Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kárùn-Ún Sáàmù
ÀWỌN ọlọ́rọ̀ lè máa sọ pé: “Àwọn ọmọkùnrin wa dà bí àwọn ọ̀gbìn kéékèèké tí ó dàgbà ní ìgbà èwe wọn, àwọn ọmọbìnrin wa dà bí àwọn igun-igun tí a gbẹ́ bí ọnà ààfin, àwọn àró wa kún, . . . àwọn agbo ẹran wa ń pọ̀ sí i ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn olówó lè máa sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí ó rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ fún!” Àmọ́ òdìkejì ohun tí wọ́n ń sọ ni onísáàmù sọ ní tiẹ̀, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!” (Sáàmù 144:12-15) Báwo ni kò ṣe ní rí bẹ́ẹ̀? Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run aláyọ̀, ayọ̀ sì ni ìpín gbogbo àwọn tó ń sìn ín. (1 Tímótì 1:11) Ìsọ̀rí tó kẹ́yìn nínú àwọn orin tí Ọlọ́run mí sí, ìyẹn Sáàmù 107 sí 150, jẹ́ ká rí i kedere pé òtítọ́ lèyí.
Ìsọ̀rí Karùn-ún nínú ìwé Sáàmù tún jẹ́ ká rí àwọn ànímọ́ àtàtà tí Jèhófà ní, àwọn ànímọ́ bí inú-rere-onífẹ̀ẹ́, òótọ́, àti bó ṣe jẹ́ ẹni rere. Bá a bá ṣe túbọ̀ ń ní òye tó jinlẹ̀ nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni yóò túbọ̀ máa wù wá láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti láti bẹ̀rù rẹ̀. Èyí á sì túbọ̀ fi kún ayọ̀ wa. Ẹ ò rí i pé ìtọ́ni tó wà nínú Ìwé Karùn-ún ìwé Sáàmù ṣeyebíye gan-an!—Hébérù 4:12.
À Ń LÁYỌ̀ NÍTORÍ INÚ-RERE-ONÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ
Àwọn Júù tó ń padà bọ̀ láti ìgbèkùn Bábílónì kọrin pé: “Kí àwọn ènìyàn máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn.” (Sáàmù 107:8, 15, 21, 31) Dáfídì fi orin yin Ọlọ́run pé: “Òótọ́ rẹ [jẹ́] títí dé sánmà.” (Sáàmù 108:4) Nínú orin atunilára tó tẹ̀ lé èyí, Dáfídì gbàdúrà pé: “Ràn mí lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run mi; gbà mí là ní ìbámu pẹ̀lú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.” (Sáàmù 109:18, 19, 26) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣàkóso Mèsáyà ni Sáàmù Àádọ́fà dá lé lórí. Sáàmù 111:10 sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n.” Gẹ́gẹ́ bí sáàmù tó tẹ̀ lé èyí sì ti wí, “aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà.”—Sáàmù 112:1.
Sáàmù Hálẹ́lì ni wọ́n ń pe Sáàmù 113 sí 118. Ìdí èyí ni pé àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò léraléra nínú rẹ̀ ni “Halelúyà,” tàbí “Ẹ Yin Jáà!” Ìwé Mishnah tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún kẹta, ìyẹn ìwé tí wọ́n kọ ìtàn ìjímìjí tó jẹ́ ìtàn àtẹnudẹ́nu sí sọ nípa àwọn orin yìí. Ó ní wọ́n máa ń kọ wọ́n lákòókò àjọ̀dún Ìrékọjá àti nígbà àjọyọ̀ mẹ́ta táwọn Júù máa ń ṣe lọ́dọọdún. Sáàmù 119 tó jẹ́ sáàmù tó gùn jù lọ tó sì tún jẹ́ orí tó gùn jù lọ nínú Bíbélì gbé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ṣí payá, lárugẹ.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
109:23—Kí ni Dáfídì ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Bí òjìji nígbà tí ó bá ń pa rẹ́ lọ, a sọ ọ́ di dandan fún mi láti lọ”? Ńṣe ni Dáfídì ń fi ewì sọ pé ara ń sọ fún òun pé àkókò tóun máa kú ti sún mọ́lé.—Sáàmù 102:11.
110:1, 2—Kí ni “Olúwa [Dáfídì],” ìyẹn Jésù Kristi ń ṣe ní àkókò tó fi jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run? Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó gòkè re ọ̀run ó sì ń dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run títí di ọdún 1914 tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Láàárín àkókò yẹn, Jésù ń ṣàkóso lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì-òróró lórí, ó ń tọ́ wọn sọ́nà nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n ń ṣe, bákan náà ló sì ń múra wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè bá a ṣàkóso nínú Ìjọba rẹ̀.—Mátíù 24:14; 28:18-20; Lúùkù 22:28-30.
110:4—Kí ni Jèhófà ‘búra láti ṣe tí kì yóò sì pèrò dà’? Májẹ̀mú tí Jèhófà bá Jésù Kristi dá láti jẹ́ Ọba àti Àlùfáà Àgbà ni ìbúra yìí.—Lúùkù 22:29.
113:3—Ọ̀nà wo ni orúkọ Jèhófà fi yẹ fún ìyìn “láti yíyọ oòrùn títí di ìgbà wíwọ̀ rẹ̀”? Èyí ju ọ̀ràn pé àwùjọ èèyàn kan ṣoṣo ló ń jọ́sìn Jèhófà lójoojúmọ́ o. Láti ìlà oòrùn tí oòrùn ti máa ń yọ títí dé ìwọ̀ oòrùn tó ti máa ń wọ̀ ni ìtànṣán rẹ̀ máa ń mọ́lẹ̀ kárí ayé. Lọ́nà kan náà, Jèhófà yẹ fún ìyìn ní gbogbo ayé. Èyí kò lè ṣeé ṣe tí gbogbo àwọn tó ń yìn ín kò bá ní ètò kan. Bá a ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àǹfààní ṣíṣeyebíye ló jẹ́ fún wa pé a lè máa yin Ọlọ́run àti pé á lè máa fi ìtara kéde Ìjọba rẹ̀.
116:15—Báwo ni ‘ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin Jèhófà ṣe ṣeyebíye tó lójú rẹ̀’? Àwọn olùjọ́sìn Jèhófà ṣeyebíye gan-an lójú rẹ̀ débi pé kò lè fàyè gba ikú gbogbo wọn lápapọ̀. Bí Jèhófà bá jẹ́ kí ìyẹn ṣẹlẹ̀, ńṣe ló máa dà bíi pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lágbára jù ú lọ. Yàtọ̀ síyẹn, kò ní sẹ́nì kankan lórí ilẹ̀ ayé tó máa jẹ́ ìpìlẹ̀ ayé tuntun.
119:71—Àǹfààní wo la lè rí nínú Ìpọ́njú? Ìṣòro lè kọ́ wa láti túbọ̀ máa gbára lé Jèhófà, láti máa gbàdúrà sí i tọkàntara, ká túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an, ká sì máa fi ohun tí Bíbélì sọ sílò. Ìyẹn nìkan kọ́, ohun tá a bá ṣe nígbà tá a wà nínú ìpọ́njú lè jẹ́ ká rí àwọn ibi tá a kù sí, ká sì ṣàtúnṣe. Tá a bá jẹ́ kí ìpọ́njú sọ wá dẹni rere sí i, a ò ní máa bínú tí ìpọ́njú bá dé bá wa.
119:96—Kí ni “òpin gbogbo ìjẹ́pípé” túmọ̀ sí? Ohun tí onísáàmù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ojú tí ẹ̀dá èèyàn fi ń wo ìjẹ́pípé. Ó lè jẹ́ pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé ó níbi tí òye èèyàn mọ nípa ìjẹ́pípé. Àmọ́, àwọn òfin Ọlọ́run kò ní irú ààlà bẹ́ẹ̀. Gbogbo ohun tí à ń ṣe nígbèésí ayé wa pátá ni ìtọ́sọ́nà inú rẹ̀ wúlò fún.
119:164—Kí ni ìtúmọ̀ yíyin Ọlọ́run ní “ìgbà méje lóòjọ́”? Méje sábà máa ń túmọ̀ sí pípé pérépéré. Nítorí náà, ohun tí onísáàmù náà ń sọ ni pé Jèhófà ni gbogbo ìyìn tọ́ sí.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
107:27-31. Nígbà tí Amágẹ́dọ́nì bá ṣẹlẹ̀, “ìdàrúdàpọ̀” ni ọgbọ́n ayé yìí yóò “já sí.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Kò lè gba ẹnikẹ́ni là lọ́wọ́ ìparun. Kìkì àwọn tó bá gbára lé Jèhófà fún ìgbàlà ni yóò là á já tí wọ́n á sì lè “fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.”
109:30, 31; 110:5. Apata tí jagunjagun máa ń gbé sọ́wọ́ òsì kì í sábà dáàbò bo ọwọ́ ọ̀tún tó fi ń ju idà. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Jèhófà wà “ní ọwọ́ ọ̀tún” àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti jà fún wọn. Ìyẹn ni pé ó ń dáàbò bò wọ́n ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́, èyí sì jẹ́ ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa “gbé Jèhófà lárugẹ gidigidi”!
113:4-9. Jèhófà ga débi pé, ó ní láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ “láti wo ọ̀run” pàápàá. Síbẹ̀, ó máa ń fi ìyọ́nú hàn sáwọn ẹni rírẹlẹ̀, àwọn tálákà, àtàwọn àgàn. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ó sì fẹ́ káwọn olùjọ́sìn rẹ̀ náà jẹ́ bẹ́ẹ̀.—Jákọ́bù 4:6.
114:3-7. Ó yẹ kí mímọ̀ tá a mọ̀ nípa àwọn ohun àrà tí Jèhófà ṣe nítorí àwọn èèyàn rẹ̀ ní Òkun Pupa, ní Odò Jọ́dánì, àti ní Òkè Sínáì máa mú wa ronú jinlẹ̀ gan-an. Ó yẹ kí àwọn ẹ̀dá èèyàn tá a pè ní “ilẹ̀ ayé” nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí bẹ̀rù Ọlọ́run, ìyẹn ni pé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kí wọ́n “jẹ ìrora mímúná” nítorí Olúwa.
119:97-101. Gbígba ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń kó wa yọ lọ́wọ́ ohun tó lè bá àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.
119:105. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ wa ní ti pé ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tí à ń bá yí lákòókò yìí. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó tún ń tan ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà wa nítorí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú.
A LÈ LÁYỌ̀ BÁ A TIẸ̀ WÀ NÍNÚ ÌṢÒRO
Báwo la ṣe lè kojú àwọn ìṣòro tó le gan-an, báwo la sì ṣe lè bọ́ nínú ìpọ́njú? Sáàmù 120 sí 134 fún wa ní ìdáhùn tó ṣe kedere sí ìbéèrè yìí. Títọ Jèhófà lọ fún ìrànlọ́wọ́ ló lè mú wa la àdánwò já, òun ló sì lè jẹ́ ká máa láyọ̀ nìṣó. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn sáàmù yìí, tí wọ́n ń pè ní Orin Ìgòkè, làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọ nígbà tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún.
Sáàmù 135 àti 136 fi Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹni tó máa ń ṣe ohunkóhun tó bá jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀, èyí sì mú kó yàtọ̀ pátápátá sáwọn òrìṣà tí kò lè dá nǹkan kan ṣe. Sáàmù 136 jẹ́ orin tó ní ègbè, ńṣe ni wọ́n máa ń fi apá tó kẹ́yìn ṣe ègbè apá tó ṣáájú nínú ẹsẹ kọ̀ọ̀kan. Sáàmù tó tẹ̀ lé èyí sọ nípa ipò ìbànújẹ́ táwọn Júù tó wà nílẹ̀ Bábílónì wà, nítorí pé ó wù wọ́n gan-an láti lọ jọ́sìn Jèhófà ní Síónì. Dáfídì ló kọ Sáàmù 138 sí 145. Ó fẹ́ lati ‘fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbé Jèhófà lárugẹ.’ Kí nìdí? Ó sọ pé: “Nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.” (Sáàmù 138:1; 139:14) Nínú sáàmù márùn-ún tó tẹ̀ lé èyí, Dáfídì gbàdúrà pé kí Jèhófà dáàbò bo òun lọ́wọ́ àwọn èèyàn búburú, kóun rí ìbáwí tó bá òdodo mu, kóun rí ìdándè kúrò lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣenúnibíni sóun, kóun sì rí ìtọ́sọ́nà nípa bó ṣe yẹ kóun máa hùwà. Ó tún sọ nípa ayọ̀ táwọn èèyàn Jèhófà ní. (Sáàmù 144:15) Lẹ́yìn tí Dáfídì ti sọ nípa bí Jèhófà ṣe ga tó àti jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni rere, ó wá sọ pé: “Ẹnu mi yóò máa sọ̀rọ̀ ìyìn Jèhófà; kí gbogbo ẹran ara sì máa fi ìbùkún fún orúkọ mímọ́ rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Sáàmù 145:21.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
122:3—Báwo ni Jerúsálẹmù ṣe jẹ́ ìlú “tí a so pọ̀ nínú ìṣọ̀kanṣoṣo”? Bó ṣe sábà máa ń rí nínú àwọn ìlú ayé ọjọ́un, ńṣe ni wọ́n kọ́ àwọn ilé tó wà nílùú Jerúsálẹ́mù sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí. Kíkọ́ tí wọ́n kọ́ wọn sún mọ́ra yìí jẹ́ kó rọrùn láti dáàbò bo ìlú náà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn tó ń gbé àárín ìlú láti ran ara wọn lọ́wọ́ àti láti dáàbò bo ara wọn. Èyí dúró fún ìṣọ̀kan tẹ̀mí tó wà láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá nígbà tí wọ́n bá pàdé pọ̀ láti jọ́sìn.
123:2—Ẹ̀kọ́ wo ni àkàwé ojú àwọn ìránṣẹ́ fi kọ́ wa? Ìdí méjì làwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin fi máa ń wo ọwọ́ ọ̀gá wọn. Èkíní, láti mọ ohun tí ọ̀gá wọn fẹ́ àti èkejì, kí wọ́n lè rí ààbò àtohun tí wọ́n nílò. Bẹ́ẹ̀ làwa náà ṣe ń wo ojú Jèhófà láti mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ àti láti rí ojú rere rẹ̀.
131:1-3—Ọ̀nà wo ni Dáfídì gbà ‘tu ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀sẹ̀ tó sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́ bí ọmọ tí a já lẹ́nu ọmú tí ń bẹ lọ́wọ́ ìyá rẹ̀’? Dáfídì kẹ́kọ̀ọ́ láti rí ìtùnú àti ìbàlẹ̀ ọkàn bíi ti “ọmọ tí a já lẹ́nu ọmú, tí ń bẹ lọ́wọ́ ìyá rẹ̀.” Lọ́nà wo? Ní ti pé kì í ṣe ẹni tó ní ìrera ọkàn àtẹni tójú rẹ̀ ga fíofío, kò sì lé ohun tó ju agbára rẹ̀ lọ. Dípò kí Dáfídì máa wá ipò ńlá, ó jẹ́ ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ tó sì máa ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn. Tá a bá ní irú ẹ̀mí tó ní yìí, èyí á fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni wá, pàápàá tá a bá ń fẹ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
120:1, 2, 6, 7. Ọ̀rọ̀ tó ń ba àwọn èèyàn jẹ́ tàbí tó ń pẹ̀gàn wọn lè kó ìbànújẹ́ ọkàn ńláǹlà bá wọn. Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a “dúró fún àlàáfíà” ni pé ká máa kó ahọ́n wa níjàánu.
120:3, 4. Bó bá di dandan ká máa fara da ẹnì kan tó ní “ahọ́n àgálámàṣà,” mímọ̀ pé Jèhófà yóò ṣàtúnṣe ohun gbogbo nígbà tí àkókò bá tó lójú rẹ̀ lè fún wa ní ìtùnú. “Alágbára ńlá” yóò pa àwọn abanijẹ́ run. Dájúdájú wọn yóò rí ìdájọ́ Jèhófà tó múná, èyí tí “ẹyín iná àwọn igi wíwẹ́” dúró fún.
127:1, 2. A gbọ́dọ̀ máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe.
133:1-3. Ìṣọ̀kan àárín àwọn èèyàn Jèhófà ń fini lọ́kàn balẹ̀, ó ń gbéni ró, ó sì ń mára tuni. A ò gbọ́dọ̀ ba ìṣọ̀kan yìí jẹ́ nípa ṣíṣe àríwísí àwọn arákùnrin wa, nípa dídá aáwọ̀ sílẹ̀, tàbí nípa ríráhùn.
137:1, 5, 6. Àwọn olùjọ́sìn Jèhófà tí wọ́n wà nígbèkùn fi Síónì tó dúró fún ètò Ọlọ́run lákòókò yẹn sọ́kàn gan-an. Àwa náà ńkọ́? Ṣé a rọ̀ mọ́ ètò tí Jèhófà ń lò lónìí láìjuwọ́ sílẹ̀?
138:2. Jèhófà ‘gbé àsọjáde rẹ̀ ga lọ́lá àní lékè gbogbo orúkọ rẹ̀’ ní ti pé, ìmúṣẹ gbogbo ohun tó ṣèlérí láti ṣe lórúkọ rẹ̀ yóò kọjá ohunkóhun tá a lè máa fọkàn rò. Ká sòótọ́, ohun tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú kàmàmà.
139:1-6, 15, 16. Gbogbo ohun tí à ń ṣe pátá ni Jèhófà mọ̀, títí kan èrò ọkàn wa àtàwọn ọ̀rọ̀ wa, àní ká tiẹ̀ tó sọ wọ́n rárá. Nígbà tá a ṣì jẹ́ ọlẹ̀ nínú ìkún ìyá wa, káwọn ẹ̀ya ara wa tó máa fara hàn, ó ti mọ̀ wá. Mímọ̀ tí Ọlọ́run mọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa jẹ́ ohun “àgbàyanu gidigidi” tó ṣòro láti lóye. Ẹ ò rí i pé ohun ìtùnú ló jẹ́ pé Jèhófà rí àwọn ìṣòro lílekoko tí à ń dojú kọ, ó sì tún mọ ipa táwọn ìṣòro náà ń ní lórí wa!
139:7-12. Kò sí ibikíbi tá a lè lọ tó jìnnà jù fún Jèhófà láti fún wa lókun.
139:17, 18. Ṣé ìmọ̀ Jèhófà ń gbádùn mọ́ wa? (Òwe 2:10) Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé a ti rí orísun ìdùnnú tí kò lópin nìyẹn. Àwọn èrò Jèhófà “pọ̀ ju àwọn egunrín iyanrìn pàápàá.” Kò sígbà kankan tá ò ní rí nǹkan kọ́ nípa rẹ̀.
139:23, 24. Ó yẹ ká fẹ́ kí Jèhófà yẹ àwọn èrò inú wa lọ́hùn-ún wò bóyá àwọn “ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára” wà nínú ọkàn wa, ìyẹn àwọn bí èrò tí kò tọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àti ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀, kó sì bá wa mú wọn kúrò.
143:4-7. Báwo la ṣe lè fara da ìpọ́njú, kódà èyí tó nira gan-an? Ìdáhùn tí onísáàmù fún wa ní pé: Ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, káwọn iṣẹ́ rẹ̀ máa jẹ wá lọ́kàn, ká sì máa gbàdúrà sí i pé kó ràn wá lọ́wọ́.
“Ẹ Yin Jáà!”
Ọ̀rọ̀ ìyìn sí Jèhófà ló kádìí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìsọ̀rí sáàmù mẹ́rin àkọ́kọ́. (Sáàmù 41:13; 72:19, 20; 89:52; 106:48) Ọ̀rọ̀ ìyìn ló sì kádìí ìsọ̀rí kárùn-ún tó kẹ́yìn yìí. Sáàmù 150:6 sọ pé: “Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà. Ẹ yin Jáà!” Dájádájú, èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ nínú ayé tuntun Ọlọ́run.
Bá a ti ń retí àkókò aláyọ̀ yẹn, ọ̀pọ̀ ìdí ló fi yẹ ká máa fògo fún Ọlọ́run tòótọ́ ká sì máa yin orúkọ rẹ̀. Nígbà tá a bá ronú nípa ayọ̀ tá a ní nítorí pé a mọ Jèhófà àti pé a ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀, ǹjẹ́ èyí kò sún wa láti yìn ín pẹ̀lú ọkàn ìmọrírì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ làwọn àgbàyanu iṣẹ́ Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn èrò Jèhófà “pọ̀ ju àwọn egunrín iyanrìn pàápàá”