Ẹ Kún fun Ayọ̀
“Awọn ọmọ-ẹhin ntẹsiwaju lati kún fun ayọ̀ ati ẹ̀mí mimọ.”—Iṣe 13:52, New World Translation.
1. (a) Ayọ̀ jẹ́ irú èso wo? (b) Fun ìpèsè aláyọ̀ wo ni a nilati yin Ọlọrun lógo?
AYỌ̀! Ànímọ́ Kristian yii ni o tẹle ìfẹ́ ninu itolẹsẹẹsẹ apejuwe Pọọlu nipa awọn èso ti ẹ̀mí. (Galatia 5:22-25) Kinni ó sì ńmú ayọ̀ yẹn wá? Ó jẹ́ ihinrere tí angeli Ọlọrun kede fun awọn olùṣọ́-àgùtàn onírẹ̀lẹ̀ ní nǹkan tí ó ju 1,900 ọdun sẹhin: “Sáwò ó, mo mú ihinrere ayọ̀ ńlá fun yin wá, tí yoo ṣe ti ènìyàn gbogbo. Nitori a bí olùgbàlà fun yin lonii ní ìlú Dafidi.” Lẹhin naa ògídímèje awọn angeli farahàn wọn sì darapọ̀ mọ́ angeli naa ninu fífi ìyìn fun Ọlọrun pẹlu ayọ̀ ní wiwi pe: “Ògo ni fun Ọlọrun ní òkè ọ̀run, ati ní ayé alaafia, ìfẹ́ inúrere sí ènìyàn.”—Luku 2:10-14.
2, 3. (a) Eeṣe tí ó fi yẹrẹ́gí pe Ọlọrun rán Ọmọkunrin àkọ́bí rẹ̀ lati di Olùtúnràpadà aráyé? (b) Ní awọn ọ̀nà miiran wo ni Jesu gba fi ṣiṣẹ́sìn fun ète Ọlọrun nigbati ó wà lórí ilẹ̀-ayé?
2 Ìfẹ́ inúrere Jehofa sí awọn ènìyàn ni a fihàn ninu pípèsè ìgbàlà nipasẹ Kristi Oluwa. Akọbi Ọmọkunrin Ọlọrun yii jẹ́ àpẹẹrẹ ọgbọ́n tootọ a sì ṣàpèjúwe rẹ̀ pe o sọ nipa Baba rẹ̀ ní àkókò ìṣẹ̀dá pe: “Nigba naa ni emi di òṣìṣẹ́ dídájú ati afìdímúlẹ̀gbọnyin ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, nigba naa ni emi di ẹni tí ó kún fun ìdùnnú ní ọjọ́ dé ọjọ́, tí ńyọ ayọ̀ àṣeyọrí ní iwaju rẹ̀ ní gbogbo àkókò; tí ńyọ ayọ̀ àṣeyọrí ninu ilẹ̀ eléso rẹ̀ ti ilẹ̀-ayé, bẹẹni ìdùnnú mi kíkún wà pẹlu awọn ọmọkunrin ènìyàn.”—Owe 8:30, 31, Rotherham.
3 Ó bá a mu rẹ́gí, nigba naa, pe Jehofa rán Ọmọkunrin yii, ẹni tí ó ní irú ìdùnnú bẹẹ ninu awọn ọmọkunrin ènìyàn, lati jẹ́ Olùràpadà aráyé. Bawo sì ni eyi yoo ṣe mú ògo wá fun Ọlọrun? Yoo ṣí ọ̀nà silẹ fun un lati ṣàṣeparí ète títóbilọ́lá rẹ̀ ti fifi ẹ̀dá-ènìyàn olódodo ati olùfẹ́ alaafia kun ilẹ-aye. (Jẹnẹsisi 1:28) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ọmọkunrin yii, Jesu, nigbati ó bá wà lórí ilẹ̀-ayé, yoo fihàn lábẹ́ ìdánwò mímúná jùlọ pe ọkunrin pípé kan lè ṣègbọràn sí Jehofa gẹgẹbi Oluwa Ọba-alaṣẹ pẹlu ìdúróṣinṣin, ti o tipa bayii dá ẹ̀tọ́ agbára ìṣàkóso Baba rẹ̀ lórí ìṣẹ̀dá Rẹ̀ láre ní kíkún. (Heberu 4:15; 5:8, 9) Ọ̀nà ìgbésẹ̀ Jesu ti pípa ìwàtítọ́ mọ́ tún fi apẹẹrẹ lelẹ fun gbogbo awọn Kristian tootọ lati tẹle awọn ipasẹ̀ rẹ̀ tímọ́tímọ́.—1 Peteru 2:21.
4. Ìfaradà Jesu yọrísí ayọ̀ ńláǹlà wo, bawo sì ni eyi ṣe nilati fun wa ní ìṣírí?
4 Jesu rí ayọ̀ aláìlẹ́gbẹ́ ninu ṣíṣe ìfẹ́-inú Baba rẹ̀ lọna yii, iyẹn sì jẹ́ ninu ìfojúlọ́nà fun ayọ̀ títóbijù pàápàá, gẹgẹbi apọsteli Pọọlu ti tọ́ka si i ní Heberu 12:1, 2 (NW): “Ẹ jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré-ìje tí a gbéka iwaju wa, gẹgẹ bi a ti ntẹjumọ Olórí Aṣojú ati Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jesu. Nitori ayọ̀ tí a gbéka iwájú rẹ̀, ó faradà igi oró, ó tẹ́ḿbẹ́lú ìtìjú, ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.” Ayọ̀ wo ni eyi? Ó jẹ́ ayọ̀ tí Jesu ní, kii ṣe kìkì ninu sísọ orukọ Baba rẹ̀ di mímọ́ ati ríra aráyé padà kuro ninu ikú ṣugbọn pẹlu ninu ṣíṣàkóso gẹgẹbi ọba ati alufaa àgbà gẹgẹbi oun ti mú awọn ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn padàbọ̀sípò sí ìyè ailopin ninu paradise ilẹ̀-ayé.—Matiu 6:9; 20:28; Heberu 7:23-26.
5. Awọn wo ni “awọn arakunrin” Jesu, ati ninu ayọ̀ aláìlẹ́gbẹ́ wo ni wọn ṣàjọpín?
5 Bẹẹni, Ọmọkunrin Ọlọrun maa ńrí ayọ̀ nigbagbogbo ninu ṣíṣiṣẹ́sìn aráyé. Ó sì ti jẹ́ ayọ̀ rẹ̀ lati ṣiṣẹ́sìn pẹlu Baba rẹ̀ ninu ṣíṣe àṣàyàn àwùjọ awọn ẹ̀dá ènìyàn olùpàwàtítọ́ mọ́ tí oun pè ní “arakunrin” rẹ̀ tí a sì jinde sí ọ̀run lẹhin ikú. Awọn wọnyi wọnú ayọ̀ aláìlẹ́gbẹ́ pẹlu Jesu. A pè wọn ní “aláyọ̀ ati mímọ́,” wọn ‘yoo sì di alufaa ti Ọlọrun ati ti Kristi, wọn yoo sì ṣàkóso gẹgẹbi ọba pẹlu rẹ̀ fun ẹgbẹrun ọdun.’—Heberu 2:11; Iṣipaya 14:1, 4; 20:6.
6. (a) Ìkésíni aláyọ̀ wo ni Ọba naa nawọ́ rẹ̀ sí “awọn àgùtàn miiran” rẹ̀? (b) Awọn àǹfààní wo ni pupọ ninu awọn àgùtàn wọnyi ńgbádùn lonii?
6 Siwaju síi, ogunlọgọ nla ti “awọn àgùtàn miiran,” awọn ẹni tí Ọba tí ńjọba naa yàsọ́tọ̀ sí ọwọ́ ọ̀tún ojurere rẹ̀, rí ìkésíni rẹ̀ gbà: “Ẹ wá, ẹyin alabukun fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, tí a ti pèsè silẹ fun yin lati ọjọ́ yii wá.” (Johanu 10:16; Matiu 25:34) Irú àǹfààní aláyọ̀ wo ni eyi! Ninu awọn wọnyi tí yoo jogún agbegbe ilẹ̀-ayé ninu Ijọba naa, ọpọlọpọ ńtẹ́wọ́gbà ẹrù iṣẹ́ nisinsinyi pàápàá ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu awọn ẹni-àmì-òróró, gan-an gẹgẹbi Jehofa ti sọtẹ́lẹ̀: “Awọn àlejò yoo sì dúró, wọn yoo sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran yin, awọn ọmọ àlejò yoo sì ṣe atúlẹ̀ yin, ati olùrẹ́ ọwọ́ àjàrà yin. Ṣugbọn a ó maa pè yin ní Alufaa Oluwa [“Jehofa,” NW]: wọn yoo sì maa pè yin ní iranṣẹ Ọlọrun wa.” Gbogbo awọn wọnyi darapọ̀ mọ́ wolii Ọlọrun ní wiwi pe: “Emi yoo yọ̀ gidigidi ninu Oluwa [“Jehofa,” NW], ọkàn mi yoo yọ̀ ninu Ọlọrun mi; nitori ó ti fi agbádá [“ẹ̀wù ìgbàlà,” NW] wọ̀ mi.”—Aisaya 61:5, 6, 10.
7. Eeṣe tí “ọjọ́” yii lati 1914 fi jẹ́ àkànṣe gan-an?
7 Awa ńgbé nisinsinyi ninu ọjọ́ kan ti o jẹ àkànṣe gan-an. Lati 1914 ó ti jẹ́ ọjọ́ iṣakoso Kristi gẹgẹbi Ọba ọ̀run, tí a ṣàpèjúwe ní Saamu 118:24, 25: ‘Eyi ni ọjọ́ ti Oluwa [“Jehofa,” NW] dá: awa yoo maa yọ̀, inú wa yoo sì maa dùn ninu rẹ̀. Gbani nisinsinyi, awa bẹ̀ ọ, Oluwa [“Jehofa,” NW]; Oluwa [“Jehofa,” NW], awa bẹ̀ ọ́, rán alaafia [“jẹ ki a ṣe aṣeyọrisirere,” NW].’ Ó jẹ́ ọjọ́ tí yoo dé òtéńté rẹ̀ nigbati Jehofa bá fìyà ikú jẹ ìsìn Babiloni tí ó sì so 144,000 awọn arakunrin ti wọn jẹ iyawo Kristi pọ ṣọkan pẹlu Ọba wọn ti ọ̀run. Gbogbo awọn ènìyàn Ọlọrun yoo “yọ̀, inu wọn yoo sì dùn gidigidi” ninu eyi. Wọn yoo tún yọ̀ gẹgẹbi Ọba Messiah wọn ti ńjà ní Armageddon lati gba orílẹ̀-èdè adúróṣinṣin rẹ̀ là sínú ayé titun òdodo rẹ̀. (Iṣipaya 19:1-7, 11-16) Njẹ Jehofa jẹ́ kí wọn ṣe àṣeyọrísírere bi awọn ènìyàn rẹ ti ńpòkìkí ireti aláyọ̀ yii? Ìròhìn tí ó tẹle e yii yoo ṣàlàyé.
Ìmúgbòòrò Yíká Ilẹ̀-ayé
8. (a) Bawo ni a ṣe fi ayọ̀ pẹlu ẹ̀mí mimọ han ninu ìròhìn ti o wa lójú ìwé 18 sí 21 ìwé-ìròhìn yii? (b) Kinni diẹ lara awọn koko ìtẹnumọ́ ninu ìròhìn naa?
8 Awọn Ẹlẹrii Jehofa ti òde-òní “pọ̀ ní ìrètí nipa agbára ẹ̀mí mimọ.” (Romu 15:13) Eyi ni a fihàn ninu àwòrán ìsọfúnni ní ojú-ìwé 18 sí 21 ìwé-ìròhìn yii, níbití a ti ṣàkọsílẹ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìròhìn iṣẹ́-ìsìn Ijọba yíká ilẹ̀-ayé ní 1990. Bawo ni a ti yọ̀ tó lati rí góńgó titun ti 4,017,213 awọn òjíṣẹ́ agbékánkánṣiṣẹ́ ninu pápá! Eyi sàmìsí ìbísí ti o jẹ ipin 77 nínú ọgọ́rùn-ún láàárín ọdun mẹwaa tí ó kọjá gẹgẹbi ìkójọ awọn àgùtàn ti ntẹsiwaju láìsọsẹ̀ ni 212 ilẹ̀ yíká ayé. Lẹhin 15 ọdun, baptism tun de gongo 301,518—ju ti igbakigba ri lọ! Iye awọn baptism ti wọn pọ̀ lọna àrà-ọ̀tọ̀ wà ní ọpọlọpọ apejọpọ, pàápàá awọn wọnni tí awọn Ẹlẹrii lati Ìlà-oòrùn Europe pésẹ̀ sí. Láàárín awọn wọnyi ni ọpọlọpọ ọ̀dọ́ ènìyàn wa, tí wọn ńmú ọrọ ijọba-ajumọni nírọ́ pe isin yoo dópin pẹlu awọn àgbà.
9. (a) Ikọnilẹkọọ ní kùtùkùtù igbesi aye lati ọ̀dọ̀ awọn òbí ńmú ìyọrísí aláyọ̀ wo wá? (b) Awọn ìrírí àdúgbò tabi òmíràn wo ni ó ti otitọ yii lẹhin?
9 Ògìdìgbó awọn ọ̀dọ́ ènìyàn ńdáhùn ìpè naa tí ó wà ní Saamu 32:11: “Kí inú yin kí ó dùn niti Oluwa [“Jehofa,” NW], ẹ sì maa yọ̀, ẹyin olódodo; ẹ sì maa kọrin fun ayọ̀, gbogbo ẹyin tí àyà yin dúróṣinṣin.” Ó dàbí ẹnipe ọpọlọpọ òbí ńfi ìmọ̀ràn naa sílò lati tọ́ awọn ọmọ kéékèèké wọn lẹ́kọ̀ọ́ “lati ìgbà ọmọdé.” (2 Timoti 3:15) A ti ńlò awọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ ati kásẹ́ẹ̀tì igbohunsilẹ tí a pèsè fun awọn ọ̀dọ́mọdé lọna rere. Bi awọn ọdọmọde wọnyi ti ńwọ ilé-ẹ̀kọ́, bẹẹ ni wọn ńfúnni ní ẹ̀rí rere, fun apẹẹrẹ gẹgẹbi ọdọmọbinrin ọlọ́dún mẹjọ ara Japan tí ó ròhìn pe: “Lẹhin àkókò isinmi ti ìgbà ẹ̀rùn, mo tọ olùkọ́ mi lọ mo sì beere lọwọ rẹ̀: ‘Njẹ ẹ ṣebẹwo si ibojì baba yin láàárín àkókò isinmi?’ Oun dáhùn: ‘Bẹẹni, baba mi jẹ́ ẹni jẹlẹnkẹ gan-an, mo sì maa nbẹ ibojì rẹ̀ wò lọdọọdun.’ Mo wipe: ‘Bí ẹyin bá kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ẹ sì tẹle awọn ẹ̀kọ́ Ọlọrun, ẹyin yoo rí baba yin onífẹ̀ẹ́ ninu paradise ilẹ̀-ayé kan.’ Nigba naa mo fun un ní Iwe Itan Bibeli Mi. Nisinsinyi olùkọ́ wa nka àkòrí kọọkan ninu ìwé yii fun gbogbo kilaasi lákòókò ounjẹ ọ̀sán ní ọsẹ kọọkan.”
10. Ete rere wo ni ìwé naa Young People Ask ti ṣeranwọ fun, kí sì ni apẹẹrẹ diẹ?
10 Awọn ọ̀dọ́ ní ìgbà ọ̀dọ́langba wọn ti lò ìwé naa Questions Young People Ask—Answers That Work lọna rere, fun ìdákẹ́kọ̀ọ́ funra ẹni ati ninu jíjẹ́rìí fun awọn ọ̀dọ́ miiran. Awọn òbí pẹlu ti mọrírì ìwé yii. Arabinrin kan ní Switzerland, forúkọsílẹ̀ gẹgẹ bi aṣaaju-ọna oluranlọwọ, ó pinnu lati bẹ awọn òbí awọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ ọmọ rẹ̀ wò. Eyi pèsè àyè fun ìjíròrò rere pẹlu ọpọlọpọ òbí ti oun si fi ìwé 20 (tí pupọ julọ jẹ́ Young People Ask) ati ìwé-ìròhìn 27 sílẹ̀ pẹlu wọn. Nigbati obinrin ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ kan ní Trinidad fi ìwé yii silẹ pẹlu olùkọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́, iya rẹ̀ parí ìgbésẹ̀ naa, ní pípín ẹ̀dá 25 láàárín awọn 36 òṣìṣẹ́. Oun nbaalọ wọnú oṣu tí ó tẹle e pẹlu àfiyèsí àkànṣe fun awọn òbí tí oun mọ̀ fúnraarẹ̀, ó pín 92 ìwé miiran ó sì bẹ̀rẹ̀ awọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé titun. Ní Korea olùkọ́ kan ni ilé-ẹ̀kọ́ awọn ọmọde lò ìwé naa Young People Ask ní fífúnni ní awọn asọye kúkúrú lórí irú awọn àkòrí bíi “Bawo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ipò-ìtẹ̀síwájú-ẹ̀kọ́ Mi Sunwọ̀nsíi?” ati “Bawo Ni Mo Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Pẹlu Olùkọ́ Mi?” ó sì fi ìwé naa lọni. Lẹhin tí awọn akẹ́kọ̀ọ́ ti gba ìwé 39, awọn òbí diẹ bẹrẹsii wíjọ́. Ṣugbọn olùkọ́ àgbà ṣàyẹ̀wò ẹ̀dà kan, ó pè é ní “agbayanu,” ó sì beere ọ̀kan fun ọmọbinrin rẹ̀.
Ìmọ̀-ẹ̀kọ́ Dídárajùlọ
11, 12. Kinni awọn ẹ̀rí diẹ sí òtítọ́ naa pe awọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society ńpèsè ẹ̀kọ́ dídára julọ?
11 Ìníyelórí awọn ìwé-ìròhìn wa niti ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ni ọpọlọpọ tún mọrírì, fun apẹẹrẹ gẹgẹbi ilé-ẹ̀kọ́ U.S. kan tí ó beere fun 1,200 ẹ̀dà Ji! ti July 22, 1990 [lédè Gẹẹsi], (tí ó gbé kíkó oogun crack jẹ sí ojútáyé) fun lílò ninu awọn kilaasi rẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwà àwòfiṣàpẹẹrẹ ti awọn ọmọ Ẹlẹrii Jehofa ní ilé-ẹ̀kọ́ nbaalọ lati wunilori lọna rere. Ninu kilaasi aláriwo kan ní Thailand, olùkọ́ naa pe Racha ẹni ọdun 11 siwaju kilaasi naa ó sì gbóríyìn fun un nitori ìwà rẹ̀, ní wiwi pe: “Eeṣe tí gbogbo yin kò fi mú un gẹgẹ bi apẹẹrẹ yin? Oun jẹ́ aláápọn ninu ẹkọ rẹ ó sì mọ̀wàáhù.” Lẹhin naa ó fikun un: “Ó dára, mo ro pe ẹyin yoo nilati di ọ̀kan lára awọn Ẹlẹrii Jehofa bíi Racha lati lè mú ìwà yin sunwọ̀n síi.”—Fiwera pẹlu Owe 1:8; 23:22, 23.
12 Ọ̀dọ́ arabinrin kan ní Dominican Republic kọ̀wé: “Nigbati mo jẹ́ ẹni ọdun mẹrin péré, ó kù diẹ kí npari ẹkọ mi ni ilé-ẹ̀kọ́ alakọkọbẹrẹ kan nipa ìsìn, níbití mo ti kẹ́kọ̀ọ́ lati kà ati lati kọ. Gẹgẹbi ẹ̀bùn, mo fun obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́-anìkàndágbé tí ó jẹ́ olùkọ́ mi ní ìwé naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye pẹlu ìhìn-iṣẹ́ naa: ‘Mo dupẹ gidigidi pe iwọ kọ́ mi lati kà ati lati kọ. O wu mi pe ki iwọ tún lóye ìgbàgbọ́ mi pẹlu kí o sì wá ní ireti mi ti wiwalaaye titilae lórí ilẹ̀-ayé yii nigbati a bá sọ ọ́ di paradise kan.’ Nitori eyi a lé mi jáde kuro ní ilé-ẹ̀kọ́ naa. Ọdun mẹjọ lẹhin naa mo tún pàdé olùkọ́ yii. Oun ròhìn bí o ti ṣaṣeyọri lati ka iwe naa, láìka àtakò pupọ lati ọ̀dọ̀ alufaa sí. Ó ṣí lọ sí olú ìlú naa, níbití ó ti ṣeeṣe fun un lati kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu Ẹlẹrii kan. A baptisi rẹ̀ ní Apejọpọ Àgbègbè ‘Èdè Mímọ́gaara’ papọ̀ pẹlu mi.” Gẹgẹbi a ti sọtẹ́lẹ̀, àní ọgbọ́n lè wá pàápàá lati “ẹnu awọn ọmọ-ọwọ́”!—Matiu 21:16, NW; Saamu 8:1, 2.
13. Bawo ni ọpọlọpọ awọn ọ̀dọ́langba ṣe ńdáhùnpadà sí ìmọ̀ràn Solomọni, bawo sì ni a ṣe fi eyi hàn ninu ìròhìn yíká-ayé?
13 Solomọni fúnni ní ìmọ̀ràn afúnni níṣìírí naa: “Máa yọ̀, iwọ ọ̀dọ́mọdé ninu èwe rẹ; kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó mú ọ lárayá ní ọjọ́ èwe rẹ, kí o sì maa rìn nipa ọ̀nà ọkàn rẹ.” (Oniwaasu 11:9) Ó jẹ́ ìdùnnú lonii lati rí ọpọlọpọ ọmọ awọn Ẹlẹrii Jehofa tí wọn ńfi awọn ọ̀rọ̀ wọnyi sílò, ní lílò awọn ọdun ọ̀dọ́langba wọn lati múrasílẹ̀ fun igbesi-aye iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún sí Jehofa ati wíwọnú awọn iṣẹ́ ìgbésí-ayé títóbilọ́lá julọ yii gẹgẹ bi wọn ti npari ẹkọ iwe wọn. Awọn òtú aṣaaju-ọna nbaalọ lati pọ̀síi lọna yíyára kánkán, pẹlu 821,108 ti wọn rohin ninu ọdun naa. Papọ pẹlu 11,092 awọn ara lọkunrin ati lobinrin ti wọn nṣiṣẹsin ni Bethel, ti wọn jẹ ipin 21 ninu ọgọrun-un ninu aropọ awọn akede!
14. Àjọpín wo ni awọn arabinrin wa ńṣe, ìgbóríyìn wo ni wọn sì lẹ́tọ̀ọ́sí?
14 Ó dùnmọ́ni pe ni ọpọlọpọ ilẹ̀, irú bii United States nǹkan bíi ìpín 75 nínú ọgọrun-un gbogbo awọn akéde aṣaaju-ọna jẹ́ arabinrin, ni fifi ipá kún awọn ọ̀rọ̀ Saamu 68:11 (NW) pe: “Jehofa fúnraarẹ̀ wipe ‘awọn obinrin tí ńsọ ihinrere jẹ́ ogun ńlá.’” Awọn arabinrin wa ni a nilati gbóríyìn fun niti pe wọn ńṣe apá títóbijùlọ ninu iṣẹ́ pápá naa. Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ jijafafa wọn nibi awọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inu ilé ńṣamọ̀nà ọpọlọpọ sí otitọ naa, awọn arabinrin tí wọn ti ṣègbéyàwó tí wọn sì ńfi pẹlu ìdúróṣinṣin ti awọn ọkọ wọn tí wọn ní ọpọlọpọ iṣẹ́ ninu ijọ lẹhin ni a tún nilati yìn pẹlu ọyàyà.—Owe 31:10-12; Efesu 5:21-25, 33.
Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Ńgbalẹ̀
15. (a) Bawo ni awọn orílẹ̀-èdè diẹ tí a ṣàkọsílẹ̀ ninu ìròhìn yíká-ayé ṣe tayọ ninu ìgbòkègbodò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inu ilé? (b) Awọn ìrírí wo ni iwọ lè sọ, tí ó ńfi bí awọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣe lè jẹ́ eléso tó hàn?
15 Iṣẹ́ ikọnilẹkọọ Bibeli ńgbalẹ̀, a ndari awọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli yíká ayé ní ipindọgba awọn ibi ti wọn to 3,624,091 loṣooṣu. Otitọ Bibeli lè yí awọn ànímọ́ iwa padà, gẹgẹbi ìròhìn kan ní ilẹ̀ apa ìsàlẹ̀ aye ti fihàn. Ní ìbẹ̀rẹ̀ January 1987, ọkunrin kan ni a lélọ kúrò ní ìlú sí New Zealand lati Australia lẹhin ṣíṣe oṣu 25 ninu túbú fun ìwà-ọlọ́ṣà ati ìyíwèé. Oun ti sọ oògùn di baraku ó sì tún nta wọn kiri fun ohun tí ó ju 17 ọdun lọ. Ní ọdun tí ó tẹle e aya rẹ̀ bẹrẹsii kẹ́kọ̀ọ́ pẹlu awọn Ẹlẹrii Jehofa, ati gẹgẹbi ìmọ̀ rẹ̀ ti npọsii, ọkunrin naa ṣàkíyèsí ìyípadà pípẹtẹrí ninu ìwà rẹ̀. Oun di aya ati iya ti o sanju. Nigba ti aya rẹ̀ rọ̀ ọ́, oun lọ sí apejọ ayika kan ní June 1989. Oun nisinsinyi tẹ́wọ́gbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inu ilé, awọn ìyípadà ńláǹlà ni a sì bẹrẹsii rí ninu ìrísí ati ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ̀. Gbogbo awọn mẹmba meje idile naa bẹrẹsii lọ sí awọn ipade. A baptisi rẹ̀ ní January 1990 gẹgẹbi ẹnikan tí ó ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn Pọọlu ní Efesu 4:17-24.
16. (a) Bawo ni awọn ìròhìn Iṣe-iranti 1990 ṣe jẹ́ orísun ayọ̀? (b) Ìjẹ́kánjúkánjú wo ni a nilati ṣàkíyèsí, ìsapá wo sì ni a nilati ṣe lati ṣèrànlọ́wọ́?
16 Apá-ẹ̀ka titayọ ninu ìròhìn ọdun naa ni akọsilẹ 9,950,058 iye awọn ènìyàn tí wọn wá sí ayẹyẹ Iṣe-iranti, tí a ṣe ní Tuesday, April 10, 1990. Iye ti o ju 70 lọ ninu 212 awọn orílẹ̀-èdè ròhìn iye awọn ènìyàn tí wọn wá tí wọn fi ilọpo mẹta ju gongo iye awọn akede wọn lọ! Fun apẹẹrẹ, laika ikalọwọko si, awọn orilẹ-ede Africa meje pẹlu apapọ gongo 62,712 awọn akede rohin 204,356 awọn ti wọn wa sibi Iṣe-iranti. Awọn akede 1,914 ni Liberia ti ogun ti bajẹ yọ lati ri 7,811 eniyan ti wọn wa sibi Iṣe-iranti. Haiti, pẹlu gongo akede ti o jẹ 6,427, rohin 36,551. Awọn 886 akede ni awọn erekuṣu Micronesia ti ko korajọ soju kan ni 3,958. Awọn 1,298 akede ti wọn wa ni Sri Lanka rohin 4,521, Zambia ni tirẹ, ti o ni 73,729 akede, ni 326,991 awọn eniyan ti wọn wa si Iṣe-iranti, iṣiro eniyan kan si eniyan mẹẹdọgbọn ninu aropọ iye eniyan Zambia. Ìròhìn yíká ilẹ̀-ayé ṣípayá lẹẹkan síi pe araadọta ọkẹ awọn ènìyàn olótìítọ́-inú nbẹ tí wọn ńretí kí a kó wọn jọ sínú agbo àgùtàn. Ṣugbọn otitọ-inu nikan kò tó. Njẹ awa lè mú ìjójúlówó iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inu ilé wa sunwọ̀n síi kí a sì mú un pọ̀síi, kí a baa ran pupọ awọn olùwá sibi Iṣe-iranti lọwọ lati lè gbe ìgbàgbọ́ alágbára ro? Awa fẹ́ kí wọn di alábàákẹ́gbẹ́ wa ti ngbekankan ṣiṣẹ, tí wọn nyin Jehofa. Ó tumọsi iwalaaye wọn gan-an!—Saamu 148:12, 13; Johanu 17:3; 1 Johanu 2:15-17.
Ẹkunrẹrẹ Ayọ̀
17. Awọn apẹẹrẹ ọ̀rúndún kìn-ínní wo ni wọn nilati ṣeranwọ lati fun ìpinnu wa lókun lati di ayọ̀ wa mú pinpin?
17 Ohunkohun tí ó lè jẹ́ àdánwò tí ó dojúkọ wa, ẹ jẹ́ kí a pinnu lati di ayọ̀ wa mú pinpin. Ó ṣeeṣe kí awa má la ìrírí tí ó nira gan-an gẹgẹbi ti Stefanu kọjá, sibẹ apẹẹrẹ rere rẹ̀ lè fun wa lókun. Lábẹ́ ẹ̀sùn, oun lè pa ìbàlẹ̀-ọkàn aláyọ̀ mọ́. Awọn ọ̀tá rẹ̀ “ńwo ojú rẹ̀ bí ẹnipe ojú angeli.” Ọlọrun dúró tì í láàárín àkókò ìrírí adánniwò rẹ̀. Oun jẹ́rìí pẹlu àìṣojo, niwọnbi ó ti “kún fun ẹ̀mí mímọ́” jálẹ̀ títí de ikú ajẹ́rìíkú rẹ̀. Bi Pọọlu ati Barnaba ti yípadà sí awọn orílẹ̀-èdè ninu iwaasu wọn, awọn wọnyi pẹlu “yọ̀ wọn sì yin ọ̀rọ̀ Ọlọrun lógo.” Inúnibíni dìde lẹẹkan síi. Ṣugbọn kò mú awọn wọnni tí wọn gbàgbọ́ rẹ̀wẹ̀sì. “Awọn ọmọ-ẹhin sì kún fun ayọ̀ ati fun ẹ̀mí mimọ.” (Iṣe 6:15; 7:55; 13:48-52) Ohun yoowu kí awọn ọ̀tá wa ṣe sí wa, ohun yoowu kí ó jẹ awọn àdánwò wa ninu igbesi-aye ojoojumọ, awa kò gbọdọ jẹ́ kí ayọ̀ ẹ̀mí mímọ́ wa di tútù. Pọọlu gbaninímọ̀ràn: “Ẹ maa yọ̀ ní ìrètí; ẹ maa mú suuru ninu ìpọ́njú; ẹ maa dúró gangan ninu adura.”—Romu 12:12.
18. (a) Kinni Jerusalẹmu Titun naa, eesitiṣe tí awọn ènìyàn Ọlọrun fi nilati yọ̀ ninu rẹ̀? (b) Bawo ni “awọn ọrun titun ati ayé titun” yoo ṣe bukun aráyé?
18 Bawo ni ireti yẹn ti jẹ agbayanu tó! Sí gbogbo awọn ènìyàn rẹ̀, Jehofa polongo pe: “Sáwò ó, emi [ńdá awọn] ọ̀run titun ati ayé titun: a kì yoo sì ranti awọn ti iṣaaju, bẹẹ ni wọn kì yoo wá sí àyà. Ṣugbọn kí ẹyin kí ó yọ̀, kí inú yin kí ó sì dùn titilae ninu eyi tí emi [dá].” Kristi Oluwa naa papọ̀ pẹlu “Jerusalẹmu Titun” (tí ó jẹ́ olú ìlú ètò-àjọ ọ̀run ti Ọlọrun, “Jerusalẹmu ti òkè” nisinsinyi) ati ẹgbẹ́ àwùjọ ayé titun lórí ilẹ̀-ayé yoo mú ayọ̀ pupọ wá fun aráyé. (Galatia 4:26) Ajinde awọn òkú ènìyàn, gbigbe gbogbo awọn ènìyàn onígbọràn dide sí iye ainipẹkun ninu ipo ẹ̀dá-ènìyàn pípé, ti iwalaaye wíwúlò, tí ó jípépé lórí paradise ilẹ̀-ayé titi ayeraye—irú ireti titobilọla ati ìdí fun ayọ̀ àṣeyọrí wo ni eyi jẹ́! Gẹgẹbi Jehofa fúnraarẹ̀ ti rí ‘ayọ̀ ninu Jerusalẹmu tí ó sì yọ ayọ̀ àṣeyọrí ninu awọn ènìyàn rẹ̀,’ bẹẹ ni wolii rẹ̀ ṣe ṣe ìkésíni siwaju síi fun awọn ènìyàn Ọlọrun: “Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yin sì dùn pẹlu rẹ̀, gbogbo ẹyin tí ó fẹ́ ẹ; ẹ bá a yọ̀ fun ayọ̀.” (Aisaya 65:17-19; 66:10; Iṣipaya 14:1; 20:12, 13; 21:2-4) Njẹ kí awa kún fun ayọ̀ ati ẹ̀mí mimọ titilae gẹgẹbi a ti ńkọbiara sí ọrọ ìṣílétí apọsteli Pọọlu: “Ẹ maa yọ̀ ninu Oluwa [“Jehofa,” NW] nigbagbogbo: mo sì tún wí, Ẹ maa yọ̀.”—Filippi 4:4.
Ṣíṣàkópọ̀ Ayọ̀ Wa:
◻ Apẹẹrẹ ìfaradà aláyọ̀ wo ni Jesu ti fisílẹ̀ fun wa?
◻ Awọn àwùjọ olùṣèyàsímímọ́ meji ní awọn ìdí wo lati yọ̀?
◻ Bawo ni awọn èwe ati àgbà lonii ṣe ńyọ ayọ̀ àṣeyọrí ninu otitọ?
◻ Ni ṣíṣàtúnyẹ̀wò ìròhìn ọdun 1990, ìdáhùn wo nisinsinyi ni a ti ńfún adura naa, “Jehofa, awa bẹ ọ, jẹ ki a ṣe aṣeyọrisirere”?
◻ Nigbawo ati bawo ni awa yoo ṣe wá ní ẹkunrẹrẹ ayọ̀?
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 18-21]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 1990 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Angeli Jehofa kede ìbí Kristi Oluwa gẹgẹbi “ihinrere ayọ̀ ńláǹlà”