ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 26
Máa Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Ní Ìdààmú Ọkàn
“Kí èrò gbogbo yín ṣọ̀kan, kí ẹ máa bára yín kẹ́dùn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ ará, kí ẹ lójú àánú, kí ẹ sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.”—1 PÉT. 3:8.
ORIN 107 Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́?
JÈHÓFÀ Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Jòh. 3:16) Ó sì yẹ káwa náà fara wé e. Torí náà, gbogbo èèyàn ló yẹ ká máa bá kẹ́dùn, ká nífẹ̀ẹ́ wọn, ká sì máa fàánú hàn sí wọn. Àmọ́ ní pàtàkì, ó yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ sáwọn “tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (1 Pét. 3:8; Gál. 6:10) Nígbà táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa bá ní ìdààmú ọkàn, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ wà nínú ìdílé Jèhófà ló máa kojú onírúurú ìṣòro. (Máàkù 10:29, 30) Kò sí àní-àní pé ṣe làwọn ìṣòro yẹn á máa pọ̀ sí i bí ètò Sátánì ṣe ń kógbá wọlé. Báwo la ṣe lè ran ara wa lọ́wọ́ lẹ́nì kìíní kejì? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lọ́ọ̀tì, Jóòbù àti Náómì. A tún máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ìṣòro táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ń kojú, àá sì rí bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
MÁA MÚ SÙÚRÙ
3. Bó ṣe wà nínú 2 Pétérù 2:7, 8, ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu wo ni Lọ́ọ̀tì ṣe, kí nìyẹn sì yọrí sí?
3 Ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu ni Lọ́ọ̀tì ṣe nígbà tó yàn láti máa gbé láàárín àwọn ará Sódómù tí wọ́n jẹ́ oníṣekúṣe. (Ka 2 Pétérù 2:7, 8.) Òótọ́ ni pé nǹkan rọ̀ṣọ̀mù lágbègbè yẹn, àmọ́ Lọ́ọ̀tì jìyà ìpinnu tó ṣe. (Jẹ́n. 13:8-13; 14:12) Ó jọ pé ọkàn ìyàwó rẹ̀ ò kúrò nílùú yẹn tàbí kó jẹ́ pé kò fẹ́ fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀. Èyí mú kó ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí Jèhófà rọ̀jò iná àti imí ọjọ́ sórí ìlú náà. Bákan náà, àwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì méjèèjì pàdánù àwọn àfẹ́sọ́nà wọn nígbà tí Jèhófà pa ìlú Sódómù run. Lọ́ọ̀tì pàdánù ilé rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní, èyí tó sì dunni jù ni pé ó pàdánù ìyàwó rẹ̀, ó mà ṣé o! (Jẹ́n. 19:12-14, 17, 26) Àmọ́ ṣé Jèhófà mú sùúrù fún Lọ́ọ̀tì ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira yìí? Bẹ́ẹ̀ ni.
4. Báwo ni Jèhófà ṣe mú sùúrù fún Lọ́ọ̀tì? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Lọ́ọ̀tì ló pinnu láti gbé nílùú Sódómù, síbẹ̀ Jèhófà fàánú hàn sí i nígbà tó rán àwọn áńgẹ́lì láti gba òun àti ìdílé rẹ̀ là. Àmọ́ kàkà kí Lọ́ọ̀tì ṣègbọràn sí àwọn áńgẹ́lì náà pé kó kúrò nílùú yẹn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣe ló “ń lọ́ra ṣáá.” Làwọn áńgẹ́lì náà bá gbá ọwọ́ rẹ̀ mú, wọ́n sì mú òun àti ìdílé rẹ̀ jáde nílùú náà. (Jẹ́n. 19:15, 16) Wọ́n wá sọ fún un pé kó sá lọ sí agbègbè olókè. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí Lọ́ọ̀tì sọ? Ó sọ fáwọn áńgẹ́lì náà pé kí wọ́n jẹ́ kí òun lọ sí ìlú kan tó wà nítòsí. (Jẹ́n. 19:17-20) Síbẹ̀, Jèhófà mú sùúrù fún un, ó sì gbà á láyè láti lọ sí ìlú náà. Nígbà tó yá, ẹ̀rù àwọn tó ń gbé ìlú yẹn ba Lọ́ọ̀tì, ló bá forí lé agbègbè olókè, ìyẹn ibi tí Jèhófà sọ fún un pé kó lọ tẹ́lẹ̀. (Jẹ́n. 19:30) Àbí ẹ ò rí i pé Jèhófà mú sùúrù fún Lọ́ọ̀tì gan-an! Báwo làwa náà ṣe lè fara wé Jèhófà?
5-6. Báwo la ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú 1 Tẹsalóníkà 5:14 sílò bá a ṣe ń sapá láti fara wé Jèhófà?
5 Bíi ti Lọ́ọ̀tì, àwọn ará kan lè ṣèpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu, kíyẹn sì kó wọn síṣòro. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan, kí ló yẹ ká ṣe? Ó lè ṣe wá bíi pé ká fọ̀rọ̀ gún un lára, ká sì jẹ́ kó mọ̀ pé ohun téèyàn bá gbìn ló máa ká, òótọ́ sì nìyẹn. (Gál. 6:7) Àmọ́ dípò ká ṣe bẹ́ẹ̀, á dáa ká ràn án lọ́wọ́ bí Jèhófà ṣe ran Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́. Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
6 Jèhófà rán àwọn áńgẹ́lì sí Lọ́ọ̀tì kí wọ́n lè kìlọ̀ fún un, àmọ́ ó tún fẹ́ kí wọ́n ràn án lọ́wọ́ kó lè la ìparun Sódómù já. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká kìlọ̀ fún arákùnrin tàbí arábìnrin kan tá a bá rí i pé ohun tó fẹ́ ṣe lè kó o síṣòro. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ ká ràn án lọ́wọ́. Àmọ́, tá a bá rí i pé kò tètè fi àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, ó yẹ ká mú sùúrù fún un, ká ṣe bíi tàwọn áńgẹ́lì méjì yẹn. Dípò tá a fi máa pa á tì, ṣe ló yẹ ká ronú ohun pàtó tá a lè ṣe fún un. (1 Jòh. 3:18) A lè gbá ọwọ́ rẹ̀ mú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ká sì ràn án lọ́wọ́ kó lè fi àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un sílò.—Ka 1 Tẹsalóníkà 5:14.
7. Kí la rí kọ́ látinú ojú tí Jèhófà fi wo Lọ́ọ̀tì?
7 Kì í ṣe àwọn àṣìṣe Lọ́ọ̀tì ni Jèhófà gbájú mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pétérù láti kọ, ó pe Lọ́ọ̀tì ní olódodo. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà máa ń gbójú fo àwọn àṣìṣe wa! (Sm. 130:3) Báwo làwa náà ṣe lè fara wé Jèhófà? Tó bá jẹ́ pé ibi táwọn ará wa dáa sí là ń wò, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ máa mú sùúrù fún wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ yá wọn lára láti fi ìmọ̀ràn wa sílò.
MÁA FÀÁNÚ HÀN
8. Tá a bá jẹ́ aláàánú, kí nìyẹn máa mú ká ṣe?
8 Jóòbù kojú àwọn ìṣòro tó lékenkà, àmọ́ kì í ṣe torí pé ó ṣèpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu bíi ti Lọ́ọ̀tì. Ó pàdánù gbogbo ohun tó ní, àìsàn burúkú kọlù ú, ó wá dẹni ẹ̀tẹ́ láwùjọ. Èyí tó burú jù ni pé, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ kú lójú rẹ̀. Dípò káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta tù ú nínú kí wọ́n sì fàánú hàn sí i, ṣe ni wọ́n bẹnu àtẹ́ lù ú. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọn ò lóye ohun tó fa ìṣòro ẹ̀, torí náà wọ́n dá a lẹ́bi, wọ́n sì sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i. Kí ló yẹ ká ṣe ká má bàa dà bí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù yìí? Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà nìkan ló mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó fa ìṣòro tẹ́nì kan ń kojú àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀. Torí náà, ó yẹ ká jẹ́ aláàánú, ká sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹni náà dáadáa. Àmọ́ kì í ṣèyẹn nìkan, ó tún yẹ ká sapá ká lè mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀. Ìgbà yẹn la máa tó lóye ohun tẹ́ni náà ń kojú, àá sì lè ràn án lọ́wọ́.
9. Tá a bá jẹ́ aláàánú, kí la ò ní ṣe, kí sì nìdí?
9 Tá a bá jẹ́ aláàánú, a ò ní máa sọ ìṣòro àwọn ará wa kiri fáwọn míì. Ẹni tó ń ṣòfófó kì í gbé ìjọ ró, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa ń tú ìjọ ká. (Òwe 20:19; Róòmù 14:19) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í tuni lára, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa ń sọ̀rọ̀ láìronú, ọ̀rọ̀ ẹ̀ sì máa dá kún ìṣòro ẹni tó ní ìdààmú ọkàn. (Òwe 12:18; Éfé. 4:31, 32) Ẹ wo bó ṣe máa dáa tó pé ibi tẹ́nì kan dáa sí là ń wò, ká sì ronú ohun tá a lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́ kó lè fara da ìṣòro ẹ̀.
10. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó wà nínú Jóòbù 6:2, 3?
10 Ka Jóòbù 6:2, 3. Àwọn ìgbà kan wà tí Jóòbù sọ “ọ̀rọ̀ ẹhànnà.” Àmọ́ nígbà tó yá, ó gbà pé kò yẹ kóun sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. (Jóòbù 42:6) Bíi ti Jóòbù, ẹnì kan tó ní ìdààmú ọkàn lè máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó dà bí ọ̀rọ̀ ẹhànnà, ìyẹn ni pé kó máa sọ àwọn ohun tí kò yẹ kó sọ. Tá a bá wà pẹ̀lú irú ẹni bẹ́ẹ̀, kí ló yẹ ká ṣe? Dípò ká máa dá a lẹ́bi, ṣe ló yẹ ká fàánú hàn sí i. Ká rántí pé Jèhófà dá wa ká lè máa gbádùn ni, kì í ṣe ká máa jìyà. Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu tí ìránṣẹ́ Jèhófà kan bá ń sọ̀rọ̀ láìronú torí àwọn ìṣòro tó dé bá a. Kódà tẹ́ni náà bá sọ àwọn nǹkan tí kò tọ́ nípa Jèhófà tàbí nípa wa, kò yẹ ká bínú sí i tàbí ká dá a lẹ́bi torí ohun tó sọ.—Òwe 19:11.
11. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fara wé Élíhù tí wọ́n bá fẹ́ fúnni nímọ̀ràn?
11 Nígbà míì, ó lè gba pé ká tún èrò ẹnì kan tó ní ìdààmú ọkàn ṣe tàbí ká fìfẹ́ bá a wí. (Gál. 6:1) Ọ̀nà wo làwọn alàgbà lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Á dáa kí wọ́n fara wé Élíhù tó fara balẹ̀ tẹ́tí sí Jóòbù kó lè mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀. (Jóòbù 33:6, 7) Ẹ̀yìn tí Élíhù lóye Jóòbù dáadáa ló tó fún un nímọ̀ràn tó tún èrò rẹ̀ ṣe. Bíi ti Élíhù, ó ṣe pàtàkì káwọn alàgbà fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹni tó ní ìdààmú ọkàn kí wọ́n lè lóye bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀. Tí wọ́n bá wá fún ẹni náà nímọ̀ràn, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ wọn wọ̀ ọ́ lọ́kàn.
MÁA SỌ̀RỌ̀ ÌTÙNÚ
12. Báwo ni nǹkan ṣe rí lára Náómì lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì kú?
12 Obìnrin olóòótọ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni Náómì. Àmọ́ lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì kú, ìdààmú ọkàn bá a débi tó fi sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n má pe òun ní Náómì mọ́, “Márà” tó túmọ̀ sí “Ìkorò” ni kí wọ́n máa pe òun. (Rúùtù 1:3, 5, 20, àlàyé ìsàlẹ̀, 21) Ṣùgbọ́n Rúùtù tó jẹ́ ìyàwó ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dúró tì í ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira yẹn. Yàtọ̀ sí pé Rúùtù ṣe àwọn ohun pàtó láti ràn án lọ́wọ́, ó tún máa ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un. Rúùtù lo àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára láti jẹ́ kí Náómì mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.—Rúùtù 1:16, 17.
13. Kí nìdí tó fi yẹ ká dúró ti àwọn tó bá pàdánù ọkọ tàbí aya wọn?
13 Tí ẹnì kan nínú ìjọ bá pàdánù ọkọ tàbí aya rẹ̀, ó ṣe pàtàkì ká dúró ti irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ṣe làwọn tọkọtaya dà bí igi méjì tí wọ́n jọ hù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, gbòǹgbò wọn á máa lọ́ mọ́ra. Tí wọ́n bá hú ọ̀kan nínú wọn tó sì kú, ó máa ṣàkóbá fún ìkejì gan-an. Lọ́nà kan náà, tí ọkọ tàbí aya ẹnì kan bá kú, ó máa ń fa ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára gan-an, ó sì lè má lọ bọ̀rọ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arábìnrin Paula,b tí ọkọ rẹ̀ ṣàdédé kú, ó sọ pé: “Ṣe ni ìgbésí ayé mi dojú rú, gbogbo nǹkan sì tojú sú mi. Ọ̀rẹ́ tí mo nífẹ̀ẹ́ jù ni mo pàdánù yìí. Kò sí nǹkan tí mi ò kì í bá ọkọ mi sọ, òun ló máa ń dúró tì mí lọ́jọ́ dídùn àti lọ́jọ́ kíkan. Òun ni alábàárò àti alátìlẹ́yìn mi. Torí náà, nígbà tó kú, ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n là mí sí méjì.”
14-15. Báwo la ṣe lè tu ẹni tó pàdánù ọkọ tàbí aya rẹ̀ nínú?
14 Báwo la ṣe lè tu ẹni tó pàdánù ọkọ tàbí aya rẹ̀ nínú? Ohun àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì ká ṣe ni pé ká bá ẹni náà sọ̀rọ̀ kódà tó bá ń ṣe wá bákan tàbí tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò mọ ohun tá a lè sọ. Paula tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mo mọ̀ pé kì í rọrùn fáwọn èèyàn tí wọ́n bá gbọ́ pé èèyàn ẹnì kan kú. Wọ́n lè máa bẹ̀rù pé àwọn lè ṣi ọ̀rọ̀ sọ lọ́dọ̀ ẹni náà. Àmọ́ ní tèmi, ó sàn tí ẹnì kan bá sọ ọ̀rọ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ bọ́ sójú ẹ̀ ju pé kó kàn dákẹ́ láìsọ nǹkan kan.” Òótọ́ kan ni pé ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ ò retí pé ká sọ ohun tó máa yanjú ìṣòro òun. Paula wá fi kún un pé: “Ó máa ń tù mí lára táwọn ọ̀rẹ́ mi bá kàn sọ fún mi pé, ‘Ikú ọkọ yín dùn wá gan-an.’”
15 Arákùnrin William tí ìyàwó ẹ̀ kú lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn sọ pé: “Inú mi máa ń dùn táwọn míì bá ń sọ ohun tó dáa nípa ìyàwó mi, ìyẹn máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí máa ń mú kára tù mí gan-an, kínú mi sì dùn torí pé mo nífẹ̀ẹ́ ìyàwó mi gan-an, òun sì ni igi lẹ́yìn ọgbà mi.” Arábìnrin Bianca tí ọkọ rẹ̀ ti kú sọ pé: “Ara máa ń tù mí táwọn míì bá gbàdúrà pẹ̀lú mi tí wọ́n sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì fún mi. Ó máa ń wú mi lórí tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọkọ mi tí wọ́n sì tẹ́tí sílẹ̀ tí mo bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”
16. (a) Kí ló yẹ ká ṣe fẹ́ni tó ń ṣọ̀fọ̀? (b) Bó ṣe wà nínú Jémíìsì 1:27, iṣẹ́ wo ni Jèhófà gbé fún wa?
16 Bí Rúùtù ṣe dúró ti Náómì, bẹ́ẹ̀ náà ló yẹ ká dúró ti àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ká sì máa bá a lọ láti tù wọ́n nínú. Paula tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Lẹ́yìn tí ọkọ mi kú, àwọn ará gbárùkù tì mí gan-an. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn èèyàn gbọ́kàn kúrò lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi, wọ́n sì ń bá ìgbésí ayé wọn lọ. Bó ti wù kó rí, ìgbésí ayé mi ti yí pa dà, mi ò sì lè yí ọwọ́ aago pa dà sẹ́yìn mọ́. Mo ti wá rí i pé ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an táwọn ará bá mọ̀ pé ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ ṣì nílò ìtùnú kódà lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún bá ti kọjá.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé bí nǹkan ṣe ń rí lára kálukú yàtọ̀ síra. Àwọn kan máa ń tètè gbé nǹkan kúrò lára. Àmọ́, ìgbà gbogbo làwọn míì máa ń rántí ẹnì kejì wọn tó kú pàápàá tí wọ́n bá ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n sábà máa ń ṣe pa pọ̀. Báwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe nígbà tí ọ̀fọ̀ bá ṣẹ̀ wọ́n yàtọ̀ síra. Torí náà, ká rántí pé ara iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa ni pé ká máa tu àwọn tó pàdánù ọkọ tàbí aya wọn nínú, ká sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́.—Ka Jémíìsì 1:27.
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká dúró ti àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn pa tì?
17 Ẹ̀dùn ọkàn táwọn kan máa ń ní tí ọkọ tàbí aya wọn bá fi wọ́n sílẹ̀ máa ń burú gan-an. Arábìnrin Joyce tí ọkọ rẹ̀ fi sílẹ̀ lọ fẹ́ obìnrin míì sọ pé: “Ọgbẹ́ ọkàn tí mo ní lẹ́yìn tí ọkọ mi fi mí sílẹ̀ lágbára gan-an, ì bá sàn ká sọ pé ṣe ló kú. Ká sọ pé àìsàn tàbí ìjàǹbá ọkọ̀ ló pa á, màá mọ̀ pé kì í ṣe ẹ̀bi ẹ̀. Àmọ́ ṣe ni ọkọ mi dìídì fi mí sílẹ̀. Mo wá dà bí ẹni tí ò wúlò rárá.”
18. Kí la lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí kò ní ọkọ tàbí aya mọ́?
18 Tá a bá ṣenúure sáwọn tí kò ní ọkọ tàbí aya mọ́, á jẹ́ kó dá wọn lójú pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Àsìkò yìí gan-an ni wọ́n nílò àwọn ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini. (Òwe 17:17) Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn dénú? O lè ní kí wọ́n wá kí ẹ, kẹ́ ẹ sì jọ jẹun. Bákan náà, ẹ lè jọ ṣeré jáde tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Ohun míì tó o lè ṣe ni pé kó o ní kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ìdílé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tẹ́ ẹ bá fẹ́ ṣe Ìjọsìn Ìdílé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mú inú Jèhófà dùn, torí pé Jèhófà “wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn,” òun ló sì “ń dáàbò bo àwọn opó.”—Sm. 34:18; 68:5.
19. Kí lo pinnu láti ṣe bí 1 Pétérù 3:8 ṣe sọ?
19 Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, gbogbo ‘wàhálà máa di ohun ìgbàgbé.’ Ẹ wo bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí ‘àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí, tí wọn ò sì ní wá sí ọkàn mọ́.’ (Àìsá. 65:16, 17) Títí dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa ran ara wa lọ́wọ́ ká sì máa fi hàn lọ́rọ̀ àti níṣe pé a nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará wa.—Ka 1 Pétérù 3:8.
ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
a Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà, àpẹẹrẹ gidi ni Lọ́ọ̀tì, Jóòbù àti Náómì jẹ́, síbẹ̀ wọ́n kojú àwọn ìṣòro tó le gan-an. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tá a lè kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. A tún máa jíròrò ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa mú sùúrù fáwọn ará wa tó ń kojú ìṣòro, ká máa fi àánú hàn sí wọn, ká sì máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn.
b A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.
c ÀWÒRÁN: Inú ń bí arákùnrin kan, ìyẹn sì mú kó máa sọ “ọ̀rọ̀ ẹhànnà,” àmọ́ alàgbà kan tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Nígbà tí ara arákùnrin náà balẹ̀, alàgbà yẹn fún un nímọ̀ràn tìfẹ́tìfẹ́.
d ÀWÒRÁN: Tọkọtaya kan ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ arákùnrin kan tí ìyàwó rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú. Wọ́n jọ ń wo fọ́tò ìyàwó rẹ̀, wọ́n sì ń sọ àwọn nǹkan rere tó ṣe.