KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Àwọn Ìwà Rere Tó Ń Mú Káyé Ẹni Dára
Christina kọ́kọ́ rò pé àlá lòun ń lá! Ó rí àpò dúdú kan tí owó ńlá wà nínú rẹ̀. Iye tó wà nínú àpò náà tó àpapọ̀ owó oṣù rẹ̀ fún ogún ọdún! Ó sì mọ ẹni tí owó náà sọ nù lọ́wọ́ rẹ̀. Kí ló yẹ kó ṣe? Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni, kí lo máa ṣe? Ìdáhùn rẹ máa jẹ́ ká mọ èrò rẹ nípa jíjẹ́ olóòótọ́, ó sì máa fi hàn bó o ṣe jẹ́ olóòótọ́ tó.
Kí ni ìwà ọmọlúwàbí? Ìwà ọmọlúwàbí jẹ́ ìlànà ìwà rere tàbí ìwà tó bójú mu tá a kà sí ohun tó dáa, tó sì ṣe pàtàkì. Lára irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ni ìdáríjì, jíjẹ́ olóòótọ́, ìfẹ́, ọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Àwọn ìlànà tá a kà sí pàtàkì máa ń nípa lórí ìwà wa, àwọn ohun tá a fi ṣe àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Ó sì máa nípa lórí ìwà tá a máa fi kọ́ àwọn ọmọ wa. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé, bí ìwà rere ti ṣe pàtàkì tó yìí, ó ti ń dàwátì.
ÌWÀ RERE TI DÀWÁTÌ
Lọ́dún 2008, àwọn olùṣèwádìí kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́. Wọ́n ní kí wọ́n sọ èrò wọn nípa ìwà rere. Ọ̀gbẹ́ni David Brooks tó jẹ́ akọ̀ròyìn fún ìwé ìròyìn New York Times sọ pé: “Ó ṣeni láàánú pé wọn ò ka ọ̀rọ̀ nípa ìwà rere sí nǹkan pàtàkì, wọn ò tiẹ̀ kì í ronú nípa rẹ̀ rárá.” Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló gbà pé ìfipábánilò àti ìpànìyàn kò dára, àmọ́ “yàtọ̀ sí irú àwọn ìwà tó burú jáì bẹ́ẹ̀, wọn kì í ronú nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, kódà tó bá kan àwọn nǹkan bíi kéèyàn mutí kó sì tún máa wakọ̀, kéèyàn máa jí ìwé wò nígbà ìdánwò tàbí kẹ́ni tó ti ṣègbéyàwó tún lójú síta.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tiẹ̀ sọ pé: “Mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ da ara mi láàámù nípa ohun tó dára àti ohun tí kò dára.” Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ rèé: ‘Tó bá ṣáà ti dáa lójú ẹ, ṣe é. Ohun tọ́kàn ẹ bá ti sọ ni kó o ṣe.’ Ǹjẹ́ irú èrò bẹ́ẹ̀ tọ̀nà?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn lè fi ìfẹ́ tó lágbára àti àánú hàn látinú ọkàn wa wá, ọkàn èèyàn tún lè ṣe ‘ètàn, ó sì burú jayi.’ (Jeremáyà 17:9, Bíbélì Mímọ́) Tá a bá sì wo bí ìwà ọmọlúwàbí ṣe ń dàwátì láyé yìí, àá rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí, Bíbélì sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé bí nǹkan ṣe máa rí nìyẹn. Ó sọ pé, ‘Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, òǹrorò.’ Wọ́n á tún jẹ́ ‘aláìní ìfẹ́ ohun rere àti olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.’—2 Tímótì 3:1-5.
Òótọ́ pọ́ńbélé lohun tí Bíbélì sọ yìí. Èyí sì fi hàn pé ńṣe ló yẹ ká máa ṣọ́ ọkàn wa, kì í ṣe pé ká kàn máa ṣe ohun tí ọkàn wa bá ṣáà ti sọ pé ká ṣe! Kódà, Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn.” (Òwe 28:26) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká fi ohun rere kún inú ọkàn wa kó bàa lè máa mú ká ṣe ohun tó tọ́. Ibò la ti lè rí irú àwọn ohun rere bẹ́ẹ̀? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fọkàn tán Bíbélì nítorí pé ó kún fún ọgbọ́n, òótọ́ ọ̀rọ̀ pọ́ńbélé ló sì wà nínú rẹ̀.
ÀWỌN ÌWÀ RERE TÍ KÒ LẸ́GBẸ́!
Àwọn ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára pé àwa èèyàn ni Ọlọ́run dìídì ṣe Bíbélì fún. Díẹ̀ lára wọn ni: ìfẹ́, inú rere, ìwà ọ̀làwọ́ àti jíjẹ́ òlóòótọ́.
Nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.
Ìwé kan tó ń jẹ́ Engineering Happiness—A New Approach for Building a Joyful Life sọ pé: “Tó o bá ń nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ńṣe ni wọ́n á máa fi ìfẹ́ wá ẹ kiri.” Ó ṣe kedere pé, bí kò bá sí ìfẹ́ láàárín àwa èèyàn, a ò lè láyọ̀.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Òǹkọ̀wé Bíbélì tó kọ eṣẹ Ìwé Mímọ́ yẹn tún sọ pé: “Bí . . . èmi kò ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ nǹkan kan.”—1 Kọ́ríńtì 13:2.
Ìfẹ́ tá à ń sọ yìí kì í ṣe ti ìbálòpọ̀ takọtabo tàbí ìfẹ́ aláìnírònú; ṣùgbọ́n ó jẹ́ èyí tá a gbé karí ìlànà. Irú ìfẹ́ yìí ló máa ń mú kéèyàn ran àjèjì kan tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́, láìsí pé èèyàn ń retí àsanpadà tàbí èrè. 1 Kọ́ríntì 13:4-7 sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, . . . a máa fara da ohun gbogbo.”
Bí irú ìfẹ́ yìí kò bá sí nínú ìdílé, ilé náà kò ní tòrò, àwọn ọmọ ló sì máa ń jìyà rẹ̀ jù. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Monica kọ̀wé pé nígbà tóun wà lọ́mọdé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń kó ìdààmú ọkàn bá òun, wọ́n lu òun nílùkulù, wọ́n sì tún fipá bá òun lò pọ̀. Ó ní: “Mi ò rẹ́ni fìfẹ́ hàn sí mi, ayé sì sú mi pátápátá.” Àmọ́ nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó kó lọ sọ́dọ̀ bàbá àti ìyá rẹ̀ àgbà tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Monica sọ pé: “Mo máa ń tijú gan-an, ara mi kì í sì í yá mọ́ èèyàn, àmọ́ láàárín ọdún méjì ti mo fi gbé lọ́dọ̀ wọn, wọ́n kọ́ mi béèyàn ṣe ń ṣe ọ̀yàyà, béèyàn ṣe lè nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn àti béèyàn ṣe ń ṣaájò wọn. Wọ́n tún ràn mí lọ́wọ́ tí mo fi dẹni táwọn èèyàn ń bọ̀wọ̀ fún.” Ní báyìí, Monica ti ṣègbéyàwó, ilé rẹ̀ sì tòrò dáadáa. Òun àti ọkọ rẹ̀ pẹlú àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn eèyàn nípa kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Nǹkan kan wà tó jẹ́ pé téèyàn kò bá fura, kò ní jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ohun náà ni ìfẹ́ owó àtàwọn nǹkan tí owó lè rà. Téèyàn bá sì ní irú ẹ̀mí yìí ńṣe lonítọ̀hún á máa ronú pé owó, àwọn nǹkan tówó lè rà àti ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé. Àmọ́, àwọn ìwádìí táwọn kan ṣe fi hàn dáadáa pé, kò dìgbà téèyàn bá lówó rẹpẹtẹ kó tó láyọ̀. Kódà, Bíbélì gan-an jẹ́rìí sí i pé ìbànújẹ́ ló máa ń gbẹ̀yìn àwọn tó bá ń fi ojoojúmọ́ ayé wọn wá bí wọ́n ṣe máa ní owó àtàwọn nǹkan tí owó lè rà. Ìwé Oníwàásù 5:10 sọ pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá. Asán ni èyí pẹ̀lú.” Bíbélì tún sọ pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó.”—Hébérù 13:5.
Inú rere àti ìwà ọ̀làwọ́.
Àjọ kan tó ń jẹ́ Greater Good Science ní Yunifásítì Kalifóníà, nílùú Berkeley lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà sọ nínú àpilẹ̀kọ kan pé: “Báwo ló ṣe máa rí ná, ká sọ pé èèyàn lè rí ayọ̀ rà lọ́jà? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí ilé ìtajà kankan tó o ti lè rí ayọ̀ rà, àmọ́ o lè rí ojúlówó ayọ̀ tó o bá lọ sọ́jà tó o sì ra nǹkan fún ẹlòmíì.” Kí la fẹ́ mú jáde látinú ọ̀rọ̀ yìí? Ayọ̀ tẹ́nì kan máa ní nígbà tó bá fúnni ní nǹkan ju ayọ̀ tó máa ní nígbà tó bá gba nǹkan.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Ohun tó dára jù lọ tó sì lérè jù lọ tá a lè fún àwọn èèyàn ni àwa fúnra wa, ìyẹn àkókò àti okun wa. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń jẹ́ Karen rí obìnrin kan àtàwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjì tí wọ́n jókòó sínu mọ́tò kan tí wọ́n ṣí orí rẹ̀ sílẹ̀. Obìnrin yìí àti ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ fẹ́ lọ wọ ọkọ̀ òfurufú ni; àmọ́ mọ́tò wọn takú sọ́nà, ọkọ̀ èrò tí wọ́n tún pè kò tètè dé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó má tó ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta [45] kí Karen tó wakọ̀ dé pápákọ̀ òfurufú náà, ó sọ pé òun á gbé wọn lọ. Àwọn náà sì gbà pé kó gbé àwọn. Nígbà tí Karen ń pa dà bọ̀, ó rí ọmọbìnrin kejì tó ṣì jókòó sínú mọ́tò rẹ̀ níbi ìgbọ́kọ̀sí kan.
Obìnrin náà sọ fún Karen pé, “Ọkọ mi ń bọ̀ lọ́nà.”
Karen wá sọ pé, “Inú mi dùn pé àlàáfíà lo wà. Mo fẹ́ lọ ṣàtúnṣe ọgbà Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ìyẹn ṣọ́ọ̀ṣì wa.”
Obìnrin náà wá béèrè pé, “Ṣé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́ ni?”
Karen dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nìyẹn.
Ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, ẹnì kan fi lẹ́tà kan ránṣẹ́ sí Karen. Apá kan lẹ́tà náà sọ pé: “Èmi àti màmá mi kò lè gbàgbé oore ńlá tó o ṣe fún wa. A rí ọkọ̀ òfurufú náà wọ̀! Ẹ̀gbọ́n mi tiẹ̀ sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́. Abájọ tó o fi ṣoore ńlá bẹ́ẹ̀ fún wa. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni màmá mi náà, àmọ́ èmí ò lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí mọ́. Ṣùgbọ́n màá tún bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́!” Inú Karen dùn gan-an pé òun ran àwọn arábìnrin òun méjì lọ́wọ́. Ó ní, “Omi bọ́ lójú mi.”
Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Charles D. Warner kọ̀wé pé: “Ọ̀kan lára ohun tó ń mú kí ayé gbádùn mọ́ni ni pé, téèyàn bá ti ń fi tọkàntọkàn ran ẹlòmíì lọ́wọ́, ńṣe ló ń ran ara rẹ̀ lọ́wọ́.” Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé, Ọlọ́run ti dá àwa èèyàn láti máa gbé àwọn ìwà rẹ̀ yọ, gbogbo àwọn ìwà náà ló sì ṣeyebíye. Torí náà, òun la fi ìwà ọ̀làwọ́ jọ.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.
Jíjẹ́ olóòótọ́.
Ó ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn jẹ́ olóòótọ́ kí nǹkan tó lè máa lọ dáadáa láwùjọ. Ìwà àìṣòótọ́ máa ń fa ìbẹ̀rù, kì í jẹ́ káwọn èèyàn lè fọkàn tán ara wọn, ó sì máa ń fà ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ [Ọlọ́run]?” Kí wá ni ìdáhùn? “Ẹni tí ń rìn láìlálèébù . . . tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Sáàmù 15:1, 2) Torí náà, bíi tàwọn ìwà tó kù tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, jíjẹ́ olóòótọ́ wà lára àwọn ìwà tí wọ́n lè mọ èèyàn mọ̀. Kì í ṣe ipò téèyàn bá wà lásìkò kan tàbí bó ṣe rọrùn fún èèyàn tó láti ṣòótọ́ ló máa pinnu bóyá kéèyan jẹ́ olóòótọ́ tàbí kó má ṣe jẹ́ olóòótọ́.
Ṣó o rántí Christina tó rí àpò kan tí owó ńlá wà nínú rẹ̀? Bó ṣe máa ṣohun tó máa mú inú Ọlọ́run dùn ló wà lọ́kàn rẹ̀ kì í ṣe bó ṣe máa di olówó. Torí náà, nígbà tí ọkùnrin tó ni owó náà dé, ó sọ fún un pé òun bá a rí owó rẹ̀ tó sọ nù. Ẹnu ya ọkùnrin yìí fún bí Christina ṣe jẹ́ olóòótọ́ èèyàn yìí. Ó tún ya ọ̀gá Christina lẹ́nu pàápàá. Nígbà tó yá, ọ̀gá Christina gbé e ga sí ipò alábòójútó gbogbo ibi tí wọ́n ń kó ọjà sí nílé iṣẹ́ náà, ẹni tó sì ṣeé fọkàn tán gidigidi ni wọ́n máa ń fi sírú ipò bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ni ohun tó wà ní 1 Pétérù 3:10, tó sọ pé: “Ẹni tí yóò bá nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè, tí yóò sì rí àwọn ọjọ́ rere, kí ó kó . . . ètè rẹ̀ kúrò nínú ṣíṣe ẹ̀tàn.”
“MÁA RÌN NÍ Ọ̀NÀ ÀWỌN ÈNÌYÀN RERE”
Àwọn ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni jẹ́ ẹ̀rí pé Ẹlẹ́dàá wa nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, torí pé àwọn ìwà rere yẹn ń jẹ́ ká lè “máa rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere.” (Òwe 2:20; Aísáyà 48:17, 18) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà yẹn, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó sì máa bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Máa pa ọ̀nà [Ọlọ́run] mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé. Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò ìwọ yóò rí i.”—Sáámù 37:34.
Ọjọ́ ọla ń bọ̀ wá dára gan-an fún àwọn tó bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Wọ́n á máa gbé ìgbé ayé àlááfíà níbi tí kò ti ní sí àwọn èèyàn burúkú mọ́! Kò sí àní-àní pé ó yẹ kéèyàn fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni.