“O Mu Mi Lọ si Iha Omi Dikakẹ Rọ́rọ́”
NÍ ÀWỌN ilẹ̀ olóoru tí Bíbélì mẹ́nu kàn, àwọn àgùntàn gbọ́dọ̀ máa mu omi lójoojúmọ́. Ìdí rèé tí fífún àwọn àgùntàn lómi fi jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Nígbà míì, inú kànga làwọn olùṣọ́ ti máa ń pọn omi fún agbo ẹran wọn, wọ́n á pọn omi náà sínú ọpọ́n, àwọn àgùntàn á sì máa mu ún níbẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 29:1-3) Àmọ́, tó bá dìgbà òjò, àwọn àgbègbè tí omi wà tàbí tí odò wà máa ń ní “àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa.”—Sáàmù 23:2.
Olùṣọ́ àgùntàn tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ gbọ́dọ̀ mọ ibi tó ti máa rí omi fún agbo àgùntàn rẹ̀ mu àti koríko tí wọ́n á jẹ. Mímọ̀ tó bá mọ àgbègbè kan dunjú ló máa mú káwọn àgùntàn rẹ̀ róúnjẹ jẹ. Dáfídì tó fi ọ̀pọ̀ ọdún tọ́jú àgùntàn lórí àwọn òkè Jùdíà, fi ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nípa tẹ̀mí wé bí olùṣọ́ àgùntàn kan ṣe ń kó àwọn àgùntàn rẹ̀ lọ jẹ̀ níbi tí wọ́n á ti rí koríko tútù yọ̀yọ̀, tí wọ́n á sì rí omi mu kí wọ́n lè wà láàyè. Bíbélì kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ Dáfídì báyìí: “O mu mi lọ si iha omi dikakẹ rọ́rọ́.”—Sáàmù 23:1-3, Bibeli Mimọ.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà tún gba ẹnu wòlíì Ìsíkíẹ́lì lo irú àkàwé kan náà. Ó ṣèlérí pé òun á kó àwọn èèyàn òun jọ láti ilẹ̀ tá a fọ́n wọn ká sí, gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń kó àwọn àgùntàn rẹ̀ jọ. Ó fi dá wọn lójú pé: “Èmi yóò mú . . . wọn wá sórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò sì bọ́ wọn ní orí àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì, lẹ́bàá àwọn ojú ìṣàn omi.”—Ìsíkíẹ́lì 34:13.
Pípèsè omi tẹ̀mí jẹ Jèhófà Ọlọ́run lógún púpọ̀púpọ̀. Ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe “odò omi ìyè kan” tó ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run. (Ìṣípayá 22:1) Gbogbo èèyàn la sì ké sí láti wá mu nínú omi yìí. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ [lè] gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìṣípayá 22:17.
Omi ìyè ìṣàpẹẹrẹ yìí dúró fún àwọn ètò tí Ọlọ́run ti ṣe fún ìwàláàyè títí láé. Ẹnikẹ́ni lè bẹ̀rẹ̀ sí mu nínú omi náà nípa ‘gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ó rán jáde, Jésù Kristi.’—Jòhánù 17:3.