Fiyè Sí Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run
“Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa; kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé.”—SÁÀMÙ 40:5.
1, 2. Àwọn ẹ̀rí wo la ní nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run, kí ló sì yẹ kí èyí sún wa ṣe?
NÍGBÀ tóo bá ka Bíbélì, wàá rí i kedere pé Ọlọ́run ṣe àwọn ohun àgbàyanu fún Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn rẹ̀ ayé ọjọ́un. (Jóṣúà 3:5; Sáàmù 106:7, 21, 22) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀nà yẹn ni Jèhófà gbà ń dá sọ́ràn aráyé báyìí, a ṣì ń rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tó ń fi àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ hàn. Fún ìdí yìí, àwa náà lè sọ bíi ti onísáàmù náà pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe. Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.”—Sáàmù 104:24; 148:1-5.
2 Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni kì í ṣú já tàbí ni kì í kọbi ara sí irú àwọn ẹ̀rí tó ṣe kedere bẹ́ẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá. (Róòmù 1:20) Ṣùgbọ́n, á dáa kí àwa ní tiwa ronú jinlẹ̀ nípa wọn, ká sì dé ìparí èrò tó bọ́gbọ́n mu nítorí ipò wa níwájú Ẹlẹ́dàá wa àti ojúṣe wa sí i. Jóòbù orí 38 sí 41 yóò ràn wá lọ́wọ́ gidigidi nínú ṣíṣe èyí, nítorí pé níbẹ̀ Jèhófà pe àfiyèsí Jóòbù sáwọn apá kan nínú iṣẹ́ àgbàyanu Rẹ̀. Gbé àwọn kókó pàtàkì kan tí Ọlọ́run gbé dìde yẹ̀ wò.
Àwọn Iṣẹ́ Alágbára àti Àgbàyanu
3. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú Jóòbù 38:22, 23, 25-29, kí ni àwọn nǹkan tí Ọlọ́run béèrè ìbéèrè nípa wọn?
3 Nígbà tí ọ̀rọ̀ débì kan, Ọlọ́run bi Jóòbù pé: “Ìwọ ha ti wọ àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ ti ìrì dídì, tàbí ìwọ ha rí àní àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ ti yìnyín, èyí tí mo pa mọ́ de àkókò wàhálà, de ọjọ́ ìjà àti ogun?” Ìrì dídì àti yìnyín kì í ṣàì wáyé láwọn ibi púpọ̀ láyé. Ọlọ́run ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ta ní la ipa ojú ọ̀nà fún ìkún omi àti ọ̀nà fún àwọsánmà ìjì tí ń sán ààrá, láti mú kí ó rọ̀ sórí ilẹ̀ níbi tí ènìyàn kankan kò sí, sórí aginjù nínú èyí tí ará ayé kankan kò sí, láti tẹ́ àwọn ibi tí ìjì kọlù àti ibi ahoro lọ́rùn, kí ó sì mú kí èéhù koríko hù? Òjò ha ní baba, tàbí, ta ní bí ìrì tí ń sẹ̀? Ikùn ta ni omi dídì ti jáde wá ní ti gidi, ní ti ìrì dídì wínníwínní ojú ọ̀run, ta sì ni ó bí i ní tòótọ́?”—Jóòbù 38:22, 23, 25-29.
4-6. Báwo ló ṣe jẹ́ pé òye èèyàn nípa ìrì dídì kò kún?
4 Ní àwọn àgbègbè kan tó jẹ́ pé ìgbésí ayé sáré-n-bájà làwọn èèyàn ń gbé, tó ń béèrè pé kí wọ́n rìnrìn àjò láìsí ìdádúró rárá, wọ́n lè ka ìrì dídì sí ohun tí ń díni lọ́wọ́. Àmọ́, àìmọye àwọn èèyàn ló ka ìrì dídì sí ohun ìdùnnú, tó máa ń mú kí yìnyín tẹ́ rẹrẹ sójú ilẹ̀ lọ́nà àrà, tí àwọn èèyàn á sì máa dá onírúurú àrà lórí rẹ̀. Báa ti ń ronú lórí ìbéèrè Ọlọ́run, ǹjẹ́ o mọ nǹkan tí wọ́n ń pè ní yìnyín dunjú, ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ bó ṣe rí pàápàá? Áà, a mọ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yìnyín ṣe rí kẹ̀, àá ti rí fọ́tò àwọn òkè yìnyín rí, tàbí ká tiẹ̀ ti fojú ara wa rí ọ̀pọ̀ yanturu yìnyín. Àmọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan ìrì wínníwínní dídì tó sẹ̀ pa pọ̀ sójú kan ńkọ́? Ǹjẹ́ o mọ bí wọ́n ṣe rí, bóyá nípa yíyẹ orísun wọn wò?
5 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún làwọn kan ti fi ṣèwádìí, tí wọ́n sì ń ya fọ́tò ìrì wínníwínní dídì. Ìdì kọ̀ọ̀kan lè ní tó ọgọ́rùn-ún egunrín yìnyín fúlẹ́fúlẹ́ tó jẹ́ aláràbarà. Ìwé náà Atmosphere sọ pé: “Ohun táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ni, pé ọ̀kẹ́ àìmọye ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọn ìrì wínníwínní dídì ló wà, bó sì tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti sọ ọ́ lásọtúnsọ pé kò sófin tó ní kò gbọ́dọ̀ sí ìrì wínníwínní dídì méjì tó jọra, síbẹ̀ kò sẹ́ni tó tíì rí méjì tó jọra rí. Wilson A. Bentley . . . fi ohun tó ju ogójì ọdún lo awò-asọhun-kékeré-di-ńlá láti fi ṣèwádìí àti láti fi ya fọ́tò àwọn ìrì wínníwínní dídì tó pọ̀ bíi rẹ́rẹ, kò sì rí méjì tó rí bákan náà rí.” Bó bá sì tiẹ̀ wá di pé a ṣàdédé rí méjì tó jọra, ṣé ìyẹn á wá jẹ́ ká sọ pé ọ̀kan-kò-jọ̀kan wọn tó pọ̀ lọ jàra kì í ṣe ohun àrà mọ́ ni bí?
6 Rántí ìbéèrè Ọlọ́run, pé: “Ìwọ ha ti wọ àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ ti ìrì dídì?” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìkuukùu ni ilé ìrì dídì. Ǹjẹ́ o lè ronú gbígbéra lọ sínú ilé yẹn láti lọ ṣàkọsílẹ̀ ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọn ìrì wínníwínní tó wà, kí o sì wá máa ṣèwádìí nípa bí wọ́n ṣe pilẹ̀? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó dá lórí sáyẹ́ǹsì sọ pé: “Bí èyí tó ṣe bíńtín jù lọ nínú omi dídì ṣe jẹ́ gan-an àti bó tiẹ̀ ṣe máa ń pilẹ̀ kò tíì yéni, bẹ́ẹ̀ sì rèé, òun ló máa ń jẹ́ kí ẹ̀kán omi dì tó bá ti tutù dórí nǹkan bí ogójì nísàlẹ̀ òdo lórí òṣùwọ̀n Celsius (-40°C).”—Sáàmù 147:16, 17; Aísáyà 55:9, 10.
7. Báwo ni òye ọmọ aráyé nípa òjò ti pọ̀ tó?
7 Òjò wá ńkọ́ o? Ọlọ́run bi Jóòbù pé: “Òjò ha ní baba, tàbí, ta ní bí ìrì tí ń sẹ̀?” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan náà tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé: “Bó ṣe jẹ́ pé ọ̀nà tó díjú ni afẹ́fẹ́ gbà ń fẹ́ yí ká, tó sì jẹ́ pé onírúurú làwọn ohun tó para pọ̀ sínú afẹ́fẹ́, ó jọ pé kò ṣeé ṣe láti gbé àbá tó máa ṣe àlàyé kínníkínní kalẹ̀ pé báyìí ni ìkuukùu àti òjò ṣe ń pilẹ̀.” Ká sọ ọ́ lọ́nà tó máa yé tàgbàtèwe, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti gbé oríṣiríṣi àbá kalẹ̀, àmọ́ wọn ò lè ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa òjò. Síbẹ̀, o sáà mọ̀ pé òjò tí ń gbé ìwàláàyè ró ń rọ̀, ó ń bomi rin ilẹ̀ ayé, ó ń mú kí ewéko dàgbà, ó ń jẹ́ kí ohun alààyè wà, kí ayé sì tù wọ́n lára.
8. Èé ṣe tí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù nínú Ìṣe 14:17 fi bá a mu wẹ́kú?
8 Ǹjẹ́ o ò fara mọ́ ibi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù parí èrò sí? Ó rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n fi ohun tí wọ́n rí kọ́ látinú iṣẹ́ àgbàyanu wọ̀nyí ṣe ẹ̀rí nípa Ẹni tó ṣe wọ́n. Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Ìṣe 14:17; Sáàmù 147:8.
9. Báwo làwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run ṣe fi agbára ńlá rẹ̀ hàn?
9 Kò sí àní-àní pé Ẹni tó ṣe irú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tó ṣàǹfààní bẹ́ẹ̀ jẹ́ oníbú ọgbọ́n àti agbára. Ní ti agbára rẹ̀, gba èyí yẹ̀ wò: Wọ́n ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta [45,000] ààrá ló ń sán lóòjọ́, èyí tó ju mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún lọ́dọọdún. Tó túmọ̀ sí pé nǹkan bíi ẹgbàá [2,000] ààrá ló ń sán ní ìṣẹ́jú yìí. Agbára ìbúgbàù tí ń bẹ nínú àgbájọ ìkuukùu tí ń sán ààrá kan ṣoṣo jẹ́ déédéé mẹ́wàá irú bọ́ǹbù átọ́míìkì tí wọ́n jù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì tàbí kó tiẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Lára agbára yẹn ló di mànàmáná tó ń kọ yẹ̀rì tóo máa ń rí. Yàtọ̀ sí pé mànàmáná máa ń dáni níjì, ó tún máa ń mú oríṣiríṣi afẹ́fẹ́ nitrogen jáde, tó máa ń wọnú ilẹ̀ lọ, ìwọ̀nyí sì ni àwọn ewéko máa ń lò gẹ́gẹ́ bí ajílẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, mànàmáná jẹ́ ohun àmúṣagbára tó máa ń bú gbàù, àmọ́ ó tún ṣàǹfààní gidigidi pẹ̀lú.—Sáàmù 104:14, 15.
Ipa Wo Ló Ní Lórí Rẹ?
10. Báwo lo ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nínú Jóòbù 38:33-38?
10 Fi ara rẹ sípò Jóòbù, bí ẹni pé ìwọ ni Ọlọ́run Olódùmarè ń bi ní àwọn ìbéèrè. Wàá gbà pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn kì í sábà fiyè sí àwọn àgbàyanu iṣẹ́ Ọlọ́run. Jèhófà tún béèrè àwọn ìbéèrè táa ó kà nínú Jóòbù 38:33-38. Ó ní: “Ìwọ ha ti wá mọ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ọ̀run, tàbí ìwọ ha lè fi ọlá àṣẹ rẹ̀ lélẹ̀ ní ilẹ̀ ayé? Ìwọ ha lè gbé ohùn rẹ sókè àní dé àwọsánmà, kí ìrọ́sókè-sódò àgbájọ omi lè bò ọ́? Ìwọ ha lè rán mànàmáná jáde, kí wọ́n lè lọ kí wọ́n sì sọ fún ọ pé, ‘Àwa rèé!’? Ta ní fi ọgbọ́n sínú àwọn ipele àwọsánmà, tàbí tí ó fi òye fún ohun àrà ojú sánmà? Ta ní lè fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmà ní pàtó, tàbí àwọn ìṣà omi ọ̀run—ta ní lè mú wọn dà jáde, nígbà tí ekuru dà jáde bí ẹni pé sínú ìṣùpọ̀ tí a mọ, tí àwọn ògúlùtu sì lẹ̀ mọ́ra?”
11, 12. Kí ni díẹ̀ lára ohun tó fi hàn pé Oníṣẹ́ àrà ni Ọlọ́run?
11 A ti mẹ́nu ba ìwọ̀nba díẹ̀ lára nǹkan tí Élíhù pe àfiyèsí Jóòbù sí, a tún ti kíyè sí díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí Jèhófà ní kí Jóòbù dáhùn “bí abarapá ọkùnrin.” (Jóòbù 38:3) “Díẹ̀” la pè é nítorí pé, nínú Jóòbù orí 38 àti 39, Ọlọ́run tún pe àfiyèsí sí àwọn apá pàtàkì mìíràn nínú ìṣẹ̀dá. Bí àpẹẹrẹ, ó mẹ́nu kan àwọn àgbájọ ìràwọ̀ ojú ọ̀run. Ta ló mọ gbogbo òfin tàbí ìlànà wọn? (Jóòbù 38:31-33) Jèhófà tọ́ka Jóòbù sí àwọn ẹranko kan—àwọn ẹranko bíi kìnnìún àti ẹyẹ ìwò, ewúrẹ́ orí òkè àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, akọ màlúù ìgbẹ́ àti ògòǹgò, ẹṣin alágbára àti ẹyẹ idì. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ńṣe ni Ọlọ́run ń bi Jóòbù léèrè bóyá òun ló fún onírúurú ẹranko wọ̀nyí ní ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ní, tó sì wá jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa wà nìṣó, kí wọ́n sì máa bí sí i. O lè gbádùn kíka orí wọ̀nyí, pàápàá tóo bá fẹ́ràn ẹṣin tàbí àwọn ẹranko mìíràn.—Sáàmù 50:10, 11.
12 O tún lè ṣàyẹ̀wò Jóòbù orí 40 àti 41, níbi tí Jèhófà tún ti sọ fún Jóòbù pé kó fèsì àwọn ìbéèrè tí òun ń bí i nípa àwọn ẹranko méjì kan. A mọ àwọn ẹranko wọ̀nyẹn sí erinmi (Béhémótì), tó tóbi fàkìàfakia tó sì ki pọ́pọ́, àti àkòtagìrì ọ̀nì (Léfíátánì) odò Náílì. Kálukú wọn ló jẹ́ ẹ̀dá àgbàyanu tó yẹ fún àfiyèsí. Ẹ wá jẹ́ ká ronú lórí ipa tó yẹ kí nǹkan wọ̀nyí ní lórí wa.
13. Ipa wo ni àwọn ìbéèrè Ọlọ́run ní lórí Jóòbù, ipa wo ló sì yẹ kí nǹkan wọ̀nyí ní lórí wa?
13 Jóòbù orí 42 jẹ́ ká mọ ipa tí àwọn ìbéèrè Ọlọ́run ní lórí Jóòbù. Tẹ́lẹ̀, àfiyèsí tí Jóòbù ń pè sí ara rẹ̀ àti sáwọn ẹlòmíràn ti pàpọ̀jù. Ṣùgbọ́n Jóòbù gba ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run fún un nípasẹ̀ àwọn ìbéèrè náà, ó sì ṣàtúnṣe. Ó jẹ́wọ́ pé: “Mo ti wá mọ̀ pé o [Jèhófà] lè ṣe ohun gbogbo, kò sì sí èrò-ọkàn kankan tí ó jẹ́ aláìṣeélébá fún ọ. ‘Ta nìyí tí ń ṣú òkùnkùn bo ìmọ̀ràn láìní ìmọ̀?’ Nítorí náà, mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kò lóye àwọn ohun tí ó jẹ́ àgbàyanu gidigidi fún mi, èyí tí èmi kò mọ̀.” (Jóòbù 42:2, 3) Bẹ́ẹ̀ ni o, lẹ́yìn tí Jóòbù pe àfiyèsí sí àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run, ó wá sọ pé nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àgbàyanu gidigidi lójú òun. Ó yẹ kí àwọn ohun àrà inú ìṣẹ̀dá, táa mẹ́nu kàn wọ̀nyí, mú kí ọgbọ́n àti agbára Ọlọ́run wú wa lórí. Fún ète wo? Ṣé pé kí ibú agbára Jèhófà àtàwọn ohun tó gbé ṣe kàn wú wa lórí lásán ni? Tàbí ó yẹ kí ipa tó ní lórí wa jù bẹ́ẹ̀ lọ?
14. Ojú wo ni Dáfídì fi wo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run?
14 Dáfídì sọ irú ọ̀rọ̀ báwọ̀nyí nínú Sáàmù 86, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti sọ ṣáájú pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọjọ́ kan tẹ̀ lé ọjọ́ mìíràn ń mú kí ọ̀rọ̀ ẹnu tú jáde, òru kan tẹ̀ lé òru mìíràn sì ń fi ìmọ̀ hàn.” (Sáàmù 19:1, 2) Ṣùgbọ́n Dáfídì kò fi mọ síbẹ̀. Nínú Sáàmù 86:10, 11, a kà á pé: “Ẹni ńlá ni ọ́, o sì ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu; ìwọ ni Ọlọ́run, ìwọ nìkan ṣoṣo. Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà rẹ. Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ. Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.” Ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tí Dáfídì ní fún Ẹlẹ́dàá nítorí gbogbo ohun àrà tó ṣe, kan fífi tó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bẹ̀rù rẹ̀, bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. O lè mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Dáfídì ò fẹ́ ṣẹ Ẹni tó ń ṣe irú iṣẹ́ àgbàyanu wọ̀nyí. Kò sì yẹ kí àwa náà ṣẹ̀ ẹ́.
15. Èé ṣe tó fi bá a mu wẹ́kú pé Dáfídì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run?
15 Dáfídì ti ní láti gbà pé níwọ̀n bí agbára tó bùáyà ti ń bẹ níkàáwọ́ Ọlọ́run, ó lè lò ó láti fi jẹ ẹnikẹ́ni tó bá bínú sí níyà. A jẹ́ pé wọ́n gbé nìyẹn o. Ọlọ́run ti bi Jóòbù tẹ́lẹ̀ pé: “Ìwọ ha ti wọ àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ ti ìrì dídì, tàbí ìwọ ha rí àní àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ ti yìnyín, èyí tí mo pa mọ́ de àkókò wàhálà, de ọjọ́ ìjà àti ogun?” Ìrì dídì, yìnyín, ìjì òjò, ẹ̀fúùfù, àti ààrá, gbogbo rẹ̀ ń bẹ lára ohun ìjà Ọlọ́run. Àrágbá-yamúyamù agbára sì ń bẹ nínú àwọn ipá àdáyébá wọ̀nyí lóòótọ́!—Jóòbù 38:22, 23.
16, 17. Kí ni ó ṣàpèjúwe agbára ńláǹlà tí Ọlọ́run ní, báwo ló sì ṣe lo agbára yẹn láyé àtijọ́?
16 Ó ṣeé ṣe kóo rántí ìjábá tí ọ̀kan lára ìwọ̀nyí ti fà ládùúgbò yín—yálà ìjì líle ni o, ìjì òjò oníyìnyín ni o, tàbí omíyalé. Bí àpẹẹrẹ, ní apá ìparí ọdún 1999, ìjì ńlá kan jà níhà gúúsù ìwọ̀-oòrùn Yúróòpù. Ó ya àwọn ògbógi awojú-ọjọ́ pàápàá lẹ́nu. Ńṣe ni ẹ̀fúùfù líle kan bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́, ó ń sáré ní ìwọ̀n igba [200] kìlómítà láàárín wákàtí kan, ó ṣí ẹgbẹẹgbẹ̀rún òrùlé dà nù, ó sì ṣẹ́ àwọn òpó iná onírin gìrìwò-gìrìwò, bẹ́ẹ̀ náà ló dojú àwọn ọkọ̀ dé. Gbìyànjú láti fojú inú wo èyí ná: Iye igi tí ìjì yẹn fà tu tàbí tó ṣẹ́ sí méjì jẹ́ nǹkan bíi mílíọ̀nù lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ó dín ọgbọ̀n [270,000,000], tí ẹgbàárùn-ún [10,000] lára rẹ̀ jẹ́ látinú ọgbà ìnàjú Versailles nìkan, èyí tó wà lẹ́yìn òde ìlú Paris. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ilé ni kò rí iná mànàmáná lò. Iye àwọn tó kú fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún. Bẹ́ẹ̀, ìṣẹ́jú díẹ̀ ni ìjì yìí fi jà o, tó sì ṣe gbogbo èyí tán. Áà, agbára yẹn bùáyà!
17 Ẹnì kan lè pe ìjì ní ìkà, tó kàn ń jà kiri, tó ń ṣàkóbá fáwọn ẹni ẹlẹ́ni. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ gọngọ ò ní sọ bí Olódùmarè, oníṣẹ́ àrà, bá dìídì rán irú àwọn nǹkan alágbára bẹ́ẹ̀ síbì kan fún ète pàtàkì kan? Láyé Ábúráhámù, ó ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ó gbọ́ pé Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé ti díwọ̀n ìwà ibi ìlú méjèèjì náà, Sódómù àti Gòmórà. Ìwà ìbàjẹ́ wọn gogò débi pé igbe ẹ̀sùn nípa wọn gòkè dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tó ṣe ọ̀nà àbáyọ fún gbogbo àwọn olódodo kúrò nínú àwọn ìlú tí ìdájọ́ ń bọ̀ lórí ẹ̀ yẹn. Ìtàn yẹn sọ pé: “Nígbà náà ni Jèhófà mú kí òjò imí ọjọ́ àti iná rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, láti ọ̀run,” sórí ìlú wọ̀nyẹn. Ìyẹn pẹ̀lú jẹ́ iṣẹ́ àrà, ìyẹn dídá tó dá àwọn olódodo sí, àti pípa tó pa àwọn olubi run.—Jẹ́nẹ́sísì 19:24.
18. Àwọn ohun àgbàyanu wo ni Aísáyà orí 25 tọ́ka sí?
18 Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ọlọ́run dá ìlú Bábílónì àtijọ́ lẹ́jọ́, ó sì jọ pé òun ni ìlú táa tọ́ka sí nínú Aísáyà orí 25. Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé ìlú ńlá kan yóò pa run, ó ní: “Ìwọ ti sọ ìlú ńlá kan di ìtòjọpelemọ òkúta, o ti sọ ìlú olódi di ìrúnwómúwómú, o ti sọ ilé gogoro ibùgbé àwọn àjèjì di èyí tí kì í ṣe ìlú ńlá mọ́, tí a kì yóò tún kọ́, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 25:2) Lóde òní, àwọn tó bá ṣèbẹ̀wò sí ibi tí Bábílónì wà tẹ́lẹ̀ lè jẹ́rìí sí i pé bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí. Ṣé ìparun Bábílónì ṣèèṣì wáyé ni? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè tẹ́wọ́ gba ojú tí Aísáyà fi wo ọ̀ràn náà, ó ní: “Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run mi. Mo gbé ọ ga, mo gbé orúkọ rẹ lárugẹ, nítorí pé o ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu, àwọn ìpinnu láti àwọn àkókò ìjímìjí, nínú ìṣòtítọ́, nínú ìṣeégbẹ́kẹ̀lé.”—Aísáyà 25:1.
19, 20. Ìmúṣẹ wo la lè retí pé kí Aísáyà 25:6-8 ní?
19 Ọlọ́run mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà lókè yìí ṣẹ láyé àtijọ́, yóò sì tún ṣe ohun ìyanu lọ́jọ́ iwájú. Nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí tí Aísáyà ti mẹ́nu kan “àwọn ohun àgbàyanu” tí Ọlọ́run ṣe, a rí àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ṣeé gbára lé, tí kò tíì ṣẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ lórí Bábílónì ṣe ṣẹ. Kí ni “ohun àgbàyanu” tó ṣèlérí? Aísáyà 25:6 sọ pé: “Dájúdájú, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì se àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn fún gbogbo àwọn ènìyàn ní òkè ńlá yìí, àkànṣe àsè wáìnì tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti àwọn oúnjẹ tí a fi òróró dùn, èyí tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ti wáìnì sísẹ́, èyí tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.”
20 Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn yóò ṣẹ dájúdájú nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, tó ti dé tán yìí. Nígbà yẹn, aráyé yóò bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó wọ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́rùn nísinsìnyí. Àní, àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 25:7, 8 mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò lo agbára ìṣẹ̀dá tó ní láti ṣe ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu jù lọ, ó kà pé: “Ní ti tòótọ́, òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn. Ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òun yóò sì mú kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ ọ́.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí yọ, ó sì fi ṣàlàyé jíjí tí Ọlọ́run yóò jí àwọn òkú dìde. Àgbàyanu gbáà ni iṣẹ́ yìí yóò mà jẹ́ o!—1 Kọ́ríńtì 15:51-54.
Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Lọ́jọ́ Iwájú
21. Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu wo ni Ọlọ́run yóò ṣe fáwọn òkú?
21 Ìdí mìíràn tí omijé ìbànújẹ́ yóò fi pòórá ni pé gbogbo àrùn ara ọmọ aráyé la ó mú kúrò pátá. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó wo ọ̀pọ̀ èèyàn sàn—ó mú kí afọ́jú ríran, kí adití gbọ́ràn, ó sì mú kí àwọn abirùn máa ta kébékébé. Jòhánù 5:5-9 ròyìn pé ó mú ọkùnrin kan tó ti yarọ fún ọdún méjìdínlógójì lára dá. Ohun àrà, tàbí iṣẹ́ ìyanu làwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn pè é. Ohun àrà sì ni lóòótọ́! Àmọ́, Jésù sọ pé ohun ìyanu tó ju èyí lọ ni jíjí tí òun yóò jí àwọn òkú dìde, ó ní: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá, àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè.”—Jòhánù 5:28, 29.
22. Èé ṣe tí àwọn òtòṣì àtàwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ fi lè nírètí pé ọjọ́ iwájú á dára?
22 Ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀ nítorí pé Jèhófà ló ṣèlérí rẹ̀. Ìdánilójú wà pé nígbà tó bá fẹ̀sọ̀ lo agbára ńlá rẹ̀ fún àmúdọ̀tun, àgbàyanu ni ìyọrísí rẹ̀ yóò jẹ́. Sáàmù 72 sọ ohun tí yóò ṣe nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Ọba. Àwọn olódodo yóò rú jáde nígbà yẹn. Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà yóò sì wà. Ọlọ́run yóò dá àwọn òtòṣì àtàwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ nídè. Ó ṣèlérí pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá. Èso rẹ̀ yóò rí bí ti Lẹ́bánónì [ìgbàanì], àwọn èyí tí ó sì ti inú ìlú ńlá wá yóò yọ ìtànná bí ewéko ilẹ̀.”—Sáàmù 72:16.
23. Ó yẹ kí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run sún wa láti ṣe kí ni?
23 Dájúdájú, ìdí tó pọ̀ rẹpẹtẹ ń bẹ, tó fi yẹ ká fiyè sí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà—ìyẹn àwọn ohun tó ti ṣe sẹ́yìn, àwọn ohun tó ń ṣe lónìí, àtàwọn ohun tí yóò ṣe láìpẹ́ láìjìnnà. “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo ni ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àgbàyanu. Ìbùkún sì ni fún orúkọ rẹ̀ ológo fún àkókò tí ó lọ kánrin, kí ògo rẹ̀ sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé. Àmín àti Àmín.” (Sáàmù 72:18, 19) Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló yẹ ká máa fi ìtara sọ nígbà gbogbo fún àwọn ẹ̀bi wa àtàwọn ẹlòmíì. Àní sẹ́, ẹ jẹ́ ká “máa polongo ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn.”—Sáàmù 78:3, 4; 96:3, 4.
Báwo Ni Wàá Ṣe Fèsì?
• Báwo ni àwọn ìbéèrè táa bi Jóòbù ṣe fi ibi tí òye èèyàn mọ hàn kedere?
• Àwọn wo ló wú ọ lórí lára àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run táa mẹ́nu kàn nínú Jóòbù orí 37 sí 41?
• Kí ló yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa lẹ́yìn táa ti jíròrò díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kí ni ìparí èrò rẹ nípa ọ̀pọ̀ ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìrì wínníwínní dídì àti agbára ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ tí mànàmáná ní?
[Credit Line]
snowcrystals.net
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Jẹ́ kí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run wà lára ohun tí o ń jíròrò nígbà gbogbo