. Owe 30:24 sọ nipa rẹ̀ pe: “Wọ́n gbọ́n.” Lati sọ pe iru ọgbọ́n bẹẹ wulẹ lè ṣẹlẹ nipa èèṣì kò bọgbọnmu; lati kuna lati woye Ẹlẹdaa ọlọgbọn kan ti ó wà nidii ọ̀ràn naa jẹ́ àìríwí.
11. (a) Eeṣe ti igi sequoia giga fiofio fi jẹ́ amuni kun fun ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀ tobẹẹ? (b) Ki ni o yanilẹnu tobẹẹ gan-an nipa iṣiṣẹpọmọra akọkọ ninu photosynthesis?
11 Ọkunrin kan ti o wà labẹ igi sequoia giga fiofio kan, ti ìṣebatakun rẹ̀ titobilọla yalẹnu, lọna ti o yeni nimọlara dídàbí èèrùn kekere kan. Ìtóbi igi naa jẹ́ agbayanu: 90 mita (300 ẹsẹ bata) ni gíga, mita 11 (ẹsẹ bata 36) ni ìwọ̀n-ìdábùú-òbììrí, èèpo rẹ̀ fi 0.6 mita (ẹsẹ bata 2) nípọn, awọn gbongbo rẹ̀ tànká fun iwọn sarè mẹta si mẹrin. Sibẹ, eyi ti o tubọ yanilẹnu jù ni ti igbekalẹ eroja ati ipa adanida tí idagbasoke rẹ̀ ní ninu. Awọn ewé rẹ̀ ń fa omi lati inu awọn gbongbo, afẹ́fẹ́ carbon dioxide lati inu afẹ́fẹ́, ati agbára-ìṣiṣẹ́ lati inu òòrùn lati ṣe ṣuga ki o sì pese afẹ́fẹ́ oxygen—ilana iṣiṣẹ kan ti a ń pe ni photosynthesis eyi ti o wémọ́ nǹkan bii 70 iṣiṣẹpọmọra kẹmika, ti kìí ṣe gbogbo rẹ̀ ni a loye. Lọna yiyanilẹnu, iṣiṣẹpọmọra akọkọ sinmi lori ìmọ́lẹ̀ lati inu òòrùn eyi ti o ní àwọ̀ tí ó yẹ gan-an, ìgbì afẹ́fẹ́ tí ó yẹ; bi bẹẹ kọ awọn mólékù omiro chlorophyll kì yoo gbà á wọle lati bẹrẹ ilana iṣiṣẹ photosynthesis.
12. (a) Ki ni ó yanilẹnu nipa bi igi sequoia ṣe ń lo omi? (b) Eeṣe ti a fi nilo nitrogen ninu idagbasoke eweko, bawo sì ni o ṣe ń pari àyípoyípo rẹ̀?
12 Eyi ti o tun ń yanilẹnu ni otitọ naa pe igi naa lè fa awọn ọwọ̀n omi lati inu awọn gbongbo lọ si òkè igi gígùn gbannasan ti o fi 90 mita (300 ẹsẹ bata) ga yii. Omi pupọ sii ju eyi ti a nilo fun photosynthesis ni o ń fà soke. Omi ti o ṣẹ́kù ń rin gba inu ewé jade bọ sinu afẹfẹ. Ó mu ki igi naa di eyi ti ó tutù yọ̀yọ̀ bi ìgbà ti òógùn bá mú ara silé. Lati lè ṣe eroja protein fun idagbasoke, a nilati fi afẹ́fẹ́ nitrogen kún ṣuga, tabi carbohydrate. Ewé naa kò lè lo afẹ́fẹ́ nitrogen ti ó fà lati inu afẹ́fẹ́, ṣugbọn awọn ohun ẹlẹmii inu erupẹ lè yí afẹfẹ nitrogen ninu ilẹ naa pada si awọn eroja nitrate ati nitrite ti wọn ṣeéyọ́ ninu omi, eyi ti yoo wá rinrin-ajo nigba naa lati inu awọn gbòǹgbò lọ soke sinu awọn ewé. Nigba ti awọn eweko ati ẹranko ti wọn ti lo eroja nitrogen yii ninu eroja protein wọn bá kú ti wọn sì jẹrà, eroja nitrogen naa ni a óò tú silẹ, ni mímú àyípoyípo eroja nitrogen naa wá si ipari. Ninu gbogbo eyi, ìlọ́júpọ̀ ti o ni ninu jẹ́ amunita gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, kò lè jẹ́ iṣẹ́-òpò kan ti a lè ṣaṣeyọri rẹ̀ laisi iṣeto tabi itọsọna.
Laisi Agbara-Isọrọ Tabi Ọ̀rọ̀ Tabi Ohùn, Wọn Ń Fọhùn!
13. Ki ni ọ̀run ti o kun fun irawọ sọjade fun Dafidi, ki sì ni wọn ń tẹsiwaju lati sọ fun wa?
13 Ẹ wo bi àgbéyọ ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀ Ẹlẹdaa naa ti wá lati inu àṣálẹ́ ti o kúnfọ́fọ́ fun irawọ ti mú awọn oluworan kún fun ọ̀wọ̀ nla tó! Ninu Orin Dafidi 8:3, 4, Dafidi sọ ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀ ti oun nimọlara rẹ̀ jade: “Nigba ti mo ro ọ̀run rẹ, iṣẹ ìka rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ. Ki ni eniyan, ti iwọ fi ń ṣe iranti rẹ̀? Ati ọmọ eniyan, ti iwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?” Fun awọn wọnni ti wọn ni ojú lati fi ríran, etí lati fi gbọ́ràn, ati ọkan-aya lati fi mòye, awọn ọ̀run wọnyi tí wọn kún fun irawọ ń sọrọ, gẹgẹ bi wọn ti ṣe sí Dafidi: “Awọn ọ̀run ń sọrọ ògo Ọlọrun.”—Orin Dafidi 19:1-4.
14. Eeṣe ti agbara-iṣiṣẹ pipabanbari ọ̀kan ninu awọn irawọ fi ṣepataki tobẹẹ fun wa?
14 Bi a bá ṣe ń mọ̀ nipa awọn irawọ sii tó, bẹẹ ni wọn ṣe ń sọrọ soke si wa sii tó. Ni Isaiah 40:26 a késí wa lati ṣakiyesi agbára-ìṣiṣẹ́ wọn pípabanbarì pe: “Gbé oju yin soke sibi giga, ki ẹ si wò, ta ni ó dá nǹkan wọnyi, ti ń mú ogun wọn jade wá ni iye: o ń pe gbogbo wọn ni orukọ nipa titobi ipá rẹ̀, nitori pe oun le ní ipá; kò sí ọ̀kan ti ó kù.” Agbára òòfà-ilẹ̀ ati okun-inu alagbara-iṣẹ́ ọ̀kan lara wọn, òòrùn wa, di ilẹ̀-ayé mú sí ààyè rẹ̀ ninu iyipoyika rẹ̀, ó ń mú ki awọn eweko dagba, ó ń mú wa mooru, ó sì ń mú ki igbesi-aye ṣeeṣe níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé. Aposteli Paulu labẹ imisi sọ pe: “Irawọ sá yatọ si irawọ ni ògo.” (1 Korinti 15:41) Imọ-ijinlẹ mọ̀ nipa awọn irawọ alawọ òféèfé bi òòrùn wa, ati awọn irawọ alawọ búlúù, awọn irawọ òmìrán pupa, kúrékùré funfun, awọn irawọ neutron, ati awọn irawọ abúgbàù mímọ́lẹ̀ ju òòrùn lọ ti ń tú awọn agbara àwámárìídìí sode pẹlu ipá lilagbara.
15. Ki ni pupọ awọn oluhumọ ti kọ́ lati inu iṣẹda ti wọn sì gbiyanju lati farawe?
15 Pupọ awọn oluhumọ ti kẹkọọ lati inu iṣẹda wọn sì ti gbiyanju lati ṣafarawe agbara-iṣe awọn ohun alaaye. (Jobu 12:7-10) Ṣakiyesi kiki apá iṣẹda diẹ kan. Awọn ẹyẹ etí òkun ti wọn ní ẹsẹ̀ ti ń sọ awọn omi òkun di aláìníyọ̀; awọn ẹja ati awọn àdàgbá ti wọn ń pèsè ìtakìjí agbara iná manamana; awọn ẹja, ìdin ati awọn kòkòrò ti ń mú iná adanida jade; awọn àdán ati awọn ẹja lámùṣóò ti ń lo ẹ̀rọ aṣàwárí ohun-abẹ́-omi; agbọ́n ti ń ṣe bébà; awọn èèrùn ti ń kọ́ afárá; awọn ẹranko beaver ti ń kọ́ awọn ìsédò; awọn ejò ti a dá pẹlu adíwọ̀n-ooru-oun òtútù; awọn kòkòrò inu ọ̀gọ̀dọ̀ ti wọn ń lo ọ̀pá oniho afẹ́fẹ́ ati awọn àgógó ti a fi ń lúwẹ̀ẹ́; ẹran omi octopus ti ń lo agbara ìgbọ́kọ̀rìn ayára-bí-àṣá; awọn alantakun ti ń ṣe oriṣi okùn alantakun meje ti o sì ń ṣe awọn ilẹ̀kùn ẹ̀bìtì, àwọ̀n, ati okùn ìso ti o sì ń ní awọn ọmọ ti wọn jẹ́ afò-nínú-afẹ́fẹ́, ti ń rinrin-ajo ẹgbẹẹgbẹrun kilomita loke réré; ẹja ati awọn ẹ̀dá inu omi ti wọn ń lo awọn àgbá omi bii ti awọn ọkọ̀ ogun abẹ́ omi; awọn ẹyẹ, kòkòrò, ijapa inu òkun, awọn ẹja, ati awọn ẹranko afọ́mọlọ́mú ti wọn ń dábírà lọna yiyanilẹnu niti iṣikiri—awọn agbára-òye ti o rekọja agbara imọ-ijinlẹ lati ṣalaye.
16. Awọn otitọ wo nipa imọ-ijinlẹ ni Bibeli ṣakọsilẹ ni ọpọ ẹgbẹẹgbẹrun ọdun ṣaaju ki imọ-ijinlẹ tó ṣawari wọn?
16 Bibeli ṣe akọsilẹ awọn otitọ nitiimọ-ijinlẹ ni ẹgbẹẹgbẹrun ọdun ṣaaju ki imọ-ijinlẹ tó mọ̀ nipa wọn. Ofin Mose (ọrundun kẹrindinlogun B.C.E.) fi imọdaju nipa awọn kòkòrò arun hàn ni ẹgbẹẹgbẹrun ọdun ṣaaju ìgbà Pasteur. (Lefitiku, ori 13, 14) Ní ọrundun kẹtadinlogun B.C.E., Jobu sọ pe: “Oun . . . fi ayé rọ̀ ni ojú òfo.” (Jobu 26:7) Ní ẹgbẹrun ọdun kan ṣaaju akoko Kristi, Solomoni kọwe nipa iwọkiri ẹ̀jẹ̀; imọ-ijinlẹ nipa iṣegun nilati duro titi di ọrundun kẹtadinlogun C.E. lati kọ́ nipa rẹ̀. (Oniwasu 12:6) Ṣaaju iyẹn, Orin Dafidi 139:16 ṣagbeyọ imọ nipa isọfunni inú ara nipa apilẹ̀-àbùdà: “Oju rẹ ti rí ohun ara mi ti o wà laipe: ati ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si, ni ojoojumọ ni a ń dá wọn, nigba ti ọ̀kan wọn kò tii sí.” Ni ọrundun keje B.C.E., ṣaaju ki awọn onimọ-ijinlẹ nipa awọn ohun abẹ̀mí ati ewéko tó ni òye nipa ìṣíkiri, Jeremiah kọwe gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Jeremiah 8:7 pe: “Ẹyẹ àkọ̀ ní oju ọ̀run mọ akoko lati ṣílọ, àdàbà ati ẹyẹ olófèéèré ati irú ẹyẹ àkókó mọ ìgbà lati pada.”—NE.
“Ẹlẹdaa” Tí Awọn Ẹlẹkọọ Ẹfoluṣọn Ń Yàn
17. (a) Ki ni Romu 1:21-23 sọ nipa awọn kan ti wọn kọ̀ lati ri Ẹlẹdaa olóye kan lẹhin awọn iyanu ti a ṣẹ̀dá? (b) Ni ọ̀nà kan, ki ni awọn ẹlẹkọọ ẹfoluṣọn ń yàn gẹgẹ bi “ẹlẹdaa” wọn?
17 Ẹsẹ iwe mimọ kan sọ nipa awọn kan ti wọn kọ̀ lati fi òye mọ̀ nipa Ẹlẹdaa olóye kan ti o wà lẹhin awọn iyanu ti a ṣẹda: “Wọn wá ìdasán ni ironu wọn, a sì mú ọkàn omugọ wọn ṣokunkun. Wọn ń pe araawọn ni ọlọgbọ́n, wọn di aṣiwere, wọn sì pa ògo Ọlọrun tí kìí dibajẹ dà, si aworan ère eniyan tii dibajẹ, ati ti ẹyẹ, ati ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin, ati ohun ti ń rákò.” Wọn “yí otitọ Ọlọrun pada si èké, wọn si bọ, wọn si sin ẹ̀dá ju Ẹlẹdaa lọ.” (Romu 1:21-23, 25) Ó ri bakan-naa pẹlu awọn onimọ-ijinlẹ nipa ẹkọ ẹfoluṣọn, awọn ẹni ti, niti gasikia, wọn fi ògo fun isokọra onípele ti ohun abẹ̀mí tín-ń-tín ti o di ekòló, ti o di ẹja, ti o di ẹranko jomijòkè, ti o di ẹranko afàyàfà, ti o di ẹranko afọ́mọlọ́mú, ti o di “ìnàkí eniyan” gẹgẹ bi “ẹlẹdaa” wọn. Bi o ti wu ki o ri, wọn mọ̀ pe kò si ohun kan lasan ti o jẹ́ ẹlẹmii niti gidi lati bẹrẹ isokọra naa. Ohun ẹlẹmii ti o rọrun julọ ti a mọ̀ ní awọn ọgọrun-un billion atom, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun awọn iṣiṣẹpọmọra kẹmika ti ń ṣẹlẹ laaarin rẹ̀ papọ nigba kan-naa.
18, 19. (a) Ta ni Ẹni yiyẹ naa ti a nilati fi ìyìn iṣẹda iwalaaye fun? (b) Bawo ni awọn iṣẹda Jehofa ti a lè rí ti pọ̀ tó?
18 Jehofa Ọlọrun ni Ẹlẹdaa iwalaaye. (Orin Dafidi 36:9) Oun ni Ẹni nla Akọkọ Ti O Mú Kí Ó Wà. Orukọ rẹ̀, Jehofa, tumọsi “O mú ki ó wà.” A kò lè ka iye awọn iṣẹda rẹ̀. Ni tootọ araadọta-ọkẹ pupọ sii ni o wà ju eyi ti eniyan mọ̀ lọ. Orin Dafidi 104:24, 25 fitonileti nipa eyi pe: “Oluwa, iṣẹ rẹ ti pọ̀ tó! Ninu ọgbọ́n ni iwọ ṣe gbogbo wọn.” Jobu 26:14 sọ gbangba nipa eyi pe: “Kiyesi i, eyi ni opin ọ̀nà rẹ̀, ohùn eyi ti a gbọ́ ti kere tó! Ṣugbọn àrá ipá rẹ̀ ta ni òye rẹ̀ lè ye?” A rí fírífírí diẹ, a gbọ́ fínrín-fínrín niwọnba, ṣugbọn lati loye itumọ àrá rẹ̀ alagbara ni kikun kọja ohun ti a lè mọ̀ lẹkun-un-rẹrẹ.
19 Bi o ti wu ki o ri, a ní orisun ti o tubọ dara kan fun riri i ju nipasẹ awọn iṣẹda rẹ̀ ti a lè fojuri lọ. Orisun didara ju naa ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Orisun yẹn ni a o wá yiju sí ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹlee.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Ki ni Jobu kọ́ nigba ti Jehofa bá a sọrọ lati inu ìjì ajàyíká?
◻ Eeṣe ti Paulu fi sọ pe awọn eniyan kan jẹ́ aláìríwí?
◻ Bawo ni àyípoyípo omi ṣe ń ṣiṣẹ?
◻ Awọn ohun pataki wo ni ìmọ́lẹ̀ òòrùn ń ṣe fun wa?
◻ Awọn otitọ wo nipa imọ-ijinlẹ ni Bibeli ṣipaya ṣaaju ki imọ-ijinlẹ tó ṣawari wọn?