Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ló ń mú kí “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” wá sínú “ilé” ìjọsìn tòótọ́?—Hágáì 2:7.
Jèhófà gbẹnu wòlíì Hágáì sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí.” (Hágáì 2:7) Ǹjẹ́ mímì tí Jèhófà ń mi “gbogbo orílẹ̀-èdè” jìgìjìgì ló ń mú kí “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ìyẹn àwọn tó ń wá Ọlọ́run tọkàntọkàn, wá sínú ìjọsìn tòótọ́? Rárá o.
Wo ohun tó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nítorí ìmìjìgìjìgì náà. Bíbélì sọ pé ‘àwọn orílẹ̀-èdè wà nínú ìrúkèrúdò, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè sì ń sọ nǹkan òfìfo lábẹ́lẹ̀.’ (Sáàmù 2:1) “Nǹkan òfìfo” tí wọ́n ń ‘sọ lábẹ́lẹ̀,’ tàbí tí wọ́n ń pète-pèrò rẹ̀ ni bí ìjọba wọn á ṣe máa bá a nìṣó. Kò sì sí ohun tó ń ba àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́rù tó ohunkóhun tó bá ń fi hàn pé ìjọba wọn máa pa run.
Iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe jákèjádò ayé nípa Ìjọba Ọlọ́run tó ti fìdí múlẹ̀ jẹ́ irú ohun tó ń bà wọ́n lẹ́rù bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù Kristi jẹ́ alákòóso rẹ̀ yìí yóò “fọ́ [àwọn ìjọba èèyàn] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ńṣe ni ìhìn ìdájọ́ tó wà lára ohun tá à ń wàásù ń mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì. (Aísáyà 61:2) Bí iṣẹ́ ìwàásù sì ṣe ń dé ibi púpọ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń kópa nínú rẹ̀ ni ìmìjìgìjìgì yìí ń le sí i. Àmì kí ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmìjìgìjìgì tó wà nínú Hágáì 2:7 jẹ́?
Hágáì 2:6 kà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Lẹ́ẹ̀kan sí i—láìpẹ́—èmi yóò sì mi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ jìgìjìgì.’” Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń fa ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí yọ, ó kọ̀wé pé: “Ó ti ṣèlérí pé: ‘Síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i dájúdájú kì í ṣe ilẹ̀ ayé nìkan ni èmi yóò fi sínú arukutu ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.’ Wàyí o, gbólóhùn náà ‘Síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i’ tọ́ka sí ìmúkúrò àwọn ohun tí a ń mì gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun tí a ti ṣe, kí àwọn ohun tí a kò mì [Ìjọba Ọlọ́run] lè dúró.” (Hébérù 12:26, 27) Láìsí àní-àní, Ọlọ́run yóò gbo ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí jìgìjìgì, tó túmọ̀ sí pé yóò pa á run pátápátá kí ayé tuntun tó ń ṣètò lè wọlé wá.
Òótọ́ ni pé àwọn tó ń wá Ọlọ́run tọkàntọkàn ń wá sínú ìjọsìn tòótọ́, àmọ́ kì í ṣe mímì tí Ọlọ́run ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì ló ń jẹ́ kí wọ́n wá. Ohun tó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì náà lohun tó ń mú kí àwọn èèyàn sún mọ́ Jèhófà kí wọ́n sì máa jọ́sìn rẹ̀, ohun náà sì ni ìwàásù jákèjádò ayé nípa Ìjọba Ọlọ́run tó ti fìdí múlẹ̀. Ìpolongo ‘ìhìn rere àìnípẹ̀kun tó jẹ́ làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀’ ló ń mú káwọn tó ń wá Ọlọ́run tọkàntọkàn wá sínú ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́.—Ìṣípayá 14:6, 7.
Apá méjì ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run pín sí, ìhìn ìdájọ́ àti ti ìgbàlà. (Aísáyà 61:1, 2) Ohun méjì ló sì ń ṣẹlẹ̀ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere jákèjádò ayé. Ìkíní, iṣẹ́ ìwàásù wa ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì. Ìkejì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra nínú àwọn orílẹ̀-èdè ń wọlé wá, èyí tó ń mú kí ògo Jèhófà túbọ̀ pọ̀ sí i.