Bẹ̀rù Jèhófà Káyé Rẹ Lè Dùn
“Ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ̀yin ẹni mímọ́ rẹ̀, nítorí kò sí àìní kankan fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.”—SÁÀMÙ 34:9.
1, 2. (a) Èrò méjì tó yàtọ̀ síra wo làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní nípa ìbẹ̀rù Ọlọ́run? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò báyìí?
ÀWỌN oníwàásù ní ṣọ́ọ̀ṣì máa ń wàásù pé káwọn èèyàn bẹ̀rù Ọlọ́run nítorí kí wọ́n má bàa lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì níbi tí wọ́n sọ pé Ọlọ́run ti ń dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lóró títí ayé. Àmọ́, ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni yìí kò bá ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ mu. Ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà ni pé ó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ àti onídàájọ́ òdodo. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19; Diutarónómì 32:4; Róòmù 6:23; 1 Jòhánù 4:8) Ọ̀tọ̀ sì tún lohun táwọn oníwàásù mìíràn máa ń sọ nínú ìwàásù tiwọn. Wọn kì í sọ pé káwọn èèyàn bẹ̀rù Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n máa ń kọ́ àwọn èèyàn ni pé kò sí ìwà tẹ́nì kan ń hù tí kò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Bíbélì kò sì fi irú nǹkan báyìí kọ́ni.—Gálátíà 5:19-21.
2 Ká sòótọ́, Bíbélì rọ̀ wá pé ká bẹ̀rù Ọlọ́run. (Ìṣípayá 14:7) Ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí mú ká béèrè àwọn ìbéèrè kan. Àwọn ìbéèrè náà ni pé, Kí nìdí tí Ọlọ́run tó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ fi fẹ́ ká máa bẹ̀rù òun? Irú ìbẹ̀rù wo ni Ọlọ́run ń fẹ́? Ọ̀nà wo ni bíbẹ̀rù Ọlọ́run lè gbà ṣe wá láǹfààní? A óò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjíròrò Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n.
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Bẹ̀rù Ọlọ́run
3. (a) Kí lèrò tìrẹ nípa àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé ká bẹ̀rù òun? (b) Kí nìdí táwọn tó bẹ̀rù Jèhófà fi máa ń láyọ̀?
3 Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá àti Alákòóso ayé àtọ̀run, ó yẹ ká bẹ̀rù rẹ̀. (1 Pétérù 2:17) Àmọ́ ṣá o, bíbẹ̀rù Ọlọ́run ò túmọ̀ sí pé kéèyàn máa gbọ̀n jìnnìjìnnì bí ìgbà táwọn èèyàn ń bẹ̀rù òrìṣà kan tó rorò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìbẹ̀rù tó ní ọ̀wọ̀ nínú nítorí irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ó tún jẹ́ ìbẹ̀rù ṣíṣàì fẹ́ ṣe ohun tó máa bí i nínú. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ ohun tó dára gan-an ó sì máa ń jẹ́ káyé ẹni dùn, kì í ṣe ohun tó ń kó ìbànújẹ́ báni tàbí tó ń kó ìpayà báni. Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ó sì fẹ́ káwa èèyàn tá a jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ gbádùn ayé wa. (1 Tímótì 1:11) Àmọ́ kí èyí tó lè rí bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́. Èyí túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ní láti yí bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn padà. Gbogbo àwọn tó ṣe ìyípadà tó yẹ ló ń rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Dáfídì, ọkàn lára àwọn tó kọ sáàmù sọ, ó ní: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í. Ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ̀yin ẹni mímọ́ rẹ̀, nítorí kò sí àìní kankan fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” (Sáàmù 34:8, 9) Gbogbo àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà kì í ṣaláìní ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní títí ayé, nítorí pé àárín àwọn àti Ọlọ́run gún régé.
4. Ọ̀rọ̀ ìdánilójú wo ni Dáfídì àti Jésù sọ?
4 Kíyè sí i pé Dáfídì pe àwọn ọkùnrin tó ń tẹ̀ lé e káàkiri ní “ẹni mímọ́.” Dáfídì lo ọ̀rọ̀ yẹn láti fi yẹ́ wọn sí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe láyé ìgbà yẹn. Ara orílẹ̀-èdè mímọ́ tó jẹ́ ti Ọlọ́run ni wọ́n. Bákan náà, wọ́n tún ń fi ẹ̀mí wọn wewu láti lè máa tẹ̀ lé Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń sá kiri nítorí Sọ́ọ̀lù Ọba, ọkàn Dáfídì balẹ̀ pé Jèhófà kò ní dáwọ́ dúró láti máa pèsè ohun táwọn nílò. Dáfídì sọ pé: “Àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ ní díẹ̀ lọ́wọ́, ebi sì ń pa wọ́n; ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ń wá Jèhófà, wọn kì yóò ṣaláìní ohun rere èyíkéyìí.” (Sáàmù 34:10) Irú ọ̀rọ̀ ìdánilójú yìí náà ni Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Mátíù 6:33.
5. (a) Irú èèyàn wo ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù? (b) Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fún wọn lórí ọ̀ràn ìbẹ̀rù?
5 Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Jésù ló jẹ́ àwọn Júù tí nǹkan ò ṣẹnuure fún, tí wọn kì í ṣe ẹni ńlá láwùjọ. Ìdí rèé tí ‘àánú wọn fi ṣe Jésù, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.’ (Mátíù 9:36) Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò ní ìgboyà láti tẹ̀ lé Jésù? Kí wọ́n tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rù Jèhófà, wọn ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù èèyàn. Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara àti lẹ́yìn èyí tí wọn kò lè ṣe nǹkan kan jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ́ka ẹni tí ẹ ní láti bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó jẹ́ pé lẹ́yìn pípani, ó ní ọlá àṣẹ láti sọni sínú Gẹ̀hẹ́nà. Bẹ́ẹ̀ ni, mo sọ fún yín, Ẹni yìí ni kí ẹ bẹ̀rù. Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n irun orí yín pàápàá ni a ti ka iye gbogbo wọn. Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́.”—Lúùkù 12:4-7.
6. (a) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ wo ló ń fún àwọn Kristẹni níṣìírí? (b) Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára jù lọ tá a bá ń sọ nípa níní ìbẹ̀rù Ọlọ́run?
6 Nígbà táwọn ọ̀tá bá gbé wàhálà dìde sáwọn tó bẹ̀rù Jèhófà láti mú kí wọ́n jáwọ́ nínú sísin Ọlọ́run, wọ́n lè rántí ìmọ̀ràn Jésù pé: “Gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ níní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi níwájú àwọn ènìyàn, Ọmọ ènìyàn pẹ̀lú yóò jẹ́wọ́ níní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi níwájú àwọn ènìyàn ni a óò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:8, 9) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti fún àwọn Kristẹni níṣìírí láti má ṣe jáwọ́ nínú sísin Ọlọ́run, àgàgà láwọn orílẹ̀-èdè tí ìjọba ti fòfin de ìjọsìn tòótọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń fi ọgbọ́n yin Jèhófà nìṣó láwọn ìpàdé Kristẹni àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Ìṣe 5:29) Tó bá di ọ̀rọ̀ fífi ‘ìbẹ̀rù Ọlọ́run’ hàn, Jésù fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀. (Hébérù 5:7) Nígbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sàsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù, ó ní: “Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e, ẹ̀mí . . . ìbẹ̀rù Jèhófà; ìgbádùn rẹ̀ yóò sì wà nínú ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Aísáyà 11:2, 3) Nípa báyìí, Jésù kúnjú ìwọ̀n gan-an láti kọ́ wa nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
7. (a) Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni gbà ń ṣe ohun tó jọ nǹkan tí Dáfídì ní káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe? (b) Ọ̀nà wo làwọn òbí lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere ti Dáfídì?
7 Ńṣe ni gbogbo àwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tí wọ́n sì ń fi àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílò ń ṣe ohun kan tó jọ èyí tí Dáfídì ní káwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣe. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ fetí sí mi; ìbẹ̀rù Jèhófà ni èmi yóò kọ́ yín.” (Sáàmù 34:11) Ó rọrùn fún Dáfídì láti pe àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní “ọmọ” nítorí wọ́n mọ̀ pé aṣáájú àwọn ló jẹ́. Dáfídì pàápàá sì ran àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wọ̀nyí lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run, kí wọ́n lè wà níṣọ̀kan kí wọ́n sì rí ojú rere Ọlọ́run. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fáwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni! Jèhófà ti fún wọn láṣẹ lórí àwọn ọmọ wọn, pé kí wọ́n “máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Báwọn òbí bá ń jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn lójoojúmọ́ tí wọ́n sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, wọ́n á lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti bẹ̀rù Jèhófà, èyí táá jẹ́ káwọn ọmọ náà lè gbádùn ayé wọn.—Diutarónómì 6:6, 7.
Bá A Ṣe Lè Máa Fi Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Hàn
8, 9. (a) Kí nìdí tí bíbẹ̀rù Ọlọ́run nígbèésí ayé ẹni fi dára gan-an? (b) Kí ni fífi ìṣọ́ ṣọ́ ahọ́n wa túmọ̀ sí?
8 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, bíbẹ̀rù Jèhófà kò ní kéèyàn má láyọ̀. Dáfídì béèrè pé: “Ta ni ènìyàn tí ó ní inú dídùn sí ìwàláàyè, tí ó nífẹ̀ẹ́ ọjọ́ púpọ̀, kí ó lè máa rí ohun rere?” (Sáàmù 34:12) Dájúdájú, ìbẹ̀rù Jèhófà ṣe pàtàkì téèyàn bá fẹ́ kí ẹ̀mí òun gùn, káyé òun dára, kóun sì rí ohun rere láyé. Àmọ́ ó rọrùn kẹ́nì kan sọ pé, “Mo bẹ̀rù Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ká máa fi hàn nínú ìwà wa. Ìdí nìyí tí Dáfídì fi tẹ̀ síwájú láti ṣàlàyé ọ̀nà tá a lè gbà fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn.
9 “Máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ahọ́n rẹ kúrò nínú ohun búburú, àti ètè rẹ kúrò nínú ṣíṣe ẹ̀tàn.” (Sáàmù 34:13) Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù ti fún àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa fìfẹ́ bá ara wọn lò, Ọlọ́run mí sí i láti fa ọ̀rọ̀ inú Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n yìí yọ. (1 Pétérù 3:8-12) Fífi ìṣọ́ ṣọ́ ahọ́n wa kúrò nínú ohun tó burú túmọ̀ sí pé a ó ní máa tan òfófó tó ń pani lára kálẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó máa sapá nígbà gbogbo láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí à ń sọ máa gbé àwọn ẹlòmíràn ró. Síwájú sí i, a ó sapá láti jẹ́ onígboyà ká lè máa sọ òtítọ́.—Éfésù 4:25, 29, 31; Jákọ́bù 5:16.
10. (a) Ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti yí padà kúrò nínú ohun búburú. (b) Kí ni ṣíṣe ohun tó dára túmọ̀ sí?
10 “Yí padà kúrò nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe ohun rere; máa wá ọ̀nà láti rí àlàáfíà, kí o sì máa lépa rẹ̀.” (Sáàmù 34:14) A kì í ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́, irú bí àgbèrè tàbí panṣágà, wíwo àwòrán oníhòòhò, olè jíjà, ìbẹ́mìílò, ìwà ipá, mímú ọtí nímukúmu, àti lílo oògùn olóró. Bẹ́ẹ̀ la ò kì í wo irú àwọn nǹkan ìríra wọ̀nyẹn lórí tẹlifíṣọ̀n, íńtánẹ́ẹ̀tì àti làwọn ibòmíràn. (Éfésù 5:10-12) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó dára là ń lo àkókò wa fún. Ohun tó sì dára jù lọ tá a lè ṣe ni pé ká máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ká máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Àwọn ohun rere mìíràn tá a tún lè máa ṣe ni mímúra àwọn ìpàdé Kristẹni sílẹ̀ ká sì máa wà níbẹ̀, ká máa fi owó wa ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ karí ayé, ká máa tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ká sì máa ṣèrànwọ́ fáwọn Kristẹni tó jẹ́ aláìní.
11. (a) Báwo ni Dáfídì ṣe fi ohun tó sọ nípa àlàáfíà sílò? (b) Kí lo lè ṣe kó o lè máa ‘lépa àlàáfíà’ nínú ìjọ?
11 Dáfídì fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ wíwá àlàáfíà. Ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló láǹfààní láti pa Sọ́ọ̀lù. Àmọ́ nígbà méjèèjì yìí, ó kọ̀ láti pa á, ó sì bá ọba náà sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lẹ́yìn náà, kí àlàáfíà tún lè padà wà láàárín wọn. (1 Sámúẹ́lì 24:8-11; 26:17-20) Kí la lè ṣe lónìí bí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó fẹ́ dá ìṣòro sílẹ̀ nínú ìjọ? Ó yẹ ká “wá ọ̀nà láti rí àlàáfíà, kí [a] sì máa lépa rẹ̀.” Nípa báyìí, tá a bá ṣàkíyèsí pé àárín àwa àti onígbàgbọ́ bíi tiwa kan kò dán mọ́rán, ó yẹ ká fi ìmọ̀ràn Jésù sílò, èyí tó sọ pé: “Kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ.” Lẹ́yìn náà ká wá máa bá àwọn apá yòókù nínú ìjọsìn tòótọ́ lọ.—Mátíù 5:23, 24; Éfésù 4:26.
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Lérè Púpọ̀
12, 13. (a) Àǹfààní wo làwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run ń rí gbà lọ́wọ́lọ́wọ́? (b) Èrè tí kò lẹ́gbẹ́ wo làwọn tó ń sin Jèhófà máa rí gbà láìpẹ́?
12 “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.” (Sáàmù 34:15) Àkọsílẹ̀ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá Dáfídì lò fi hàn pé òótọ́ lohun tí sáàmù yìí sọ. Lọ́jọ́ òní, à ní ojúlówó ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn nítorí a mọ̀ pé Jèhófà ń pa wá mọ́. Ọkàn wa balẹ̀ pé kò sígbà kan tí kò ní pèsè ohun tá a nílò fún wa, kódà bá a tilẹ̀ wà nínú ìṣòro ńlá pàápàá. A mọ̀ pé láìpẹ́, gbogbo àwọn olùjọ́sìn Jèhófà pátá ni yóò rí inúnibíni tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù máa ṣe sí wọn, àti pé “ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà” ń bọ̀ lọ́nà. (Jóẹ́lì 2:11, 31; Ìsíkíẹ́lì 38:14-18, 21-23) Ìṣòro yòówù ká rí lákòókò náà, ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yóò ṣẹ sí wa lára pé: “Wọ́n ké jáde, Jèhófà sì gbọ́, ó sì dá wọn nídè nínú gbogbo wàhálà wọn.” —Sáàmù 34:17.
13 Ó dájú pé ìdùnnú á ṣubú layọ̀ lákòókò yẹn nígbà tá a bá rí i tí Jèhófà gbé orúkọ ńlá rẹ̀ ga! A óò túbọ̀ wá ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run gan-an nínú ọkàn wa ju ti ìgbàkígbà rí lọ, gbogbo àwọn alátakò yóò sì kú ikú ẹ̀sín. “Ojú Jèhófà lòdì sí àwọn tí ń ṣe ohun búburú, láti ké mímẹ́nukàn wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ ayé pàápàá.” (Sáàmù 34:16) Ẹ ò rí i pé èrè tí kò lẹ́gbẹ́ ló máa jẹ́ tiwa nígbà tí Jèhófà bá gbà wá là lọ́nà àgbàyanu sínú ayé tuntun rẹ̀ tí yóò dá lórí òdodo!
Àwọn Ìlérí Tó Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Ní Ìfaradà
14. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfaradà bá a tiẹ̀ wà nínú ìṣòro?
14 Kí àkókò yẹn tó dé, a nílò ìfaradà láti lè máa ṣègbọràn sí Jèhófà nìṣó nínú ayé tó ti bàjẹ́ yìí, táwọn èèyàn ò sì nífẹ̀ẹ́ èèyàn ẹlẹ́gbẹ́ wọn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti máa ṣègbọràn. Nítorí pé àkókò lílekoko la wà, àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń rí ìnira tó lékenkà tó sì ń kó ìbànújẹ́ ọkàn ńláǹlà àti ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Àmọ́ o, kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó dá wọn lójú gan-an pé, bí wọ́n bá gbára lé Jèhófà, yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìfaradà. Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ lè fún wọn ní ojúlówó ìtùnú, ó ní: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:18) Dáfídì tún wá sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí mìíràn pé: “Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo, ṣùgbọ́n Jèhófà ń dá a nídè nínú gbogbo wọn.” (Sáàmù 34:19) Bó ti wù káwọn ìṣòro wa pọ̀ tó, Jèhófà lágbára láti gbà wá.
15, 16. (a) Àjálù wo ni Dáfídì gbọ́ pé ó wáyé kété lẹ́yìn tó ṣàkójọ Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n? (b) Ọ̀rọ̀ ìdánilójú wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti lè fara da àdánwò?
15 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Dáfídì ṣàkójọ Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n yẹn ló gbọ́ nípa àjálù tó bá àwọn ará ìlú Nóbù, nígbà tí Sọ́ọ̀lù pa àwọn èèyàn náà nípakúpa tó sì tún pa èyí tó pọ̀ jù lára àwọn wòlíì tó ń gbé níbẹ̀. Ẹ wo bí inú Dáfídì yóò ti bà jẹ́ tó nígbà tó bá rántí pé lílọ tóun lọ sílùú Nóbù ló fa ìbínú Sọ́ọ̀lù yìí! (1 Sámúẹ́lì 22:13, 18-21) Kò sí àní-àní pé Dáfídì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ó sì dájú pé ìrètí tó ní pé àjíǹde wà fún “àwọn olódodo” lọ́jọ́ iwájú tù ú nínú gan-an.—Ìṣe 24:15.
16 Lónìí, ìrètí pé àjíǹde ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú ń fún àwa náà lókun. A mọ̀ pé kò sí ohunkóhun táwọn ọ̀tá wa lè ṣe tó lè ṣèpalára ayérayé fún wa. (Mátíù 10:28) Dáfídì fi hàn pé òun ní irú ìdánilójú yìí nígbà tó sọ pé: “Ó ń ṣọ́ gbogbo egungun ẹni yẹn; a kò ṣẹ́ ìkankan nínú wọn.” (Sáàmù 34:20) Jésù ni ẹsẹ sáàmù yìí ṣẹ sí lára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ìkà ni wọ́n gbà pa Jésù, wọn ò “fọ́” ìkankan lára egungun rẹ̀. (Jòhánù 19:36) Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n ẹsẹ ogún yìí tún ń nímùúṣẹ lọ́nà mìíràn, ó mú un dá wa lójú pé kò sí àdánwò tó lè dé bá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó lè ṣèpalára fún wọn títí ayé. Àwọn ọ̀tá kò ní fọ́ egungun wọn láé, tó túmọ̀ sí pé wọn ò lè rí wọn gbé ṣe.—Jòhánù 10:16.
17. Àjálù wo ló ń dúró de àwọn tó kórìíra àwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n sì kọ̀ tí wọn ò ronú pìwà dà?
17 Àmọ́, àwọn ẹni ibi kò lè rí irú ààbò yìí o. Láìpẹ́, wọ́n á kórè ìwà ibi tí wọ́n ń hù. “Ìyọnu àjálù ni yóò fi ikú pa ẹni burúkú alára; àní àwọn tí ó kórìíra olódodo ni a ó kà sí ẹlẹ́bi.” (Sáàmù 34:21) Gbogbo àwọn tí kò yéé ta ko àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò rí àjálù tírú rẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí. Nígbà ìfarahàn Jésù Kristi, wọn “yóò fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.”—2 Tẹsalóníkà 1:9.
18. Ọ̀nà wo làwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” gbà dẹni tá a rà padà nísinsìnyí, àǹfààní wo ló sì máa jẹ́ tiwọn lọ́jọ́ iwájú?
18 Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ ni Dáfídì fi kádìí sáàmù yìí, ó ní: “Jèhófà ń tún ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rà padà; kò sì sí ìkankan lára àwọn tí ń sá di í tí a ó kà sí ẹlẹ́bi.” (Sáàmù 34:22) Nígbà tí ogójì ọdún tí Dáfídì Ọba fi ṣàkóso ń lọ sópin, ó ní: “[Ọlọ́run] tún ọkàn mi rà padà kúrò nínú gbogbo wàhálà.” (1 Àwọn Ọba 1:29) Bíi ti Dáfídì, á ṣeé ṣe láìpẹ́ fáwọn tó bẹ̀rù Jèhófà láti ronú padà sẹ́yìn tí wọ́n á sì láyọ̀ pé Ọlọ́run kò jẹ́ káwọn ní ìdálẹ́bi ọkàn mọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀. Wọ́n á sì tún láyọ̀ pé ó kó àwọn yọ nínú gbogbo àdánwò wọn. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, èyí tò pọ̀ jù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti gba èrè wọn lọ́run. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” èèyàn tí wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ń dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn arákùnrin Jésù láti sin Ọlọ́run, èyí sì mú kí wọ́n wà nípò mímọ́ lójú Jèhófà. Ìdí ni pé, wọ́n ń ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù tó lè rani padà. Nígbà Ìjọba Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Kristi tó ń bọ̀ lọ́nà, wọ́n á jàǹfààní ẹbọ ìràpadà náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, èyí táá mú kí wọ́n di ẹni pípé.—Ìṣípayá 7:9, 14, 17; 21:3-5.
19. Kí làwọn tó jẹ́ ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” pinnu láti máa ṣe?
19 Ki nìdí tí gbogbo àǹfààní yìí yóò fi jẹ́ ti “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí wọ́n jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run? Ìdí ni pé wọ́n pinnu láti máa bẹ̀rù Jèhófà nìṣó, wọ́n ń sìn ín pẹ̀lú ìwárìrì, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ká sòótọ́, ìbẹ̀rù Jèhófà ń mú ká gbádùn ayé wa lákòókò yìí, ó sì ń jẹ́ ká lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run.—1 Tímótì 6:12, 18, 19; Ìṣípayá 15:3, 4.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká bẹ̀rù Ọlọ́run, kí sì ni bíbẹ̀rù rẹ̀ túmọ̀ sí?
• Báwo ló ṣe yẹ kí ìbẹ̀rù Ọlọ́run nípa lórí ìwà wa?
• Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run?
• Àwọn ìlérí wo ló ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà máa ń fi ọgbọ́n sin Ọlọ́run nígbà tí ìjọba bá fòfin de ìjọsìn wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Oore tó tóbi jù lọ tá a lè ṣe fáwọn èèyàn ni pé ká sọ ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fun wọn