Ọlọ́run ‘Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-tìyanu’
“Lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.”—SÁÀMÙ 139:14.
1. Kí nìdí táwọn èèyàn tó mọnúúrò fi gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn ohun àwòyanu tó wà láyé?
ÀWỌN ohun àgbàyanu pọ̀ lọ súà láyé yìí. Báwo ló ṣe di pé wọ́n wà? Àwọn kan ò gbà pé Ẹlẹ́dàá ọlọ́gbọ́n-lóye kan wà tó dá wọn. Àmọ́ àwọn míì sọ pé téèyàn bá kọ̀ jálẹ̀ pé òun ò gbà pé Ẹlẹ́dàá kankan wà, olúwarẹ̀ ò ní lè mọ gbogbo ohun tó yẹ kó mọ̀ nípa àwọn ohun àgbàyanu inú ayé yìí. Wọ́n gbà pé pẹ̀lú bí àwọn ohun tó wà láyé ṣe jẹ́ àgbàyanu tó, bí wọ́n ṣe pọ̀ lóríṣiríṣi tó àti bí wọ́n ṣe díjú tó, kò kàn lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ṣàdédé wà. Ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan, gbà pé ẹ̀rí fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan tó jẹ́ ọlọgbọ́n, alágbára àti ọ̀làwọ́ ló dá ọ̀run òun ayé àti gbogbo nǹkan tó wà nínú wọn.a
2. Kí ló mú kí Dáfídì yin Jèhófà?
2 Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un jẹ́ ẹnì kan tó gbà pé ìyìn yẹ Ẹlẹ́dàá fún dídá tó dá àwọn ohun àgbàyanu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé ìgbà tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ò tíì gbilẹ̀ ni Dáfídì gbé láyé, ó róye pé àwọn ohun tóun ń rí láyìíká òun gbogbo jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run. Kò dìgbà tí Dáfídì bá rìn jìnnà kí iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run ṣe nínú ìṣẹ̀dá tó lè jọ ọ́ lójú gan-an. Wíwò tó wo ara rẹ̀ lásán ti tó. Ìyẹn ló mú kó kọ̀wé pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.”—Sáàmù 139:14.
3, 4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ronú jinlẹ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà?
3 Ohun tó mú kó dá Dáfídì lójú hán-únhán-ún pé Ẹlẹ́dàá kan ní láti wà ni pé ó ro àròjinlẹ̀. Lóde òní, àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni níléèwé àtàwọn ohun tí wọ́n ń gbé jáde nínú tẹlifíṣọ̀n, rédíò àtàwọn ìwé ìròyìn kún fún onírúurú èrò táwọn èèyàn hùmọ̀ nípa bí ìran èèyàn ṣe pilẹ̀ṣẹ̀, àwọn èrò náà sì lè sọ̀ọ̀yàn dẹni tí kò gbà pé Ẹlẹ́dàá wà. Nítorí náà, ká tó lè nígbàgbọ́ bíi ti Dáfídì, a ní láti ronú jinlẹ̀ bíi tiẹ̀. Ó léwu tá a bá kàn ń gba ohun táwọn èèyàn sọ láì fúnra wa ronú, pàápàá nínú àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì bíi bóyá Ẹlẹ́dàá wà àti bóyá òun ló dá ohun gbogbo tàbí òun kọ́.
4 Ìyẹn nìkan kọ́, tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà, àá túbọ̀ mọrírì àwọn ohun tó ṣe, á sì dá wa lójú pé àwọn ìlérí tó ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la yóò ṣẹ dandan. Ìyẹn lè mú ká fẹ́ láti túbọ̀ mọ Jèhófà ká sì túbọ̀ máa sìn ín. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wo bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ṣe kín ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ lẹ́yìn pé Ọlọ́run ‘ṣẹ̀dá wa tìyanu-tìyanu.’
Bí Ara Wa Ṣe Ń Dàgbà Lọ́nà Ìyanu
5, 6. (a) Báwo ni ìwàláàyè kálukú wa ṣe bẹ̀rẹ̀? (b) Iṣẹ́ wo ni kíndìnrín ń ṣe nínú ara?
5 Dáfídì sọ pé: “Ìwọ tìkára rẹ ni ó ṣe àwọn kíndìnrín mi; ìwọ ni ó yà mí sọ́tọ̀ nínú ikùn ìyá mi.” (Sáàmù 139:13) Ìwàláàyè kálukú wa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ẹyin fẹ́ra kù níkùn ìyá wa tó sì di sẹ́ẹ̀lì tín-ń-tín kan tá ò lè fojúyòójú rí. Síbẹ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye èròjà tó máa fi dàgbà ti wà nínú rẹ̀! Ńṣe ni sẹ́ẹ̀lì tín-ń-tín tó di ọlẹ̀ yìí sì ń sáré dàgbà débi pé nígbà tó fi máa di ìparí oṣù méjì, àwọn ẹ̀yà ara wa pàtàkì-pàtàkì ti fara hàn. Kíndìnrín jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà ara náà. Nígbà tí wọ́n fi máa bí wa, kíndìnrín wa ti wà ní sẹpẹ́ láti máa sẹ́ àwọn ohun olóró tó lè ṣàkóbá fún ara àti omi tára wa ò nílò kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ wa. Tí nǹkan kan ò bá ṣe kíndìnrín méjèèjì, nǹkan bí omi lítà márùn-ún ló máa ń sẹ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ àgbàlagbà láàárín ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta [45]!
6 Kíndìnrín tún máa ń jẹ́ kí oríṣi àwọn èròjà aṣaralóore kan, ásíìdì inú ẹ̀jẹ̀ àti agbára tí ẹ̀jẹ̀ fi ń ṣàn yí po ara, wà ní ìwọ̀n tó yẹ. Kíndìnrín tún máa ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan pàtàkì míì, bíi kó yí èròjà tí wọ́n ń pè ní fítámì-D padà di èròjà tó máa ń mú kí egungun wa dàgbà bó ṣe yẹ tó sì máa ń pèsè oríṣi omi ara kan tí wọ́n ń pè ní erythropoietin, èyí tó máa ń mú kí mùdùnmúdùn inú egungun pèsè àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀. Abájọ tí wọ́n fi ń pe kíndìnrín ní “ògbóǹkangí oníṣègùn ara”!b
7, 8. (a) Ṣàlàyé bí ọlẹ̀ ṣe máa ń dàgbà. (b) Ọ̀nà wo ló fi jẹ́ pé a hun ọmọ tó ṣì wà nínú ilé ọlẹ̀ “ní àwọn apá ìsàlẹ̀ jù lọ ní ilẹ̀ ayé”?
7 Dáfídì tún sọ pé: “Àwọn egungun mi kò pa mọ́ fún ọ nígbà tí a ṣẹ̀dá mi ní ìkọ̀kọ̀, nígbà tí a hun mí ní àwọn apá ìsàlẹ̀ jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 139:15) Ohun tín-ń-tín tó bẹ̀rẹ̀ ìwàláàyè èèyàn, tá à ń pè ní sẹ́ẹ̀lì, á bẹ̀rẹ̀ sí í pín ní àpíntúnpín sí oríṣiríṣi ọ̀nà níbàámu pẹ̀lú iṣẹ́ kálukú wọn nínú ara. Wọ́n á di sẹ́ẹ̀lì inú iṣan ara, sẹ́ẹ̀lì inú ẹran ara, sẹ́ẹ̀lì inú awọ ara, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn sẹ́ẹ̀lì irú kan náà á wá para pọ̀ di ẹ̀yà ara kan. Bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà ara yòókù á ṣe máa fara hàn. Bí àpẹẹrẹ, láàárín ọ̀sẹ̀ kẹta, àwọn egungun á bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn. Nígbà tó bá fi máa di ọ̀sẹ̀ keje, ọlẹ̀ náà ò lè tíì gùn ju nǹkan bí ìdajì igi ìṣáná lọ o, síbẹ̀ gbogbo igba ó lé mẹ́fà [206] egungun tó máa ń wà lára wa tá a bá dàgbà á ti bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà díẹ̀díẹ̀ nínú rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì rọ̀.
8 Ọmọ máa ń dàgbà lọ́nà ìyanu nínú ilé ọlẹ̀ ìyá, níbi tí ojú ẹ̀dá èèyàn kankan ò tó, àfi bíi pé ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé. Ká sòótọ́, ṣín-ń-ṣín lọmọ èèyàn tíì mọ̀ nípa bí ara ṣe ń dàgbà nínú ilé ọlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kí ló máa ń sún èròjà tó máa ń pinnu bí ara ṣe máa rí láti mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ọlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà níbàámu pẹ̀lú iṣẹ́ kálukú wọn nínú ara? Bóyá lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìwádìí, ó ṣeé ṣe káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mọ̀ ọ́n, síbẹ̀, bí ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ tẹ̀ lé e ṣe fi hàn, gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹ̀ ni Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa ti mọ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀.
9, 10. Báwo ló ṣe jẹ́ pé ọ̀nà táwọn ẹ̀yà ara ọlẹ̀ gbà ń fara hàn “wà ní àkọsílẹ̀” nínú “ìwé” Ọlọ́run?
9 Dáfídì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀, ní ti àwọn ọjọ́ tí a ṣẹ̀dá wọn, tí ìkankan lára wọn kò sì tíì sí.” (Sáàmù 139:16) Ìlànà bí ara látòkèdélẹ̀ ṣe máa rí wà nínú ohun tín-ń-tín, ìyẹn sẹ́ẹ̀lì àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ ìwàláàyè èèyàn. Ìlànà yìí ló máa darí bí ara ṣe máa dàgbà fún oṣù mẹ́sàn-án kí wọ́n tó bí èèyàn, òun náà ní á sì máa darí bí ara ṣe máa dàgbà fún ohun tó lé ní ogún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bá bí èèyàn. Láàárín àkókò yìí, ọ̀pọ̀ ìpele ni ara máa là kọjá bó ṣe ń dàgbà, ìlànà tí Ẹlẹ́dàá sì ti fi sínú ohun tín-ń-tín àkọ́kọ́ yẹn ló máa darí gbogbo èyí.
10 Dáfídì ò mọ̀ nípa àwọn nǹkan tín-tìn-tín tí wọ́n ń pè ní sẹ́ẹ̀lì, kò mọ̀ nípa èròjà tó máa ń pinnu bí ara ṣe máa rí, kódà kò ní awò amúǹkantóbi. Àmọ́ ó fòye mọ̀ pé ìlànà kan ti wà nílẹ̀ tí ara òun tẹ̀ lé bó ṣe ń dàgbà nínú ilé ọlẹ̀, èyí sì tọ̀nà. Ó sì ṣeé ṣe kí Dáfídì mọ̀ díẹ̀ nípa bí ọlẹ̀ ṣe ń dàgbà, ìdí nìyẹn tó fi lè ronú pé ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ló ń dàgbà ní gbogbo ìpele-ìpele rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú àkókò àti ìlànà kan tó ti wà nílẹ̀. Ó wá fi èdè ewì sọ̀rọ̀, ó ní ìlànà bí ara ṣe ń dàgbà nínú ilé ọlẹ̀ “wà ní àkọsílẹ̀” nínú “ìwé” Ọlọ́run.
11. Kí ló pinnu bí ara kálukú wa ṣe rí?
11 Lóde òní, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rí i pé èròjà inú ẹ̀jẹ̀ tó máa ń pinnu bí ara ṣe máa rí ló pinnu àwọn ohun tá a fi jọ àwọn òbí wa àtàwọn babańlá àti ìyá ńlá wa, irú bá a ṣe ga sí, bí ojú wa ṣe rí, àwọ̀ ẹyinjú wa àti irun wa, àti àìmọye àwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn sẹ́ẹ̀lì tó wà lára wa ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún èròjà tó máa ń pinnu bí ara ṣe máa rí, àwọn èròjà yìí sì wà nínú ohun tí wọ́n ń pè ní DNA (deoxyribonucleic acid). Ìlànà bí ara á ṣe máa dàgbà ti “wà ní àkọsílẹ̀” nínú DNA yìí tó wà nínú sẹ́ẹ̀lì kálukú wa. Èròjà DNA wa ló ń mú káwọn sẹ́ẹ̀lì ara wa máa pín káwọn sẹ́ẹ̀lì mìíràn lè jẹ yọ tàbí káwọn sẹ́ẹ̀lì tuntun lè pààrọ̀ àwọn èyí tó ti gbó. Èyí ló ń jẹ́ ká lè máa wà láàyè lọ ki ìrísí wa sì máa wà bó ṣe wà. Áà, agbára àti ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa tí ń bẹ lọ́run mà pọ̀ o!
Ọpọlọ Wa Ò Láfiwé
12. Ohun wo ní pàtàkì ló mú káwa èèyàn yàtọ̀ sí ẹranko?
12 Dáfídì sọ pé: “Nítorí náà, lójú mi, àwọn ìrònú rẹ mà ṣe iyebíye o! Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn pátápátá mà pọ̀ o! Ká ní mo fẹ́ gbìyànjú láti kà wọ́n ni, wọ́n pọ̀ ju àwọn egunrín iyanrìn pàápàá.” (Sáàmù 139:17, 18a) Ọ̀nà ìyanu ni Ọlọ́run gbà dá àwọn ẹranko náà. Àwọn nǹkan kan tiẹ̀ wà tí wọ́n lè ṣe táwa ò lè ṣe. Àmọ́ Ọlọ́run fún àwa èèyàn ní ọpọlọ tó ju tiwọn lọ fíìfíì. Ìwé kan tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan kan wà táwa èèyàn ń ṣe táwọn ẹranko náà lè ṣe, a yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo ẹ̀dá inú ayé nítorí pé à ń sọ èdè a sì lè ronú. Ohun mìíràn tó tún mú ká ta wọ́n yọ ni pé a máa ń ṣèwádìí gan-an láti mọ̀ nípa ara wa. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń ronú pé: Kí ló para pọ̀ di ara wa? Báwo ni Ẹlẹ́dàá ṣe ṣẹ̀dá ara wa?” Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni Dáfídì pẹ̀lú ronú nípa rẹ̀.
13. (a) Ọ̀nà wo ni Dáfídì fi lè ṣàṣàrò lórí àwọn èrò Ọlọ́run? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì?
13 Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwọn ọ̀nà tá a fi yàtọ̀ sí ẹranko ni pé, a lè ṣàṣàrò lórí èrò Ọlọ́run.c Àkànṣe ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá wa “ní àwòrán rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Dáfídì lo ẹ̀bùn yìí dáadáa. Ó ronú nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, ó tún ronú nípa àwọn ànímọ́ rere tí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá fi hàn pé Ọlọ́run ní. Bákan náà, ó ní àwọn ìwé inú Bíbélì tó ti wà nígbà ayé rẹ̀ lọ́wọ́. Nínú àwọn ìwé náà, Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ nípa òun àti iṣẹ́ ọwọ́ òun. Àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí yìí jẹ́ kí Dáfídì mọ èrò Ọlọ́run, irú ẹni tó jẹ́, àtàwọn ohun tó pinnu láti ṣe. Ṣíṣàṣàrò tí Dáfídì ṣàṣàrò lórí Ìwé Mímọ́, lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, àti lórí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá òun lò, mú kó yin Ẹlẹ́dàá rẹ̀.
Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Ṣe Kó Tó Lè Sọ Pé Òun Nígbàgbọ́
14. Kí nìdí tá ò fi ní láti mọ gbogbo nǹkan nípa Ọlọ́run ká tó lè nígbàgbọ́ nínú rẹ̀?
14 Bí Dáfídì ṣe ń ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá àti Ìwé Mímọ́ tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe ń rí i pé òun ò lè mọ ibi tí ìmọ̀ Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ dé. (Sáàmù 139:6) Bó ṣe rí fún àwa náà nìyẹn. Kò sí bá a ṣe lè mọ gbogbo nǹkan nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. (Oníwàásù 3:11; 8:17) Àmọ́ Ọlọ́run mú kí ìmọ̀ tó pọ̀ tó “fara hàn kedere” nínú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ohun tó dá, káwọn olùfẹ́ òtítọ́ lákòókò èyíkéyìí lè ní ìgbàgbọ́ tí ẹ̀rí tó dájú tì lẹ́yìn.—Róòmù 1:19, 20; Hébérù 11:1, 3.
15. Ṣàpèjúwe bí ìgbàgbọ́ àti àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run ṣe wọnú ara wọn.
15 Pé kẹ́nì kan nígbàgbọ́ kọjá pé kó wulẹ̀ gbà pé Ẹlẹ́dàá ọlọ́gbọ́n-lóye kan wà tó dá ayé òun ọ̀run àtàwọn ohun abẹ̀mí. Ó gba pé kẹ́ni náà ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà Ọlọ́run, kó mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká mọ òun ká sì tún ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú òun. (Jákọ́bù 4:8) Ẹ jẹ́ ká fi ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí ọmọ máa ń ní nínú bàbá tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe àpẹẹrẹ. Tí alárìíyànjiyàn ẹ̀dá bá sọ pé kò dájú pé bàbá rẹ á ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá wà nínú ìṣòro, ó ṣeé ṣe kí gbogbo àlàyé rẹ má lè yí i lọ́kàn padà pé bàbá rẹ̀ ṣeé fọkàn tán. Àmọ́ tó o bá ti rí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí látẹ̀yìnwá tó fi hàn pé èèyàn rere ni bàbá rẹ, ó máa dá ẹ lójú pé kò ní já ẹ kulẹ̀. Lọ́nà kan náà, bí àwa náà bá mọ Jèhófà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àti nípa ríronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tó dá, tá a sì ń rí i pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá gbàdúrà sí i, èyí á mú ká gbẹ́kẹ̀ lé e. Á mú ká fẹ́ mọ̀ sí i nípa rẹ̀ ká sì máa yìn ín títí láé nítorí pé a fẹ́ràn rẹ̀ àti nítorí pé ó wù wá ká máa sìn ín, kì í ṣe nítorí ohun tá a máa rí gbà lọ́wọ́ rẹ̀. Ohun tó dára jù lọ kí ẹ̀dá èèyàn máa lépa nìyẹn.—Éfésù 5:1, 2.
Wá Ìtọ́sọ́nà Ẹlẹ́dàá Wa!
16. Kí la lè rí kọ́ nínú bí àjọṣe tímọ́tímọ́ ṣe wà láàárín Dáfídì àti Jèhófà?
16 Dáfídì tún sọ̀rọ̀, ó ní: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi. Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè, Kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 139:23, 24) Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà mọ òun láìkù síbì kan, ì báà jẹ́ ohun tóun ń rò, ohun tóun ń sọ lẹ́nu tàbí ohun tóun ń ṣe. Ó mọ̀ pé gbogbo rẹ̀ ni Ẹlẹ́dàá òun mọ̀. (Sáàmù 139:1-12; Hébérù 4:13) Mímọ̀ tí Ọlọ́run mọ Dáfídì láìkù síbì kan yìí mú kí ọkàn Dáfídì balẹ̀ bí ọkàn ọmọ ṣe máa ń balẹ̀ táwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bá gbé e dání. Dáfídì mọyì àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín òun àti Jèhófà, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí àjọṣe náà má bà jẹ́. Ó máa ń ṣe èyí nípa ríronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá àti nípa gbígbàdúrà sí i. Kódà, ọ̀pọ̀ lára àwọn sáàmù Dáfídì, tó fi mọ́ Sáàmù kọkàndínlógóje [139], ló jẹ́ àdúrà tó kọ lórin. Táwa náà bá ń ṣàṣàrò tá a sì ń gbàdúrà, a ó lè sún mọ́ Jèhófà.
17. (a) Kí nìdí tí Dáfídì fi fẹ́ kí Jèhófà yẹ ọkàn òun wò? (b) Ipa wo ni ọ̀nà tá à ń gbà lo òmìnira tí Ọlọ́run fún wa láti yan ohun tó wù wá ń ní lórí ìgbésí ayé wa?
17 Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti dá wa ní àwòrán rẹ̀, a ní òmìnira láti yan ohun tó wù wá. A lè yàn láti ṣe ohun tó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́. Àmọ́ nítorí òmìnira tá a ní yìí, a máa jíhìn fún Ọlọ́run nípa irú ìwà tá a bá hù. Dáfídì ò fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn ẹni ibi. (Sáàmù 139:19-22) Kò fẹ́ ṣe àṣìṣe tó máa kó o sí ìṣòro. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tó ronú jinlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe mọ ohun gbogbo, ó bẹ Ọlọ́run tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé kó yẹ ọkàn òun wò kó sì ṣamọ̀nà òun ní ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Gbogbo wa ni ìlànà ìwà híhù tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ kàn, nítorí náà ó yẹ káwa náà yàn láti ṣe ohun tó tọ́. Jèhófà ń rọ gbogbo wa pé ká máa ṣègbọràn sóun. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò rí ojú rere rẹ̀, á sì tún ṣe wá lọ́pọ̀ àǹfààní. (Jòhánù 12:50; 1 Tímótì 4:8) Tá a bá ń bá Jèhófà rìn lójoojúmọ́, a óò ní àlàáfíà ọkàn, kódà nígbà tá a bá ní ìṣòro tó kàmàmà.—Fílípì 4:6, 7.
Máa Ṣègbọràn Sẹ́ni Tó Dá Wa Lọ́nà Ìyanu!
18. Èrò wo ni Dáfídì ní lẹ́yìn tó ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá?
18 Nígbà tí Dáfídì wà lọ́mọdé, ó sábà máa ń wà níta níbi tó ti ń tọ́jú àwọn àgùntàn. Báwọn àgùntàn ṣe tẹrí mọ́lẹ̀ tí wọ́n ń jẹ koríko lálẹ́, Dáfídì gbórí sókè, ó ń wojú ọ̀run. Ó ronú bí ayé àti ọ̀run àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn ṣe tóbi lọ́lá tó àti ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ wa. Ó wá kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọjọ́ kan tẹ̀ lé ọjọ́ mìíràn ń mú kí ọ̀rọ̀ ẹnu tú jáde, òru kan tẹ̀ lé òru mìíràn sì ń fi ìmọ̀ hàn.” (Sáàmù 19:1, 2) Dáfídì mọ̀ pé òun ní láti wá Ẹni tó dá ohun gbogbo lọ́nà àgbàyanu kóun sì máa ṣègbọràn sí i. Bó sì ṣe yẹ káwa náà ṣe nìyẹn.
19. Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni tèwe-tàgbà wa lè rí kọ́ nínú dídá tí Jèhófà ‘dá wa tìyanu-tìyanu’?
19 Nígbà tí Dáfídì wà láyé, ó ṣe ohun tí Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ wá gba àwọn ọ̀dọ́ nímọ̀ràn lẹ́yìn náà pé kí wọ́n ṣe. Ìmọ̀ràn náà ni pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin . . . Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.” (Oníwàásù 12:1, 13) Àní nígbà tí Dáfídì wà lọ́dọ̀ọ́, ó fòye mọ̀ pé Ọlọ́run ‘dá òun lọ́nà ìyanu.’ Nígbà tó gbé ìgbé ayé rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ohun tó mọ̀ yìí, ó ṣe é láǹfààní ńlá jálẹ̀ ayé rẹ̀. Tí gbogbo wa lọ́mọdé lágbà bá ń yin Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá, tá a sì ń sìn ín, ayé wa á dùn nísinsìnyí àti lọ́jọ́ ọ̀la. Bíbélì ṣèlérí fáwọn tí wọ́n sún mọ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń pa ìlànà òdodo rẹ̀ mọ́ pé: “Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú, wọn yóò máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjàyọ̀yọ̀, láti lè sọ pé adúróṣánṣán ni Jèhófà.” (Sáàmù 92:14, 15) Paríparí rẹ̀ ni pé, àá nírètí àtigbádùn àwọn ohun àgbàyanu tí Ẹlẹ́dàá wa dá títí láé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jí! ti June 22, 2004 lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
b Tún wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Kíndìnrín Rẹ—Asẹ́ Ìgbẹ́mìíró,” tó wà nínú Jí! August 8, 1997.
c Ó dà bíi pé Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 139:18, apá kejì nínú ẹsẹ náà, túmọ̀ sí pé tó bá tiẹ̀ ka èrò Jèhófà látàárọ̀ títí dìgbà tó fi sùn lálẹ́, tó bá tún jí láàárọ̀, á ṣì rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ kà sí i.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Báwo ni ọ̀nà tí ọlẹ̀ gbà ń dàgbà ṣe fi hàn pé Ọlọ́run ‘ṣẹ̀dá wa tìyanu-tìyanu’?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣàṣàrò lórí àwọn èrò Jèhófà?
• Báwo ni ìgbàgbọ́ wa àti àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà ṣe wọnú ara wọn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọmọ máa ń dàgbà nínú ilé ọlẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ìlànà tó ti wà nílẹ̀
Èròjà DNA
[Credit Line]
Àwòrán ọmọ inú ilé ọlẹ̀: Lennart Nilsson
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
A gbọ́kàn lé Jèhófà bíi tọmọ tó gbẹ́kẹ̀ lé bàbá tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ríronú tí Dáfídì ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tí Jèhófà dá mú kó yin Jèhófà