Ojú Ìwòye Bíbélì
Yíyá Àwọn Ọ̀rẹ́ Lówó àti Yíyáwó Lọ́wọ́ Wọn
“ẸNI BÚBURÚ Ń YÁ NǸKAN, KÌ Í SÌ Í SAN ÁN PADÀ, ṢÙGBỌ́N OLÓDODO Ń FI OJÚ RERE HÀN, Ó SÌ Ń FÚNNI NÍ Ẹ̀BÙN.”—SÁÀMÙ 37:21.
“MÁ ṢE yáwó, má sì ṣe yáni lówó; nítorí pé o lè máà rí owó tí o yáni gbà, okùn ọ̀rẹ́ a sì já.” Ohun tí William Shakespeare, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ òǹkọ̀wé eré onítàn kọ nìyẹn nígbà tó ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ọgbọ́n àtayébáyé. Dájúdájú, kò sí ohun tó lè dá rúgúdù sílẹ̀ nínú àjọṣepọ̀ ẹ̀dá tó yíyáwó àti yíyánilówó. Kódà, bí a bá tilẹ̀ ṣètò dídára gan-an, tí a sì ní èrò rere lọ́kàn, nǹkan kì í fìgbà gbogbo rí bí a ṣe rò ó.—Oníwàásù 9:11, 12.
Àwọn nǹkan lè ṣẹlẹ̀ tí ó lè mú kí ó ṣòro tàbí kí ó má ṣeé ṣe fún ẹni tó yáwó láti san án padà. Tàbí kí ẹni tó yáni lówó rí i pé òun nílò owó tó yáni náà láìròtẹ́lẹ̀. Bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, okùn ọ̀rẹ́ lè já kí àjọṣepọ̀ sì forí sọgi gẹ́gẹ́ bí Shakespeare ti sọ.
Ká sọ tòótọ́, ìdí pàtàkì lè wà tí ẹnì kan fi ní láti yá owó díẹ̀. Bí owó kò bá sí lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí pé ìjàǹbá burúkú kan ṣẹlẹ̀ sí i tàbí tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó lè rí i bí ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tí òun ní. Bíbélì rọ àwọn tí wọ́n bá lágbára àtiṣèrànwọ́ pé kí wọ́n ran àwọn tí wọ́n ṣaláìní lọ́wọ́. (Òwe 3:27) Èyí lè ní yíyánilówó nínú. Nígbà náà, báwo ló ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni tí ń kó wọnú irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ wo ẹrù tí èyí gbé ka iwájú wọn?
Àwọn Ìlànà Tó Yẹ Kí A Gbé Yẹ̀wò
Bíbélì kì í ṣe ìwé àlàyé ìṣètò ìnáwó. Kò sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí yíyáwó àti yíyánilówó lè ní nínú. Àwọn ọ̀ràn bí bóyá ó yẹ ká gba èlé tàbí ká má gbà á àti iye tó yẹ ká gbà bí èlé ni ó fi sílẹ̀ fún àwọn tí ọ̀ràn kàn.a Àmọ́, ohun tí Bíbélì pèsè jẹ́ ìlànà onífẹ̀ẹ́, tó ṣe kedere tó yẹ kó darí ìrònú àti ìhùwà ẹnikẹ́ni tí ń yáwó tàbí tí ń yáni lówó.
Gbé àwọn ìlànà tó kan ẹni tó yáwó yẹ̀wò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú láti má ṣe “máa jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ẹyọ ohun kan, àyàfi láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 13:8) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà tí Pọ́ọ̀lù sọ níhìn-ín kan ọ̀pọ̀ nǹkan, ó dájú pé a lè wo ìmọ̀ràn rẹ̀ bí ìkìlọ̀ lòdì sí títọrùn bọ gbèsè. Nígbà mìíràn, ó máa ń sàn kí a máà lówó lọ́wọ́ rárá ju kí a jẹ ẹnì kan ní gbèsè lọ. Èé ṣe? Òwe 22:7 ṣàlàyé pé, “ayá-nǹkan . . . ni ìránṣẹ́ awínni.” Títí ìgbà tí ẹni tó yáwó máa fi san án padà, ó gbọ́dọ̀ mọ̀ pé gbèsè wà lọ́rùn òun. Bí a bá fẹ́ wò ó bó ṣe rí gan-an, kì í ṣe gbogbo owó tí ń wọlé fún un ló jẹ́ tirẹ̀. Sísan gbèsè rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn tí wọ́n ṣe ló gbọ́dọ̀ mú ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ akutupu lè hu.
Fún àpẹẹrẹ, tí kò bá san owó tó yẹ kí ó san bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, inú lè bí ẹni tó yá a lówó. Ẹni tó yá a lówó náà lè wá máa fura sí àwọn ohun tí ẹni tó yáwó náà ń ṣe bíi ríra aṣọ, jíjẹun ní ilé àrójẹ, tàbí lílọ fún ìsinmi. Ó lè tanná ran ìkórìíra. Àjọṣe tó wà láàárín wọn àti láàárín àwọn ìdílé wọn tilẹ̀ lè forí ṣánpọ́n tàbí kí ó tilẹ̀ bàjẹ́. Ohun burúkú tó lè ṣẹlẹ̀ nìyẹn bí ẹni tí a yá lówó náà kò bá mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ.—Mátíù 5:37.
Ṣùgbọ́n tó bá ṣẹlẹ̀ pé ohun kan ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ tó ju agbára ẹni tó yáwó náà lọ, tí kò fi lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ ńkọ́? Ṣé èyí yóò fagi lé gbèsè rẹ̀ ni? Ó lè máà rí bẹ́ẹ̀. Onísáàmù sọ pé olódodo “ti búra sí ohun tí ó burú fún ara rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kò yí padà.” (Sáàmù 15:4) Bí irú ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, ohun tó mọ́gbọ́n dání tó sì fi ìfẹ́ hàn tó yẹ kí ẹni tó yáwó náà ṣe ni pé kí ó lọ ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ẹni tó yá a lówó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Nígbà náà, wọ́n lè wá ṣàdéhùn mìíràn. Èyí yóò mú kí àlàáfíà wà, yóò sì mú inú Jèhófà Ọlọ́run dùn.—Sáàmù 133:1; 2 Kọ́ríńtì 13:11.
Ní gidi, ọ̀nà tí ẹnì kan ń gbà yanjú ọ̀ràn gbèsè tó jẹ ń fi ohun púpọ̀ hàn nípa rẹ̀. Fífi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn sísan owó náà padà ń fi hàn pé kò bìkítà fún àwọn ẹlòmíràn. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tó ní ìṣarasíhùwà yẹn ń fi ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan hàn—ìfẹ́-ọkàn àti àníyàn tirẹ̀ ló jẹ ẹ́ lógún jù. (Fílípì 2:4) Kristẹni kan tó mọ̀ọ́mọ̀ má san gbèsè rẹ̀ ń fi ìdúró rẹ̀ níwájú Ọlọ́run sínú ewu, àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ sì lè fi hàn pé ó ní ọkàn-àyà burúkú, tí ó níwọra.—Sáàmù 37:21.
Ayánilówó
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó yáwó ló ni ẹrù tó pọ̀ jù níbẹ̀, àwọn ìlànà kan tún wà tó kan ẹni tó yáni lówó. Bíbélì sọ pé tí a bá ní agbára láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́, kí á ṣe bẹ́ẹ̀. (Jákọ́bù 2:14-16) Ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ọ̀ràn-anyàn ni pé kí ẹnì kan yáni lówó, bí ẹni tó wá yá owó náà bá tilẹ̀ jẹ́ arákùnrin nípa tẹ̀mí pàápàá. Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.”—Òwe 22:3.
Bí olóye ènìyàn bá mọ àwọn òfin gidi tó wà nínú yíyánilówó àti yíyáwó, tí ó sì lóye wọn, yóò ròóore tí ó bá ń gbé ọ̀ràn ẹni tó fẹ́ wá yáwó lọ́wọ́ rẹ̀ yẹ̀wò. Ǹjẹ́ ìdí tó fi wá béèrè fún owó náà fẹsẹ̀ múlẹ̀? Ǹjẹ́ ẹni tó fẹ́ yáwó yìí ti rò ó dáadáa? Ǹjẹ́ ẹni tó fẹ́ yáwó náà máa ń ṣe nǹkan létòlétò, tí a sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere? Ǹjẹ́ ó múra tán láti buwọ́ lu ìwé àdéhùn nípa owó tó fẹ́ yá náà? (Fi wé Jeremáyà 32:8-14.) Ǹjẹ́ ó múra tán ní gidi láti san án padà?
Èyí kò fi hàn pé kí Kristẹni kan kọ̀ láti ṣèrànlọ́wọ́ fún ẹnì kan tó ṣaláìní, tó sì jọ pé ó lè léwu láti yá lówó. Ẹrù iṣẹ́ Kristẹni kan sí àwọn ẹlòmíràn ré kọjá bíbá wọn da òwò tó lówó lórí pọ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù béèrè pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ní àlùmọ́ọ́nì ayé yìí fún ìtìlẹyìn ìgbésí ayé, tí ó sì rí i tí arákùnrin rẹ̀ ṣe aláìní, síbẹ̀ tí ó sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mọ́ ọn, lọ́nà wo ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi dúró nínú rẹ̀?” Òótọ́ ni, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.”—1 Jòhánù 3:17, 18.
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ẹnì kan lè yàn láti máà yá arákùnrin rẹ̀ tó ṣaláìní lówó. Ó lè yàn láti fún un ní ẹ̀bùn tàbí kí ó ṣe àwọn ìrànlọ́wọ́ mìíràn fún un. Pẹ̀lú irú ẹ̀mí kan náà, bí ìṣòro bá ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn owó yíyá, ẹni tó yáni lówó lè yàn láti fi àánú hàn. Ó lè fẹ́ láti gba ti ipò nǹkan tó yí padà fún ẹni tó yáwó náà rò, kí ó sì túbọ̀ sún ìgbà tí yóò san owó náà padà síwájú, tàbí kí ó dín iye tí yóò san kù, tàbí kí ó tilẹ̀ fagi lé gbèsè náà pátápátá. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìpinnu ti ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣe fúnra rẹ̀.
Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé Ọlọ́run ń rí gbogbo ohun tí ń lọ, a óò sì jíhìn ọ̀nà tí a ń gbà hùwà tí a sì ń gbà lo ohun tí a ní fún un. (Hébérù 4:13) Dájúdájú, ìmọ̀ràn Bíbélì pé kí a jẹ́ kí gbogbo “àlámọ̀rí [wa] máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́” wúlò nínú ọ̀ràn yíyá àwọn ọ̀rẹ́ lówó àti yíyáwó lọ́wọ́ wọn.—1 Kọ́ríńtì 16:14.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti rí ìsọfúnni sí i lórí ọ̀ràn gbígba èlé lórí owó tí a yáni, jọ̀wọ́ wo Ilé-Ìṣọ́nà, October 15, 1991, ojú ìwé 25 sí 28.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
“Aṣẹ́nilówó àti Ìyàwó Rẹ̀” (1514), láti ọwọ́ Quentin Massys
[Credit Line]
Scala/Art Resource, NY