Iwalaaye—Ẹbun Kan Lati Ọdọ Ọlọrun
FUN wakati 24 lojumọ, ọkan-aya wa ń pọ́ ẹ̀jẹ̀ ṣiṣeyebiye jade yika ara wa. A sùn, awọn ẹ̀dọ̀fóró wa sì ń baa lọ lati wú ati lati súnkì. A jẹun, ounjẹ naa sì dà fúnraarẹ̀. Gbogbo eyi ń wáyé lojoojumọ, pẹlu isapa diẹ tabi eyi ti a kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Awọn ìṣiṣẹ́ jijinlẹ ti ó sì kún fun iyanu wọnyi, ti ó rọrun lati foju tẹ́ḿbẹ́lú, jẹ́ apakan ninu ẹbun ti a ń pè ni iwalaaye. Ni èrò itumọ kan ó jẹ́ ẹbun kan ti a lè pè ni agbayanu.
Gbé iṣiṣẹ́ eto ìlóyún ati ibimọ eniyan yẹwo. Bi o tilẹ jẹ pe ara sábà maa ń kọ iṣupọ sẹẹli ajeji, àpò-ọmọ ní àyàfi kan fun ẹyin kan ti a ti sọ di ọmọ. Dipo kíkọ ọlẹ̀ tí ń dagba naa gẹgẹ bi iṣupọ sẹẹli ajeji kan, yoo founjẹ bọ́ ọ yoo sì daabobo o titi di ìgbà ti ó bá ṣetan lati jade gẹgẹ bi ọmọ jòjòló kan. Laisi agbara àpò-ọmọ lati fún ilana kíkọ iṣupọ sẹẹli ajeji silẹ ni àyàfi pataki yii, ibimọ eniyan ki yoo ṣeeṣe.
Àní bi o tilẹ ri bẹẹ, iwalaaye fun ọmọ jòjòló kan ti a ṣẹṣẹ bí yoo kuru bi kìí bá ṣe ti idagbasoke ti ń wáyé ninu àpò-ọmọ nigba ti ọmọ-inu-oyun kan bá jẹ́ kìkì nǹkan bii oṣu mẹrin. Ni akoko yẹn ó bẹrẹ sii mu ìka rẹ̀, ní mimura awọn iṣu-ẹran ti yoo lè jẹ́ ki ó ṣeeṣe fun un lati mu ọmú ìyá rẹ̀ nigba ti o bá yá silẹ. Eyi sì wulẹ jẹ́ ọ̀kan lara ọpọlọpọ ọ̀ràn ìyè-ati-ikú ti a yanju tipẹ ṣaaju ìbí ọmọ jòjòló kan.
Nigba ti ọmọ-inu-oyun kan bá ṣì wà ninu àpò-ọmọ, ihò kan wà ni ara ogiri ọkan-aya rẹ̀. Ihò yii, bi o ti wu ki o ri, ń padé fúnraarẹ̀ nigba ìbí. Ni afikun, ìṣàn-ẹ̀jẹ̀ titobi ti o kọja lara awọn ẹ̀dọ̀fóró nigba ti ọmọ-inu-oyun naa wà ninu àpò-ọmọ a maa papó fúnraarẹ̀ nigba ìbí; ẹ̀jẹ̀ á wá lọ sinu awọn ẹ̀dọ̀fóró nisinsinyi, nibi ti ó ti lè gba afẹfẹ tútù bi ọmọ jòjòló naa ti bẹrẹ síí mí.
Gbogbo eyi wulẹ jẹ́ ibẹrẹ ni. Jalẹ igbesi-aye, ọ̀wọ́ eto igbekalẹ ti a ṣe ọnà rẹ̀ meremere (iru bii awọn eto igbekalẹ ti mímí, ìyípo-ẹ̀jẹ̀, iṣan-ìmọ̀lára, ati ti ìsun-inú-ara) yoo ṣe iṣẹ ti wọn yoo sì ṣe kòkáárí iṣẹ wọn pẹlu ìjáfáfá ti o daamu òye eniyan—gbogbo rẹ̀ fun mímú ẹmi gùn. Abajọ ti òǹkọ̀wé igbaani kan fi sọ ni itọka si Ọlọrun pe: “Emi ó yìn ọ; nitori tẹ̀rù-tẹ̀rù ati tiyanu-tiyanu ni a dá mi: iyanu ni iṣẹ rẹ: eyiini ni ọkàn mi sì mọ dajudaju.”—Orin Dafidi 139:14.
Ni kedere, òǹkọ̀wé awọn ọ̀rọ̀ didara wọnni kò gbagbọ pe iwalaaye wulẹ jẹ́ imujade aláìṣeélóye, ti èèṣì efoluṣọn tabi akọsẹba. Bi o bá jẹ́ pe bẹẹ ni ọ̀ràn rí ni, awa ki yoo ni aigbọdọmaṣe gidi tabi ẹrù-iṣẹ́ niti bi a ṣe gbọdọ lo igbesi-aye wa. Bi o ti wu ki o ri, ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ iwalaaye ni kedere fi iṣẹ́-ọnà hàn, iṣẹ́-ọnà kan sì beere fun oníṣẹ́-ọnà. Bibeli fi ilana yii lélẹ̀ pe: “Lati ọwọ́ eniyan kan ni a sá ti kọ́ olukuluku ilé; ṣugbọn ẹni ti o kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọrun.” (Heberu 3:4) Nitori naa ó ṣe pataki lati “mọ̀ pe Jehofa ni Ọlọrun. Oun ni o dá wa, kìí sìí ṣe awa funraawa.” (Orin Dafidi 100:3, NW) Bẹẹni, iwalaaye ju akọsẹba rirọrun lasan kan lọ; ó jẹ́ ẹbun kan lati ọdọ Ọlọrun funraarẹ.—Orin Dafidi 36:9.
Bi iyẹn ti jẹ́ bẹẹ, awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe wo ni a ní siha ọdọ Olufunni ni ìyè? Bawo ni oun ṣe ń reti pe ki a lo igbesi-aye wa? Iwọnyi ati awọn ibeere ti o tanmọ́ ọn ni a o gbeyẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti o kàn.