Ọ̀ràn Pàtàkì Kan Tó Kàn Ẹ́ Gbọ̀ngbọ̀n
ṢÓ O lọ́rẹ̀ẹ́ kan tàbí aráalé kan tí ìwọ àtiẹ̀ mọwọ́ ara yín? Ká wá sọ pé ẹnì kan fẹ̀sùn kàn ẹ́ pé torí ohun tó ò ń rí gbà lọ́dọ̀ ẹ̀ lọwọ́ yín ṣe wọwọ́ ńkọ́? Ṣéyẹn ò ní múnú bí ẹ tàbí kó tiẹ̀ mórí ẹ gbóná? Ẹ̀sùn yẹn gan-an ni Sátánì Èṣù fi kan gbogbo àwọn tí àárín wọn àti Jèhófà Ọlọ́run bá ti gún régé.
Ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sátánì ti tọkọtaya àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, dédìí rírú òfin Ọlọ́run tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ dara pọ̀ mọ́ ọn láti dìtẹ̀ mọ́ Ọlọ́run. Ṣóhun tó ṣẹlẹ̀ yẹn fi hàn pé kìkì ìgbà tí ìgbọràn sí Jèhófà bá pé èèyàn nìkan lèèyàn tó lè máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu? (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún lẹ́yìn tí Ádámù ti kúrò lẹ́yìn Ọlọ́run, Sátánì tún dá ọ̀ràn kan náà yìí sílẹ̀. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí Jóòbù ló dájú sọ. Níwọ̀n bí ẹ̀sùn tí Èṣù fi kan Jóòbù yìí ti mú kí ọ̀ràn tó ń fa wàhálà lé lórí gan-an túbọ̀ ṣe kedere, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò.
“Èmi Kì Yóò Mú Ìwà Títọ́ Mi Kúrò”
“Ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú” ni Jóòbù. Síbẹ̀ náà, Sátánì sọ pé jíjẹ́ tí Jóòbù jẹ́ adúróṣánṣán yẹn lọ́wọ́ èrú nínú. Ó béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé: “Lásán ha ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run bí?” Lẹ́yìn náà ló wá fẹ̀sùn ṣíṣe èrú kan Ọlọ́run àti Jóòbù, ó sọ pé torí pé Jèhófà ti ra Jóòbù pa nípa dídáàbò bò ó àti nípa bíbùkún un ló jẹ́ kí Jóòbù jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Sátánì pe Ọlọ́run níjà pé: “Fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fọwọ́ kan ohun gbogbo tí ó ní, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.”—Jóòbù 1:8-11.
Láti fèsì sí gbogbo ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà àti Jóòbù yìí, Jèhófà fàyè gba Sátánì láti dán Jóòbù wò. Torí àtiyí Jóòbù tó jẹ́ olóòótọ́ padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, Èṣù bẹ̀rẹ̀ sí í mú oríṣiríṣi àjálù wá bá a lọ́kọ̀ọ̀kan. Wọ́n jí lára ẹran ọ̀sìn Jóòbù lọ, àwọn yòókù sì run; wọ́n pa àwọn ẹmẹ̀wà Jóòbù, àwọn ọmọ ẹ̀ sì kú mọ́ ọn lójú. (Jóòbù 1:12-19) Àmọ́, ṣé Sátánì pàpà rọ́wọ́ mú lórí ọ̀rọ̀ Jóòbù? Irọ́ o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ò mọ̀ pé Èṣù ló wà nídìí gbogbo àdánwò tó dé bá a, síbẹ̀ ó sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti fi fúnni, Jèhófà fúnra rẹ̀ sì ti gbà lọ. Kí orúkọ Jèhófà máa bá a lọ láti jẹ́ èyí tí a bù kún fún.”—Jóòbù 1:21.
Lẹ́yìn tí Sátánì ti ta jàǹbá fún Jóòbù tán, ó wá síwájú Jèhófà, Jèhófà wá sọ fún un pé: “[Jóòbù] ṣì di ìwà títọ́ rẹ̀ mú ṣinṣin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ru mí lọ́kàn sókè sí i, láti gbé e mì láìnídìí.” (Jóòbù 2:1-3) Ọ̀ràn pàtàkì tó wà nílẹ̀ ni ọ̀ràn ìṣòtítọ́ Jóòbù, kéèyàn sì tó lè jẹ́ olùṣòtítọ́, ó béèrè pé kí onítọ̀hún dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ kí gbogbo ohun tó bá ń ṣe sì máa jẹ́ òdodo. Níbi tọ́ràn dé yìí, Jóòbù ti jagunmólú lórí ọ̀ràn ìṣòtítọ́. Síbẹ̀, Èṣù ò mà jáwọ́ nínú ọ̀ràn náà o.
Sátánì wá sọ ọ̀rọ̀ kan tó fi fẹ̀sùn kan gbogbo aráyé lápapọ̀. Ó sọ fún Jèhófà pé: “Awọ fún awọ, ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀. Fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fi kan egungun rẹ̀ àti ẹran ara rẹ̀, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.” (Jóòbù 2:4, 5) Bí Èṣù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà, “ènìyàn,” dípò kó dárúkọ Jóòbù, ohun tí Èṣù ń fìyẹn sọ ni pé lásán kọ́ ni gbogbo ẹni tó bá ń fòtítọ́ sin Jèhófà ń sìn ín. Nǹkan tóhun tó ń sọ túmọ̀ sí ni pé: ‘Kò sí nǹkan téèyàn ò lè ṣe láti gbẹ̀mí ara ẹ̀ là. Fún mi láàyè lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, kò sẹ́ni tí mi ò lè yí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.’ Ṣóòótọ́ ni pé tọ́ràn bá dójú ẹ̀, kò sí ẹ̀dá táá lè dúró gbọn-in sẹ́yìn Ọlọ́run táá sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbàkigbà?
Jèhófà gba Èṣù láàyè láti fi àrùn tó ń pọ́nni lójú dààmú Jóòbù. Ìyà jẹ Jóòbù débi tó fi gbàdúrà ikú fúnra ẹ̀. (Jóòbù 2:7; 14:13) Síbẹ̀, Jóòbù sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!” (Jóòbù 27:5) Ìdí tí Jóòbù fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ràn Ọlọ́run kò sì sóhun tó lè paná ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́kàn ẹ̀. Jóòbù fi hàn pé ẹni tó ń ṣohun tó tọ́ lòun. Bíbélì sọ pé: “Ní ti Jèhófà, ó bù kún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.” (Jóòbù 42:10-17) Ǹjẹ́ a ráwọn míì tó dà bíi Jóòbù? Látìgbà náà wá, kí la ti rí tó ti ṣẹlẹ̀?
Báwọn Kan Ṣe Já Èṣù Nírọ́
Ní orí kọkànlá ìwé Hébérù nínú Bíbélì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dárúkọ àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó ti fìgbà kan wà láyé kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀. Lára wọn ni Nóà, Ábúráhámù, Sárà àti Mósè. Àpọ́sítélì yìí wá fi kún un pé: “Àkókò kì yóò tó fún mi bí mo bá ń bá a lọ láti ṣèròyìn nípa [àwọn yòókù].” (Hébérù 11:32) Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyí pọ̀ débi tí Pọ́ọ̀lù fi pè wọ́n ní “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀.” Ó tipa báyẹn fi wọ́n wé àwọsánmà tó pọ̀ débi tó fi gba gbogbo ojú òfuurufú. (Hébérù 12:1) Òótọ́ sì ni, láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ẹgbàágbèje èèyàn ló ti lo òmìnira tí wọ́n ní láti yan ohun tó wù wọ́n, wọ́n sì yàn láti dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run.—Jóṣúà 24:15.
Ohun tí Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ gbélé ayé ṣe ló wá tú irọ́ Sátánì fó pátápátá porogodo, ìyẹn irọ́ tó pa pé, òun lè yí gbogbo èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ pé ikú oró ló kú pẹ̀lú ìrora lórí òpó ìdálóró, ìyẹn ò ní kó fi ìṣòtítọ́ ẹ̀ sí Ọlọ́run sílẹ̀. Bí èémí ṣe ń bọ́ lọ lẹ́nu Jésù, ó kígbe pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.”—Lúùkù 23:46.
Gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò tó ti kọjá lọ ti fi hàn pé Èṣù ò tíì rí gbogbo èèyàn pátá yí kúrò nínú sísin Ọlọ́run tòótọ́. Àìmọye èèyàn ló ti wá mọ Jèhófà tí wọ́n sì ‘fi gbogbo ọkàn-àyà wọn àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú wọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.’ (Mátíù 22:37) Bí wọ́n ṣe dúró ṣinṣin ti Jèhófà láìyẹsẹ̀ ti fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa lórí ọ̀ràn ìṣòtítọ́ ẹ̀dá. Ò báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ìwọ náà lè já Èṣù nírọ́ bó o bá jẹ́ ẹni ìdúróṣinṣin.
Kí Lo Gbọ́dọ̀ Ṣe?
Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Báwo lo ṣe lè wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́? Ṣètò láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o sì ‘gba ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tó rán jáde, Jésù Kristi.’—Jòhánù 17:3.
Bí Sátánì ṣe sọ pé tinútinú kọ́ làwọn èèyàn fi ń sin Ọlọ́run, ohun tó ń sọ ni pé kò sí olùṣòtítọ́ kan láàárín wọn. Tó o bá fẹ́ máa ṣe ohun tó ò ń ṣe níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀, ìmọ̀ ọ̀hún gbọ́dọ̀ dénú ọkàn ẹ. Kíyẹn sì tó lè ṣẹlẹ̀, o ní láti ṣe ju pé kó o kàn ka nǹkan kan látinú Bíbélì lásán lọ. Sọ ọ́ dàṣà láti máa ṣàṣàrò lórí ohun tó o bá kọ́. (Sáàmù 143:5) Nígbà tó o bá ń ka Bíbélì tàbí ìwé kan tó dá lórí Bíbélì, rí i dájú pé o wá ààyè láti ṣàṣàrò lórí àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: ‘Kí lèyí kọ́ mi nípa Jèhófà? Àwọn ànímọ́ Ọlọ́run wo ni ibi tí mo kà yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Lápá ibo nínú ìgbésí ayé mi ló ti yẹ kí n máa fàwọn ànímọ́ yìí ṣèwà hù? Kí ni Ọlọ́run fọwọ́ sí, kí ló sì lòdì sí? Báwo nìyẹn ṣe lè nípa lórí bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe rí lọ́kàn mi?’ Ṣíṣàṣàrò lórí irú àwọn ìbéèrè báwọ̀nyí á mú kí ìfẹ́ Ẹlẹ́dàá jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ á sì túbọ̀ mú kó o mọrírì rẹ̀.
Jíjẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọ́run ò mọ sórí ohun téèyàn gbà gbọ́ nìkan. (1 Àwọn Ọba 9:4) Jíjẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run tún nasẹ̀ débi pé kó o máa hùwà títọ́ nínú ìgbésí ayé ẹ látòkèdélẹ̀. Àmọ́ jíjẹ́ olùṣòtítọ́ ò ní kó o pàdánù ohunkóhun. “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì fẹ́ kó o gbádùn ayé ẹ. (1 Tímótì 1:11) Ní báyìí, jẹ́ ká wá wo àwọn ìwà tí kò yẹ kó o lọ́wọ́ sí kó o bàa lè jẹ́ oníwà mímọ́, kí ìgbésí ayé ẹ lè dùn sí i kó o sì jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Má Ṣèṣekúṣe
Jèhófà fúnra rẹ̀ ló gbé ìlànà tí yóò máa darí ọ̀ràn ìgbéyàwó kalẹ̀ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, níbi tó ti sọ pé: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:21-24) Níwọ̀n bí àwọn méjì tó ṣègbéyàwó ti di “ara kan,” láti lè fi hàn pé wọ́n ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ìṣètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ṣe, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ìbálòpọ̀ mọ sáàárín ara wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) Ohun tí gbólóhùn náà “ibùsùn ìgbéyàwó” túmọ̀ sí ni ìbálòpọ̀ takọtabo láàárín ọkùnrin kan àti obìnrin kan tí wọ́n ti ṣègbéyàwó lọ́nà tó bófin mu. Bí èyíkéyìí nínú wọn bá lọ ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin míì lò pọ̀ yàtọ̀ sẹ́ni tí wọ́n jọ ṣègbéyàwó, panṣágà ló ṣe yẹn, ó sì lè forí gba ìdájọ́ mímúná lọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Málákì 3:5.
Báwọn méjì tí wọn ò tíì ṣègbéyàwó bá ń bára wọn sùn ń kọ́? Ìyẹn náà ò bá ilànà ìwà tó tọ́ tí Jèhófà fi lélẹ̀ mu. Bíbélì sọ pé: “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ . . . pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè.” (1 Tẹsalóníkà 4:3) Àwọn ìwà míì tó tún lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run ni bíi kọkùnrin àtọkùnrin tàbí obìnrin àtobìnrin máa bá ara wọn lò pọ̀, káwọn méjì tí wọ́n jẹ́ ìbátan máa bá ara wọn lò pọ̀ àti kéèyàn máa bá ẹranko lò pọ̀. (Léfítíkù 18:6, 23; Róòmù 1:26, 27) Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣohun tó máa múnú Ọlọ́run dùn tó sì fẹ́ láyọ̀ ní tòótọ́ kò gbọdọ́ máa ṣe ìṣekúṣe.
Tẹ́nì kan bá lọ ń ṣe ohun tó lè máa mú kí ọkàn ẹ̀ fà sí ìbálòpọ̀ láìjẹ́ pé ó ti ṣègbéyàwó ńkọ́? Ìwà yìí pẹ̀lú á bí Jèhófà nínú. (Gálátíà 5:19) Bákan náà la ò gbọdọ̀ fààyè gba èròkérò nínú ọkàn wa. Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:28) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn kan wíwo àwòrán ìṣekúṣe nínú ìwé, lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì; ó tún kan kíka báwọn èèyàn ṣe ń bá ara wọn lò pọ̀ àti gbígbọ́ orin tí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ dọ́gbọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ tí kò yẹ kéèyàn máa sọ. Téèyàn ò bá dédìí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, inú Ọlọ́run á dùn sí i ó sì máa mú káyé onítọ̀hún túbọ̀ nítumọ̀.
Títage ńkọ́? Ìwé kan sọ pé títáge túmọ̀ sí “fífa ojú ẹlòmíì mọ́ra pẹ̀lú èrò ìbálòpọ̀ lọ́kàn.” Tọ́kùnrin kan tó níyàwó ńlé bá ń fa ojú obìnrin míì mọ́ra tàbí tí obìnrin kan tó wà lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ bá ń fa ojú ọkùnrin míì mọ́ra lọ́nà báyẹn, ohun tó ń ṣe lòdì sí ìlànà Bíbélì, ó sì jẹ́ àmì pé kò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà. (Éfésù 5:28-33) Àbí ẹ ò rí i bó ṣe burú tó pé káwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó máa fi ìwà tàbí ọ̀rọ̀ fa ẹlòmíì lójú mọra, kí wọ́n sì sọ pé eré làwọn fi ń ṣe! Tẹ́ni téèyàn ń bá tage bá lọ gbà á sí òótọ́ ju bẹ́ni tó ń bá a tage ṣe rò ó lọ ńkọ́? Ronú lórí ẹ̀dùn ọkàn tíyẹn lè kó bá irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ohun tó yẹ kéèyàn tún rò dáadáa ni pé títage lè sún èèyàn dédìí panṣágà tàbí àgbèrè. Dípò téèyàn á fi máa ṣèṣekúṣe, téèyàn bá ń hùwà mímọ́ nígbà tó bá wà lọ́dọ̀ ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀, kò ní dẹni tó fi ara ẹ̀ wọ́lẹ̀.—1 Tímótì 5:1, 2.
Bá A Ṣe Lè Máa Ṣèfẹ́ Ọlọ́run Láwọn Ọ̀nà Míì Nígbèésí Ayé Wa
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ọtí líle pọ̀ dáadáa. Ṣó burú kéèyàn máa mú un ni? Ìwé Mímọ́ ò ní kéèyàn má mu wáìnì, bíà tàbí irú ọtí líle míì níwọ̀ntúnwọ̀nsì. (Sáàmù 104:15; 1 Tímótì 5:23) Àmọ́, àmujù ọtí líle àti ìmutípara burú lójú Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13) Ó dájú pé o ò ní fẹ́ ṣàkóbá fún ìlera ẹ bẹ́ẹ̀ lo ò ní fẹ́ da ilé ara ẹ rú.—Òwe 23:20, 21, 29-35.
“Ọlọ́run òtítọ́” ni Jèhófà. (Sáàmù 31:5) Bíbélì tún sọ pé “kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” (Hébérù 6:18) Bó o bá fẹ́ kí Ọlọ́run fojú rere wò ọ́, o ò ní máa purọ́. (Òwe 6:16-19; Kólósè 3:9, 10) Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.”—Éfésù 4:25.
Bákan náà ni ti tẹ́tẹ́ títa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ràn tẹ́tẹ́ títa, síbẹ̀ àpẹẹrẹ ìwà ìwọra ni tẹ́tẹ́ títa torí pé ìlànà tó wà níbẹ̀ ni pé bówó ẹnì kan ò bá gbé, ẹlòmíì ò lè rówó jẹ. Jèhófà ò fojú rere wo àwọn tó jẹ́ “oníwọra fún èrè àbòsí.” (1 Tímótì 3:8) Tó o bá fẹ́ ṣe nǹkan tó máa múnú Jèhófà dùn, nígbà náà, o ò ní máa lọ́wọ́ nínú onírúurú tẹ́tẹ́ títa, tó fi mọ́ tẹ́tẹ́ oríire, kàlòkàlò àti títa púùlù. O lè wá rí i pé ìyẹn á mú kó o lówó lọ́wọ́ díẹ̀ sí i láti bójú tó ìdílé ẹ.
Olè jíjà, ìyẹn mímú nǹkan tí kì í ṣe tẹni, tún jẹ́ irú ìwà ìwọra míì. Bíbélì sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.” (Ẹ́kísódù 20:15) Kò bójú mu pé kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ ra ẹrù olè, bẹ́ẹ̀ sì ni kò bójú mu pé kéèyàn mú nǹkan tí kì í ṣe tèèyàn láìtọrọ ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere, kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (Éfésù 4:28) Dípò táwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà á fi máa lo àkókò tó yẹ kí wọ́n fi ṣiṣẹ́ tí wọ́n gbà wọ́n sí fún nǹkan míì, ṣe ni wọ́n máa ń gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn ní gbogbo àkókò tó yẹ kí wọ́n lò nídìí ẹ̀. Wọ́n fẹ́ “láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Téèyàn bá ń ṣe nǹkan tí ẹ̀rí ọkàn ò fi ní máa dà á láàmú, á ní ìbàlẹ̀ ọkàn.
Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ẹni tó máa ń bínú fùfù? Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́; má sì bá ènìyàn tí ó máa ń ní ìrufùfù ìhónú wọlé.” (Òwe 22:24) Béèyàn bá ń bínú láìkó ara ẹ̀ níjàánu, ó sábà máa ń mú kó hùwà ipá. (Jẹ́nẹ́sísì 4:5-8) Bó bá sì dọ̀ràn gbígbẹ̀san, Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn. Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’” (Róòmù 12:17-19) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn àtàtà bí irú èyí, àlàáfíà á túbọ̀ jọba nínú ìgbésí ayé wa, ìyẹn á sì mú kí ayọ̀ wa kún.
Á Ṣeé Ṣe fún Ọ Láti Jagunmólú
Ṣó lè ṣeé ṣe fún ìwọ náà láti dúró ṣinṣin lẹ́yìn Ọlọ́run láìka ti pé àwọn nǹkan tó lè mú kó nira fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ wà lọ́tùn-ún lósì? Bẹ́ẹ̀ ni, á kúkú ṣeé ṣe fún ọ. Mọ̀ dájú pé Ọlọ́run fẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ láti fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa pé èèyàn ò lè jẹ́ olùṣòtítọ́, torí pé Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.”—Òwe 27:11.
O lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ọ lókun láti lè máa ṣe ohun tó tọ́ lójú ẹ̀. (Fílípì 4:6, 7, 13) Torí náà, má ṣe jáwọ́ nínú sísapá láti fi kún ìmọ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó o ní. Bó o bá ń ṣàṣàrò lórí ohun tó o ti kọ́ látinú Bíbélì, tó o sì mọrírì rẹ̀, ìyẹn á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú kí ìfẹ́ tó o ní sí Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i á sì mú kó wù ẹ́ láti máa ṣe ohun táá máa múnú ẹ̀ dùn. Jòhánù kìíní orí karùn-ún ẹsẹ kẹta sọ pé: “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” Tayọ̀tayọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò ẹ á fi ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A rọ̀ ẹ́ pé kó o kàn sí wọn ní àdúgbò yín tàbí kó o kọ̀wé sáwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ìṣòtítọ́ Jóòbù ò yingin lábẹ́ àdánwò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bó o bá fi kún ìmọ̀ tó o ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìpinnu rẹ láti máa ṣe ohun tó tọ́ á túbọ̀ lágbára sí i