“Ta Ni Èmi Yóò Ní Ìbẹ̀rùbojo Fún?”
“Bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò ní ìgbẹ́kẹ̀lé.” —SM. 27:3.
BÍ ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ ṢE SỌ, KÍ LÓ LÈ MÚ KÓ O NÍ ÌGBOYÀ?
1. Àwọn ìbéèrè wo ni Sáàmù 27 máa jẹ́ ká rí ìdáhùn sí?
KÍ NÌDÍ tí iṣẹ́ ìwàásù wa fi ń gbòòrò sí i bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni ipò àwọn nǹkan túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé? Kí nìdí tá a fi ń fínnú fíndọ̀ lo àkókò àti okun wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò ọrọ̀ ajé kò fara rọ fún ọ̀pọ̀ èèyàn? Báwo la ṣe lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ onígboyà nígbà tí ẹ̀rù ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú orin kan tí Ọlọ́run mí sí Dáfídì Ọba láti kọ, èyí tó wà nínú Sáàmù 27.
2. Kí ni ìbẹ̀rùbojo máa ń ṣe fúnni, àmọ́ kí ló dá wa lójú?
2 Nígbà tí Dáfídì bẹ̀rẹ̀ orin tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ yìí, ó sọ pé: “Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi. Ta ni èmi yóò bẹ̀rù? Jèhófà ni odi agbára ìgbésí ayé mi. Ta ni èmi yóò ní ìbẹ̀rùbojo fún?” (Sm. 27:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbẹ̀rù lásán lè mú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í káàárẹ̀, ohun tí ìbẹ̀rùbojo ń ṣe fúnni tún wá burú ju ìyẹn lọ. Àmọ́, kò sí ìbẹ̀rùbojo èyíkéyìí tó gbọ́dọ̀ mú kí àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà máa mikàn. (1 Pét. 3:14) Tá a bá fi Jèhófà ṣe odi agbára wa, a ó ‘máa gbé nínú ààbò, a ó sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.’ (Òwe 1:33; 3:25) Kí nìdí?
“JÈHÓFÀ NI ÌMỌ́LẸ̀ MI ÀTI ÌGBÀLÀ MI”
3. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ ìmọ́lẹ̀ wa, àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
3 Àfiwé náà, “Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi” mú ká rántí pé Jèhófà ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àìmọ̀kan ó sì ti jẹ́ ká lóye òtítọ́. (Sm. 27:1) Ìmọ́lẹ̀ lè jẹ́ ká rí ewu tàbí ohun ìkọ̀sẹ̀ tó bá wà lójú ọ̀nà wa, àmọ́ kò lè bá wa mú un kúrò. Ó pọn dandan ká hùwà ọgbọ́n nípa sísá fún irú ewu bẹ́ẹ̀. Bákan náà, Jèhófà máa ń jẹ́ ká lóye àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. Ó sì máa ń kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ewu tó wà nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ó ń fún wa ní àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ń ràn wá lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà, àmọ́ ká tó lè jàǹfààní látinú àwọn ìlànà náà, a gbọ́dọ̀ máa fi wọ́n sílò. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè máa fọgbọ́n hùwà ju àwọn ọ̀tá wa tàbí àwọn olùkọ́ wa lọ.—Sm. 119:98, 99, 130.
4. (a) Kí nìdí tí Dáfídì fi lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé: “Jèhófà ni . . . ìgbàlà mi”? (b) Ìgbà wo gan-an ni Jèhófà máa gbà wá là?
4 Ohun tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 27:1 fi hàn pé ó ti ní láti rántí bí Jèhófà ṣe dá a nídè, tàbí bó ṣe gbà á sílẹ̀ láwọn ìgbà kan. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti dá a nídè kúrò “ní àtẹ́sẹ̀ kìnnìún . . . àti kúrò ní àtẹ́sẹ̀ béárì.” Jèhófà tún mú kó ṣẹ́gun òmìrán náà, Gòláyátì. Nígbà tó ṣe, Sọ́ọ̀lù Ọba gbìyànjú láti fi ọ̀kọ̀ gún Dáfídì pa, àmọ́ gbogbo ìgbà tí Sọ́ọ̀lù gbìyànjú rẹ̀ ni Jèhófà dá a nídè. (1 Sám. 17:37, 49, 50; 18:11, 12; 19:10) Abájọ tí Dáfídì fi lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé: “Jèhófà ni . . . ìgbàlà mi”! Bí Jèhófà ṣe jẹ́ ìgbàlà fún Dáfídì náà ló ṣe máa jẹ́ ìgbàlà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Lọ́nà wo? Nípa gbígba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ là nígbà “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀.—Ìṣí. 7:14; 2 Pét. 2:9.
MÁA RÁNTÍ ÀWỌN ÀṢEYỌRÍ TÓ O TI ṢE
5, 6. (a) Báwo ni ohun tá à ń rántí ṣe máa ń mú ká ní ìgboyà? (b) Báwo ni àkọsílẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò ṣe mú kó o túbọ̀ jẹ́ onígboyà?
5 Ìwé Sáàmù 27:2, 3 mẹ́nu kan kókó pàtàkì kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní ìgboyà. (Kà á.) Dáfídì rántí bí Jèhófà ṣe dá a nídè nígbà tí àwọn ohun kan ṣẹlẹ̀ sí i. (1 Sám. 17:34-37) Àwọn ohun tó rántí yẹn mú kó ní ìgboyà tó pọ̀, ìyẹn sì jẹ́ kó lè fàyà rán àwọn ìpọ́njú tó le koko pàápàá. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ìwọ náà bíi ti Dáfídì bó o bá rántí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ? Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o ti gbàdúrà kíkankíkan rí nípa ìṣòro kan tó mu ẹ́ lómi tó o sì wá rí bí Jèhófà ṣe fún ẹ ní ọgbọ́n àti okun láti kojú ìṣòro náà? Àbí o lè rántí bí Jèhófà ṣe bá ẹ mú àwọn nǹkan tó máa ń ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀ tó ò ń ṣe kúrò tàbí bí ilẹ̀kùn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i ṣe ṣí sílẹ̀ fún ẹ? (1 Kọ́r. 16:9) Tó o bá rántí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀, ipa wo ló máa ní lórí rẹ? Ǹjẹ́ irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í mú kó o gbà pé Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn ohun ìdènà tàbí ìpọ́njú tó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ tàbí kó o lè fara dà wọ́n?—Róòmù 5:3-5.
6 Bí ìjọba kan tó lágbára bá gbìmọ̀ láti pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà run lódindi ńkọ́? Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ti gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ lóde òní, àmọ́ wọ́n ti kùnà. Tá a bá rántí bí Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́, ìyẹn ò ní jẹ́ kí àwọn nǹkan tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú máa bà wá lẹ́rù.—Dán. 3:28.
MỌRÍRÌ ÌJỌSÌN MÍMỌ́
7, 8. (a) Kí ni Dáfídì béèrè lọ́wọ́ Jèhófà nínú Sáàmù 27:4? (b) Kí ni tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jèhófà, báwo làwọn èèyàn sì ṣe ń sin Ọlọ́run níbẹ̀?
7 Ohun pàtàkì míì tó tún lè mú ká máa fi ìgboyà ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ni pé ká ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ìsìn tòótọ́. (Ka Sáàmù 27:4.) Nígbà tí Dáfídì wà láyé, àgọ́ ìjọsìn ni “ilé Jèhófà.” Dáfídì fúnra rẹ̀ ló ṣètò bí Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ṣe máa kọ́ tẹ́ńpìlì arabarìbì kan fún Jèhófà. Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, Jésù jẹ́ kó di mímọ̀ pé kò ní pọn dandan mọ́ pé kí ẹnì kan lọ síbi ìjọsìn kíkàmàmà kan tó ní ìbùkún Ọlọ́run kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn rẹ̀. (Jòh. 4:21-23) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó ṣe kedere nínú Hébérù orí 8 sí 10 pé tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí kan bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, tó sì yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Héb. 10:10) Tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí yìí ni ètò tí Jèhófà ti ṣe ká bàa lè máa tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù tọ Ọlọ́run lọ lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà. Báwo la ṣe ń jọ́sìn Jèhófà níbẹ̀? A lè máa jọ́sìn Jèhófà níbẹ̀ tá a bá ń gbàdúrà “pẹ̀lú ọkàn-àyà tòótọ́ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ti ìgbàgbọ́”; tá a bá ń polongo ìrètí wa ní gbangba láìmikàn; tá à ń gba ti àwọn tá a jọ jẹ́ ará rò, tá à ń ru ara wa sókè, tá a sì ń fún ara wa níṣìírí nígbà tá a bá pé jọ pọ̀ láwọn ìpàdé ìjọ wa àti nígbà tá a bá ń ṣe ìjọsìn ìdílé. (Héb. 10:22-25) Ìmọrírì tá a ní fún ìjọsìn tòótọ́ á máa fún wa lókun ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko yìí.
8 Kárí ayé, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ń ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, wọ́n ń kọ́ èdè tuntun, wọ́n sì ń lọ sìn ní àwọn àgbègbè tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Wọ́n ń fi hàn pé àwọn dà bí onísáàmù náà tó béèrè fún ohun kan lọ́wọ́ Jèhófà. Wọ́n fẹ́ láti máa jẹ̀gbádùn adùn Jèhófà, kí wọ́n sì máa lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìsìn mímọ́ rẹ̀ láìka ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀ sí.—Ka Sáàmù 27:6.
NÍ ÌGBẸ́KẸ̀LÉ PÉ ỌLỌ́RUN LÈ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́
9, 10. Kí ni ìtumọ̀ ohun tí Jèhófà mú kó dá wa lójú nínú Sáàmù 27:10?
9 Láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀, Dáfídì sọ bó ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó pé Jèhófà lè ran òun lọ́wọ́. Ó ní: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sm. 27:10) A lè rí i látinú ohun tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì orí 22 pé àwọn òbí Dáfídì kò pa á tì. Àmọ́, lóde òní ọ̀pọ̀ èèyàn ni ìdílé wọn ti kọ̀ sílẹ̀ pátápátá, síbẹ̀ wọ́n ń fara dà á. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti pa tì bẹ́ẹ̀ ti rí ìrànlọ́wọ́ àti ààbò nínú ìjọ Kristẹni táwọn ará ti ń fi ìfẹ́ hàn.
10 Níwọ̀n bí Jèhófà ti ṣe tán láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà tí àwọn míì bá kọ̀ wọ́n sílẹ̀, ṣé kò wá ní mú ẹsẹ̀ wọn dúró bí wọ́n bá bá ara wọn nínú irú ìpọ́njú èyíkéyìí mìíràn? Bí àpẹẹrẹ, bí a bá ń ṣàníyàn nípa bí a ó ṣe máa pèsè jíjẹ, mímu, aṣọ àti ibùgbé fún ìdílé wa, ṣé kò yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́? (Héb. 13:5, 6) Ó mọ ipò tí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ wà, ó sì mọ àwọn nǹkan tí wọ́n ṣaláìní.
11. Báwo ni ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Jèhófà ṣe lè nípa lórí àwọn míì. Ṣàpèjúwe.
11 Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Victoria, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lórílẹ̀-èdè Làìbéríà. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe ń tẹ̀ síwájú tó sì ń sún mọ́ bèbè àtiṣe ìrìbọmi, ọkùnrin tí wọ́n jọ ń gbé já òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jù sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò nílé lórí, kò sì níṣẹ́ lọ́wọ́, ó ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn tí Victoria ti ṣèrìbọmi, ọmọbìnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá, rí pọ́ọ̀sì kan tí owó kún inú rẹ̀ he. Kí wọ́n lè yẹra fún ìdẹwò, wọ́n pinnu pé àwọn ò ní ka owó náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n yára kàn sí sójà tó ni pọ́ọ̀sì náà. Sójà náà sọ fún wọn pé bí gbogbo èèyàn bá jẹ́ olóòótọ́ bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gbogbo ayé á sàn ju bó ṣe wà yìí lọ àlàáfíà á sì túbọ̀ jọba. Victoria fi ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ayé tuntun han sójà náà nínú Bíbélì. Ìwà ìṣòtítọ́ Victoria wọ sójà náà lọ́kàn gan-an ni, ó sì fún Victoria ní ẹ̀bùn tó jọjú lára owó tó bá a rí náà. Dájúdájú, ìgbàgbọ́ tó dájú tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní pé Jèhófà lè pèsè ohun táwọn ṣaláìní ti mú kí wọ́n ṣe orúkọ rere fún ara wọn gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ èèyàn.
12. Kí là ń fi hàn tá a bá ń bá a nìṣó láti máa sin Jèhófà bí a bá tilẹ̀ pàdánù àwọn nǹkan tara? Ṣàpèjúwe.
12 O sì tún lè ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí lára Thomas, akéde kan tí kò tíì ṣèrìbọmi, ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ girama kan, àmọ́ ó tó ọdún kan tí kò fi rí owó oṣù rẹ̀ gbà, torí pé iṣẹ́ ò tíì parí lórí ìwé tí wọ́n máa fi gbé owó rẹ̀ jáde. Kí ni ohun tó gbẹ̀yìn tí wọ́n béèrè pé kí Thomas ṣe kó tó lè gba owó oṣù rẹ̀ àti owó tí wọ́n ti jẹ ẹ́ sẹ́yìn? Alákòóso ilé ẹ̀kọ́ náà tó jẹ́ àlùfáà máa fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò. Àlùfáà náà sọ pé ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò bá ti ilé ẹ̀kọ́ náà mu. Ó wá fi àáké kọ́rí pé àfi kí Thomas yan èyí tó fẹ́ láàárín iṣẹ́ rẹ̀ àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó bá Bíbélì mu. Thomas ní láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, kò sì rí owó iṣẹ́ ọdún kan tó ti ṣe gbà. Àmọ́, ó rí iṣẹ́ míì. Ó ń tún rédíò àti tẹlifóònù alágbèéká ṣe. Bí àpẹẹrẹ yìí àti ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ mìíràn tó jọ ọ́ ṣe fi hàn, ó lè jẹ́ pé ẹ̀rù àtijẹ àtimu ló ń ba àwọn míì, ṣùgbọ́n ìyẹn ò tó nǹkan tá a bá fi wé ìgbẹ́kẹ̀lé tó jinlẹ̀ tá a ní nínú Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo tó máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.
13. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń tẹ̀ síwájú ní àwọn ilẹ̀ tí àwọn nǹkan ìní tara ti ṣọ̀wọ́n?
13 Àwọn tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run sábà máa ń wà lẹ́nu iṣẹ́ pẹrẹu ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tí àtijẹ àtimu àti ọ̀rọ̀ ibùgbé ti ṣòro. Kí ló fà á tí ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Ẹ̀ka ọ́fíìsì kan kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́, torí náà, wọ́n ní àkókò púpọ̀ sí i láti fi kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ àárọ̀ tàbí lọ́sàn-án. Àwọn ará náà tún ní àkókò púpọ̀ sí i láti fi wàásù. Kò sì dìgbà tá a sọ fáwọn èèyàn láwọn ibi tí nǹkan ti burú jáì pé à ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn; àwọn fúnra wọ́n rí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wọn.” Míṣọ́nnárì kan tó ti ń sìn fún ohun tó lé ní ọdún méjìlá ní orílẹ̀-èdè kan tí olúkúlùkù akéde ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́tà, ó kéré tán, sọ pé: “Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn akéde ti ń gbé ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ, tí kò sì sí ìpínyà ọkàn tó pọ̀ fún wọn, wọ́n sábà máa ń ní àkókò púpọ̀ sí i láti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”
14. Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá lè gbà rí ààbò Ọlọ́run?
14 Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn òun lápapọ̀, òun máa dáàbò bò wọ́n, òun sì máa dá wọn nídè nípa tara àti nípa tẹ̀mí, a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ohun tó sọ. (Sm. 37:28; 91:1-3) Ó dájú pé ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí yóò la “ìpọ́njú ńlá náà” já máa pọ̀ gan-an ni. (Ìṣí. 7:9, 14) Torí náà, Ọlọ́run máa dáàbò bo ogunlọ́gọ̀ èèyàn yẹn lódindi kí wọ́n má bàa pa run ní èyí tó kù kí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí parí. Ọlọ́run máa fún wọn ní gbogbo nǹkan tí wọ́n nílò láti lè fara da àdánwò kí ohunkóhun má sì ba àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Jèhófà sì máa dáàbò àwọn èèyàn rẹ̀ jálẹ̀ apá tó kẹ́yìn ìpọ́njú ńlá náà.
“JÈHÓFÀ, FÚN MI NÍ ÌTỌ́NI NÍ Ọ̀NÀ RẸ”
15, 16. Báwo la ṣe ń jàǹfààní tá a bá ń ṣègbọràn sí ìtọ́ni Ọlọ́run? Ṣàpèjúwe.
15 Ká lè máa jẹ́ onígboyà, ó pọn dandan pé ká jẹ́ kí Ọlọ́run máa bá a nìṣó láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Èyí ṣe kedere nínú ẹ̀bẹ̀ Dáfídì pé: “Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni ní ọ̀nà rẹ, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán ní tìtorí àwọn ọ̀tá mi.” (Sm. 27:11) Ká bàa lè máa hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà yìí, a gbọ́dọ̀ máa fara balẹ̀ kíyè sí ìtọ́ni èyíkéyìí tá a gbé karí Bíbélì, èyí tá a bá rí gbà nípasẹ̀ ètò Jèhófà ká sì fi í sílò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Láwọn ìgbà tí ètò ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ti sá fún jíjẹ gbèsè láìnídìí lè jẹ́rìí sí i pé bí wọ́n ṣe fi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n náà sílò pé kí wọ́n má ṣe kó ohun ìní jọ ti ṣe wọ́n láǹfààní. Dípò kí wọ́n kó àwọn nǹkan ìní tí wọn kò nílò sọ́wọ́, wọ́n tà wọ́n kí wọ́n lè san gbèsè tó wà lọ́rùn wọn, wọ́n sì ní àǹfààní láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Torí náà, ó dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ mo tètè máa ń fi gbogbo ohun tí mo bá kà nínú Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye sílò, kódà bó bá gba pé kí n yááfì àwọn nǹkan kan?’—Mát. 24:45.
16 Bí a bá jẹ́ kí Jèhófà máa fún wa ní ìtọ́ni kó sì máa ṣamọ̀nà wa ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán, kò ní sí ìdí fún wa láti máa bẹ̀rù. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nígbà tí aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan kọ̀wé béèrè fún irú iṣẹ́ kan tó yàtọ̀ níbi iṣẹ́ rẹ̀, èyí tó máa jẹ́ kí òun, ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ọ̀gá rẹ̀ sọ fún un pé kò lè rí irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ gbà láìjẹ́ pé ó ní ìwé ẹ̀rí yunifásítì. Ká sọ pé ìwọ ni ọkùnrin yìí, ṣe wàá kábàámọ̀ pé ò ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún dípò kó o lọ kàwé ní yunifásítì? Ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọ̀gá yẹn, ọ̀gá míì tó rọ́pò rẹ̀ sì béèrè ohun tó jẹ́ àfojúsùn arákùnrin yẹn. Kíá ló ṣàlàyé fún un pé òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni òun àti ìyàwó òun, ó sì wu àwọn láti máa bá iṣẹ́ náà nìṣó. Kí arákùnrin náà tó sọ ohun mìíràn , ọ̀gá náà sọ pé: “Abájọ, mo ti ń wò ó pé ohun kan wà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa rẹ! Kí bàbá mi tó kú, méjì lára àwọn èèyàn yín máa ń wá ka Bíbélì fún un lójoojúmọ́. Mo sì fi í sọ́kàn pé bí mo bá ní àǹfààní láti ran Ẹlẹ́rìí Jèhófà èyíkéyìí lọ́wọ́, màá ṣe bẹ́ẹ̀.” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n fún arákùnrin yìí ní iṣẹ́ tí ọ̀gá àkọ́kọ́ kọ̀ láti fún un. Ó dájú pé tá a bá fi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa, Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé jíjẹ, mímu àti ibùgbé kò ní wọ́n wa.—Mát. 6:33.
Ó ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ NÍ ÌGBÀGBỌ́ ÀTI ÌRÈTÍ
17. Kí ni kò ní jẹ́ ká máa bẹ̀rù ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
17 Lẹ́yìn náà ni Dáfídì tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí. Ó sọ pé: “Ká ní èmi kò ní ìgbàgbọ́ nínú rírí oore Jèhófà ní ilẹ̀ àwọn alààyè ni—!” (Sm. 27:13) Ibo là bá wà ní tòótọ́, bí a kò bá ní ìrètí, tí a kò sì mọ àwọn ohun tá a ti jíròrò nínú Sáàmù 27 yìí? Nígbà náà, ǹjẹ́ ká máa bá a nìṣó láti fi ìgbọ́kànlé gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa lókun kó sì mú ká la Amágẹ́dọ́nì já.—Ka Sáàmù 27:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ohun tó fún Dáfídì lókun ni pé ó rántí àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà dá a nídè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Bí ètò ọrọ̀ ajé bá dẹnu kọlẹ̀, ǹjẹ́ a máa ń wò ó bí ohun tó máa jẹ́ ká lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i?