Gbogbo Kìràkìtà Wa Láti Pẹ́ Láyé
“Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo. Ó jáde wá bí ìtànná, a sì ké e kúrò, ó sì fẹsẹ̀ fẹ bí òjìji, kò sì sí mọ́.”—Jóòbù 14:1, 2.
KÓDÀ àwọn ènìyàn díẹ̀ lónìí ló lè sọ pé ọ̀rọ̀ táa kà nípa bí ìgbésí ayé ènìyàn ṣe kúrú tó yìí kò rí bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ ọ́ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀tàdínlógún ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn. Kì í sábà tẹ́ àwọn ènìyàn lọ́rùn láti tọ́ ìgbà ọ̀ṣìngín nínú ìgbésí ayé wò fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà kí wọ́n darúgbó, kí wọ́n sì kú. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé jálẹ̀ ìtàn làwọn èèyàn ti ń dọ́gbọ́n àtimú kí ẹ̀mí wọn gùn sí i.
Ní àkókò Jóòbù, àwọn ará Íjíbítì a máa jẹ kórópọ̀n ẹranko kí wọ́n bàa lè máa ta kébékébé. Ọ̀kan nínú olórí ète àwọn apoògùn ní sànmánì agbedeméjì ni pé kí àwọn ṣe oògùn àjídèwe tó lè mú kí ẹ̀mí túbọ̀ gùn sí i. Ọ̀pọ̀ àwọn oníṣẹ́ idán ló gbà gbọ́ pé wúrà àtọwọ́dá lè múni wà láàyè títí láé àti pé fífi àwo olómi wúrà jẹun yóò mú ẹ̀mí ẹni gùn sí i. Àwọn onísìn Tao ti China ìgbà àtijọ́ rò pé àwọn lè yí ọ̀nà tí ara gbà ń ṣiṣẹ́ padà nípa lílo irú ọgbọ́n bíi ṣíṣe àṣàrò, fífi mímí sínú àti síta ṣe eré ìmárale, àti ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tí kò ní kú mọ́.
Olùṣàyẹ̀wòkiri ọmọ ilẹ̀ Sípéènì nì, Juan Ponce de León, ni a mọ̀ bí ẹní mowó nítorí wíwá tó ń wá oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn darúgbó kiri lójú méjèèjì. Dókítà ọ̀rúndún kejìdínlógún kan sọ nínú ìwé rẹ̀ Hermippus Redivivus pé kí wọ́n kó àwọn wúńdíá ọlọ́mọge jọ sínú yàrá kékeré kan nígbà ìrúwé, kí wọ́n gba èémí wọn sínú ìgò, ó ní, ó ṣeé fi ṣe oògùn ẹ̀mí gígùn. Láì tiẹ̀ sọ ọ́ jáde, òtúbáńtẹ́ ni gbogbo ọgbọ́n wọ̀nyí já sí.
Lónìí, tó ń lọ sí nǹkan bí ẹgbẹ̀tàdínlógún ààbọ̀ [3,500] ọdún lẹ́yìn tí Mósè ti kọ ọ̀rọ̀ Jóòbù nì sílẹ̀, àwọn ènìyàn ti rìn nínú òṣùpá, wọ́n ti ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti kọ̀ǹpútà, wọ́n sì ti ṣàyẹ̀wò átọ́ọ̀mù àti sẹ́ẹ̀lì. Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo irú ìlọsíwájú nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀, a ṣì jẹ́ ‘ọlọ́jọ́ kúkúrú tó kún fún ṣìbáṣìbo.’ Òótọ́ ni pé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, iye ọdún tí ẹnì kan lè gbé láyé ti lọ sókè gan-an lọ́nà tó kàmàmà ní ọ̀rúndún tó kọjá. Àmọ́, èyí jẹ́ àbájáde àbójútó ìlera tí wọ́n mú sunwọ̀n sí i, àìgbagbẹ̀rẹ́ lórí ọ̀ràn ìmọ́tótó, àti oúnjẹ tó ń ṣara lóore tó pọ̀ sí i. Fún àpẹẹrẹ, láti àárín ọ̀rúndún kọkàndínlógún sí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, ìpíndọ́gba ọdún tí àwọn ọkùnrin ará Sweden ń lò láyé lọ sókè láti ogójì ọdún sí ọdún márùndínlọ́gọ́rin, tàwọn obìnrin pẹ̀lú sì fò sókè láti ọdún mẹ́rìnlélógójì sí ọgọ́rin ọdún. Àmọ́, ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé a ti yanjú ìṣòro èèyàn láti pẹ́ láyé sí i?
Rárá o, nítorí pé bí àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i tiẹ̀ ń dàgbà, tí wọ́n ń darúgbó láwọn orílẹ̀-èdè kan, ọ̀rọ̀ tí Mósè kọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ṣì kàn wọ́n, ó sọ pé: “Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún; bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá . . . , nítorí pé kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.” (Sáàmù 90:10) Láìpẹ́ sígbà táa wà yí, ǹjẹ́ nǹkan kò ní yí padà? Ṣé yóò ṣeé ṣe fún ènìyàn láti pẹ́ láyé ní ti gidi? Àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí la ó jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.