Ọlọ́run Mọyì Àwọn Arúgbó
ÌWÀ ìkà sáwọn arúgbó tó wọ́pọ̀ gan-an lónìí kò yani lẹ́nu rárá. Látìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí, àwọn èèyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:1-3) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìfẹ́ni àdánidá” ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín àwọn tó jọ jẹ́ ara ìdílé kan náà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wí, irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ti dín kù gan-an lóde òní.
Jèhófà Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sáwọn tó ń hùwà ìkà sáwọn arúgbó. Ó mọyì wọn gan-an, ó sì ń bójú tó àwọn tó ti dàgbà gan-an lọ́jọ́ orí. Wo ọ̀nà tí Bíbélì gbà fi èyí hàn.
“Onídàájọ́ fún Àwọn Opó”
Bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe bìkítà fáwọn arúgbó hàn kedere nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Bí àpẹẹrẹ, nínú Sáàmù 68:5, Dáfídì pe Ọlọ́run ní “onídàájọ́ àwọn opó,” tí wọ́n sábà máa ń jẹ́ àgbàlagbà.a Ohun táwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn tú ọ̀rọ̀ náà “onídàájọ́” sí ni “olùgbèjà,” “aláàbò,” àti “akọgun.” Láìsí àní-àní, Jèhófà bìkítà fáwọn opó. Kódà, Bíbélì sọ pé bí wọ́n bá fìyà jẹ wọ́n pẹ́nrẹ́n, ìbínú rẹ̀ yóò ru. (Ẹ́kísódù 22:22-24) Àwọn opó, àti gbogbo àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ṣe pàtàkì gan-an lójú Ọlọ́run àti lójú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Òwe 16:31 jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀ fi ń wo àwọn arúgbó nígbà tó sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.”
Abájọ tí ọ̀rọ̀ bíbọ̀wọ̀ fáwọn arúgbó fi jẹ́ apá pàtàkì nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí o dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó, kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ. Èmi ni Jèhófà.” (Léfítíkù 19:32) Nítorí náà, nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ọ̀wọ̀ tẹ́nì kan ní fáwọn àgbàlagbà kan àjọṣe tó wà láàárín onítọ̀hún àti Jèhófà Ọlọ́run. Ẹnì kan ò lè máa hùwà ìkà sáwọn arúgbó, kó sì sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.
Àwọn Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́, àmọ́ wọ́n wà lábẹ́ “òfin Kristi.” Èyí sì ń nípa lórí ìwà àti ìṣe wọn gan-an, títí kan fífi ìfẹ́ hàn sáwọn òbí wọn àtàwọn arúgbó, kí wọ́n sì máa bójú tó wọn. (Gálátíà 6:2; Éfésù 6:1-3; 1 Tímótì 5:1-3) Kì í ṣe tìtorí pé a pa á láṣẹ fáwọn Kristẹni láti máa fìfẹ́ hàn nìkan ló jẹ́ kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ nítorí pé ọkàn wọn máa ń sún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni. Àpọ́sítélì Pétérù rọni pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.”—1 Pétérù 1:22.
Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù tún mẹ́nu kan ìdí mìíràn tó fi yẹ ká máa bójú tó àwọn àgbàlagbà. Ó kọ̀wé pé: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.” (Jákọ́bù 1:27) Jákọ́bù mẹ́nu kan kókó kan tó wọni lọ́kàn ṣinṣin. Ó jẹ́ ká mọ báwọn ẹni ọ̀wọ́n wọ̀nyí ti ṣe pàtàkì tó lójú Jèhófà.
Nítorí náà, ṣíṣàì hùwà ìkà sáwọn arúgbó nìkan kò tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, a tún gbọ́dọ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, nípa ṣíṣe àwọn ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní fún wọn. (Wo àpótí náà, “Ohun Tí Ìfẹ́ Lè Múni Ṣe,” lójú ìwé 6 sí 7.) Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.”—Jákọ́bù 2:26.
Báwọn Àgbàlagbà Ṣe Lè Ní Ìtùnú “Nínú Ìpọ́njú Wọn”
Kókó mìíràn tún wà téèyàn lè mú jáde nínú ọ̀rọ̀ Jákọ́bù yìí. Kíyè sí i pé Jákọ́bù sọ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn opó “nínú ìpọ́njú wọn.” Ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìpọ́njú” dìídì túmọ̀ sí ni ìrora ọkàn, ìyọnu, tàbí ìbànújẹ́ táwọn ìṣòro tá a máa ń dojú kọ nígbèésí ayé sábà máa ń mú bá wa. Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ lára àwọn arúgbó ló máa ń ní irú ìrora ọkàn bẹ́ẹ̀. Àwọn kan kò ní alábàárò. Àwọn kan ń ní ìdààmú ọkàn nítorí pé ọjọ́ ogbó kò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe tó bí wọ́n ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Kódà, àwọn tó ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n máa ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lè ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nígbà mìíràn. Gbé ọ̀rọ̀ John yẹ̀ wò.b Ó ti lé ní ogójì ọdún tó ti jẹ́ olóòótọ́ olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run, kódà iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún lọ́nà àkànṣe ló fi ọgbọ̀n ọdún tó kẹ́yìn lára àwọn ọdún náà ṣe. Nísinsìnyí tí John ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún, ó sọ pé àwọn ìgbà mìíràn wà tóun máa ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. Ó ní: “Mo sábà máa ń ronú padà sẹ́yìn, tí mo si máa ń rántí àwọn àṣìṣe tí mo ti ṣe, àwọn àṣìṣe náà pọ̀ gan-an. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú pé ó yẹ kí n ṣe dáadáa jùyẹn lọ.”
Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè rí ìtùnú tí wọ́n bá ń rántí pé bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni pípé tó, ó mọ̀ pé aláìpé ni wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ àwọn àṣìṣe wa, síbẹ̀ Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sáàmù 130:3) Bẹ́ẹ̀ ni o, kì í ṣe àwọn àṣìṣe wa ni Jèhófà ń ṣọ́, ohun tó wà lọ́kàn wa ló máa ń wò. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
Dáfídì Ọba tóun alára jẹ́ aláìpé tó sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣìṣe ni Ọlọ́run mí sí láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 139:1-3 sílẹ̀, èyí tó kà pé: “Jèhófà, ìwọ ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, ìwọ sì mọ̀ mí. Ìwọ alára ti wá mọ jíjókòó mi àti dídìde mi. Ìwọ ti gbé ìrònú mi yẹ̀ wò láti ibi jíjìnnàréré. Ìrìn àjò mi àti ìnàtàntàn mi lórí ìdùbúlẹ̀ ni ìwọ ti díwọ̀n, ìwọ sì ti wá mọ gbogbo ọ̀nà mi dunjú.” Ohun tí ọ̀rọ̀ náà “díwọ̀n” tó lò níbí yìí túmọ̀ sí lólówuuru ni “sísẹ́ nǹkan,” bí ìgbà tí àgbẹ̀ kan bá fẹ́ èèpo ọkà dà nù kó lè ku kìkì hóró ọkà nìkan. Ọlọ́run mí sí Dáfídì láti mú un dáni lójú pé Jèhófà lè gbójú fo àwọn àṣìṣe wa kó sì máa rántí kìkì àwọn iṣẹ́ rere wa.
Bàbá wa ọ̀run aláàánú ń rántí àwọn iṣẹ́ rere wa, ó sì mọyì wọn níwọ̀n ìgbà tá a bá ti ń jẹ́ olóòótọ́ sí i. Kódà, Bíbélì sọ pé yóò ka ara rẹ̀ sí aláìṣòdodo tó bá gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ tá a ní sí orúkọ rẹ̀.—Hébérù 6:10.
“Àwọn Ohun Àtijọ́ Ti Kọjá Lọ”
Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run kò dá ìṣòro ọjọ́ ogbó mọ́ aráyé ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ìgbà táwọn òbí wa àkọ́kọ́, ìyẹn ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá wọn ni àìlera tí ọjọ́ ogbó ń fà wá di ara ohun tọ́mọ aráyé ń bá yí. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19; Róòmù 5:12) Èyí kò ní máa rí bẹ́ẹ̀ lọ títí láé.
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lókè yìí, ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan búburú téèyàn ń fojú winá rẹ̀ lóde òní, títí kan ìwà ìkà táwọn kan máa ń hù sáwọn arúgbó, jẹ́ ara ẹ̀rí tó fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò nǹkan ìsinsìnyí la wà. (2 Tímótì 3:1) Ọlọ́run ti pinnu láti mú àwọn ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ kúrò, títí kan àwọn àìlera tí ọjọ́ ogbó ń fà àti ikú. Bíbélì sọ pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.
Nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run, gbogbo ó-ń-ta-mí, ó-ń-ro-mí tí ọjọ́ ogbó máa ń fà ni yóò di ohun àtijọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà ìkà táwọn èèyàn máa ń hù sáwọn arúgbó yóò kásẹ̀ nílẹ̀ pẹ̀lú. (Míkà 4:4) Kódà àwọn tó ti kú àmọ́ tí Ọlọ́run ń rántí wọn yóò padà wà láàyè, káwọn náà lè láǹfààní àtigbé inú Párádísè orí ilẹ̀ ayé títí láé. (Jòhánù 5:28, 29) Ní àkókò yẹn, yóò wá hàn gbangba ju ti ìgbàkígbà rí lọ pé Jèhófà Ọlọ́run bìkítà fáwọn arúgbó, ó tún bìkítà fún gbogbo àwọn tó ń ṣègbọràn sí i pẹ̀lú.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lóòótọ́, àwọn opó kan wà tí wọn kì í ṣe àgbàlagbà. Ó hàn kedere pé Ọlọ́run tún ń bójú tó àwọn opó tí wọn ò tíì dàgbà lọ́jọ́ orí pẹ̀lú, àpẹẹrẹ èyí wà nínú ìwé Léfítíkù 22:13.
b Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gan-an nìyí.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
Ohun Tí Ìfẹ́ Lè Múni Ṣe
Láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn alàgbà ìjọ máa ń mú ipò iwájú nínú bíbójú tó àwọn arúgbó. Wọn ò fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù yẹn ṣeré rárá, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín.” (1 Pétérù 5:2) Bíbójú tó àwọn arúgbó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ jẹ́ ara ṣíṣe àbójútó agbo Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ṣe èyí?
Ó gba sùúrù gan-an, ó sì tún lè gba kéèyàn máa lọ sọ́dọ̀ arúgbó kan déédéé, kó máa bá a fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀, kéèyàn tó lè mọ gbogbo ohun tí arúgbó náà nílò. Ó ṣeé ṣe kí irú arúgbó bẹ́ẹ̀ fẹ́ kẹ́nì kan bá òun ra nǹkan lọ́jà, ó lè nílò ẹni tó máa bá òun tún ilé ṣe tó sì tún máa bá òun fọṣọ, ó lè máa wá ẹni táá máa fi mọ́tò gbé òun lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, ẹni táá máa ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sóun létí, àti ẹni táá máa bá òun ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn. Níbikíbi tó bá ti ṣeé ṣe, a gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ètò tó gbéṣẹ́ tó sì ṣeé gbára lé, ká sì rí i pé à ń tẹ̀ lé ètò náà.c
Àmọ́, tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin àgbàlagbà kan nínú ìjọ nílò ìrànlọ́wọ́ pàjáwìrì ńkọ́, bíi kó nílò owó kan? Lákọ̀ọ́kọ́, á dára ká mọ̀ bóyá ó láwọn ọmọ tàbí àwọn ìbátan mìíràn tó lè ṣèrànwọ́. Èyí á sì wà níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú ìwé 1 Tímótì 5:4, tó sọ pé: “Bí opó èyíkéyìí bá ní àwọn ọmọ tàbí àwọn ọmọ-ọmọ, kí àwọn wọ̀nyí kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe ìwà hù nínú agbo ilé tiwọn, kí wọ́n sì máa san àsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà, nítorí tí èyí ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run.”
Ó lè jẹ́ pé arúgbó náà nílò ìrànlọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá òun lẹ́tọ̀ọ́ sí ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí tí ìjọba ń ṣe fún àwọn àgbàlagbà. Ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú ìjọ lè ṣèrànwọ́. Bí kò bá sí ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí tó lè rí gbà lọ́dọ̀ ìjọba, àwọn alàgbà lè pinnu bí irú arúgbó bẹ́ẹ̀ bá yẹ lẹ́ni tí ìjọ lè ràn lọ́wọ́. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ipò kan làwọn ìjọ ọ̀rúndún kìíní, nítorí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ kan náà pé: “Kí a fi orúkọ opó kan sínú ìwé àkọsílẹ̀, ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò dín ní ọgọ́ta ọdún, tí ó jẹ́ aya ọkọ kan, tí ó ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí i fún àwọn iṣẹ́ àtàtà, bí ó bá tọ́ àwọn ọmọ, bí ó bá ṣe àwọn àjèjì lálejò, bí ó bá wẹ ẹsẹ̀ àwọn ẹni mímọ́, bí ó bá mú ìtura bá àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú, bí ó bá fi taápọn-taápọn tẹ̀ lé gbogbo iṣẹ́ rere.”—1 Tímótì 5:9, 10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
c Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Kíkájú Awọn Àìní Awọn Àgbàlagbà wa—Ìpènijà Kristian Kan,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti July 15, 1988.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Dọ́káàsì bójú tó àwọn opó tí wọ́n jẹ́ aláìní.—Ìṣe 9:36-39