Ori 17
Fifi Iduroṣinṣin Ranti Ètò-Àjọ Jehofa
1. A gbọdọ maa ronu nipa iduroṣinṣin si ta ni, ki ni Ọba Dafidi si wi nipa eyi?
AMAA ń sọrọ pupọ lonii nipa iduroṣinṣin ẹnikan si orilẹ-ede rẹ̀. Ṣugbọn bawo ni awọn alaṣẹ ati awọn eniyan ayé yii ti ṣe ń sọrọ pupọ to nipa iduroṣinṣin si Ọlọrun, ẹni ti ń ṣe Ẹlẹ́dàá ilẹ tí orilẹ-ede ẹnikọọkan wà lori rẹ̀? Ní awọn akoko igbaani, Ọba Dafidi ti Israeli jẹ́ olujọsin ati aduroṣinṣin ti Ẹlẹ́dàá naa, Jehofa Ọlọrun. Ní biba Ọlọrun aduroṣinṣin yii sọrọ, Dafidi sọ awọn ọ̀rọ̀ wọnyi pe: “Fun ẹni iduroṣinṣin ní ododo ni iwọ o fi araarẹ hàn ni iduroṣinṣin ní ododo.” (2 Samueli 22:26; Orin Dafidi 18:25) Awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ha fi iṣarasihuwa rẹ si Ọlọrun hàn bi?
2. Bawo ni a ṣe mọ̀ pe Jehofa ṣì ń baa lọ ní jíjẹ́ aduroṣinṣin si idile iran eniyan?
2 Iṣarasihuwa awọn eniyan ní gbogbogboo lonii kii ṣe ọkan ti ó jẹ́ ti alaniyan titobi nipa iduroṣinṣin si Ọlọrun. Ṣugbọn laika eyiini si, Jehofa jẹ́ aduroṣinṣin si idile eniyan. Oun kò tii ta á nù. Ọmọkunrin rẹ̀ aduroṣinṣin wi pe: “Ọlọrun fẹ araye tobẹẹ gẹẹ, ti ó fi Ọmọ bibi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti ó bá gba a gbọ ma baa ṣegbe, ṣugbọn ki ó lè ní iye ainipẹkun.” (Johannu 3:16) Ọlọrun kò fi ayé iran eniyan silẹ sọwọ olori ọta rẹ̀, Satani, ẹni ti ó ti fi ẹtan sun awọn obi wa akọkọ lati di alaiduroṣinṣin si Ọlọrun. Ọlọrun tun fi iduroṣinṣin rẹ̀ hàn si idile eniyan ní 2370 B.C.E. nipa pipa Noa ati idile rẹ̀ mọ́ la Ikun-Omi kárí-ayé já eyi ti ó gbá iyoku iran eniyan lọ. (2 Peteru 2:5) Ní ọna yii Ẹlẹ́dàá naa fi ibẹrẹ titun lélẹ̀ fun idile iran eniyan.
3. (a) Ki ni ohun ti a lè sọ nipa iwa ipa lonii, ki sì ni Ọlọrun ti pète lati ṣe nipa rẹ̀? (b) Ki ni èrè fun iduroṣinṣin si Jehofa?
3 Lonii iwa ipa kárí-ayé tayọ rekọja ti akoko Noa ní eyi ti ó ju 4,000 ọdun sẹhin. (Genesisi 6:11) Nitori naa ẹ̀tọ́ wà fun Ọlọrun kan naa lati pa eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi rẹ́ kuro. Eyi ni oun ti pète lati ṣe, ṣugbọn nigba ti ó ba ń ṣe bẹẹ, oun ki yoo pa awọn ẹni aduroṣinṣin rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé run. Nigba naa oun yoo wá huwa ní ibamu pẹlu Orin Dafidi 37:28: “Nitori ti Oluwa fẹ́ idajọ, kò si kọ awọn eniyan mímọ́ rẹ̀ silẹ.” Gẹgẹ bi ti ọjọ Noa, oun yoo fi ibẹrẹ ododo jinki eto-igbekalẹ awọn nǹkan titun ti yoo ní ninu “awọn ọ̀run titun ati ayé titun.” (2 Peteru 3:13) Èrè fun jijẹ aduroṣinṣin tobi. O ń funni ní iye!
4. Bawo ni a ṣe mọ̀ pe orilẹ-ede Israeli ni ètò-àjọ Jehofa ti a le fojuri ti igba yẹn?
4 Nigba iṣakoso Ọba Dafidi, orilẹ-ede Israeli fihan pe wọn jẹ́ aduroṣinṣin si Jehofa. Dafidi fi apẹẹrẹ lélẹ̀ fun orilẹ-ede naa lapapọ. Orilẹ-ede yẹn jẹ́ ètò-àjọ Jehofa ti a lè fojuri. Wọn jẹ awọn eniyan kan ti a ṣetojọ ti wọn dìídíì jẹ́ tirẹ̀ lara ọ̀tọ̀. Laisi àníàní eyi ni ohun ti irannileti Ọlọrun, bi a ti tò ó lẹsẹẹsẹ ninu Amosi 3:1, 2, tumọsi: “Ẹ gbọ ọ̀rọ̀ yii ti Oluwa ti sọ si yin, ẹyin ọmọ Israeli, si gbogbo idile ti mo mu goke lati ilẹ Egipti wá, wi pe, ẹyin nikan ni mo mọ̀ ninu gbogbo idile ayé.”—Fiwe 1 Ọba 8:41-43.
5. (a) Nigba ayé awọn aposteli Jesu Kristi, awọn isapa ha wà lati mu awọn aṣiṣe wọnú ijọ Kristian bi? (b) Ki ni ohun ti a sọtẹlẹ pe yoo ṣẹlẹ lẹhin iku awọn aposteli?
5 Ní ibaradọgba pẹlu otitọ itan Bibeli yii, Ọlọrun yii kan naa, Jehofa, ní awọn eniyan ti a ṣetojọ kan, ètò-àjọ kan ti a lè fojuri, lori ilẹ̀-ayé lonii. Ó jẹ ètò-àjọ kan ti ó jẹ́ kiki tirẹ nikan. Bi o ti wu ki o ri, awọn igbesẹ waye lati mú awọn aṣiṣe wọnú ètò-àjọ Ọlọrun paapaa ní ibẹrẹpẹpẹ rẹ̀ nigba ayé awọn aposteli Jesu Kristi, awọn ẹni ti wọn jẹ́ olugbeja lilagbara fun iwatitọ ijọ Kristian naa. (1 Korinti 15:12; 2 Timoteu 2:16-18) Lẹhin iku aposteli Johannu, dajudaju laipẹ pupọ lẹhin 98 C.E., iṣubu kuro naa ti a ti sọtẹlẹ bẹrẹsii ṣẹlẹ.—Iṣe 20:30; 2 Peteru 2:1, 3; 1 Timoteu 4:1.
6. (a) Bawo ni akoko ti ipẹhinda jẹgaba ti gun tó, pẹlu abajade wo si ni? (b) Inu igbekun wo ni awọn ètò-àjọ isin Kristẹndọm kówọ̀, awọn ibeere wo ni ó si dide?
6 Ipẹhinda naa jẹgaba fun eyi ti ó ju ọrundun 17 lọ, wọnú idaji ti ó kẹhin ninu ọrundun kọkandinlogun. Nigba yẹn Kristẹndọm ti pin yẹlẹyẹlẹ si awọn ọgọrọọrun ẹya-isin. Ami idanimọ awọn eniyan tootọ Ọlọrun ti di bàìbàì. Kristẹndọm jẹ idarudapọ awọn ètò-àjọ onisin, ati kekere ati nla, ti ń sọ amulumala awọn ede isin ti a kò fidi rẹ̀ mulẹ ninu ede isin ti Iwe Mímọ́ ti a misi. Iru awọn ètò-àjọ isin bẹẹ ni ilẹ-ọba kan ti ó fi pupọpupọ tobi ju Ilẹ-ọba Babiloni ti ó pa Jerusalemu run ti mu nigbekun niti gidi. Ṣugbọn bawo ni Babiloni igbaani ṣe ri, ki ni o si ti nilati jẹ́ iṣarasihuwa awọn Ju oluṣotitọ wọnni ti a mu ní igbekun?
Awọn Igbekun ní Babiloni Fi Pẹlu Iduroṣinṣin Ranti Sioni
7. (a) Ki a sọrọ lọna ti isin, bawo ni ilẹ Babiloni igbaani ti ri? (b) Iyọrisi wo ni eyi ti lè ní lori awọn igbekun Ju?
7 Babiloni igbaani jẹ ilẹ awọn ọlọrun eke, ti ère wọn kun inu rẹ̀ fọfọ. (Danieli 5:4) A lè fi oju inu woye ipa ti ijọsin ọpọ awọn ọlọrun eke wọnyi ní lori ọkan-aya awọn Ju oluṣotitọ ti wọn ti sin kiki Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa laisi iru ère eyikeyii. Dipo wiwo tẹmpili Jehofa ninu gbogbo ẹwà rẹ̀ ní Jerusalemu, wọn ri awọn tẹmpili awọn ọlọrun eke wọnyi pẹlu awọn ère wọn la gbogbo ilẹ Babiloni já.a Ẹ wo bi awọn olujọsin Ọlọrun otitọ kanṣoṣo naa yoo ti jiya imọlara ikoriira oju ẹsẹ tó nitori gbogbo awọn nǹkan wọnyi!
8. (a) Yoo ti pẹ tó ti awọn Ju yoo nilati farada wíwà ní igbekun wọn, iyanhanhan wo ni awọn Ju aduroṣinṣin sì ní? (b) Bawo ni Orin Dafidi 137:1-4 ṣe ṣapejuwe ipo ibanujẹ ọkan-aya ti awọn igbekun Ju aduroṣinṣin ní?
8 Ní ibamu pẹlu asọtẹlẹ Jeremiah, wọn nilati farada eyi fun 70 ọdun ki imupadabọsipo tó de. (2 Kronika 36:18-21; Jeremiah 25:11, 12) Ipo ibanujẹ ọkan-aya awọn igbekun Ju ololufẹ Jehofa ti wọn nifẹẹ lati sin in ninu tẹmpili kan ti a yasimimọ fun un ninu ilu ayanfẹ rẹ̀ ni a ṣapejuwe fun wa ninu Orin Dafidi 137:1-4 pe: “Ní ẹ̀bá odo Babeli, nibẹ ni awa gbe jokoo, awa si sọkun nigba ti awa ranti Sioni. Awa fi dùrù wa kọ́ si ori igi willo ti ó wà laaarin rẹ̀. Nitori pe nibẹ ni awọn ti ó kó wa ní igbekun beere orin lọwọ wa; ati awọn ti ó ni wa lara beere idaraya wi pe; Ẹ kọ orin Sioni kan fun wa. Awa o ti ṣe kọ orin Oluwa ní ilẹ ajeji?”
9. Bawo ni awọn ara Babiloni yoo ṣe ka kikọ “orin Oluwa” si, ṣugbọn ki ni yoo ṣẹlẹ lẹhin 70 ọdun naa?
9 “Orin Oluwa” gbọdọ jẹ orin awọn eniyan olominira ti ń sin in ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀. Si awọn ara Babiloni wọnni, kikọ “orin Oluwa” lati ẹnu awọn Ju wọnyi ni ilẹ igbekun wọn yoo jẹ́ akoko kan fun awọn amunisin wọn lati maa fi orukọ Jehofa ṣẹ̀fẹ̀ bi orukọ ọlọrun kan ti ó rẹlẹ si awọn ọlọrun Babiloni. Orukọ mímọ́ rẹ̀ ti wá sabẹ ẹgan nlanla nipa jijẹ ki a mu awọn eniyan rẹ̀ kuro ninu ilẹ ti Ọlọrun yọnda fun wọn ki a si mu wọn yan jade lọ si ilẹ kan ti ó ní ọgọọrọ awọn ọlọrun. Ṣugbọn akoko ti awọn ara Babiloni wọnyẹn yoo fi i ṣẹ̀fẹ̀ ti wọn yoo si foju tin-inrin awọn eniyan fun orukọ rẹ̀ yoo wulẹ jẹ́ fun akoko kan ti ó ní aala—70 ọdun. Nigba naa ki awọn ọlọrun eke Babiloni wọlẹ̀ ki Ọlọrun otitọ naa, Jehofa, si di ẹni ti a gbé ga!
Fifi Ọkan-Aya Dirọmọ Ètò-Àjọ Jehofa
10. Ibeere wo ni ó dide nipa awọn eniyan Jehofa ti ọrundun ogun yii ti a mú wá sinu igbekun Babiloni Nla?
10 Lonii ètò-àjọ onisin kan wà ti a ń pe ní Babiloni Nla ti a ko fimọ si kiki agbegbe ilẹ Babiloni atetekọṣe ṣugbọn ti ó jẹ́ kárí-ayé. Njẹ iṣarasihuwa ọkan-aya awọn Ju ní Babiloni igbaani ha fi ipilẹ ilana titọ lelẹ fun awọn eniyan Jehofa ti ọrundun ogun yii ti a fi tipatipa mu wá sinu igbekun Babiloni Nla gẹgẹ bi ibawi lati ọdọ Ọlọrun Israeli igbaani bi?
11. (a) Njẹ awọn Ju aduroṣinṣin wọnyẹn ha jẹ́ ki ilẹ ibilẹ wọn parẹ kuro ninu iranti wọn bi? (b) Bawo ni olorin ti ó wà nigbekun naa ṣe sọ imọlara awọn igbekun ẹlẹgbẹ rẹ̀ jade?
11 Bi o tilẹ jẹ pe wọn iba ti maa gbe ní pẹ̀lẹ́tù ninu Babiloni igbaani ki wọn si sọ ibẹ di ile, niwọn ìgbà ti akoko igbekun wọn yoo ti fẹrẹẹ tó iran kan ní gigun, wọn ha jẹ́ ki ilẹ ibilẹ wọn parẹ kuro ninu iranti wọn bi? Olorin naa ti ó wà nigbekun sọ ọ jade lọna ẹlẹwa nigba ti ó sọ imọlara awọn igbekun ẹlẹgbẹ rẹ̀ jade pe: “Jerusalemu, bi emi ba gbagbe rẹ, jẹ́ ki ọwọ ọtun mi ki o gbagbe ilo rẹ̀. Bi emi ko ba ranti rẹ, jẹ́ ki ahọ́n mi ki o lẹ̀ mọ́ erigi mi; bi emi ko ba fi Jerusalemu ṣaaju olori ayọ̀ mi gbogbo.”—Orin Dafidi 137:5, 6.
12. Ki ni iṣarasihuwa ọkan-aya olorin ti ó wà nigbekun naa fihan?
12 Ki ni iṣarasihuwa ọkan-aya igbekun ọmọ Israeli yii fihan? Eyi: iduroṣinṣin si ètò-àjọ Jehofa ti a le fojuri ti igba yẹn nigba ti ó rii ti ilẹ ti Ọlọrun fifun awọn eniyan ayanfẹ Rẹ̀ dahoro fun 70 ọdun. Bẹẹni, ètò-àjọ Jehofa ti a le fojuri ṣì walaaye sibẹ ninu ọkan-aya awọn ọmọ Israeli wọnyẹn.
13. Bawo ni a ṣe san èrè fun iduroṣinṣin sí ètò-àjọ Jehofa ti a lè fojuri?
13 Iru iduroṣinṣin si ètò-àjọ Ọlọrun ti a le fojuri ti igbaani ni a san èrè fun bi o ti tọ́. Iyẹn jẹ nigba ti Babiloni, agbara ayé kẹta ninu itan Bibeli, di eyi ti a da oju rẹ̀ de, ti Medo-Persia, agbara ayé kẹrin, mu ifẹ-inu Ọlọrun Israeli ṣẹ. Bawo? Nipa mimu awọn igbekun Ju padabọ si ilẹ ètò-àjọ Jehofa ti a lè fojuri, pẹlu itọni lati tun tẹmpili Ọlọrun wọn kọ gẹgẹ bi ibi ikorijọ awọn igbokegbodo olú-ilú naa, Jerusalemu. (2 Kronika 36:22, 23) Kii ṣe kiki pe a tun tẹmpili ijọsin tootọ kọ́ nikan ni ṣugbọn odi ilu-nla Jerusalemu ni a tunkọ pẹlu, lati di ilu-nla naa ti Jehofa ti ń ṣakoso bi Ọba lori awọn eniyan rẹ̀.
14. (a) Ní ọpọ ọrundun lẹhin naa, ki ni ohun ti Messia naa sọ nipa ètò-àjọ Jehofa ti a le fojuri? (b) Lọna wo ni Jehofa fi ń ṣakoso lati Jerusalemu wá?
14 Ní eyi ti ó ju ọrundun mẹfa lẹhin ti a ti pa Jerusalemu run, Jesu wi pe: “Ẹ maṣe búra rara, ibaa ṣe ifi ọ̀run búra, nitori pe itẹ Ọlọrun ni, tabi ayé, nitori apoti itisẹ rẹ̀ ni, tabi Jerusalemu, nitori ilu ọba nla ni.” (Matteu 5:34, 35) Nigba ti Messia naa wà lori ilẹ̀-ayé, tẹmpili Jehofa ti a tunkọ wà ní Jerusalemu, ati, ní sisọrọ lọna iṣapẹẹrẹ, Jehofa Ọlọrun ń ṣakoso ninu Ibi Mímọ́ Julọ tẹmpili yẹn. Nitori naa lati Jerusalemu bi olu-ilu awọn eniyan rẹ̀, Jehofa ṣakoso lori ètò-àjọ rẹ̀ ti a lè fojuri.
Jehofa Ṣì Ń Baa Lọ Lati Jẹ́ Aduroṣinṣin si Ètò-Àjọ Rẹ̀
15. Jesu ha ń ṣa apa ti ó ṣee fojuri ninu ètò-àjọ Jehofa tì nigba ti ó tudii aṣiri awọn aṣaaju isin alaiṣotitọ ti Israeli? Ṣalaye.
15 O dara, nisinsinyi, Jesu ha ta ètò-àjọ Ọlọrun ti a lè fojuri nù nigba ti ó tudii aṣiri awọn aṣaaju isin alaiṣotitọ ti Israeli ti ó si dẹbi fun wọn bi? Bẹẹni, nitori oun wi pe: “Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti ó pa awọn wolii, ti ó si sọ okuta lu awọn ti a rán si ọ pa, igba meloo ni emi ń fẹ radọ bo awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ ti iradọ bo awọn ọmọ rẹ̀ labẹ apa rẹ̀, ṣugbọn ẹyin kò fẹ́! Sawo o, a fi ile yin silẹ fun yin ní ahoro.” (Matteu 23:37, 38) Nigba ti Jesu kọ Jerusalemu ati “awọn ọmọ” rẹ̀ silẹ, oun ha ń tipa bayii fi Baba rẹ̀ ọ̀run silẹ laini ètò-àjọ ori ilẹ̀-ayé kankan bi? Bẹẹkọ! Nitori Jesu funraarẹ ni ipilẹ ètò-àjọ titun ti a lè fojuri tí Ẹlẹ́dàá agbaye naa fẹ́ gbéró.
16. Ní igba iku Jesu lori igi oro, bawo ni a ṣe fi ikọsilẹ Israeli abinibi hàn?
16 Ikọsilẹ Israeli abinibi ni a fihan dajudaju nigba ti aṣọ ìkélé gbigbopọn ti ó ge Ibi Mímọ́ Julọ kuro lara Ibi Mímọ́ ninu tẹmpili ní Jerusalemu di eyi ti a fàya si meji “lati oke de isalẹ,” nigba iku Jesu lori igi oro. Lẹsẹkan naa, “ilẹ si mi tìtì, awọn apata sì san.” Awọn wọnyi jẹ iṣẹ iyanu niha ọdọ Ọlọrun naa ti ó ti ń ṣakoso nibẹ tẹlẹri lọna iṣapẹẹrẹ kan, ti ń fi kíkọ̀ ti oun kọ orilẹ-ede Israeli ati ijọsin rẹ̀ silẹ hàn.—Matteu 27:51.
17. Bawo ni Jesu ati Jehofa ṣe fi iduroṣinṣin hàn si awọn mẹmba ti wọn fojusọna lati wà ninu ètò-àjọ Ọlọrun titun ti a lè fojuri?
17 Awọn mẹmba ti wọn fojusọna lati wà ninu ètò-àjọ titun naa tí Jehofa Ọlọrun fẹ́ gbéró laipẹ si ìgbà naa ni a fi silẹ nibẹ ní agbegbe Jerusalemu. Jesu fi wọn si ìkáwọ́ itọju Ọlọrun, ẹni ti ń fi ilu-nla ilẹ̀-ayé naa silẹ nitori ohun kan ti ó sanju. (Johannu 17:9-15) Nipa bayii Jehofa ṣi ń baa lọ lati jẹ́ aduroṣinṣin si ètò-àjọ rẹ̀, ní fifi igbatẹniro akanṣe hàn si awọn babanla wọn oluṣotitọ, Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu pẹlu awọn ọmọkunrin Jakọbu 12. (Danieli 12:1) Akori ti ó tẹ̀lé e yoo tẹsiwaju sii lori ijiroro nipa iduroṣinṣin, ti a gbeka Orin Dafidi 137.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ikọwe ti finfin ọ̀rọ̀ sara amọ̀ (cuneiform) lati Babiloni igbaani rohin pe: “Lapapọ tẹmpili 53 awọn ọlọrun pataki pataki, 55 awọn ile ijọsin kekere fun Marduk, 300 awọn ile ijọsin kekere fun awọn oriṣa ilẹ̀-ayé, 600 fun awọn oriṣa ọ̀run, 180 awọn pẹpẹ fun ọlọrun obinrin Ishtar, 180 fun awọn ọlọrun Nergal ati Adad ati awọn pẹpẹ 12 miiran fun awọn oriṣiriṣi ọlọrun ni wọn wà ní Babiloni.”