Ìwọ Ha Ń Bọlá fún Iyì Wọn Bí?
LẸ́YÌN tí a ti há àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Áfíríkà mọ́ bí ẹran, tí a sì kó wọn sí ibi ẹlẹ́gbin, tí ń bù tìì, a fi ọkọ̀ òkun wà wọ́n lọ bí ẹrù sí àwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà. A retí pé kí wọ́n tó dé ibi tí a ń kó wọn lọ, ìdajì nínú wọn, ó kéré tán, yóò kú. A ya àwọn mẹ́ńbà ìdílé nípa lọ́nà tí ó fi ìwà òǹrorò hàn, wọn kò sì fojú kan ara wọn mọ́ láé. Òwò ẹrú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíbani nínú jẹ́ jù lọ nínú ìwà ẹranko tí ènìyàn hù sí ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn bẹ́ẹ̀ wáyé nígbà tí àwọn ajagunṣẹ́gun alágbára ńlá fi ìwà òǹrorò tẹ àwọn ọmọ onílẹ̀ tí kò lólùgbèjà lórí ba.
Fífi àbùkù olóroǹbó kan ẹnì kan lè burú ju dída ìkúùkù bò ó lọ. Ó ń bani lọ́kàn jẹ́. Bí a tilẹ̀ ti fi òpin sí òwò ẹrú ní ọ̀pọ̀ jù lọ ilẹ̀, fífojú kéré iyì ẹ̀dá ènìyàn ṣì ń bá a lọ, bóyá ní àwọn ọ̀nà mìíràn tí a kò lè tètè fura sí.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń làkàkà láti kọbi ara sí ìṣílétí Jésù Kristi láti ‘nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn gẹ́gẹ́ bí ara wọn.’ Nítorí náà, wọ́n ń bi ara wọn pé, ‘Mo ha ń bọlá fún iyì àwọn ẹlòmíràn bí?’—Lúùkù 10:27.
A Fi Àpẹẹrẹ Iyì Hàn
Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè kan ti sọ, iyì jẹ́ ànímọ́ tàbí ipò jíjẹ́ ẹni ẹ̀yẹ, ẹni ọlá, tàbí ẹni tí a kà sí. Èyí mà bá ipò Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, Jèhófà Ọlọ́run, mu rẹ́gí o! Ní tòótọ́, léraléra ni Ìwé Mímọ́ so iyì mọ́ Jèhófà àti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀. Mósè, Aísáyà, Ìsíkẹ́ẹ̀lì, Dáníẹ́lì, àpọ́sítélì Jòhánù, àti àwọn mìíràn ní àǹfààní láti rí ìran tí a mí sí ti Ọ̀gá Ògo Jù Lọ àti ààfin rẹ̀ ní ọ̀run, àwọn àpèjúwe wọn sì fi ọlá ọba tí ó kún fún ẹ̀rù àti iyì hàn lọ́nà tí ó bára mu délẹ̀. (Ẹ́kísódù 24:9-11; Aísáyà 6:1; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 1:26-28; Dáníẹ́lì 7:9; Ìṣípayá 4:1-3) Nínú àdúrà ìyìn, Ọba Dáfídì wí pé: “Tìrẹ, Jèhófà, ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ìtayọlọ́lá àti iyì; nítorí ohun gbogbo tí ó wà ní ọ̀run àti ní ilẹ̀ ayé jẹ́ tìrẹ.” (1 Kíróníkà 29:11) Ní tòótọ́, kò sí ẹni tí ọlá àti ìkàsí yẹ fún ju Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ lọ.
Jèhófà fi ẹ̀yẹ, ọ̀wọ̀ ara ẹni, àti iyì tí ó tó jíǹkí ènìyàn ní dídá wọn ní àwòrán àti ìrí ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Nítorí náà, nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ó yẹ kí a bu ọlá àti ọ̀wọ̀ tí ó yẹ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ní ti gidi, a ń fi hàn pé a mọ Orísun iyì ẹ̀dá ènìyàn, Jèhófà Ọlọ́run.—Sáàmù 8:4-9.
Iyì Nínú Ipò Ìbátan Ìdílé
Lábẹ́ ìmísí, àpọ́sítélì Pétérù, tí ó ti láya sílé, ṣí àwọn Kristẹni ọkọ létí láti fún aya wọn ní “ọlá . . . gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera.” (1 Pétérù 3:7; Mátíù 8:14) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé: “Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Nítorí náà, nínú ìgbéyàwó, bíbu ọlá àti ọ̀wọ̀ fún iyì alábàáṣègbéyàwó ẹni jẹ́ ohun tí Bíbélì béèrè. Àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà fi èyí hàn?
Bí omi ṣe ń fún ọ̀gbìn tí ń dàgbà ní okun, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tí ó kún fún oore ọ̀fẹ́ àti ìwà onínúure láàárín ọkọ àti aya, ní gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀, ṣe ń fún ipò ìbátan tímọ́tímọ́ wọn lókun. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ gbàkanṣubú, ọ̀rọ̀ èébú tàbí ìwọ̀sí, ọ̀rọ̀ àbùkù, irú èyí tí a sábà ń gbọ́ nínú àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n, ń ba ipò ìbátan jẹ́ pátápátá. Wọ́n lè ru ìmọ̀lára tí ń pani lára ti àìníláárí, ìsoríkọ́, àti ìkórìíra sókè; wọ́n tilẹ̀ lè dá ọgbẹ́ ìmọ̀lára tí kò lè tètè san pàápàá sínú ẹni.
Bíbọlá fún iyì àwọn ẹlòmíràn tún túmọ̀ sí títẹ́wọ́gbà wọ́n bí wọ́n ṣe wà, kí a má gbìyànjú láti sọ wọ́n di irú ẹnì kan tí a ti fọkàn yàwòrán rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tàbí kí a fi wọ́n wé àwọn ẹlòmíràn lọ́nà tí kò yẹ. Èyí ṣe pàtàkì gan-an láàárín ọkọ àti aya. Níbi tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídán mọ́rán wà, tí a sì ń sọ̀rọ̀ fàlàlà láìkọminú, tí kò sí ẹni tí ń bẹ̀rù pé a lè ṣe lámèyítọ́ òun tàbí ṣáátá òun, ipò ìbátan yóò jinlẹ̀ sí i. Nígbà tí ẹnì kan bá lè hùwà bí òun ṣe máa ń hùwà gan-an nínú ìgbéyàwó, nígbà náà, ilé yóò jẹ́ ibi ìsádi ní tòótọ́ lọ́wọ́ ipò ayé lẹ́yìn òde ìdílé, tí ó rorò, tí ó sì ń dáni lágara.
Àwọn ọmọ wà lábẹ́ àṣẹ Ìwé Mímọ́ láti bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì ṣègbọràn sí wọn. Ẹ̀wẹ̀, yóò dára kí àwọn òbí olóye àti onífẹ̀ẹ́ bu iyì fún àwọn ọmọ wọn. Gbígbóríyìn fúnni tọ̀yàyàtọ̀yàyà nítorí ìwà rere tí a hù, àti fífi sùúrù báni wí nígbà tí ó bá pọn dandan, ń ṣiṣẹ́ dáadáa láti mú kí “ìlànà èrò orí Jèhófà” wọni lọ́kàn. Ṣíṣe lámèyítọ́ wọn nígbà gbogbo, kíké rara lé wọn, àti pípè wọ́n ní orúkọ tí ń tẹ́ni, bí “arìndìn” tàbí “òpònú” yóò wulẹ̀ mú wọn bínú ni.—Éfésù 6:4.
Kristẹni kan tí ó jẹ́ alàgbà àti bàbá, tí ń tọ́ àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin mẹ́ta dàgbà, sọ pé: “Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, a ń bá wọn wí jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Rírọra fọwọ́ tọ́ni àti fífojú kìlọ̀ fúnni ti tó lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ìbáwí tí ó ju ìyẹn lọ bá pọn dandan, a óò ṣe é ní kọ̀rọ̀ yàrá, kò ní jẹ́ níbi tí àwọn ọmọ mìíràn wà. Nísinsìnyí tí àwọn ọmọ ti dàgbà, ìbáwí kan fífún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ àti ti ọlọ́gbọ́n láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìbámu pẹ̀lú ohun tí olúkúlùkù nílò. A ń gbìyànjú láti pa àṣírí mọ́ nínú ọ̀ràn ara ẹni wọ̀nyí, a sì ń tipa báyìí fi ọ̀wọ̀ hàn fún ẹ̀tọ́ tí ọmọ kọ̀ọ̀kan ní sí ọ̀ràn ara rẹ̀ àti iyì rẹ̀.”
Ohùn mìíràn tí a kò ní láti gbójú fò dá ní ìjẹ́pàtàkì ìwà ọmọlúwàbí nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe láàárín ìdílé. Kò yẹ kí ìfararora mú wa gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ bí “jọ̀wọ́,” “ẹ ṣeun,” “mo tọrọ gáfárà o,” àti “ẹ má bínú.” Ìwà ọmọlúwàbí ṣe pàtàkì nínú pípa iyì ara ẹni mọ́ àti nínú bíbọlá fún àwọn ẹlòmíràn.
Nínú Ìjọ Kristẹni
Jésù wí pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.” (Mátíù 11:28) Àwọn tí a ni lára, àwọn tí ó sorí kọ́, àní àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá, fà mọ́ Jésù lọ́nà tí kò ṣeé dá lẹ́kun. Àwọn àlùfáà àti aṣáájú tí wọ́n jẹ́ ọ̀fẹgẹ̀ àti olódodo lójú ara wọn nígbà náà ṣáátá wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n rí i pé Jésù buyì tí ó yẹ àwọn fún àwọn.
Ní fífarawé Jésù, àwa pẹ̀lú fẹ́ láti jẹ́ orísun ìtura fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Èyí túmọ̀ sí wíwá àǹfààní láti gbé wọn ró nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. Ó jẹ́ ohun yíyẹ nígbà gbogbo láti máa jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ onínúure tí ó tọkàn wá, tí ó sì gbéni ro pọ̀ nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wa. (Róòmù 1:11, 12; 1 Tẹsalóníkà 5:11) A ń fi hàn pé a bìkítà nípa ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn nípa ṣíṣọ́ ohun tí a ń sọ àti ọ̀nà tí a gbà ń sọ ọ́. (Kólósè 4:6) Ìmúra àti ìrísí bíbójúmu ní àwọn ìpàdé Kristẹni tún ń fi ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tí a ní fún iyì Ọlọ́run wa, ìjọsìn rẹ̀, àti àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa, hàn.
Jésù bọlá fún iyì àwọn ènìyàn àní nígbà tí ó ń sìn wọ́n pàápàá. Kò fìgbà kan gbé ara rẹ̀ ga láti lè rẹ àwọn ẹlòmíràn sílẹ̀ tàbí láti lè tẹ́ wọn. Nígbà tí adẹ́tẹ̀ kan wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún ìwòsàn, Jésù kò lé ọkùnrin yìí, kí ó sọ pé ó jẹ́ aláìmọ́ àti aláìníláárí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sọ ọ́ di ẹni àpéwò nípa dídarí àfiyèsí sí ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí adẹ́tẹ̀ náà bẹ Jésù pé, “Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́,” Ó buyì fún adẹ́tẹ̀ náà ní sísọ pé, “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.” (Lúùkù 5:12, 13) Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun àgbàyanu tó fún wa láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́, kí a sì tún mú un dá wọn lójú pé wọn kì í ṣe ẹrù ìnira fún wa, ṣùgbọ́n pé a nílò wọn, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn! Lọ́pọ̀ ìgbà, nínú ayé, a ń gbójú fo àwọn onítìjú, àwọn tí ó sorí kọ́, àti àwọn aláàbọ̀ ara, a ń dìídì yẹra fún wọn, a sì ń tẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí wọ́n rí ìbákẹ́gbẹ́ tòótọ́ àti ìtẹ́wọ́gbà nígbà tí wọ́n bá wà láàárín àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wọn. A gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa láti fi kún ẹ̀mí yìí.
Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àwọn tirẹ̀,” ó sì “nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin” láìka ìkù-díẹ̀-káàtó àti ìwà wọn sí. (Jòhánù 13:1) Ó rí i pé wọ́n ní ọkàn-àyà mímọ́ gaara àti ìfọkànsìn pátápátá sí Bàbá rẹ̀. Bákan náà, kò yẹ kí a rò pé àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa ní ète búburú lọ́kàn láé, kìkì nítorí pé wọ́n kò ṣe nǹkan bí àwa ì bá ti ṣe tàbí nítorí pé ìṣe wọn tàbí ìwà wọn ń bí wa nínú. Ọ̀wọ̀ tí a ní fún iyì àwọn arákùnrin wa yóò sún wa láti nífẹ̀ẹ́ wọn, kí a sì gbà wọ́n bí ìwà wọn ti rí, kí a ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé àwọn pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì ń fi ète mímọ́ gaara sìn ín.—1 Pétérù 4:8-10.
Àwọn alàgbà, ní pàtàkì, yẹ kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọ́n má baà kó àníyàn tí kò nídìí bá àwọn tí a fà lé wọn lọ́wọ́ láti bójú tó. (1 Pétérù 5:2, 3) Nígbà tí wọ́n bá ń jókòó pẹ̀lú mẹ́ńbà ìjọ kan tí ó ti ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, yóò dára kí àwọn alàgbà mú kí inú rere àti ìgbatẹnirò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ́n tù ú lára, kí wọ́n sì yẹra fún bíbèèrè àwọn ìbéèrè tí kò bára dé láìnídìí. (Gálátíà 6:1) Àní nígbà tí ìbáwí lílágbára bá yẹ, wọn yóò máa bá a nìṣó láti bọlá fún iyì àti ọ̀wọ̀ ara ẹni tí ó tọ́ sí oníwà àìtọ́ náà.—1 Tímótì 5:1, 2.
Pípa Iyì Ara Ẹni Mọ́
Nítorí tí a dá wa ní àwòrán àti ìrí Ọlọ́run, a ní láti fi àwọn ànímọ́ ọlá ńlá ti Ọlọ́run hàn—títí kan iyì rẹ̀—nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ dé ìwọ̀n tí ó bá ṣeé ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Bákan náà, títẹ̀lé àṣẹ náà láti “nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀” ń béèrè pé kí a ní iyì ara ẹni àti ọ̀wọ̀ ara ẹni dé ìwọ̀n tí ó wà déédéé. (Mátíù 22:39) Òtítọ́ náà ni pé bí a bá fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn fi ọ̀wọ̀ hàn fún wa, kí wọ́n sì buyì fún wa, a gbọ́dọ̀ fi hàn pé a yẹ fún un.
Pípa ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́ mọ́ jẹ́ kókó pàtàkì kan nínú pípa ọ̀wọ̀ ara ẹni àti iyì ara ẹni mọ́. Ẹ̀rí ọkàn tí a ti sọ dẹ̀gbin àti oró ẹ̀bi tí a ní lè yọrí sí ìmọ̀lára àìníláárí, ìjákulẹ̀, àti ìsoríkọ́. Nítorí náà, bí ẹnì kan bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan tí ó wúwo, ó yẹ kí ó gbé ìgbésẹ̀ kíá láti ronú pìwà dà, kí ó sì wá ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí ti àwọn alàgbà, kí ó bàa lè gbádùn “àsìkò títunilára . . . láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.” Ìtura náà tún kan jíjèrè iyì ara ẹni àti ọ̀wọ̀ ara ẹni padà.—Ìṣe 3:19.
Síbẹ̀, ó sàn láti máa sapá nígbà gbogbo láti dáàbò bo ẹ̀rí ọkàn wa tí a ti fi Bíbélì kọ́, kí a má ṣe yọ̀ǹda kí ohunkóhun kó àbààwọ́n bá a tàbí kí ó sọ ọ́ di ahẹrẹpẹ. Lílo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́—jíjẹ, mímu, ṣíṣiṣẹ́ ajé, ṣíṣeré ìnàjú, nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà kejì—yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pa ẹ̀rí ọkàn mímọ́ mọ́, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ògo Ọlọ́run àti iyì rẹ̀ yọ nínú ìgbésí ayé wa.—1 Kọ́ríńtì 10:31.
Bí ẹ̀bi tí a ní nítorí àwọn àṣìṣe wa kò bá kúrò lọ́kàn wa ńkọ́? Tàbí bí àwọn ìwà ìkà tí a ti hù sí wa bá ṣì ń dùn wá? Ìwọ̀nyí lè wó iyì ara ẹni wa palẹ̀, kí ó sì mú wa sorí kọ́ gidigidi. Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ Ọba Dáfídì tí ó wà nínú Sáàmù 34:18, ti tuni nínú tó: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là!” Jèhófà múra tán, ó sì ṣe tán láti gbé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ró nígbà tí wọ́n bá ní láti kojú ìsoríkọ́ àti ìmọ̀lára àìníláárí. Rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i àti wíwá ìrànlọ́wọ́ àwọn tí ó tóótun nípa tẹ̀mí, irú bí àwọn Kristẹni òbí, àwọn alàgbà, àti àwọn mìíràn tí wọ́n dàgbà dénú nínú ìjọ, ni ọ̀nà tí a lè gbà jèrè ọ̀wọ̀ ara ẹni wa àti iyì ara ẹni wa padà.—Jákọ́bù 5:13-15.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a ní láti wà lójúfò sí mímọ ìyàtọ̀ láàárín iyì ara ẹni àti ìgbéraga. Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ ni pé kí a “má ṣe ro ara [wa] ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí [a] bàa lè ní èrò inú yíyèkooro, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pín ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún un.” (Róòmù 12:3) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ohun yíyẹ láti mú ọ̀wọ̀ ara ẹni dàgbà, a kò fẹ́ láti ro ara wa ju bí a ṣe mọ lọ tàbí kí a má mọ ìyàtọ̀ láàárín iyì ẹ̀dá ènìyàn àti ìmọtara-ẹni-nìkan pẹ̀lú ipá àṣerégèé tí àwọn kan ń sà láti pa iyì wọn mọ́ lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn lójú méjèèjì.
Bẹ́ẹ̀ ni, níní ọ̀wọ̀ fún iyì àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ohun tí a ń béèrè lọ́wọ́ Kristẹni. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, gbogbo wọ́n yẹ fún ọ̀wọ̀ wa, ọlá wa, àti ìkàsí wa. Jèhófà ti fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní iyì àti ọlá tí ó tó, tí a gbọ́dọ̀ mọ̀, kí a sì pa mọ́. Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, a gbọ́dọ̀ mú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ dàgbà fún iyì àti ọlá tí kò lẹ́gbẹ́ tí Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà Ọlọ́run, ní.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn èwe lè fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn aláàbọ̀ ara