Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Tànmọ́lẹ̀ Sí Òpópónà Rẹ
“Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ . . . ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.”—SÁÀMÙ 119:105.
1, 2. Kí la máa ṣe kí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó lè tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà wa?
Ọ̀RỌ̀ Jèhófà yóò máa tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà wa tá a bá ṣe ohun tó yẹ. Ìyẹn ni pé ká tó lè jàǹfààní ìmọ́lẹ̀ nípa tẹ̀mí yìí, a ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójú méjèèjì, ká sì máa fi ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò. Ìgbà yẹn lọ̀rọ̀ wa tó máa rí bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.”—Sáàmù 119:105.
2 Ẹ jẹ́ ká gbé Sáàmù 119:89-176 yẹ̀ wò wàyí. Ọ̀rọ̀ ki sínú orin tó pín sí ìsọ̀rí mọ́kànlá yìí! Ohun tó wà níbẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa bá ìrìn wa lọ lọ́nà ìyè ayérayé.—Mátíù 7:13, 14.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
3. Báwo ni Sáàmù 119:89, 90 ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeé gbára lé?
3 Tá a bá fẹ́ràn ọ̀rọ̀ Jèhófà, àá lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nípa tẹ̀mí. (Sáàmù 119:89-96) Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Fún àkókò tí ó lọ kánrin, Jèhófà, ọ̀rọ̀ rẹ dúró ní ọ̀run. . . . Ìwọ ti fi ilẹ̀ ayé sọlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, kí ó lè máa bá a nìṣó ní dídúró.” (Sáàmù 119:89, 90) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn “àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ọ̀run” tó fi lélẹ̀, ni oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ ń tẹ̀ lé tí wọ́n fi ń yí po lójú ọ̀run láìtàsé ipa ọ̀nà wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí náà ló sì jẹ́ kí ayé fìdí múlẹ̀ gbọn-in títí láé. (Jóòbù 38:31-33; Sáàmù 104:5) Gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá ti ẹnu Jèhófà jáde ló ṣeé gbára lé torí pé tí Ọlọ́run bá ti sọ pé báyìí lòun fẹ́ ṣe, ó di dandan kí ohun tó sọ “ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú.”—Aísáyà 55:8-11.
4. Ọ̀nà wo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ gbà ń jàǹfààní nítorí pé wọ́n fẹ́ràn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
4 Ńṣe ni onísáàmù náà ì bá ‘ṣègbé nínú ṣíṣẹ́ tí wọ́n ń ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́ bí kì í bá ṣe pé ó fẹ́ràn òfin Ọlọ́run.’ (Sáàmù 119:92) Ẹ sì wá wò ó o, àwọn àjèjì kọ́ ló ń ṣẹ́ onísáàmù yìí níṣẹ̀ẹ́ o; àwọn arúfin kan tó kórìíra rẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni. (Léfítíkù 19:17) Àmọ́ èyí ò kó ṣìbáṣìbo bá a, torí pé ó fẹ́ràn òfin Ọlọ́run tó ń gbéni ró. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà ní Kọ́ríńtì, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe wà nínú “ewu láàárín àwọn èké arákùnrin.” Ó ṣeé ṣe kí àwọn ‘àpọ́sítélì adárarégèé’ tó ń wá ẹ̀sùn tí wọ́n á kà sí i lọ́rùn wà lára àwọn tó ń yọ ọ́ lẹ́nu yìí. (2 Kọ́ríńtì 11:5, 12-14, 26) Síbẹ̀, wọn ò borí Pọ́ọ̀lù nípa tẹ̀mí nítorí ó fẹ́ràn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí pé àwa náà fẹ́ràn Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Jèhófà, a sì ń fi ohun tó wí sílò, ìfẹ́ wà láàárín àwa àtàwọn arákùnrin wa. (1 Jòhánù 3:15) Bó ti wù kí ayé kórìíra wa tó, kò yẹ ká tìtorí ìyẹn gbàgbé èyíkéyìí nínú ìtọ́ni Ọlọ́run. Ńṣe ló yẹ ká máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìṣó nípa jíjẹ́ kí ẹ̀mí ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan jọba láàárín àwa àtàwọn ará wa bá a ṣe ń wọ̀nà fún ìgbà tá a ó lè máa fi ayọ̀ sin Jèhófà títí ayérayé.—Sáàmù 119:93.
5. Kí ni Ásà Ọba ṣe tó fi hàn pé ó wá Jèhófà?
5 A lè gbàdúrà sí Jèhófà bíi ti Onísáàmù náà láti fi hàn pé òun la rọ̀ mọ́, ká sọ báyìí pé: “Tìrẹ ni èmi. Gbà mí là, nítorí pé mo ti wá àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ.” (Sáàmù 119:94) Ásà Ọba wá Ọlọ́run, ìyẹn ló mú kó fòpin sí ìpẹ̀yìndà ní Júdà. Nígbà tó di ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìjọba Ásà, (ọdún 963 ṣáájú Sànmánì Tiwa), gbogbo olùgbé Júdà ṣe àpéjọ ńlá kan, ibẹ̀ ni wọ́n ti “wọnú májẹ̀mú láti fi gbogbo ọkàn-àyà wọn àti gbogbo ọkàn wọn wá Jèhófà.” Ọlọ́run sì “jẹ́ kí wọ́n rí òun,” ó sì “ń bá a lọ láti fún wọn ní ìsinmi yí ká.” (2 Kíróníkà 15:10-15) Ó yẹ kí ẹnikẹ́ni tó bá ti sú lọ kúrò nínú ìjọ Kristẹni fi ti Ásà Ọba yìí ṣe àwòkọ́ṣe, kí onítọ̀hún tún bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan sí i. Jèhófà yóò bù kún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn èèyàn Ọlọ́run pé jọ, yóò sì dáàbò bò wọ́n.
6. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tí ò ní jẹ́ ká kó sínú ewu nípa tẹ̀mí?
6 Ọ̀rọ̀ Jèhófà máa ń kọ́ wa lọ́gbọ́n tí ò ní jẹ́ ká kó sínú ewu nípa tẹ̀mí. (Sáàmù 119:97-104) Àṣẹ Ọlọ́run máa ń mú wa gbọ́n ju àwọn ọ̀tá wa lọ. Bí a bá ń kọbi ara sí àwọn ìránnilétí rẹ̀, a óò ní ìjìnlẹ̀ òye, tí a bá sì ń ‘pa àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ̀ mọ́, a óò máa fi òye tó ju tàwọn àgbà lọ hùwà.’ (Sáàmù 119:98-100) Tá a bá jẹ́ kí àwọn àsọjáde Jèhófà máa ‘dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in mọ́ òkè ẹnu wa ju oyin lọ,’ a ó lè kórìíra “gbogbo ipa ọ̀nà èké.” (Sáàmù 119:103, 104) A ò sì ní kó sínú ewu nípa tẹ̀mí bá a ṣe ń gbé láàárín àwọn onírera àti òǹrorò ẹ̀dá tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.—2 Tímótì 3:1-5.
Fìtílà fún Ẹsẹ̀ Wa
7, 8. Kí ọ̀rọ̀ wa tó lè rí gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 119:105 ṣe wí, kí la ní láti ṣe?
7 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ orísun ìmọ́lẹ̀ nípa tẹ̀mí tí kì í ṣẹ́jú pẹ́ú. (Sáàmù 119:105-112) Yálà Kristẹni ẹni àmì òróró ni wá tàbí ara “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ohun kan náà tá a jọ ń sọ ni pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” (Jòhánù 10:16; Sáàmù 119:105) Ńṣe ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí ìmọ́lẹ̀ tó ń mọ́lẹ̀ sí ọ̀nà wa ká má bàa kọsẹ̀ ká sì ṣubú nípa tẹ̀mí. (Òwe 6:23) Síbẹ̀, àwa fúnra wa ni yóò mú kí ọ̀rọ̀ Jèhófà yìí jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ wa.
8 Ó yẹ ká dúró ṣinṣin bíi tẹni tó kọ orin inú Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà [119]. Ó ti pinnu pé òun ò ní yà kúrò nínú àwọn àṣẹ Ọlọ́run. Ó ní: “Mo ti sọ gbólóhùn ìbúra, èmi yóò sì mú un ṣẹ dájúdájú, láti máa pa àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ [ìyẹn ti Jèhófà] tí ó jẹ́ òdodo mọ́.” (Sáàmù 119:106) Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé àwa náà ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn kíkọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì àti lílọ sípàdé ìjọ déédéé.
9, 10. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn ẹni tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà lè ‘rìn gbéregbère kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ̀,’ ṣùgbọ́n kí la lè ṣe kí èyí má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa?
9 Onísáàmù náà kò ‘rìn gbéregbère kúrò nínú àwọn àṣẹ Ọlọ́run,’ ṣùgbọ́n ẹnì kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà lè rìn kúrò nínú àwọn àṣẹ Ọlọ́run. (Sáàmù 119:110) Ṣebí Sólómọ́nì Ọba tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà, tó ń lo ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún un nígbà kan rí, rìn gbéregbère kúrò nínú àwọn àṣẹ Ọlọ́run. ‘Àní àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè mú un dẹ́ṣẹ̀’ nítorí pé wọ́n mú un dẹni tó lọ ń bọ̀rìṣà.—Nehemáyà 13:26; 1 Àwọn Ọba 11:1-6.
10 Sátánì “pẹyẹpẹyẹ” ti kẹ́ pańpẹ́ tó pọ̀ rẹpẹtẹ sílẹ̀. (Sáàmù 91:3) Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nígbà kan rí lè máa gbìyànjú láti mú wa rìn gbéregbère kúrò ní ọ̀nà ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ká lè di apẹ̀yìndà tí ń bẹ nínú òkùnkùn. Ní ìlú Tíátírà ayé ìgbàanì, “obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì” wà láàárín àwọn Kristẹni, ó sì ṣeé ṣe kí Jésíbẹ́lì yìí jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn obìnrin kan tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn mìíràn pé kí wọ́n máa bọ̀rìṣà, kí wọ́n sì máa ṣàgbèrè. Àmọ́ Jésù ò gba irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ láyè, àwa náà ò sì gbọ́dọ̀ gbà á láyè. (Ìṣípayá 2:18-22; Júúdà 3, 4) Nítorí náà, ńṣe ni ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà má ṣe jẹ́ ká rìn gbéregbère kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n kó fẹsẹ̀ wa múlẹ̀ gbọn-in nínú ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Sáàmù 119:111, 112.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Gbé Wa Ró
11. Kí ni Ọlọ́run ka àwọn ẹni burúkú sí gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 119:119 ṣe fi hàn?
11 Ọlọ́run yóò gbé wa ró bí a kò bá ti ṣáko lọ kúrò nínú àwọn ìlànà rẹ̀. (Sáàmù 119:113-120) A kórìíra “àwọn aláàbọ̀-ọkàn” bí Jésù pàápàá ṣe lòdì sí àwọn tó pera wọn ní Kristẹni lóde òní, àmọ́ tí wọn ò gbóná tí wọn ò sì tutù. (Sáàmù 119:113; Ìṣípayá 3:16) Nígbà tá a ti ń fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà, “ibi ìlùmọ́” ló jẹ́ fún wa, yóò sì gbé wa ró. Ṣùgbọ́n ‘fífọ́n ni yóò fọ́n gbogbo àwọn tó bá ṣáko lọ kúrò nínú àwọn ìlànà rẹ̀ dà nù’ nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ̀tàn tó ń hùwà àgálámàṣà àti èké. (Sáàmù 119:114, 117, 118; Òwe 3:32) “Ìdàrọ́” ló ka irú àwọn ẹni burúkú bẹ́ẹ̀ sí, ìyẹn ìdọ̀tí tá a máa ń finá yọ́ kúrò lára ohun iyebíye bíi fàdákà àti wúrà. (Sáàmù 119:119; Òwe 17:3) Ẹ jẹ́ ká fẹ́ràn àwọn ìránnilétí Ọlọ́run dáadáa ká má bàa pa run pọ̀ mọ́ àwọn ẹni burúkú tí Ọlọ́run kà sí ìdàrọ́ tá à ń dà sí ààtàn!
12. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ní ìbẹ̀rù Jèhófà?
12 Onísáàmù náà sọ pé: “Nítorí ìbẹ̀rùbojo fún ọ [Jèhófà], ara mi ti sẹ́gìíìrì.” (Sáàmù 119:120) Kí Jèhófà tó lè kà wá sí ìránṣẹ́ rẹ̀ tó máa gbé ró, a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù rẹ̀ látọkànwá, ká máa sá fún gbogbo ohun tí kò fẹ́. Ìbẹ̀rù Jèhófà tí Jóòbù ní lọ́kàn ló mú kó lè jẹ́ olódodo jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Jóòbù 1:1; 23:15) Ìbẹ̀rù Ọlọ́run yìí ò ní jẹ́ ká yà kúrò nínú ṣíṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, bó ti wù kí ìṣòro wa pọ̀ tó. Ṣùgbọ́n ká tó lè ní ẹ̀mí ìfaradà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń gbàdúrà lemọ́lemọ́ ká sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ń gbọ́.—Jákọ́bù 5:15.
Máa Gbàdúrà Kó O sì Gbà Gbọ́ Pé Ọlọ́run Ń Gbọ́
13-15. (a) Kí ló mú ká gbà gbọ́ pé Ọlọ́run yóò gbọ́ àdúrà wa? (b) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bá ò bá mọ bó ṣe yẹ ká gba àdúrà wa? (d) Ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ Sáàmù 119:121-128 ṣe lè bá ‘àwọn ìkérora wa tí a kó sọ jáde’ mu tá a bá fẹ́ gbàdúrà.
13 Bí a bá ń gbàdúrà, ó yẹ ká gbà gbọ́ pé Ọlọ́run yóò gbọ́ àdúrà wa. (Sáàmù 119:121-128) Kí ló máa jẹ́ kó dá wa lójú bíi ti onísáàmù náà pé Ọlọ́run yóò gbọ́ àdúrà wa? Ohun náà ni pé a nífẹ̀ẹ́ àṣẹ Ọlọ́run “ju wúrà, àní wúrà tí a yọ́ mọ́” lọ. Àti pé a ‘ka gbogbo àṣẹ ìtọ́ni Ọlọ́run nípa ohun gbogbo sí èyí tí ó tọ̀nà.’—Sáàmù 119:127, 128.
14 Jèhófà máa ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa nítorí ìgbàgbọ́ tá a ní pé yóò gbọ́ àdúrà wa, àti nítorí pé à ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. (Sáàmù 65:2) Bí ìṣòro bá kà wá láyà débi pé a ò tiẹ̀ wá mọ bó ṣe yẹ ká gbàdúrà ńkọ́? Ìgbà yẹn ni “ẹ̀mí tìkára rẹ̀ [yóò] jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú àwọn ìkérora tí a kò sọ jáde.” (Róòmù 8:26, 27) Nírú àkókò wọ̀nyẹn, tá a bá lo àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì nínú àdúrà wa, Ọlọ́run á gbà pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àdúrà tó bá ohun tá à ń fẹ́ mu.
15 Onírúurú àdúrà àti àníyàn ọkàn ọmọ ènìyàn tó bá ‘àwọn ìkérora wa tí a kò sọ jáde’ mu pọ̀ gan-an nínú Ìwé Mímọ́. Ẹ̀yin ẹ wo àpẹẹrẹ kan nínú Sáàmù 119:121-128 ná. Ọ̀nà tí onísáàmù yìí gbà sọ̀rọ̀ níbẹ̀ lè bá ipò tiwa náà mu. Bí àpẹẹrẹ, ká ní à ń bẹ̀rù pé àwọn èèyàn lè lù wá ní jìbìtì, a lè ké pe Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí onísáàmù yẹn ṣe ké pè é níbẹ̀. (Ẹsẹ 121 sí 123) Ká wá sọ pé ìpinnu pàtàkì kan la fẹ́ ṣe ńkọ́? Nígbà náà, a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè rántí àwọn ìránnilétí rẹ̀ ká sì fi wọ́n sílò. (Ẹsẹ 124 àti 125) Lóòótọ́ a lè jẹ́ ẹni tó ‘kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà èké,’ síbẹ̀ ó ṣì yẹ ká máa bẹ Ọlọ́run pé kó jọ̀wọ́ má ṣe jẹ́ ká rí ohun tí yóò mú wa rú òfin rẹ̀. (Ẹsẹ 126 sí 128) Bí a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́, bí irú àwọn wọ̀nyí, lè sọ sí wa lọ́kàn nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà.
Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́
16, 17. (a) Kí nìdí tá a fi nílò àwọn ìránnilétí Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe yẹ kí wọ́n máa rí lára wa? (b) Irú ojú wo làwọn ẹlòmíràn lè máa fi wò wá, àmọ́ kí ló jẹ àwa lógún?
16 Kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa kó sì tún fi ojú rere wò wá, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kọbi ara sí àwọn ìránnilétí rẹ̀. (Sáàmù 119:129-136) A sábà máa ń gbàgbé nǹkan, ìdí nìyẹn tá a fi nílò àwọn àgbàyanu ìránnilétí Jèhófà tó máa ń jẹ́ ká rántí ìtọ́ni rẹ̀ àtàwọn àṣẹ rẹ̀. Kò sí àní-àní pé inú wa máa ń dùn sí ìmọ́lẹ̀ nípa tẹ̀mí tó tàn sí wa tó bá ṣẹlẹ̀ pé a mọ ohun tuntun kan nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 119:129, 130) A sì dúpẹ́ pé Jèhófà ‘mú kí ojú rẹ̀ tàn sára wa’ ní ti pé a rí ojú rere rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘ìṣàn omi ń ṣàn sílẹ̀ ní ojú wa’ torí pé àwọn ẹlòmíràn ń rú òfin rẹ̀.—Sáàmù 119:135, 136; Númérì 6:25.
17 Ó dájú pé bá a bá ń ṣe ohun tí ìránnilétí òdodo Ọlọ́run wí, a óò máa rí ojú rere rẹ̀ nìṣó. (Sáàmù 119:137-144) Nítorí pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, a mọ̀ dájú pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ àwọn ìránnilétí rẹ̀ fún wa kó sì pàṣẹ pé ká máa pa á mọ́. (Sáàmù 119:138) Onísáàmù yìí máa ń pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́, àmọ́ kí ló mú kó tún sọ pé: “Aláìjámọ́ pàtàkì àti aláìníláárí ni mí”? (Sáàmù 119:141) Ó jọ pé irú ojú táwọn ọ̀tá rẹ̀ fi ń wò ó nìyẹn, lòun náà fi wá kúkú sọ bẹ́ẹ̀. Tá ò bá yẹ̀ lórí òdodo tá a dúró lé, àwọn èèyàn lè máa kẹ́gàn wa. Ṣùgbọ́n, ohun tó jẹ àwa lógún ni pé ká rí ojú rere Jèhófà nítorí pé a tẹ̀ lé àwọn ìránnilétí òdodo rẹ̀.
Ààbò àti Àlàáfíà Ń Bẹ fún Wa
18, 19. Àǹfààní wo la máa ń rí nínú pípa tá à ń pa àwọn ìránnilétí Ọlọ́run mọ́?
18 Bí a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìránnilétí Ọlọ́run, a ó dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run. (Sáàmù 119:145-152) Nítorí pé à ń pa àwọn ìránnilétí Jèhófà mọ́, ó máa ń yá wa lára láti fi gbogbo ọkàn wa ké pè é, ó sì dá wa lójú pé á gbọ́ tiwa. Ó ṣeé ṣe ká “tètè dìde ní wíríwírí òwúrọ̀” láti kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Àsìkò yẹn sì dára láti kúnlẹ̀ àdúrà lóòótọ́! (Sáàmù 119:145-147) A mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ń bẹ nítòsí wa torí pé a yàgò fún ìwà àìníjàánu, a sì tún gbà pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ bí Jésù alára ṣe gbà. (Sáàmù 119:150, 151; Jòhánù 17:17) Àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà máa ń gbé wa ró nínú ayé oníhílàhílo yìí, yóò sì mú wa la Amágẹ́dọ́nì, ogun ńlá tó ń bọ̀ já.—Ìṣípayá 7:9, 14; 16:13-16.
19 Inú ààbò gidi la wà nítorí pé a fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 119:153-160) A ò dà bí àwọn ẹni burúkú ní tiwa, torí ‘a kò yapa kúrò nínú àwọn ìránnilétí Jèhófà.’ A nífẹ̀ẹ́ àwọn àṣẹ ìtọ́ni Ọlọ́run, ìyẹn sì jẹ́ kó máa fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ dáàbò bò wá. (Sáàmù 119:157-159) Àwọn ìránnilétí Jèhófà ń mú ọpọlọ wa jí pépé ká lè rántí àwọn ohun tó fẹ́ ká ṣe nínú ipò tá a bá bá ara wa. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn àṣẹ ìtọ́ni Ọlọ́run, ìtọ́sọ́nà ni wọ́n jẹ́, àwa gan-an ò sì janpata pé Ẹlẹ́dàá wa láṣẹ lórí wa láti máa darí wa. Nígbà tá a ti mọ̀ pé ‘òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ àti pé a ò lè fúnra wa máa darí ìṣísẹ̀ wa, tinútinú la fi ń gbà kí Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà.—Sáàmù 119:160; Jeremáyà 10:23.
20. Kí ló jẹ́ ká ní “ọ̀pọ̀-yanturu àlàáfíà”?
20 Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà là ń ní nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà. (Sáàmù 119:161-168) Inúnibíni kò lè dí “àlàáfíà Ọlọ́run” tí ò láfiwé tá a ní lọ́wọ́. (Fílípì 4:6, 7) A mọyì àwọn ìpinnu ìdájọ́ Jèhófà gan-an débi pé ńṣe là ń yìn ín léraléra, bíi pé ní “ìgbà méje lóòjọ́.” (Sáàmù 119:161-164) Onísáàmù náà kọrin pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ, kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.” (Sáàmù 119:165) Bí àwa fúnra wa bá nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà tá a sì ń pa á mọ́, a ò ní jẹ́ kí ohun tẹ́nì kan ṣe tàbí ohunkóhun mìíràn mú wa kọsẹ̀ nípa tẹ̀mí.
21. Àwọn àpẹẹrẹ wo látinú Ìwé Mímọ́ ló fi hàn pé kò yẹ kí ìṣòro kankan tó bá yọjú nínú ìjọ mú wa kọsẹ̀?
21 Nínú Bíbélì, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ni ò jẹ́ kí nǹkan kan di ohun ìkọ̀sẹ̀ tí wọn ò lè borí. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó jẹ́ Kristẹni tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gáyọ́sì kò jẹ́ kí ìwà burúkú tí Dìótíréfè hù mú òun kọsẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló “ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 1-3, 9, 10) Pọ́ọ̀lù gba àwọn obìnrin méjì kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Yúódíà òun Síńtíkè, tí àwọn méjèèjì jọ jẹ́ Kristẹni, níyànjú pé kí wọ́n “ní èrò inú kan náà nínú Olúwa,” bóyá nítorí èdèkòyédè tó wà láàárín wọn. Ó sì jọ pé wọ́n rí ọ̀ràn àárín wọn yanjú, tí wọ́n sì ń bá a lọ láti máa sin Jèhófà. (Fílípì 4:2, 3) Nítorí náà kò yẹ ká jẹ́ kí ìṣòro yòówù tí ì báà yọjú nínú ìjọ mú wa kọsẹ̀ rárá. Ńṣe ló yẹ ká gbájú mọ́ bá a ṣe máa pa àwọn àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà mọ́, ká máa rántí pé ‘gbogbo ọ̀nà wa ń bẹ ní iwájú rẹ̀.’ (Sáàmù 119:168; Òwe 15:3) Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní sí ohunkóhun tó máa lè ba “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà” tá a ní jẹ́ títí ayé.
22. (a) Àǹfààní wo la lè ní bí a bá ń pa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́? (b) Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tí ò wá sípàdé ìjọ mọ́?
22 Bí a bá ń pa ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́ nígbà gbogbo, a ó lè máa yìn ín títí lọ. (Sáàmù 119:169-176) Bí a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run ní ìgbésí ayé wa, a óò láàbò nípa tẹ̀mí, ‘ètè wa á sì máa tú ìyìn Jèhófà jáde.’ (Sáàmù 119:169-171, 174) Ìyẹn sì làǹfààní tó ga jù lọ tọ́mọ èèyàn lè ní ní ìkẹyìn ọjọ́ tá a wà yìí. Onísáàmù náà fẹ́ wà láàyè kó lè máa yin Jèhófà nìṣó, àmọ́ ó ṣẹlẹ̀ bá kan ṣá pé ó “rìn gbéregbère bí àgùntàn tí ó sọnù.” (Sáàmù 119:175, 176) Lónìí, àwọn kan tó ti rìn lọ, tí wọn ò wá sípàdé ìjọ mọ́ ṣì lè fẹ́ràn Ọlọ́run, kí wọ́n ṣì fẹ́ láti máa yìn ín. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè padà wá sínú ààbò tẹ̀mí kí wọ́n lè máa rí ayọ̀ tó wà nínú yíyin Jèhófà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.—Hébérù 13:15; 1 Pétérù 5:6, 7.
Ìmọ́lẹ̀ Tí Ò Lópin Yóò Máa Mọ́lẹ̀ sí Ọ̀nà Wa
23, 24. Ọ̀nà wo ni Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà ti gbà ṣe ọ́ làǹfààní?
23 Onírúurú ọ̀nà ni Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà lè gbà ṣe wá láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú ká túbọ̀ gbára lé Ọlọ́run, nítorí ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà téèyàn bá “ń rìn nínú òfin Jèhófà” lèèyàn lè ní ojúlówó ayọ̀. (Sáàmù 119:1) Onísáàmù náà rán wa létí pé “òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀” Ọlọ́run. (Sáàmù 119:160) Láìsí àní-àní, ó yẹ kí èyí mú ká túbọ̀ mọrírì gbogbo ohun tí ń bẹ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tá a bá ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ inú Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà, a ó lè fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ jinlẹ̀jinlẹ̀. Lemọ́lemọ́ ni onísáàmù náà ń bẹ Ọlọ́run pé: “Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.” (Sáàmù 119:12, 68, 135) Ó tún bẹ̀ ẹ́ pé: “Kọ́ mi ní ìwà rere, ìlóyenínú àti ìmọ̀ pàápàá, nítorí pé mo ti lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn àṣẹ rẹ.” (Sáàmù 119:66) Á dára kí àwa náà gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀.
24 Ńṣe ni ẹ̀kọ́ Jèhófà máa mú kí àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín àwa àti Jèhófà. Léraléra ni onísáàmù náà ń sọ ọ́ pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run lòun. Kódà, ó fi tinútinú sọ fún Jèhófà pé: “Tìrẹ ni èmi.” (Sáàmù 119:17, 65, 94, 122, 125; Róòmù 14:8) Àǹfààní gidi ló jẹ́ pé a wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń yin Ọlọ́run lógo. (Sáàmù 119:7) Ṣé akéde Ìjọba Ọlọ́run ni ọ́, ṣé o sì ń fi ayọ̀ sin Ọlọ́run? Bó o bá jẹ́ akéde Ìjọba Ọlọ́run tó ń fi ayọ̀ sin Ọlọ́run, mọ̀ dájú pé Jèhófà yóò máa tì ọ́ lẹ́yìn nìṣó, yóò sì máa bù kún ọ bó o ṣe ń bá iṣẹ́ àtàtà yìí nìṣó tó o bá ń gbára lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo tó o sì ń jẹ́ kó tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà rẹ.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ràn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
• Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń gbé wa ró?
• Ọ̀nà wo ni àwọn ìránnilétí Jèhófà gbà ń ràn wá lọ́wọ́?
• Kí ló ń mú kí àwọn èèyàn Jèhófà ní ààbò àti àlàáfíà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ orísun ìmọ́lẹ̀ nípa tẹ̀mí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Bí a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí Jèhófà, kò ní kà wá sí “ìdàrọ́”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Tí a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ lè sọ sí wa lọ́kàn nígbà tá a bá ń gbàdúrà