Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Mà Pọ̀ O!
“Jèhófà . . . pọ̀ ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.”—SÁÀMÙ 145:8.
1. Ibo ni ìfẹ́ Ọlọ́run nasẹ̀ dé?
“ỌLỌ́RUN jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Gbólóhùn amọ́kànyọ̀ yìí fi hàn pé ìfẹ́ ni Jèhófà fi ń ṣàkóso. Àní, àwọn tí kò ṣègbọràn sí i pàápàá ń gbádùn oòrùn àti òjò tó ń fìfẹ́ pèsè! (Mátíù 5:44, 45) Kódà ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún aráyé yìí lè mú káwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá ronú pìwà dà, kí wọ́n yí padà sọ́dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16) Àmọ́ ṣá o, láìpẹ́ Jèhófà yóò pa gbogbo àwọn ẹni ibi tó bá kọ̀ láti ronú pìwà dà run, káwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lè gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun òdodo.—Sáàmù 37:9-11, 29; 2 Pétérù 3:13.
2. Irú ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ wo ni Jèhófà fi hàn sáwọn tó ya ara wọn sí mímọ́ fún un?
2 Jèhófà fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí kò lópin hàn sáwọn olùjọsìn rẹ̀ tòótọ́. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ la fi ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” tàbí “ìfẹ́ dídúróṣinṣin” ṣàpèjúwe. Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì mọyì inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní yìí gidigidi. Ohun tójú Dáfídì alára ti rí àti àṣàrò tó ti ṣe lórí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá àwọn èèyàn lò mú kó kọrin láìmikàn pé: “Jèhófà . . . pọ̀ ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ [tàbí, “ìfẹ́ dídúróṣinṣin”].”—Sáàmù 145:8.
Bá A Ṣe Lè Dá Àwọn Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Ọlọ́run Mọ̀
3, 4. (a) Báwo ni Sáàmù 145 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti dá àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà mọ̀? (b) Báwo làwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run ṣe ń “fi ìbùkún” fún un?
3 Nígbà tí Hánà, màmá wòlíì Sámúẹ́lì ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run, ó ní: “Ó ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ẹsẹ̀ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 2:9) Àwọn wo ni irú “àwọn ẹni ìdúróṣinṣin” bẹ́ẹ̀? Dáfídì Ọba dáhùn ìbéèrè náà. Lẹ́yìn tó yin àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jèhófà ní wọ̀nyẹn, ó wá sọ pe: “Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò sì máa fi ìbùkún fún ọ.” (Sáàmù 145:10) O lè máa ṣe kàyéfì pé báwo làwọn èèyàn ṣe lè fi ìbùkún fún Ọlọ́run? Ọ̀nà pàtàkì tí wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n máa yìn ín tàbí kí wọ́n máa sọ ohun tó dára nípa rẹ̀.
4 Àwọn tá a lè gbà pè ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ni àwọn tó ń fi ẹnu wọn sọ ohun tó dára nípa rẹ̀. Kí ni ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ níbi àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti láwọn ìpàdé Kristẹni? Ó dájú pé ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Jèhófà ni! Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ adúróṣinṣin wọ̀nyí ní èrò kan náà tí Dáfídì ní, èyí tó kọ lórin pé: “Wọn yóò máa sọ̀rọ̀ nípa ògo ipò ọba rẹ [Jèhófà], wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa agbára ńlá rẹ.”—Sáàmù 145:11.
5. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń fetí sílẹ̀ nígbà táwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i bá ń sọ ohun tó dáa nípa rẹ̀?
5 Ǹjẹ́ Jèhófà máa ń fetí sílẹ̀ nígbà táwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i bá ń yìn ín? Dájúdájú, ó máa ń fetí sí ohun tí wọ́n ń sọ. Nígbà tí Málákì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn tòótọ́ ní ọjọ́ wa, ó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, olúkúlùkù pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.” (Málákì 3:16) Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an nígbà táwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i bá ń sọ ohun tó dáa nípa rẹ̀, ó sì máa ń rántí wọn.
6. Àwọn ìgbòkègbodò wo ló ràn wá lọ́wọ́ láti dá àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run mọ̀?
6 Ohun tá a tún lè fi dá àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà mọ̀ ni bí wọ́n ṣe máa ń fìgboyà bá àwọn tí kì í ṣe olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀ níbi gbogbo. Ká sòótọ́, àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run máa ń “sọ àwọn ìṣe agbára ńlá rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn àti ògo ọlá ńlá ipò ọba rẹ̀.” (Sáàmù 145:12) Ǹjẹ́ o máa ń lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti bá àwọn aláìgbàgbọ́ sọ̀rọ̀ nípa ipò ọba Jèhófà? Láìdàbí ìjọba ènìyàn tó máa kọjá lọ láìpẹ́, ńṣe ni ipò ọba tirẹ̀ yóò wà títí láé. (1 Tímótì 1:17) Ó jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú pé káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa ipò ọba Jèhófà tí yóò wà títí lọ fáàbàdà, kí wọ́n sì múra tán láti tì í lẹ́yìn. Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Ipò ọba rẹ jẹ́ ipò ọba tí ó wà fún gbogbo àkókò tí ó lọ kánrin, àgbègbè ìṣàkóso rẹ sì jẹ́ jálẹ̀ gbogbo ìran-ìran tí ń dìde ní ṣísẹ̀-ń-tẹ̀lé.”—Sáàmù 145:13.
7, 8. Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914, ẹ̀rí wo ló sì fi hàn pé Ọlọ́run ti ń ṣàkóso báyìí nípasẹ̀ Ìjọba Ọmọ rẹ̀?
7 Àtọdún 1914 la tún ti rí ìdí pàtàkì mìíràn láti sọ̀rọ̀ nípa ipò ọba Jèhófà. Ọdún yẹn ni Ọlọ́run gbé Ìjọba ọ̀run ti Mèsáyà kalẹ̀, tó sì fi Jésù Kristi, Ọmọ Dáfídì ṣe Ọba rẹ̀. Jèhófà wá tipa bẹ́ẹ̀ mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé ipò ọba Dáfídì yóò fìdí múlẹ̀ gbọn-n gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kanrin.—2 Sámúẹ́lì 7:12, 13; Lúùkù 1:32, 33.
8 Ẹ̀rí tó ń fi hàn pé Jèhófà ti ń jọba báyìí nípasẹ̀ Ìjọba Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, là ń rí nínú báwọn àmì wíwàníhìn-ín Jésù ṣe ń nímùúṣẹ lákòókò tá a wà yìí. Apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àmì náà ni iṣẹ́ tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé gbogbo àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ṣe, nígbà tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:3-14) Bí àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ tìtaratìtara ti mú kí iye tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn ọmọdé máa kópa nínú iṣẹ́ kíkọyọyọ tá a ò ní tún ṣe mọ́ yìí. Láìpẹ́, òpin yóò dé bá gbogbo àwọn tó jẹ́ alátakò Ìjọba Jèhófà.—Ìṣípayá 11:15, 18.
Jíjàǹfààní Látinú Jíjẹ́ Tí Jèhófà Jẹ́ Ọba Aláṣẹ
9, 10. Kí ló mú kí Jèhófà yàtọ̀ sáwọn èèyàn tó jẹ́ alákòóso?
9 Tá a bá jẹ́ Kristẹni tó ti ya ara wa sí mímọ́, àjọṣe tó wà láàárín àwa àti Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún wa. (Sáàmù 71:5; 116:12) Bí àpẹẹrẹ, bíbẹ̀rù tá a bẹ̀rù Ọlọ́run tá a sì ń ṣe iṣẹ́ òdodo la fi ń rí ojú rere rẹ̀ tá a sì sún mọ́ ọn nípa tẹ̀mí. (Ìṣe 10:34, 35; Jákọ́bù 4:8) Èyí yàtọ̀ sí ti àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso tó jẹ́ pé àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn ni wọ́n máa ń bá kẹ́gbẹ́, àwọn bí àwọn ọ̀gá ológun, àwọn oníṣòwò ńláńlá, tàbí àwọn tó gbajúmọ̀ nídìí eré ìdárayá. Ohun tá a gbọ́ látinú ìròyìn kan tí ìwé ìròyìn Sowetan ti ilẹ̀ Áfíríkà gbé jáde ni pé, gbajúmọ̀ ọkùnrin kan tó jẹ́ ọ̀gá nídìí iṣẹ́ ìjọba sọ ohun tó tẹ̀ lé e yìí nípa àwọn àgbègbè tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ní orílẹ̀-èdè rẹ̀, ó ní: “Mo mọ ìdí tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn kì í fẹ́ lọ sí irú àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé a ó fẹ́ máa rántí rárá pé àwọn kan wà nírú ipò bẹ́ẹ̀. Nítorí pé ó máa ń da ẹ̀rí ọkàn wa láàmú ó sì máa ń mára tini nígbà tá a bá ń wo ara wa nínú àwọn [ọkọ̀] dẹ̀ǹkùdẹ̀ǹkù tá a ń gùn.”
10 Àmọ́ ṣá o, lóòtọ́ làwọn alákòóso kan máa ń ṣàníyàn nípa ire àwọn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso wọn. Síbẹ̀ àwọn tó ṣèèyàn jù lọ láàárín wọn ò mọ àwọn ọmọ abẹ́ wọn dunjú. Nítorí náà, a lè béèrè pé: Ǹjẹ́ alákòóso èyíkéyìí tiẹ̀ wà tó bìkítà nípa gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ débi pé kíá ló máa ń dìde ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bá wà nínú ìṣòro? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà. Dáfídì kọ̀wé pé: “Jèhófà ń fún gbogbo àwọn tí ó ṣubú ní ìtìlẹyìn, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde.”—Sáàmù 145:14.
11. Àwọn àdánwò wo ló ń dé bá àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, ìrànlọ́wọ́ wo ni wọ́n sì máa ń rí gbà?
11 Ọ̀pọ̀ àdánwò àti àjálù ló ń dé bá àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà Ọlọ́run nítorí àìpé tiwọn fúnra wọn àti nítorí pé wọ́n ń gbé nínú ayé kan tó wà lábẹ́ agbára Sátánì, “ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19; Sáàmù 34:19) Àwọn èèyàn máa ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni. Àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tàbí ikú èèyàn ẹni ni ìṣòro táwọn kan ní. Àwọn ìgbà mìíràn wà tí àṣìṣe táwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà bá ṣe máa ń jẹ́ kí ìbànújẹ́ ‘dorí wọn kodò.’ Àmọ́ ṣá o, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń múra tán láti tu ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú kó sì fún wọn lókun nípa tẹ̀mí nígbàkigbà tí wọ́n bá bá ara wọn nínú àdánwò. Irú ìfẹ́ àtọkànwá kan náà yìí ni Jésù Kristi Ọba ní sí àwọn adúróṣinṣin tó ń ṣàkóso lé lórí.—Sáàmù 72:12-14.
Oúnjẹ Tó Tẹ́ni Lọ́rùn Lákòókò Tó Yẹ
12, 13. Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè ohun tí “gbogbo ohun alààyè” nílò?
12 Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ní ló ń mú kó fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò. Oúnjẹ afúnnilókun tó fi ń tẹ́ wọn lọ́rùn wà lára èyí. Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Ìwọ [Jèhófà] ni ojú gbogbo gbòò ń wò tìrètí-tìrètí, ìwọ sì ń fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò rẹ̀. Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sáàmù 145:15, 16) Kódà láwọn àkókò àjálù, Jèhófà lè bójú tó àwọn ọ̀ràn lọ́nà tí àwọn ẹnì tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i yóò fi rí ‘oúnjẹ òòjọ́ wọn.’—Lúùkù 11:3; 12:29, 30.
13 Dáfídì sọ pé “gbogbo ohun alààyè” là ń tẹ́ lọ́rùn. Ìyẹn sì kan àwọn ẹranko pẹ̀lú. Tí kì í bá ṣe pé àwọn ohun ọ̀gbìn pọ̀ rẹpẹtẹ lórí ilẹ̀, tí àwọn ewéko sì pọ̀ nínú òkun, àwọn ẹ̀dá inú omi, àwọn ẹyẹ, àtàwọn ẹranko tó ń rìn lórí ilẹ̀ ì bá má rí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tí wọ́n máa mí sínú tàbí oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ́. (Sáàmù 104:14) Síbẹ̀, Jèhófà rí i pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò ni òun fi ń tẹ́ wọn lọ́rùn.
14, 15. Báwo la ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lóde òní?
14 Láìdàbí àwọn ẹranko, ohun tẹ̀mí tún máa ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn. (Mátíù 5:3) Ẹ wo ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà gbà ń fi ohun tẹ̀mí tẹ́ àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i lọ́rùn! Kí Jésù tó kú, ó ṣèlérí pé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” yóò pèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu” nípa tẹ̀mí fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. (Mátíù 24:45) Ìyókù àwọn ẹni àmì òróró tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ló para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ ẹrú náà lónìí. Jèhófà sì ti tipasẹ̀ wọn pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu lóde òní.
15 Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn Jèhófà ló ń jàǹfààní báyìí látinú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tuntun tá a ṣe lọ́nà tó péye ní àwọn èdè ìbílẹ̀ wọn. Ẹ wo bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe jẹ́ ìbùkún àgbàyanu tó! Kò tán síbẹ̀ o, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la tún ń tẹ̀ jáde ní àwọn èdè tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300] báyìí. Gbogbo oúnjẹ tẹ̀mí yìí ti jẹ́ ìbùkún fún àwọn olùjọsìn tòótọ́ kárí ayé. Ta ló yẹ ká fi ìyìn gbogbo èyí fún? Jèhófà Ọlọ́run ni. Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ti mú kó ṣeé ṣe fún ẹgbẹ́ ẹrú náà láti máa pèsè “oúnjẹ . . . ní àsìkò rẹ̀.” Nípasẹ̀ irú àwọn ìpèsè bẹ́ẹ̀, “ìfẹ́ ọkàn gbogbo ohun alààyè” ti di èyí tí a tẹ́ lọ́rùn nínú Párádísè tẹ̀mí tó wà lóde òní. Ẹ sì wo bí inú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe ń dùn pé láìpẹ́ àwọn á rí ilẹ̀ ayé tí yóò di Párádísè!—Lúùkù 23:42, 43.
16, 17. (a) Àwọn àpẹẹrẹ oúnjẹ tẹ̀mí wo ló ń wá lásìkò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu? (b) Báwo ni Sáàmù 145 ṣe jẹ́ ká mọ bí ọ̀ràn pàtàkì tí Sátánì gbé dìde ṣe rí lára àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run?
16 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan tó gbàfiyèsí yẹ̀ wò nípa báwọn èèyàn ṣe rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. Ọdún 1939 ni Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù. Ní ọdún yẹn kan náà ni ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ti November 1, gbé àpilẹ̀kọ kan jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Àìdásí-tọ̀túntòsì.” Ìsọfúnni tó ṣe kedere tá a gbé jáde níbẹ̀ jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé rí i pé àwọn ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀ràn ogun tó ń lọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Èyí ru ìbínú àwọn aláṣẹ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì tó ń jagun náà sókè fún odindi ọdún mẹ́fà tí ogun náà fi jà. Àmọ́, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe fòfin dè wọ́n tó, tí wọ́n tún ṣe inúnibíni sí wọn, àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run ń bá a lọ ní wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Ọlọ́run bù kún wọn gan-an nípa bí wọ́n ṣe pọ̀ sí i lọ́nà àrà tí wọ́n fi ìpín mẹ́tà-dín-lọ́gọ́jọ lórí ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i láàárín 1939 sí 1946. Yàtọ̀ síyẹn, bí wọ́n ṣe pa ìwà títọ́ wọn mọ́ lákòókò ogun yẹn túbọ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti dá ìsìn tòótọ́ mọ̀.—Aísáyà 2:2-4.
17 Kì í ṣe pé oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè bọ́ sásìkò nìkan, ó tún jẹ́ èyí tó tẹ́ni lọ́rùn dáadáa. Gbogbo bí ogun gbígbóná janjan ṣe ń lọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè nígbà Ogun Àgbáyé Kejì yẹn, ńṣe là ń rọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà láti gbájú mọ́ ohun kan tó ṣe pàtàkì ju ìgbàlà àwọn fúnra wọn lọ. Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ tó kan gbogbo àgbáyé ni ọ̀ràn ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bi ọba aláṣẹ. Ó mà mọ́kàn ẹni yọ̀ o, láti mọ̀ pé ìdúróṣinṣin ẹnì kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ní ipa díẹ̀ tó ń kó nínú dídá ipò Jèhófà láre gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ àti nínú fífihàn pé Èṣù jẹ́ òpùrọ́! (Òwe 27:11) Láìdàbí Sátánì tó fi ọ̀rọ̀ èké ba orúkọ Jèhófà àti ọ̀nà tó gbà ń ṣàkóso jẹ́, ńṣe làwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ń bá a lọ ní pípolongo ní gbangba pé: “Olódodo ni Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.”—Sáàmù 145:17.
18. Àpẹẹrẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sásìkò tó sì tẹni lọ́rùn gan-an wo la rí gbà lẹ́nu àìpẹ́ yìí?
18 Àpẹẹrẹ oúnjẹ tẹ̀mí mìíràn tó bọ́ sásìkò tó sì tẹ́ni lọ́run gan-an ni ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, èyí tá a mú jáde ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” tá a ṣe káàkiri ayé ní ọdún 2002 sí 2003. Ìwé tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ṣe tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì tẹ̀ jáde yìí, dá lórí àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jèhófà Ọlọ́run ní, títí kan àwọn tá a mẹ́nu kàn nínú Sáàmù 145. Ó dájú pé ìwé àtàtà yìí yóò kó ipa pàtàkì nínú ríran àwọn adúróṣinṣin sí Ọlọ́run lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ ọn.
Àkókò Láti Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà
19. Àkókò pàtàkì wo ló sún mọ́lé, kí ni a sì ní láti ṣe nípa rẹ̀?
19 Àkókò pàtàkì láti yanjú ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ Jèhófà ti sún mọ́lé báyìí. Gẹ́gẹ́ bí Ìsíkíẹ́lì orí 38 ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, láìpẹ́ sí àkókò yìí ni Sátánì yóò parí ipa tó ń kó gẹ́gẹ́ bí “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.” Èyí yóò kan gbígbógun ti àwọn èèyàn Jèhófà jákèjádò ayé. Sátánì yóò sa gbogbo agbára rẹ̀ láti ba ìwà títọ́ àwọn adúróṣinṣin sí Ọlọ́run jẹ́. Àwọn olùjọsìn Jèhófà ní láti ké pè é jù ti ìgbàkígbà rí lọ, kódà wọ́n ní láti bẹ̀ ẹ pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Ǹjẹ́ ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ àti ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run yóò já sí asán? Rárá o, nítorí pé Sáàmù 145 sọ pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́. Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là. Jèhófà ń ṣọ́ gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni burúkú ni òun yóò pa rẹ́ ráúráú.”—Sáàmù 145:18-20.
20. Báwo làwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 145:18-20 ṣe máa nímùúṣẹ lọ́jọ́ iwájú?
20 Ẹ wo bó ṣe máa múni lọ́kàn yọ̀ tó láti jàǹfààní sísún tí Jèhófà sún mọ́tòsí àti agbára tó ní láti dàábò boni nígbà tó bá pa gbogbo àwọn ẹni ibi rẹ́ ráúráú! Kìkì “àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́” ni Jèhófà yóò fetí sí ní àkókò pàtàkì tó ti sún mọ́lé gan-an báyìí. Ó dájú pé kò ní fetí sí àwọn alágàbàgebè. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn kedere pé pàbó ló máa ń já sí fáwọn ẹni ibi tó máa ń lo orúkọ rẹ̀ nígbà tí ẹ̀pa ò bá bóró mọ́.—Òwe 1:28, 29; Míkà 3:4; Lúùkù 13:24, 25.
21. Báwo làwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ṣe fi hàn pé inú àwọn máa ń dùn láti lo orúkọ Ọlọ́run?
21 Àkókò yìí gan-an ló túbọ̀ jẹ́ kánjúkánjú jù ti ìgbàkigbà rí lọ pé káwọn tó bẹ̀rù Jèhófà máa “ké pè é ní òótọ́.” Inú àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i máa ń dùn láti lo orúkọ rẹ̀ nínú àdúrà wọn àti nígbà tí wọ́n bá ń dáhùn làwọn ìpàdé. Wọ́n máa ń lo orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ìjíròrò wọn. Wọ́n sì máa ń fìgboyà polongo orúkọ Jèhófà nínú iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe ní gbangba.—Róòmù 10:10, 13-15.
22. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dènà ẹ̀mí ayé àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀?
22 Ohun tó tún ṣe pàtàkì fún wa láti ṣe tá a bá fẹ́ túbọ̀ máa jàǹfààní látinú àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run ni pé ká máa báa lọ ní dídènà àwọn ohun tó lè ṣèpalára fún ipò tẹ̀mí wa. Ìyẹn àwọn nǹkan bí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, eré ìnàjú tí kò bójú mu, àìní ẹ̀mí ìdáríjì, tàbí dídágunlá sí àwọn aláìní. (1 Jòhánù 2:15-17; 3:15-17) Tá a ò bá tètè wá nǹkan ṣe sí i, irú àṣà bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí dídá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, ó sì lè mú kéèyàn pàdánù ojú rere Jèhófà nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (1 Jòhánù 2:1, 2; 3:6) Ìwà ọlọ́gbọ́n gidi ló jẹ́ láti máa rántí pé Jèhófà yóò máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn sí wa kìkì tá a bá ń jẹ́ olóòótọ́ sí i.—2 Sámúẹ́lì 22:26.
23. Irú ọjọ́ iwájú alárinrin wo ló ń dúró de gbogbo àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run?
23 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa ọjọ́ ọ̀la alárinrin tó ń dúró de gbogbo àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ó máa fojú sọ́nà de àǹfààní àgbàyanu ti wíwà lára àwọn tí yóò gbé Jèhófà ga, tí wọn yóò fi ìbùkún fún un, tí wọn yóò sì máa yìn ín “láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀,” “àní títí láé.” (Sáàmù 145:1, 2) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ‘pa ara wa mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.’ (Júúdà 20, 21) Bí a ti ń bá a lọ láti jàǹfààní látinú àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Baba wa ọ̀run ní, títí kan inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tó fi hàn sáwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ǹjẹ́ kí èrò inú wa máa dà bí ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ kẹ́yìn nínú Sáàmù 145 pé: “Ẹnu mi yóò máa sọ̀rọ̀ ìyìn Jèhófà; kí gbogbo ẹran ara sì máa fi ìbùkún fún orúkọ mímọ́ rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni Sáàmù 145 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti dá àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run mọ̀?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń ‘tẹ́ ìfẹ́ ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn’?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Inú àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run máa ń dún láti jíròrò àwọn ìṣe agbára ńlá rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń fi ìgboyà ran àwọn àjèjì lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ògo ipò ọba rẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jèhófà pèsè oúnjẹ fún “gbogbo ohun alààyè”
[Credit Line]
Àwọn ẹranko: Parque de la Naturaleza de Cabárceno
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Jèhófà ń fi okun fún àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí í, tí wọ́n ń gbàdúrà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, ó sì ń tọ́ wọn sọ́nà pẹ̀lú