Ẹ Yin Ọba Ayérayé!
“Jehofa ni Ọba títí àkókò àìlópin, àní títí láé.”—ORIN DAFIDI 10:16, NW.
1. Àwọn ìbéèrè wo ni ó dìde nípa ayérayé?
AYÉRAYÉ—kí ni ìwọ yóò sọ pé ó jẹ́? O ha rò pé ìgbà lè máa bá a lọ títí láé bí? Ó dára, kò sí iyè méjì pé àkókò lọ láìlópin bí a bá kà á lọ sẹ́yìn. Nítorí náà, èé ṣe tí kò fi lè jẹ́ aláìlópin bí a bá ṣírò rẹ̀ lọ sí ọjọ́ iwájú? Ní tòótọ́, Bibeli New World Translation tọ́ka sí Ọlọrun bí ẹni tí a ń yìn “láti àkókò àìlópin, àní títí di àkókò àìlópin.” (Orin Dafidi 41:13, NW) Kí ni ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí? A lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀ bí a bá tọ́ka sí kókó ẹ̀kọ́ kan tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀—gbalasa òfuurufú.
2, 3. (a) Àwọn ìbéèrè wo nípa gbalasa òfuurufú, ni ó ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ayérayé? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a fẹ́ láti jọ́sìn Ọba ayérayé?
2 Báwo ni gbalasa òfuurufú ṣe gbòòrò tó? Ó ha lópin bí? Títí di 400 ọdún sẹ́yìn, a rò pé ilẹ̀ ayé wa ni àárín gbùngbùn àgbáyé. Nígbà tí ó yá, Galileo ṣe awò awọ̀nàjíjìn, tí ó mú kí ó ṣeé ṣe láti túbọ̀ rí àwọn ọ̀run lọ́nà tí ó kàmàmà. Wàyí o, Galileo lè rí àwọn ìràwọ̀ púpọ̀ sí i, ó sì ṣeé ṣe fún un láti fi hàn pé ilẹ̀ ayé àti àwọn pílánẹ́ẹ̀tì míràn ń yí oòrùn po. Ìṣùpọ̀ Ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà kò ní ìrísí wàrà mọ́. Ó wá di ìṣùpọ̀ àwọn ìràwọ̀, tí iye rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù. A kò lè ka ọ̀pọ̀ ìràwọ̀ gidi náà, kódà ní gbogbo àkókò ìgbésí ayé ẹnì kan. Lẹ́yìn náà, àwọn onímọ̀ nípa òfuurufú tẹ̀ síwájú láti ṣàwárí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìṣùpọ̀ ìràwọ̀. Èyí tẹ́ lọ rẹrẹ wọnú gbalasa òfuurufú, ní ìwọ̀n tí awò awọ̀nàjíjìn tí ó lágbára jù lọ lè rí i dé. Ó jọ pé gbalasa òfuurufú kò ní òpin. Bẹ́ẹ̀ náà gan-an ni ayérayé rí—kò ní òpin.
3 Èrò nípa ayérayé dà bí ohun tí ó ré kọjá òye ọpọlọ tí ẹ̀dá ènìyàn ní, èyí tí ó ní ibi tí agbára rẹ̀ mọ. Bí ó ti wù kí ó rí, Ẹnì Kan ń bẹ tí ó lóye rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ó lè ka iye bílíọ̀nù lọ́nà mílíọ̀nù àwọn ìràwọ̀ nínú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ wọn, kí ó sì sọ wọ́n lórúkọ pàápàá! Ẹni yìí sọ pé: “Gbé ojú yín sókè síbi gíga, kí ẹ sì wò, ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí, tí ń mú ogun wọn jáde wá ní iye: ó ń pe gbogbo wọn ní orúkọ nípa títóbi ipá rẹ̀, nítorí pé òún le ní ipá; kò sí ọ̀kan tí ó kù. Ìwọ kò tí ì mọ̀? Ìwọ kò tí ì gbọ́ pé, Ọlọrun ayérayé, Oluwa, Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ayé, kì í ṣàárẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àárẹ̀ kì í mú un? kò sí àwárí òye rẹ̀.” (Isaiah 40:26, 28) Ọlọrun àgbàyanu ni èyí mà jẹ́ o! Dájúdájú, òun ni Ọlọrun tí ó yẹ kí a fẹ́ láti jọ́sìn!
“Ọba Títí Àkókò Àìlópin”
4. (a) Báwo ni Dafidi ṣe sọ ọ̀rọ̀ ìmọrírì rẹ̀ jáde nípa Ọba ayérayé? (b) Kí ni ọ̀kan nínú àwọn ògbóǹtarìgì onímọ̀ sáyẹ́ǹsì parí èrò sí nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ àgbáyé?
4 Ní Orin Dafidi 10:16 (NW), Dafidi sọ nípa Ọlọrun Ẹlẹ́dàá pé: “Jehofa ni Ọba títí àkókò àìlópin, àní títí láé.” Ní Orin Dafidi 29:10 (NW) pẹ̀lú, ó tún un sọ pé: “Jehofa jókòó gẹ́gẹ́ bí Ọba títí àkókò àìlópin.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jehofa ni Ọba ayérayé! Síwájú sí i, Dafidi jẹ́rìí sí i pé, Ọba tí a gbé ga yìí ni Olùronúpète àti Olùṣẹ̀dá gbogbo ohun tí a rí ní gbalasa òfuurufú, ní sísọ ní Orin Dafidi 19:1 pé: “Àwọn ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ogo Ọlọrun; àti òfuurufú ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ hàn.” Ní nǹkan bí 2,700 ọdún lẹ́yìn náà, ìlú-mọ̀ọ́ká onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà, Alàgbà Isaac Newton, fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú Dafidi, ní kíkọ̀wé pé: “Ètò ìgbékalẹ̀ tí ó lẹ́wà jù lọ ti àwọn oòrùn, pílánẹ́ẹ̀tì, àti ìràwọ̀ onírù lè jẹ yọ kìkì láti inú ète àti ipò ọba aláṣẹ ẹnì kan, tí ó jẹ́ olóye, tí ó sì tóbi lọ́lá.”
5. Kí ni Isaiah àti Paulu kọ́ nípa Orísun ọgbọ́n?
5 Ẹ wo bí ó ti yẹ kí ó mú wa ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó, láti mọ̀ pé Jehofa Oluwa Ọba Aláṣẹ, ẹni tí “ọ̀run àti ọ̀run” pàápàá “kò lè gbà,” wà láàyè títí ayérayé! (1 Ọba 8:27) Jehofa, tí a ṣàpèjúwe ní Isaiah 45:18 gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, . . . tí ó mọ ayé, tí ó sì ṣe é,” ni Orísun ọgbọ́n tí ó ga fíìfíì ju èyí tí ọpọlọ ẹ̀dá ènìyàn tí ó lè kú lè lóye lọ. Gẹ́gẹ́ bí a ti tẹnu mọ́ ọn ní 1 Korinti 1:19, Jehofa wí pé: “Emi yoo mú kí ọgbọ́n awọn ọlọ́gbọ́n ṣègbé, ati làákàyè awọn amòye ni emi yoo rọ́ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́kan.” Aposteli Paulu fi kún èyí ní ẹsẹ 20 pé: “Níbo ni ọlọ́gbọ́n ènìyàn naa wà? Níbo ni akọ̀wé òfin naa wà? Níbo ni olùjiyàn ọ̀rọ̀ ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii wà? Ọlọrun kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé di òmùgọ̀?” Bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí Paulu ti ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ní orí 3, ẹsẹ 19, pé, “ọgbọ́n ayé yii jẹ́ ìwà òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun.”
6. Kí ni Oniwasu 3:11 (NW) fi hàn nípa “àkókò àìlópin”?
6 Àpapọ̀ àwọn ohun tí ń bẹ lókè ọ̀run wà lára ìṣẹ̀dá tí Ọba Solomoni tọ́ka sí pé: “[Ọlọrun] ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àkókò tirẹ̀. Àní ó ti fi àkókò àìlópin sí wọn ní ọkàn-àyà, kí aráyé má baà rí ìdí iṣẹ́ náà tí Ọlọrun tòótọ́ ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.” (Oniwasu 3:11, NW) Lóòótọ́ ni pé, a gbìn ín sínú ọkàn-àyà ènìyàn láti gbìyànjú láti ṣàwárí ìtumọ̀ “àkókò àìlópin,” ìyẹn ni, ayérayé. Ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ ha lè tẹ irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ láé bí?
Ìfojúsọ́nà Ìwàláàyè Àgbàyanu Kan
7, 8. (a) Ìfojúsọ́nà fún ìwàláàyè àgbàyanu wo ni ó wà níwájú fún aráyé, báwo sì ni ọwọ́ ṣe lè tẹ̀ ẹ́? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a láyọ̀ pé ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yóò máa bá a lọ títí ayérayé?
7 Nínú àdúrà sí Jehofa, Jesu Kristi wí pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ iwọ, Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo naa sínú, àti ti ẹni naa tí iwọ rán jáde, Jesu Kristi.” (Johannu 17:3) Báwo ni a ṣe lè jèrè irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀? A ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli Mímọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè jèrè ìmọ̀ pípéye nípa àwọn ète kíkọyọyọ ti Ọlọrun, títí kan ìpèsè tí ó ṣe nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀ fún ìyè àìnípẹ̀kun nínú paradise kan lórí ilẹ̀ ayé. Èyí yóò jẹ́ “ìyè tòótọ́ gidi” tí a tọ́ka sí ní 1 Timoteu 6:19. Yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Efesu 3:11 ṣàpèjúwe bí “ète ayérayé tí [Ọlọrun] gbé kalẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹlu Kristi, Jesu Oluwa wa.”
8 Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá àti ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu. Yóò ti pẹ́ tó tí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yìí yóò fi máa bá a nìṣó? Yóò máa bá a nìṣó títí ayérayé, bí aráyé ti ń bá a lọ láti máa gba ìtọ́ni nínú ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ọgbọ́n Jehofa kò ní òpin. Ní mímọ èyí, aposteli Paulu polongo pé: “Óò ìjìnlẹ̀ awọn ọrọ̀ ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ Ọlọrun! Awọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó awọn ọ̀nà rẹ̀ sì rékọjá àwákàn!” (Romu 11:33) Ní tòótọ́, ẹ wo bí ó ti ṣe kòńgẹ́ tó, pé 1 Timoteu 1:17 pe Jehofa ní “Ọba ayérayé”!
Ọgbọ́n Ìṣẹ̀dá Tí Jehofa Ní
9, 10. (a) Àwọn iṣẹ́ kíkọyọyọ wo ni Jehofa ṣàṣeparí ní mímúra ilẹ̀ ayé sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún aráyé? (b) Báwo ni ọgbọ́n Jehofa tí ó ga lọ́la ṣe yọ lára àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀? (Wo àpótí.)
9 Ronú nípa ogún-ìní àgbàyanu tí Ọba ayérayé náà ti pèsè fún àwa ẹ̀dá ènìyàn. Orin Dafidi 115:16 sọ fún wa pé: “Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Oluwa; ṣùgbọ́n ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” O kò ha rò pé ohun afúnniṣọ́ yíyani lẹ́nu ni èyí jẹ́ bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni! Ẹ sì wo bí a ṣe mọrírì òye ìrítẹ́lẹ̀ títayọ lọ́lá tí Ẹlẹ́dàá wa ní tó, ní ṣíṣètò ilẹ̀ ayé wa gẹ́gẹ́ bí ilé wa!—Orin Dafidi 107:8.
10 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu wáyé lórí ilẹ̀ ayé nígbà “àwọn ọjọ́” mẹ́fà ti ìṣẹ̀dá, ti inú Genesisi orí 1, tí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan sì nasẹ̀ dé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí Ọlọrun ṣe yóò fi pápá títẹ́ rẹrẹ aláwọ̀ tútù yọ̀yọ̀, ẹgàn dúdú kìjikìji àti àwọn òdòdó tí ó jojú ní gbèsè kún ilẹ̀ ayé. Yóò kún fún ògìdìgbó ẹ̀dá òkun tí wọ́n ṣàrà ọ̀tọ̀, agbo àwọn arẹwà ẹyẹ abìyẹ́, àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ẹran agbéléjẹ̀ àti ẹranko ẹhànnà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ń mú irú ọmọ jáde “ní irú tirẹ̀,” kárí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn àpèjúwe ìṣẹ̀dá ọkùnrin àti obìnrin, Genesisi 1:31 ṣàlàyé pé: “Ọlọrun sì rí ohun gbogbo tí ó dá, sì kíyè sí i, dáradára ni.” Ẹ wo irú àyíká gbígbádùn mọ́ni tí èyí jẹ́ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ wọ̀nyẹn! A kò ha wòye mọ ọgbọ́n, ìrítẹ́lẹ̀, àti ìbìkítà Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá wọ̀nyí bí?—Isaiah 45:11, 12, 18.
11. Báwo ni Solomoni ṣe pòkìkí ọgbọ́n ìṣẹ̀dá tí Jehofa ní?
11 Ẹnì kan tí ó ṣe kàyéfì nípa ọgbọ́n Ọba ayérayé náà ni Solomoni. Léraléra ni ó pe àfiyèsí sí ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá náà. (Owe 1:1, 2; 2:1, 6; 3:13-18) Solomoni mú un dá wa lójú pé, “ayé dúró títí láé.” Ó mọrírì ọ̀pọ̀ ohun àràmàǹdà ti ìṣẹ̀dá, títí kan ipa tí àwọsánmà òjò ń kó nínú títu ilẹ̀ ayé lára. Nípa báyìí, ó kọ̀wé pé: “Odò gbogbo ní ń ṣàn sínú òkun; ṣùgbọ́n òkun kò kún, níbi tí àwọn odò ti ń ṣàn wá, níbẹ̀ ni wọ́n sì tún padà lọ.” (Oniwasu 1:4, 7) Bí ó ṣe máa ń rí nìyẹn lẹ́yìn tí òjó bá rọ̀, tí àwọn odò sì ti tu ilẹ̀ ayé lára, omi wọn ń yípo padà láti inú agbami òkun sí àwọsánmà. Báwo ni ilẹ̀ ayé yìí ì bá ti rí, ibo ni àwa ì bá sì wà, láìsí ìsọdimímọ́ gaara àti àyípopadà omi báyìí?
12, 13. Báwo ni a ṣe lè fi ìmọrírì hàn fún ìṣẹ̀dá Ọlọrun?
12 Ó yẹ kí a fi iṣẹ́ ti ìmọrírì wa fún ìwàdéédéé nínú ìṣẹ̀dá lẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí Ọba Solomoni ṣe sọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àsọparí Oniwasu pé: “Òpin gbogbo ọ̀rọ̀ náà tí a gbọ́ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọrun kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́: nítorí èyí ni fún gbogbo ènìyàn. Nítorí pé Ọlọrun yóò mú olúkúlùkù iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́, àti olúkúlùkù ohun ìkọ̀kọ̀, ì báà ṣe rere, ì báà ṣe búburú.” (Oniwasu 12:13, 14) Ó yẹ kí a bẹ̀rù ṣíṣe ohunkóhun tí ó lè ba Ọlọrun nínú jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a gbìyànjú láti ṣègbọràn sí i pẹ̀lú ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.
13 Dájúdájú, ó yẹ kí a fẹ́ láti yin Ọba ayérayé fún àwọn iṣẹ́ ológo rẹ̀ ti ìṣẹ̀dá! Orin Dafidi 104:24 polongo pé: “Oluwa, iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó! nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn: ayé kún fún ẹ̀dá rẹ.” Pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìgbọràn sí ẹsẹ tí ó kẹ́yìn nínú psalmu yìí nípa sísọ fún ara wa àti fún àwọn ẹlòmíràn pé: “Fi ìbùkún fún Oluwa, ìwọ ọkàn mi. Ẹ fi ìyìn fún Oluwa.”
Àgbà Iṣẹ́ Ìṣẹ̀dá Lórí Ilẹ̀ Ayé
14. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ẹ̀dá ènìyàn tí Ọlọrun dá fi ga lọ́lá fíìfíì ju àwọn ẹranko lọ?
14 Àgbà iṣẹ́ ni gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá Jehofa. Ṣùgbọ́n èyí tí ó pẹtẹrí jù lọ nínú ẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé ni àwa—ìran aráyé. A dá Adamu, lẹ́yìn náà Efa, gẹ́gẹ́ bí àṣekágbá ìṣẹ̀dá tí Jehofa ṣe ní ọjọ́ kẹfà—ìṣẹ̀dá kan tí ó ga lọ́lá fíìfíì ju àwọn ẹja, ẹyẹ, àti ẹranko lọ! Bí púpọ̀ lára àwọn wọ̀nyí tilẹ̀ gbọ́n lọ́nà ìtẹ̀sí ìwà àdánidá, ènìyàn ni a fi agbára ìrònú jíǹkí, ẹ̀rí ọkàn tí ó lè fi ìyàtọ̀ sí ohun tí ó tọ́, àti èyí tí kò tọ́, àti agbára láti wéwèé fún ọjọ́ ọ̀la, àti ìfẹ́ ọkàn àbímọ́ni láti jọ́sìn. Báwo ni gbogbo èyí ṣe wáyé? Dípò wíwá láti inú ẹranko aláìnírònú, a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọrun. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ènìyàn nìkan ni ó lè ṣàgbéyọ àwọn ànímọ́ Ẹlẹ́dàá wa, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí “OLUWA, OLUWA, Ọlọrun aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, onípamọ́ra, àti ẹni tí ó pọ̀ ní oore àti òtítọ́.”—Eksodu 34:6.
15. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ kókìkí Jehofa?
15 Ẹ jẹ́ kí a yin Jehofa fún àgbàyanu iṣẹ́ ọnà ara wa, kí a sì fi ọpẹ́ fún un. Ìṣàn ẹ̀jẹ̀ wa, tí ó ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè, ń yípo ara ní gbogbo 60 ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí Deuteronomi 12:23 ṣe sọ pé, “ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí”—ìwàláàyè wa—tí ó ṣeyebíye lójú Ọlọrun. Egungun líle koránkorán, àwọn iṣan tí ó ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, àti ètò ìgbékalẹ̀ iṣan tí ń múni nímọ̀lára, ni a fi ọpọlọ kan tí ó ga lọ́lá fíìfíì ju ti ẹranko èyíkéyìí lọ kádìí rẹ̀, tí ó sì ní agbára tí inú kọ̀m̀pútà kan tí ó tóbi tó ilé àwòṣífìlà kan kò lè gbà. Èyí kò ha mú kí o ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bí? Ó yẹ kí ó mú kí o ṣe bẹ́ẹ̀. (Owe 22:4) Ronú nípa èyí pẹ̀lú: Ẹ̀dọ̀fóró wa, fùkùfúkù, ahọ́n, eyín, àti ẹnu lè ṣiṣẹ́ pọ̀ láti pèsè ọ̀rọ̀ ẹ̀dá ènìyàn ní èyíkéyìí nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún èdè. Dafidi kọrin atunilára yíyẹ wẹ́kú sí Jehofa, ní sísọ pé: “Èmi óò yìn ọ́; nítorí tẹ̀rùtẹ̀rù àti tìyanutìyanu ni a dá mi: ìyanu ni iṣẹ́ rẹ; èyíinì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.” (Orin Dafidi 139:14) Ẹ jẹ́ kí a dara pọ̀ mọ́ Dafidi ní fífi ọpẹ́ yin Jehofa, Olùronúpète wa àti Ọlọrun wa àgbàyanu!
16. Orin atunilára wo ni gbajúmọ̀ olórin kan kọ láti fi yin Jehofa, ìkésíni tí ń fi dandan rọni wo sì ni a lè dáhùn padà sí?
16 Ègbè orin ìwé orin ọ̀rúndún kejìdínlógún kan láti ọwọ́ Joseph Haydn sọ ní fífi ìyìn fún Jehofa pé: “Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin iṣẹ́ àràmàǹdà Rẹ̀! Ẹ kọrin ọlá Rẹ̀, ẹ kọrin ògo Rẹ̀, ẹ fi ìbùkún fún Orúkọ Rẹ̀ kí ẹ sì gbé e ga! Ìyìn Jehofa wà títí láéláé, Àmín, Àmín!” Àwọn gbólóhùn onímìísí tí a sọ léraléra lọ́pọ̀ ìgbà nínú Orin Dafidi tilẹ̀ tún dùn ju èyí lọ, irú bí ìkésíni tí a nawọ́ rẹ̀ síni nígbà mẹ́rin nínú Orin Dafidi kẹtàdínláàádọ́fà (NW) pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ènìyàn fi ìyìn fún Jehofa fún inúrere-ìfẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn iṣẹ́ àràmàǹdà rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn.” O ha ń dara pọ̀ nínú ìyìn yẹn bí? Ó yẹ bẹ́ẹ̀, nítorí pé, gbogbo ohun rírẹwà ní tòótọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Jehofa, Ọba ayérayé.
Àwọn Iṣẹ́ Títóbi Sí I
17. Báwo ni ‘orin Mose àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn’ ṣe gbé Jehofa ga?
17 Láàárín ẹgbàáta ọdún tí ó ti kọjá, Ọba ayérayé ti bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ títóbi sí i. Nínú ìwé tí ó kẹ́yìn Bibeli, ní Ìṣípayá 15:3, 4, a kà nípa àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run, tí wọ́n ti yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí àwọn ẹ̀mí èṣù abániṣọ̀tá pé: “Wọ́n sì ń kọ orin Mose ẹrú Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa, wí pé: ‘Títóbi ati àgbàyanu ni awọn iṣẹ́ rẹ, Jehofa Ọlọrun, Olódùmarè. Òdodo ati òótọ́ ni awọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kì yoo bẹ̀rù rẹ níti gidi, Jehofa, tí kì yoo sì yin orúkọ rẹ lógo, nitori pé iwọ nìkan ni adúróṣinṣin? Nitori gbogbo awọn orílẹ̀-èdè yoo wá wọn yoo sì jọ́sìn níwájú rẹ, nitori a ti fi awọn àṣẹ àgbékalẹ̀ rẹ tí ó jẹ́ òdodo hàn kedere.’” Èé ṣe tí a fi pe èyí ní ‘orin Mose àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà’? Ẹ jẹ́ kí a wò ó.
18. Iṣẹ́ títóbi wo ni orin inú Eksodu orí 15 ránni létí rẹ̀?
18 Ní nǹkan bí 3,500 ọdún sẹ́yìn, nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun alágbára ńlá ti Farao ṣègbé sínú Òkun Pupa, àwọn ọmọ Israeli fi ọpẹ́ yin Jehofa nípa kíkọrin. A kà ní Eksodu 15:1, 18 pé: “Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israeli kọ orin yìí sí OLUWA wọ́n sì wí pé, Èmi óò kọrin sí OLUWA, nítorí tí ó pọ̀ ní ògo: àti ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin òun ni ó bì ṣubú sínú òkun. OLUWA yóò jọba láé àti láéláé.” Àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ òdodo ti Ọba ayérayé yìí hàn kedere nínú ṣíṣe ìdájọ́ àwọn ọ̀tá tí wọ́n pe ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ níjà àti pípa wọn.
19, 20. (a) Èé ṣe tí Jehofa fi gbé orílẹ̀-èdè Israeli kalẹ̀? (b) Báwo ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti àwọn mìíràn ṣe dáhùn ìpènijà Satani?
19 Èé ṣe tí èyí fi pọn dandan? Nínú ọgbà Edeni ni Ejò ọlọ́gbọ́n àyínìke náà ti sún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀. Èyí yọrí sí àìpé tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ tí a tàtaré rẹ̀ sórí gbogbo aráyé. Ṣùgbọ́n, kíámọ́sá ni Ọba ayérayé náà gbé ìgbésẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀, tí yóò jálẹ̀ sí gbígbá gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ kúrò ní pápá àkóso ilẹ̀ ayé, tí yóò sì mú ipò paradise padà bọ̀ sípò. Ọba ayérayé náà gbé orílẹ̀-èdè Israeli kalẹ̀, ó sì pèsè Òfin rẹ̀ láti ṣàpẹẹrẹ bí òun yóò ṣe ṣàṣeparí èyí.—Galatia 3:24.
20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nígbà tí ó yá, Israeli fúnra rẹ̀ rì sínú àìṣòótọ́, ipò bíbani nínú jẹ́ yìí sì dé òtéńté rẹ̀ nígbà tí àwọn aṣáájú rẹ̀ fi Ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọrun lé àwọn ará Romu lọ́wọ́, láti dá a lóró lọ́nà rírorò, kí wọ́n sì pa á. (Ìṣe 10:39; Filippi 2:8) Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́nà títayọ, ìwà títọ́ Jesu títí dé ojú ikú gẹ́gẹ́ bí “Ọ̀dọ́ Àgùtàn Ọlọrun” fún ìrúbọ, dáhùn ìpèníjà tí Elénìní Ọlọrun láti ìjímìjí, Satani, gbé dìde—pé kò sí ènìyàn kankan lórí ilẹ̀ ayé tí yóò lè di ìṣòtítọ́ sí Ọlọrun mú lábẹ́ àdánwò líle koko. (Johannu 1:29, 36; Jobu 1:9-12; 27:5) Bí wọ́n tilẹ̀ jogún àìpé láti ọ̀dọ̀ Adamu, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn míràn tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọrun ti tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jesu nípa pípa ìwà títọ́ mọ́ lójú ìgbéjàkò tí Satani ń ṣe.—1 Peteru 1:18, 19; 2:19, 21.
21. Ní ìbámu pẹ̀lú Ìṣe 17:29-31, kí ni a óò jíròrò tẹ̀ lé e?
21 Wàyí o, ọjọ́ náà ti dé fún Jehofa láti san èrè fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, kí ó sì ṣe ìdájọ́ gbogbo ọ̀tá òtítọ́ àti òdodo. (Ìṣe 17:29-31) Báwo ni èyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wa tí ó tẹ̀ lé e yóò ṣàlàyé.
Àpótí Àtúnyẹ̀wò
◻ Èé ṣe tí Jehofa fi lẹ́tọ̀ọ́ sí pípè é ní “Ọba ayérayé”?
◻ Báwo ni a ṣe fi ọgbọ́n Jehofa hàn nínú àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni ènìyàn fi jẹ́ àgbà iṣẹ́ ìṣẹ̀dá?
◻ Àwọn iṣẹ́ wo ni ó fa ‘orin Mose àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn’?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Ọgbọ́n Títayọ Lọ́lá Tí Jehofa Ní
Ọ̀nà púpọ̀ ni a gbà fi ọgbọ́n Ọba ayérayé náà hàn nínú àwọn ohun tí ó ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ Aguri pé: “Gbogbo ọ̀rọ̀ Oluwa ni funfun: òun ni asà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.” (Owe 30:5) Lẹ́yìn náà, Aguri tọ́ka sí ọ̀pọ̀ àwọn ìṣẹ̀dá abẹ̀mí tí Ọlọrun dá, ńlá àti kékeré. Fún àpẹẹrẹ, ní ẹsẹ 24 sí 28, ó ṣàpèjúwe ‘àwọn ohun mẹ́rin tí ó kéré jù lórí ilẹ̀, síbẹ̀ tí wọ́n gbọ́n [lọ́nà ìtẹ̀sí ìwà àdánidá, NW].’ Àwọn wọ̀nyí ni èèrà, ehoro, eṣú, àti ọmọọ́lé.
Wọ́n “gbọ́n [lọ́nà ìtẹ̀sí ìwà àdánidá]”—bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀nà tí a gbà dá àwọn ẹranko nìyẹn. Wọn kì í ronú lórí nǹkan bí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ti ń ṣe, ṣùgbọ́n, wọ́n gbára lé ọgbọ́n tí a dá mọ́ wọn. Èyí ha ti ṣe ọ ní kàyéfì rí bí? Ẹ wo bí wọ́n ti jẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó wà létòlétò tó! Fún àpẹẹrẹ, a ṣètò àwọn èèrùn sí ẹgbẹ́ àwùjọ olùgbé, tí ó ní yèyé èèrùn, àwọn òṣìṣẹ́, àti àwọn akọ nínú. Nínú àwọn irú kan, àwọn èèrùn òṣìṣẹ́ tilẹ̀ máa ń kó àwọn kòkòrò tí ń mu omi inú irúgbìn jọ sínú àkámọ́ tí wọ́n ti kọ́. Níbẹ̀ ni wọ́n yóò ti máa fa omi ara àwọn kòkòrò náà mú, nígbà tí àwọn èèrùn ọmọ ogun yóò máa lé àwọn ọ̀tá tí ó bá fẹ́ gbógun tì wọ́n jù nù. A fúnni ní ọ̀rọ̀ ìyànjú náà ní Owe 6:6 pé: “Tọ èèrùn lọ, ìwọ ọ̀lẹ: kíyè sí ìṣe rẹ̀, kí ìwọ kí ó sì gbọ́n.” Kò ha yẹ kí irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ sún àwa ẹ̀dá ènìyàn láti ‘ṣe púpọ̀ rẹpẹtẹ nínú iṣẹ́ Oluwa’ bí?—1 Korinti 15:58.
Ènìyàn ti ṣe àwọn ọkọ̀ òfuurufú ràgàjì-ragaji. Ṣùgbọ́n ẹ wo bí àwọn ẹyẹ ṣe lè fò síwá sẹ́yìn tó, títí kan àwọn ẹyẹ akùnyunmu, tí ìwọ̀n wọn kò tó 30 gíráàmù! Ọkọ̀ òfuurufú Boeing 747 gbọ́dọ̀ gbé 180,000 lítà epo rìn, agbo òṣìṣẹ́ tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ sì gbọ́dọ̀ máa darí rẹ̀, ó sì gbọ́dọ̀ lo ètò ìgbékalẹ̀ ìwakọ̀ òfuurufú dídíjú kan láti lè ré òkun kọjá. Síbẹ̀, ẹyẹ akùnyunmu rodo-ríndín kan gbára lé epo ọ̀rá tí ó wọn gíráàmù kan péré, láti fò kọjá láti Àríwá America, ré kọjá Ìyawọlẹ̀ Òkun ti Mexico, kí ó sì dé Gúúsù America. Kò sí ẹrù epo wíwọni lọ́rùn, kò sí ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú ìṣàwárí ọ̀nà òfuurufú, kò sí àwòrán ọ̀nà tàbí kọ̀m̀pútà dídíjú! Agbára yìí ha wá láti inú ọ̀nà èèṣì ẹfolúṣọ̀n bí? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀! Ẹyẹ rodo-ríndín yìí gbọ́n lọ́nà ti ìtẹ̀sí ìwà àdánidá, tí a ti lànà rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀, Jehofa Ọlọrun.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Onírúurú ìṣẹ̀dá tí “Ọba ayérayé” ṣe ń gbé ògo rẹ̀ ga
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Gẹ́gẹ́ bí Mose àti gbogbo Israeli ṣe ṣàjọyọ̀ bí Jehofa ṣe ṣẹ́gun ní Òkun Pupa, ayọ̀ ńláǹlà yóò wà lẹ́yìn Armageddoni