Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Yin Jèhófà?
“Ẹ yin Jáà! . . . Nítorí tí ó dùn mọ́ni, ìyìn yẹ ẹ́!”—SM. 147:1.
1-3. (a) Ìgbà wo ló ṣeé ṣe kí wọ́n kọ Sáàmù 147? (b) Àwọn nǹkan wo la máa kọ́ bá a ṣe ń jíròrò Sáàmù 147?
BÍ ẸNÌ kan bá ṣe iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un lọ́nà tó wúni lórí tàbí tó bá hùwà ọmọlúàbí, a máa ń gbóríyìn fún un. Tá a bá ní láti gbóríyìn fún àwọn èèyàn torí pé wọ́n ṣe dáadáa, ǹjẹ́ kò yẹ ká yin Jèhófà, Ọlọ́run wa? Ó yẹ ká yin Ọlọ́run torí agbára rẹ̀ tó kàmàmà, a sì rí èyí nínú àwọn nǹkan àgbàyanu tó dá. A tún lè yìn ín torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, pàápàá bó ṣe rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé kó lè rà wá pa dà.
2 Ẹni tó kọ Sáàmù kẹtàdínláàádọ́jọ [147] yin Jèhófà torí àwọn ohun ribiribi tó ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún rọ àwọn míì pé kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ òun láti yin Ọlọ́run.—Ka Sáàmù 147:1, 7, 12.
3 A ò mọ ẹni tó kọ Sáàmù yìí, àmọ́ ó jọ pé ìgbà tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ nígbèkùn Bábílónì tí wọ́n sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù ni onísáàmù náà gbáyé. (Sm. 147:2) Bí Jèhófà ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kí wọ́n lè pa dà máa jọ́sìn rẹ̀ wú onísáàmù náà lórí, ìyẹn ló sì mú kó máa yin Jèhófà. Kò mọ síbẹ̀, ó tún sọ àwọn ìdí míì tó fi yẹ ká yin Jèhófà. Kí làwọn ìdí náà? Kí nìdí tó fi yẹ kí ìwọ náà máa yin Jáà?—Sm. 147:1.
JÈHÓFÀ MÁA Ń TU ÀWỌN TÓ NÍ Ẹ̀DÙN ỌKÀN NÍNÚ
4. Báwo ló ṣe rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn nígbà tí Ọba Kírúsì dá wọn nídè? Kí nìdí tí inú wọn fi dùn?
4 Ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé àwọn wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì. Àwọn tó mú wọn lẹ́rú ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Ẹ kọ ọ̀kan lára àwọn orin Síónì fún wa.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò rí ìdí tí wọ́n fi máa kọrin torí pé Jerúsálẹ́mù tí wọ́n ti máa ń yin Jèhófà ti di ahoro. (Sm. 137:1-3, 6) Ọkàn wọn gbọgbẹ́, torí náà wọ́n nílò ìtùnú gan-an. Àmọ́, bí Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀, Kírúsì ọba Páṣíà dá wọn nídè lẹ́yìn tó ṣẹ́gun Bábílónì. Kírúsì kéde pé: “Jèhófà . . . ti fàṣẹ yàn mí pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù . . . Ẹnì yòówù tí ń bẹ láàárín yín nínú gbogbo ènìyàn rẹ̀, kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí náà, kí ó gòkè lọ.” (2 Kíró. 36:23) Ó dájú pé inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé ní Bábílónì máa dùn gan-an láti gbọ́ pé àwọn máa tó pa dà sílùú àwọn.
5. Kí ni onísáàmù náà sọ pé Jèhófà máa ń ṣe tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn?
5 Bí Jèhófà ṣe ń tu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú lápapọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ń tù wọ́n nínú lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ohun kan náà ló ń ṣe lónìí. Bí àpẹẹrẹ, onísáàmù náà sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ó ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.” (Sm. 147:3) Ó ṣe kedere pé Jèhófà máa ń ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́, yálà ẹ̀dùn ọkàn ni wọ́n ní tàbí ìṣòro míì. Lónìí, ó máa ń wu Jèhófà láti tù wá nínú, pàápàá nígbà tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn. (Sm. 34:18; Aísá. 57:15) Ó sì máa ń fún wa ní ọgbọ́n àti okun tá a nílò ká lè fara da àwọn ìṣòro wa.—Ják. 1:5.
6. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí onísáàmù náà sọ nínú Sáàmù 147:4? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
6 Ẹ̀yìn ìyẹn ni onísáàmù náà wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìràwọ̀ tí Jèhófà dá sójú ọ̀run, ó sì sọ pé Jèhófà “ka iye àwọn ìràwọ̀” àti pé “gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ wọn pè.” (Sm. 147:4) Kí nìdí tí onísáàmù náà fi yí àfíyèsí wa sójú ọ̀run? Jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Onísáàmù náà máa ń rí àwọn ìràwọ̀ tó pọ̀ lọ súà, àmọ́ kò mọ iye wọn. Lásìkò tiwa yìí, ó ti ṣeé ṣe fún wa láti rí àwọn ìràwọ̀ tó pọ̀ ju èyí tí onísáàmù náà rí lọ. Àwọn kan sọ pé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìràwọ̀ ló wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way nìkan. Tá a bá sì ní ká máa ka iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà, wọn ò lóǹkà! Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò sẹ́ni tó mọ iye ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run! Àmọ́, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé Ọlọ́run fún gbogbo wọn pátá ní orúkọ. Èyí túmọ̀ sí pé Jèhófà mọ àwọn ìràwọ̀ náà lọ́kọ̀ọ̀kan. (1 Kọ́r. 15:41) Tí Jèhófà bá mọ ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan, àwa èèyàn tó dá sáyé ńkọ́? Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run mọ ibi tí ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan wà. Torí náà, ó mọ àwa náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó mọ ibi tí kálukú wa wà, ó mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa gan-an, ó sì mọ ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa nílò nígbàkigbà!
7, 8. (a) Kí ni Jèhófà mọ̀ nípa wa? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé Jèhófà máa ń fìfẹ́ bójú tó wa.
7 Yàtọ̀ sí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó tún mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa, ó sì lágbára láti ràn wá lọ́wọ́ tá a bá wà nínú ìṣòro. (Ka Sáàmù 147:5.) Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ìṣòro rẹ ti wọ̀ ẹ́ lọ́rùn, tàbí pé àwọn ìṣòro náà kọjá agbára rẹ. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run mọ ibi tágbára rẹ mọ, ‘ó rántí pé ekuru ni ẹ́.’ (Sm. 103:14) Torí pé a jẹ́ aláìpé, a lè máa ṣe àṣìṣe kan náà léraléra. Ẹ wo bó ṣe máa ń dùn wá tó tá a bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ tàbí tá a gbaná jẹ lórí ohun tí kò tó nǹkan, ó sì lè jẹ́ pé ṣe la máa ń jowú àwọn míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kì í ṣàṣìṣe, síbẹ̀ ó mọ bó ṣe máa ń rí lára wa tá a bá ṣàṣìṣe, òye tó ní kò ṣeé díwọ̀n, kódà kò sí àwárí òye rẹ̀!—Aísá. 40:28.
8 Ó ṣeé ṣe kó o rántí ìgbà tí Jèhófà fi ọwọ́ agbára rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o wà nínú ìṣòro. (Aísá. 41:10, 13) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Kyoko tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá a lẹ́yìn tí ètò Ọlọ́run rán an lọ sìn ní ibòmíì. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun lóye ìṣòro rẹ̀? Níbi tí Kyoko wà, àwọn ará fìfẹ́ hàn sí i torí wọ́n mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀. Kyoko sọ pé ṣe ló dà bíi pé Jèhófà ń sọ fún òun pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ, kì í ṣe torí pé o jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ torí pé o jẹ́ ọmọ mi ọ̀wọ́n, o sì ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún mi. Mi ò fẹ́ kó o banú jẹ́, ohun tí mo fẹ́ ni pé kó o máa láyọ̀ pé Ẹlẹ́rìí mi ni ọ́!” Ìwọ ńkọ́, kí ni Jèhófà ti ṣe láyé rẹ tó fi hàn pé “òye rẹ̀ ré kọjá ríròyìn lẹ́sẹẹsẹ”?
JÈHÓFÀ Ń FÚN WA LÁWỌN OHUN TÁ A NÍLÒ
9, 10. Kí ni Jèhófà kọ́kọ́ máa ń pèsè fún wa? Sọ àpẹẹrẹ kan.
9 Gbogbo wa pátá la nílò oúnjẹ, aṣọ àti ilé tá a máa gbé. Nígbà míì, o lè máa ṣàníyàn nípa ọ̀rọ̀ àtijẹ àtimu. Àmọ́, rántí pé Jèhófà ló dá oòrùn, òjò àtàwọn nǹkan míì tó ń mú kí irè oko hù, òun náà ló sì mú kí oúnjẹ wà fún àwọn nǹkan tó ṣẹ̀dá, títí kan àwọn ọmọ ẹyẹ. (Ka Sáàmù 147:8, 9.) Níwọ̀n bí Jèhófà ti ń bójú tó àwọn ọmọ ẹyẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó máa pèsè gbogbo ohun tó o nílò.—Sm. 37:25.
10 Ohun tó ṣe pàtàkì jù tí Jèhófà máa ń pèsè fún wa làwọn nǹkan tá a nílò nípa tẹ̀mí, èyí sì máa ń mú ká ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílí. 4:6, 7) Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Mutsuo àti ìyàwó rẹ̀. Jèhófà fún wọn lókun nígbà tí àkúnya omi kan ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Japan lọ́dún 2011. Omi yẹn ì bá gbé wọn lọ tí kì í bá ṣe pé wọ́n gun orí ilé wọn. Àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo nǹkan tí wọ́n ní lomi gbé lọ. Inú yàrá kan tó ṣókùnkùn tó sì tutù rinrin ní àjà kejì ilé wọn ni wọ́n wà mọ́jú. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n wá gbogbo inú ilé náà kí wọ́n lè rí ohun tó máa tù wọ́n nínú, wọ́n sì rí Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2006. Bí wọ́n ti ń ṣí ìwé náà, Mutsuo rí àkòrí kan tá a pè ní “The Deadliest Tsunamis Ever Recorded,” ìyẹn Àkúnya Omi Tó Tíì Burú Jù Láyé. Ìwé yẹn sọ nípa ìmìtìtì kan tó ṣẹlẹ̀ nílùú Sumatra lọ́dún 2004, tó sì mú kí àkúnya omi tó burú jù lọ ṣẹlẹ̀. Ṣe ni omijé ń dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú Mutsuo àti ìyàwó rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ka ìrírí yẹn. Ó ṣe wọ́n bíi pé Jèhófà fìfẹ́ gbá wọn mọ́ra tó sì fún wọn ní ìṣírí tí wọ́n nílò lásìkò yẹn gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún pèsè ohun tí wọ́n nílò nípa tara. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin fún wọn láwọn ohun tí wọ́n nílò. Àmọ́ ohun tó fún wọn lókun jù lọ ni bí àwọn aṣojú ètò Ọlọ́run ṣe wá bẹ ìjọ wọn wò tí wọ́n sì fún wọn níṣìírí. Arákùnrin Mutsuo sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé Jèhófà dúró ti ọ̀kọ̀ọ̀kan wa, tó sì ń tọ́jú wa. Ara sì tù mí pẹ̀sẹ̀!” Ó ṣe kedere pé àwọn nǹkan tẹ̀mí ni Jèhófà kọ́kọ́ máa ń pèsè fún wa, lẹ́yìn náà ló máa ń pèsè àwọn ohun tá a nílò nípa tara.
JẸ́ KÍ ỌLỌ́RUN DÁ Ẹ́ NÍDÈ
11. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dá wa nídè?
11 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kò sì sì ìgbà tí kò lè ràn wá lọ́wọ́. Kódà, ó máa “ń mú ìtura bá àwọn ọlọ́kàn tútù.” (Sm. 147:6a) Àmọ́ báwo la ṣe lè rí ìtura yìí gbà? Ó ṣe pàtàkì pé ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Tá a bá máa nírú àjọṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ọlọ́kàn tútù. (Sef. 2:3) Àwọn ọlọ́kàn tútù gbà pé Ọlọ́run máa gbèjà àwọn lásìkò tó tọ́, á sì dá wọn nídè lọ́wọ́ ìyà tó ń jẹ wọ́n. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń múnú Jèhófà dùn gan-an.
12, 13. (a) Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká yẹra fún tá a bá fẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́? (b) Àwọn wo ni inú Jèhófà máa ń dùn sí?
12 Bákan náà, Ọlọ́run máa ń “rẹ àwọn ẹni burúkú wá sí ilẹ̀.” (Sm. 147:6b) Ó dájú pé a ò fẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, àbí? Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa títí ayé, tá ò sì fẹ́ kó bínú sí wa, ó yẹ ká kórìíra ohun tó kórìíra. (Sm. 97:10) Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ kórìíra ìṣekúṣe. Ìyẹn túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tó lè mú ká ṣe ìṣekúṣe, kódà a ò gbọ́dọ̀ wo ìwòkuwò. (Sm. 119:37; Mát. 5:28) Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, àmọ́ gbogbo ohun tá a bá ṣe ká lè rí ojúure Jèhófà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.
13 Àmọ́ o, ká tó lè ja ìjà yìí ní àjàṣẹ́gun, ó ṣe pàtàkì pé ká gbára lé Jèhófà, kì í ṣe ara wa. Ṣé a rò pé inú Jèhófà máa dùn tá a bá gbára lé “agbára ńlá tí ẹṣin ní,” ìyẹn ibi táwọn èèyàn ń yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́? Ó dájú pé inú rẹ̀ kò ní dùn. Bákan náà, kò yẹ ká gbára lé “ẹsẹ̀ ènìyàn,” ká máa ṣe bíi pé àwa tàbí àwọn míì lè dá wa nídè. (Sm. 147:10) Dípò tá a fi máa ṣèyẹn, ṣe ló yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Jèhófà ò dà bí àwa èèyàn, kò sí iye ìgbà tá a bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ tí kì í gbọ́ wa torí pé ọ̀rọ̀ wa kì í sú u. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ní ìdùnnú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, sí àwọn tí ń dúró de inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.” (Sm. 147:11) Torí pé ìfẹ́ Jèhófà kì í yẹ̀, ó dá wa lójú pé Jèhófà á dúró tì wá, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ohun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀.
14. Kí ló dá onísáàmù lójú?
14 Jèhófà mú kó dá wa lójú pé òun máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ní ìṣòro. Nígbà tí onísáàmù náà ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ó sọ pé: “Nítorí pé ó ti sọ ọ̀pá ìdábùú àwọn ẹnubodè rẹ di alágbára; ó ti bù kún àwọn ọmọ rẹ ní àárín rẹ. Ó fi àlàáfíà sí ìpínlẹ̀ rẹ.” (Sm. 147:13, 14) Ó dájú pé ọkàn onísáàmù náà máa balẹ̀ pé Jèhófà á dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀!
15-17. (a) Báwo ni ìṣòro wa ṣe máa ń rí lára wa nígbà míì, àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan nípa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe máa ń yára kánkán.
15 Àwọn ìṣòro rẹ lè mú kó o máa ṣàníyàn. Àmọ́ jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa fún ẹ lọ́gbọ́n táá jẹ́ kó o fara dà á. Onísáàmù náà sọ nípa Ọlọ́run pé, “ó ń fi àsọjáde rẹ̀ ránṣẹ́ sí ilẹ̀ ayé; ìyára kánkán ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ń sáré.” Ó tún sọ pé Jèhófà máa ń ‘fúnni ní ìrì dídì, ó ń tú ìrì dídì wínníwínní ká, ó sì ń ju omi dídì.’ Lẹ́yìn náà ló béèrè pé: “Ta ní lè dúró níwájú òtútù rẹ̀?” Ó tún wá sọ pé Jèhófà ń “rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde, ó sì ń yọ́ wọn.” (Sm. 147:15-18) Jèhófà Ọlọ́run wa ló lágbára jù lọ láyé àtọ̀run, òun ló sì gbọ́n jù, òun ló ń darí ìrì dídì tàbí yìnyín. Torí náà, ìṣòro yòówù ká ní, Jèhófà lágbára láti bá wa ṣẹ́gun wọn, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀.
16 Lónìí, Jèhófà ń tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. “Ìyára kánkán ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ń sáré” ní ti pé ó máa ń tọ́ wa sọ́nà ní gbogbo ìgbà tá a bá nílò rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, à ń jàǹfààní gan-an bá a ṣe ń ka Bíbélì àtàwọn ìwé tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń ṣe jáde. A tún ń jàǹfààní bá a ṣe ń wo Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW, tá à ń lọ sórí ìkànnì jw.org, tá à ń bá àwọn alàgbà sọ̀rọ̀ àti nígbà tá a bá wà pẹ̀lú àwọn ará wa. (Mát. 24:45) Ṣé ìwọ náà kíyè sí i pé Jèhófà tètè máa ń fún wa láwọn ìtọ́sọ́nà tá a nílò lásìkò?
17 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Simone gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára gan-an. Ìgbà kan wà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bò ó mọ́lẹ̀ débi tó fi ronú pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ irú èèyàn bíi tòun. Àmọ́ ní gbogbo àsìkò yẹn, kò yé gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ran òun lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Ó sọ pé, “Kò sígbà tí mi kì í rọ́wọ́ Jèhófà láyé mi, ó máa ń tọ́ mi sọ́nà, ó sì máa ń fún mi lókun.” Ohun tó ràn án lọ́wọ́ nìyẹn tó fi ń láyọ̀.
18. Kì nìdí tó o fi gbà pé Jèhófà dá ẹ lọ́lá, kí sì nìdí tó fi yẹ kó o máa “yin Jáà”?
18 Onísáàmù náà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì gan-an. Àwọn nìkan ni Ọlọ́run fún ní “ọ̀rọ̀” rẹ̀ àtàwọn “ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀.” (Ka Sáàmù 147:19, 20.) Lóde òní, Jèhófà dá wa lọ́lá ní ti pé àwa nìkan là ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọn. Torí pé a mọ Jèhófà, a sì ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà, a ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Bíi ti ẹni tó kọ Sáàmù 147, ǹjẹ́ àwa náà ní ìdí tó pọ̀ láti máa “yin Jáà,” ká sì máa rọ àwọn míì pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?