Ìdí Tí Bíbélì Fi Wúlò Lóde Òní
“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún . . . fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà.”—2 TÍMÓTÌ 3:16.
ỌJỌ́ pẹ́ táwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ti máa ń mú kí onírúurú èèyàn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra yí ìgbésí ayé wọn pa dà sí rere. Ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ìdí tí Bíbélì fi máa ń nírú ipa rere bẹ́ẹ̀ lórí àwọn èèyàn, ìdí ni pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ti wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ló kọ Bíbélì, ó dájú pé àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ló wà níbẹ̀. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—2 Pétérù 1:21.
Ó kéré tán, ọ̀nà pàtàkì méjì ni Bíbélì gbà wúlò fún wa. Àkọ́kọ́ ni pé ó jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí lóòótọ́ pé kí ìgbésí ayé èèyàn dára. Ìkejì sì ni pé, ó lágbára láti mú kéèyàn yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà káyé ẹni lè dára. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀nà méjèèjì tí Bíbélì gbà wúlò fún wa yìí.
Bá A Ṣe Lè Fòye Mọ Àwọn Nǹkan Tó Máa Wúlò fún Wa
Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sáàmù 32:8) Kíyè sí pe kì í ṣe ìmọ̀ràn nìkan ni Ọlọ́run máa ń fún wa, àmọ́ ó tún ń jẹ́ ká ní ìjìnlẹ̀ òye, ìyẹn agbára tó ń jẹ́ ká fòye mohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀. Tá a bá ń fi ìjìnlẹ̀ òye mọ àwọn nǹkan tó máa ṣe wá láǹfààní lóòótọ́, ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa fàkókò wa ṣòfò lórí àwọn nǹkan tí kò ní láárí.
Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa rí towó ṣe tàbí bí wọn ṣe máa dolókìkí ló jẹ wọ́n lógún nígbèésí ayé. Àìmọye ìwé làwọn kan ti kọ lórí báwọn èèyàn ṣe lè ta àwọn ẹlòmíì yọ láti dépò ọlá tàbí kí wọ́n lè lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Bíbá ẹnì kìíní-kejì díje” jẹ́ “asán . . . àti lílépa ẹ̀fúùfù.” Ó tún sọ pé, “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà.” (Oníwàásù 4:4; 5:10) Ṣé ìmọ̀ràn yìí wúlò fún wa lóde òní?
Jẹ́ ká fohun tó ṣẹlẹ̀ sí Akinori, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Japan, ṣàpèjúwe báwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì ṣe wúlò tó. Ọ̀kan lára àwọn yunifásítì tó lórúkọ lórílẹ̀-èdè Japan ni Akinori ti kàwé, ìdíje pọ̀ ní yunifásítì yẹn, àmọ́ ọwọ́ Akinori tẹ ohun tó ń wá, ó kẹ́kọ̀ọ́ yege, ó sì ríṣẹ́ síléeṣẹ́ ńlá kan lẹ́yìn náà. Ó dà bíi pé gbogbo nǹkan ń lọ déédéé fún un, àmọ́ àwọn àṣeyọrí tó ní yìí ò fún un nírú ìdùnnú tó ti ń wá. Dípò ìyẹn, àárẹ̀ àti ìdààmú ọkàn tó máa ń ní ṣàkóbá fún ìlera ẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ tó ní níbiiṣẹ́ ò fi bẹ́ẹ̀ mú nǹkan rọrùn fún un. Ìdààmú ọkàn tó bá a wá mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í mutí àmupara, ó tiẹ̀ tún ronú láti gbẹ̀mí ara ẹ̀ pàápàá. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ látinú Bíbélì mú kó yí àwọn nǹkan tó kà sí pàtàkì nígbèésí ayé pa dà. Ìdààmú ọkàn tó ní bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù díẹ̀díẹ̀. Dípò tí Akinori ì bá fi jẹ́ kí ìgbéraga àti lílépa ipò ọlá jẹ òun lọ́kàn, òwe kan nínú Bíbélì ló ṣẹ sí i lára, ìyẹn ni pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.”—Òwe 14:30.
Kí lo rò pé o lè fi ṣe àfojúsùn tó máa wúlò fún ẹ jù lọ nígbèésí ayé? Àṣeyọrí wo lo lè ní tó máa fún ẹ ní ojúlówó ayọ̀? Ṣé tó o bá ní ìdílé aláyọ̀ ni? Àbí tó o bá ráyè tọ́ àwọn ọmọ ẹ dáadáa láti kékeré? Ṣé tó o bá láwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ ni? Àbí tó o bá ń gbádùn ìgbésí ayé? Gbogbo àwọn àfojúsùn yìí ló dáa. Bíbélì pàápàá ò tiẹ̀ ní ká máà ní àwọn nǹkan wọ̀nyí, àmọ́ kò ní ká fi wọ́n ṣe olórí ohun tá ó máa fi gbogbo ìgbésí ayé wa lépa. Bíbélì jẹ́ ká fòye mohun tó ṣe pàtàkì jù tó lè jẹ́ kí ìgbésí ayé wa dùn bí oyin nígbà tó sọ pé: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.” (Oníwàásù 12:13) Nígbàkigbà téèyàn bá kọ̀ láti ṣohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, ìgbésí ayé kò ní nítumọ̀, ọ̀pọ̀ ìdáwọ́lé ló máa já sí pàbó, ìjákulẹ̀ ló sì máa gbẹ̀yìn ẹ̀. Àmọ́, Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Aláyọ̀ . . . ni ẹni tí ó [bá] gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”—Òwe 16:20.
Bí Bíbélì Ṣe Ń Mú Káwọn Èèyàn Yí Pa Dà
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” Bí idà olójú méjì tó mú, Bíbélì máa ń nípa lórí àwọn nǹkan téèyàn bá ń rò lọ́kàn àtàwọn nǹkan tá a bá fẹ́ ṣe. (Hébérù 4:12) Ìdí tí Bíbélì fi máa ń mú káwọn èèyàn yí ìgbésí ayé wọn pa dà ni pé, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an dípò ohun tí wọ́n rò pé àwọn jẹ́. Ìyẹn á jẹ́ káwọn èèyàn tí wọ́n ní ọkàn tó dáa ronú pé ó yẹ káwọn ṣe àwọn ìyípadà kan. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn kan, nínú ìjọ Kristẹni tó wà nílùú Kọ́ríńtì, tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ olè, ọ̀mùtípara, alágbèrè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́ . . . pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.” (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́, ó sì lágbára títí dòní olónìí, ó sì lè mú káwọn èèyàn ṣe àwọn ìyípadà tó bá pọn dandan.
Oníjàgídíjàgan èèyàn ni Mario tó ń gbé nílẹ̀ Yúróòpù, ó máa ń mugbó, ó sì ń tagbó. Ó fìbínú lu ọlọ́pàá kan lọ́jọ́ kan, ó sì ba mọ́tò ọlọ́pàá náà jẹ́ torí pé ọlọ́pàá yẹn gba àwọn oògùn olóró tó ń tà lọ́wọ́ ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Mario ò níṣẹ́ lọ́wọ́, ó sì ní gbèsè rẹpẹtẹ lọ́rùn. Nígbà tó rí i pé òun ò lè tán àwọn ìṣòro tóun ní fún ra òun, ó gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí Mario ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í túnra ṣe, ó jáwọ́ nínú igbó mímu, kò ta oògùn olóró mọ́, ó sì jáwọ́ nínú ìwà jàgídíjàgan. Ẹnú ya ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀. Wọ́n sábà máa ń dá a dúró lójú ọ̀nà, wọ́n á sì bi í pé, “Mario, ṣéwọ nìyí ṣá?”
Kí ló mú káwọn èèyàn bí Akinori àti Mario yí ìgbésí ayé wọn pa dà kí wọ́n sì wá ní ojúlówó ìbàlẹ̀ ọkàn àti ayọ̀ nígbèésí ayé wọn? Kò sí àní-àní pé ìmọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà nínú Bíbélì ni. Ọlọ́run nìkan ló lè fún wa ní ìtọ́ni tó wúlò, tó máa jẹ́ ká lè kẹ́sẹ járí nínú ìgbésí ayé wa nísinsìnyí tó sì máa jẹ́ ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà tipasẹ̀ Bíbélì bá wa sọ̀rọ̀ bíi Bàbá, ó ní: “Gbọ́, ọmọ mi, kí o sì tẹ́wọ́ gba àwọn àsọjáde mi. Nígbà náà ni ọdún ìwàláàyè yóò di púpọ̀ fún ọ. . . . Nígbà tí o bá ń rìn, ìṣísẹ̀rìn rẹ kì yóò há; bí o bá sì ń sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀. Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kí ó lọ. Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, nítorí òun ni ìwàláàyè rẹ.” (Òwe 4:10-13) Ìmọ̀ràn wo ló tún lè wúlò fún wa nígbèésí ayé ju pé ká gba ìtọ́sọ́nà Ẹlẹ́dàá wa lọ?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ìmọ̀ràn Tó Wúlò Lóde Òní
Àwọn ìlànà tó ṣe pàtàkì tó sì wúlò, tó lè máa tọ́ wa sọ́nà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe lóde òní wà nínú Bíbélì. Jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò nínú wọn:
• Bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì
“Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.
“Ẹni tí ó bá hùwà bí ẹni tí ó kéré jù láàárín gbogbo yín ni ẹni ńlá.”—Lúùkù 9:48.
“Ẹ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.” —Róòmù 12:13.
• Bá a ṣe lè jáwọ́ nínú ìwàkiwà
“Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.
“Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri.”—Òwe 23:20.
“Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́.”—Òwe 22:24.
• Bí tọkọtaya ṣe lè máa ṣera wọn lọ́kan
“Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—Éfésù 5:33.
“Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà.”—Kólósè 3:12, 13.
• Bá a ṣe lè tọ́mọ yanjú
“Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6.
“Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.
• Bá a ṣe lè yẹra fún aáwọ̀
“Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.”—Òwe 15:1.
“Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.”—Róòmù 12:10.
A lè yẹra fún awuyewuye lórí ọ̀rọ̀ òwò, kódà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ pàápàá, tá a bá jọ fọwọ́ síwèé àdéhùn. Ìdí nìyẹn tí Jeremáyà, tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, fi kọ̀wé pé: “Mo kọ ìwé àdéhùn, mo sì fi èdìdì sí i, mo sì gba àwọn ẹlẹ́rìí bí mo ti ń wọn owó náà lórí òṣùwọ̀n.”—Jeremáyà 32:10.
• Bá a ṣe lè ní ẹ̀mí pé nǹkan á dáa
“Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, . . tí ó dára ní fífẹ́, . . . tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8.
Bíbélì ò fọwọ́ sí níní èrò òdì, ó sì dẹ́bi fún “àwọn olùráhùn nípa ìpín wọn nínú ìgbésí ayé.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ẹ máa yọ̀ nínú ìrètí.”—Júúdà 4, 16; Róòmù 12:12.
Tá a bá ń fàwọn ìlànà dáadáa yìí sílò, a máa wà lálàáfíà, a máa ní ìtẹ́lọ́rùn, a máa lè ṣàwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́, a sì máa rí ìbùkún Ọlọ́run gbà. Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Akinori rèé (lápá òsì) nígbà tó ṣì ń ṣòwò, òun àtìyàwó ẹ̀ ni wọ́n jọ ń fìdùnnú wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run báyìí