Má Ṣe Máa Wo Àwọn Ohun Tí Kò Ní Láárí!
“Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí; pa mí mọ́ láàyè ní ọ̀nà tìrẹ.”—SM. 119:37.
1. Báwo ni ẹ̀bùn ojú tí Ọlọ́run fún wa ti ṣe pàtàkì tó?
OJÚ wa ṣeyebíye gan-an ni! A máa ń lò ó láti fi wo oríṣiríṣi ẹwà àti àwọ̀ tó wà láyìíká wa. Ojú la fi ń rí àwọn ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n tàbí àwọn ewu tó yẹ ká sá fún. À ń fi ojú wo àwọn ohun rírẹwà, a fi ń mọyì àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run dá, a sì fi ń rí àwọn ohun tó ń jẹ́rìí sí wíwà Ọlọ́run àti ọlá ńlá rẹ̀. (Sm. 8:3, 4; 19:1, 2; 104:24; Róòmù 1:20) Pàtàkì ni ojú jẹ́ nínú ẹ̀yà ara tó máa ń gbé ìsọfúnni lọ sínú ọpọlọ, torí náà iṣẹ́ pàtàkì ló ń ṣe láti mú ká ní ìmọ̀ Jèhófà ká sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Jóṣ. 1:8; Sm. 1:2, 3.
2. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fọwọ́ kékeré mú àwọn ohun tá à ń rí, kí la sì lè rí kọ́ látinú ẹ̀bẹ̀ tí onísáàmù náà fi ìtara bẹ Ọlọ́run?
2 Àmọ́ ṣá o, àwọn ohun tá à ń fojú rí tún lè ṣàkóbá fún wa. Àwòrán tí ojú bá gbé lọ sínú ọpọlọ máa ń lágbára débi pé ó lè mú kí àwọn èrò kan sọ sí wa lọ́kàn tàbí kó túbọ̀ máa wù wá láti ṣe àwọn ohun kan. Àti pé, nítorí pé à ń gbé nínú ayé bíbàjẹ́ bàlùmọ̀ tí Sátánì Èṣù ń ṣàkóso, táwọn èèyàn ti máa ń fẹ́ tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn, ọ̀pọ̀ àwòrán àti àwọn ìpolongo èké tó ń rọ́ wọlé tọ̀ wá wá lè kóni ṣìnà, kódà kó jẹ́ pé ńṣe la wò wọ́n fìrí. (1 Jòh. 5:19) Abájọ tí onísáàmù náà fi bẹ Ọlọ́run pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí; pa mí mọ́ láàyè ní ọ̀nà tìrẹ.”—Sm. 119:37.
Bí Ojú Wa Ṣe Lè Ṣì Wá Lọ́nà
3-5. Àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì wo ló jẹ́ ká rí ewu tó wà nínú jíjẹ́ kí ojú wa mú ká ṣe ohun tí a kò fẹ́ ṣe?
3 Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Éfà, obìnrin àkọ́kọ́, yẹ̀ wò. Sátánì sọ fún un pé “ó dájú pé ojú [rẹ̀] yóò là” bó bá jẹ èso “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” Ara Éfà ti ní láti wà lọ́nà nígbà tó gbọ́ pé ojú òun máa “là.” Ohun tó tún wá mú kó túbọ̀ wù ú láti jẹ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ yẹn ni pé ó “rí i pé igi náà dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni, bẹ́ẹ̀ ni, igi náà fani lọ́kàn mọ́ra láti wò.” Bí Éfà ṣe yán hànhàn fún èso tó wà lórí igi náà ló sún un tó fi ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run. Ádámù, ọkọ rẹ̀ náà ṣàìgbọràn, ìyẹn sì mú àbájáde bíburú jáì wá sórí gbogbo aráyé.—Jẹ́n. 2:17; 3:2-6; Róòmù 5:12; Ják. 1:14, 15.
4 Ohun tí àwọn áńgẹ́lì kan rí nígbà ayé Nóà nípa lórí àwọn náà. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 6:2 sọ nípa wọn pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.” Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yẹn ní sí àwọn ọmọbìnrin èèyàn tí wọ́n ń wò, mú kó wù wọ́n láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn. Ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ yìí sì mú kí àwọn ọmọbìnrin náà bí àwọn jàgídíjàgan ọmọ fún wọn. Ìwà búburú táwọn èèyàn ń hù nígbà yẹn mú kí Ọlọ́run pa gbogbo èèyàn run. Nóà àti ìdílé rẹ̀ nìkan ló dá sí.—Jẹ́n. 6:4-7, 11, 12.
5 Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, ohun tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Ákáánì rí wọ̀ ọ́ lójú tó fi jí díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó rí nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun ìlú Jẹ́ríkò. Ọlọ́run pàṣẹ pé gbogbo ohun tí wọ́n bá rí ní ìlú náà ni kí wọ́n pa run, àyàfi àwọn nǹkan tó bá yẹ kí wọ́n kó lọ sí ibi ìṣúra Jèhófà. Ọlọ́run kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ yẹra fún àwọn nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun, kí ojú yín má bàa wọ̀ ọ́” kí ẹ sì tipa bẹ́ẹ̀ kó lára àwọn ohun tí ẹ bá rí nínú ìlú náà. Nígbà tí Ákáánì ṣàìgbọràn sí àṣẹ yìí, àwọn ará ìlú Áì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọ̀pọ̀ lára wọn sì kú. Ákáánì ò jẹ́wọ́ olè tó jà títí tí àṣírí rẹ̀ fi tú. Ó sọ pé “nígbà tí mo rí” àwọn nǹkan náà, “nígbà náà ni mo fẹ́ ní wọn, mo sì kó wọn.” Ohun tó wọ̀ ọ́ lójú ló mú kí òun àti “ohun gbogbo tí ó jẹ́ tirẹ̀” di èyí tí a pa run. (Jóṣ. 6:18, 19; 7:1-26) Ọkàn Ákáánì fà sí ohun tí Ọlọ́run sọ pé kò gbọ́dọ̀ ṣe.
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Kíyè Sára
6, 7. Èwo nínú “àwọn ète ọkàn” Sátánì ló sábà máa ń lò láti dẹkùn mú wa, báwo làwọn tó ń polówó ọjà sì ṣe máa ń lò ó?
6 Ọ̀nà tí Èṣù gbà tan Éfà, àwọn áńgẹ́lì tó ṣàìgbọràn àti Ákáánì jẹ, ló ń gbà tan aráyé jẹ lónìí. Nínú “àwọn ète ọkàn” tí Sátánì ń lò láti ṣi aráyé lọ́nà, “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” ló ṣì lágbára jù lọ. (2 Kọ́r. 2:11; 1 Jòh. 2:16) Àwọn tó ń polówó ọjà lóde òní mọ̀ pé ọjọ́ pẹ́ tí ohun táwọn èèyàn bá rí ti máa ń wù wọ́n. Ògbóǹkangí onímọ̀ nípa káràkátà kan nílẹ̀ Yúróòpù sọ pé: “Ojú ni ẹ̀yà ara tó dùn ún tàn jẹ jù lọ. Ńṣe ló máa ń tẹ àwọn ẹ̀yà ara tó kù lórí ba, ó sì lágbára láti mú kéèyàn ṣe ohun téèyàn mọ̀ pé kò tọ́.”
7 Abájọ tí àwọn tó ń polówó ọjà fi máa ń gbé ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwòrán tí wọ́n fọgbọ́n hùmọ̀ wá sí ojútáyé lọ́nà táá mú kí wọ́n jẹ́ àrímáleèlọ, kéèyàn bàa lè fẹ́ láti ra ọjà wọn tàbí kó gbé iṣẹ́ fún wọn. Olùṣèwádìí ará ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tó ṣèwádìí nípa bí ìpolówó ọjà ṣe máa ń nípa lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan sọ pé wọ́n “ṣe é tó fi jẹ́ pé kì í ṣe pé onítọ̀hún á wulẹ̀ gbọ́ ìpolówó náà, àmọ́ ohun tó gbọ́ máa fà á lọ́kàn mọ́ra ó sì máa fẹ́ láti ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀.” Irú ìpolówó tí wọ́n sábà máa ń lò jù lọ ni èyí tó máa ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìbálòpọ̀. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń sọ pé “gbogbo ayé ló ń gba ti ìbálòpọ̀.” Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká máa díwọ̀n ohun tá à ń wò àti ohun tá à ń jẹ́ kó kọjá sínú ọkàn àti àyà wa!
8. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé ó ṣe pàtàkì pé ká pa ojú wa mọ́?
8 Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara lè nípa lórí àwọn Kristẹni pẹ̀lú. Torí náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká máa kíyè sára nípa àwọn ohun tá à ń wò àtàwọn ohun tí ọkàn wa ń fà sí. (1 Kọ́r. 9:25, 27; ka 1 Jòhánù 2:15-17.) Ọkùnrin adúróṣinṣin náà, Jóòbù mọ bí ohun téèyàn rí ṣe máa ń nípa lórí ohun téèyàn ń fẹ́. Ó sọ pé: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá?” (Jóòbù 31:1) Kì í ṣe pé Jóòbù kọ̀ láti fọwọ́ kan obìnrin nítorí àti bá a ṣèṣekúṣe nìkan ni, àmọ́ kò tún ní fẹ́ láti máa ro irú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn. Jésù tẹnu mọ́ ọn pé a kò gbọ́dọ̀ gba èròkérò kankan láyè nínú ọkàn wa, ìyẹn ló fi sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Mát. 5:28.
Àwọn Ohun Tí Kò Ní Láárí Tó Yẹ Ká Sá Fún
9. (a) Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa kíyè sára nígbà tá a bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì? (b) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àkókò díẹ̀ lèèyàn fi wo àwòrán oníhòòhò?
9 Nínú ayé tá à ń gbé lónìí, ó túbọ̀ ń wọ́pọ̀ sí i pé káwọn èèyàn ‘máa bá a nìṣó ní wíwo’ àwòrán oníhòòhò, pàápàá jù lọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kò dìgbà tá a bá ń wá irú ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì bẹ́ẹ̀ kiri, àwọn gan-an ló ń wá wa! Lọ́nà wo? Ìpolówó kan tó ní àwòrán tó fani mọ́ra lè ṣàdédé yọ gannboro sí ojú kọ̀ǹpútà wa. A sì lè rí lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tó dà bí èyí tí kò léwu gbà, àmọ́ gbàrà tá a bá ti ṣí lẹ́tà náà wò, àwọn àwòrán oníhòòhò lè bẹ̀rẹ̀ sí fara hàn táá sì wá ṣòro láti mójú kúrò lára wọn. Kódà, bó ṣe ìwọ̀nba díẹ̀ lèèyàn rí lára rẹ̀ kó tó pa á, àwòrán yẹn ti kọjá sínú ọpọlọ. Ọṣẹ́ tí wíwo àwòrán oníhòòhò ń ṣe kò kéré rárá, ì báà tiẹ̀ ṣe àkókò díẹ̀ lèèyàn fi wò ó. Ó lè mú kí ẹ̀rí ọkàn máa dáni lẹ́bi léraléra, kéèyàn sì máa jìjàkadì láti mú ọkàn kúrò lára àwòrán náà. Èyí tó tún wá burú jù lọ ni pé bí ẹnikẹ́ni bá “ń bá a nìṣó ní wíwo” àwòrán oníhòòhò, ńṣe nìyẹn ń fi hàn pé kò tíì sọ ìfẹ́ ọkàn búburú tó ní di òkú.—Ka Éfésù 5:3, 4, 12; Kól. 3:5, 6.
10. Kí nìdí tó fi tètè máa ń wu àwọn ọmọdé láti wo àwòrán oníhòòhò, kí ló sì lè ṣẹlẹ̀ sí wọn bí wọ́n bá ń wò ó?
10 Nítorí pé àwọn ọmọdé fẹ́ràn láti máa ṣe ojúmìító, ó ṣeé ṣe kó máa wù wọ́n láti wo àwòrán oníhòòhò. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè nípa tí kò dáa lórí ojú tí wọ́n á máa fi wo ìbálòpọ̀. Ìròyìn kan tiẹ̀ sọ pé, ipa tó máa ní lórí wọn yìí á mú kí wọ́n ní èrò òdì nípa ìbálòpọ̀, á sì tún mú kó “ṣòro fún wọn láti mọ béèyàn ṣe ń fi ìfẹ́ báni lò, láìjà láìta; wọ́n á máa fi ojú tí kò tọ́ wo àwọn obìnrin; wọ́n lè di ẹni tí wíwo àwòrán oníhòòhò di bárakú fún, èyí sì lè mú kí wọ́n má lè pọkàn pọ̀ níléèwé, kí àárín wọn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé wọn má sì gún mọ́.” Èyí tó tiẹ̀ wá burú ju gbogbo rẹ̀ lọ ni pé ó lè ṣàkóbá fún wọn tí wọ́n bá gbéyàwó lọ́jọ́ iwájú.
11. Fúnni ní àpẹẹrẹ kan tó lè jẹ́ ká mọ ewu tó wà nínú wíwo àwòrán oníhòòhò.
11 Arákùnrin kan sọ pé: “Nínú gbogbo nǹkan tí mo sọ di bárakú kí n tó di Ẹlẹ́rìí, wíwo àwòrán oníhòòhò ni àṣà tó ṣòro jù lọ fún mi láti jáwọ́ nínú rẹ̀. Àwọn àwòrán yìí ṣì máa ń sọ sí mi lọ́kàn nígbà tí mo bá gbọ́ òórùn kan, ohùn orin kan, tí mo bá rí ohun kan, tàbí ìgbà tí mi ò bá ní ohun kan pàtó tí mò ń rò. Ojoojúmọ́ ni mò ń gbéjà ko èrò búburú náà, láìsinmi.” Arákùnrin mìíràn tún wà tó jẹ́ pé nígbà tó wà lọ́mọdé, ó máa ń wo ìwé àwòrán oníhòòhò tí bàbá rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tọ́jú sínú ilé, nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ kò bá sí nílé. Ó kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, ipa búburú ni àwọn àwòrán wọ̀nyẹn máa ń ní lórí mi! Kódà, lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, mo ṣì máa ń rántí díẹ̀ lára àwọn àwòrán yẹn. Bí mo ti ń sapá láti gbé wọn kúrò lọ́kàn tó, wọ́n ò kúrò lọ́kàn mi. Èyí máa ń mú kí n dá ara mi lẹ́bi bó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í ronú lé wọn lórí.” Ẹ wo bó ti bọ́gbọ́n mu tó pé kéèyàn má di ẹrù ìnira ru ara rẹ̀ nípa wíwo àwọn ohun tí kò ní láárí! Ọ̀nà wo lẹnì kan lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ó gbọ́dọ̀ sapá láti mú “gbogbo ìrònú wá sí oko òǹdè láti mú un ṣègbọràn sí Kristi.”—2 Kọ́r. 10:5.
12, 13. Àwọn ohun tí kò ní láárí wo ni kò yẹ káwọn Kristẹni máa wò, kí sì nìdí?
12 Ohun míì “tí kò dára fún ohunkóhun,” tàbí tí kò ní láárí tá a gbọ́dọ̀ sá fún ni eré ìnàjú tó ń gbé ìfẹ́ fún ọrọ̀ tàbí iṣẹ́ awo lárugẹ tàbí èyí tó ń gbé ìwà ipá, ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìpànìyàn sáfẹ́fẹ́. (Ka Sáàmù 101:3.) Jèhófà fẹ́ kí àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ṣe àṣàyàn ohun tí wọ́n á gba àwọn ọmọ wọn láyè láti máa wò nínú ilé wọn. Òótọ́ ni pé kò sí Kristẹni tòótọ́ tó máa mọ̀ọ́mọ̀ lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò. Síbẹ̀, ó yẹ kí àwọn òbí mọ irú fíìmù, eré orí tẹlifíṣọ̀n, géèmù fídíò, àwọn eré àwòrẹ́rìn-ín àtàwọn ìwé ọmọdé tó ń gbé agbára òkùnkùn lárugẹ yálà lọ́nà tó ṣe tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà.—Òwe 22:5.
13 Yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà, kò yẹ ká máa fi àwọn géèmù fídíò tó ń gbé ìwà ipá lárugẹ tí wọn sì ti ń dúńbú èèyàn bí ẹní dúńbú ẹran, dá ara wa lára yá. (Ka Sáàmù 11:5.) A kò gbọ́dọ̀ máa pọkàn pọ̀ sórí ìgbòkègbodò èyíkéyìí tí Jèhófà bá sọ pé kò dáa. Ká sì máa rántí pé èrò ọkàn wa gan-an ni Sátánì ń fojú sùn. (2 Kọ́r. 11:3) Kódà, bá a bá rò pé eré ìdárayá kan kò burú, tá a sì ń lo àkókò tó pọ̀ jù láti máa wo eré ìdárayá náà, ìyẹn pẹ̀lú lè máa gba àkókò tó yẹ ká lò fún ìjọsìn ìdílé, kíka Bíbélì lójoojúmọ́ àti mímúra sílẹ̀ fáwọn ìpàdé.—Fílí. 1:9, 10.
Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
14, 15. Kí ni ohun tó gbàfiyèsí nínú ọ̀nà tí Sátánì gbà dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kẹta, báwo sì ni Jésù ṣe kojú ìdánwò náà?
14 Ó ṣeni láàánú pé kò sí bí a ò ṣe ní máa rí àwọn ohun kan tí kò ní láárí, nínú ayé burúkú yìí. Kódà, Èṣù fi irú àwọn nǹkan tí kò ní láárí bẹ́ẹ̀ han Jésù. Nígbà tí Èṣù gbìdánwò lẹ́ẹ̀kẹta láti mú kí Jésù jáwọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó “mú un lọ sí òkè ńlá kan tí ó ga lọ́nà kíkàmàmà, ó sì fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án.” (Mát. 4:8) Kí nìdí tí Sátánì fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ó dájú pé ńṣe ló fẹ́ kí Jésù lo ojú rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́. Bó ṣe mú kí Jésù rí ọlá ńlá àti ògo gbogbo àwọn ìjọba ayé lè mú kó fẹ́ láti di gbajúmọ̀ nínú ayé. Àmọ́ kí ni Jésù ṣe?
15 Jésù ò pọkàn pọ̀ sórí ohun fífani mọ́ra tí Èṣù fi lọ̀ ọ́. Kò gba èròkérò láyè nínú ọkàn rẹ̀. Kò sì gbé ohun tí Èṣù fi lọ̀ ọ́ yẹ̀ wò kó tó kọ̀ ọ́. Ó sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó pàṣẹ fún Èṣù lójú ẹsẹ̀ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” (Mát. 4:10) Àjọṣe tí Jésù ní pẹ̀lú Jèhófà ló jẹ ẹ́ lógún, ó sì dáhùn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó tìtorí rẹ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn ni láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Héb. 10:7) Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún Jésù láti borí ọgbọ́n àrékérekè Sátánì.
16. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú bí Jésù ṣe kọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn ìdẹwò Sátánì?
16 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù. Àkọ́kọ́, kò sẹ́ni tí Sátánì ò lè fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ dán wò. (Mát. 24:24) Èkejì, ohun tá a bá ń tẹ ojú wa mọ́ lè mú kí ìfẹ́ ọkàn wa lágbára, yálà láti ṣe rere tàbí búburú. Ẹ̀kẹta, Sátánì máa ń lo “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” débi tó bá lè lò ó dé bó ṣe ń gbìyànjú láti ṣì wá lọ́nà. (1 Pét. 5:8) Ìkẹrin ni pé àwa pẹ̀lú lè kọjú ìjà sí Sátánì, ìyẹn bá a bá gbégbèésẹ̀ láìjáfara.—Ják. 4:7; 1 Pét. 2:21.
Ẹ Jẹ́ Kí Ojú Yín “Mú Ọ̀nà Kan”
17. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé ká dúró di ìgbà tá a bá rí ohun tí kò ní láárí ká tó pinnu ohun tá a máa ṣe?
17 Lára ìlérí tá a ṣe nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà ni pé a kò ní máa wo àwọn ohun tí kò ní láárí. Ńṣe ni ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run mú ká dara pọ̀ mọ́ onísáàmù náà ní sísọ pé: “Èmi ti kó ẹsẹ̀ mi ní ìjánu kúrò nínú gbogbo ipa ọ̀nà búburú, kí èmi kí ó lè máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.” (Sm. 119:101) Kò bọ́gbọ́n mu pé ká dúró di ìgbà tá a bá rí ohun tí kò ní láárí ká tó pinnu ohun tá a máa ṣe. Ìwé Mímọ́ ti jẹ́ káwọn nǹkan tí Ọlọ́run kò fẹ́ ṣe kedere sí wa. A kò ṣaláì mọ àwọn ète ọkàn Sátánì. Ìgbà wo ni Sátánì dán Jésù wò pé kó sọ òkúta di ìṣù búrẹ́dì? Lẹ́yìn tó ti gbààwẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru tí ‘ebi sì ń pa á.’ (Mát. 4:1-4) Ó ṣeé ṣe fún Sátánì láti mọ ìgbà tí agbára wa bá dín kù tá a sì lè tètè juwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò. Torí náà, ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká fara balẹ̀ gbé àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí yẹ̀ wò. A kò gbọ́dọ̀ sọ ọ́ di ìgbà mìíràn! Bí a bá ń rántí ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ fún Jèhófà lójoojúmọ́, a ó máa dúró gbọn-in lórí ìpinnu wa pé a kò ní máa wo àwọn ohun tí kò ní láárí.—Òwe 1:5; 19:20.
18, 19. (a) Sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ojú tó “mú ọ̀nà kan” àti ojú tó “burú.” (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó ṣeyebíye, ìmọ̀ràn wo sì ni Fílípì 4:8 fún wa nípa ìyẹn?
18 Ìgbà gbogbo là ń rí ọ̀pọ̀ nǹkan mèremère tó ń pín ọkàn níyà, ńṣe ni wọ́n sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́. Èyí lè mú ká mọrírì ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù pé ká jẹ́ kí ojú wa “mú ọ̀nà kan.” (Mát. 6:22, 23) Ohun kan ṣoṣo ni ojú tó “mú ọ̀nà kan” máa ń fojú sùn, ìyẹn ni ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ojú tó “burú” máa ń ṣe àdàkàdekè, gbogbo nǹkan ló máa ń wù ú, ohun tí kò ní láárí sì máa ń fà á mọ́ra.
19 Má ṣe gbàgbé pé ohun tójú bá rí ni ọpọlọ ń rò, ohun tá a bá sì ń rò la máa ń hù níwà. Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà pé ká máa bá a nìṣó láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan tó ṣeyebíye. (Ka Fílípì 4:8) Dájúdájú, a lè máa sọ ọ̀rọ̀ onísáàmù náà ní àsọtúnsọ pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.” Lẹ́yìn náà, bá a ti ń sapá láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà yẹn, a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà máa “pa [wá] mọ́ láàyè ní ọ̀nà [tirẹ̀].”—Sm. 119:37; Héb. 10:36.
Kí Ló Yẹ Ká Rántí Nípa . . .
• bí ojú, ọpọlọ, àti ọkàn-àyà ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀?
• ewu tó wà nínú wíwo àwòrán oníhòòhò?
• bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ kí ojú wa “mú ọ̀nà kan”?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn ohun tí kò ní láárí wo làwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ máa wò?