Gbé Èrò Inú Rẹ Ka Ẹ̀mí, Kí o Sì Yè!
“Gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè.”—RÓÒMÙ 8:6.
1, 2. Ìyàtọ̀ wo ni Bíbélì fi hàn pé ó wà láàárín “ẹran ara” àti “ẹ̀mí”?
KÌ Í ṣe ohun tó rọrùn rárá láti wà ní mímọ́ níwà lójú Ọlọ́run nígbà téèyàn ń gbé láàárín àwọn oníwà ìbàjẹ́ tí ń gbé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara lárugẹ. Àmọ́ o, Ìwé Mímọ́ fi ìyàtọ̀ sáàárín “ẹran ara” àti “ẹ̀mí.” Ó pa ààlà tó fi hàn gbangba pé aburú gbáà ló máa ń yọrí sí téèyàn bá jẹ́ kí ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ jẹ gàba lé òun lórí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ ìbùkún ló máa ń yọrí sí téèyàn bá ń tẹ̀ lé ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.
2 Fún àpẹẹrẹ, Jésù Kristi sọ pé: “Ẹ̀mí ni ó ń fúnni ní ìyè; ẹran ara kò wúlò rárá. Àwọn àsọjáde tí mo ti sọ fún yín, ẹ̀mí ni wọ́n, ìyè sì ni wọ́n.” (Jòhánù 6:63) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tí ń bẹ ní Gálátíà pé: “Ẹran ara lòdì sí ẹ̀mí nínú ìfẹ́-ọkàn rẹ̀, ẹ̀mí sì lòdì sí ẹran ara; nítorí àwọn wọ̀nyí kọjú ìjà sí ara wọn.” (Gálátíà 5:17) Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: “Ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara rẹ̀ lọ́kàn yóò ká ìdíbàjẹ́ láti inú ẹran ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn yóò ká ìyè àìnípẹ̀kun láti inú ẹ̀mí.”—Gálátíà 6:8.
3. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti lè já ara wa gbà lọ́wọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti èròkérò?
3 Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà—ìyẹn ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀—lè paná “ìfẹ́-ọkàn ti ara” tó jẹ́ aláìmọ́ àti ìjẹgàba ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ wa tí ń ṣekú pani. (1 Pétérù 2:11) Kí a tó lè bọ́ ní oko ẹrú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, a gbọ́dọ̀ gba ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run, nítorí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú, ṣùgbọ́n gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.” (Róòmù 8:6) Kí ló túmọ̀ sí láti gbé èrò inú ka ẹ̀mí?
“Gbígbé Èrò Inú Ka Ẹ̀mí”
4. Kí ni “gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí” túmọ̀ sí?
4 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa “gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí,” ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó lò túmọ̀ sí “ọ̀nà ìrònú, ibi téèyàn fọkàn sí, . . . ìfojúsùn, góńgó, ìlépa.” Ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó tan mọ́ ọn túmọ̀ sí “láti ronú, láti fọkàn síbì kan pàtó.” Fún ìdí yìí, gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí jíjẹ́ kí ipá ìṣiṣẹ́ Jèhófà máa darí wa, kó máa ṣàkóso wa, kó sì máa sún wa ṣiṣẹ́. Ó túmọ̀ sí pé a ń fínnúfíndọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí ìrònú wa, ìṣesí wa, àti góńgó wa.
5. Báwo ló ṣe yẹ ká jọ̀wọ́ ara wa fún ìdarí ẹ̀mí mímọ́ tó?
5 Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ bó ṣe yẹ ká jọ̀wọ́ ara wa fún ìdarí ẹ̀mí mímọ́ tó, nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa jíjẹ́ ‘ẹrú nípasẹ̀ ẹ̀mí.’ (Róòmù 7:6) Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ táwọn Kristẹni ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, ẹ̀ṣẹ̀ ò jẹ gàba lórí wọn mọ́, wọ́n sì ti tipa bẹ́ẹ̀ “kú” nínú ipò wọn àtijọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 6:2, 11) Àwọn tó ti kú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ ṣì wà láàyè nípa tara, wọ́n sì ní òmìnira báyìí láti máa tẹ̀ lé Kristi gẹ́gẹ́ bí “ẹrú fún òdodo.”—Róòmù 6:18-20.
Ìyípadà Pípẹtẹrí
6. Ìyípadà wo ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ń di “ẹrú fún òdodo”?
6 Yíyí padà látorí jíjẹ́ “ẹrú ẹ̀ṣẹ̀” dórí sísin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “ẹrú fún òdodo” jẹ́ ìyípadà pípẹtẹrí lóòótọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn kan tí irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, pé: ‘A ti wẹ̀ yín mọ́, a ti sọ yín di mímọ́, a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.’—Róòmù 6:17, 18; 1 Kọ́ríńtì 6:11.
7. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti máa wo àwọn nǹkan bí Jèhófà ti ń wò wọ́n?
7 Táwa náà bá fẹ́ kí irú ìyípadà tó pabanbarì bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, Dáfídì onísáàmù náà fi taratara rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà . . . Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi.” (Sáàmù 25:4, 5) Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Dáfídì, Ó sì lè gbọ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà lóde òní pẹ̀lú. Níwọ̀n bí àwọn ọ̀nà Ọlọ́run àti òtítọ́ rẹ̀ ti jẹ́ mímọ́, ṣíṣe àṣàrò lórí wọn yóò ràn wá lọ́wọ́ bí ó bá ń ṣe wa bíi pé ká lọ́wọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara.
Ipa Pàtàkì Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Kó
8. Èé ṣe tó fi pọndandan pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
8 Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀mí rẹ̀. Fún ìdí yìí, ọ̀kan lára ọ̀nà pàtàkì táa fi lè jẹ́ kí ẹ̀mí yẹn máa ṣiṣẹ́ lára wa ni pé ká máa ka Bíbélì ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀—lójoojúmọ́ tó bá ṣeé ṣe. (1 Kọ́ríńtì 2:10, 11; Éfésù 5:18) Fífi àwọn òtítọ́ àti ìlànà Bíbélì kún èrò inú àti ọkàn-àyà wa yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìpèníjà tó lè wu ipò tẹ̀mí wa léwu. Nígbà tí ìdẹwò láti ṣèṣekúṣe bá yọjú, ẹ̀mí Ọlọ́run lè jẹ́ ká rántí àwọn ìránnilétí látinú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìlànà tí ń tọ́ni sọ́nà, èyí tó lè fún ìpinnu wa lókun láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Sáàmù 119:1, 2, 99; Jòhánù 14:26) Nítorí náà, a kò ní di ẹni táa ṣì lọ́nà.—2 Kọ́ríńtì 11:3.
9. Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe túbọ̀ ń fún wa lókun láti pa àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà mọ́?
9 Báa ti ń bá a nìṣó ní fífi tọkàntọkàn àti taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì, ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí èrò inú àti ọkàn-àyà wa, ó ń jẹ́ ká túbọ̀ máa fojú pàtàkì wo àwọn ìlànà Jèhófà. Àjọṣe tó wà láàárín àwa àti Ọlọ́run yóò wá di ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Táa bá dojú kọ ìdẹwò, a kò ní máa ronú nípa bí ìwà àìtọ́ ṣe lè gbádùn mọ́ni tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí yóò wà ní góńgó ẹ̀mí wa ni láti pa ìwà títọ́ mọ́ sí Jèhófà. Ìmọrírì jíjinlẹ̀ táa ní fún àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ ń fún wa ní ìṣírí láti gbógun ti ìwà èyíkéyìí tó lè ba àjọṣe ọ̀hún jẹ́.
“Mo Mà Nífẹ̀ẹ́ Òfin Rẹ O!”
10. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti máa ṣègbọràn sí òfin Jèhófà láti lè gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí?
10 Bí a óò bá gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí, ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan kò tó. Sólómọ́nì Ọba sáà mọ gbogbo ìlànà Jèhófà látòkè délẹ̀, ṣùgbọ́n kò pa wọ́n mọ́ ní ọjọ́ alẹ́ rẹ̀. (1 Àwọn Ọba 4:29, 30; 11:1-6) Bí nǹkan tẹ̀mí bá ń jẹ wá lọ́kàn, a ò ní fi ọ̀ràn wa mọ sórí wíwulẹ̀ mọ ohun tí Bíbélì wí, ṣùgbọ́n a óò rí ìjẹ́pàtàkì fífi tọkàntọkàn ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run. Èyí túmọ̀ sí fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Jèhófà, kí a sì máa ṣe gbogbo ohun táa bá lè ṣe láti pa wọ́n mọ́. Irú ẹ̀mí tí onísáàmù ní nìyẹn. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 119:97) Ọkàn wa yóò sún wa láti máa fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló ń jẹ wá lọ́kàn láti máa pa òfin Ọlọ́run mọ́. (Éfésù 5:1, 2) Dípò kí ìwà àìtọ́ máa dá wa lọ́rùn, ńṣe ni a óò máa fi èso tẹ̀mí hàn, ìfẹ́ láti wu Jèhófà yóò sì mú ká máa yàgò fún àwọn iṣẹ́ ibi, ìyẹn, “iṣẹ́ ti ara.”—Gálátíà 5:16, 19-23; Sáàmù 15:1, 2.
11. Àlàyé wo lo máa ṣe láti fi hàn pé òfin tí Jèhófà fi ka àgbèrè léèwọ̀ ń dáàbò bò wá?
11 Báwo la ṣe lè ní ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún òfin Jèhófà? Ọ̀nà kan táa lè gbà ṣe èyí ni nípa fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìníyelórí rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò òfin Ọlọ́run tó sọ pé àárín tọkọtaya nìkan ni kí ìbálòpọ̀ takọtabo mọ, tó sì ka àgbèrè àti panṣágà léèwọ̀. (Hébérù 13:4) Ǹjẹ́ ṣíṣègbọràn sí òfin yìí fi ohun rere kankan dù wá? Ǹjẹ́ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ lè ṣòfin tí yóò fi ohun tí yóò ṣe wá láǹfààní dù wá? Rárá o! Ṣebí àwa náà rí bí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tí kò tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere tí Jèhófà fi kọ́ni ṣe dà. Àwọn oyún àìròtẹ́lẹ̀ sábà máa ń fa oyún ṣíṣẹ́ tàbí kí ó fa ìgbéyàwó àìròtẹ́lẹ̀ tó kún fún ẹ̀dùn ọkàn. Ọ̀pọ̀ ló ń dá tọ́ ọmọ láìsí ìrànlọ́wọ́ ọkọ tàbí aya. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn tí ń ṣe àgbèrè lè kó àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré. (1 Kọ́ríńtì 6:18) Bí ìránṣẹ́ Jèhófà bá sì ṣe àgbèrè, àròdùn tó máa tìdí ẹ̀ yọ lè sọ ayé onítọ̀hún dìdàkudà. Gbígbìyànjú láti pa ẹ̀rí ọkàn tí ń dáni lẹ́bi lẹ́nu mọ́ lè fa àìróorunsùn lóru àti ìdààmú ọkàn. (Sáàmù 32:3, 4; 51:3) Ǹjẹ́ kò ṣe kedere, nígbà náà, pé òfin tí Jèhófà fi ka àgbèrè léèwọ̀ ń dáàbò bò wá? Ní tòótọ́, àǹfààní pọ̀ púpọ̀ nínú pípa ìwà rere mọ́!
Máa Gbàdúrà fún Ìrànlọ́wọ́ Jèhófà
12, 13. Èé ṣe tó fi bójú mu ká máa gbàdúrà nígbà tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá gbà wá lọ́kàn?
12 Dájúdájú, ó ń béèrè àdúrà àtọkànwá láti lè máa bá a lọ ní gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí. Ó bójú mu láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run, nítorí Jésù sọ pé: “Bí ẹ̀yin . . . bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:13) Nínú àdúrà, a lè mẹ́nu kàn án pé ẹ̀mí la gbára lé fún ìrànlọ́wọ́ láti borí àwọn àìlera wa. (Róòmù 8:26, 27) Bí a bá rí i pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ti fẹ́ máa nípa lórí wa, tàbí bí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa bá fi tìfẹ́tìfẹ́ pe àfiyèsí wa sí i, á bọ́gbọ́n mu ká mẹ́nu kan ìṣòro náà pàtó nínú àdúrà wa, ká sì béèrè fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti lè borí ìtẹ̀sí wọ̀nyí.
13 Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó jẹ́ òdodo, tó mọ́ níwà, tó níwà funfun, tó sì yẹ fún ìyìn. Ẹ sì wo bó ti bójú mu tó láti fi tọkàn tara rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i, kí “àlàáfíà Ọlọ́run” lè máa ṣọ́ ọkàn-àyà àti agbára èrò orí wa! (Fílípì 4:6-8) Fún ìdí yìí, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà báa ti ń “lépa òdodo, ìfọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù.” (1 Tímótì 6:11-14) Lágbára Baba wa ọ̀run, àníyàn àti ìdẹwò kò ní kọjá ohun tí apá wa yóò ká. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Ọlọ́run á jẹ́ kí ayé wa tòrò minimini.
Má Ṣe Kó Ẹ̀dùn Ọkàn Bá Ẹ̀mí
14. Èé ṣe tí ẹ̀mí Ọlọ́run fi ń gbin ìjẹ́mímọ́ síni lọ́kàn?
14 Àwọn tó dàgbà dénú lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò, pé: “Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí.” (1 Tẹsalóníkà 5:19) Níwọ̀n bí ẹ̀mí Ọlọ́run ti jẹ́ “ẹ̀mí ìjẹ́mímọ́,” ó mọ́ tónítóní, kò ní àbààwọ́n, kò sì ní èérí. (Róòmù 1:4) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí ẹ̀mí yẹn bá ń ṣiṣẹ́ lára wa, ó máa ń gbin ìjẹ́mímọ́ sí wa lọ́kàn. Ó máa ń jẹ́ ká máa tọ ọ̀nà ìgbésí ayé mímọ́ tó jẹ́ ti ìgbọràn sí Ọlọ́run. (1 Pétérù 1:2) Ìwà àìmọ́ èyíkéyìí jẹ́ ṣíṣàìka ẹ̀mí yẹn sí, èyí sì lè fa àjálù. Lọ́nà wo?
15, 16. (a) Báwo la ṣe lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run? (b) Báwo la ṣe lè yẹra fún kíkó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí Jèhófà?
15 Ó dára, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, èyí tí a fi fi èdìdì dì yín fún ọjọ́ ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà.” (Éfésù 4:30) Ìwé Mímọ́ sọ pé ẹ̀mí Jèhófà jẹ́ èdìdì tàbí “àmì ìdánilójú ohun tí ń bọ̀,” fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Ìyẹn, ìwàláàyè àìleèkú ní ọ̀run. (2 Kọ́ríńtì 1:22; 1 Kọ́ríńtì 15:50-57; Ìṣípayá 2:10) Ẹ̀mí Ọlọ́run lè darí àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé sí ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́, ó sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yàgò fún àwọn iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
16 Àpọ́sítélì náà kìlọ̀ nípa èké ṣíṣe, olè jíjà, ìwà tí ń tini lójú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí a bá jẹ́ kí ọkàn wa fà sírú nǹkan bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé a ń tàpá sí ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ẹ̀mí mí sí nìyẹn. (Éfésù 4:17-29; 5:1-5) Ó kéré tán títí dé àyè kan, èyí yóò túmọ̀ sí kíkó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run, ó sì dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Nínú ọ̀ràn yìí, bí ẹnikẹ́ni nínú wa bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ etí ikún sí ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ Jèhófà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ẹ̀mí kan dàgbà tàbí ká bẹ̀rẹ̀ sí hu àwọn ìwà kan tó lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, a sì lè pàdánù ojú rere Ọlọ́run pátápátá. (Hébérù 6:4-6) Bí a kò tiẹ̀ tíì jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀ nísinsìnyí, ó lè jẹ́ ibi tí ọ̀rọ̀ wa ń lọ nìyẹn. Nípa bíbá a nìṣó ní kíkọ̀ láti tọ ọ̀nà tí ẹ̀mí ní ká tọ̀, a ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a nìyẹn. Èyí pẹ̀lú yóò túmọ̀ sí ṣíṣoríkunkun àti kíkó ẹ̀dùn ọkàn bá Jèhófà, ẹni tí ẹ̀mí mímọ́ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a ò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ kí a má ṣe kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí a lè mú ọlá wá fún orúkọ mímọ́ rẹ̀ nípa gbígbé èrò inú wa ka ẹ̀mí.
Máa Bá A Nìṣó Láti Gbé Èrò Inú Ka Ẹ̀mí
17. Kí ni díẹ̀ lára àwọn góńgó tẹ̀mí táa lè gbé kalẹ̀, èé sì ti ṣe tí ṣíṣiṣẹ́ láti lé wọn bá fi mọ́gbọ́n dání?
17 Ọ̀nà kan pàtàkì táa fi lè máa bá a nìṣó láti gbé èrò inú ka ẹ̀mí ni láti gbé àwọn góńgó tẹ̀mí kalẹ̀, kí a sì sapá láti lé wọn bá. Lẹ́yìn táa bá gbé àìní àti ipò wa yẹ̀ wò, àwọn góńgó táa fẹ́ gbé kalẹ̀ lè jẹ́ títẹramọ́ ẹ̀kọ́ kíkọ́, ṣíṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù, tàbí nínàgà fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan pàtó, irú bí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún, iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì, tàbí iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Èyí yóò fi àwọn nǹkan tẹ̀mí kún èrò inú wa, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti dènà jíjọ̀wọ́ ara wa fún àìpé ẹ̀dá tàbí ká máa lé àwọn nǹkan tayé àtàwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó wọ́pọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan yìí kiri. Láìsí àní-àní, ipa ọ̀nà ọgbọ́n nìyí, nítorí Jésù rọ̀ wá pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè. Nítorí pé ibi tí ìṣúra rẹ bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú.”—Mátíù 6:19-21.
18. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì gan-an láti máa gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí ní ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí?
18 Ó dájú pé gbígbé èrò inú wa ka ẹ̀mí, kí a sì máa tẹ àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé rì ni ipa ọ̀nà ọgbọ́n ní “ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí. (2 Tímótì 3:1-5) A sáà mọ̀ pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:15-17) Fún àpẹẹrẹ, bí Kristẹni ọ̀dọ́ kan bá fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe góńgó rẹ̀, èyí lè máa tọ́ ọ sọ́nà láwọn ọdún ọ̀dọ́langba tàbí nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dàgbà di géńdé. Nígbà tí nǹkan kan bá fẹ́ mú kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ juwọ́ sílẹ̀, yóò tètè rántí ohun tó fẹ́ gbé ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Irú ẹni tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ yóò rí i pé kò mọ́gbọ́n dání, àní yóò kà á sí ìwà òmùgọ̀ pàápàá, láti fi àwọn góńgó tẹ̀mí tó ń lé sílẹ̀ torí àtilépa àwọn nǹkan tara tàbí ìgbádùn tí ẹ̀ṣẹ̀ lè mú wá. Rántí pé Mósè tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí “yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” (Hébérù 11:24, 25) Ní tèwe-tàgbà, a lè ṣe irú yíyàn bẹ́ẹ̀ táa bá ń gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí dípò ẹran ara ẹlẹ́ṣẹ̀.
19. Àwọn àǹfààní wo la óò gbádùn bí a bá ń gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí?
19 “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run,” ṣùgbọ́n “gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.” (Róòmù 8:6, 7) Bí a bá ń gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí, a óò ní àlàáfíà tí kò ṣeé fowó rà. Ọkàn-àyà àti làákàyè wa yóò sì túbọ̀ rí ààbò kúrò lọ́wọ́ agbára ipò ẹ̀ṣẹ̀ wa. Yóò túbọ̀ rọrùn fún wa láti dojú ìjà kọ ìdẹwò láti hùwà àìtọ́. Ọlọ́run yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìwọ̀yá ìjà tí ń lọ lọ́wọ́ láàárín ẹran ara àti ẹ̀mí.
20. Èé ṣe tó fi dá wa lójú pé ó ṣeé ṣe láti ja àjàṣẹ́gun nínú ìjà tó ń lọ láàárín ẹran ara àti ẹ̀mí?
20 Bí a bá ń bá a lọ láti gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí, àjọṣe pàtàkì tí ń bẹ láàárín àwa àti Jèhófà, orísun ìwàláàyè àti ẹ̀mí mímọ́, kò ní bà jẹ́. (Sáàmù 36:9; 51:11) Sátánì Èṣù àtàwọn elégbè lẹ́yìn rẹ̀ ń sa gbogbo ipá wọn láti rí i dájú pé wọ́n ba àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Wọ́n ń gbìyànjú láti ṣàkóso èrò inú wa, nítorí wọ́n mọ̀ pé táa bá juwọ́ sílẹ̀, èyí yóò yọrí sí ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run, yóò sì já sí ikú níkẹyìn. Àmọ́ a lè ja àjàṣẹ́gun nínú ìjà tó ń lọ láàárín ẹran ara àti ẹ̀mí yìí. Bó ṣe rí fún Pọ́ọ̀lù gẹ́lẹ́ nìyẹn, nítorí pé nígbà tó ń kọ̀wé nípa ìjà tirẹ̀, ó kọ́kọ́ béèrè pé: “Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?” Lẹ́yìn náà, láti fi hàn pé ìdáǹdè ṣeé ṣe, ó kígbe pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:21-25) Àwa náà lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi nítorí pé ó pèsè ọ̀nà táa lè gbà kojú àìpé ẹ̀dá, kí a sì máa gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí pẹ̀lú ìrètí àgbàyanu ti ìyè àìnípẹ̀kun.—Róòmù 6:23.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí?
• Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ẹ̀mí Jèhófà máa ṣiṣẹ́ lára wa?
• Nínú ìjà tí a ń bá ẹ̀ṣẹ̀ jà, ṣàlàyé ìdí tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣíṣègbọràn sí òfin Jèhófà, àti gbígbàdúrà sí i fi ṣe pàtàkì.
• Báwo ni gbígbé àwọn góńgó tẹ̀mí kalẹ̀ ṣe lè mú ká máa tọ ipa ọ̀nà ìyè nìṣó?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ohun tó ń gbógun ti ipò tẹ̀mí wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ó bójú mu láti gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà láti lè borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn góńgó tẹ̀mí lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí