Fi Jehofa Ṣe Ààbò-Ìsádi
“Ìwọ, Óò Jehofa, ni mo fi ṣe ààbò-ìsádi mi.”—ORIN DAFIDI 31:1, NW.
1. Bawo ni Orin Dafidi 31 ṣe fi ìgbọ́kànlé nínú agbára Jehofa láti pèsè ààbò-ìsádi hàn?
OHÙN atunilára kan kọrin nípa ọkùnrin kan tí ó gbáralé Jehofa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àárẹ̀ ọkàn àti ti ara. Ọ̀rọ̀-orin mímọ́-ọlọ́wọ̀ náà sọ pé ìgbàgbọ́ ṣẹ́gun. Nínú ọwọ́ Olódùmarè tí ń dúró dè é, ọkùnrin yìí rí ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn onínúnibíni tí ń dọdẹ rẹ̀. “Ìwọ, Óò Jehofa, ni mo fi ṣe ààbò-ìsádi mi,” ni psalmu rẹ̀ wí. “Óò kí èmi máṣe di ẹni àdójútì láé. Pèsè àsálà fún mi nínú òdodo rẹ.”—Orin Dafidi 31:1, NW.
2. (a) Orí awọn ọwọ̀n méjì wo ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí a lè ní nínú Jehofa gẹ́gẹ́ bí ibi-odi-agbára wa sinmilé? (b) Irú Ọlọrun wo ni Jehofa jẹ́?
2 Onipsalmu náà ní ààbò-ìsádi kan—ọ̀kan tí ó dára jùlọ! Jẹ́ kí àwọn nǹkan mìíràn wà nínú iyèméjì, síbẹ̀ òtítọ́ yìí ṣì dúró: Jehofa ni ibi-odi-agbára rẹ̀, ibi-ààbò rẹ̀. Ìgbọ́kànlé rẹ̀ sinmilórí àwọn ọwọ̀n dídájú méjì. Èkínní, ìgbàgbọ́ rẹ̀, èyí tí Jehofa kì yóò dójútì, àti èkejì, òdodo Jehofa, èyí tí ó túmọ̀sí pé Òun kò ní pa ìránṣẹ́ Rẹ̀ tì láé fún àkókò wíwà títílọ. Jehofa kìí ṣe Ọlọrun tí ń dójúti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́; òun kìí ṣe olùba ìlérí jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun jẹ́ Ọlọrun òtítọ́ àti olùṣẹ̀san fún àwọn wọnnì tí ń fi taratara ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀. Ní òpin rẹ̀, ìgbàgbọ́ ni a ó san èrè-ẹ̀san fún! Àsálà yóò dé!—Orin Dafidi 31:5, 6.
3. Báwo ni onipsalmu náà ṣe gbé Jehofa ga?
3 Ní kíkó orin rẹ̀ jọ pẹ̀lú àwọn ohùn-ìkọrin tí ń lọ sókè lọ sódò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú sísọ ẹ̀dùn-ọkàn àti kíké ègbé jáde dé òtéńté sísọ ọ̀rọ̀ nípa ìgbọ́kànlé, onípsalmu náà rí okun àtinúwá. Ó gbé Jehofa ga fún ìfẹ́ àdúróṣinṣin Rẹ̀. Ó kọrin pé: “Olùbùkún ni Oluwa; nítorí tí ó ti fi ìṣeun-ìfẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn mí ní ìlú-olódi.”—Orin Dafidi 31:21.
Ẹgbẹ́ Agberin Ńlá ti Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba
4, 5. (a) Ẹgbẹ́ agberin ńlá wo ni ń yin Jehofa lónìí, báwo ni wọ́n sì ti ṣe ìyẹn ní ọdún iṣẹ́-ìsìn tí ó kọjá yìí? (Wo àwòrán-ìsọfúnni ní ojú-ewé 12 si 15.) (b) Ní ọ̀nà wo ni àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí gbà fihàn pé àwọn púpọ̀ síi wà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́-ìmúratán láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́-agberin ti àwọn olùpòkìkí Ìjọba? (Wo àwòrán-ìsọfúnni.) (d) Àwọn àwùjọ wo nínú ìjọ rẹ ni wọ́n lè wà ní ipò láti darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ agberin náà?
4 Lónìí, àwọn ọ̀rọ̀ psalmu yẹn tún ti gbé àfikún ìtumọ̀ rù. Àwọn orin ìyìn sí Jehofa ni olubi alátakò kan, ìjábá ti ìṣẹ̀dá kan, tàbí àdánù ètò-ọrọ̀-ajé èyíkéyìí kò lè dádúró; nítòótọ́, ìṣeun-ìfẹ́ Jehofa ti jásí àgbàyanu fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Yíká ayé ní ọdún iṣẹ́-ìsìn tí ó kọjá, ẹgbẹ́ agberin ńlá kan, tí góńgó iye rẹ̀ jẹ́ 4,709,889 ní 231 ilẹ̀, kọrin ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba Ọlọrun. Àkóso Jehofa ní òkè ọ̀run nípasẹ̀ Kristi Jesu jẹ́ ààbò-ìsádi kan tí kì yóò já wọn kulẹ̀. Ní ọdún tí ó kọjá, àwọn olùpòkìkí Ìjọba wọ̀nyí láti 73,070 àwọn ìjọ lo àròpọ̀ wákàtí 1,057,341,972 nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere náà. Èyí ti yọrísí mímú kí 296,004 ènìyàn ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn fún Ọlọrun nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi. Ẹ sì wo ìyàlẹ́nu àgbàyanu tí gbogbo àwọn olùpésẹ̀ síbi Àpéjọpọ̀ Àgbáyé ti Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá tí a ṣe ní Kiev, Ukraine, ní oṣù August tí ó kọjá yìí gbádùn. Wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan nínú ọ̀rọ̀-ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ní ṣíṣẹlẹ́rìí ìrìbọmi ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Kristian tòótọ́ tí ó tíì wáyé rí! Gẹ́gẹ́ bí a ti sọtẹ́lẹ̀ ní Isaiah 54:2, 3, àwọn ènìyàn Ọlọrun ń rúnlẹ̀ nìṣó ní iye kan tí a kò rí irú rẹ̀ rí.
5 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn onífẹ̀ẹ́-ìmúratán ọmọ-abẹ́ Ìjọba Ọlọrun mìíràn síi ń wọ̀nà fún dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ agberin náà. Ní ọdún tí ó kọjá, àròpọ̀ iye àwọn ènìyàn tí ń mú háà ṣeni ti 11,865,765 ni wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí ikú Jesu. A nírètí pé, ọ̀pọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí yóò tóótun láti kọ orin Ìjọba náà láti ẹnu-ọ̀nà dé ẹnu-ọ̀nà nínú ọdún iṣẹ́-ìsìn yìí. Ẹ wo bí ìfojúsọ́nà yẹn ti gbọ́dọ̀ mú kí ọ̀tá òtítọ́ náà, Satani Eṣu, kún fún ìhónú tó!—Ìfihàn 12:12, 17.
6, 7. Ṣàlàyé bí olùfìfẹ́hàn kan ṣe ṣẹ́pá ìfòòró ẹ̀mí-èṣù pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa.
6 Satani yóò gbìyànjú láti dí àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti máṣe fi ohùn wọn kún ti ẹgbẹ́ agberin ńlá yẹn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn akéde ní Thailand ríi pé iye àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ síi ni ìfòòró àwọn ẹ̀mí-èṣù ń dàláàmú. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ àwọn olótìítọ́-inú, ti di òmìnira pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa. Lẹ́yìn ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ adáhunṣe kan nítorí ìfẹ́-ìtọpinpin, ọkùnrin kan wà lábẹ́ agbára àwọn ẹ̀mí-èṣù fún ọdún mẹ́wàá. Ó sakun láti já araarẹ̀ gbà kúrò lọ́wọ́ agbára wọn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àlùfáà-ṣọ́ọ̀ṣì kan, ṣùgbọ́n kò nírìírí ìmúsunwọ̀nsíi gidi èyíkéyìí. Òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan pẹ̀lú ọkùnrin náà ó sì fi ọ̀nà kanṣoṣo láti gbà dòmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀mí-èṣù kọ́ ọ láti inú Bibeli—gba ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ sínú, ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa Ọlọrun, kí o sì rawọ́-ẹ̀bẹ̀ síi nínú àdúrà.—1 Korinti 2:5; Filippi 4:6, 7; 1 Timoteu 2:3, 4.
7 Ní alẹ́ lẹ́yìn tí ìjíròrò yìí wáyé, ọkùnrin náà lá àlá kan nínú èyí tí baba rẹ̀ tí ó ti kú ti halẹ̀mọ́ ọn bí kò bá padà lọ́ sídìí iṣẹ́ ìbẹ́mìí-èṣù-lò rẹ̀. Ìdílé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí jìyà. Bí kò ti múratán láti di ẹni tí a mú yàbàrá kúrò lọ́nà, ọkùnrin náà ń bá àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli rẹ̀ nìṣó ó sì bẹ̀rẹ̀ síí lọ sí àwọn ìpàdé. Lákòókò ọ̀kan nínú irú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ wọnnì, aṣáájú-ọ̀nà náà ṣàlàyé pé nígbà mìíràn àwọn ohun tí a ń lò nínú ààtò-àṣà ìbẹ́mìílò lè fún àwọn ẹ̀mí-èṣù ní àǹfààní láti fòòró àwọn ènìyàn tí wọ́n bá ń gbìyànjú láti dòmìnira kúrò lábẹ́ agbára wọn. Ọkùnrin náà rántí pé òun ní epo díẹ̀ tí òun ti lò gẹ́gẹ́ bí oògùn-àwúre. Ó wá mọ̀ nísinsìnyí pé òun níláti dà á nù. Láti ìgbà tí ó sì ti dà á nù, àwọn ẹ̀mí-èṣù kò tún yọ ọ́ lẹ́nu mọ́. (Fiwé Efesu 6:13; Jakọbu 4:7, 8.) Òun àti aya rẹ̀ ń tẹ̀síwájú dáradára nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn, wọ́n sì ń lọ sí àwọn ìpàdé déédéé fún ìtọ́ni Bibeli.
8, 9. Àwọn ohun-ìdínà mìíràn wo ni àwọn olùpòkìkí Ìjọba kan ti ṣẹ́pá?
8 Àwọn ohun-ìdínà mìíràn lè mú kí ohùn ìhìnrere náà máṣe dún lọ́nà jíjágaara. Nítorí ipò-ọ̀ràn ètò-ọrọ̀-ajé tí ń ninilára gan-an ní Ghana, àwọn òṣìṣẹ́ ni a ti dàsílẹ̀. Owó ìgbọ́bùkátà ti fòsókè, èyí tí ó mú kí ó jẹ́ ìṣòro gidi kan láti ní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí-ayé. Báwo ni àwọn ènìyàn Jehofa ṣe ń kojú rẹ̀? Nípa níní ìgbẹ́kẹ̀lé, kìí ṣe nínú araawọn, ṣùgbọ́n nínú Jehofa. Fún àpẹẹrẹ, ní ọjọ́ kan, ọkùnrin kan fi àpòòwé kan tí a lẹ̀pa sórí tábìlì alápòótí ní ibi-ìgbàlejò ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Nínú àpòòwé náà ní $200, tàbí owó-iṣẹ́ oṣù mẹ́ta fún òṣìṣẹ́ tí ń gbowó pọ́ọ́kú jùlọ wà. Àpòòwé náà wá láti ọ̀dọ̀ olùfúnni ní ẹ̀bùn kan tí a kò mọ orúkọ rẹ̀, ṣùgbọ́n lára ohun tí ó fi di owó náà ni àkọlé yìí wà: “Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n Jehofa ti pèsè òmíràn fún mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ òun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Kristi Jesu. Láti ṣètìlẹ́yìn nínú títan ìhìnrere Ìjọba náà kálẹ̀ ṣáájú kí òpin tóó dé, mo fi ọrẹ táṣẹ́rẹ́ sínú àpòòwé yìí.”—Fiwé 2 Korinti 9:11.
9 Lílọ sí ìpàdé ń ṣèrànlọ́wọ́ láti kọ́ àwọn wọnnì tí ń darapọ̀ nínú kíkọ ègbè orin ìyìn ńlá sí Jehofa. (Fiwé Orin Dafidi 22:22.) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ìjọ kan wà tí a ń pè ní El Jordán, ní ìhà gúúsù Honduras. Kí ni ó jẹ́ àkànṣe tóbẹ́ẹ̀ nípa àwùjọ kékeré yìí? Ìṣòtítọ́ wọn ní lílọ sí ìpàdé ni. Nínú àwọn akéde 19 tí ó ní, 12 níláti sọdá odò fífẹ̀ kan láti lọ sí àwọn ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Èyí kìí ṣe ìṣòro ńlá nígbà ẹ̀rùn, níwọ̀nbí wọ́n ti lè sọdá odò náà nípa lílo àwọn àpáta gẹ́gẹ́ bí òkúta-àtẹ̀gùn. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà òjò, àwọn ipò máa ń yípadà. Ohun tí ó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ ojú-odò gbígbòòrò tí kò kaniláyà á wá di àgbàrá tí ń gbé ohunkóhun tí ó bá wà ní ipa-ọ̀nà rẹ̀ lọ. Láti borí ìdínà yìí, àwọn arákùnrin àti arábìnrin náà níláti jẹ́ ọ̀jáfáfá òmùwẹ̀. Kí wọ́n tó sọdá, wọ́n a kó aṣọ ìpàdé wọn sínú tina (ọpọ́n onírin) wọ́n a sì fi ọ̀rá dì í. Òmùwẹ̀ tí ó lágbára jùlọ a lo tina náà gẹ́gẹ́ bíi tìmùtìmù agbéniléfòó tí yóò si ṣamọ̀nà àwùjọ náà sọdá. Bí wọ́n bá ti wẹ̀ jákè tán, wọ́n a nu araawọn gbẹ, wọ́n a wọṣọ, wọ́n a sì dé sí Gbọ̀ngàn Ìjọba pẹ̀lú ọ̀yàyà àti ìmọ́tónítóní tí ó wunijọjọ!—Orin Dafidi 40:9.
Ibi-Ààbò Kan tí A Lè Gbé
10. Èéṣe tí a fi lè yíjúsí Jehofa ní àwọn àkókò másùnmáwo?
10 Yálà o wà lábẹ́ ìgbéjàkò ẹ̀mí-èṣù ní tààràtà tàbí o ń nímọ̀lára másùnmáwo láti àwọn orísun mìíràn, Jehofa lè jẹ́ ibi-odi-agbára rẹ. Képè é nínú àdúrà. Òun máa ń fetísílẹ̀ gidi gan-an àní sí ìkédàárò tí kò dún ketekete pàápàá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀. Onípsalmu náà ríi pé ìyẹn jẹ́ òtítọ́ ó sì kọ̀wé pé: “Dẹ etí rẹ sílẹ̀ sí mi: gbà mí nísinsìnyí: ìwọ máa ṣe àpáta agbára mi, ilé-ààbò láti gbà mí sí. Nítorí ìwọ ni àpáta mi àti odi mi: nítorí náà nítorí orúkọ rẹ máa ṣe ìtọ́ mi, kí o sì máa ṣe amọ̀nà mi. Yọ mí jáde nínú àwọ̀n tí wọ́n nà sílẹ̀ fún mi ní ìkọ̀kọ̀: nítorí ìwọ ni ààbò mi.”—Orin Dafidi 31:2-4.
11. Ṣàlàyé bí ó ṣe jẹ́ pé ibi-ààbò Jehofa kìí ṣe ibikan tí ó wà fún ìgbà díẹ̀.
11 Jehofa kò wulẹ̀ pèsè ààbò-ìsádi fún ìgbà díẹ̀ kan lásán ṣùgbọ́n ibi-ààbò kan tí kò ṣeéfipákọlù níbi tí a lè gbé láìséwu. Ìdarí àti ìtọ́nisọ́nà rẹ̀ kò já àwọn ènìyàn rẹ̀ kulẹ̀ rí. Agbára àtọ̀runwá yóò sọ gbogbo ìgbégbèésẹ̀ alárèékérekè ti Satani àti àwọn ọ̀wọ́ rẹ̀ di aláìwúlò. (Efesu 6:10, 11) Bí a ti fi tọkàntara gbẹ́kẹ̀lé Jehofa, òun yóò fà wá sẹ́yìn kúrò nínú àwọn ìdẹkùn Satani. (2 Peteru 2:9) Ní ọdún mẹ́rin tí ó ti kọjá, iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tún ń báa lọ ní gbangba ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi 35. Bákan náà, ní àwọn agbègbè ilẹ̀-ayé níbi tí àwọn ipò ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ti ètò-ọrọ̀-ajé, tàbí ti ìṣèlú ti dí wíwàásù ìhìnrere lọ́wọ́, àwọn ẹni-bí-àgùtàn díẹ̀ ti ṣí lọ síbi ti a ti lè túbọ̀ dé ọ̀dọ̀ wọn ní fàlàlà. Irú ibi bẹ́ẹ̀ ni Japan.
12. Báwo ni aṣáájú-ọ̀nà kan ni Japan ṣe fi Jehofa ṣe ibi-odi-agbára rẹ̀?
12 Ní Japan àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ àlejò ń rọ́wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè, a sì ti fìdí ọ̀pọ̀ àwọn ìjọ tí ń sọ èdè àjèjì múlẹ̀. Ìrírí arákùnrin kan nínú ìjọ kan tí ń sọ èdè Japanese ṣàpèjúwe bí pápá èdè àjèjì yìí ti ń mésojáde tó. Ó fẹ́ láti lọ ṣiṣẹ́sìn níbi tí àìní gbé pọ̀jù. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mẹ́wàá níbi tí ó wà. Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ lọ́nà àwàdà pé: “Bí o bá lọ sí ibi tí àìní gbé pọ̀jù, ìwọ yóò níláti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli 20 níbẹ̀!” Ó gba iṣẹ́-àyànfúnni kan ó sì lọ sí Hiroshima. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn oṣù mẹ́rin, ó ní kìkì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kanṣoṣo. Lọ́jọ́ kan ó kàn sí ọkùnrin kan tí ó wá láti Brazil tí ń sọ èdè Portuguese nìkan. Níwọ̀nbí arákùnrin náà kò ti lè ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin náà, ó ra ìwé-ẹ̀kọ́ kan lórí èdè Portuguese. Lẹ́yìn kíkọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ rírọrùn díẹ̀, ó tún padà bẹ ọkùnrin náà wò. Nígbà tí arákùnrin náà kí i ní èdè Portuguese, ó ya ọkùnrin náà lẹ́nu ó sì ṣílẹ̀kùn sílẹ̀ gbayawu fún un láti késí i wọlé, pẹ̀lú ẹ̀rín mùkẹ̀mukẹ. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan. Láìpẹ́ arákùnrin náà ń darí àròpọ̀ iye ikẹ́kọ̀ọ́ 22, àwọn 14 ní èdè Portuguese, 6 ní èdè Spanish, àti 2 ní èdè Japanese!
Wíwàásù Pẹ̀lú Ìgbọ́kànlé
13. Èéṣe tí a kò fi níláti gbìyànjú láti ṣiṣẹ́sin Jehofa nítorí ìtìjú ẹnikẹ́ni?
13 Àwọn ènìyàn Jehofa ń fi ìgbọ́kànlé kọ orin Ìjọba pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kíkún pé Jehofa ni ààbò-ìsádi wọn. (Orin Dafidi 31:14) Ojú kì yóò tì wọ́n—Jehofa kì yóò rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí tí yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. (Orin Dafidi 31:17) Eṣu àti àwọn ẹ̀mí-èṣù amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni ojú yóò tì. Níwọ̀nbí ó ti jẹ́ pé àwọn ènìyàn Jehofa ni a fi àṣẹ fún níṣẹ́ láti wàásù ìhìn-iṣẹ́ kan tí kìí tinilójú, kìí ṣe ìtìjú àwọn ẹlòmíràn ni ó ń sún wọn láti wàásù. Kìí ṣe ọ̀nà tí Jehofa, tàbí Ọmọkùnrin rẹ̀, ń gbà ru àwọn ènìyàn sókè láti jọ́sìn Òun nìyẹn. Nígbà tí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn bá kún fún ìgbàgbọ́ àti ìmọrírì fún ìwàrere-ìṣeun àti ìṣeun-ìfẹ́ Jehofa, ipò rere ọkàn-àyà wọn ni ó ń sún ẹnu wọn láti sọ̀rọ̀. (Luku 6:45) Nípa báyìí, àkókò yòówù kí a lò nínú iṣẹ́-ìsìn lóṣooṣù, pàápàá jùlọ bí àkókò yẹn bá dúró fún ohun dídára jùlọ tí a lè ṣe, ó dára, kò sì yẹ kí ó tinilójú. Jesu ati Baba rẹ̀ kò há mọrírì ẹ̀bùn kékeré ti opò náà lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ bí?—Luku 21:1-4.
14. Ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí wo ni o lè sọ nípa iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà? (Tún wo àwòrán-ìsọfúnni náà.)
14 Fún iye àwọn akéde tí ń ga síi, fífi tọkàntọkàn ṣe ìjọsìn wọn tún ní ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà nínú—góńgó ti ọdún tí ó kọjá jẹ́ 890,231! Bí ìtẹ̀síwájú ti ọdún tí ó kọjá bá ṣì ń báa lọ, ó ṣeéṣe kí iye yìí rékọjá 1,000,000. Ìrírí tí ó tẹ̀lé e yìí fihàn bí arábìnrin kan ní Nigeria ṣe wọnú òtú àwọn aṣáájú-ọ̀nà. Ó kọ̀wé pé: “Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí n jáde ilé-ẹ̀kọ́ gíga, mo lọ ṣèrànlọ́wọ́ láti gbọ́únjẹ fún àwọn wọnnì tí wọ́n lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ aṣáájú-ọ̀nà ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Mo bá àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jú ìyá mi àgbà lọ pàdé níbẹ̀. Nígbà tí mo ṣàwárí pé aṣáájú-ọ̀nà tí ó wá sí ilé-ẹ̀kọ́ náà ni wọ́n, mo rò ó wò nínú araami pé, ‘Bí àwọn méjì wọ̀nyẹn bá lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, èéṣe tí èmi ko fi lè ṣe é?’ Nítorí náà lẹ́yìn tí mo jáde ní ilé-ẹ̀kọ́, èmi pẹ̀lú di aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan.”
15. Ní ọ̀nà wo ní ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà lè gbà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn láti fi Jehofa ṣe ààbò-ìsádi?
15 Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni ó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ṣùgbọ́n wọ́n lè jẹ́rìí. Ní Belgium arábìnrin ẹni ọdún 82 kan lọ sí ọjà ẹran. Ó kíyèsi pé aya alápatà náà ni rúkèrúdò ìṣèlú tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ kó ìyọlẹ́nu bá. Nítorí náà arábìnrin náà ki ìwé-àṣàrò-kúkúrú náà Kinni Awọn Ẹlẹrii Jehofah Gbagbọ? bọ àárín owó nígbà tí ó sanwó ẹ̀ran tí ó rà. Nígbà tí arábìnrin náà padà lọ sí ìsọ̀ náà, aya alápatà náà, láìlọ́tìkọ̀ rárá, béèrè ohun tí Bibeli sọ nípa ṣiṣeéṣe náà pé kí ogun àgbáyé kẹta jà. Arábìnrin náà mú ìwé True Peace and Security—How Can You Find It? wá fún un. Ní ìwọ̀nba ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, bí arábìnrin àgbàlagbà náà tí ń wọnú ilé ìtajà náà, aya alápatà náà ní ìbéèrè púpọ̀ síi láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Arábìnrin náà bá obìnrin yìí kẹ́dùn; o wulẹ̀ níláti nawọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan síi ni, èyí ni ó sì tẹ́wọ́gbà. Nísinsìnyí, aya alápatà náà fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Alápatà náà ńkọ́? Ó ka ìwé-àṣàrò-kúkúrú náà ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nísinsìnyí pẹ̀lú.
‘Ìṣúra Ìwàrere-Ìṣeun’
16. Ọ̀nà wo ni Jehofa ti gbà ya ìṣúra ìwàrere-ìṣeun sọ́tọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀?
16 Nínú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn onímásùnmáwo wọ̀nyí, Jehofa kò ha ti “fi ìṣeun-ìfẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn” fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti fi í ṣe ààbò-ìsádi bí? Gẹ́gẹ́ bíi baba onífẹ̀ẹ́, tí ń dáàbòboni, Jehofa ti ya ìṣúra ìwàrere-ìṣeun sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀-ayé. Ó ti ń da ọ̀wààrà ayọ̀ lé wọn lórí níwájú gbogbo àwọn òǹwòran, gan–an gẹ́gẹ́ bí onípsalmu náà ti sọ pé: “Ore rẹ ti tóbi tó, tí ìwọ fi ṣúra de àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ: ore tí ìwọ ti ṣe fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ níwájú àwọn ọmọ ènìyàn!”—Orin Dafidi 31:19, 21.
17-19. Ní Ghana, rere wo ni ó jẹyọ láti inú mímú tí ọkùnrin àgbàlagbà kan mú ìgbéyàwó rẹ̀ bá òfin mu?
17 Nítorí náà, àwọn ènìyàn ayé di ẹlẹ́rìí olùfojúrí fún ìwà-àìlábòsí àwọn wọnnì tí wọ́n ń jọ́sìn Jehofa, ẹnu sì yà wọ́n. Fún àpẹẹrẹ, ní Ghana ọkùnrin ẹní ọdún 96 kan lọ sí ọ́fíìsì akọ̀wé tí ń fi orúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ lábẹ́ òfin ó sì béèrè pé kí a fi orúkọ̀ ìgbéyàwó tí ó ti ṣe lábẹ́ àṣà ìbílẹ̀ fún 70 ọdún báyìí sílẹ̀. Ìjòyè-òṣìṣẹ́ ìgbéyàwó náà takìjí ó sì béèrè pé: “Ó ha dá ọ lójú pé ohun tí o fẹ́ láti ṣe nìyẹn bí? Bí o ti dàgbà tó yìí?”
18 Ọkùnrin náà ṣàlàyé pé: “Mo fẹ́ láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kí n sì nípìn-ín nínú iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ṣáájú òpin ayé—iṣẹ́ wíwàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun. Iṣẹ́ yìí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣègbọràn sí òfin orílẹ̀-èdè, títíkan òfin tí ó wà fún ìforúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Nítorí náà jọ̀wọ́ ṣe ìforúkọsílẹ̀ náà fún mi.” Kẹ́kẹ́ pa mọ́ ìjòyè-òṣìṣẹ́ náà lẹ́nu. Ó ṣe ìforúkọsílẹ̀ náà, ọkùnrin àgbàlagbà náà sí kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀ pé òun ti ní ìgbéyàwó kán tí ó bófinmu nísinsìnyí.—Fiwé Romu 12:2.
19 Lẹ́yìn ìyẹn, akọ̀wé tí ń fi orúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ lábẹ́ òfin náà sinmẹ̀dọ̀ rónu lórí àwọn ohun tí ó ti gbọ́. “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa . . . iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ . . . òpin ayé . . . Ìjọba Ọlọrun . . . ìyè àìnípẹ̀kun.” Bí ohun tí gbogbo èyí túmọ̀sí nínú ìgbésí-ayé ọkùnrin ẹní ọdún 96 kan ti rú u lójú, ó pinnu láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí kàn kí ó baà lè wádìí ọ̀ràn náà yẹ̀wò síwájú síi. Ó tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé ó sì tẹ̀síwájú lọ́nà yíyárakánkán. Lónìí, akọ̀wé tí ń fi orúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ yìí jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí a ti baptisi. Nípa báyìí, nígbà tí a bá ṣègbọràn sí Jehofa àní nínú ohun tí àwọn ẹlòmíràn lè kà sí ọ̀ràn kékeré pàápàá, ó lè yọrísí rere tí kò ṣeéfẹnusọ fún wa àti fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí ìwà wa.—Fiwé 1 Peteru 2:12.
20. Ní Myanmar, báwo ní ìwà-àìlábòsí arábìnrin ọ̀dọ́ kan ṣe ṣamọ̀nà sí ìjẹ́rìí dídára kan?
20 Àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ti jẹ́ kí òtítọ́ sọ wọ́n di aláìlábòsí ènìyàn fi àpẹẹrẹ dídára lélẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ nínú ayé alábòòsí yìí. Ní Myanmar ni irú arábìnrin ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ń gbé. Ó wá láti inú ìdílé rírẹlẹ̀ ọlọ́mọ mẹ́wàá kan tí ó tòṣì. Baba rẹ̀, tí ń gba owó ìfẹ̀yìntì kúrò lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan. Ní ọjọ́ kan ní ilé-ẹ̀kọ́, arábìnrin náà rí òrùka dáyámọ́ǹdì kan, èyí tí ó mú lọ sọ́dọ̀ olùkọ́ rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bí kíláàsì ti péjọpọ̀ ní ọjọ́ kejì, olùkọ́ sọ fún gbogbo kíláàsì bí a ti rí òrùka náà tí a sì mú un wá kí a lè fún ẹni tí ó ni ín. Lẹ́yìn náà ni ó sọ pé kí arábìnrin ọ̀dọ́ náà dìde dúró níwájú gbogbo kíláàsì kí ó sì ṣàlàyé ìdí tí ó fi ṣe bẹ́ẹ̀, ní mímọ̀ pé àwọn ọmọ yòókù ti lè yàn láti gbé e pamọ́. Arábìnrin náà ṣàlàyé pé òun jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa àti pé Ọlọrun òun kò nífẹ̀ẹ́ sí olè-jíjà tàbí irú ìwà-àbòsí èyíkéyìí. Gbogbo ilé-ẹ̀kọ́ náà gbọ́ nípa rẹ̀, ní fífún arábìnrin wa ní àǹfààní dídára láti jẹ́rìí fún àwọn olùkọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bákan náà.
21. Bí àwọn ọ̀dọ́ ti ń gbẹ́kẹ̀lé Jehofa, kí ni ìwà wọn ń fihàn nípa rẹ̀?
21 Ní Belgium olùkọ́ kan sọ ọ̀rọ̀ àkíyèsí kan tí ó ru ọkàn-ìfẹ́ sókè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó ti kíyèsí ìwà ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀, tí òun pẹ̀lú jẹ́ arábìnrin ọ̀dọ́ kan, ó sì wí pé: “Mo ní èrò mìíràn nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nísinsìnyí. Ẹ̀tanú ti mú kí n ronú pé àwọn ní yóò jẹ́ aláìrí ara gba nǹkan sí jùlọ. Ẹ̀rí fihàn pé wọ́n jẹ́ ẹni tí ó rí ara gba nǹkan sí jùlọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò jẹ́ fi àwọn ìlànà wọn bánidọ́rẹ̀ẹ́.” Lọ́dọọdún, àwọn olùkọ́ náà a máa fún ọmọ kíláàsì wọn tí ó bá ṣe dáradára jùlọ ní ẹ̀bùn. Lára àwọn ẹ̀bùn náà ni ti ẹ̀kọ́ nípa ìlànà-ìwàhíhù. Fún ọdún mẹ́ta tí ó tẹ̀léra, àwọn ẹ̀bùn fún ipo-ẹ̀kọ́ gíga jùlọ mẹ́ta ni àwọn olùkọ́ yìí fifún àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí ó ti sábà máa ń ri fún àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé dídúróṣinṣin nínú Jehofa nìyẹn.—Orin Dafidi 31:23.
22. Báwo ni Orin Dafidi 31 ṣe wá sí ìparí aláyọ̀-ìṣẹ́gun, báwo sì ni ìyẹn ṣe ràn wá lọ́wọ́ ní ìparí àwọn ọjọ́ ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí?
22 Orin Dafidi 31 dún jáde pẹ̀lú ìparí aláyọ̀-ìṣẹ́gun pé: “Ẹ tújúká, yóò sì mú yín ní àyà le, gbogbo ẹ̀yin tí ó ní ìrètí níti Oluwa.” (Orin Dafidi 31:24) Nítorí náà, bí a ti dojúkọ òpin àwọn ọjọ́ ètò-ìgbékalẹ̀ búburú ti Satani, kàkà kí òun fi wá sílẹ̀, Jehofa yóò súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí gan-an yóò si fi agbára tirẹ̀ gan-an sí wa nínú. Olùṣòtítọ́ ni Jehofa kìí sìí kùnà. Òun ni ààbò-ìsádi wa; òun ni ilé-ìṣọ́ wa.—Owe 18:10.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Èéṣe tí a lè fi pẹ̀lú ìgbọ́kànlé fi Jehofa ṣe ààbò-ìsádi wa?
◻ Ẹ̀rí wo ni ó wà níbẹ̀ pé ẹgbẹ́ agberin ńlá kan ń fi ìgboyà kọ orin ìyìn Ìjọba?
◻ Èéṣe tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé pé àwọ̀n Satani kì yóò dẹkùn mú àwọn ènìyàn Jehofa?
◻ Ìṣúra wo ni Jehofa ti yàsọ́tọ̀ fún àwọn wọnnì tí wọ́n ń fi í ṣe ààbò-ìsádi wọn?
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 12-15]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 1993 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn wọnnì tí wọ́n fi Jehofa ṣe ààbò-ìsádi di ẹgbẹ́ agberin ńlá ti àwọn olùpòkìkí Ìjọba—tí iye wọn jẹ́ 4,709,889!
1. Senegal
2. Brazil
3. Chile
4. Bolivia