Àwọn Ẹranko Ń Gbé Jèhófà Ga
TÉÈYÀN bá rí onírúurú ẹranko tí Jèhófà dá, èèyàn á gbà pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba. Ọlọ́run máa ń bójú tó àwọn ẹranko dáadáa, gẹ́gẹ́ bó ṣe ń tọ́jú àwa ọmọ èèyàn. (Sáàmù 145:16) Àṣìṣe ńlá ló máa jẹ́ tọ́mọ èèyàn bá wá ń dá Ẹlẹ́dàá èèyàn àti ẹranko lẹ́bi! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé adúróṣinṣin ni Jóòbù, síbẹ̀ “ó polongo ọkàn ara rẹ̀ ní olódodo dípò Ọlọ́run.” Ká má purọ́, ẹ̀kọ́ pọ̀ tí Jóòbù ní láti kọ́!—Jóòbù 32:2; 33:8-12; 34:5.
Àwọn ẹranko tí Ọlọ́run fi ṣàpẹẹrẹ nígbà tó ń bá Jóòbù sọ̀rọ̀ jẹ́ kó mọ̀ pé ọmọ èèyàn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa sọ pé Ọlọ́run ò ṣe nǹkan bó ṣe tọ́. Tá a bá wo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jóòbù ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ, a óò rí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí!
Àwọn Ẹranko Ò Nílò Ìrànlọ́wọ́ Ọmọ Aráyé
Jóòbù ò lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí Ọlọ́run bi í nípa àwọn ẹranko. (Jóòbù 38:39-41) Ó dájú pé, Jèhófà ò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti dúró de ọmọ aráyé kó tó pèsè oúnjẹ fún kìnnìún àti ẹyẹ ìwò. Òótọ́ ni pé àwọn ẹyẹ ìwò ń fò káàkiri láti wá oúnjẹ, àmọ́ Ọlọ́run gan-an ló ń fún wọn lóúnjẹ.—Lúùkù 12:24.
Nígbà tí Ọlọ́run bi Jóòbù léèrè nípa àwọn ẹranko igbó, ńṣe lẹnu rẹ̀ wọhò. (Jóòbù 39:1-8) Kò sẹ́ni tó lè dáàbò bo egbin àtàwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá. Àní, ó tiẹ̀ ṣòro gan-an láti dé itòsí àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá! (Sáàmù 104:18) Ọgbọ́n tí Ọlọ́run dá mọ́ egbin ló ń jẹ́ kó máa lọ síbi tó pa mọ́ nínú igbó tó bá fẹ́ bímọ. Kì í fọ̀rọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ ṣeré rárá, àmọ́ tí wọ́n bá ti “sanra bọ̀kíbọ̀kí,” wọ́n á ‘jáde lọ wọn ò sì ní padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.’ Àtìgbà yẹn ni wọ́n á sì ti máa dá jẹ̀.
Ibi tó bá wu àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà ni wọ́n máa ń lọ, aṣálẹ̀ sì ni ibùgbé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́. Jóòbù ò lè fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ kó ẹrù. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yìí máa ń “wá gbogbo onírúurú ọ̀gbìn tútù,” á sì máa yẹ àwọn òkè wò láti rí ibi tó ti máa rí koríko jẹ. Bí ẹranko yìí ṣe ń jẹ̀ kiri nínú igbó fàlàlà tẹ́ ẹ lọ́rùn ju pé kó máa gbé láàárín àwọn èèyàn níbi tí wọ́n á ti máa fún un lóúnjẹ. “Kì í gbọ́ ariwo ayọ́dẹ,” nítorí pé ńṣe ló máa ń feré gé e béèyàn bá dé ibi tó ń gbé.
Ẹ̀yìn èyí ni Ọlọ́run tún wá mẹ́nu kan akọ màlúù ìgbẹ́. (Jóòbù 39:9-12) Awalẹ̀pìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Austen Layard kọ̀wé nípa ẹranko yìí pé: “Téèyàn bá rí ère ẹranko yìí tí wọ́n sábà máa ń gbẹ́, ó jọ pé díẹ̀ ni kìnnìún fi lágbára jù ú lọ torí pé àkòtagìrì ni òun náà, ó sì gbayì gan-an bíi kìnnìún. A máa ń rí i nínú àwọn ère tí wọ́n gbẹ́ pé ọba ń bá ẹranko náà jà, àwọn ọmọ ogun sì ń fi ẹṣin àti ẹsẹ̀ lépa rẹ̀.” (Ìwé Nineveh and Its Remains, 1849, Apá kejì, ojú ìwé 326) Síbẹ̀, kò sí ọlọgbọ́n kankan tó máa jẹ́ fìjánu sẹ́nu ẹranko tẹ́nikẹ́ni ò lè dá dúró yìí.—Sáàmù 22:21.
Àwọn Ẹ̀dá Abìyẹ́ Ń Gbé Jèhófà Ga
Ọlọ́run tún wá bi Jóòbù léèrè nípa àwọn ẹ̀dá abìyẹ́. (Jóòbù 39:13-18) Ẹyẹ àkọ̀ máa ń fi ìyẹ́ rẹ̀ tó lágbára fò lọ sókè réré. (Jeremáyà 8:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ògòǹgò máa ń gbọn ìyẹ́ apá rẹ̀ pìpì, kò lè fi fò. Àmọ́ ògòǹgò kì í yé ẹyin sínú ìtẹ́ lórí igi bíi ti ẹyẹ àkọ̀. (Sáàmù 104:17) Ńṣe ló máa ń wa ilẹ̀, tí yóò sì yé ẹyin rẹ̀ síbẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe pé ẹyẹ yìí á fi ẹyin rẹ̀ sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ o. Ó máa ń fi iyẹ̀pẹ̀ bo ẹyin náà mọ́lẹ̀ kí ibi tí wọ́n wà lè móoru. Akọ àti abo ògòǹgò ló sì jọ ń tọ́jú àwọn ẹyin náà.
Èèyàn lè máa wò ó pé ó dà bíi pé ògòǹgò “gbàgbé ọgbọ́n” nígbà tó bá rí i pé ẹnì kan fẹ́ kó ẹyin rẹ̀, tó wá ṣe bíi pé ó fẹ́ sá lọ. Àmọ́ o, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko inú Bíbélì, ìyẹn An Encyclopedia of Bible Animals sọ pé: “Ọgbọ́n tí ẹyẹ [ògòǹgò] fi ń tan ohun tó bá ń bọ̀ níbi ẹyin rẹ̀ kúrò níbẹ̀ nìyí: á wá síbi tí ọ̀tá ọ̀hún á ti rí i dáadáa á sì máa gbọn ìyẹ́ apá rẹ̀ pìpì láti fi gbàfiyèsí èèyàn tàbí ẹranko tó ń lọ síbi ẹyin náà, á sì dọ́gbọ́n tàn wọ́n kúrò níbẹ̀.”
Báwo ni ògòǹgò ṣe máa ń “fi ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún rẹ́rìn-ín”? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ògòǹgò ò lè fò, àmọ́ eré tó ń sá lórí ilẹ̀ kọyọyọ. Tó bá na ẹsẹ̀ gígùn rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, ó lè dé ibi tó lé ní mítà mẹ́rin àtààbọ̀, ó sì lè sáré tó tó kìlómítà mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ní wákàtí kan.”
Ọlọ́run Ló Ń Fún Ẹṣin Lágbára
Ìbéèrè tí Ọlọ́run tún béèrè lọ́wọ́ Jóòbù lọ́tẹ̀ yìí dá lórí ẹṣin. (Jóòbù 39:19-25) Láyé ìgbàanì, àwọn jagunjagun máa ń fi ẹṣin jagun, ẹṣin ló sì máa ń fa kẹ̀kẹ́ ẹṣin, èyí tí ẹni tó ń darí ẹṣin náà máa gùn. Ó sì tún ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ ogun méjì mìíràn wà pẹ̀lú rẹ̀. Ara ẹṣin ogun kì í balẹ̀ tí ogun bá ti yá, ńṣe ni yóò máa yán tí yóò sì máa fi pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ talẹ̀. Ẹ̀rù kì í bà á bẹ́ẹ̀ ni kì í yíjú padà tó bá rí idà. Bó bá ti gbọ́ tí wọ́n fun ìwo báyìí, ńṣe ni gbogbo iṣan ara rẹ̀ máa dìde bíi pé ó ń sọ pé, “Àháà!” Ńṣe ni yóò bẹ́ gìjà síwájú, ‘tí yóò máa gbé ilẹ̀ mì.’ Síbẹ̀, ẹṣin ogun yìí máa ń gbọ́ràn sí ẹni tó ń gùn ún.
Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni Layard tó jẹ́ awalẹ̀pìtàn ń ṣe àpèjúwe kan tó bá ọ̀rọ̀ Bíbélì mu, ó kọ̀wé pé: “Ó rọrùn láti darí abo ẹṣin ilẹ̀ Arébíà béèyàn ṣe lè darí àgùntàn, ẹni tó ń kó o níjàánu nìkan sì ti tó láti darí rẹ̀. Àmọ́ o, tí ẹṣin yìí bá gbọ́ pé àwọn ará Arébíà kígbe ogun, tó sì rí i tí ọ̀kọ̀ ẹni tó ń gùn ún ń fì síwá sẹ́yìn, ńṣe ni ojú rẹ̀ yóò pọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tí yóò máa ṣáná, tí ihò imú rẹ̀ tó ní àwọ̀ pupa bí ẹ̀jẹ̀ á fẹ̀ sí i, ọrùn rẹ̀ yóò wá nà ṣanṣan, bẹ́ẹ̀ ni ìrù àti gọ̀gọ̀ rẹ̀ yóò sì máa fẹ́ lẹ́lẹ́.”—Látinú ìwé Discoveries Among the Ruins of Nineveh and Babylon, 1853, ojú ìwé 330.
Ẹ Jẹ́ Ká Sọ̀rọ̀ Nípa Àṣáǹwéwé àti Idì
Ọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹyẹ mìíràn ni Jèhófà tún bá Jóòbù sọ. (Jóòbù 39:26-30) Àwọn àṣáǹwéwé máa ń ‘ròkè lálá, wọ́n á sì na ìyẹ́ apá wọn sí ẹ̀fúùfù gúúsù.’ Ìwé The Guinness Book of Records sọ pé àṣáǹwéwé ni ẹyẹ tó ń sáré jù lọ nínú gbogbo ẹyẹ. Ó ṣàlàyé pé “eré tó kọ yọyọ ni ẹyẹ yìí máa ń sá tó bá ń fò wálẹ̀ láti ibi tó ga gan-an nígbà tó bá ń dárà lójú òfuurufú, tàbí nígbà tó bá fẹ́ mú ẹran ìjẹ rẹ̀ lójú òfuurufú.” Àní, wọ́n ní nígbà kan, ibi tó jìnnà tó ọgọ́rùn ún mẹ́ta ó lé mọ́kàndínláàádọ́ta [349] kìlómítà ni ẹyẹ yìí já ṣòòròṣò wálẹ̀ dé láti ojú ọ̀run láàárín wákàtí kan!
Idì máa ń fò tó àádóje [130] kìlómítà ní wákàtí kan bó ṣe ń fò lókè. Jóòbù fi bí ìgbésí ayé ọmọ èèyàn ṣe kúrú gan-an wé eré àsápajúdé tí idì máa ń sá tó bá ń wá ohun tí yóò jẹ. (Jóòbù 9:25, 26) Ọlọ́run ń fún wa lókun ká lè máa fara da ipòkípò, bíi pé a wà lórí ìyẹ́ apá idì tó ń fò lọ sókè, tó dá bíi pé àárẹ̀ kì í mú. (Aísáyà 40:31) Atẹ́gùn tó móoru tó ń lọ sókè máa ń ran ẹyẹ idì lọ́wọ́ tó bá ń fò. Bí ẹyẹ yìí bá ti ń rà bàbà nínú atẹ́gùn tó móoru yìí ni yóò máa túbọ̀ ròkè sí i. Tó bá ti fò lọ sókè gan-an, yóò ré kọjá sí ibi mìíràn tí atẹ́gùn tún ti móoru ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì lè máa rà bàbà lókè lọ́hùn-ún fún ọ̀pọ̀ wákàtí láìsí pé ó ń lo agbára púpọ̀.
Ẹyẹ idì máa “ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè fíofío” níbi tí kò rọrùn láti dé, kí ohunkóhun má bàa pa àwọn ọmọ rẹ̀ lára. Ọgbọ́n tí Jèhófà dá mọ́ idì ló ń jẹ́ kó ṣe gbogbo èyí. Agbára ìríran tí Ọlọ́run sì fún ẹyẹ yìí ló ń jẹ́ kí “ojú rẹ̀ [máa] wo ọ̀nà jíjìn.” Ọ̀nà àrà tí idì fi ń tètè darí agbára ìríran rẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàsé ẹran tó fẹ́ pa tàbí òkú ẹran tó fẹ́ gbé nígbà tó bá ń já ṣòòròṣò bọ̀ nílẹ̀ láti ọ̀nà jíjìn. Idì máa ń jẹ òkú ẹran, abájọ tí Bíbélì fi sọ pé “ibi tí àwọn ohun tí a pa bá wà, ibẹ̀ ni ó ń wà.” Ẹyẹ yìí tún máa ń gbé àwọn ẹranko kéékèèké lọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n lè rí nǹkan jẹ.
Jèhófà Bá Jóòbù Wí
Kí Ọlọ́run tó bẹ̀rẹ̀ sí bi Jóòbù láwọn ìbéèrè mìíràn nípa àwọn ẹranko, ó kọ́kọ́ bá Jóòbù wí. Kí ni Jóòbù wá ṣe? Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fi tinútinú gba ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run tún fún un.—Jóòbù 40:1-14.
Níbi tí ọ̀rọ̀ dé yìí nínú ìtàn Jóòbù tí Ọlọ́run mí sí, a rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kan kọ́, ìyẹn ni pé: Kò sí ẹnikẹ́ni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti dá Olódùmarè lẹ́bi. Ohun tó máa múnú Baba wa ọ̀run dùn ló yẹ ká máa sọ ká sì máa ṣe. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ohun tó yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ ni bí orúkọ mímọ́ Jèhófà ṣe máa di èyí tá a yà sí mímọ́ àti bí a ó ṣe dá a láre pé òun ni ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run.
Béhémótì Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run
Nígbà tí Ọlọ́run tún máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko, ó bi Jóòbù léèrè nípa Béhémótì, èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí erinmi. (Jóòbù 40:15-24) Erinmi tó bá ti gbó dáadáa lè gùn tó mítà mẹ́rin sí márùn-ún, ó sì lè tẹ̀wọ̀n tó àpò sìmẹ́ǹtì méjìléláàádọ́rin [72]. “Agbára [Béhémótì] wà ní ìgbáròkó rẹ̀,” ìyẹn àwọn iṣan ìbàdí rẹ̀. Awọ ikùn Béhémótì tó nípọn gan-an wúlò fún un púpọ̀ torí pé ó ń jẹ́ kí ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ kúńkú yìí lè fàyà wọ́ kọjá lórí òkúta inú odò. Tá a bá wo bí Béhémótì ṣe tóbi fàkìà-fakia tó, bí ẹnu rẹ̀ ṣe fẹ̀ tó àti bí párì rẹ̀ ṣe lágbára tó, ó dájú pé kò sí ọmọ èèyàn tó lè bá a wọ̀yá ìjà.
Béhémótì máa ń jáde látinú odò kó lè wá jẹ “koríko tútù.” Àní, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ gbogbo koríko tó wà ní òkè ńlá kan tán! Tí wọ́n bá kó koríko tó máa ń jẹ lọ́jọ́ kan jọ, ìwọ̀n rẹ̀ á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àpò símẹ́ǹtì méjì sí mẹ́rin. Bó bá ti wá jẹun yó tán, á lọ sinmi lábẹ́ igi lótọ́sì tàbí abẹ́ ibòji igi pọ́pílà. Bí odò tí erinmi ń gbé bá kún àkúnya, ó lè gbé orí rẹ̀ sókè omi, kó sì máa lúwẹ̀ẹ́ lọ ní tiẹ̀ ní ìdojúkọ ìṣàn alagbalúgbú omi ọ̀hún. Bí Jóòbù bá wo bí ẹnu Béhémótì ṣe tóbi fẹ̀ǹfẹ̀ tó tó sì rí bi eyín gígùn rẹ̀ ṣe lágbára tó, kò dájú pé Jóòbù á jẹ́ sọ pé òun máa fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú.
Léfíátánì Ń Fi Ìyìn fún Ọlọ́run
Ọ̀rọ̀ nípa Léfíátánì ni Jóòbù tún gbọ́ tẹ̀ lé e. (Jóòbù 41:1-34) Ohun tí Léfíátánì túmọ̀ sí lédè Hébérù ni “ẹranko tí nǹkan kan tó wà ní ìṣẹ́po-ìṣẹ́po bò lára.” Ó sì jọ pé ọ̀nì ni Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ǹjẹ́ Jóòbù lè gbé Léfíátánì fáwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n máa fi ṣeré? Ó tì o! Ẹni tó bá ti rí ìjà ẹranko yìí rí á mọ̀ pé kì í ṣe ẹran rírọ̀. Àní, béèyàn kan bá gbìyànjú láti gbá Léfíátánì mú pẹ́nrẹ́n, ìjà náà á pọ̀ débi pé onítọ̀hún ò ní jẹ́ dán irú ẹ̀ wò mọ́!
Bí Léfíátánì bá yọrí jáde látinú omi nígbà tí oòrùn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ, ńṣe ni ojú rẹ̀ á máa tàn yòò “bí ìtànyanran ọ̀yẹ̀.” Àwọn ìpẹ́ ara rẹ̀ fún mọ́ ara wọn pinpin ni, àwọn eegun líle tó rọra bo awọ ara rẹ̀ sì le korán-korán débi pé ọta ìbọn kì í tètè wọnú wọn, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ idà tàbí ọ̀kọ̀. Tí àwọn ìpẹ́ tó mú bí abẹ tó wà níkùn ọ̀nì bá wọ́ kọjá lórí ẹrẹ̀ etídò, ńṣe ló máa ń dà bíi pé wọ́n wọ́ “ohun èlò ìpakà” kọjá níbẹ̀. Tí ẹranko yìí bá ń bínú, ńṣe ni ìfófòó á máa yọ lójú omi bí epo tí wọ́n ń sè. Ẹ̀rù kì í bà á torí pé àkòtagìrì ẹran ni, bó ṣe ní ohun tó lè fi gbèjà ara rẹ̀ náà ló ní ohun tó lè fi ṣọṣẹ́, ìyẹn ẹnu fẹ̀ǹfẹ̀ tó ní àti ìrù ńlá rẹ̀.
Jóòbù Kó Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Jẹ
Jóòbù gbà pé lóòótọ́ ni òun ‘sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n òun kò lóye àwọn ohun tí ó jẹ́ àgbàyanu gidigidi fún òun, èyí tí òun kò mọ̀.’ (Jóòbù 42:1-3) Ó gba ìbáwí tí Ọlọ́run fún un, ó kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ, ó sì ronú pìwà dà. Ọlọ́run bá àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù wí lọ́nà tó le koko, àmọ́ ó bù kún Jóòbù jìgbìnnì.—Jóòbù 42:4-17.
Ó mà dára ká máa fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù sọ́kàn o! A ò lè dáhùn gbogbo ìbéèrè tí Ọlọ́run bi í. Àmọ́, ó yẹ ká máa fi ìmọrírì wa hàn fún onírúurú ohun ìyanu tí Jèhófà dá tó ń gbé e ga.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ewúrẹ́ orí òkè ńlá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ẹyẹ ìwò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Abo kìnnìún
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ògòǹgò máa ń rìn kúrò níbi tí ẹyin rẹ̀ wà, ṣùgbọ́n kì í ṣe pé ó fi wọ́n sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ o
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ẹyin ògòǹgò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]
Àṣáǹwéwé
[Credit Line]
Àṣáǹwéwé: © Joe McDonald/Visuals Unlimited
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Abo ẹṣin ilẹ̀ Arébíà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Idì aláwọ̀ wúrà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé Béhémótì ni erinmi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn èèyàn sọ pé Léfíátánì ni ọ̀nì alágbára