ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1
‘Àwọn Tó Ń Wá Jèhófà Kò Ní Ṣaláìní Ohun Rere’
ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ TI ỌDÚN 2022: ‘Àwọn tó ń wá Jèhófà kò ní ṣaláìní ohun rere.’—SM. 34:10.
ORIN 4 “Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Ìṣòro wo ló dé bá Dáfídì?
OHUN kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí Dáfídì máa sá fún ẹ̀mí ẹ̀. Kí lohun náà? Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọba Ísírẹ́lì ló ń wọ́nà àtigbẹ̀mí ẹ̀. Níbi tí Dáfídì ti ń sá lọ, ebi ń pa á, ó wá fẹsẹ̀ kan yà nílùú Nóbù, ó sì ní kí wọ́n fún òun ní búrẹ́dì márùn-ún péré. (1 Sám. 21:1, 3) Nígbà tó sì yá, òun àtàwọn èèyàn ẹ̀ fara pa mọ́ sínú ihò kan. (1 Sám. 22:1) Kí ló fà á tí Ọba Sọ́ọ̀lù fi ń lé Dáfídì kiri, tó sì ń wọ́nà àtigbẹ̀mí ẹ̀?
2. Kí ni Sọ́ọ̀lù ṣe tó mú kó dà bíi pé ó ń bá Ọlọ́run jà? (1 Sámúẹ́lì 23:16, 17)
2 Inú ń bí Sọ́ọ̀lù burúkú burúkú sí Dáfídì, ó sì ń jowú ẹ̀ torí pé àwọn èèyàn gba ti Dáfídì gan-an, wọ́n sì ń yìn ín torí pé ó jẹ́ akin lójú ogun. Yàtọ̀ síyẹn, Sọ́ọ̀lù mọ̀ pé Jèhófà ti kọ òun lọ́ba nítorí ìwà àìgbọràn tóun hù àti pé Jèhófà ti yan Dáfídì láti di ọba dípò òun. (Ka 1 Sámúẹ́lì 23:16, 17.) Síbẹ̀, torí pé Sọ́ọ̀lù ṣì ni ọba Ísírẹ́lì àti pé òun ló ń darí àwọn ọmọ ogun, àwọn èèyàn ń tì í lẹ́yìn gan-an. Torí náà, Dáfídì ní láti sá fún ẹ̀mí ẹ̀. Ṣé Sọ́ọ̀lù ronú pé òun lè ṣe é kí Dáfídì má di ọba bí Ọlọ́run ṣe sọ? (Àìsá. 55:11) Bíbélì ò sọ, àmọ́ ohun kan dá wa lójú. Ṣe ló dà bí ẹni pé Sọ́ọ̀lù ń bá Ọlọ́run jà, ó sì yẹ kó mọ̀ pé kò sẹ́ni tó máa bá Ọlọ́run jà tó lè borí!
3. Bí ipò nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn, kí ni Dáfídì ò ṣe? Àmọ́ kí ló ṣe?
3 Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Dáfídì, òun kọ́ ló ń wá bó ṣe máa di ọba Ísírẹ́lì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ló yàn án. (1 Sám. 16:1, 12, 13) Àmọ́ ní ti Sọ́ọ̀lù, ó kórìíra Dáfídì, kò sì fẹ́ rí imí ẹ̀ láàtàn. Bó ti wù kó rí, Dáfídì ò sọ pé Jèhófà ló fà á tí Sọ́ọ̀lù fi ń wọ́nà àtigbẹ̀mí òun, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ráhùn pé òun ò fi bẹ́ẹ̀ rí oúnjẹ jẹ àti pé inú ihò lásán-làsàn lòun ọmọ onílé ọlọ́nà ń gbé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ inú ihò yẹn ló wà nígbà tó kọrin ìyìn sí Jèhófà pé: ‘Àwọn tó ń wá Jèhófà kò ní ṣaláìní ohun rere.’—Sm. 34:10.
4. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká dáhùn àwọn ìbéèrè náà?
4 Lónìí, ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lọ̀rọ̀ àtijẹ àtimu ti di ìṣòro fún, bẹ́ẹ̀ sì la ò fi bẹ́ẹ̀ láwọn nǹkan ìgbẹ́mìíró míì.b Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn, pàápàá lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn yìí. A sì tún lè retí pé kí nǹkan túbọ̀ nira ní báyìí tí “ìpọ́njú ńlá” ti sún mọ́lé. (Mát. 24:21) Pẹ̀lú àwọn kókó yìí lọ́kàn wa, ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́rin yìí. Àkọ́kọ́, kí ló fi hàn pé Dáfídì ò “ṣaláìní ohun rere”? Ìkejì, kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ káwọn nǹkan tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn? Ìkẹta, kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa bójú tó wa? Àti ìkẹrin, báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú?
“ÈMI KÌ YÓÒ ṢALÁÌNÍ”
5-6. Báwo ni Sáàmù 23:1-6 ṣe jẹ́ ká lóye ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò ní “ṣaláìní ohun rere”?
5 Kí ni Dáfídì ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò ní “ṣaláìní ohun rere”? A lè lóye ohun tó ní lọ́kàn tá a bá wo Sáàmù kẹtàlélógún (23) níbi tó ti lo ọ̀rọ̀ kan náà. (Ka Sáàmù 23:1-6.) Gbólóhùn àkọ́kọ́ tí Dáfídì sọ nínú sáàmù yẹn ni: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní.” Nínú àwọn ẹsẹ tó kù, Dáfídì sọ nípa àwọn nǹkan tó ṣeyebíye jù lọ, ìyẹn àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣe fún un torí pé ó gbà kí Jèhófà máa bójú tó òun. Jèhófà darí Dáfídì “ní ipa ọ̀nà òdodo,” ó sì dúró tì í nígbà dídùn àti nígbà kíkan. Dáfídì mọ̀ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé “ibi ìjẹko tútù” ni Jèhófà mú kóun dùbúlẹ̀ sí, òun ò bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìgbà kan wà tó rẹ̀wẹ̀sì, bí ìgbà tó ń rìn “nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri,” bẹ́ẹ̀ ló tún ní àwọn ọ̀tá. Àmọ́ Dáfídì ò “bẹ̀rù ewukéwu” torí pé abẹ́ àbójútó Jèhófà ló wà.
6 Torí náà, kí ni ìdáhùn ìbéèrè wa àkọ́kọ́, ìyẹn: Kí ló fi hàn pé Dáfídì ò “ṣaláìní ohun rere”? Ìdáhùn náà ni pé Dáfídì ní gbogbo ohun tó nílò táá jẹ́ kí àjọṣe àárín òun àti Jèhófà túbọ̀ gún régé. Kì í ṣe àwọn nǹkan tara ló mú kó máa láyọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí ìwọ̀nba nǹkan tí Jèhófà fún òun tẹ́ òun lọ́rùn. Ohun tó jẹ Dáfídì lógún ni bó ṣe máa rí ojúure Jèhófà àti ààbò rẹ̀.
7. Bó ṣe wà nínú Lúùkù 21:20-24, ìṣòro wo làwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní?
7 Ohun tí Dáfídì sọ jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra káwọn nǹkan tara má lọ gbà wá lọ́kàn jù. Kò sóhun tó burú nínú pé ká gbádùn àwọn nǹkan tara tá a ní, àmọ́ a gbọ́dọ̀ kíyè sára kó má di pé àwọn nǹkan yìí la kà sí pàtàkì jù. Kókó yìí làwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tó gbé ní Jùdíà lọ́gọ́rùn-ún ọdún kìíní rántí nígbà tí ipò nǹkan yí pa dà. (Ka Lúùkù 21:20-24.) Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù ti kìlọ̀ fún wọn pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “àwọn ọmọ ogun [máa] pàgọ́ yí Jerúsálẹ́mù ká.” Ó sọ fún wọn pé tó bá ti ṣẹlẹ̀, kí wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.” Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á sá àsálà. Àmọ́, ìyẹn máa gba pé kí wọ́n filé fọ̀nà wọn sílẹ̀. Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: “Wọ́n filé fọ̀nà wọn sílẹ̀, wọn ò tiẹ̀ kó dúkìá tí wọ́n ní sílé pàápàá. Nítorí pé wọ́n nígbọ̀ọ́kànlé pé Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn àti pé yóò pèsè fáwọn, wọ́n fi ìjọsìn rẹ̀ ṣáájú ohunkóhun tó lè jọ pé ó ṣe pàtàkì.”
8. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yẹn?
8 Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yẹn? Ilé Ìṣọ́ kan náà yẹn sọ pé: “Lọ́jọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe ká kojú àwọn àdánwò kan torí ojú tá a fi ń wo nǹkan tara; ṣé àwọn nǹkan yẹn la kà sí pàtàkì jù àbí bí Ọlọ́run ṣe máa gbà wá là? Tó bá dìgbà yẹn, ó lè pọn dandan pé ká ṣe àwọn àyípadà kan, ìyẹn sì lè mú kí nǹkan nira fún wa. Torí náà, ó yẹ ká múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó yẹ ká ṣe, bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n sá kúrò ní Jùdíà.”c
9. Kí lo rí kọ́ nínú ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Hébérù?
9 Wo bí nǹkan ṣe máa rí fáwọn Kristẹni yẹn lẹ́yìn tí wọ́n filé fọ̀nà wọn sílẹ̀ lọ sílùú míì. Ṣé o rò pé ó máa rọrùn? Kò sí àní-àní pé ó gba ìgbàgbọ́ torí ó gbọ́dọ̀ dá wọn lójú pé Jèhófà máa pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Bó ti wù kó rí, ohun kan wà tó mú kíyẹn ṣeé ṣe. Kí ni nǹkan náà? Lọ́dún márùn-ún ṣáájú ìgbà táwọn ọmọ ogun Róòmù yí Jerúsálẹ́mù ká, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù yẹn nímọ̀ràn tó máa ṣe wọ́n láǹfààní, ó ní: “Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn. Torí ó ti sọ pé: ‘Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.’ Ká lè nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?’” (Héb. 13:5, 6) Ẹ wo bí nǹkan ṣe máa rọrùn tó fáwọn tó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù kó tó di pé àwọn ọmọ ogun Róòmù dé. Ìyẹn ni ò jẹ́ kó nira fún wọn láti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ní níbi tuntun tí wọ́n lọ. Wọn ò ṣiyèméjì pé Jèhófà máa bójú tó àwọn. Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí jẹ́ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa bójú tó wa.
“ÀWỌN NǸKAN YÌÍ MÁA TẸ́ WA LỌ́RÙN”
10. “Àṣírí” wo ni Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀?
10 Irú ìmọ̀ràn yìí náà ni Pọ́ọ̀lù gba Tímótì, ìmọ̀ràn yẹn sì wúlò fáwa náà lónìí. Ó sọ pé: “Torí náà, tí a bá ti ní oúnjẹ àti aṣọ, àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.” (1 Tím. 6:8) Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé a ò lè gbádùn oúnjẹ aládùn, ká gbélé tó dùn ún wò tàbí pé a ò lè ra aṣọ látìgbàdégbà? Rárá, ohun tó ń sọ kọ́ nìyẹn. Ohun tó ń sọ ni pé ká jẹ́ káwọn nǹkan tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn. Ìyẹn ló pè ní “àṣírí” nínú Fílípì 4:12. Ká má gbàgbé pé ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa ni àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà kì í ṣe àwọn nǹkan tara tá a ní.—Háb. 3:17, 18.
11. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tí Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn?
11 Nígbà míì, ohun tá a rò pé a nílò lè yàtọ̀ sí ohun tí Jèhófà mọ̀ pé a nílò gan-an. Àpẹẹrẹ kan lohun tí Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n ti lo ogójì ọdún nínú aginjù. Ó sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o ṣe. Ó mọ gbogbo bí o ṣe ń rìn nínú aginjù tó tóbi yìí dáadáa. Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà pẹ̀lú rẹ jálẹ̀ ogójì (40) ọdún yìí, o ò sì ṣaláìní ohunkóhun.” (Diu. 2:7) Jálẹ̀ gbogbo ogójì ọdún yẹn, Jèhófà bójú tó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ń fún wọn ní mánà jẹ. Bákan náà, aṣọ wọn ò gbó, ìyẹn àwọn aṣọ tí wọ́n mú kúrò ní Íjíbítì. (Diu. 8:3, 4) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára wọn gbà pé àwọn nǹkan yẹn ò tó, Mósè rán wọn létí pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò ni Jèhófà fún wọn. Inú Jèhófà máa dùn tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn. Ó fẹ́ ká mọyì àwọn nǹkan tí òun ń ṣe fún wa, ká gbà pé ìbùkún látọ̀dọ̀ òun ni wọ́n jẹ́, ká sì fi hàn pé a moore.
GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ, Ó MÁA BÓJÚ TÓ Ẹ
12. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ni Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé, kì í ṣe ara ẹ̀?
12 Dáfídì mọ̀ pé atóófaratì ni Jèhófà, kò sì fọ̀rọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣeré rárá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí Dáfídì wà nínú ewu nígbà tó kọ Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n (34), ó dá a lójú pé “áńgẹ́lì Jèhófà pàgọ́ yí [òun] ká.” (Sm. 34:7) Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni Dáfídì ń fi áńgẹ́lì Jèhófà wé ọmọ ogun kan tó wà lójúfò káwọn ọ̀tá má bàa yọ́ wọ àárín wọn. Òótọ́ ni pé akin lójú ogun ni Dáfídì àti pé Jèhófà ti fi í lọ́kàn balẹ̀ pé òun ló máa di ọba Ísírẹ́lì, síbẹ̀ kò gbára lé ara ẹ̀ kó wá máa ronú pé òun lè fi kànnàkànnà tàbí idà rẹ́yìn àwọn ọ̀tá. (1 Sám. 16:13; 24:12) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì dá a lójú pé áńgẹ́lì Jèhófà ‘ń gba àwọn tó bẹ̀rù Rẹ̀ sílẹ̀.’ Ká sòótọ́, a ò retí pé kí Jèhófà dá wa nídè lọ́nà ìyanu lónìí, àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé ẹnikẹ́ni tó gbẹ́kẹ̀ lé e. Bí wọ́n tiẹ̀ kú, ó ṣì máa jí wọn dìde kí wọ́n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun.
13. Kí nìdí tó fi máa dà bíi pé a ò ní olùrànlọ́wọ́ nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbéjà kò wá, àmọ́ kí nìdí tí ò fi yẹ ká bẹ̀rù? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
13 Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, gbogbo wa pátá la máa fi hàn bóyá ó dá wa lójú tàbí kò dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bò wá. Nígbà tí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tí Bíbélì pè ní Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run, ṣe ló máa dà bíi pé wẹ́rẹ́ ni wọ́n á pa wá run. Lásìkò yẹn, ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti dá wa nídè, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀. Lójú àwọn orílẹ̀-èdè yẹn, a máa dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ tó lè dáàbò bò wọ́n. (Ìsík. 38:10-12) Ó ṣe tán, a ò níbọn tàbí àwọn nǹkan ìjà ogun míì, bẹ́ẹ̀ la ò sì kọ́ṣẹ́ ogun. Torí náà, àwọn orílẹ̀-èdè máa ronú pé ṣìnkún báyìí lọwọ́ àwọn á tẹ̀ wá. Ó mà ṣe o, àwọn orílẹ̀-èdè ò ní rí ohun tá à ń fojú ìgbàgbọ́ wa rí, ìyẹn àwọn ọmọ ogun ọ̀run tí wọ́n pagbo yí wa ká, tí wọ́n sì ṣe tán láti gbèjà wa. Kí nìdí tí wọn ò fi rí àwọn ọmọ ogun ọ̀run yẹn? Ìdí ni pé wọn ò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ó dájú pé wọ́n á kan ìdin nínú iyọ̀ nígbà tí àwọn ọmọ ogun ọ̀run bá gbèjà wa!—Ìfi. 19:11, 14, 15.
MÚRA SÍLẸ̀ DE ÌPỌ́NJÚ ŃLÁ
14. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe ká lè múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá?
14 Kí làwọn nǹkan tá a lè ṣe báyìí ká lè múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá? Àkọ́kọ́, ká rí i dájú pé a ò jẹ́ káwọn nǹkan tara gbà wá lọ́kàn jù, torí pé bópẹ́bóyá, a máa fi àwọn nǹkan yẹn sílẹ̀. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ káwọn ohun tá a ní báyìí tẹ́ wa lọ́rùn, àmọ́ ká rí i dájú pé àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà lohun tó ń fún wa láyọ̀ jù lọ. Ìdí ni pé bá a ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà, tí àárín wa pẹ̀lú rẹ̀ sì gún régé, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ dá wa lójú pé ó máa dá wa nídè nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbéjà kò wá.
15. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì nígbà tó wà ní kékeré tó jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà ò ní fi òun sílẹ̀?
15 Ẹ jẹ́ ká wo ohun míì tó ran Dáfídì lọ́wọ́ láti fara da àdánwò tó sì tún lè ran àwa náà lọ́wọ́. Dáfídì sọ pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà, aláyọ̀ ni ọkùnrin tí ó fi í ṣe ibi ààbò.” (Sm. 34:8) Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí jẹ́ ká rí ìdí tó fi gbà pé Jèhófà ò ní fòun sílẹ̀ láé. Ó sábà máa ń gbára lé Jèhófà, Jèhófà náà ò sì já a kulẹ̀. Nígbà tí Dáfídì wà ní kékeré, ó kojú Gòláyátì tó jẹ́ àkòtagìrì olórí ogun Filísínì, ó sì sọ fún un pé: “Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́.” (1 Sám. 17:46) Nígbà tó yá, Dáfídì di ìránṣẹ́ fún Ọba Sọ́ọ̀lù, àwọn ìgbà kan sì wà tí Sọ́ọ̀lù ń wá bó ṣe máa pa á. Àmọ́ “Jèhófà wà pẹ̀lú” Dáfídì. (1 Sám. 18:12) Bí Dáfídì ṣe rí ọwọ́ Jèhófà nígbèésí ayé ẹ̀ yìí mú kó dá a lójú pé Jèhófà ò ní fi òun sílẹ̀ láé, kò sì ní dá òun dá ìṣòro òun.
16. Àwọn ìgbà wo la lè “tọ́” Jèhófà wò, ká sì rí i pé ẹni rere ni?
16 Tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára báyìí láti máa gbára lé Jèhófà, ọkàn wa á túbọ̀ balẹ̀ pé á ràn wá lọ́wọ́, á sì dáàbò bò wá lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, ó gba ìgbàgbọ́, ó sì gba pé kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kéèyàn tó lè lọ tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá ẹ̀ pé òun fẹ́ lọ sí àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ agbègbè. Ohun kan náà ló máa gbà kéèyàn tó lè béèrè pé kí wọ́n fún òun láyè láti máa lọ sí gbogbo ìpàdé, kóun sì tún máa jáde òde ẹ̀rí déédéé. Àmọ́ ká wá sọ pé ọ̀gá wa ò fún wa láyè, tí iṣẹ́ sì bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́ ńkọ́? Ṣé a nígbàgbọ́ pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ tàbí pa wá tì láé àti pé ó máa pèsè àwọn ohun tá a nílò? (Héb. 13:5) Àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ti rí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Wọ́n láwọn ìrírí tó fi hàn pé Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n wà nínú ìṣòro. Ká sòótọ́, adúrótini ni Jèhófà.
17. Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2022, kí sì nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú?
17 Torí pé Jèhófà wà lẹ́yìn wa, kò sídìí pé à ń bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó dá wa lójú pé Baba wa ọ̀run ò ní fi wá sílẹ̀ láé. Ìyẹn tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Ìjọba rẹ̀ ló gbawájú láyé wa. Torí náà, ká lè máa rántí bó ti ṣe pàtàkì tó láti múra sílẹ̀ de àwọn àdánwò tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá pé kò ní fi wá sílẹ̀, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti yan Sáàmù 34:10 pé kó jẹ́ Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tọdún 2022. Ó kà pé: ‘Àwọn tó ń wá Jèhófà kò ní ṣaláìní ohun rere.’
ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára
a Inú Sáàmù 34:10 la ti mú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2022. Ó kà pé: ‘Àwọn tó ń wá Jèhófà kò ní ṣaláìní ohun rere.’ Òótọ́ kan ni pé ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ni ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé wọn ò ní “ṣaláìní ohun rere”? Tá a bá lóye ohun tí Sáàmù yìí ń sọ, báwo ló ṣe máa jẹ́ ká lè múra de ìṣòro tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?
b Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ September 15, 2014.
d ÀWÒRÁN: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ihò àpáta ni Dáfídì sá pa mọ́ sí kọ́wọ́ Ọba Sọ́ọ̀lù má bàa tẹ̀ ẹ́, ó mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún òun.
e ÀWÒRÁN: Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi Íjíbítì sílẹ̀, Jèhófà fi mánà bọ́ wọn, kò sì jẹ́ kí aṣọ wọn gbó.